Lesson 266 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nitori ohun gbogbo ti mbẹ li aiye, ifẹkufẹ ara, ati ifẹkufẹ oju, ati irera aiye, ki iṣe ti Baba, bikoṣe ti aiye” (1Johannu 2:16).Notes
“Nipa Eso Wọn”
“Gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu” (Matteu 7:17). Aye n reti lati ri Jesu ninu awọn ọmọlẹyin Rè̩. Ọna ti o pọ ju ti eniyan fi n ba Jesu pade ni nipasẹ ẹni ti o ba ti ri igbala; bi eyi si ti ri bẹẹ, o ṣe dandan pupọ ju lọ pe ki olukuluku Onigbagbọ ri i daju pe oun n so eso rere.
Loni ohun ti aye n pọnle pupọ ni è̩kọ, ara lile, ọpọlọ ti o ji pépé, gbajumọ ati imura daradara. Awọn ọmọbinrin ati ọmọkunrin ti wọn mọ àṣa igbalode ni a maa n yẹsi kaakiri ile iwe ati ni ibi ipade ninu aye. S̩ugbọn ẹni ti Onigbagbọ n pọnle ni eniyan ti o ti fi le ilè̩ ni ọna ti o dajú, eto ile rè̩ nipa ti ẹmi, ti o si n fi Ounjẹ nì ti o ti Ọrun wa bọ ọkan rè̩ lọjọọjọ. Dajudaju Oluwa pẹlu a maa fi inudidun wo eniyan ti a ba ti fi Ẹjẹ Ọdọ-agutan wẹ ọkàn rè̩ mọ, ti ọṣọ rè̩ kò si jẹ ọṣọ ti ode-ara bi kò ṣe “ti ẹniti o farasin li ọkàn.” Kiki awọn ti wọn ba n pa ohun gbogbo ti o le ba irẹpọ wọn pẹlu Kristi jẹ tì si apa kan ni wọn maa n ri iyọnu Rè̩ lori igbesi aye wọn.
Idanwo
Satani a maa ti ipasẹ ero wa ati oju wa dan wa wò. Gẹgẹ bi kò ti le ṣe e ṣe pe ki a má jẹ ki ẹiyẹ fo kọja lori wa, bẹẹ ni ko le ṣe ẹ ṣe pe ki idanwo má de ọdọ wa; ṣugbọn, gẹgẹ bi ẹni kan ti wi, “Mo le ṣe e ki awọn ẹiyẹ má kọ itẹ wọn sinu irun ori mi.” Idanwo yoo de lati gbiyanju lati yẹ ẹsẹ rẹ kuro ninu ohun ti o mọ pe o tọna. O le dabi ẹni pe a gbà awọn kan laaye lati maa ṣe ohun ti a ti kọ ọ pe kò dara fun Onigbagbọ lati maa ṣe. Satani le sọ wi pe, “Bi lagbaja ba le wọ ẹwu ti kò lapa bayii, ki ni ṣe ti iwọ naa kò le ṣe bẹẹ?” S̩ugbọn ranti pe ti o ba n kó diẹdiẹ ninu awọn aṣa ti o n ri kaakiri, kò ni pẹ ki o to di bakan naa pẹlu ọgọọrọ awọn ẹni aye. Nipa kikọju ija si awọn amọran Satani ni iwọ o ṣẹgun. Bi o ba ti n rìn jinna si eti bebe aṣa ayé to, bẹẹ ni iwọ o ti wà lai lewu to. A ki yoo dan ọ wo kọja ohun ti iwọ le gbà lọ.
Ni akoko kan a beere lọwọ ọmọde kan ohun ti yoo ṣe ti idanwo ba kan ilẹkun ile rè̩. O wi pe, “Ni temi, n o jẹ ki Jesu da a lohun.”
