Lesson 269 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “È̩ṣẹ awọn ẹlomiran a mā han gbangba, a mā lọ ṣaju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mā tẹle wọn” (1Timoteu 5:24).Cross References
I Labẹ Ofin
1. Ẹni naa ti o dẹṣẹ kan si ẹnikeji rè̩ dẹṣẹ si Oluwa pẹlu, Lefitiku 6:2, 3; Numeri 5:6
2. Ironupiwada si Ọlọrun n fẹ ki a dá ohun gbogbo ti a ti fi aitọ gbà lọwọ ẹlomiiran pada pẹlu idamarun un ohun naa, Lefitiku 6:4. 5; Numeri 5:7
3. Bi a kò ba le ni anfaani lati ṣe atunṣe naa fun oluwarẹ tabi ibatan rè̩, a ni lati san an pada fun Oluwa, Numeri 5:8
II Igba Ayé Awọn Woli
1. È̩ṣẹ ati iwa buburu a maa fa ikú wa sori ọkàn; ṣugbọn yiyipada kuro ninu è̩ṣẹ, ṣiṣe atunṣe ati ririn pẹlu ikiyesara ati lai lẹṣẹ a maa fun ọkàn ni iye ainipẹkun, Esekiẹli 33:14-16
III Igba Aye Oore-ọfẹ
1. Jesu fi hàn gbangba pe gbogbo ẹni ti o ba fẹ ba Ọlọrun laja ni lati ba arakunrin wọn laja pẹlu, Matteu 5:23, 24
2. Iyipada Sakeu fi hàn pe o ṣe e ṣe ki Ọlọrun da wa lare ṣiwaju atunṣe bi a ba fi otitọ ọkàn ṣeleri niwaju Rè̩ pe a o ṣe atunṣe naa, Luku 19:8 9
Notes
ALAYÉPataki itumọ ọrọ ti a n pe ni atunṣe ni dida pada; paapaa ju lọ dida ohun-olohun pada fun ẹni ti o ni in; fifi ohun ti o kaju dipo eyi ti o sọnu tabi ti o bajẹ. Jakejado Bibeli ni a ri i bi atunṣe ti fara kọ ipadabọ ẹlẹṣè̩ kuro lọna è̩ṣẹ lati sìn Ọlọrun otitọ ati alaaye. Nigbà pupọ ti eniyan ba ṣẹ si Ọlọrun ni awọn eniyan miiran a maa jiya nitori è̩ṣẹ naa. Igba gbogbo ni idakeji ọrọ yìí jẹ otitọ. Nigba ti eniyan ba ṣẹ si ẹni keji rè̩ o ṣẹ si Ọlọrun pẹlu nitori pe o ti ru ọkan ninu ofin Ọlọrun. Ọlọrun a maa fi è̩ṣẹ ti a ṣè̩ si I ji tọkantọkan, nigba ti a ba jẹwọ awọn è̩ṣẹ naa; ṣugbọn O n fẹ ki a ṣe atunṣe fun ẹni ti a ti pa lara tabi ti a ṣe aitọ si nipa è̩ṣẹ naa.
Ofin Ọlọrun
Dida ohun-olohun pada fun un tabi atunṣe wà ninu awọn ofin ti a fi fun ni ni Oke Sinai. Eniyan ni lati da ohun-olohun ti o ti sọ di ti rè̩ lai tọ tabi ti o ti ji pada ni ọjọ ti o ba mu ẹbọ ẹbi wa fun Oluwa. Ofin ṣe ilana pe ohunkohun ti eniyan ba fi èrú, ẹtan tabi arekereke gbà, ki o da a pada ni oju owo rè̩, ki a si fi idamarun un rè̩ le e pẹlu.
