Matteu 5:23, 24, 43-48; 18:15, 21, 22; Marku 11:23-26; Romu 12:9, 10, 14, 17, 19-21

Lesson 272 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi ẹnyin ba fi è̩ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi è̩ṣẹ ti nyin ji nyin. S̩ugbọn bi ẹnyin ko ba fi è̩ṣẹ awọn enia ji wọn, Baba nyin ki yio fi è̩ṣẹ ti nyin ji nyin” (Matteu 6:14, 15).
Cross References

I Didariji-ni Tinutinu

1. Didariji arakunrin wa ni lati ṣiwaju biba Ọlọrun laja, Matteu 5:23, 24; 18:15; Marku 11:25, 26.

2. Idariji-ni ti kò niwọn jé̩ ohun ti o ṣe pataki, Matteu 18:21, 22

3. Ohun idena igbagbọ ní lati kuro ki a to le ri idahun gba lati ọdọ Ọlọrun, Marku 11:23-26.

II Ifẹ Aiṣẹtan

1. Ni ifẹ otitọ si awọn ara, Romu 12:9, 10; 1Johannu 3:11-19; 4:7-11, 20, 21.

2. Fé̩ awọn ọta rẹ, Matteu 5:43; Romu 12:14.

3. Fi rere san ibi, Matteu 5:44; Romu 12:17, 19-21.

4. Ọlọrun fé̩ ẹlẹṣẹ, Matteu 5:45-48; Romu 5:8

Notes
ALAYÉ

Ilaja S̩aaju

“Nitorina bi iwọ ba nmu è̩bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ, Fi è̩bun rẹ silẹ nibè̩ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn è̩bun rẹ” (Matteu 5:23, 24).

Nihinyi, Jesu n ṣe apejuwe Ọmọ Israẹli kan ti o mu ẹbọ rè̩ wá si ibi pẹpẹ ti o si n duro de akoko ti alufaa yoo wa gba ẹbọ náà lọwọ rẹ. Ni akoko ọwọ yii, bi o ti n reti lati ri idariji Ọlọrun gba nipa irubọ, o ranti lojiji pe arakunrin kan ni ohun kan ninu si oun. Ki ni ki o ṣe? Njẹ o yẹ ki o wi pe, “Lẹsẹkẹsẹ ti mo ba ti ru ẹbọ yii tan, emi yoo lọ taara sọdọ arakunrin mi lati ṣe ilaja pẹlu rè̩?” Rara o, ki o to gbé iṣisẹ miiran, ani ki o to bun ẹbun rè̩ -- o ni lati lọ ṣe ilaja ki o to ṣe irubọ bi o tilẹ gba pe ki o fi ẹbun rè̩ silẹ nibi pẹpẹ.

Fifi ẹbun silẹ nibi pẹpẹ le jẹ ẹbun iṣẹ-isin tabi talẹnti ti a yọọda fun Oluwa. Iṣẹ-isin rẹ si Ọlọrun kò nilaari bi iwọ ba ni ohun kan ninu si ẹni kan, tabi ti iwọ ba ni arankan tabi ikoro ọkàn si ẹlomiiran. Bi iwọ ba n kọrin tabi o n gbadura, tabi o n ṣiṣẹ ninu ile-iṣẹ ijọ, tabi oniwaasu, ti o si ni ohun kan ninu ọkàn rẹ si arakunrin rẹ, o san ki o má tilẹ ṣiṣẹ fun Ọlọrun rara. O ni lati ba arakunrin rẹ laja, ki o si yanju ọrọ naa ki ẹbun rẹ to le jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun.

Ohun kekere nì ti awọn eniyan gba laye ninu ọkàn wọn ni kò jẹ ki wọn ni iṣẹgun. Eyi ni ohun ti o n ja wọn lole ẹmi, agbara ati iṣẹgun ni igbesi-aye wọn, wọn kò si le ni itẹsiwaju ninu Ihinrere afi bi wọn ba mu un wa si ibi pẹpẹ, ti wọn si jọwọ rè̩ sibẹ. Bi ẹni kan ba wá si ibi pẹpẹ ti o si ranti pe arakunrin oun ni ohun kan ninu si oun, o ni lati fi ẹbun rè̩ silẹ nibi pẹpẹ, ki o lọ bá arakunrin rè̩ laja, ki o si pada wa lati bun ẹbun rè̩, nigba naa ni ẹbun rè̩ yoo si jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun.

