Johannu 17:21-23; Galatia 5:22, 23; Efesu 4:17-32; 5:25-27; Kolosse 3:1-15; Titu 2:11-14

Lesson 263 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ mā lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa” (Heberu 12:14).
Notes

Igbesi-ayé Titun

ẹkọ yii a nkọ nipa igbesi-aye Onigbagbọ. Nigba ti eniyan ba ri igbala, yio maa gbe igbesi-aye titun. Aye rè̩ ti yipada kò si tun gbé iru igbesi-aye ti o ti n gbe tẹlẹ ki o to ri igbala. Oun kii ṣe bi awọn ti kò mọ Ọlọrun. Oun kii ṣe bi awọn ẹlẹṣẹ ti n ṣe. Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn o jẹ “iṣura .. jú gbogbo enia lọ” fun Oun bi wọn ba gbọran si aṣẹ Oun (Ẹksodu 19:5). Jesu n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ jẹ “ini on tikalarẹ, awọn onitara iṣẹ rere” (Titu 2:14).

Onigbagbọ kò tun si ninu è̩ṣẹ mọ, ṣugbọn o wà “ninu Kristi ...ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i nwọn si di titun” (2Kọrinti 5:17). Nigba ti eniyan bá ri igbala, a dari awọn è̩ṣẹ rè̩ ji i, a o si mu wọn kuro ninu ayé rè̩. Bi o ti n gbadura ti o si ṣe ifararubọ aye rè̩, Oluwa yoo sọ ọ di mimọ. A ti kọ nipa isọdi-mimọ ninu Ẹkọ 232 ati 238. Jesu gbadura bayii fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩: “Sọ wọn di mimọ ninu otitọ: otitọ li ọrọ rẹ” (Johannu 17:17). Jesu gbadura pe ki iṣọkan ki o wà laaarin awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ (Johannu 17:21). Isọdi-mimọ ni o n mu iṣọkan pipe ati wiwà ni ọkàn kan yii wá. Awọn eniyan ti a sọ di mimọ a maa wà ni imọ kan. A ti ṣe apejuwe rè̩ pe igbala dabi igba ti a ba ge igi lulẹ, isọdi-mimọ si dabi fifa kukute ati gbongbo rè̩ tu. Siwaju sii apejuwe miiran fi han pe nigba ti a ba gba eniyan là, a kan ẹda è̩ṣẹ -- “ogbologbo ọkunrin ni” -- mọ Agbelebu, ṣugbọn nigba ti a ba sọ ọ di mimọ “ogbologbo ọkunrin ni” yoo kú. Nigba ti Paulu n kọwe si awọn ara Efesu, o gbà wọn niyanju lati bọ “ogbologbo ọkunrin ni” silẹ ati gbogbo iwa atijọ ki wọn si gbé “ọkunrin titun nì wọ, eyiti a dá nipa ti Ọlọrun li ododo ati li iwa mimọ otitọ” (Efesu 4:22-24).

Paulu kọwe si awọn ara Kolosse pe nipa gbigbe “ọkunrin titun nì” wọ, ọmọ-ẹyin Kristi yoo ni aworan Ọlọrun ẹni ti o dá a (Kolosse 3:10). Yoo maa ronu awọn nnkan ti o wà loke, kìi ṣe awọn nnkan ini aye yii (Kolosse 3:2). Awọn nnkan ti ẹmi ni akọkọ ni igbesi-aye rè̩, ki o to kan ohun ti ara. Alaafia Ọlọrun ni n ṣakoso ọkàn rè̩, ifẹ si wà ninu ọkan rè̩ pẹlu “ti iṣe àmure iwa pipé” (Kolosse 3:14, 15). Ami kan ti a fi le mọ pe ẹni kan jẹ ọmọ-ẹyin Jesu ni nini ifẹ si awọn Onigbagbọ iyokù, nitori pe Bibeli sọ fun wa bayi: “Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin” (Johannu 13:35).

