Johannu 15:11-13; Jakọbu 4:4; 1Johannu 2:15-17; Matteu 5:8; 1Kọrinti 6:20; Romu 12:2

Lesson 265 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun” (Matteu 5:8).
Notes

Awọn Ọrẹ

Jesu n fẹ ki awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni inu didun. Nigba ti O pari ọrọ ikẹyin Rè̩ pẹlu awọn Apọsteli ki a to kan An mọ agbelebu, O ni: “Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ mi ki o le wà ninu nyin, ati ki ayọ nyin ki o le kún” (Johannu 15:11). O n fun wọn ni nnkan kan ti yoo fi ayọ kún inu wọn.

Igbala kuro ninu è̩ṣẹ ati iriri ti Ẹmi ti o jinlẹ ju bẹẹ lọ, a maa mu ayọ nlá nlà wá sinu igbesi-aye wa; ṣugbọn eniyan ni a jẹ sibẹsibẹ a si n fẹ ibakẹgbẹ ati idaraya lati mu inu wa dùn nigba ti a wà ni aye nihin.

Jesu mọ bi nini ọrẹ ti ṣe pataki to, O si n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ gbadun ara wọn. Eyi ti o pọ ju ninu akoko Rè̩ ni O maa n lo pẹlu awọn eniyan afi igba ti Oun nikan ba lọ lati gbadura. O fẹran lati lọ si ile Maria, Marta, ati Lasaru lati bè̩ wọn wò. Awọn miiran laaarin awọn Farisi ti wọn n wá ọna lati ri nnkan wi si Jesu, pe E ni “Ọjẹun ati ọmuti” (Luku 7:34), nitori pe Jesu a maa gbadun lilọ si ibi àsè pẹlu awọn ọrẹ Rè̩ ati awọn ti O nireti pe wọn o di ọrẹ Oun nigba ti wọn ba mọ Oun.

Onigbagbọ ni lati kiyesara nipa iru ọrẹ ti o n yàn. Wọn ni lati ni ifẹ si ṣiṣe ohun ti o tọ ki wọn má si ṣe tan an lọ sinu igbadun è̩ṣẹ. Onipsalmu kọ akọsilẹ pe: “Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bè̩ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ rẹ mọ” (Orin Dafidi 119:63). Ọlọrun wi pe: “Ẹ kò mọ pe ibaré̩ aiye iṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jé̩ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun” (Jakọbu 4:4). Nitori naa a ri i bi o ti jẹ ohun pataki lati yàn awọn ọrẹ wa laaarin awọn ti o fẹran Oluwa.

Ere Idaraya ti Ode

Njẹ nisisiyi ti a ti ni ọrẹ, iru awọn nnkan wo ni a le jẹ igbadun rè̩ ti iranti wọn yoo si maa mu inu wa dun? Ọlọrun ti fun wa ni awọn ohun idaraya daradara ti ode lati mu inu wa dùn. Ọpọlọpọ awọn ọmọde ni o n gbadun fifi ẹsẹ rin irin ajo, gigun ori oke, ṣiṣere lori yinyin, lilọ pa agọ, sise ounjẹ lori ina ni ode gbangba, ọdẹ ṣiṣe, ẹja pipa, iluwẹ ninu omi, ati gigun kẹkẹ.

Awọn ọmọde miiran a maa gbadun mimu awọn labalaba ati awọn kokoro miiran, tabi wiwá okuta. Ni igba otutu nigba ti wọn ni lati wà ninu ile wọn le pin awọn nnkan ti wọn kojọ nigba ooru si oriṣiriṣi ọna ki wọn si tò wọn pọ. Wọn le ka iwe lati mọ ohun ijinlẹ nipa iwa awọn ẹranko ati kokoro ati ọgbọn inu ti Ọlọrun fi fun wọn lati gbé, lati kọ ile, lati mu iru ti wọn jade lọna àrà. Ni ile akojọpọ ohun laelae, wọn le ri akojọpọ ti awọn ẹlomiran ti ṣe, eyi ti o n fi gbogbo igbesi-aye awọn ẹranko keekeeke wọnyii ti Ọlọrun ti fun ni ọgbọn ti o pọ bayii hàn.

