Deuteronomi 4:9, 10; 6:3-15; Joṣua 24:15; Jobu 1:1-5; Orin Dafidi 78:1-8; Matteu 14:19; 15:36; 1Timoteu 5:4

Lesson 270 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awọn ti o bè̩ru OLUWA mba ara wọn sọrọ nigbakugba; OLUWA si tẹti si i, o si gbọ, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rè̩, fun awọn ti o bè̩ru OLUWA, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rè̩” (Malaki 3:16).
Cross References

I Eredi Rè̩

1. Isin Agbo-ile wà fun ati gbin Ọrọ Ọlọrun ati awọn iṣẹ agbara Rè̩ sinu ọkàn awọn ọmọde, Deuteronomi 4:9, 10; Orin Dafidi 78:1-8

2. Gbogbo ojuṣe eniyan si Ọlọrun ni a ni lati fi kọ ni ninu isin agbo-ile, Deuteronomi 6:3-5

3. Oluwa jé̩ Ọlọrun owu, Oun ki yoo si fi ogo Rè̩ fun ẹlomiiran, Deuteronomi 6:10-15

II Nibo: Ni Ile

1. Ọmọde ni lati kọkọ kọ ibẹru Ọlọrun ninu ile ná, 1Timoteu 5:4; Owe 31:1; Isaiah 38:19; Efesu 6:4; Kolosse 3:21

2. Kikọni ni ẹkọọ nipa ti Ọlọrun ninu ile yoo mu ni tè̩ siwaju si iwa-bi-Ọlọrun, Owe 22:6; Deuteronomi 31:13; 1Awọn Ọba 2:1-4

3. Ile maa n di ibugbe Ọlọrun nipa ijọsin aarin agbo-ile tootọ, Luku 10:38-42; Matteu 18:20

III Akoko Wo: Lojoojumọ

1. A paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati maa kọ awọn ọmọ wọn nigbakuugba ti àyè bá ṣi silẹ, Deuteronomi 6:7

2. A le fi ipilẹ iwa-bi-Ọlọrun lelẹ lọkàn awọn ọmọ kekere paapaa, Isaiah 28:9, 10; Marku 10:14; Johannu 21:15;Iṣe Awọn Apọsteli 2:39

3. Awọn ti o jé̩ jagunjagun nlá nlà fun Ọlọrun ni igba ti wọn, rii pe o ṣe pataki lati maa sin In nigbakuugba, Joṣua 1:8; Jobu 1:1-5; Orin Dafidi 55:17; Daniẹli 6:10; Iṣe Awọn Apọsteli 2:46, 47; 6:4; 12:12

IV Ọna Wo?

1. Ọrọ Ọlọrun ni lati jé̩ koko pataki kan ninu ijọsin agbo-ile, Deuteronomi 6:8, 9

2. Ki ijọsin agbo-ile to le mu ire ti a n fé̩ jade, ẹni ti igbesi-aye rè̩ mọ ti o si jẹ apẹẹrẹ rere ni o ni lati jẹ alakoso rè̩, Joṣua 24:15

3. Ọlọrun ni o n fi Ọrọ naa fun ni; iṣẹ ti awọn eniyan Rè̩ ni lati ṣe ipin-fun-ni rè̩ ni otitọ ati ododo, Matteu 14:19; 15:36

Notes
ALAYÉ

Anfaani

“Ta ni Ọlọrun?” “Nibo ni O n gbe?” “Bawo ni O ti ri?” “Njẹ O fẹran mi?” Ọpọlọpọ iru ibeere ti o tọna báyìí nipa Ọlọrun, wiwa laaye Rè̩ ati iha ti O kọ si ẹda, ni o wà lọkàn olukuluku ọmọde. Ohun kan wà lọkàn awọn ọmọde ti o fẹ sin Ọlọrun, ọmode ti a ba si bi ni ile Onigbagbọ ti a si fi Ọrọ Ọlọrun kọ yoo layọ. Nigba ti a ba fi ọmọde silẹ lati nikan wá idahun si awọn ibeere ọkàn rè̩ wọnyi, eṣu wà ni tosi lati gbe itan asan ati itumọ eke gun un lọwọ ki ọmọ naa má baa ni imọ otitọ. Eredi rè̩ niyi ti isin agbo-ile fi jẹ odi agbara ninu ija pe ki otitọ le bori eke, lati ayebaye, o si ni lati ri bẹẹ titi Jesu yoo fi pada wá si aye yìí lẹẹkeji.