Bi ẹni kan ba ṣẹ si aladugbo rè̩ nipa jija a ni ole, aladugbo rè̩ tilẹ le ṣe alaimọ pe o ti ja oun ni ole; tabi bi o tilẹ mọ, o ṣe e ṣe ki o má ri ẹni ti yoo jẹri gbe e lati mu ẹlẹbi wa si idajọ. Bi kò ba si ẹlẹri, bi ẹni ti a fi sùn naa ba sé̩ ẹsùn ti aladugbo rè̩ fi sùn un, ẹsùn naa ki yoo duro niwọnbi o ti jẹ ilana ni ile idajọ awọn Ọmọ Israẹli pe a ni lati ri to ẹlẹri meji tabi ju bẹẹ lọ ki a to le da ẹni ti a fi sùn lẹbi. S̩ugbọn ti Ile Ẹjọ Ododo ti Ọlọrun yatọ si eyi. Ọlọrun mọ ọkàn olukuluku eniyan, O si mọ gbogbo è̩ṣẹ ti a da; nitori naa ẹni ti o ba mu ẹbọ ẹbi rè̩ wa, ti o si n beere fun idariji kikún fun irekọja rè̩ ki yoo jẹ itẹwọgba lọdọ Oluwa titi yoo fi ṣe atunṣe gbogbo iwa aitọ ti o ti hù si aladugbo rè̩.
Ofin igbesi-aye ododo ga bakan naa, -- o tilẹ ga ju bẹẹ lọ -- labẹ Oore-ọfẹ ju labẹ Ofin lọ. Iyipada ọkàn ati atunṣe jẹ apakan ninu Ihinrere bakan naa. Nigba ti eniyan ba ri igbala, oun yoo jẹwọ, yoo si da ohunkohun ti o ba ji pada bi o ba ti ja ẹnikẹni ni ole; yoo tọrọ idariji, bi o ba ti purọ, tabi ti o ba ti ṣeke, tabi ki o ti sọrọ eniyan ni buburu lai tọ, tabi lọnakọna ti o ba gba ṣè̩ si ẹlomiiran ninu ọrọ tabi iṣe. Ọlọrun beere eyi lọwọ olukuluku eniyan, ṣugbọn Oun yoo fun ni ni agbara ati oore-ọfẹ lati mu un ṣẹ. Ẹnikẹni ti o ba ni idalẹbi tootọ fun è̩ṣẹ rè̩ yoo ṣafẹri lati bọ lọnakọna, ohunkohun ti o wu ki o gba a, ki yoo si ka atunṣe si inira. Yoo fi tayọtayọ ṣe ohun gbogbo ti o yẹ lati bọ kuro labẹ ẹru è̩ṣẹ. Kò ṣe anfaani lati sọ wi pe a fi gbogbo ọkàn, gbogbo àyà, gbogbo inu ati gbogbo agbara fẹ Oluwa afi bi ifẹ naa ba mu ki ohun atijọ ki o kọja lọ, ki o si ti fun un ni anfaani lati ṣe atunṣe fun gbogbo aṣiṣe atẹyinwa.
Ọna ti O Dọgba
Laaarin gbogbo atako awọn eniyan ati eṣu paapaa lati igba nì titi di oni-oloni, Ọrọ Ọlọrun kò yipada. Awọn Ọmọ Israẹli gbiyanju lati lọ itumọ Ọrọ yii ki o ba le bá ifẹ ati igbesi aye è̩ṣẹ wọn dọgba, ṣugbọn awọn Woli Ọlọrun duro bi oluṣọ lati kilọ fun awọn eniyan pe Ọrọ Ọlọrun kò yipada. Awọn Ọmọ Israẹli, ni akoko isinru wọn ni ilẹ Babiloni nitori è̩ṣẹ ati ibọriṣa wọn, sọ fun Woli Esekiẹli pe ọna Ọlọrun kò gún; ṣugbọn bi a ba fara balẹ ka Iwe Mimọ, a o ri i bi ibalo Ọlọrun pẹlu awọn ọmọ eniyan lati irandiran ti dọgba ti o si jẹ alailẹgan to.
Ọlọrun ṣe alaye idọgba eto Rè̩ fun Esekiẹli bayi pe: “Bi emi ti wà, ni Oluwa ỌLỌRUN wi, emi kò ni inu-didun ni ikú enia buburu; ṣugbọn ki enia buburu yipada kuro ninu ọna rè̩ ki o si yè” (Esekiẹli 33:11). Oluwa wi pe ododo olododo kì yoo gba a la ni ọjọ irekọja rè̩, bẹẹ ni oun kì yoo la nipa ododo rè̩ ni ọjọ ti o dẹṣẹ. Ọpọlọpọ eniyan ro pe a o gbe iṣẹ ododo ti ara wọn si apa kan iwọn Ọlọrun, a o si gbe buburu wọn si apa keji. Eyikeyi ti o ba tẹwọn jù -- ibaa ṣe iṣẹ ododo tabi iṣẹ è̩ṣẹ ni wọn lero wi pe yoo fi ibi ti wọn yoo gbe lo ayeraye hàn, ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun kò fi idi ero bẹẹ mulẹ. Ọrọ Ọlọrun wi pe, “Nitori ẹnikẹni ti o ba pa gbogbo ofin mọ, ti o si rú ọkan, o jẹbi gbogbo rè̩” (Jakọbu 2:10).
