Matteu 25:31-40; 1Kọrinti 15:19-23; Efesu 5:23-32; 1Tẹssalonika 4:13-18; Ifihan 11:15-18; 12:10, 11; 19:7-16; 20:4-6; 21:1-7

Lesson 274 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o ba ṣẹgun ni yio jogún nkan wọnyi; emi o si mā jẹ Ọlọrun rè̩, on o si mā jẹ ọmọ mi” (Ifihan 21:7).
Cross References

I Ifojusọna Ologo ti Ijọ Aṣẹgun

1. Ireti ajinde kuro ninu oku ni ireti ti o ṣe pataki ju lọ fun Ijọ Ọlọrun, 1Kọrinti 15:19-23; 1Tẹssalonika 4:13-18; Johannu 6:39, 40; 11:24-26; Iṣe Awọn Apọsteli 24:14-16; 1Peteru 1:3-5

2. A fi ẹwa iwa-mimọ ati ogo Ijọ han ninu Iwe Mimọ, Efesu 5:23-32

3. A o fi ere ti o logo fun Ijọ fun jijẹ oloootọ ni gbogbo ọna rè̩, Matteu 25:20-23, 31-40; Malaki 3:16, 17

4. Ijọ, gẹgẹ bi iyawo Kristi, yoo jẹ Ase Igbeyawo ti Ọdọ-agutan, Ifihan 19:7-9; Matteu 25:10; Luku 12:37

5. Ijọ Aṣẹgun yoo wà niwaju itẹ Ọlọrun ni akoko ipọnju nlá nlà ti yoo wà ninu aye, Ifihan 4:10; 5:8-10; 7:9-17; 15:1-4; Isaiah 26:20; Gẹnẹsisi 7:1, 16

6. A o fi Ijọ Aṣẹgun han ninu ogo rè̩ ni igba Ifarahan Kristi, Ifihan 19:11-16; 1Tẹssalonika 4:14

7. Kristi yoo jọba ninu aye, Ijọ Aṣẹgun ni yoo si jé̩ oluranlọwọ Rẹ, Ifihan 2:26; 3:21; 11:15-18; 12:10, 11; 20:4-6

8. Ipo ti Ijọ Aṣẹgun yoo wà titi lae jé̩ eyi ti yoo kún fun ogo ati igbadun ti kò ṣe e fi ẹnu sọ, Ifihan 2:7, 11, 17; 21:1-7; 22:1-5

Notes
ALAYÉ

Ni ọdun pupọ sẹyin, a n bá ọgbẹni kan ti i ṣe ijimi ninu ẹkọ Ọrọ Ọlọrun wi nitori pe o mu iduro rè̩ lori ẹkọ kan ti aṣiwaju rè̩ kò gbà. Ni biba eniyan Ọlọrun yìi wi, olori ijọ náà sọ bayii pe, “Mo yọ ọ kuro laaarin Ijọ Ajagun.” Pẹlu oore-ọfẹ Onigbagbọ tootọ, a sọ fun ni pe eniyan Ọlọrun yii dahun pe, “Eyi ti o tọ loju rẹ ni iwọ le ṣe, ṣugbọn ohun kan daju, eyi nì ni pe, iwọ kò le yọ mi kuro ninu

Ijọ Aṣẹgun

Ijọ Ajagun jẹ ọkan, o si logo. A n ri i gẹgẹ bi akopọ awọn wọnni ti a pe jade ni kọọkan kuro ninu ayé lati ja ija rere ti igbagbọ, awọn ti o si n fi itara ṣiṣẹ fun Ijọba Ọlọrun. S̩ugbọn a ri i pe Ijọ Aṣẹgun tún ni ogo ju eyi lọ, nitori oun ni Ijọ awọn Ajagun ti o ti ṣẹgun -- ẹgbẹ ologo ti awọn Onigbagbọ ti wọn ti fọ aṣọ wọn ninu Ẹjẹ Ọdọ-agutan, awọn ẹni ti yoo maa tẹle Ọdọ-agutan, titi ayeraye, si ibikibi ti O ba n lọ. S̩ugbọn ki a to le jé̩ ọmọ-ẹgbẹ Ijọ Aṣẹgun a ni lati kọ jẹ ọmọ-ẹgbẹ Ijọ Ajagun. Kò ṣe e ṣe lati

“. . . gbe wa lọ sọrun

Lori ibusun oniyẹ,

Gbati awọn miiran ja lati gbade,

Ti wọn fori la ikú.”