Iran kan si ekeji lati igba ti aye ti ṣẹ titi di wakati yìí, fi idi otitọ yìí mulẹ pe gbogbo eniyan ni a bi si aye yi pẹlu ẹda è̩ṣẹ. Iwa abinibi eniyan ni lati lọ kuro lọdọ Ọlọrun, ki i ṣe lati rin sun mọ Ọn. Titi di igba ti a ba paarọ ẹda abinibi yìí, eniyan kò le bẹrẹsi i ṣe bi Ọlọrun ti n fẹ. S̩ugbọn Ọlọrun ti ṣe ilana fun irapada ọkàn ọmọ-eniyan ati iparun ẹda è̩ṣẹ kuro ninu ọkàn rè̩. “Ọlọrun fẹ araiye tobḝ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun” (Johannu 3:16).

Ki a sọ nipa ẹda, ọmọ-eniyan kò ni ẹtọ si ẹbun iyanu Ọlọrun yìí, bẹẹ ni wọn kò si le ri igbala afi bi wọn ba wá a tọkantọkan. A bi eniyan pẹlu agbara ti o mu ki o ṣe e ṣe fun ni lati sin Ọlọrun alaaye ati otitọ, ṣugbọn ki o to le sin Ọlọrun, a ni lati kọ ọ ni ọna ti yoo fi le ri Ọlọrun. Bi a ba ti tete bẹrẹsi i kọ ni ni ẹkọ yìí to ni anfaani fun irapada ọkàn naa yoo ti pọ to. Bibeli sọ bayi pe “Tọ ọmọde li ọna ti yio tọ: nigbati o si dàgba tan, ki yio kuro ninu rè̩” (Owe 22:6).

Iṣẹ Òbi

Ofin Mose fi dandan le e fun olukuluku obi lati kọ awọn ọmọ rè̩ ni iṣẹ iyanu Ọlọrun ati ofin ti Ọlọrun fun wọn lati maa ṣakoso igbesi-aye wọn. Ọlọrun kò fi ara Rè̩ han lori Oke Sinai fun anfaani awọn ti a ṣẹṣẹ dá silẹ loko ẹru Egipti nikan, ṣugbọn fun awọn iran-iran Israẹli ti o n bọ lẹyin. Majẹmu ti a dá ni Sinai wà fun gbogbo iru-ọmọ Abrahamu, lati igba Mose titi di igba Kristi. Awọn Ọmọ Israẹli a maa ni ayọ pupọ ati ọpọ ibukun, nipa ti ara, niwọn igba ti wọn ba pa ofin Ọlọrun mọ. Nigba ti awọn baba ba tọ Ọlọrun lẹyin tọkantọkan, ti wọn si jẹ ki awọn ọmọ wọn mọ ohun ti Ọlọrun n beere lọwọ wọn, ti awọn ọmọ naa ba si fara balẹ lati tẹle ẹkọ baba wọn, ti wọn si n sin Oluwa tọkantọkan, nigba naa ni ibukun Oluwa yoo jẹ ti wọn lati iran-de-iran. Ilana Ọlọrun ni eyi lati ayebaye. S̩ugbọn eto yìí a maa bajẹ nigba ti awọn baba ba kuna lati kọ awọn ọmọ wọn ni ilana Oluwa, tabi ti awọn ọmọ ba kuna lati rin ni ọna iwa-bi-Ọlọrun ti a tọ wọn si.

Isin agbo-ile jẹ ọkan ninu awọn ọna ti o dara ju lọ lati kọ awọn ọmọde ni imọ Ọlọrun, ati lati dahun awọn ibeere ti o jẹ awọn ọmọde lọkàn gidigidi. Ọlọrun ka kikọ awọn ọmọde ni ilana Ọlọrun si ohun pataki to bẹẹ ti o fi paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati maa sọ asọye nipa ọna ati ọrọ Oluwa “nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọna, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide” (Deuteronomi 6:7). Itumọ eyi ni pe, wọn ni lati kọ awọn ọmọ wọn nigbakuugba ti aye ba ṣi silẹ.

