Gẹnẹsisi 14:18-20; 28:20-22; Lefitiku 27:30-32; Deuteronomi 16:16, 17; Malaki 3:8-10; Matteu 23:23; Luku 18:12; 21:1-4; 1Kọrinti 16:2

Lesson 264 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ” (2Kọrinti 9:7).
Notes

Abrahamu Olóòótọ

Lẹẹkan sii ẹkọ wa tun lọ sinu iṣẹlẹ kan ninu igbesi-aye Abrahamu ẹni ti a pe ni baba Igbagbọ, ọrẹ Ọlọrun ati baba orilẹ-ède pupọ. A mọ Abrahamu fun igbagbọ ati igbọran rè̩ si Ọlọrun.

Lati igbàa nì, ni kete ti a ti dá aye, ni ogun ti wà, gẹgẹ bi o ti wà loni pẹlu. Ni ọjọ kan Abramu, (orukọ yii ni a fi n pe e nigba naa) gbọ pé ogun ọta kan ti di Lọti ọmọ arakunrin rè̩ ni igbekun, a si ti kó awọn ara ile rè̩ ati gbogbo ẹrù rẹ lọ. Loju kan naa, Abramu fi ihamọra wọ awọn iranṣẹ rè̩, awọn ọọdunrun-le-mejidinlogun (318) eniyan ti a ti kọ, o si lepa awọn ota naa. O ni iṣẹgun nla, o gba Lọti ọmọ arakunrin rè̩ silẹ ti oun ti awọn ara ile rè̩, o si gbà awọn ẹrù ti a ti kó lọ pada.

Nigba ti Abramu n bọ lati oju ogun naa Mẹlkisedeki, Ọba Salẹmu pade rè̩ o si ki i. Ọba Ododo ati Ọba Alaafia ni a pe ẹni abami yii ninu Iwe Mimọ; a si wi pe o wà “laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bḝni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye, ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun” (Heberu 7:2, 3). Mẹlkisedeki sure fun Abramu, eyi ti o fi han pe o tilẹ ju Abramu lọ (Heberu 7:6, 7). Ti ẹni ti o fara han ninu Majẹmu Laelae yii ki ba i ṣe Kristi tikara Rè̩, O jẹ apẹẹrẹ Kristi. Lati fi ẹmi imoore han, Abramu dá idamẹwaa fun Mẹlkisedeki. Eyi ni igba kin-in-ni ti a sọrọ nipa idamẹwaa ninu Bibeli.

Ọmọ-ọmọ Abrahamu

Ni iwọn aadọjọ (150) ọdun lẹyin naa nigba ti Jakọbu ọmọ-ọmọ Abrahamu n salọ kuro niwaju arakunrin rè̩, ilẹ ṣú u, o si dubulẹ sori erupẹ ilẹ o si fi okuta ṣe irọri. Ninu ala rè̩ o ri akasọ kan ti o gùn lati aye lọ si Ọrun, awọn angẹli Ọlọrun si n lọ wọn si n bọ lori rè̩. Ni oke akasọ naa ni Oluwa Ọlọrun dúró. Nigba ti Jakọbu ji o wi pe, “OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ; emi kò si mọ ... eyi si li ẹnubode ọrun” (Gẹnẹsisi 28:16, 17). O wá mu okuta ti o ti fi ṣe irọri rè̩ o si ta ororo si ori rè̩. “Jakọbu si jé̩ ẹjé̩ wipe, Bi Ọlọrun ba pẹlu mi, ti o si pa mi mọ li ọna yi ti emi ntọ, ti o si fun mi li ohun jijẹ, ati aṣọ bibora, ti mo si pada wá si ile baba mi li alafia; njẹ OLUWA ni yio ma ṣe Ọlọrun mi ... ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rè̩ fun ọ” (Gẹnẹsisi 28:20-22). O ṣe e ṣe ki o jẹ lati ọdọ Isaaki baba rè̩ tabi lati ọdọ Abrahamu baba rè̩ agba ni o ti kọ è̩kọ nipa ọran idamẹwa.