Ogun wà fun gbogbo wa lati jà ni ọjọ aye wa bi a ba fẹ wà pẹlu ẹgbẹ awọn aṣẹgun ni aye ti n bọ.

Ireti Onigbagbọ

Peteru Apọsteli sọ fun wa nipa imisi Ẹmi Mimọ pe a tun wa bi “sinu ireti āye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú” (1Peteru 1:3). O si tun pe ogún wa ni ogún “aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti kì iṣá, ti a ti fi pamọ ni ọrun” dè wa. Nipa imisi Ẹmi Mimọ, Paulu Apọsteli tun sọ fun wa pẹlu nipa ireti Onigbagbọ, ati pe ajinde Kristi ati ajinde awọn eniyan mimọ ti yoo tẹle e, ni ipilẹ ati agbara ireti naa.

Ayọ ki ba ti si bi o ba ṣe pe ajinde okú kò si. Ki ba ti si ijọsin atọkanwa, igbagbọ tabi awọn ami ti n tẹle iwaasu Ọrọ Ọlọrun; ki ba ti si igbala kuro ninu è̩ṣẹ, tabi iwẹnumọ kuro ninu idibajẹ ti ẹda ṣubu si, bi o ba ṣe pe ajinde kò si. Igbagbọ wa i ba jẹ asan awa i ba si wà ninu è̩ṣẹ wa sibẹ. Nitori naa ẹ jẹ ki a yẹ otitọ ati ogo ti o wà ninu ajinde ati ipalarada Ijọ Ọlọrun wo, nitori ni ipadabọ Kristi ni ẹẹkeji ni Ijọ Ajagun yoo di Ijọ Aṣẹgun.

Ajinde Kin-in-ni

Ọpọ iwe ati ainiye iwaasu ni o ti jade ti o fi ẹsẹ ẹkọ nipa ajinde okú mulẹ, bakan naa ni ọgọọrọ iwaasu ati iwe si ti jade ti o n tako ẹkọ yii kan naa. Awọn alatako Kristi ni akoko iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ ninu ayé, gbe ogun ti I lori ọrọ yii. Wọn gboju-gboya lati maa sọrọ iwọsi si Ẹni ti Oun tikara Rè̩ jẹ Ajinde ati Iye! Ẹni ti O ni agbara lati fi Ẹmi Rè̩ lelẹ ati lati gba a pada, ṣe bẹẹ ki a ba le ji awa pẹlu dide kuro ninu okú, ki a si le duro niwaju Itẹ Ọlọrun ninu ogo ti a kò le fẹnu sọ ati ẹwa ti kò lé̩gbé̩.

Awọn alatako ti o sé̩ agbara Ọlọrun ati otitọ Ọrọ Ọlọrun a maa sé̩ otitọ ologo yii pẹlu. S̩ugbọn otitọ yii duro ṣinṣin – Apata ti ireti Onigbagbọ duro le lori – ani pe ajinde wà, ninu eyi ti Oluwa ati Olugbala wa jade kuro ninu iboji ti O si goke re Ọrun lati jé̩ Alagbawi wa. Ati nitori ti O ṣẹgun ikú ati ipo okú, awa pẹlu yoo jinde lati pade Rè̩ ni awọsanma nigbooṣe. Awọn ti o ti lọ ṣaaju, ti okú wọn wà ninu iboji yoo ji dide. Awọn ti o si wà laaye ni a o pa lara da, a o si gba wọn soke pẹlu awọn eniyan mimọ ti o ti jinde. Gbogbo awọn wọnyi, pẹlu okú awọn oloootọ ti a o ji dide lẹyin Ipọnju Nla, yoo jẹ awọn ọmọ-ẹgbẹ Ajinde Kin-in-ni, eyi ti Kristi i ṣe akọso rè̩. A le pe awa ti a o pa lara da lati pade Rè̩ ni akoko Ipalarada ni ikore gidi, awọn wọnni ti a o ji dide lẹyin Ipọnju Nla ni a le pe ni eeṣé̩ ikore (1Kọrinti 15:20-23; 1Tẹssalonika 4:13-18).

