Johannu 1:1-14, 29-51; Matteu 3:13-17; Gẹnẹsisi 1:1, 26

Lesson 262 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19).
Notes

Jesu gẹgẹ bi Eniyan

Johannu Apọsteli, ẹni ti a tun mọ si ọmọ-ẹyin ti Jesu fẹran, ba Olugbala rin timọtimọ laaarin ọdun mẹta ati aabọ iṣẹ-iranṣẹ Rè̩. Wọn jọ n rin kiri ni lori ita gbigbona ati eleruku; ti wọn si jọ n joko papọ ti ounjẹ ti kò nilaari kan naa, wọn si jẹ ki iru ounjẹ kan naa té̩ wọn lọrùn. Nigba miiran, Johannu le ti gbe lọdọ Jesu, gẹgẹ bi Peteru ati Anderu ti maa n ṣe.

Jesu gbé gẹgẹ bi eniyan laaarin awọn eniyan. Lai ṣe aniani, O ṣiṣẹ fun ọdun pupọ ninu ile-iṣẹ Josẹfu gbẹnàgbẹnà, O si mọ bi aarẹ ti maa n mu eniyan. O bá awọn eniyan kẹdun. O kiyesi ipọnju wọn, O si ba wọn jiya, O si sọkun pẹlu wọn; O ri ayọ wọn, O si ba wọn yọ pẹlu.

Lati Ọrun

Sibẹ, Johannu mọ pe Jesu yatọ si awọn eniyan iyokù. Nigba pupọ ti wọn ba n sọrọ timọtimọ pẹlu Peteru ati Jakọbu, Jesu maa n sọ fun wọn nipa igbesi-aye ti Oun ti n gbe ki Oun to wá sinu ayé. Ni akoko kan O mu wọn lọ si oke kan O si jẹ ki wọn ri itọwò iru ogo ti Oun ti ni ni Ọrun. “Oju rè̩ si nràn bi õrun; aṣọ rè̩ si fún, o dabi imọlẹ.” Mose ati Elijah, awọn ẹni ti wọn ti lọ si Ọrun ni ọpọlọpọ ọgọrun ọdun ṣiwaju akoko yii si fara hàn, wọn si ba A sọrọ. Wọn mọ Jesu. Wọn ti mọ Ọn ni Ọrun ki o to di pe a bi I gẹgẹ bi ọmọ-ọwọ ni Bẹtlẹhẹmu. Nigbooṣe a kò ri Mose ati Elijah mọ; awọn Apọsteli naa si gbọ ti ohùn Ọlọrun sọrọ si wọn lati inu awọsanma wá pe: “Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dun si gidigidi; ẹ mā gbọ tirè̩” (Matteu 17:5).

Ọmọ Ọlọrun

Eyi jé̩ otitọ ti Johannu kò le gbagbe. Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe; kokó ọrọ yii ni Johannu si tẹnu mọ ninu awọn iwe ti o kọ, ti wọn si wà ninu Bibeli.

Ọpọlọpọ nnkan ni Johannu kọ silẹ lati fi hàn pe Jesu ju eniyan kan ṣá, ọmọ Maria ati Josẹfu, lọ. Ọrọ ti Johannu fi bẹrẹ Ihinrere rè̩ ni pe, “Li àtetekọṣe li Ọrọ wà, Ọrọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọrọ na.” “Ọrọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rè̩, ogo bi ti ọmọ bibi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ” (Johannu 1:1, 14). Ọrọ naa ti o “di ara” ni Jesu. O ti wà lọdọ Ọlọrun lati ipilè̩ṣẹ, ni igbà dida aye. “Nipasẹ rè̩ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rè̩ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da” (Johannu 1:3).