Idunnu Ọlọrun

Itan aanu ati ifẹ iyanu Ọlọrun ni awọn obi ni lati fi kọ awọn ọmọ wọn: itan idasilẹ nlá nlà ati aabo Ọlọrun. Ọlọrun Israẹli wà ni tosi, a le ri imisi Ẹmi Rè̩, a si le gbọ ohun Rè̩. Ki ni ṣe ti awọn baba ki yoo fi sọ fun awọn ọmọ wọn nipa Ẹni naa ti o han gbangba pe O ni inudidun si alaafia wọn? Ọlọrun ran awọn Ọmọ Israẹli leti nipa eyi nigba ti o wi pe, “Orilẹ-ède nla wo li o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn to, bi OLUWA Ọlọrun wa ti ri ninu ohun gbogbo ti awa kepè e si? . . . Kiki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o mā fi wọn kọ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ” (Deuteronomi 4:7, 9).

Dajudaju yoo jẹ anfaani fun awọn Onigbagbọ ode oni lati mu awọn ọrọ itọni wọnyi lati inu Ofin lo. Awọn ti o ba ṣe aapọn lati kọ awọn ọmọ wọn ni ẹkọ ibẹru ati ifẹ Ọlọrun lati inu ọkàn ti o kún fun iriri ati imọ Ọlọrun, yoo ni ibukun Ọlọrun ni igbesi-aye wọn; ṣugbọn obi ti o ba kuna ninu ojuṣe pataki yìí yoo ri idajọ ati ibinu Ọlọrun nikẹyin igbesi-aye rè̩. Ọlọrun sọ fun Esekiẹli pe, “Bi oluṣọ na bá ri ti idà mbọ, ti ko si fun ipè, ti a kò si kilọ fun awọn enia; bi idà ba de, ti o ba si mu ẹnikẹni lārin wọn, a mu u kuro nitori aiṣedẽde rè̩, ṣugbọn ẹjẹ rè̩ li emi o bere lọwọ oluṣọ na” (Esekiẹli 33:6). Dajudaju Oluwa ti fi iṣẹ oluṣọ ati itọju ile ati ẹbi le awọn obi lọwọ.

Ẹkọ ti o Tọna

Aye yìí i ba jẹ ibi idunnu ati alaafia bi ẹbi Onigbagbọ kọọkan ba ṣe e fọkantan fun Ọlọrun gẹgẹ bi O ti fọkantan ẹbi Abrahamu! Ki ni Ọlọrun sọ nipa Abrahamu? “Mo mọ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rè̩ ati fun awọn ara ile rè̩ lẹhin rè̩, ki wọn ki o ma pa ọna OLUWA mọ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u” (Gẹnẹsisi 18:19). Ẹkọ taara lati inu Ọrọ Ọlọrun a maa fi ipilẹ iṣẹ iwa-bi-Ọlọrun lelẹ ninu igbesi-aye awọn ọmọde, awọn ọdọmọkunrin ati awọn ọdọmọbinrin; ṣugbọn nigba pupọ ni awọn obi n kuna lati fiyesi ikilọ pataki yìí.

S̩e ayẹwo aṣeyọri ti isin agbo-ile ti mu ba ọpọlọpọ awọn eniyan ti o ti rin ninu ọna tooro ati ọna hiha lọ si Ọrun. Wo bi anfaani naa ti pọ to lati ni pẹpẹ adura ninu ile. Ogunlọgọ ọkàn ni o wà ni Ọrun nitori pe a fi ẹsẹ wọn le ọna rere ni ibẹrẹ irin ajo wọn si ilu Ọrun nipa isin agbo-ile. Ohun ti ọpọ ninu awọn alufa Ọlọrun le ranti nipa ibẹrẹ igbesi-aye wọn ni awọn itan Bibeli ti baba tabi iya wọn sọ fun wọn lati inu Ọrọ Ọlọrun. Ọpọ ninu awọn ajihinrere ti n sọ itan igbala fun awọn eniyan ti o wà ninu okunkun ni ilẹ keferi ni o jẹ wi pe ni ayika ile baba wọn ni wọn ti gbọ ti wọn si mọ itan Ihinrere. A kò le sọ ire ti isin agbo-ile n ṣe tan: awọn oṣiṣẹ Ihinrere, awọn olukọ Ile-ẹkọ Ọjọ isinmi, awọn ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn kò lọ si ilu okeere, awọn olorin ti o ti fi ara wọn ji fun isin Ọlọrun. Ẹri wọn n dún bi agogo pe: “Ninu isin agbo-ile ni mo gbe kẹkọọ nipa Jesu nigba ti mo wà ni ọmọde” tabi, “Mo ri igbala nigba ti baba ati iya mi n ba mi gbadura lori pẹpẹ adura ninu ile wa.” Olukuluku obi i ba jẹ le ṣaapọn lati ṣe iṣẹ ti o leso pupọ yìí! Ọlọrun sọ fun wa pe: “Mā ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ rẹ; mā duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ ọrọ rẹ là” (1Timoteu 4:16).