Wo bi yoo ti dun to lati ni ipin ninu Ajinde Kin-in-ni! Ara wọnyi ti o ti mọ oriṣiriṣi aisan ati ailera yoo di ara ologo. Gbogbo irora yoo dopin. Gbogbo ailera ati ijatilẹ ẹda ki yoo si mọ. Awa yoo dabi Kristi, nitori awa yoo ri I gẹgẹ bi Oun ti ri. Iṣẹ iwẹnumọ yii ti bẹrẹsi i ṣe ninu ọkàn awọn eniyan Ọlọrun. Wọn n mura silẹ fun ọjọ ni nigba ti Oun yoo pe wọn. S̩ugbọn ni ọjọ ologo ni Oun yoo ṣe wa ni aṣepe, yoo si mu wa ri bi Oun tikara Rè̩ ti ri.

A ó ni imọ pipe. Akoko tabi ọna jijin kò ni dá wa lọwọ kọ mọ. A ki yoo tọ ikú wò mọ laelae. Ẹru ki yoo wà ninu ọkàn ati aya wa mọ. Iṣubu kuro ninu oore-ọfẹ ki yoo si mọ, a ki yoo si ba è̩ṣẹ ati idanwo ja mọ. A o wà pẹlu Jesu, Oluwa ati Olugbala wa ati Ọkọ wa lae ati laelae. Gbogbo ibukun wọnyi – ati ju bẹẹ lọ -- jé̩ ti awọn ti o bá mura silẹ lati ni ipin ninu Ajinde Kin-in-ni.

A le ni ipọnju nihin. Ara wa le bajẹ ki a si di alábùkù-ara, yala nipa èṣe ti o le ti ṣe awa funra wa, tabi ki o jẹ ajogunba nipa iṣubu Adamu. A le ni ailera ninu ara wa ti o le di wa lọwọ lati ṣiṣẹ bi a ti n fẹ ninu ọgba ajara Oluwa. S̩ugbọn ni ọjọ ajinde ologo nì, agbara ti o ji Jesu dide kuro ninu okú yoo sọ ara kikú wa di aaye nipa Ẹmi Rè̩ ti o n gbe inu wa, awa yoo si bọ lọwọ gbogbo irora ati aarẹ, a o si le maa sìn In ni pipe lae ati laelae.

Igbaradi fun Iṣẹgun

Gẹgẹ bi a ti ri ninu ẹkọ wa lori Ijọ Ajagun, ọpọlọpọ ogun ẹmi ni a ni lati ja ninu aye yii, a si ni lati wà ni igbaradi gidigidi bi a ba fẹ lati pade Oluwa ati Olugbala wa. Olukuluku ẹni ti o ba ni ireti yii ninu Oluwa yoo wẹ ara rè̩ mọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti jẹ mimọ (I Johannu 3:3). Iru ẹni bẹẹ yoo maa wa “li airekọja, li ododo, ati ni iwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi” (Titu 2:12). Ẹni bẹẹ yoo jẹ “mimọ ati alaini àbuku,” ọmọ ẹgbẹ “ijọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni” (Efesu 5:27). Gbogbo imurasilẹ yii ni a ni lati ṣe ni igba aye wa nitori Ipalarada Ijọ Ọlọrun yoo ṣẹlẹ lojiji lai si ikilọ, àyè ki yoo si si nigba naa fun imurasilẹ (Ka Matteu 24:17; 25:1-13). Ẹni ti o “bọ ogo rè̩ silẹ, o si mu awọ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia,” ẹni ti “o rè̩ ara rè̩ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu” (Filippi 2:7, 8) ṣe eyi ki awa ki o le dabi Rè̩, o si jé̩ ọranyan fun wa lati dabi Rè̩ nihin, ki awa ki o le dabi Rè̩ nigba ti a ba pade Rè̩ ni Ọrun lọhunEre