Lẹyin nini ifẹ lọkàn, awọn oore-ọfẹ Onigbagbọ miiran yoo tun pẹlu. Ninu awọn “eso Ẹmi” ni “ayọ, alafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ, iwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu”, awọn wọnyi ni o pẹlu ifẹ (Galatia 5:22, 23). A le mọ ẹni ti i ṣe Onigbagbọ nipa igbesi-aye ti o n gbé. “Nipa eso wọn li ẹnyin o fi mọ wọn” (Ka Matteu 7:15-20). Bi eniyan kò ba sọ otitọ, i baa ṣe ọmọde tabi agba, eyi fi han pe kò i ti ri igbala ni tootọ, nitori pe Bibeli kọ wa bayii, “Ẹ má si ṣe purọ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣẹ rè̩” (Kolosse 3:9). Bi ọkan ninu awọn ẹlẹgbẹ rẹ ba wi pe oun ti ri igbala, ti o si binu nigba ti kò le té̩ ifẹ ọkàn rè̩ lọrun, tabi ti o bẹrẹ si sọ ọrọ buburu ati ọrọ irira, iwọ o mọ pe, kò ni igbala mọ, nitori pe Ọrọ Ọlọrun wi pe: “S̩ugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin” (Kolosse 3:8).

Jesu, Apẹẹrẹ Wa

Nigba ti Oluwa ba pe eniyan lati tẹle E, O pè wọn lati “tọ ipasẹ rè̩.” O pe wọn lati gbe igbesi-aye bi ti Kristi (igbesi-aye Onigbagbọ.) Kristi ti fi apẹẹrẹ gbigbe igbesi-aye ti o tọ lelẹ fun wa. A kà bayii ninu Bibeli, “Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mā tọ ipasẹ rè̩” (I Peteru 2:21).

Nigba ti Kristi n gbe ni aye yii, a dan An wò ni gbogbo ọna ti a gba fi n dan wa wò, sibẹ O wà “lailè̩ṣẹ” (Heberu 4:15). Apẹẹrẹ igbesi-aye Onigbagbọ ti O gbe jẹ igbesi-aye ailẹṣẹ. Bi a ba tẹle ipasẹ Rè̩, a o gbé igbesi-aye wa bi Jesu ti fẹ ki a gbé.

Agbara lati Pa Ni Mọ

Nitori pe Jesu bori idanwo, O le ran wa lọwọ nigba ti a ba n dan wa wò (Heberu 2:18). Oluwa ti ṣeleri lati ṣe “ọna atiyọ” ninu idanwo ki a ba le dojuja kọ è̩ṣẹ (1Kọrinti 10:13). A le tẹle apẹẹrẹ igbesi-aye ailẹṣẹ Rè̩ nipa gbigbadura ati wiwo Oluwa ti O lagbara lati pa wa mọ kuro ninu ikọsè̩ (Juda 20-24). Peteru wi pe awọn ti a gbala ni a “npamọ nipa agbara Ọlọrun nipa igbagbọ si igbala” (1Peteru 1:5).

Nipa agbara Ọlọrun ati nipa oore-ọfẹ Rè̩ ni a n pa Onigbagbọ mọ, nitori pe eniyan kò le pa ara rè̩ mọ nipa agbara oun tikara rè̩. Nigba kan ti Satani n yọ Paulu lẹnu, Paulu gbadura. Oluwa dahun bayi, “Ore-ọfẹ mi to fun ọ” (2Kọrinti 12:8, 9). Nigba ti Satani ba n sọrọ kẹlẹkẹlẹ si ọ leti lati mu ọ lọ dẹṣẹ, tabi nigba ti ẹni kan ba n rọ ọ lati lọ ṣe ohun ti kò tọ, gbadura ki o si ni ki Ọlọrun ran ọ lọwọ lati ṣe ohun ti o dara ni oju Rè̩. A ti gbà wa niyanju lati “wá si ibi itẹ ore-ọfẹ pẹlu igboya, ki a le ri ānu gbà, ki a si ri ọre-ọfẹ lati mā ran-ni-lọwọ ni akoko ti o wọ” (Heberu 4:16). Itumọ eyi ni pe a le gbadura lati beere fun iranlọwọ Ọlọrun, Oun yoo si pa wa mọ kuro ninu è̩ṣẹ nigba ti a ba gbọran si aṣẹ Rè̩ ti a si gba A gbọ.