Irẹlẹ ninu Ilaja

Ninu ẹkọ nipa idariji, Bibeli kò beere ẹni ti o jẹbi. Ohun ti Ọrọ Ọlọrun beere ni pe, ki a ṣe ilaja ati atunṣe lọnakọna bi o ti wu ki o ri. Nigba miiran o gba ọpọlọpọ oore-ọfẹ Ọlọrun lati rẹ ara ẹni silẹ niwaju arakunrin tabi arabinrin, aladugbo tabi iyekan titi de oju àmi ti a o fi le wi pe, “Nitootọ, mo ti ro pe emi ni o jare, ṣugbọn emi ni o jẹbi. Jọwọ dariji mi.” O ṣe e ṣe ki ẹlomiiran ti ni aṣiro nipa ohun ti o ṣe bi o tilẹ jẹ pe ọkàn otitọ ni o fi ṣe e; ṣugbọn bi o ba fi ohun idigbolu si ọna ẹlomiiran, o ṣe dandan lati ṣe ilaja.

Idariji

Ẹmi aini-dariji jé̩ ohun ti o buru jai. Bi o tilẹ jẹ pe a ti ṣẹ ẹni kan ni è̩ṣẹ ti o buru ju ki o si ro pe oun jare lati ni ikoro ọkàn ati ẹtanu si ẹlomiiran, ko si afo fun aini-dariji ninu ọkàn onigbagbọ. Jesu sọ wi pe “Bi ẹnyin ba fi è̩ṣẹ awọn enia jì wọn, Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi è̩ṣẹ ti nyin jì nyin. S̩ugbọn bi ẹnyin ko ba fi è̩ṣẹ awọn enia ji wọn, Baba nyin ki yio si fi è̩ṣẹ ti nyin jì nyin” (Matteu 6:14, 15).

Idena Adura

Awọn ẹlomiiran ni idena ti kò jẹ ki ohùn wọn ja gaara, tabi ki eti wọn gbọran daradara, tabi ki oju wọn riran kedere, tabi ki wọn le rin kiakia. Nigba miiran awọn eniyan ní ohun ti o dena adura wọn. “Bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun ki yio si dari è̩ṣẹ nyin ji nyin” (Marku 11:26). Iwọ le ni igbagbọ ti o le ṣi awọn oke nidi, ṣugbọn ki yoo si idahun si adura rẹ afi bi o ba ni ọkàn idariji. “Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ dariji” – nigba naa ni ọna yoo la taara fun igbagbọ rẹ, iwọ yoo si ri idahun lati ọdọ Ọlọrun wa. Awọn oke kì yoo ṣidi titi iwọ yoo fi mu irugbin ija kuro. Gẹgẹ bi o ti n ri bi a ba tẹ awọn okùn duuru kan ti ohun wọn dọgba ti yoo mu ki ohun wọn dun pọ, bẹẹ gẹgẹ ni iṣọkan laarin awọn ara yoo mu ki Ẹmi Ọlọrun maa ṣiṣẹ laarin wọn. Iwọ kò le wà ni iṣọkan pẹlu Ọlọrun nigba ti ọkàn rẹ kò ṣe deedee pẹlu arakunrin rẹ.

Nini-eniyan Sinu

Nigba miiran awọn eniyan a maa ro, wọn a si maa wi pe wọn ti dari aṣiṣe arakunrin wọn jì, ṣugbọn ninu ọkàn wọn lọhun wọn ni arakunrin naa sinu. Jẹ ki wọn da orukọ ẹni ti o ti ṣẹ wọn ri, lẹsẹkẹsẹ ọkàn wọn a tun ta wuyẹ si oluwarẹ ni ikorira. Kò ni le fi ọkàn tan an mọ, ohun ti yoo sọ ni pe, “ki i ṣe ẹjọ mi, o ti ja mi tilẹ nigba kan.” Peteru beere pe, mo ha ni lati dariji “titi di igba meje?” Kristi dahun pato pe “Emi kò wi fun ọ pe, Titi di igba meje, bikoṣe Titi di igba ādọrin meje” (Matteu 18:21, 22).