Yiya fọto le jẹ iṣẹ ọwọdilẹ ti o le fun ni ni inu didun, bẹrẹ pẹlu ẹrọ yiya fọto kekere eyi ti ọmọde paapaa le fi ya aworan ti o dara ni ode gbangba nigba ti oju ọjọ ba dara. Lẹyin eyi o le kọ nipa iṣẹ fọto yiyà ti o tun jinlẹ ju bẹẹ lọ ati yiya fọto oloriṣiriṣi àwọ. Ayọ pupọ ni o le ni, ni ọpọlọpọ irọlẹ nipa fifi awọn aworan rè̩ han awọn ọrẹ rè̩.

A ni lati fi ọrọ ikilọ kan kun un. Ranti pe, iṣẹ wa si Ọlọrun ni akọkọ; a o si gbadun gbogbo nnkan wọnyi gidigidi bi a ba kọkọ kiyesara lati jẹ mimọ, ti a si n ba Oluwa wa sọrọ nigba gbogbo. Yoo kọ wa ni ohun akọtun ati eyi ti o kún fun imisi bi a ti n ka Ọrọ Rè̩.

Orin

Orin ti mu ki igbesi-aye ọpọlọpọ awọn ọdọ layọ. Awọn miiran a maa bẹrẹ ẹkọ wọn ninu orin ki wọn to bẹrẹ si i lọ ile-iwe. Ni ile-iwe wọn a bẹrẹ si i lo ohun elo orin ninu ẹgbẹ alo-ohun-elo orin. Eyi yii fun wọn ni anfaani lati mọ awọn ọmọde miiran ti o n gbadun ohun kan naa ti awọn fẹran. Wọn le lo talẹnti wọn ninu isin Oluwa, pẹlu, eyi ti i maa fun ni ni inu didun sii. Bi imọ eniyan ninu orin rere ti n pọ si i ni yoo maa gbadun titẹtisi awọn ẹgbẹ alo-ohun-elo orin nla, awọn aladakọ-orin ti wọn jé̩ ogbogi ati adapọ lilo ohun-elo orin.

Awọn ọdọ le gbadun ṣiṣe akojọpọ awo rẹkọdu ti a fi gba orin awọṅ ọjọgbọn ninu orin-kikọ silẹ. Nipa pe ki ẹni kan yá ẹni keji lati lo, wọn a ni anfaani lati gbadun ju iye awo rẹkọdu ti wọn le rà lọ. Awọn ile ikawe fun gbogbo eniyan miiran a maa ni awo rẹkọdu ti o dara ti wọn le yá eniyan.

S̩ugbọn gbogbo orin kọ ni o dara. Ohun ti o maa n ti inu ìlù ajótàpá jade ni pe a maa rú ifẹkufẹ ọkàn soke ninu awọn ti o n gbọ ọ. Didún lẹsẹẹsẹ ti ilu ijo maa n dún, nigba ti o ba de gongo, a maa rú ifẹkufẹ ati awọn è̩ṣẹ irira miiran soke ninu ọkàn. Di eti rẹ si eyikeyi ti o n yi ero pada kuro ninu eyi ti i ṣe mimọ ati aileri.

Aimọ-ti-ara-ẹni-nikan

Awọn nnkan miiran wà lẹyin eré ti o maa n mu inu wa dun. Ki a ba le gbadun ohunkohun ni tootọ, a ni lati jẹ alai-mọ-ti-ara-wa-nikan ki a si maa ro nipa inu didun awọn ẹlomiiran ninu iṣe wa. Nigba ti Jesu n sọ nipa wa gẹgẹ bi ọrẹ Rè̩, O ni, “ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori awọn ọré̩ rè̩” (Johannu 15:13). O fi han pe Oun fẹran wa to bayii. O wá lati wá gbe Ijọba Rè̩ kalẹ ninu ọkàn awọn eniyan, lẹyin eyi O fi ara Rè̩ ṣe ẹbọ lati rà wa pada. Ayọ Rè̩ ni lati ṣe ifẹ Baba, bẹẹ ni awa paapaa yoo ri ayọ ninu ṣiṣe ifẹ Ọlọrun.