Lọna miiran ẹwẹ, Ọlọrun ayeraye, Ẹni ti gbogbo ọna rè̩ dọgba, ti ṣe ilana wi pe eniyan buburu kì yoo kú nitori iwa buburu rè̩ ni ọjọ ti o ba yipada kuro ninu iwa buburu rè̩ lati ṣe eyi ti o tọ ati eyi ti o yẹ niwaju Oluwa. S̩ugbọn lati fi ironupiwada atọkanwa hàn, a beere lọwọ ẹni ti o ti jẹ eniyan buburu lẹẹkan ri lati “mu ògo padà, ti o si san ohun ti o ti jí padà, ti o si nrìn ni ilana ìye, li aiṣe aiṣedẽde” (Esekiẹli 33:15). Eto kan ha le dọgba jù eyi lọ? Ọkàn aiṣẹtan yoo dahun pe gbogbo ọna Ọlọrun ni o dọgba – gbogbo rè̩ ni o dọgba lai si abuku!
Ironupiwada Tootọ
Ni ọjọ wọnni ti ohun Johannu Baptisti n dun bi agogo ninu iju, ti o n kede imurasilẹ fun ifarahan Messia, otitọ Ọlọrun wọ ọkàn awọn eniyan lọ ṣinṣin. Iwaasu naa kò le, ṣugbọn ire ti o ṣe tobi jọjọ: “Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dè̩dè̩” (Matteu 3:2). Ogunlọgọ eniyan ni o tọ Johannu lọ lati gbọ iwaasu iyanu rè̩ ati lati gbe igbesi aye ododo ti o fi han fun wọn. Awọn Farisi, ti wọn n pe ara wọn ni olododo, ti wọn si jé̩ ẹlẹsin igba naa wá lati gbọ iwaasu naa pẹlu; ṣugbọn Johannu mọ ọkàn è̩ṣẹ wọn, nitori naa o pe wọn nija wi pe: “Ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada” (Matteu 3:8). Ironupiwada tootọ a maa so eso ti a le fi mọ ọn yatọ, i baa ṣe ni igbesi-aye awọn ọmọluwabi tabi ni igbesi-aye awọn ti wọn jé̩ ẹlẹṣẹ paraku.
Igbala Sakeu, ọlọrọ agbowo-ode jẹ apẹẹrẹ ironupiwada tootọ. Lẹẹkan ri o jẹ ẹni ti gbogbo eniyan mọ ni ẹlẹṣẹ, eyi si fara han nipa kikùn ti awọn eniyan ti o wa pẹlu Jesu n kùn wi pe O lọ wọ si ile ẹlẹṣẹ; ṣugbọn Sakeu ki i ṣe ẹlẹṣẹ mọ. Sakeu wá ọna lati ri Jesu, ṣugbọn kò ṣe laalaa lasan. Olukuluku ẹni ti o ba wá Jesu ni tootọ, o daju pe wọn yoo ri I. Sakeu si fara pamọ sori igi sikamore kan, ṣugbọn ni ibi kan laarin ilẹ ati ori igi ti o gbe wà lọhun, igbala Ọlọrun duro de e. Jesu wi fun awọn eniyan pe, “Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là” (Luku 19:10).
Ki ni awọn ẹri ati eso igbala Sakeu? O gba Oluwa si ọkàn ati ile rè̩ tayọtayọ -- ọna kan ṣoṣo ti a fi le gba Oluwa tootọ. Kò fẹ ki ohun kan paala saarin oun ati igbala -- kò tilẹ gba ọrọ rè̩ laye pẹlu. “Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi è̩sun èke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin” (Luku 19:8). Agbowo-ode ọlọgbọn-ẹwẹ yii fi tayọtayọ dá ohun ti o ti fi èrú gba pada ni ilọpo mẹrin. Igbala Ọlọrun a maa mu ki eniyan fẹ lati dá ohun-olohun pada.