Oore-ọfẹ lati Dariji

“Bi arakunrin rẹ ba ṣè̩, ba a wi; bi o ba si ronupiwada, dari ji i. Bi o ba si ṣẹ ọ li ẹrinmeje li õjọ, ti o si pada tọ ọ wá li ẹrinmeje li õjọ pe, Mo ronupiwada; dari ji i” (Luku 17:3, 4). Jesu kò kọ wa lati ni ẹmi ifarada tabi fifi ọwọ yọbọkẹ mu ọran è̩ṣẹ dida laaarin ara wa si ara wa. Bi arakunrin rẹ ba ṣẹ, ba a wi; bi o ba ronupiwada, dariji i. Nigba ti iwọ ba si dariji i, gbagbe è̩ṣẹ rè̩. Eyi gba oore-ọfẹ. Eyi yii yoo gba pe ki o gbadura fun ọpọ oore-ọfẹ lati ṣe eyi nì. Iwọ le dariji i lẹẹkan; bi o ba tun ṣẹ ọ lẹẹkeji yoo gba iranwọ oore-ọfẹ lati tun dariji i. Bi o ba tun ṣè̩ ọ nigba kẹta, mo gbagbọ pe iwọ ki yoo sọ oore-ọfẹ rẹ nu nitori eyi, bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ? Bi o ba tọ ọ wá nigba kẹta fun idariji, njẹ iwọ yoo wi pe, “Emi ki yoo dariji?” Bi iwọ ba ri i pe iwọ kò le dariji, lọ sori eekun rẹ ki o si gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki oore-ọfẹ Rè̩ to fun ọ. Bi a ba fẹ gbọran si aṣẹ Jesu, ohun ti a gbọdọ ṣe ni eyi.

Ofófó

Nigbakuugba ti arakunrin rẹ ba ṣẹ ọ, o ti mọ ohun ti o yẹ lati ṣe: “ba a wi” -- kì i ṣe pẹlu è̩tanú bi kò ṣe pẹlu ifẹ ará. Bi ẹni kan ba wá sọdọ rẹ ti o si n ṣẹ si arakunrin rè̩ nipa sisọ ọrọ rè̩ ni buburu lẹyin rè̩, ranti pe eyi yii buru bi ẹni pe iwọ gan an ni o n sọrọ rè̩ ni buburu. Ba a wi! Iru kan naa ni ẹni ti ahọn rè̩ n sọrọ botiboti ati ẹni ti o n tẹti lelẹ lati gbọ. Ofófó a maa dá ija silẹ, awọn ti o ba si n gbọ ni lati ṣe atako rè̩. Oluwa korira “ẹniti ndá ija silẹ larin awọn arakunrin” (Owe 6:19).

Ifẹ Pipe

O rọrun lati fẹran awọn kan. Awọn agbowo-ode fẹ awọn ti o fẹ wọn. O si tun rọrun lati dariji awọn kan – bi wọn ba jẹ ọrẹ wa. S̩ugbọn aṣẹ Jesu ni pe, “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti o nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin” (Matteu 5:44). Njẹ iwọ le ni ifẹ si ẹni ti o purọ mọ ọ, ti o ba ọ lorukọ jẹ? Njẹ o le dariji ẹni ti o rẹ ọ jẹ, ti o si tun n dá ṣiọ rẹ? Njẹ iwọ le ṣe oore fun un bi aye rè̩ ba ṣí silẹ? Tabi iwọ n sọrọ rè̩ kiri?

Nigbakuugba ti iwọ ba ri ọta rẹ ninu aini, ran an lọwọ. Boya ero rẹ ni pe ki yoo gba pe ki o ran oun lọwọ, njẹ o ti fi lọ ọ ná? Boya o le wi pe ẹlẹṣẹ ni – Jesu bá awọn agbowo-ode ati ẹlẹṣẹ jẹun. Ọlọrun n rọ ojo Rè̩ sori awọn alaiṣododo. Itanṣan oorun n tan si awọn ẹlẹṣẹ gẹgẹ bi o ti n tan si awọn eniyan mimọ. Bi iwọ ba n ṣe oore fun awọn ọrẹ rẹ nikan, ki ni iwọ fi yatọ si awọn agbowo-ode? “Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pé” (Matteu 5:48).