Nigba ti awọn miiran n lo akoko wọn lati fi kó ọrọ jọ, tabi fun ẹkọ, tabi igbadun ere idaraya, Jesu ya gbogbo agbara Rè̩ sọtọ fun kikọ awọn eniyan nipa ifẹ Rè̩ fun gbogbo eniyan. O n wo awọn ti ara wọn kò da sàn, O n sọ ọrọ iṣiri, O n gbe awọn talaka ró, O si n jẹ ki wọn mọ pe ipo ọlá kan wa fun wọn ni aye yii. Nipa ṣiṣe eyi O mu aimoye eniyan ni inu didun, iwa rere Rè̩ si eniyan ti mu ayọ pupọ sii wa fun gbogbo iran ti o tẹle e.

Awọn eniyan maa n kaanu fun awọn ajihinrere ti wọn ni lati la iṣoro nla kọja lati mu Ihinrere tọ awọn Keferi lọ nitori ifararubọ ti wọn ni lati ṣe. S̩ugbọn ayọ ti wọn n ri gbà ninu iṣẹ ai-mọ-ti-ara-ẹni-nikan ti wọn n ṣe maa n fun wọn ni ayọ ti o pọ to bẹẹ ti o jẹ pe, bi eniyan ba ti jẹ ajihinrere ti Ọlọrun ran lẹẹkan ri, o ṣọwọn lati rii pe o tun pada sẹyin ninu iṣẹ yii fun Oluwa. Ayọ ọkàn rè̩ ni a sọ ninu ọrọ orin yii: “Riri ẹrin musẹ lẹnu ẹni kan ti a gbala ti to fun ere fun gbogbo laalaa.”

Awọn Ohun Idaraya Ayé

Onigbagbọ ti o ti mọ adun ti o wà ninu wiwà ni irẹpọ timọtimọ pẹlu Kristi a maa ni iru ero yii lọkàn: “Ngo lo igbesi-aye mi fun Ọlọrun ati awọn ẹlomiran, ju fun ara mi lọ. Mo n fẹ ki awọn eniyan aye ri Jesu ninu aye mi.” Ẹni ti o ni ipinnu yii lọkàn kò ni ni iṣoro lati ni iru ọkàn ti Oluwa ni nipa awọn ohun idaraya aye yii. Yoo ri i gẹgẹ bi awọn nnkan idaraya aye yii ti ṣe alainilaari to, ati bi wọn ti jẹ alaiwulo to nigba ti a ba fi we ohun ti o le ṣe fun Oluwa.

Ọrọ Ọlọrun kọ wa bayii: “Ẹ máṣe fẹran aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bi ẹnikẹni ba fẹran aiye, ifẹ ti Baba kò si ninu rè̩. Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye. Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rè̩: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai” (1Johannu 2:15-17).

Ile Iṣire

Awọn miiran a maa beere pe, “Ki ni ohun ti o buru ninu lilọ si gbọngan ile ere?” Duro ki o si ro iru ero, iru ifẹkufẹ, ti ere idaraya bẹẹ maa n rú soke. Iwọ o ri iru igbesi-aye ti ki i ṣe otitọ ti a n fi hàn ninu aworan. Awọn ti wọn n gbe igbesi-aye wọn gẹgẹ bi eyi ti a n ri ninu aworan kò ni ayọ to bi wọn ti n fara han pe wọn ni. Wọn n gbe igbesi-aye wọn gẹgẹ bi Eṣu ti paṣẹ fun wọn lati gbe e, lati té̩ ifẹkufẹ ara wọn lọrun -- ikú si ni ere è̩ṣẹ.

Ọpọlọpọ owo, aṣọ daradara, ile ti owo rè̩ pọ ati ọkọ ayọkẹlẹ, ki i ṣe awọn ohun ti a wá si aye lati ni. Nigba ti a ba ka iwe ìtàn ti a fi ọgbọn ori gbe kalẹ, eniyan le ro pe owo ni o maa n mu igbadun wa. Bẹẹ ni a si n fi iwa aye awọn eniyan ti wọn n ṣe ere itan arosọ yii hàn ninu iwe iroyin ninu gbogbo è̩ṣẹ wọn. Awọn eniyan si n fi ikọsilẹ ati agbétúngbé iyawo ati ile ti o fọ hàn bi ẹni pe kò tilẹ buru to bi o ti ri. Wọn kii tilẹ sọ nipa ibanujẹ nlá nlà ati irora ọkàn ti riru ofin Ọlọrun maa n mu wá; ati aini itọju rara ti i maa jẹ ipin awọn ọmọ wọn, ṣugbọn mọ daju pe nnkan wọnyii ni ipin awọn ti o n gbe iru igbesi-aye bẹẹ. Jesu ni, “Ẹ mā kiyesi ohun ti ẹnyin ngbọ” (Marku 4:24). O mọ pe ọpọlọpọ iwa è̩ṣẹ ni yoo fẹ lati fa ọkàn ati ifẹ wa kuro ninu Ọrọ Rè̩, bi a kò ba si ṣọra ohun ti o rọrun ni lati fa wa lọ nipa awọn ohun ti a n gbọ ati awọn nnkan ti a n ri eyi ti Satani ti dẹ silẹ gẹgẹ bi ìké̩kùn lati fi mu wa ninu àwọn rè̩.