Ninu ẹsẹ ekinni Bibeli a kà pe: “Li atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun on aiye.” Johannu si sọ fun ni pe Jesu wà pẹlu Ọlọrun ni akoko naa, ati pe Oun paapaa jẹ Ọlọrun. Ọrọ kan naa ni Paulu Apọsteli sọ: “Ọlọrun, . . . ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rè̩ ba wa sọrọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu” (Heberu 1:1, 2). Nigbà ti a si dá eniyan, Ọlọrun wi pe, “Jẹ ki a dá enia li aworan wa, gẹgẹ bi iri wa” (Gẹnẹsisi 1:26). Nigba ti a ba n sọ nipa iye eniyan ti o ju ọkan lọ ni a maa n lo a ati wa.

Ẹni Mẹta ni Ipin Ninu Dida Aye

Ẹmi Mimọ wà nibẹ pẹlu nigba ti a da ayé. “Ẹmi Ọlọrun si nràbaba loju omi” (Gẹnẹsisi 1:2). Jobu pẹlu kọwe pe: “Ẹmi Ọlọrun li o ti da mi, ati imisi Olodumare li o ti fun mi ni ìye” (Jobu 33:4); ati pe, “Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọṣọ, ọwọ rè̩ li o ti da Ejo-wiwọ nì” (Jobu 26:13). Awọn Ẹni Mẹtẹẹta ti wọn papọ jé̩ Ọlọrun ni wọn ni ipin ninu dida ayé.

Itumọ “Ẹni mẹta ninu Ọkanṣoṣo” kò le yé wa; ṣugbọn lati igba de igba ni a n sọ nipa wọn ninu Iwe Mimọ ti o ṣe alaye iṣẹ wọn, ti o si tẹnu mọ ọn pe Ẹni kọọkan wọn wà laelae, O si ni gbogbo agbara, gbogbo ọgbọn, O si wà ni ibi gbogbo. Awọn Ẹni mẹta wọnyi ni a n pe ni Mẹtalọkan Mimọ: Ọlọrun Baba, Ọlọrun Ọmọ, ati Ọlọrun Ẹmi Mimọ.

Koṣee-mani ni Ẹni Keji

Ki ni ṣe ti o fi jẹ dandan fun wa pé ki a gba Mẹtalọkan gbọ? Ki ni ṣe ti o fi jẹ ọranyan bẹẹ fun wa lati gbagbọ pe Ọmọ Ọlọrun mimọ ni Jesu i ṣe? Ki ni ṣe ti Jesu fi ni lati wá si ayé ati lati maa gbe laaarin awọn eniyan?

Ẹwà Ọlọrun ti o leke ju lọ ni iwa-mimọ. Ọlọrun mimọ kò si le wo è̩ṣẹ eniyan. Ofin Ọlọrun ni pe: “Ọkàn ti o bá ṣè̩, on o kú.” Ọlọrun giga wà ni Ọrun rè̩; O n ṣe akoso agbaye, ti Rè̩ ni gbogbo agbara, O si mọ ohun gbogbo.

S̩ugbọn nisalẹ lori ilẹ ti è̩ṣẹ ti sọ di ifibu ni eniyan wà. Fun ogo Ọlọrun ni a da a. Ọlọrun ni irẹpọ pẹlu eniyan ninu Ọgba Edẹni ki è̩ṣẹ to sọ eniyan di ẹni ègbé. S̩ugbọn è̩ṣẹ Adamu mu iyapa wá saarin Ọlọrun ati eniyan. Kò si si ohunkohun ti eniyan le ṣe funra rè̩ lati mu ki o ri ojurere Ọlọrun lẹẹkan sii. O yẹ ki o kú nitori è̩ṣẹ rè̩, nitori pe o ti rú ofin Ọlọrun.

Ipo ẹlẹgẹ yii ni o fa a ti Kristi fi wá si aye. “Ọlọrun kan ni mbẹ, Onilaja kan pẹlu larin Ọlọrun ati enia, on papa enia, ani Kristi Jesu” (1Timoteu 2:5). Onilaja jẹ alarina, ẹni ti o wa lati mu irẹpọ wá saarin awọn ẹni meji ti wọn ni ède-aiyede, tabi saarin awọn ilana meji ti wọn lodi si ara wọn.