Ẹni kan ti o Dariji

Agbara Ihinrere lati yi ọkàn ẹda pada ati lati fi ẹmi idariji sibẹ hàn gedegbe ninu itan igbesi-aye ọkunrin kan ti o ti tẹwọn de, ẹni ti gbogbo eniyan n pe ni “Aarundinlaadọta” fun ọpọlọpọ ọdun. Ki i ṣe ọpọ eniyan ni o ti i ni anfaani lati dariji ẹlomiiran ti o ga to eyi ti a ṣe si arakunrin yii ti o si dariji.

Nigba ti o wà ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun, o fi ilu rè̩ Providence ni Erekuṣu Rhode silẹ, o si lọ si agbegbe iwọ oorun. Ni alẹ ọjọ kan o ba ọkọ kekere kan wọ ilu Tacoma, ni gé̩ré̩ ti a ti pa eniyan kan nibẹ. A mu un, a ba a ṣẹjọ, a si sọ ọ si ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn pẹlu iṣẹ aṣekara.

Fun ọdun pupọ ni o fi jiya gidigidi, iru iyà ti o tọ si ọdaran ti o buru ju lọ. Lẹyin ọdun mọkanlelogun a da a silẹ ninu tubu pẹlu “ara hẹrẹpẹ ati iyè ti o ti fẹrẹ ra, kò nile, kò lọrẹ, kò ni orukọ.” Wọn fun un ni iwe ti yoo fi wọ ọkọ de ilu Portland. Fun ọjọ mẹrin gbako, o n rin kiri ilu Portland, o n wa iṣẹ, kò si ounjẹ ti yoo jẹ, bẹẹ ni kò si ibi ti yoo fi ori rè̩ lé lati sun. Nikẹyin o pinnu lati lọ bé̩ sinu odo lori afárá ti o wà ni adugbo Burnside. Oluṣọ afárá ri i, o si fa a pada, ó wi fun un pe, “Rara o, má dan an wo.” Bi ọgbẹni “Aarundinlaadọta” yii ti n kọja lọ, o ri akọle ile-isin Apostolic Faith. O dabi ẹni pe o wà laaarin awọn ojulumọ rè̩ nigba ti o wọ ile isin lọ.

Ni alẹ ọjọ naa, alufaa waasu nipa ọmọ oninakuna. Lẹyin iwaasu “Aarundinlaadọta” nawọ soke fun adura, o si lọ si ibi pẹpẹ lati gbadura; Ọlọrun si “wẹ ọkàn rẹ mọ bi sno.” Ni alẹ ọjọ kan bi o ti n sọ itan igbesi-aye rè̩ ati iyipada ti o ni, ọkunrin kan joko lẹyin, o n gbọ ẹri rè̩. Ọkunrin naa sare sọkalẹ, o si ba ti rè̩ lọ. Ẹni ti o ti ba alejo yii sọrọ sọ fun “Aarundinlaadọta” pe ọkunrin naa mọ nnkankan nipa rè̩.

Ọgbẹni “Aarundinlaadọta” wá ọkunrin yii lọ si ilu San Francisco nibi ti o ti gbe ri i ni ile itọju awọn alaisan ti Ilu ati Ijọba Ibilẹ ibẹ. “Aarundinlaadọta” lọ si ọdọ alaṣẹ ile itọju awọn alaisan naa lati wa iṣẹ. Nigba ti a beere ibi ti o ti n ṣiṣẹ tẹlẹ ri, o fọkàn gbadura si Ọlọrun o si sọ itan ara rè̩. Bi alaṣẹ yii ti n gbọ ẹri rè̩, omi n da loju rè̩. O gba “Aarundinlaadọta” lọwọ, o si wi fun un pe ki o wa bẹrẹ iṣẹ.