Ohun ti a ni lati S̩e

Afi bi a ba tẹle apẹẹrẹ igbesi-aye Jesu ti a si gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun, lai ṣe eyi a kii ṣe Onigbagbọ. Jesu wi pe, “Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rè̩, ki o si ma tọ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi” (Luku 14:27). Awọn miiran le wi pe kò ṣe e ṣe lati gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun. Awọn miiran si le wi pe o dara fun awọn diẹ lati gbe igbesi-aye ailẹṣẹ -- ṣugbọn pe ki i ṣe ọranyan fun gbogbo Onigbagbọ lati gbe igbesi-aye mimọ. S̩ugbọn bi a ti n yẹ Ọrọ Ọlọrun wò, a rii pe gbogbo awọn ti wọn jẹwọ pe wọn fẹran Kristi a maa gbe igbesi-aye aileeri, ti ododo, iwa-bi-Ọlọrun, bi kò ba ri bẹẹ wọn ki i ṣe Onigbagbọ. A ti pese oore-ọfẹ ati agbara ti awọn Onigbagbọ n fẹ lati ran wọn lọwọ lati gbe iru igbesi-aye yii silẹ, Ọlọrun si n beere pe ki wọn gbe igbesi-aye wọn bẹẹ. A kò le ṣe ọmọ-ẹyin bi a kò ba tẹle Jesu. Ki i ṣe ti Onigbagbọ lati yàn bi oun yoo gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun tabi bẹẹ kọ. Ni tootọ eniyan le yàn lati jé̩ Onigbagbọ tabi lati jé̩ ẹlẹṣẹ. S̩ugbọn Oluwa ti fi ofin lelẹ fun gbigbe igbesi-aye Onigbagbọ, O si maa n fun ni lagbara lati gbe bẹẹ gẹgẹ. A ni lati pa awọn ofin wọnyi mọ bi a ba jé̩ Onigbagbọ.

È̩ṣẹ mu Iyapa Wa

Bi eniyan ba ru ofin Ọlọrun, yoo jiya. Nigba ti Adamu ọkunrin kin-in-ni, ṣaigbọran si ofin kin-in-ni ti Ọlọrun fi fun un, Adamu dẹṣẹ o si kú ikú ẹmí. Ibẹru ti idalẹbi wọ inu ọkàn rè̩ o si fi ara rè̩ pamọ nigba ti o “gbọ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrin ninu ọgbà ni itura ọjọ” (Gẹnẹsisi 3:8). È̩ṣẹ rè̩ ti yà a kuro lọdọ Ọlọrun. Adamu kò tun le wà ninu ọgba Edẹni mọ “lati ma ro o, ati lati ma ṣọ ọ,” bẹẹ ni kò si le ba Oluwa rin ki o si ba A sọrọ mọ.

Igbọran ati Ibukun

Lẹyin eyi, Ọlọrun fi Ofin fun awọn Ọmọ Israẹli nipasẹ Mose alakoso wọn. A sọ ohun ti wọn ni lati ṣe ati ohun ti wọn kò gbọdọ ṣe fun wọn. Bi awọn Ọmọ Israẹli ba n fẹ ki aabo, iranlọwọ, ati ileri Ọlọrun jẹ ini wọn, wọn ni lati gbọran si aṣẹ Rè̩. Nigba ti wọn ba gbọran, Ọlọrun maa n wà pẹlu won, wọn a si ṣe rere. Nigba ti wọn ba ṣaigbọran, Ọlọrun yoo fi wọn silẹ, wọn a si jiya fun è̩ṣẹ wọn. A kà ninu Majẹmu Laelae nipa awọn ibukun ti awọn Ọmọ Israẹli ri gbà nigba ti wọn gbọran si aṣẹ Ọlọrun, a si tun kà nipa ìyà ati ibanujẹ ti o ba wọn nigba ti Ọlọrun kọ wọn silẹ nitori aigbọran wọn.

Ninu Majẹmu Titun Jesu fun wa ni ofin fun igbesi-aye Onigbagbọ nipa apẹẹrẹ Oun tikara Rè̩, ẹkọ Rè̩, ati nipa ẹkọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti o tipasẹ imisi Ẹmi-Mimọ wá. Bẹẹ ni a n ri apẹẹrẹ igbesi-aye ododo ninu ayé awọn Onigbagbọ tootọ loni. Awọn ti o ti dan Ọrọ Ọlọrun wò ti rii pe o ṣe e ṣe ati pe awọn paapaa n gbe igbesi-aye ti o bá ilana Ọlọrun mu nipa agbara Ọlọrun. A le gbé igbesi-aye bi ti Kristi nipa oore-ọfẹ Ọlọrun. A gbọdọ gbe igbesi-aye wa bẹẹ bi a ba jé̩ Onigbagbọ. Kiki awọn Onigbagbọ ni yoo wọ Ọrun ti wọn yoo ri Oluwa ti wọn yoo si maa ba A gbé.