Eniyan kò si ni ipo ti o le fi duro niwaju Ọlọrun mimọ ati olododo. Eniyan ti dẹṣẹ o si ni lati kú. S̩ugbọn Jesu fara hàn lati gbà a silẹ. O duro saarin eniyan ti o ti jẹbi ati Ọlọrun olododo. Nipa bẹẹ a mu ofin Ọlọrun ṣẹ.

Jesu, Ẹni keji ninu Mẹtalọkan, gbé ẹbi araye rù ara Rè̩, O si kú ni ipo ẹlẹṣẹ. Kò si eniyan ti o le ṣe onilaja, nitori pe gbogbo eniyan ni o ti ṣẹ, ti wọn si ti kùna ogo Ọlọrun (Romu 3:23). Gbogbo eniyan ni o gbọdọ ni onilaja. Nitori bẹẹ, Ọmọ Ọlọrun, Ẹni mimọ, alailẹṣẹ kò le ṣai wá lati ṣe Onilaja laaarin Ọlọrun ati eniyan.

Nipasẹ Jesu nikan ni a ti le ri igbala. Jesu wi pe, “Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi” (Johannu 14:6). Bi a ba ni ki Jesu dariji wa, Oun yoo gbà wa là kuro ninu è̩ṣẹ wa.

Aigbagbọ

Bi ọpọlọpọ alafẹnujẹ Onigbagbọ ode-oni ti jẹ alaigbagbọ, bẹẹ gan an ni awọn Ju ti akoko Jesu ti jé̩. Wọn wi pe wọn gba Ọlọrun Baba gbọ, wọn si n sin In; ṣugbọn wọn kọ Jesu.

Nipa kika Iwe Mimọ, awọn Ju ti mọ pe ni ọjọ kan Ọlọrun yoo ran Messia, ati pe wundia ni yoo bi I. Woli Isaiah, ẹni ti wọn bu ọlá fun, ti kọwe bayii, “Oluwa tikalarè̩ yio fun nyin li àmi kan, Kiyesi i, Wundia kan yio loyun, yio si bi ọmọkunrin kan, yio si pe orukọ rè̩ ni Immanuẹli” (Isaiah 7:14). Sibẹ, nigba ti eyi ri bẹẹ nipa bi a ti bi Jesu, wọn kò jé̩ gbagbọ. O kọja ironu ọpọlọ wọn bi a ti ṣe le bi ọmọ lai ni baba ti a foju ri, wọn si kọ lati fi ọkàn gbagbọ pe O jé̩ Ọmọ mimọ Ọlọrun.

Awọn Ẹlẹri ti o Gbagbọ

Anderu jé̩ ọkan ninu awọn Apọsteli ti a kọ pè. Nigba ti o n sọ fun Peteru nipa Jesu, o wi pe, “Awa ti ri Messia,” itumọ eyi ti i ṣe Kristi naa, tabi Ẹni Ami-òroró, ti yoo mu igbala wa fun aye yii. Ni ọjọ keji, Filippi tẹle Jesu, o si wi fun Natanaẹli pe, “Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rè̩.” Natanaẹli gbagbọ, o si wi pe, “Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israẹli.” Awọn Apọsteli wọnyi gbagbọ lati ibẹrẹ pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun lati Ọrun wá. Jesu sọ fun wọn lẹyin igba naa pe: “Baba tikararè̩ fẹran nyin, nitoriti ẹnyin ti fẹràn mi, ẹ si ti gbagbọ pe, lọdọ Ọlọrun li emi ti jade wá” (Johannu 16:27).

Ifihan pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu

Nipa iṣẹ-iyanu ti Jesu ṣe O fi hàn pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe. Iṣẹ-iyanu Rè̩ ekinni ṣẹlẹ nibi igbeyawo ni Kana ti Galili nibi ti O ti sọ omi di waini. Nipa ṣiṣe eyi, O “fi ogo rè̩ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rè̩ si gbà a gbọ” (Johannu 2:11), wọn gbagbọ pe Oun ni Ọmọ Ọlọrun. Pẹlu iwọnba iṣu akara marun un ati ẹja kekeke meji O bọ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan. O sọ okú di alaaye.