Awọn iwe ti a n ka ni lati jẹ eyi ti o mọ. Awọn iwe miiran ti a n tẹ jade lati igba de igba ati iwe “apanilẹrin” kò dara. Wọn a maa mu ki awọn ọmọde ati ọdọ ro ohun ti kò dara ki wọn si fi ṣe iwa hu. Jesu sọ ohun kan fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩: “Ibukun ni fun oju nyin, nitoriti nwọn ri, ati fun eti nyin, nitoriti nwọn gbọ” (Matteu 13:16). Wọn n gbọ wọn si n ri nnkan ti Ọlọrun ti o le fun wọn ni iye ainipẹkun. A ni lati la oju ati eti wa ki a si mu wọn wà ni mimọ ki a ba le gba awọn nnkan wọnni ti yoo mu wa wà ni imurasilẹ fun Ọrun láyè lati wọ inu ọkàn wa lọ.

Ọlọkàn Mimọ

Jesu wi pe “Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun” (Matteu 5:8). Awọn ọlọkàn funfun ki i gbadun ọrọ àwàdà ti o lodi, bẹẹ ni wọn ki i si wọ aṣọ lọna ti wọn o fi fa gbogbo oju sọdọ ara wọn. Awọn ọmọbinrin miiran le wọṣọ ti o bo itiju daradara, ṣugbọn ki iwa wọn, irin wọn, tabi iwò oju wọn fi ifẹkufẹ ọkàn wọn han. Iru iwa bẹẹ kò ti inu ọkàn mimọ wá. Paulu kilọ bayii: “Mā sá fun ifẹkufẹ ewe: si mā lepa ododo, igbagbọ, ifẹ, alafia, pẹlu awọn ti nkepè Oluwa lati inu ọkàn funfun wá” (2Timoteu 2:22).

Awọn aworan tẹlifiṣọn ti awọn obi n fi hàn ni ile wọn le dabi ẹni pe o dara, ṣugbọn wọn ni lati ronu iru ifẹ ti awọn aworan wọnyi yoo rú soke ninu ọkàn awọn ọmọ wọn. Yoo ha fi ifẹ sinu wọn lati gbe igbesi-aye mimọ ki wọn si ṣe iṣẹ-isin fun Oluwa, tabi yoo ha fi ifẹ kan sinu ọkàn wọn fun ohun wọnni ti awọn eniyan aye n ṣe? Tẹlifiṣọn ti mu oriṣiriṣi aworan wọ inu ile, eṣu si n lo ohun-elo alagbara yii lati fa ọkàn awọn ọdọ sinu igbadun è̩ṣẹ. Ohun ti awọn ọmọde ba ri ninu aworan a maa mu wọn lọkàn ṣinṣin; ire diẹ ti o si le ti inu rè̩ jade kò le ṣe atunṣe awọn ohun buburu ti o n tipasẹ rè̩ wọ inu ọkàn lọ.

Eré

Olukuluku ni o fẹran lati ṣe eré idaraya, a si le kọ ẹkọ ti ifi-ọwọ sowọpọ ati jijẹ akikanju ninu ire-ije bi a ba ṣe eré naa pẹlu iwa ti o tọ. S̩ugbọn a ni lati ṣọra nipa eré ti a n ṣe. Satani mura tan lati bà wa jẹ ati lati mu wa ṣako lọ pẹlu ohun ti o dàbi igbadun ti kò ni è̩ṣẹ ninu bi a kò ba kiyesara.