Èṣu mọ bi oun ti le fi igberaga dan awọn ọdọ wò. Nigba ti o ba n mi ṣàpọnloju-yoyo niwaju wọn oun a wi pe: “Bi iwọ o ba sin mi, ng o fi eyi fun ọ. Bi ng o ti sọ ọ da ni yii ti o ba ṣe bi mo ti wi.” Atike lilo tabi ète kikùn ni o maa n mu awọn ọmọbinrin miiran ṣubu. Igberaga jẹ ohun oṣi ati irira, oun si ni ohun ikọsẹ fun ọmọbinrin pupọ loni. Awọn ọmọbinrin miiran ti wọn ti kunlẹ nibi pẹpẹ adura ni wọn ti jade kuro ninu ile Ọlọrun lai ri awọn iṣura nla Rè̩ gbà, idi rè̩ kò si ju pe wọn kò le fi awọn ohun-elo alainilaari kan tabi awọn aṣa kan silẹ -- iru ki obinrin gé irun rè̩ tabi ki o fi ooya oniná jo o ki o maa gbọn yè̩yè̩, ki o si ṣe bẹẹ maa rin kiri, tabi ki o maa wọ aṣọ ti kò balẹ to, tabi ẹwu ti kò lapa, tabi ki o maa lo atike tabi ki o maa kùn ete. Wo ohun yẹpẹrẹ ti wọn tori rè̩ n ta ọkàn wọn sọwọ ọta ẹmi wọn. Iwọ naa n kọ? Ewo ni o wu ọ ju: ki a maa pe ọ ni “obinrin asikó” tabi “ọmọ akọ,” tabi ki ireti ati jẹ aṣẹgun ni pipe maa gbe inu ọkàn rẹ?
A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe a ni awọn ọdọmọbinrin ti wọn ti gbe ipo gbajumọ laaarin awọn ẹlẹṣẹ tà, wọn ti mu ijoko irẹlẹ lẹba ẹsè̩ Agbelebu, wọn si ti gba Ihinrere Kristi sinu ọkàn wọn.
Apẹẹrẹ obinrin kan ti o le tiroo wà ninu Bibeli. (Ka 2Awọn Ọba 9:30). Ki i ṣe ẹlomiiran bi kò ṣe Jẹsebẹli obinrin kan ti iwa rè̩ buru jai ti o si kú ikú buburu. Ani a kò tilẹ sin in, nitori awọn aja ni wọn jẹ ẹran-ara rè̩. Dajudaju ìtàn igbesi-aye rè̩ yẹ ki o mu eniyan tilẹ yẹra fun erokero nipa titẹle apẹẹrẹ bayii lati lé tiroo. Bi o ba nilati tẹle apẹẹrẹ, tẹle apẹẹrẹ rere, iru bẹẹ si pọ ninu Ọrọ Ọlọrun; bẹ ẹ ni a ri awọn è̩rí aayè ninu Ijọ Akọbi ti Oke, lara awọn ti wọn n yẹra fun ohunkohun ti o ba ti jọ è̩ṣẹ.
Dida Ara pọ mọ Ayé
Bi awọn ọmọde ati awọn ọdọ -- yala ninu ile, ni ibi iṣẹ, tabi ni ibi ere -- ba sọ ọ di iwa wọn lati maa wọ aṣọ ti o boju mu ti o si wà ni iwọntunwọnsi, wọn o wà ni ipo ti wọn o le fi di ọpa Ihinrere mu, ti ojurere ati inudidun Ọlọrun si le fi maa wà ninu igbesi-aye wọn. Ẹni ti o ba jé̩ Onigbagbọ ni tootọ yoo yin Ọlọrun logo ninu ara rè̩ ati ninu ẹmi rè̩, ti i ṣe ti Ọlọrun (1Kọrinti 6:20).
