Lesson 271 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ki olukuluku nyin ki o fẹran aya rè̩ bẹ gẹgẹ bi on tikararè̩; ki aya ki o si bẹru ọkọ rè̩” (Efesu 5:33).Cross References
I Idasilẹ Ilana Igbeyawo lati ọwọ Ọlọrun
1. Ilana Ọlọrun nipa igbeyawo wà lati ipilẹṣẹ aye, Gẹnẹsisi 2:18-24; Matteu 19:4-6; Marku 10:6-9
2. Nigba ti ọkan ninu awọn mejeeji ba kú nikan ni majẹmu igbeyawo dopin, Gẹnẹsisi 2:24; Malaki 2:14; Matteu 19:6-8; Marku 10:7-9; 1Kọrinti 7:10-13, 27, 39; Romu 7:2, 3
3. Onigbagbọ kò gbọdọ bá alaiwa-bi-Ọlọrun dapọ ni igbeyawo, 1Kọrinti 7:39; 2Kọrinti 6:14; Gẹnesisi 24:3, 4; 28:1; Deuteronomi 7:2-4; Joṣua 23:11-13; Ẹsra 9:11, 12; Nehemiah 13:23-27
4. Ẹni ti o ba di onigbagbọ tootọ lẹyin ti o ti gbeyawo kò le kọ aya tabi ọkọ rè̩ silẹ nitori pe o jé̩ alaigbagbọ, Gẹnẹsisi 2:24; Matteu 19:5, 6; Marku 10:6-9; 1Kọrinti 7:10, 12-16
5. Ọwọ danindanin ni Ọlọrun fi mu ojuṣe ti O n beere lọwọ tọkọ-taya, Efesu 5:22-33; 1Kọrinti 7:3
II Ọlọrun kọ Ikọsilẹ ati Atungbe Iyawo
1. Ọlọrun fi aye silẹ fun ẹnikẹni lati fi ẹni keji silẹ nitori ohun kan ṣoṣo; ṣugbọn ilana pipe ti O ti ṣe ni atetekọṣe kò fi aye silẹ fun ikọsilẹ rara, Matteu 5:32; 19:3-9; ati Marku 10:11, 12; fi we Deuteronomi 24:1-3; 1Kọrinti 7:10, 11, 27
2. Igbeyawo pẹlu ẹlomiiran niwọn igba ti ẹni akọkọ wà laaye jẹ panṣaga, Matteu 5:31, 32; 19:9; Marku 10:11, 12; Luku 16:18; Romu 7:3
3. Ọlọrun yoo mu idajọ kikoro wá sori awọn ti o ba ru ofin Rè̩ lori ọrọ yii, Matteu 15:19, 20; Marku 7:20-23; Galatia 5:19, 21; 1Kọrinti 5:11-13; 6:9, 10, 18; 10:8; Efesu 5:3, 5; Malaki 3:5; Heberu 13:4; Jakọbu 4:4; 2Peteru 2:14-17; Ifihan 2:22
Notes
ALAYÉIlana Ọlọrun ati Iha ti Eniyan Kọ Si I
Igbeyawo jé̩ asopọ ti o wà titi di ọjọ ikú. Bibeli kọ wa pe ikú ọkọ tabi ti aya nikan ni o le fi opin si majẹmu igbeyawo. O sọ pato pe: “Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn” (Marku 10:9; Malaki 2:14). (Ka 1Kọrinti 7:39 pẹlu). Ilana Ọlọrun ni eyi lati ipilẹṣẹ nigba ti Ọlọrun fun ọkunrin iṣaaju ni oluranlọwọ ti o dabi rè̩, a si le ri i ninu awọn ẹkọ Kristi pe ilana Ọlọrun ni eyi fun awa ti ode-oni. Lai si aniani, ilana Ọlọrun ti kò ni yipada lae ni eyi.
