Matteu 28:18-20; Filippi 3:1-21; Efesu 6:10-18; 1Timoteu 4:1-3; 2Timoteu 3:1-5; 4:1-8; 2Kọrinti 4:16 –18; 5:1-4

Lesson 273 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu” (Efesu 6:11).
Cross References

I Aṣẹ Nla

1. Pẹlu aṣẹ ati agbara ti Ọlọrun fi fun Jesu Kristi ni Jesu fi rán ijọ Rè̩ ni aye lati lọ kọ orilẹ-ede gbogbo, Matteu 28:18-20; Marku 16:15; Iṣe Awọn Apọsteli 5:20; 8:1, 4

2. Gbogbo awọn ti o gbagbọ lati ibẹrẹ titi de opin aye ni lati jà fun igbagbọ ti a fi le awọn eniyan mimọ lọwọ lẹẹkan ṣoṣo, Filippi 3:1-3; Juda 3

3. Ijọ Ajagun kò gbọdọ jẹ ki a da aiṣododo pọ mọ otitọ Ọrọ Ọlọrun, 1Timoteu 4:1-3, 13; 2Timoteu 3:1-5; 4:1-8; Galatia 1:6-9; 1Kọrinti 16:22; Deuteronomi 12:32; Ifihan 22:19

4. Ijọ Ajagun ni lati ja ija rere ti igbagbọ, Efesu 6:10-18; 1Timoteu 6:11-14; 2Timoteu 1:6-8, 13, 14; 2:1-15; 1Peteru 5:8, 9

5. Ireti ajinde ni iranwọ agbara ti n mu Ijọ Ajagun duro ṣinṣin lakoko idanwo ati ogun, Filippi 3:4-21; 2Kọrinti 4:16-18; 5:1-4; 1Tẹssalonika 4:15-17; 2Peteru 1:10, 11

Notes
ALAYÉ

Ijọ Ajagun

Ijọ Ajagun ni ara Kristi tootọ, Ijọ ti o dojuja kọ è̩ṣẹ ni aye isisiyi. Bi o tilẹ jẹ pe ogun ti Ijọ n ja ki i ṣe bi ti ogun aye yii – nipa itajẹsilẹ ogun ti a foju ri -- sibẹ ogun ẹmi ni ogun ti Ijọ, o si kún fun ewu pupọ bi ti ogun ti a foju ri. Ọpọ ni ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun Kristi tootọ ti wọn ti fi ẹmi wọn lelẹ nitori ẹri wọn, ti wọn si ti fi aye wọn ji nitori otitọ Ọlọrun lati tako awọn wọnni ti o fẹ yi otitọ Ọlọrun pada ti wọn si n fẹ lati pa a run.

Titi Jesu yoo fi de, ogun Onigbagbọ yoo maa gbona janjan bi ogun ti awọn ọmọ-ogun aye yii n ja loju ogun. Awọn ohun ija Onigbagbọ ki i ṣe ti ara, bikoṣe ti ẹmi; ṣugbọn sibẹ wọn daju; wọn si ni agbara ninu Ọlọrun lati wo ibi giga palẹ. Ni igba gbogbo ni ogun igbagbọ ti wa, lai si isinmi tabi idaduro lati igba ti è̩ṣẹ ti bẹrẹ; kì yoo si dẹkun titi Jesu Kristi yoo fi pa ọta nla ikẹyin nì, ti i ṣe ikú run. (Ka 1Kọrinti 15:24-28).

Otitọ ati Eke

Ogun nla ti yoo fi opin si ohun gbogbo fẹrẹ de ná. Kò ti i si akoko ti aye, ara ati eṣu dojuja kọ Ijọ Ajagun tó bi akoko ti a wa yi. Igbagbọ tootọ ati iwa mimọ ti bẹrẹsi ṣọwọn lọkàn awọn eniyan. Ni iha gbogbo, ninu ahere ati igberiko kọọkan yi gbogbo aye ká ni awọn ọta otitọ Ọlọrun ti n sare yọ kẹlẹ tan eke kaakiri. Ẹsin pọ kaakiri, ṣugbọn igbagbọ ti a ti fi le awọn eniyan mimọ lọwọ lẹẹkan ṣoṣo, ti i ṣe ihamọra iyebiye ninu ogun igbagbọ, eyi ni o ṣọwọn lati ri.