Owe yii jé̩ ododo pupọ, pe: “Aabọ ọrọ ni a a sọ fun ọmọluwabi, bi o ba denu rè̩ a di odindi!” Awọn ti wọn ba n fẹ ohun ti o dara ju lọ ti Ọlọrun n fẹ fi fun wọn – bi a ba ba wọn wi lori ọran aṣọ wiwọ tabi irun didi – ohun ti wọn saaba maa n wi ni pe, “O ṣeun pupọ ti o sọ fun mi.” Awọn ti ifẹ wọn ti n di tutu ti ọkàn wọn ti fa si ohun ti aye ni wọn ki i fẹ tete fa sẹyin kuro ninu fifọwọ pa aṣa aye lori. O ti di aṣa lati maa gba awọn ọmọde laye ni ibi iṣire ni ile-ẹkọ tabi ninu ọgba laaarin ile lati maa ṣi ara wọn silẹ lai bikita fun ohun ti o boju mu, nitori ki oorun le ta si wọn lara ki wọn si le tipa bẹẹ ni okun. Oriṣiriṣi aṣọ iluwẹ ti kò bo itiju kò yẹ obinrin Onigbagbọ rara, i baa jẹ ọmọde tabi agba. Aṣọ ti awọn ti n ya oorun n wọ ti o fẹrẹ fi gbogbo ara silẹ fun itanṣan oorun lati de ko boju mu rara. Aṣọ ti o gbẹ mọ ara tipẹtipẹ ati aṣọ ti o fi aya silẹ pupọ kò le jẹ iranwọ fun ni lati tẹsiwaju ninu iwa-bi-Ọlọrun.
Aṣọ Ọkunrin Lara Obinrin
“Obirin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ, bḝli ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obirin wọ: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bḝ irira ni wọn si OLUWA Ọlọrun rẹ” (Deuteronomi 22:5).
Nitori bẹẹ ṣokoto kukuru tabi gigun, ati aṣọkaṣọ miiran ti a ba ran bi i ti ọkunrin, ki i ṣe ohun ti o bojumu lara obinrin, i baa ṣe ọdọ tabi agbalagba. Iru aṣọ bẹẹ lodi si Ọrọ Ọlọrun o si bu ọlá obinrin kù. Bi a ba gbà awọn ọmọdebinrin layè lati maa wọ iru aṣọ awọn ọmọde-kunrin bayii, ifẹ rè̩ yoo wọ wọn lọkàn, lai si tabitabi, wọn kò ni fẹ fi i silẹ nigba ti wọn ba n dagba. Lode oni o fẹrẹ jẹ kiki iru aṣọ bayii nikan ni ogunlọgọ awọn iyawo ile asiko yii ati awọn oṣiṣẹ labẹ ile maa n wọ ṣe iṣẹ wọn ninu ile.
Boya a le wi fun awọn ọmọbinrin ile-iwe lati wọ ṣokoto nigba ti wọn ba n ṣire gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ ti n lu ilu ni ile-iwe wọn. Ni tootọ kò ṣanfaani fun Onigbagbọ lati gbọran si aṣẹ yii. Dajudaju ti o ba ṣe alaye fun olori ẹgbẹ naa tabi fun ọga ile-iwe, a le gba a laaye lati wọ aṣọ ti o bojumu dipo ṣokoto. S̩ugbọn bi wọn ba kọ, yoo sàn fun un lati fi ẹgbẹ naa silẹ. Ọlọrun yoo san ẹsan rere fun awọn ti wọn ba ni ẹmi ti yoo wi ninu wọn pe, “Ọlọrun wa ti awa nsin le gbà wa . . . ṣugbọn bi bẹkọ awa ki yoo sin ọlọrun aye yi” (Daniẹli 3:17, 18).
Awọn obinrin ọdọ ati agbalagba miiran maa n jiyan pe awọn ẹwu kan wà ti o jẹ pe, bi wọn tilẹ jọ ẹwu ọkunrin sibẹ wọn ki i ṣe iru ẹwu ti ọkunrin maa n wọ. S̩ugbọn nitori pe a tilẹ rán wọn jọ ẹwu ọkunrin, o ṣanfaani ki a yọwọ kuro ninu aṣa bẹẹ.