Ìlàjà
Ikorira ati arankan jé̩ è̩ṣẹ ti kò le wà ninu ọkàn Onigbagbọ. Ifẹ ni ẹmi igbagbọ gan an, iru igbagbọ bẹẹ kò si le fara mọ ọkàn igbẹsan ati alainifẹ. Jesu sọ asọye lori eyi nigba ti O sọ bayii pe, “Bi iwọ ba nmu è̩bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakọnrin rẹ li ohun kan ninu si ọ, fi è̩bun rẹ silẹ nibè̩ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ ba arakọnrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn è̩bun rẹ” (Matteu 5:23, 24). O ṣe anfaani lati duro diẹ ni ijọsin wa si Ọlọrun, ki a ba le ba arakunrin wa lajà, ju pe ki a maa jọsin pẹlu idalẹbi ni ookan aya wa.
Ẹri ti a kò le Sé̩
Anfaani miiran ti o niyelori pupọ ninu ilana Ọlọrun nipa atunṣe ni pe o maa n fun ẹni ti a ba ṣe atunṣe fun ni ẹri ti o daju, nigba pupọ ni o jẹ wi pe iru ẹni bẹẹ ki ba ti ni anfaani lati gbọ itan Ihinrere lọna miiran. Ọpọ awọn ti o wà ni ipo giga ninu ayé kò mọ ohun ti igbagbọ le ṣe ninu igbesi-aye eniyan; ṣugbọn nigba ti a ba jẹwọ aṣiṣe ti a si ṣe atunṣe fun wọn, otitọ yii yoo di mimọ fun wọṅ pe Ọlọrun ti yi ọkàn ati igbesi-aye kan pada. Ẹsin ti o ba mu ki a san gbese ti a jẹ, ki a dá ohun ti a ji pada, ki a si jẹwọ irọ ti a ti pa ati iwa buburu ti a ti hu, beere ifọkantan lati ọdọ awọn eniyan aye.
Ile Idajọ Ododo ti Ọrun
Ipa kan ninu atunṣe ni mimu ohunkohun ti a ti fi pa ẹlomiiran lara wa si titọ. Iru aitọ bẹẹ le jẹ è̩ṣẹ si awọn ẹgbẹ oniṣowo tabi ile iṣẹ tabi riru ofin ilu. Ẹni ti a ṣẹ si le ṣai mọ, ṣugbọn ẹni ti o dẹṣẹ naa kò lẹtọ lati ṣalai ṣe atunṣe fun un. Ki i ṣe igba gbogbo ni ofin ilẹ wa ni odiwọn nipa atunṣe. Fun apẹẹrẹ, ofin ilu fi akoko silẹ laarin eyi ti a gbọdọ san awọn gbese kan tabi ti a gbọdọ fi ṣe awọn ojuṣe kan, lẹyin akoko yii ofin naa di alailagbara; ṣugbọn kò si gbese kan ti ofin le bo mọlẹ lọdọ Ọlọrun. Akoko ki i kọja lati ṣe atunṣe fun ojuṣe ti a ti kuna lati ṣe. Awọn ilẹ miiran ni ofin fun ọran gbese nipa eyi ti a le gboju fo gbogbo gbese ti eniyan jẹ dá, bi onigbese naa ba bẹbẹ pe oun kò le ri i san ṣugbọn kò si ẹbẹ fun iru onigbese bẹẹ ti o le fẹsẹmulẹ ni Ibi Idajọ Ododo ti Ọrun. O dara ju lati ṣe gbogbo ẹtọ wọnyi ni aye yii nibi ti a le ri aanu gba ju pe ki a duro de igba ti ọran naa yoo wá siwaju Onidajọ gbogbo ayé ti yoo si ṣe idajọ lai si aanu nigba naa.