Nigba ti o ṣe, ni akoko ijọba Jehoaṣi, Jehoiada alufa mu apoti kan o si dá ideri rè̩ lu o si fi i si ẹba pẹpẹ ni apa ọtun ẹnu-ọna ile-isin (2Awọn Ọba 12:9). Owo ti wọn ri kó jọ ni wọn fi ṣe abojuto Ile Oluwa.

Ilana Ọlọrun fun Ikowojọ

Ọlọrun lana eto idamẹwaa, kii ṣe nitori pe O wà ninu aini ti O si n fẹ gba ohun ti eniyan ni, ṣugbọn nitori pe ọna bayii ni O là fun abojuto iṣẹ Rè̩. Ti Ọlọrun ni gbogbo ẹrankẹran ti o wà lori ẹgbẹrun òke, ti Rè̩ si ni fadaka ati wura. A beere lọwọ awọn Ọmọ Israẹli ti wọn jẹ agbẹ lati fun Ọlọrun ni ohun ti i ṣe ti rè̩. Kii ṣe ti wọn, ti Ọlọrun ni nitori pe Oun ni o fun wọn ni gbogbo ohun ti wọn ni. Ọlọrun ni o ni ilẹ ti o mu irugbin jade; Ọlọrun ni o ni ojo ti o mu un dàgbà; Ọlọrun ni o si mu ki o ṣe e ṣe fun wọn lati dá apa kan ninu ibisi wọn ti Oun ti yàn fun ara Rè̩, eyi nì ni idamẹwaa, pada fun Oun.

“Gbogbo idamẹwa ọwọ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jé̩ mimọ fun OLUWA” (Lefitiku 27:32).

Ọgbọn ti wọn lò lati fi maa ya idamẹwaa ẹran-ọsin wọn sọtọ ni yii: wọn mu ki awọn ẹran naa kọja ni kọọkan laaarin ẹnu-ọna tooro kan, ẹni kan si wà nibẹ lati maa sàmi si è̩yin olukuluku ẹkẹwaa. Loni awa ha n kiyesara to bayii lati yà idamẹwaa ibisi ohun-ini wa sọtọ fun Oluwa, yala o jẹ ẹran-ọsin ni, tabi ile, tabi owó?

Igbọran ṣe Pataki

Awọn kan ro pe ni igba Majẹmu Laelae nikan ni a ti n san idamẹwa, ṣugbọn a rii pe a kọ ni bẹẹ pẹlu ninu Majẹmu Titun. Ohun ti Jesu sọ fun awọn akọwe ati awọn Farisi ni pe o yẹ ki wọn maa san idamẹwaa, ki wọn si tun maa boju to awọn ọran ti o tobi ju bi idajọ, aanu, ati igbagbọ (Matteu 23:23). Gbogbo aṣẹ Jesu ni o ṣe pataki; ṣugbọn awọn kan ṣe pataki ju, wọn si tobi ju awọn miiran lọ. Nipa awọn aṣẹ kan O wi pe, “wọnyi li o tọ ti ẹnyin iba ṣe,” awọn aṣẹ iyoku ni kò si yẹ ki wọn fi silẹ lai ṣe.

Ohunkohun ti o ba ṣẹṣẹ wọle fun eniyan gẹgẹ bi ìní ni o gbọdọ san idá kan ninu mẹwaa lori rè̩, yala owo oṣu, tabi èrè ti o jẹ lori ọja lẹyin ti o ba ti yọ iye owo ọja ati owo miiran ti o ná lori ọja naa kuro, tabi ohun ti o di ti rè̩ ni ọnakọna miiran. A kò gbọdọ yọ owo ounjẹ tabi owo ile wa ki a to da idamẹwaa. O tilẹ yẹ ki awọn ọmọde kọ lati maa fun Ọlọrun ni kọbọ kan lori naira kọọkan ti wọn ba ni.