Iyatọ wa laaarin eré eyijẹ-eyi-o-jẹ ati eré fun idaraya. Ninu eré eyijẹ-eyi-o-jẹ -- tita kaadi ati bingo ati iru bẹẹ -- ni té̩té̩ tita ti n bẹrẹ. Bi tẹtẹ ba si ti wọ eniyan lọkàn, o dabi ẹni pe kò si ohun miiran lẹyin Oluwa ti o le já ide naa. Nigba miiran a maa lọ jinna de ipo ti o buru to bẹẹ ti ọpọlọpọ eniyan yoo fi jiya inira ati aini nipasẹ té̩té̩ tita ẹni kan. Tẹtẹ ti a fi kọbọkọbọ ta tabi è̩ṣín keekeeke ti a n sọ sara patako le dàbi ẹni pe nnkan kekere ni, kò si lewu, ṣugbọn a le padanu owo pupọ bi iru ere yii ba di baraku. Lai pẹ ẹni naa yoo rii i pe oun bẹrẹ si i ta tẹtẹ ti o tun tobi ju eyi lọ.

Eré fun idaraya yatọ si eyi. Eniyan ni lati ṣe aapọn lati kọ ọ ki o to le mọ ọn, eyii kii si ṣe ọran orire. S̩ugbọn bi eré yii ba di eyi ti a sọ di nnkan nla ti a si pọnle rekọja, a o tun ri iwa ibajé̩, irẹjẹ, ẹtan, ikorira, eyi ti o ti ba eré wọnyi jé̩ fun awọn ti o ni ifẹ si otitọ ati iwa-mimọ.

S̩iṣe Ihinrere Lọṣọ

Bi a ba le mọ rirì bi ẹmi kan ti ṣe iyebiye to, ati ojuṣe wa lati sọ fun ọkàn naa nipa Jesu, afẹ aye ki yoo fa ọkàn wa mọra rara. Awọn nnkan ti kò tilẹ lewu ninu paapaa yoo ja si fifi akoko ṣofo. A ni lati fi ayè silẹ fun ohun idaraya to lati mu ki a wà ni ara lile -- ṣugbọn kò gbọdọ ju bẹẹ lọ. Ranti pe a o ṣe iṣiro bi a ti ṣe lo akoko wa niwaju Ọlọrun. Oluwa n kiyesi ohun gbogbo ti a n ṣe. A ṣe ọwọn ni oju Rè̩. “Nitori a ti rà nyin ni iye kan: nitorina ẹ yin Ọlọrun logo ninu ara nyin, ati ninu ẹmi nyin, ti iṣe ti Ọlọrun” (1Kọrinti 6:20).

Ọpọlọpọ eniyan ni kii ka Bibeli. Wọn n ṣọ ọkunrin tabi obinrin naa, ọmọkunrin naa tabi ọmọbinrin naa, ti o wi pe Onigbagbọ ni oun. Iwọ ha jẹ ọṣọ fun Ihinrere Jesu Kristi? Njẹ iwa-mimọ rẹ ati idaṣáṣá rẹ ha le fa ẹni kan ti o n ṣọ ọ mọra? Tabi o n gbiyanju lati dara pọ mọ aye o si n ṣe bi wọn ti n ṣe, ki o ma ba yatọ? “Ki ẹ má si da ara nyin pọ mọ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé” (Romu 12:2).

Bi ilepa ọkàn wa ba jẹ lati fi Ọrun ṣe ile wa a ki yoo maa lepa afẹ aye yii. Ọwọ wa yoo di pupọ fun yiya ara wa si mimọ ki a ba le jé̩ Iyawo Kristi.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Iru ọrẹ wo ni Onigbagbọ gbọdọ yàn?
  2. Iru ere idaraya wo ni iwọ maa n gbadun? Ki ni ṣe?
  3. Bawo ni Jesu ti fẹran wa to?
  4. Bawo ni a ṣe gbọdọ fẹran ara wa tó?
  5. Ki ni n mu ayọ nla wá fun ajihinrere?
  6. Ta ni yoo ri Ọlọrun?
  7. Ki ni Bibeli wi nipa ifẹ owo?
  8. Njẹ awọn ẹlé̩ṣẹ le mọ pe Onigbagbọ ni iwọ nipa igbesi-aye ti o n gbé?