“Ni ipo Kristi”

A sọ fun wa ninu Bibeli pe, “Awọn ọmọ ni ini OLUWA” (Orin Dafidi 127:3). Ọlọrun ni o fi itọju ọkàn ti ki i kú yìí sabẹ itọju awọn obi fun iwọnba ọdun diẹ. Iṣẹ awọn obi gan an ni lati kọ ọkan ti a fi sabẹ itọju wọn nipa Ọlọrun, wọn si ni lati fi gbogbo ipa wọn kọ ọ fun Ọlọrun. Ẹda è̩ṣẹ ti o wà ninu ọmọde yoo le e kuro lọdọ Ọlọrun afi bi a ba le kọ ọ lati mọ anfaani pupọ ti o wa ninu iwa-bi-Ọlọrun ati ijiya ti o muna ti o n tẹle iwa buburu.

Awọn ẹlomiiran le maa beere igba wo ni o yẹ lati bẹrẹsi kọ awọn ọmọde nipa Ọlọrun ati awọn ohun Ọrun. Woli Isaiah, nipa imisi Ẹmi Ọlọrun, sọ pe a ni lati bẹrẹsi kọ ọmọde ni imọ Ọlọrun diẹdiẹ gé̩ré̩ ti a ba ti ja a lẹnu ọmu. Jesu sọ nipa awọn ọmọ-ọwọ ti a gbe wá sọdọ Rè̩ pe, “Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun” (Luku 18:15, 16). Gé̩ré̩ ti ọmọ kekere ba ti bẹrẹsi ọrọ sisọ, ki ni ṣe ti awọn obi rè̩ ki yoo maa ba a sọrọ nipa awọn ohun ti o dara ju – awọn ohun ti Ọlọrun? Lai pẹ ti ọmọde ba ti bẹrẹsi sọrọ ni yoo di ẹni ti o le ronu, nipa bẹẹ Otitọ Ọlọrun yoo tàn sinu ọkàn ọmọ naa nigba ti awọn eniyan kò tilẹ lero pe eyi le ri bẹẹ. Ki i ya ju lati bẹrẹsi kọ ọmọde nipa ohun ti i ṣe ti Ọlọrun, ṣugbọn ewu wà bi a ba pẹ ju lati bẹrẹ. Awọn ile-iwe asiko yìí ti fi ọgbọn ẹwẹ mu ki ẹkọ odi idagbasoke (eyi ti wọn fi n wi pe awọn ohun ẹlẹmi gbogbo titi kan ẹranko ati eniyan, dagba soke diẹdiẹ lati inu nnkan bi legbenlegbe wá), ati pe “kò si Ọlọrun,” wọ inu ẹkọ, ani lati ọdọ awọn ọmọ alakọbẹrẹ pẹlu. Bi ko ṣe pe ọmọ rẹ ba ni imọ ti o yanju nipa Ọlọrun ki o si ni igbẹkẹle ninu Ọrọ Ọlọrun, a le bi igbagbọ rè̩ wó.

Maa ka Ọrọ Ọlọrun si awọn ọmọ rẹ leti nigba gbogbo, ki ẹ si jumọ maa sọ asọye nipa itan didun wọnni ti o wà ninu Bibeli. Fi ipilẹ ifẹ ati ọwọ fun Ọrọ Ọlọrun mulẹ ṣinṣin ninu ọkàn wọn. Maa tẹnumọ anfaani iyebiye ti o wà ninu sisin Ọlọrun fun ẹbi rẹ, si gba olukuluku wọn niyanju lati maa gbadura. Ọlọrun ti ṣeleri pe Ọrọ Oun ki yoo pada tọ Oun wà ni ofo.