Nigba ti àyè ṣi silẹ lati ba ọkunrin alejo naa sọrọ, o rii pe arun kokoro ti n jẹ òpó ẹyin eniyan (tuberculosis) ni o n ba a ja. Nigba ti o beere pe ki o ka Ọrọ Ọlọrun fun oun “Aarundinlaadọta” ka itan Ọmọ Oninakuna fun un. Bi wọn ti n sọrọ, ọkunrin yii fi ọwọ kọ atè̩-wọn-bọ (ex-convict) yii lọrun, o si wi pe, “Iwọ ha le dariji mi fun ibi ti mo ti ṣe si ọ?” Ọkunrin atè̩-wọn-bọ yii dahun pe, “Iwọ kò ṣe mi ni ibi rara. O le sọ ohunkohun fun mi nipa iya mi bi?” Ọkunrin naa dahun pe, “Emi kò mọ ohunkohun nipa awọn eniyan rẹ, ṣugbọn emi ni ẹni ti o pa eniyan ti a ti tori rè̩ fi ọ sinu tubu.” O si bẹbẹ pe, “Jọwọ dariji mi fun gbogbo ìyà ti o jẹ ni gbogbo ọdun ti o fi wà ninu tubu.”

Ẹni ti o pa eniyan ti a fi ran Aarundinlaadọta lọ sinu tubu lati lọ ṣẹwọn ọdun mọkanlelogun gbako ni yii! O si n bẹ “Aarundinlaadọta” lati dariji oun. Ọkàn ọkunrin atè̩-wọn-dé yii bojuwo ẹyin wo ọdun wọnni ti o lo ninu tubu. O ranti irin wuwo ati ṣẹké̩ṣẹkè̩ irin ti oun gbérù fun ọdun meji tọtọ. O tun ranti ọgbọn pàṣán ti o ti gba sara nibi ifi pàṣán-na ni, ati igba ti a ta a ni ibọn lẹsẹ, ati iye ọsẹ ti o lo ninu aja-ilẹ ti o ṣokunkun biribiri. O ri i pe oun kò le dariji i tọkantọkan. O fi ọkunrin yii silẹ, o si lọ si yara kekere kan. O sé ilẹkun, o si wolẹ, o bẹrẹsi gbadura. Fun bi wakati mẹta, o gbagbe ohun gbogbo miiran, o n sọrọ, o n gbadura, o si n ba Ọlọrun jijakadi fun ẹmi idariji tootọ. Nikẹyin o gbọ ohun kan ti o wi pe, “Dariji i nitori ti Emi.”

O pada sọdọ ọkunrin yii o si fa a mọra, o wi pe, “Mo dari ohun gbogbo ti iwọ ti ṣe si mi ji ọ, ṣugbọn lọ sọ fun Ọlọrun lati dariji ọ pẹlu.”

Leralera ni Aarundinlaadọta n gbọ bi ọkunrin yii ti n wi pe, “Ọlọrun ṣaanu fun mi, emi ẹlẹṣẹ.” Ọlọrun ṣaanu, O si dariji i. Lẹyin ọjọ diẹ, apaniyan naa kú lapa ẹni naa lọdọ ẹni ti o gbe ri idariji ti o tobi yii gba.

Aarundinlaadọta ti fi aye silẹ, o ti wà lọdọ Oluwa, o ti lọ si ayeraye pẹlu “orukọ titun,” kikan i ṣe Aarundinlaadọta lasan mọ, yoo si pade ọkunrin nì ti o gbe e jiya to bẹẹ ni ita wura. Awọn mejeeji ti ri idariji Ọlọrun alaanu gbà.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Igba meloo ni eniyan gbọdọ dariji arakunrin rè̩?
  2. Bawo ni a ṣe ni lati ṣe si awọn ọta wa?
  3. Ki ni iha ti Ọlọrun kọ si awọn ẹlẹṣẹ ni aye yii?
  4. Awọn ẹsẹ Bibeli wo ni o fi han pe aile-dariji ẹlomiiran a maa ṣe idena adura?
  5. Ki ni iwọ gbọdọ ṣe nigba ti ẹni kan ba n binu si ọ?
  6. Ọna wo ni a le gba fi ifẹ ará han?
  7. Ọna wo ni ifẹ Onigbagbọ fi yatọ si ti ẹlẹṣẹ?
  8. Ti ta ni ẹsan?
  9. Ki ni itumọ “Ki ifẹ ki o wà ni aiṣẹtan?”