Atunṣe ti yoo kó ba awọn ẹlomiiran tabi ti yoo fa ẹlomiiran si ipalara tabi iṣoro jé̩ ọran ti o ṣoro. Bi o ba ṣe iwa ọdaran ni, ohun ti ẹni ti o wá jẹwọ naa ni lati ṣe ni pe ki o jẹwọ eyi ti o ba kan an ninu ọran naa. Ohun ti Ọlọrun n beere lọwọ rè̩ ni eyi. S̩ugbọn nigba miiran o le ṣoro fun un lati mu ọran naa mọ lọdọ ara rè̩ nikan. Yoo gba a ni ọpọlọpọ adura ati diduro de Oluwa lati mọ ohun ti Ọlọrun yoo fẹ ki oun ṣe ninu ọran bẹẹ. O ṣe anfaani lati mu ọrọ bẹẹ tọ alufa Ijọ lọ fun imọran ati iranlọwọ ninu adura. Ni ọpọlọpọ igba ni alufa le fun ẹni ti o fẹ ṣe atunṣe naa ni imọran ti o ṣe iyebiye lọpọlọpọ lati inu iriri rè̩ atẹyinwa.
Igbala lori Adehun
Nigba ti a n wá igbala ni ọran atunṣe saaba maa n yọju nitori pe Ọlọrun ki yoo dari è̩ṣẹ ẹnikẹni ji afi bi oluwarẹ ba n fé̩, bi o ti wà nipa rè̩, lati mu ohun gbogbo ti o ti ṣe lodi si awọn ẹlomiiran wá si titọ. Ọlọrun a maa ṣi ẹlẹṣẹ niye A si maa fi awọn è̩ṣẹ ti ẹni naa ti dá han fun un. Nigba miiran o n gba ọdun pupọ lati ṣe gbogbo atunṣe ti Ọlọrun fi han ni iba iṣẹju diẹ, ṣugbọn Ọlọrun kì yoo fi igbala du oluwarẹ ni gbogbo akoko yii bi ẹni naa ba fi tọkantọkan ṣe ileri fun Ọlọrun pe oun yoo ṣe awọn atunṣe naa. Sakeu ri igbala ki o to ṣe ẹyọ atunṣe kan, ṣugbọn o mọ pe oun ni lati ṣe wọn, o si ṣeleri pe oun yoo ṣe wọn. Bi o ti mu ileri rè̩ ṣẹ, bẹẹ ni igbala rè̩ duro. Tinutinu ni Sakeu fi san ilọpo mẹrin ohun ti o ti fi èrú gba, ṣugbọn kò si ibi kan ninu Bibeli ti o fi han pe Jesu beere pe ki o san ilọpo mẹrin tabi ki o tilẹ mẹnu kan iye ti o jọ bẹẹ. Ibukun pupọ ni Ọlọrun n fun awọn ti igba Ihinrere ti o ti ṣe atunṣe loju owo lai fi ookan le iye owo ohun ti wọn bajẹ.
Ayọ wà ninu ṣiṣe atunṣe. Alaafia Ọlọrun a maa gba ọkàn kan nigbakuugba ti a ba mu ohun ti o ti wọ bọ si titọ. Ọpọlọpọ Onigbagbọ ni o ti jẹri pe inu wọn dun pupọ nigba ti wọn ṣe eyi ti o gbẹhin ninu atunṣe wọn, o dabi ẹni pe ki atunṣe naa má tan, ki wọn ba le maa ni iriri ayọ ti o n tẹle atunṣe.
Questions
AWỌN IBEERE- Bawo ni ẹbọ irekọja ṣe wọ ọran atunṣe labẹ Ofin?
- Eelo ni ẹni ti a palara ri gba ninu atunṣe labẹ Ofin?
- Ta ni a n san gbese fun bi olohun tabi awọn eniyan rè̩ kò ba si laaye mọ?
- Sọ ohun ti Ọlọrun fi han Esekiẹli nipa atunṣe?
- Ọwọ wo ni Jesu fi mu ijẹwọ è̩ṣẹ ati atunṣe?
- Ki ni ero Sakeu nipa atunṣe lẹyin ti o ri igbala?
- Njẹ Ọlọrun n gba ẹni ti kò fẹ ṣe atunṣe là?
- Anfaani pataki wo ni awọn eniyan aye maa n ri gba nigba ti awọn Onigbagbọ ba lọ ṣe atunṣe fun wọn?
- Ki ni anfaani iyebiye ti Onigbagbọ tikararẹ n ri gba?