Ọṣọ S̩iṣe ati Irun Didi
Ọpọlọpọ ibeere ni o maa n wà lori ọṣọ ṣiṣe ati irun didi fun awọn obinrin ọdọ ati agba. A ha le wo inu Ọrọ Ọlọrun fun awọn kókó ilana diẹ ti yoo maa tọ ni nipa nnkan wọnyi?
“Ani ẹda tikararè̩ kò ha kọ nyin pe, bi ọkọnrin ba ni irun gigun, àbuku ni fun u?
“S̩ugbọn bi obirin ba ni irun gigun, ogo li o jẹ fun u” (1Kọrinti 11:14, 15).
“Ọṣọ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ ode, ti irun didi, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ; ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọṣọ aidibajẹ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun” (1Peteru 3:3, 4).
“Ki awọn obirin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsi ṣe ara wọn li ọṣọ, pẹlu itiju ati iwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didi ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye”(1Timoteu 2:9).
Dajudaju a le ri i pe kò ba odiwọn Ọrọ Ọlọrun mu fun awọn obinrin abilekọ tabi awọn ọmọge lati maa fi ooya oniná jó irun wọn ki o le maa gbọn yè̩yè̩. Ki eniyan din akoko ti o fi n wo digi kù, ki o si fi kún akoko ti o fi n ka Bibeli ati eyi ti o fi n gbadura: ki o si maa wọ ọṣọ “ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun”: eyi ni Ọlọrun kà si. O to gẹẹ fun awọn ọdọ Onigbagbọ lati maa kigbe tako ọnakọna ti awọn eniyan fi n kó awọn aṣa igba isisiyi.
Iwọ wi pe, “N kò le fi wọn silẹ.” Ki ni o n sọ yii? O ha jẹ pe kikùn ètè tabi fi fi ọda kun eekanna ọwọ tabi tito pearli bi ilẹkẹ yi ọrun rẹ ká ṣe iyebiye fun ọ ju iye-ainipẹkun lọ? Tabi oruka wura kekere ti o wà ni ika rẹ ni o ṣọwọn loju rẹ ju ireti ati dé Ilu Wura nì ati lati maa rin ita wura rè̩ kaakiri?
Boya a le beere lọwọ rẹ nipa lilo oruka igbeyawo. Yoo dara bi awọn ọmọdekunrin ati awọn ọmọdebinrin ba tilẹ le mọ idahun si ibeere yii. Bi o tilẹ jẹ pe ami igbeyawo ni o jé̩, sibẹ ọṣọ ni. Bi oruka igbeyawo ba tọna, iyawo afẹsọna naa le fẹ maa lo oruka lẹyin ti a ti ṣe idana rè̩. Oruka iru eyi ki i ṣai jé̩ olowo iyebiye, bẹẹ si ni lilo ọṣọ “wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye” kò tọna (Ka 1Timoteu 2:9). Bi Onigbagbọ ba le lo iru oruka kan, omiiran kò buru ju, lai pẹ awọn ti wọn le ra oruka alarabara yoo fẹ lati maa lo wọn ni ọna ti kò yẹ awọn ọmọ Ọlọrun.
S̩ugbọn a kò lodi si lilo wura lati fi ṣe eyin tabi fun ilo miiran ti a kò le ri ohun miiran lo, kiki ki o má jẹ lilo lati fi ṣe ọṣọ.