Ẹsẹ pupọ ninu Ọrọ Ọlọrun ni a gbe sọ ere wọnni ti a o fi fun Ijọ Aṣẹgun nigba ti wọn ba duro niwaju Itẹ Ọlọrun. A o maa “tàn bi imọlẹ ofurufu” ati “bi irawọ lai ati lailai” (Daniẹli 12:3). Ọlọrun yoo gbe wa leke (Orin Dafidi 91:14), pẹlu Ọmọ Rè̩, lori itẹ ogo ati àṣẹ. Ọlọrun yoo kà wa yẹ si ọṣọ iyebiye Rè̩, yoo si fun wa ni anfaani lati jẹ igbadun alailẹgbẹ ti ogo Ọrun titun ati aye titun titi ayeraye. Akoko Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun yoo jẹ akoko isin fun Oluwa wa, Ẹni ti a jẹ ni igbese ifẹ ati isin atọkanwa lọpọlọpọ. A o jẹ onidajọ nigba naa, a o le jẹ anfaani igba ologo yii ni kikún.

Ibẹru-bojo fun idajọ ki yoo si mọ fun wa. Awọn okú ẹlẹṣẹ ni a o ji dide lati duro niwaju Itẹ Nla Funfun, lati gba idajọ gbogbo iwa buburu ti wọn ti hù ni aye yii. Idajọ gbigbona nikan ni ohun ti awọn ẹlẹṣẹ yoo ri gbà lati ọdọ Ọlọrun, ṣugbọn Ijọ Aṣẹgun ki yoo ni ipin ninu rè̩ rara. Ọlọrun yoo jẹ Onifẹ julọ, Alaanu, Onibu-ọrẹ ati Oloore ju lọ si wọn. Wọn yoo ri oju Rè̩ ati imọlẹ oju Rè̩. Ọlọrun mimọ ati pipe ninu ẹwa Rè̩, ki yoo fi oju ibinu wo Ijọ Aṣẹgun rara. Ijọ Aṣẹgun yoo wà ninu alaafia ati ayọ ti kò lẹgbẹ titi aye ainipẹkun.

Ijọ Aṣẹgun yoo ṣe iranlọwọ lati dá awọn ẹlẹṣẹ lẹjọ, wọn yoo tilẹ ṣe idajọ awọn angẹli paapaa. Iru iṣẹ ti a o fun wọn ṣe yoo duro lori bi wọn ba ti lo anfaani ti wọn ni ni aye yii si lati sin Ọlọrun. Igbesi aye wọn ki yoo jé̩ ti ọlẹ tabi ti wiwa lasan ṣugbọn yoo kún fun igboke-gbodo ti o mu ayọ ati itẹlọrun wa titi ayeraye. Wọn yoo maa jẹ eso igi iye, wọn yoo si maa mu omi iye. Igi iye yii yoo maa so eso ni gbogbo akoko; ki yoo si akoko ti omi ti o mọ ju lọ yii yoo gbẹ. Gbogbo idaamu ti awọn ohun irọrun ti aye igbalode isisiyi n kó ba ni ki yoo si mọ. A ki yoo wá imọlẹ nitori Ọdọ-agutan Ọlọrun ni imọlẹ ibẹ. Ki yoo si ole, eke, alaimọ tabi ohun ti n ba ni jé̩, bẹẹ ni ki yoo si ifoya tabi ipaya, tabi aidaniloju ọjọ ọla. A o maa gbe ninu isinmi ati ogo lae ati laelae.

Ifihan

Ni akoko isisiyi Ijọ Ọlọrun wà ni akoko ipọnju ti rẹ. O n la idanwo ati iyiiriwo idaamu kọja. Akoko imurasilẹ rè̩ ni eyi. S̩ugbọn akoko n bọ nigba ti a o fi i han ninu gbogbo ogo rè̩.

Oluwa pe awọn eniyan Rè̩ si igbesi-aye iwa mimọ, ki wọn ki o le jẹ eniyan ọtọ, iran ti a yàn ati iṣura iyebiye. S̩ugbọn aye kò mọ wọn bẹẹ. Eṣu kò ka iwa-bi-Ọlọrun ti o wà ninu awọn eniyan Ọlọrun si. Kaka bẹẹ o n dojukọ awọn Onigbagbọ, o si n fẹ pa wọn run. Awọn iranṣẹ Satani si dabi oluwa wọn, gẹgẹ bi awọn iranṣẹ Kristi ti dabi Oluwa ati Olugbala wọn. Aye yii ki i ṣe ọrẹ oore-ọfẹ, awọn ọrẹ aye si jẹ ọta kikoro fun awọn iranṣẹ agbelebu.