Jesu rin lori omi, eyi ti eniyan kan ṣa kò le ṣe. Nigba ti awọn ọmọ-ẹyin ti wọn wà ninu ọkọ ri I ti O n bọ lọdọ wọn, ẹru bà wọn, nitori wọn ro pe iwin ni wọn ri. S̩ugbọn Jesu wi fun wọn pe, “Emi ni; ẹ má bè̩ru.” Loju kan naa ti Jesu ti bọ sinu ọkọ wọn, wọn ti de apa keji ebute. Iṣẹ-iyanu miiran ni eyi jé̩.

S̩ugbọn ohun ti o tobi ju lọ ti o fi hàn pe Ọmọ Ọlọrun ni ni pe O ni agbara lati fi ẹmi Rè̩ lelẹ ki O si tun gbà a pada; O ni agbara lati kú ki O si tun jinde ninu ara Rè̩ ologo. Bi O ti ṣe sọ ọ ni yi: “Ẹ wó tẹmpili yi palè̩, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró.” Ọrọ yii yà awọn Ju lẹnu o si bi wọn ninu, ṣugbọn Tẹmpili wọn ti wọn fi okuta marbili kọ, ti i ṣe ile ijọsin wọn kọ ni O n sọrọ rè̩. “On nsọ ti tempili ara rè̩” (Johannu 2:21). Ajinde Rè̩ kò ni jẹ ti ẹmi, ṣugbọn ara Rè̩ yoo ti inu iboji jade. Awọn ọmọ-ẹyin ranti ọrọ yii lẹyin ti Jesu jinde kuro ninu okú.

Awọn ẹmi eṣu paapaa jẹri pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu. Ni igba kan wọn kigbe soke wi pe: “Kini ṣe tawa tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun? iwọ wá lati da wa loro ki o to akokò?” (Matteu 8:29).

Lati Ẹnu Ẹlẹri Meji

Jesu tun ni ẹri miiran lati fi hàn pe lati Ọrun ni Oun ti wá. “Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe”, O sọ fun awọn Farisi pe “otitọ li ẹri enia meji” (Johannu 8:17). Oun tikara Rè̩ jẹ ẹri kan nipa iṣẹ-iyanu ti O n ṣe. Baba ti O ran An jẹ ẹlẹri keji. Ni ẹẹmẹta ni ohùn Ọlọrun sọrọ lati Ọrun wá, lati fi ọmọ Rè̩ hàn. “Eyiyi li ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.”

Ki a to de opin Iwe Ihinrere ti Johannu, o kọ wi pe, “Wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, Ọmọ Ọlọrun; ati ni gbigbàgbọ, ki ẹnyin ki o le ni ìye li orukọ rè̩” (Johannu 20:31).

Nwọn n S̩iṣẹ Papọ

Jesu ba Baba ṣiṣẹ pọ. O wi pe, “Ọkan li emi ati Baba mi jasi” (Johannu 10:30); “Emi kò le ṣe ohun kan fun ara mi,” “Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ.” S̩ugbọn O bu ọlá fun Baba: “Baba mi tobi jù mi lọ” (Johannu 14:28). Ninu iwe Johannu a ri ju igba ọgọrun lọ ti Jesu pe Ọlọrun ni Baba Rè̩.

Ni oru ọjọ ti a fi Jesu hàn, O bá awọn Apọsteli Rè̩ sọ ọrọ pupọ. O sọrọ pupọ nipa ipo ti Oun wà pẹlu Baba. O mọ wi pe li ọwọ Oun ni gbogbo Etutu fun Irapada wà, ati pe, “lọdọ Ọlọrun li on ti wá, on si nlọ sọdọ Ọlọrun.” Ọjọ aye Rè̩ kukuru fẹrẹ buṣe, wakati pataki ju lọ ti Oun titori rè̩ wá sinu aye si kù si dè̩dẹ. O mọ pe fun igba diẹ awọn Apọsteli Rè̩ yoo fi I silẹ, ṣugbọn O wi pe: “S̩ugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi” (Johannu 16:32).