Ọrọ woli Amosi ti ṣẹ: “Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa ỌLỌRUN wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, ki iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ ọrọ OLUWA: Nwọn o si ma rìn kiri lati okun de okun, ati lati ariwa ani titi de gabasi, nwọn o sare siwá sẹhìn lati wá ọrọ OLUWA, nwọn kì yio si ri” (Amosi 8:11, 12).

Nitori awọn ẹsin eke gbilẹ kan pẹlu ẹgbẹ okunkun ati àdámọ, iyapa ati ẹkọ kọrọkọrọ, o di ọranyan fun Ijọ Ajagun lati jé̩ ki ẹri wọn muna si i lori otitọ Ọrọ Ọlọrun. Ojuṣe ti wọn ni lati ṣe yii wà ninu Bibeli: “Ẹ mā ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan. Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wiwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye; Ẹ si mā na ọwọ ọrọ ìye jade” (Filippi 2:14-16).

Ẹri Ijọ Ajagun ni agbara kan ṣoṣo ti o kù fun otitọ Ọlọrun ninu aye è̩ṣẹ ati okunkun yii; igbala ọkàn awọn eniyan si duro lori ijolootọ Ijọ ati ifara-ẹni-ji rè̩ fun isin Kristi. Ni ikẹyin aye yii, ṣaaju ipadabọ Jesu wá si aye, yoo gba ọpọlọpọ adura ati iforiti nipa ti ẹmi ki Ijọ Ajagun ki o to le jé̩ ẹlẹri ti o muna fun Kristi, ṣugbọn ọpọ ọkàn ni a o jere si Ijọba Ọlọrun nipa ṣiṣe bẹẹ.

Ẹkọ Kọrọkọrọ

Bibeli tẹnumọ ọn bi o ti ṣe pataki tó lati dojuja kọ awọn wọnni ti o n lọ Ihinrere Kristi. A kò gbọdọ gbọjẹgẹ lọnakọna; Bibeli si sọ iha ti Ọlọrun kọ si awọn agbọjẹgẹ: “Ẹnu yà mi nitoriti ẹ tete kuro lọdọ ẹniti o pè nyin sinu ore-ọfẹ Kristi, si ihinrere miran: Eyiti ki iṣe omiran; bi o tilẹ ṣe pe awọn kan wà ti nyọ nyin lẹnu, ti nwọn si nfẹ yi ihinrere Kristi pada. S̩ugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati ọrun wá, li o ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti a ti wasu fun nyin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu. Bi awa ti wi ṣaju, bẹni mo si tún wi nisisiyi pe, Bi ẹnikan ba wasu ihinrere miran fun nyin ju eyiti ẹnyin ti gbà lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu” (Galatia 1:6-9).

Ọkan ninu iwa buburu ti o gbilẹ laye ode-oni ni fifi kún tabi yiyọ kuro ninu Ọrọ Ọlọrun ati lati maa fi adalu ẹkọ pe otitọ Ihinrere Kristi. Eṣu ni o wà nidi iru iwa buburu yii; ọpọlọpọ eniyan ni o si ti gba itanjẹ, nitori ti wọn kò fi Ọrọ Ọlọrun diwọn ẹsin wọn. Ijọ Ajagun yoo di ifibu bi kò ba waasu gbogbo Ọrọ Ọlọrun fun awọn eniyan.

Iṣẹ awọn ẹlẹtan kò ṣe ajeji si Paulu Apọsteli, nitori o sọ bayi pe, “Awa kò dabi awọn ọpọlọpọ, ti mba ọrọ Ọlọrun jé̩: ṣugbọn bi nipa otitọ inu, ṣugbọn bi lati ọdọ Ọlọrun wá, niwaju Ọlọrun li awa nsọrọ ninu Kristi” (2Kọrinti 2:17). Ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii itumọ ọrọ kan ti a lo nibẹ ni ede Griki ni “ipolowo ọja”. Eyi yii ni pe awọn ẹlomiiran n ta Ihinrere bi ẹni ti n ta ọja fun ere jijẹ. (Ka Johannu 2:16; Iṣe Awọn Apọsteli 8:18-21; 1Peteru 5:2; 2Peteru 2:1-3).