Iṣọkan

Jesu gbadura pe ki a so awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pọ ṣọkan ninu idipọ ifẹ. A so awọn Onigbagbọ pọ pẹlu ara wọn, a si dà wọn pọ gẹgẹ bi ara kan pẹlu Ọlọrun ati Ọmọ Rè̩. Jesu wi pe “Ọkan li emi ati Baba mi jasi” (Johannu 10:30). Ilana ati ifẹ Ọlọrun ni pe ki awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ -- awọn Onigbagbọ -- jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun ati Ọmọ Rè̩ (Johannu 17:21). Wọn ni lati ni ipinnu ati ilepa kan naa, ifẹ ati adura kan naa, kikọ ihà kan naa si è̩ṣẹ, ati ifẹ kan naa fun iwa otitọ.

Iṣọkan wọn jẹ ẹri – “ki aiye ki o le gbagbọ” ati pe “ki aiye ki o le mọ.” Bi igbesi-aye Onigbagbọ kò ba yatọ si ti ẹnikẹni, bawo ni aye ti ṣe le mọ pe Jesu n gbe inu rè̩, ati pe Kristi ni agbara lati gba ni la kuro ninu è̩ṣẹ?

Ẹnikẹni ti kò ba gbe igbesi-aye ododo kò le jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun ati Ọmọ Rè̩. “Gbogbo ẹniti nṣe aiṣododo, irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ” (Deuteronomi 25:16). “Bḝni ibi kò le ba ọ gbe” (Orin Dafidi 5:4). Bi è̩ṣẹ ati aigbọran ba wọ inu igbesi-aye Onigbagbọ, oun kò tun ni le gbadun iṣọkan ti o so o pọ mọ Ọlọrun ati Ọmọ Rè̩, Jesu mọ. Oluwa kò ni inudidun si è̩ṣẹ, è̩ṣẹ a si maa ya eniyan kuro lọdọ Ọlọrun (Isaiah 59:2). Bi eniyan ba dẹṣẹ kò tun si ni irẹpọ pẹlu Oluwa mọ, nitori pe “ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni” (1Johannu 3:8).

Ni Aye Isisiyi

Jesu “fi ara rè̩ funni” O si ta Ẹjẹ Rè̩ silẹ fun awọn eniyan Rè̩ -- Ijọ (Efesu 5:25). Jesu ní “ijọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni ... mimọ ati alaini àbuku” (Efesu 5:27). Ijọ le jẹ mimọ nigba ti awọn eniyan inu rè̩ ba jẹ mimọ. Agbara wà ninu Ẹjẹ Jesu lati sọ eniyan di mimọ ati alaileeri, ati lati mu u wà ni mimọ ati alaileeri. Jobu, eniyan Ọlọrun wi pe, “Olododo pẹlu yio di ọna rè̩ mu, ati ọlọwọ mimọ yio ma lera siwaju” (Jobu 17:9).

Bibeli kọ wa pe a ni lati gbe igbesi-aye mimọ nihinyi bi a ba fẹ jẹ ọkan ninu Ijọ Kristi, bi a ba si n fẹ lọ si Ọrun. “Ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá” ni o tun n kọ wa pe, “ki a sé̩ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mā wà li airekọja, li ododo, ati ni iwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi” (Titu 2:11, 12).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni n mu ki eniyan gbe igbesi-aye ti o yatọ lẹyin ti o ba ti ri igbala?
  2. Ki ni “eso Ẹmi”?
  3. Ta ni apẹẹrẹ igbesi-aye Onigbagbọ fun wa?
  4. Bawo ni Onigbagbọ ti ṣe le jẹri nipa Jesu fun ayé?
  5. Ki ni itumọ “Onigbagbọ”?
  6. Oore-ọfẹ ta ni to lati ran wa lọwọ ni igba ti a n fẹ iranlọwọ?
  7. Ki ni itumọ jijẹ “ọkan” pẹlu Ọlọrun Baba ati Jesu, Ọmọ Rè̩?
  8. Pari ọrọ yii “Ẹniti o ba n dẹṣẹ ti ...”
  9. Iru awọn eniyan wo ni Jesu ni ninu Ijọ Rè̩?
  10. Nigba wo ati nibo ni awọn Onigbagbọ ti n gbe igbesi-aye mimọ ati alaileeri?