Aye n fi oju tinrin iwa rere ati oore-ọfẹ awọn Onigbagbọ. Ninu ayé nibi ti o jẹ pe igberaga, ijọra-ẹni-loju, irera ati iṣẹ ọwọ eniyan ni o n fi iru ọlá ati iyẹsi ti a o ṣe fun un hàn, iru iyẹsi wo ni a n ṣe fun awọn ọlọkan tutu ati onirẹlẹ ọkàn? Ki ni ẹni ti o fẹ awọn ọta rè̩ le ri gba lọdọ aye ti o korira ohun gbogbo ti i ṣe rere? Ẹmi aye isisiyi lodi si ipamọra, suuru, iṣeun, iṣoore, iwa pẹlẹ, ifẹ, airekọja ati iwa rere. Awọn eniyan aye kò naani awọn ẹni ti o ni awọn ẹbun rere wọnyi tabi awọn wọnni ti n fi kiki ofin ati ilana Ọlọrun ṣe akoso igbesi-aye wọn.

S̩ugbọn ọjọ ologo kan n bọ fun awọn ti n sin Ọlọrun. Akoko inira, ijakadi kikoro pẹlu è̩ṣẹ ati iwa buburu fẹrẹ dopin. Ọjọ idande n bọ kankan. Awa ti a wà laaye ti a si n ri awọn ami ti o n fi han pe opin kù si dẹdẹ ni lati gbe ori wa soke, nitori idande wa sun mọ tosi.

Oluwa yoo de gẹgẹ bi ole li oru. Igbe yoo ta, ṣugbọn gbogbo aye kọ ni yoo gbọ ọ. Eti awọn ẹlẹṣẹ kò le gbọ ipe ti yoo dun lati Ọrun wa yii. Ohun Satani oluwa wọn nikan ni eti ẹlẹṣẹ ṣi silẹ si, oun ni o si n kesi wọn lati ṣe ifẹ rè̩, ati lati tẹle ọna tirẹ, bi o ti n sa ipa rè̩ lati bi ijọba Ọrun wó ki o ba le gba Itẹ Kristi fun ara rè̩. Ijọ Ajagun nikan ni yoo gbọ ipe naa. Gbogbọ ẹgbẹ ọmọ Ijọ Ajagun, i baa ṣe ope, bi o ti wu ki o rẹlẹ tabi ki o ṣe alaini to, tabi ki o jẹ ẹni ti a n pọn loju tabi ti a tè̩ lori ba to lọwọlọwọ -- tabi ti o ti wà ni iru ipo bayii ki o to bọ ihamọra rè̩ silẹ ni opin ijakadi aye yii – yoo gbọ ohun Ọlọrun, agbara awamaridi ti n fi iye fun ni yoo si gbe e kuro ninu aye oṣi yii lọ si ibugbe alaafia ati ogo ainipẹkun.

Awọn Ogo Ọrun

A kò sọ pupọ fun ni nipa awọn ogo Ọrun. A gba Paulu Apọsteli sinu ogo Ọrun lọhun, o si sọ fun ni pe oun ri ohun ti ahọn oun kò le royin ti kò si le ṣe apejuwe. S̩ugbọn Johannu Ayanfẹ ṣe apejuwe diẹ fun ni nipa ẹwa ti kò ṣe e fẹnusọ ti o ti ri – o si tun sọ nipa awọn ohun wọnni ti yoo ṣẹlẹ lori tabi niwaju Itẹ Ọlọrun ni akoko Ipọnju Nla lori ilẹ aye yii. Niwọn igba ti Bibeli ti fun wa ni apejuwe kikún nipa Itẹ ti Johannu ri nì, ẹwa ayika rè̩ ati awọn ohun wọnni ti yoo ṣẹlẹ lati ori rè̩ wa, a le ṣe aṣaro lori nnkan wọnyi, ki a si fi oju ẹmi ri diẹ ninu ẹwa ati ogo ti kò lẹgbẹ ti awa yoo ri lọjọ kan ti awa paapaa yoo si ṣe alabapin ninu rè̩.