Iru ero yii ni o wà lọkàn Isaiah, ninu Majẹmu Laelae, nigba ti o n ba awọn Ọmọ Israẹli sọrọ nipa ifasẹyin wọn: “Fadaka rẹ ti di ìdarọ, ọti-waini rẹ ti dà lu omi” (Isaiah 1:22). Itumọ eyi ni pe, “Awọn ọlọja rẹ ti fi omi lu waini.” Lọna miiran ẹwẹ, eyi ni pe awọn ọlọja ti fi omi lú waini ki o ba le pọ si i, wọn a si maa tà àdàlù waini naa bi ojulowo waini. A fi Ihinrere wé fadaka ati waini ti o ṣọwọn. (Ka Orin Dafidi 12:6; Isaiah 55:1). Awọn eke woli ti da òjé pọ mọ fadaka -- Otitọ Ọlọrun, wọn si ti ba gbogbo rè̩ je. Wọn ti po omi eke pọ mọ waini Igbala, gbogbo rè̩ si ti di ṣooro ati alailadùn. A kò le da àdalu ero tabi ọgbọn eniyan pọ mọ Ihinrere Jesu Kristi. Bi a ba lú otitọ Ihinrere a o sọ ọ di alainilaari. Ihinrere Jesu Kristi duro lori ifihan ti Ẹmi ati ti agbara Ọlọrun nikan, lai si iranwọ ẹda. (Ka Matteu 9:16, 17; 1Tẹssalonika 2:13; 1Kọrinti 2:4).

Onigbagbọ ki i fi kún bẹẹ ni ki i yọ kuro ninu Ọrọ Ọlọrun, nitori Ẹlẹda ati Olugbala rè̩ kun un loju, o si faramọ Ọrọ naa gẹgẹ bi o ti ri gan an. Ọlọrun ki i sọ botibòti. Ọna kan ti o daju ti a fi n mọ woli eke ni pe kò ni gba Bibeli gbọ lai si iyipada kan ṣoṣo fun odiwọn igbesi-aye gẹgẹ bi Onigbagbọ. Ọmọ Ọlọrun fẹ gbogbo ẹkunrẹrẹ otitọ Bibeli, nitori ti Iwe Mimọ sọ fun ni nipa ara rè̩ pe, “Gbogbo iwe mimọ li o ni imisi Ọlọrun, ti o si ni ère fun ẹkọ, fun iba-ni-wi, fun itọni, fun ikọni ti o wà ninu ododo: ki enia Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo” (2Timoteu 3:16, 17). Nitori naa Ijọ Ajagun duro gbọningbọnin lai yẹsẹ lori Ọrọ Ọlọrun ti kò labula lati tako gbogbo awọn ti n yi Ọrọ Ọlọrun po lọnakọna – gbogbo Ọrọ Ọlọrun; ko lé, ko din si eyi ti a fi fun ni! Lati gba ọna miiran yatọ si eyi yoo jẹ were, yoo si jasi pe a ti jọgọ silẹ fun awọn ọta Ihinrere. (Ka 2Johannu 9, 10).

Awọn Woli Eke ati Eke Oluṣọ-agutan

Ọrọ ikilọ ni akoko ti o wọ to fun gbogbo awọn Onigbagbọ, nitori ki i ṣe gbogbo awọn ti n pe orukọ Kristi ni Onigbagbọ tootọ. Episteli Paulu si ijọ Kọrinti kilọ fun awọn eniyan mimọ lati kiyesara ki a ma ba tan wọn jẹ lati ọdọ awọn ti n pe ara wọn ni iranṣẹ Kristi ti wọn kì i si ṣe bẹẹ, ṣugbọn ki wọn maa dan wọn wo ninu igbagbọ. “Nitori irú awọn enia bḝ li awọn eke Apọsteli, awọn ẹniti nṣiṣẹ è̩tan, ti npa ara wọn dà di Apọsteli Kristi. Kì si iṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararè̩ npa ara rè̩ dà di angeli imọlẹ. Nitorina ki iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rè̩ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn” (2Kọrinti 11:13-15).