O ti di iwa ọmọ eniyan lati maa fi oju tinrin ofin ati ilana Ọlọrun lọna kan tabi lọna miiran. Iwa abuku yii mu ki iwa buburu gba aye kan ni akoko kan to bẹẹ ti Ọlọrun fi pa ọpọlọpọ eniyan run kuro lori ilẹ. Lẹyin ti omi ti gbẹ kuro lori ilẹ, Ọlọrun ba awọn ti o dá si dá majẹmu pe Oun ki yoo fi omi pa aye rẹ mọ. O si ṣeleri ibukun ati anfaani pupọ fun awọn ẹni ti o ba pa majẹmu Rè̩ mọ ti wọn si rọ mọ ileri Rè̩. S̩ugbọn kò pẹ ti eniyan tun bẹrẹ si ṣe afojudi si Majẹmu ti Ọlọrun ba wọn dá, awọn eniyan si bẹrẹsi fa sẹyin kuro ninu iwa rere, iwa jagidijagan si bẹrẹ si gbilẹ lati igba naa wa.
Ọlọrun ti mu ipinnu ti Rè̩ ṣẹ -- ipa ti Rè̩ ninu Majẹmu naa, -- bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan ti da Majẹmu yii niye igba ati awọn majẹmu miiran ti O ba oniruuru eniyan inu aye dá. Ọlọrun fi aanu ati ododo ba Orilẹ-ede Ayanfẹ ni lo, ṣugbọn nigbakuugba ni wọn n ṣọtẹ, nikẹyin wọn ṣe ohun ti o buru jai ju lọ nigba ti wọn kọ ireti igbala wọn ti wọn si fi Ọmọ Ọlọrun kọ sori igi.
Awọn Keferi pẹlu ti ni anfaani ti wọn, lati gba Ọba Ifẹ tabi lati kọ Ọ; ṣugbọn lọna pupọ ni awọn paapaa ti kọ Ọba Ifẹ yii, ẹni ti O sanwo irapada wọn. Jesu sọ asọtẹlẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe è̩ṣẹ yoo gbilẹ kan, paapaa ju lọ nigba ti bibọ Rè̩ lẹẹkeji sinu aye ba kù si dẹdẹ. O sọ bayii pe, “Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bḝni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia. Nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn ngbeyawo, nwọn si nfà iyawo fun ni, titi o fi di ọjọ ti Noa wọ inu ọkọ lọ, kikun omi si de, o si run gbogbo wọn. Gẹgẹ bi o si ti ri li ọjọ Lọti; nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn nrà, nwọn ntà, nwọn ngbìn, nwọn nkọle; ṣugbọn li ọjọ na ti Lọti jade kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru rọ lati ọrun wá, o si run gbogbo wọn. Gẹgẹ bḝni yio ri li ọjọ na ti Ọmọ-enia yio farahàn” (Luku 17:26-30).
A le ri imuṣẹ awọn ọrọ asọtẹlẹ wọnyi lọjọ oni. Iwa ibajẹ awọn eniyan inu aye ti n pọ si i, paapaa ju lọ lati ọdun melo kan sẹyin, a si woye pe ni tootọ, eyi jẹ apẹẹrẹ pe ipadabọ Ọmọ Ọlọrun kù si dẹdẹ.
Igba le yipada, àṣà ọmọ-eniyan pẹlu le yipada gẹgẹ bi ọjọ ti n yi lu ọjọ. Ọmọ-eniyan le ṣe aibikita ki wọn si ṣá ọna Ọlọrun tì -- ọna ti o tọ ti o si dara ju – ki wọn si yan ọna ti yoo té̩ ifẹkufẹ ọkàn wọn lọrun. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọrun, Ilana Ọlọrun, ati Ofin Rè̩ yoo wà bakan naa titi lae. Ọlọrun sọ ni atetekọṣe pe ọkunrin yoo fi baba ati iya rè̩ silẹ, yoo si fa mọ aya rè̩ (kì i ṣe awọn aya rè̩), awọn mejeeji yoo si di ara kan. Ọrọ Ọlọrun yii kò yipada sibẹ. O wà bakan naa loni.