Ojoojumọ

Igba meloo ni a gbọdọ ni isin agbo-ile? Nipa kika Ọrọ Ọlọrun ni akaye, o han gedegbe pe, o kere ju lọ, a gbọdọ ni isin agbo-ile lẹẹkan loojọ. Awọn ajagun nipa igbagbọ fi ọwọ danindanin mu ọran yìí. Ohun ti Abrahamu i maa kọ ṣe nigbakuugba ti o ba ṣí de ibugbe miiran ni lati té̩ pẹpẹ si Ọlọrun, ki oun ati awọn ẹbi rè̩ le ri ibi ti wọn yoo gbe maa gbadura nigba gbogbo ni gbogbo akoko ti wọn yoo fi wà nibẹ. Ni kutukutu owurọ ni Jobu n ji lati rú ẹbọ sisun fun awọn ọmọ rè̩ nigba gbogbo. Dafidi kọ akọsilẹ pe, “Li alẹ, li owurọ, ati li ọsán, li emi o ma gbadura, ti emi o si ma kigbe kikan: on o si gbohùn mi” (Orin Dafidi 55:17). Daniẹli pẹlu gbadura nigba mẹta loojọ, Ọlọrun si jẹri si adura rè̩ gidigidi.

Awọn ẹbi miiran a maa pejọ ni owurọ lati jọsin ki wọn to jade ati ni alẹ nigba ti wọn ba pada de si ile. Awọn ẹbi miiran n ṣe isin agbo-ile ti wọn ni owurọ nikan, awọn miiran a si maa ṣe ti wọn ni alẹ. Otitọ Ọlọrun fara han kedere. Gẹgẹ bi awọn ọmọ Israẹli ti n kó manna wọn ni oroowurọ, afi ni Ọjọ Isinmi nikan, bakan naa ni Onigbagbọ ni lati jẹ Ounjẹ tootọ ti o ti Ọrun sọkalẹ, lati le fun ẹmi rè̩ lagbara. Eniyan Ọlọrun tootọ yoo sa ipa rè̩ lati pese ounjẹ ẹmi fun awọn ara ile rè̩ ati fun ara rè̩ pẹlu. Iyawo Kristi – Obinrin oniwa rere – “dide nigba ti ilẹ kò ti imọ, a si fi onjẹ fun enia ile rè̩, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbirin rè̩” (Owe 31:15).

Nipa Apẹẹrẹ

Ẹda a maa kọ ọpọlọpọ awọn ọmọ rè̩ nipa apẹẹrẹ, bakan naa ni Onigbagbọ ni lati kọ awọn ọmọ ti rè̩. O rọrun fun ọmọde ti o ni baba ati iya ẹni iwa-bi-Ọlọrun tootọ lati fi ṣe apẹẹrẹ. Jọṣua fi apẹẹrẹ iwa-bi-Ọlọrun tootọ lelẹ fun awọn ọmọ rè̩; o si sa ipa rè̩ lati ri i pe awọn ọmọ naa rin ni ọna Ọlọrun. O sọ bayii fun awọn Ọmọ Israẹli pe, “Ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sin li oni . . . ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sin” (Joṣua 24:15). Ni aye atijọ awọn baba ni o jẹ aṣaaju nipa kikọ awọn ọmọ wọn nipa ti Oluwa. Ki ni ṣe ti awọn baba fi le ni ero pe wọn le fi iṣẹ pataki yii le ẹlomiiran lọwọ lati ba wọn ṣe e, loni? Gẹrẹ ti itara ba wọ inu awọn baba nipa isin agbo-ile, ti wọn si n kọ awọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin nipa Ọlọrun ati iṣẹ iyanu Rè̩, isọji yoo wọ inu Ijọ -- a o si maa kọ orukọ titun silẹ ninu Ogo lati ọjọ de ọjọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti isin agbo-ile fi jé̩ koko pataki ninu iṣẹ-isin Onigbagbọ si Ọlọrun?
  2. Igba meloo ni a gbọdọ maa ṣe isin agbo-ile?
  3. Bawo ni Jobu ṣe n ṣe ijọsin rè̩ fun awọn ọmọ rè̩ ọkunrin ati obinrin?
  4. Ta ni ninu awọn ajagun fun Ọlọrun ti o sọ bayii pe, “Bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sin?”
  5. Bi ẹni kan ba jẹ oloootọ nipa kikọ awọn ọmọ rè̩ ni ilana Ọlọrun, ki ni ileri ti Ọlọrun ṣe fun iru ẹni bẹẹ?
  6. Sọ oriṣiriṣi ohun ti o sọ Abrahamu di ẹni pataki nipa ti Ọlọrun.
  7. Igba meloo ni Daniẹli n gbadura loojọ? Fi ẹsẹ Bibeli kan gbe ọrọ rẹ lẹsẹ.
  8. Ki ni aṣẹ ti Ọlọrun pa fun awọn Ọmọ Israẹli nipa kikọ awọn Ọmọ wọn?