Ọna pupọ ni o wà ninu Bibeli lati mọ awọn iranṣẹ Satani wọnyi. Jeremiah bá awọn adamọdi oluṣọ-agutan ti o wà ni aye igba ti rè̩ wi ninu iṣẹ ti Ọlọrun ran an bayii pe, “Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ ọrọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọna buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn” (Jeremiah 23:22). Bi ẹnikẹni ti o n pe ara rè̩ ni iranṣẹ Kristi kò ba ké rara mọ è̩ṣẹ, aiwa-bi-Ọlọrun ati gbogbo aiṣododo; bi kò ba gba awọn eniyan niyanju ki o si rọ wọn lati ronupiwada è̩ṣẹ wọn ati lati wá oju Ọlọrun fun idariji ati aanu, ki i ṣe Ọlọrun ni o ran an, woli eke ni a o maa pe e. Iṣẹ-iranṣẹ rè̩ dabi ti awọn wọnni ti woli Esekiẹli bá wi, awọn ti n ti “ọkàn ara wọn” sọ tẹlẹ ti wọn si n tẹle “ẹmi ara wọn” ti wọn “kò si ri nkan” (Esekiẹli 13:2, 3). Ẹwẹ, bi ohun ti wọn ba n waasu rè̩ kò ba duro lori Ọrọ Ọlọrun, ki i ṣe ti Ọlọrun: “Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni” (Isaiah 8:20).

Ọna kẹta ti a fi n mọ awọn woli eke ni a le ri ninu ọrọ Kristi ti o wi pe, “Ẹ mā kiyesi awọn eke woli ti o ntọ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõko ni nwọn ninu. Eso wọn li ẹnyin o fi mọ wọn. Enia a ma ká eso ajara lori ẹgún ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara è̩wọn? Gẹgẹ bḝ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. Igi rere ko le so eso buburu, bḝni igi buburu ko si le so eso rere . . . Nitorina nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ wọn” (Matteu 7:15-20). Nitori naa, ẹyin eniyan mimọ Ọlọrun, ẹ yẹ igi wò fun eso rè̩, ki ẹ si mọ igi rere nipa eso ododo.

Diduro tiri ni Ọjọ Ibi

Awọn ọmọ-ogun ti n lọ si oju ija a maa gba aṣẹ ati itọni nipa ogun ki wọn ba le mọ ohun ti wọn ni lati ṣe ni oju ija. Ọlọrun kò fi Ijọ Ajagun silẹ lai fun ni aṣẹ ati itọni nipa ogun, awọn aṣẹ Ọlọrun wọnyi si yanju kedere to bẹẹ ti ọmọ-ogun Ọlọrun le mọ ohun ti Olori-ogun n bere lọwọ oun. “Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro” (Efesu 6:13). Pẹlu aṣẹ pe ki a gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ lai si eyi ti kò si ẹni kan ti yoo le dojukọ awọn ọta Ihinrere, Ọlorun tun fun wa ni aṣẹ miiran nipa iwa ọmọ-ogun Kristi. Ọmọ-ogun gbọdọ wà ni imurasilẹ pẹlu ipinnu lati ba ọta otitọ Ọlọrun ja. “Ifibu li ẹniti o ṣe iṣẹ OLUWA ni imẹlẹ, ifibu si li ẹniti o dá idà rè̩ duro kuro ninu ẹjẹ” (Jeremiah 48:10). Bakan naa ni a ka ikilọ Paulu Apọsteli si Timoteu, alufaa kekere, nigba ti o kọwe bayii pe, “Mā ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ rẹ; mā duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ ọrọ rẹ là” (1Timoteu 4:16). A le sọ nigba naa pe awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii jẹ aṣẹ ati itọni ogun fun Ijọ Ajagun; bi a ba si pa wọn mọ, wọn yoo fun awọn ọmọ-ogun Kristi ni iṣẹgun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Awọn wo ni diẹ ninu ọta Ijọ Ajagun?
  2. Ki ni ṣe ti a kò gbọdọ gbọjẹgẹ pẹlu awọn ti n lọ Ọrọ Ọlọrun?
  3. Sọ oriṣiriṣi ọna ti a fi le mọ awọn eke woli.
  4. Ki ni ṣe ti Onigbagbọ kò fi gbọdọ fi kún tabi ki o yọ kuro ninu Ọrọ Ọlọrun?
  5. Ki ni ikilọ ti o wà ninu Bibeli nipa “wiwāsu ihinrere miran”?
  6. Ki ni itumọ awọn ọrọ wọnyi “Nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ wọn”?