Ainaani Ilana Ọlọrun ati Idajọ Ọlọrun
Johannu Baptisti tako è̩ṣẹ panṣaga nigba ti ijoye kan gba iyawo ẹlomiiran lati fi ṣe aya (Matteu 14:3, 4). È̩ṣẹ panṣaga jẹ eyi ti a kọ ni lati yẹra fun, a si fi ifẹ Ọlọrun han gbangba ninu awọn apẹẹrẹ ti Ọlọrun lò lati fi aiṣootọ Israẹli wé ọkunrin alaiṣootọ ti o lọ fé̩ obinrin ajeji tabi ti o ṣubu sinu è̩ṣẹ panṣaga (Malaki 2:11-15). Nigba ti Dafidi ṣubu sinu è̩ṣẹ yii, o fi aye silẹ fun orukọ Ọlọrun lati di isọrọ odi si laaarin awọn keferi, o si fa idajọ Ọlọrun sori ara rè̩ nitori è̩ṣẹ yii (2Samuẹli 12:13, 14).
Jesu bá obinrin ara Samaria sọrọ titi o fi jẹwọ fun Jesu pe alabagbe kárùn-ún ti oun ni ki i ṣe ọkọ oun (Johannu 4:16-18). Ẹmi Mimọ pẹlu, lati ẹnu Paulu Apọsteli kọ wa pe awọn ti o ba dá è̩ṣẹ buburu ti i ṣe panṣaga ki yoo ni ipa ninu Ijọba Ọrun afi bi wọn ba ronupiwada ti wọn si kọ ọna è̩ṣẹ wọn silẹ (1Kọrinti 6:9; Galatia 5:19-21; 2Peteru 2:14-17).
Ibi pupọ ninu Ọrọ Ọlọrun ni o tako iwa abuku ti awọn eniyan n hu si igbekalẹ ti Ọlọrun ṣe fun gbogbo araye. Ọpọlọpọ ni o n lọ awọn ẹkọ Bibeli lọrun, awọn miiran si n ṣa a tì ki wọn ba le bo è̩ṣẹ wọn mọlẹ. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọrun duro, idajọ Ọlọrun yoo si wá sori gbogbo ẹni ti o ba dẹṣẹ yii bi o tilẹ jẹ pe ofin ilu tabi aṣa ibilẹ fi àyè silẹ fun panṣaga.
Igbeyawo Tootọ
Ọrọ Ọlọrun yanju lori igbeyawo. Ọlọrun sọ fun wa pe ki i ṣe ifẹ Oun pe ki awọn eniyan Oun ki o fi aidọgba dapọ mọ awọn alaigbagbọ (2Kọrinti 6:14). (Ka 1Kọrinti 7:10-16 pẹlu). Ọlọrun sọ wi pe igbeyawo ni ọla (Heberu 13:4) ṣugbọn O ti ṣe ikilọ gidigidi nipa ojuṣe aya si ọkọ rè̩ ati ojuṣe ọkọ si aya rè̩ (Efesu 5:22-33; Romu 7:1-3; 1Kọrinti 7:2-6, 10-16, 27-33).
Gẹgẹ bi a ti sọ tẹlẹ, Ọlọrun kò gba ikọsilẹ tọkọ-taya láàyè ninu ilana Rè̩, nitori awọn idi pataki diẹ si ni Ọlọrun ṣe fi aye silẹ fun ipinya. Ikú nikan ni o le tú awọn meji ti Ọlọrun ba so pọ ṣọkan ká. Ifarabalẹ lati ṣe akiyesi ilana Ọlọrun yii ni finnifinni ati ni ẹkunrẹrẹ yoo bojuto gbogbo iṣoro, yoo si yanju gbogbo adiitu. Ọlọrun bu ọla fun gbogbo igbeyawo. Kò di igba ti alufa Ọlọrun so wọn pọ, tabi ti a ṣe ni ile Ọlọrun, niwọn igba ti igbeyawo naa ba ti ba Ọrọ Ọlọrun mu ti kò si lodi si ofin ilu tabi ofin ibilẹ ibi ti a gbe ṣe igbeyawo naa.