Iribọmi Jesu

A ti tẹnu mọ irẹpọ ti o wà laaarin Ọlọrun Baba, ati Ọlọrun Ọmọ, a si ti fi hàn pe wọn jẹ Ẹni meji ti n ṣiṣẹ papọ. S̩ugbọn lati ipilẹṣẹ ni a ti ri ẹri nipa ti Ẹni kẹta ninu Mẹtalọkan. Nigba ti a ti ọwọ Johannu Baptisti ri Jesu bọmi ni odo Jọrdani O rin wọ inu omi lọ, Johannu si kede pe Oun ni “Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó è̩ṣẹ aiye lọ!” Nigba ti isin iribọmi naa buṣe, Ẹmi Ọlọrun (Ẹmi Mimọ) bà le Jesu ni awọ àdaba; a si gbọ bi ohun Ọlọrun ni Ọrun ti n wi pe, “Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi” (Luku 3:22). Johannu Baptisti wi pe: “Emi si ti ri, emi si ti njẹri pe, Eyi li Ọmọ Ọlọrun.”

Olutunu

Ni alẹ ikẹyin ti Jesu lo pẹlu awọn Apọsteli Rè̩ ninu aye, O ṣe alaye nipa iṣẹ Ẹmi Mimọ, Ẹni ti Oun pe ni Olutunu. O wi pe Oun kò le ṣai má lọ si Ọrun ki Olutunu ba le wá lati maa tọ wọn. Ninu Johannu 14:26, a ka nipa gbogbo awọn Ẹni mẹtẹẹta ti wọn papọ jé̩ Ọlọrun: “Olutunu na, Ẹmi Mimọ, ẹniti Baba yio rán li orukọ mi, on ni yio kọ nyin li ohun gbogbo.” Ọlọrun Baba, ni orukọ Ọlọrun Ọmọ, ni yoo rán Olutunu, eyi nì ni Ọlọrun Ẹmi Mimọ, sinu aye lati maa gbé inu awọn eniyan Rè̩. Yoo sọ fun wọn sii nipa Jesu, Oun kò si ni sọ nipa ara Rè̩. Yoo si tun fun wọn ni agbara lati jé̩ ẹlẹri fun Jesu.

Ninu ọrọ ikẹyin ti Jesu sọ nipa aṣẹ nla nì O jẹwọ awọn Ẹni mẹta ninu ọkan ṣoṣo, O si ran awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lọ si gbogbo aye lati maa waasu Ihinrere fun gbogbo awọn orilẹ-ède, ki wọn maa “baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19). Aṣẹ Jesu ni eyi jé̩, a si ni lati ṣe bi O ti palaṣẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ohun pataki ju lọ ti o mu ki Johannu Apọsteli kọ awọn iwe rè̩?
  2. Njẹ Johannu mọ Jesu daradara?
  3. Ki ni awọn ọrọ ti a fi bẹrẹ iwe Ifihan?
  4. Awọn Ẹni meloo ni wọn papọ jé̩ Ọlọrun kan ṣoṣo? ta ni wọn i ṣe?
  5. Ki ni ṣe ti Jesu fi wá sinu aye?
  6. Ni orukọ ta ni a maa n gbadura si Ọlọrun Baba?
  7. Darukọ awon kan ti wọn gbagbọ ti wọn si kọkọ jé̩ ẹlẹri pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe.
  8. Sọ diẹ ninu awọn ọna ti Jesu gbà fi hàn pé Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe?
  9. S̩e alaye ohun ti o ṣẹlẹ lẹyin ti a ti ṣe iribọmi fun Jesu.
  10. Ka akọsọri awọn ọrọ ti Jesu wi pe ki a maa lo nigba iribọmi (Matteu 28:19).