Kò si ẹni ti o ti i padanu nipa fifi gbogbo ọkàn rè̩ sin Ọlọrun, bẹẹ ni kò si ẹni ti o ti i jere nipa fifi aabọ ọkàn sin In. Ibukun maa n wà fun awọn eniyan Ọlọrun nigba kuugba ti wọn ba san idamẹwaa. Boya ibeere yii le ti ẹnu ẹnikẹni jade: “S̩e ọranyan ni, tabi ti mo ba fẹ ni mo le san idamẹwaa?” Ọrọ Ọlọrun fun wa ni idahun:

“Enia yio ha jà Ọlọrun li olè? ṣugbọn ẹnyin sa ti jà mi li olè. S̩ugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa fi jà ọ li olè? Nipa idamẹwa ati ọrẹ.

“Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè, ani gbogbo orilẹ-ède yi.

“Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobḝ ti ki yio si aye to lati gbà a”(Malaki 3:8-10).

Njẹ a ri i bayii pe ẹnikẹni ti kò ba san idamẹwaa rè̩ jé̩ ole tabi ọlọṣà. Iwa buburu ni lati ja Ọlọrun lólè ọrẹ atinuwa, ṣugbọn o tilẹ buru rekọja lati ja A lólè idamẹwaa! Kii ṣe ti rẹ tabi temi – “Ti OLUWA ni” (Lefitiku 27:30-32). Bi o ba tete fẹ ri ibukun gbà lati Oke wá, mu “gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura.” O le jẹ pe kii ṣe idamẹwa owó nikan ni o ti fi dù Ọlọrun, ṣugbọn idamẹwa ifẹ, iyọọda ara rẹ fun iṣẹ, ifararubọ tabi talẹnti pẹlu. Ronu lori igbesi-aye rẹ; bi iwọ kò ba n ri ibukun Ọlọrun lori rẹ, o le jẹ pe, ni ọna kan tabi ọna miiran, o ti n ja Ọlọrun lólè. Bi a ba n reti pe ki Ọlọrun ṣi ile iṣura Rè̩, a ni lati ṣi ti wa naa pẹlu.

Ni idi Iṣẹ Oluwa

A ti kọ ninu awọn ẹkọ wa iṣaaju nipa awọn Ọmọ Lefi, awọn ti a yà sọtọ fun awọn iṣẹ-isin kan fun Ọlọrun, bi lati maa ran awọn alufáà lọwọ, lati maa ru Agọ, ati lati maa ni ipin ninu ohun elo orin lilo ati orin kikọ (1Kronika 25:1; 15:16-22; 2Kronika 5:13). Gẹgẹ bi a ti ni awọn olóòótọ oniwaasu tabi alabojuto loni ti wọn n fi gbogbo akoko wọn ṣe itọju awọn eniyan mimọ Ọlọrun, awọn wọnyii fi gbogbo akoko wọn silẹ fun iṣẹ Ọlọrun. Gẹgẹ bi o si ti n ri loni, ẹtọ ni pe ki ijọ maa bojuto wọn nipa jijẹ ati mimu ati lilò. Paulu Apọsteli wi pe, “Ẹnyin kò mọ pe awon ti nṣiṣe nipa ohun mimọ, nwọn a mā jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ... Gẹgẹ bḝli Oluwa si ṣe ilana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere” (1Kọrinti 9:13, 14). O yẹ ki a ni ẹmi imoore fun awọn alakoso tootọ ti wọn n fi ohun pupọ dù ara wọn ki wọn ba le bojuto awọn ọmọ Ọlọrun! A sọ fun wa pe ki a “mā bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn” (1Tẹssalonika 5:12, 13).