A le ri bayii pe igbeyawo ti Ọlọrun kò fi ọwọ si ni awọn wọnni ti a ṣe laaarin awọn eniyan meji lẹyin ti ẹni kan ninu wọn tabi awọn mejeeji ti ṣe igbeyawo pẹlu ẹlomiiran tẹlẹ ri, ti ẹni keji wọn iṣaaju si wà laaye sibẹ. Nitori naa, niwọn igba ti ọkọ tabi aya ti o tọna fun ẹni ti o ba fẹ ṣe igbeyawo ba wà laaye, è̩jé̩ igbeyawo iṣaaju wa sibẹsibẹ, igbeyawo keji kò tọna, o si lodi si aṣẹ Ọlọrun. Iru igbeyawo bẹẹ ni a n pe ni panṣaga. Ide igbeyawo iṣaaju wà sibẹ, ikú nikan ni o le tu u; igbeyawo miiran lẹyin eyi si jẹ aifi igbeyawo iṣaaju pè.
Iṣoro pupọ ni o dojukọ ojiṣẹ Ọlọrun ti a fi iṣẹ ati maa gba awọn ẹni ti eṣu, ọta wa ẹmi ti fi è̩ṣẹ ti o wọpọ yii dè ni igbekun, niyanju. Eniyan Ọlọrun tootọ yoo gbadura pupọ yoo si yẹ ọran igbeyawo naa wo finnifinni lati wo bi o ba eto Ọlọrun mu. Aṣẹ Ọlọrun ati ilana ti O fi lelẹ lati atetekọṣe nipa igbeyawo saba maa n tó lati sọ boya igbeyawo kan tọna tabi kò tọna. Ifihan ifẹ Ọlọrun yii ni atọna ati odiwọn ti awa, gẹgẹ bi ẹni kọọkan, ni lati lo lati fi diwọn iriri wa ati ọna wa, ki igbesi-aye wa ba le jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun, ki iwa wa si le jẹ alailẹgan niwaju gbogbo eniyan. Nitori naa, “Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni” (Isaiah 8:20).
Questions
AWỌN IBEERE- Sọ ilana ti Ọlọrun ṣe ni atetekọṣe nipa igbeyawo ati bawo ni awọn ohun ti o beere ti lagbara tó?
- Darukọ diẹ ninu awọn ajagun fun Ọlọrun ninu Bibeli ti wọn tako è̩ṣẹ panṣaga; ki o si sọ ni ede ti rẹ, ohun ti olukuluku wọn sọ nipa rè̩.
- Nigba wo, ati ni igba kan ṣoṣo wo ni ide igbeyawo n tú?
- Njẹ o di igba ti a ba ṣe igbeyawo ni ile Ọlọrun tabi niwaju alufaa nikan ki Ọlọrun to fi ọwọ si i pe iru igbeyawo bẹẹ tọna? Sọ idi ti o fi dahun bẹẹ.
- Ojuṣe wo ni Ọlọrun n beere lọwọ aya si ọkọ rè̩?
- Ojuṣe wo ni Ọlọrun n beere lọwọ ọkọ si aya rè̩?
- Irú igbeyawo wo ni kò tọna niwaju Ọlọrun?
- Bi a ba fẹ ṣe igbeyawo ki ni Ọlọrun sọ ti a gbọdọ ṣe akiyesi? Sọ ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o fi idi idahun si ibeere yii mulẹ ninu Kọrinti keji.
- Njẹ Ọlọrun fi àyè silẹ ni atetekọṣe fun ikọsilẹ?
- Ki ni idahun ti obinrin ara Samaria fun Jesu nigba ti O sọ fun un lati lọ pe ọkọ rè̩ wá? Ki ni ṣe ti Jesu fi sọ pe o fesi rere?