Isaiah sọ fun wa pe Itẹ Ọlọrun “ga, ti o si gbe ara soke” (Isaiah 6:1). Iwe Mimọ tun fi kún eyi nibomiiran pe, Itẹ naa funfun laulau, o si n kọ mọnà. O yẹ ki a fi apejuwe yii sọkan, ki a si paapọ pẹlu apejuwe ti Johannu Ayanfẹ ṣe fun wa nipa imisi Ẹmi Mimọ.

Johannu Ayanfẹ sọ fun wa pe oun ri Ẹni kan joko lori Itẹ naa, a si mọ pe Ẹni naa ki i ṣe ẹlomiiran bi kò ṣe Ọlọrun Ayeraye ninu Iwa Mẹtalọkan Rè̩. Iwọn iba ọrọ ti Johannu le lò lati ṣe apejuwe Iwa-Ọlọrun yii fétè lọpọlọpọ, ṣugbọn bi o ti fétè to nì, o fun wa ni apejuwe ti o tayọ òye wa.

Johannu sọ pe irisi Ọga-ogo “dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo.” A le ri i nipa eyi pe itanṣan nla kan n ti Itẹ Ọlọrun wá ti o dabi itanṣan ti o n tan jade lara awọn okuta iyebiye wọnyi ti a ti dán gbadun gbadun. A le fi oju ẹmi wo ninu ohun ti Johannu ri: Itẹ ti o funfun gboo, ti o n dan, ti o si n kọ mọna ti o “ga, ti o si gbe ara soke”; oṣumare alawọ ewe yi i ka, a si gbe e ka ori okun digi ti o mọ bi kristali.

Nigba ti Mose ati awọn agbagba Israẹli wà lori Oke, wọn ri “Ọlọrun Israẹli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsè̩ rè̩, o si dabi irisi ọrun ni imọtoto rè̩” (Ẹksodu 24:10, 11). Ninu iran ti Esekiẹli ri, o kọ akọsilẹ pe ibi ti Itẹ Ọlọrun wa dabi “aworan ofurufu . . . bi àwọ kristali ti o ba ni li è̩ru” (Esekiẹli 1:22). Lai si aniani, okun digi ti irisi rè̩ dabi kristali, ti Johannu ri ki i ṣe ohun miiran bi kò ṣe awọ ofurufu ti o mọ kedere ti o n tan ninu ẹwa rè̩ -- ijoko itẹ Ọlọrun Mẹtalọkan Mimọ ninu ogo Rè̩ ti kò si ohun ti a le fi ṣe akawe.

Ogo Ijọ Aṣẹgun

S̩ugbọn iran ologo mimọ yii ti kò si ọlọgbọn tabi amoye ninu aye ti o le ṣe apejuwe rè̩ -- ki a ma tilẹ sọ bi iba apejuwe diẹ ti a tilẹ ṣe ti tayọ òye inu wa lati fi ọkàn ṣiro -- kò ni ṣe ajeji fun awọn wọnni ti yoo ṣe alabapin ninu awọn iṣẹlẹ wọnni ti yoo mi gbogbo agbaye kijikiji.

Niwaju ati ni ayika Itẹ, Johannu ri awọn ẹda alaaye ati awọn agbaagba ti a mọ pe wọn jẹ ẹgbẹ awọn ẹni irapada nipa orin ati iyin wọn. Johannu kò mọ iye wọn gan an nitori o wi pe wọn jẹ ẹgbaarun lọna ẹgbaarun ati ẹgbẹẹgbẹrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun. Wọn yoo gbe ohun orin iyin wọn soke nitori irapada wọn ati idande wọn kuro ninu idajọ ti i ba wa sori wọn nitori è̩ṣẹ wọn. S̩ugbọn apa kan ni eyi ninu iran ti Johannu ri nitori ẹgbẹ awọn wọnni ti ẹnikẹni kò le kà, awọn ti yoo ti inu ipọnju nla wa, lati fọ aṣọ wọn ninu È̩jẹ Ọdọ-agutan, ti wọn yoo si sin Ọlọrun niwaju Itẹ Rè̩ lae ati laelae n bọ wa pẹlu wọn (Ifihan 7:9-17).