Ninu iwe Owe 3:9, 10, a ri aṣẹ kan lori eyi ti ileri wà: “Fi ohun-ini rẹ bọwọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: bḝni aká rẹ yio kún fun ọpọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun.” Bi a ba mu ilana idamẹwaa yii ṣẹ, ki i ṣe wi pe a o ri ọpọlọpọ ibukun gba fun ara wa nikan, a o si le to iṣura wa jọ si Ọrun pẹlu. Fun abojuto ile Ọlọrun ati iṣẹ Oluwa ni idamẹwaa wà fun. Owo ti a da yoo mu ki o ṣe e ṣe lati fi awọn iwe Ihinrere ranṣẹ jakejado gbogbo agbaye; yoo si tun ṣe iranwọ fun awọn ajihinrere ni okeere, lati pese fun iwaasu Ihinrere lori ẹrọ redio, ati lati polowo awọn ipade; lati fi tọju awọn mọto ayọkẹlẹ ati mọto akero ti Ihinrere, ati awọn ọkọ oju omi ti n tan Ihinrere kalẹ loju omi. Bi a ba n fi igbagbọ, adura ati ifararubọ kún owo ti a n dá, gbogbo wa ni o le ṣe iranwọ lati jere awọn ọkàn ti wọn ṣe iyebiye fun Kristi, ere wa yoo si tobi pupọ.

Awọn ti wọn n ba Ọlọrun rìn timọtimọ ki i jiyan otitọ yii, tabi awọn otitọ miiran ti Iwe Mimọ kọ ni. Laaarin awọn ti kò ri igbala ni ariyanjiyan ti maa n bẹrẹ lori ọrọ yii. Ọlọrun ki i fi ẹni ti n fi otitọ ọkàn beere silẹ ninu okunkun.

A sọ fun ni nipa ọdọmọkunrin kan ti owo oṣu rè̩ kere pupọ. Oluwa fi otitọ sisan idamẹwaa ye e, o si wi pe, “Oluwa emi yoo ṣe e.” Ẹni kan wi fun un pe, “Kò le ṣe e ṣe fun ọ lati san idamẹwaa lori owo rẹ kekere. Aṣa awọn Ju ni igba laelae ni sisan idamẹwaa. Ki i ṣe ti awọn Onigbagbọ ode-oni.” Ọdọmọkunrin naa dahun pe, “Mo ri i pe o jẹ ọranyàn fun mi, o si jẹ ojuṣe mi si Ọlọrun.” O gbọran, Ọlọrun bukun un, O si bu ọla fun un.

Iṣẹ Ọlọrun

Lati inu ilana idamẹwa ati ọrẹ ni Ọlọrun ti n pese fun iṣẹ Ijọ Igbagbọ Apọsteli (Apostolic Faith,) kò si si igbà kan ri ti a gbe igbá idawo tabi apo isọwosi kiri. Ni ẹyin ile isin lara ogiri ni a gbe apoti kekere kan si ninu eyi ti awọn eniyan le maa sọ idamẹwaa ati orẹ wọn si. Ọlọrun nikan ṣoṣo ati ẹni ti o mu ọrẹ naa wa ni o mọ iye owo ti a sọ sinu apoti naa. Gbogbo awọn Onigbagbọ ti a ti tunbi ni tootọ ti wọn si ni imọlẹ nipa ẹkọ ododo Ihinrere yii ni wọn n mu un ṣe ti wọn si n ri ibukun ti Ọlọrun ṣeleri gbà. “Bi ẹnyin ba mọ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn” (Johannu 13:17).

O ha wi pe “Emi kò lagbara lati san idamẹwaa”? Nnkan ti o wà nibẹ ni pe kò le ṣe ọ ni anfaani lati ṣe aigbọran si eyikeyi ninu awọn aṣẹ Ọlọrun. “Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amìpọ, akún-wọsilẹ ...” (Luku 6:38).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ọkunrin wo ni a kọkọ sọrọ rè̩ ninu Iwe Mimọ nipa sisan idamẹwaa?
  2. Ki ni a sọ nipa awọn ti n ja Ọlọrun lólè?
  3. Sọ itan obinrin opó ti o sọ owo-idẹ wé̩wé̩ meji sinu apoti iṣura.
  4. Ki ni Jesu sọ nipa rè̩?
  5. Ẹkọ wo ni eleyi kọ wa?
  6. Ni akoko awọn Ọmọ Israẹli ki ni a n lo idamẹwaa fun?
  7. Njẹ o ro pe o jẹ ọranyan fun wa lati maa san idamẹwaa?
  8. A ha ri eyikeyi ninu awọn aṣẹ Ọlọrun ti a le kà si eyi ti kò yẹ?