Bi o ba ṣe e ṣe fun ọ, fi oju ẹmi wo iran ologo ati ẹwa ailopin yii ni iṣẹju kan. Fi ọkàn ṣe aṣaro awọn ogo ti yoo jẹ ti awọn Onigbagbọ tootọ fun iṣẹju kan pere. Lẹyin eyi ki iwọ wa ṣe aropọ gbogbo anfaani wọnyi ti o wà ninu iṣẹju kọọkan ti o wà ninu ayeraye ainipẹkun. Awamaridi? Bẹẹ ni! Ko ṣe e fẹnu sọ? Bẹẹ ni!

Tabi ọwọ eniyan kò le tẹẹ? Bẹẹ kọ! Ati nigba ẹgbaa, Bẹẹ kọ. Ẹjẹ Jesu tó, idariji ti Ọlọrun pese tó lati ṣe gbogbo ọkàn ti o n ṣe afẹri yẹ, to bẹẹ ti wọn yoo fi le maa wo ogo wọnyi. Ẹbọ pipe, arukun aruda nì lagbara to lati sọ gbogbo eniyan di ọmọ ẹgbẹ aimoye awọn wọnni ti a ti wè̩ mọ ti yoo wolẹ niwaju Itẹ nì, ti wọn yoo si fi ade wọn lelẹ lori okun ti o mọ gaara bi kristali nì, ti wọn yoo si maa kọrin pe:

“Iwọ li o yẹ . . . nitoriti a ti pa ọ, iwọ si ti fi

è̩jẹ rẹ ṣe irapada enia si Ọlọrun lati inu ẹyà

gbogbo, ati ède gbogbo, ati inu enia gbogbo,

ati orilẹ-ède gbogbo wá” (Ifihan 5:9).

Si tun wo ogo ti yoo tun jé̩ ti awọn ẹni irapada wọnni. Bi ẹni pe ogo wọnni ti a ti sọrọ nipa rè̩ kò i to, Ọlọrun fun ẹgbẹ awọn ẹni irapada yii ni anfaani lati gun ori ẹṣin funfun, a o si wọ wọn ni aṣọ ọgbọ wiwẹ, funfun ati mimọ, wọn o si pada wa si aye yii pẹlu Oluwa ati Olugbala wọn Aṣẹgun lẹyin Ipọnju Nla. (Ka Ifihan 19:11-16 ati Juda 14).

Wo anfaani wọnni ti a o fifun olukuluku wọn ninu Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun Kristi ni aye yii (Ifihan 20:4-6). Leke gbogbo rè̩ ṣiro aṣekagba ohun gbogbo, nigba ti a o pa Ọrun ati aye ti o wà nisisiyi run ti a o si paarọ rè̩ pẹlu Ọrun titun ati aye titun ninu eyi ti ki yoo si abawọn è̩ṣẹ tabi ohun aimọ. Lẹyin ti iwọ ti fi oju ẹmi wo gbogbo nnkan wọnyi, fara balẹ ki o si ṣe aṣaro lori rè̩ fun igba diẹ, ki o si fi eyi kun un pe, laaarin gbogbo ogo wọnyi, lẹba Ọlọrun ti o ti ra awọn eniyan Rè̩ pada ti o si ti mu wọn wá si ibi ogo ainipẹkun yii, ni Ijọ ologo naa yoo wà, ni aini abawọn tabi aleebu – awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun ologo -- Ijọ Aṣẹgun!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni a ni lati ṣe ki a to di ọmọ ẹgbẹ Ijọ Aṣẹgun?
  2. Nigba wo ni Ijọ Ajagun yoo di Ijọ Aṣẹgun?
  3. Ki ni a n pe ni “aṣẹgun ni kikun”?
  4. Darukọ diẹ ninu awọn ere ti a o fi fun Ijọ Ọlọrun.
  5. Ki ni Jesu yoo ṣe fun Ijọ Ọlọrun nibi Ase Igbeyawo Ọdọ-agutan?
  6. Àyè wo ni a o fi fun Ijọ Ọlọrun ninu eto idajọ ayeraye ati ti ẹgbẹrun ọdun?
  7. Nigba wo ni awọn olugbe ayé yoo kọ ri Ijọ Aṣẹgun ninu ogo rè̩ ayeraye? S̩e apejuwe bi ogo rè̩ yoo ti ri?
  8. Ayè wo ni Ijọ Ọlọrun yoo wà titi lae?
  9. Kọ Efesu 5:23-32 sori.
  10. Kọ kókó pataki ohun ti o wà ninu Matteu 25:31-40 sori.