Biba Tẹmpili Ọlọrun Jé̩
Awọn ọdọmọkunrin miiran maa n ro pe ohun ti o gbayi ni awọn n ṣe ti awọn ba fi iṣẹ abẹ ya aworan si ara wọn. Awọn oṣiṣẹ inu ọkọ oju omi ti wọn ti gbó sinu igbesi-aye è̩ṣẹ maa n saaba ni iru ami yii ni ọwọ, apa ati àyà wọn; awọn ọdọmọkunrin ti wọn n fẹ ki a maa pe awọn ni “ọmọ akọ” a si maa fi ami buburu wọnyi ba ẹwa ara wọn jé̩. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọrun lodi si iru iwa bẹẹ, nitori a kà ninu rè̩ pe: “ẹnyin kò gbọdọ sín gbé̩rẹ kan si ara nyin . . . bḝli ẹnyin kò gbọdọ kọ àmi kan si ara nyin” (Lefitiku 19:28). N ṣe ni awọn ti n ṣe iru nnkan bayii n ba ara wọn ti i ṣe Tẹmpili Ọlọrun alaaye jé̩; Ọrọ naa si sọ kedere pe, “Bi ẹnikan bá ba tempili Ọlọrun jẹ, on ni Ọlọrun yio parun.” Eyi le jẹ ọkan ninu awọn “ifẹkufẹ ewe” ti Bibeli sọ nipa rè̩, o si wi pe ki a “mā sá” fun nnkan wọnyi, eyi ni pe ki a yẹra kuro ninu wọn, ki a fi wọn silẹ, ki a si “mā lepa ododo, igbagbọ, ifẹ, alafia” (Ka 2Timoteu 2:22).
Ni awọn ilu miiran pẹlu, awọn ara ilẹ ibẹ a maa ṣe ọpọlọpọ nnkan ti n pa ara wọn lara. Awọn miiran a maa fi oruka ribiti si imú ati eti wọn; awọn miiran mu ki ẹsẹ wọn wọ; awọn miiran è̩wẹ a maa tẹ ori awọn ọmọ wọn titun lọna ti ìrí wọn yoo fi ba ni lẹrú, ti kò si ni jọ ti eniyan rara. Iru nnkan bayii yoo ti buru tó loju Ọlọrun!
Igberaga
Ninu Bibeli a darukọ ohun meje ti Ọlọrun korira: njẹ o mọ eyi ti o jẹ akọkọ? “Oju igberaga.” Bi o ba fẹ mọ si i ohun ti Ọlọrun sọ nipa igberaga, ka awọn ibomiiran ninu Bibeli (Ka Owe 6:16-19; 8:13; 16:18; ati 29:23). Tun ka nipa Nebukadnessari, ọba nla nì, ti Ọlọrun rè̩ silẹ to bẹẹ ti o fi ni lati maa fi ọwọ ati eekun rè̩ wọ kiri ti o si n jẹ koriko bi malu. Nigba ti Ọlọrun ninu aanu Rè̩ mú iyè rè̩ bọ sipo, o wi pe, “Awọn ti nrin ninu igberaga, on le rè̩ wọn silẹ” (Daniẹli 4:37). È̩ṣẹ buburu mẹtala ni a darukọ ninu Iwe Ihinrere ti Marku, ninu eyi ti ipaniyan jẹ ọkan ti igberaga si jẹ omiiran (Marku 7:21, 22). “Lati inu wá ni gbogbo nkan buburu wọnyi ti ijade, nwọn a si sọ enia di alaimọ.”
Woli Isaiah kọwe nipa awọn idajọ ti a ṣe lori awọn obinrin Juda ti wọn gberaga. O fi ori pipa dipo irun didi daradara, O si pinnu lati fi eepa lu atari wọn. O wi pe Oun yoo mu ọṣọ wọn ati ipaarọ aṣọ wiwọ wọn kuro, oorun buburu ni yoo si dipo oorun didun (Isaiah 3:16-24).
Kiakia ni aṣa aye n yipada, ṣugbọn eyi kò sọ pe ki Onigbagbọ fi ọkàn rè̩ fun iṣẹ èṣu ki o si maa ba igba yí. Awọn ọdọmọbinrin ati agba obinrin ti wọn n ge irun ori wọn, ge apa ẹwu wọn, ti wọn si n ge ọrun ẹwu wọn sisalẹ, ti ja ohun ti o so wọn pọ mọ Ọrun kuro.
Nigba ti Jesu Bá Dé
Ofin yii dara lati maa tẹle: “Maṣe ṣe ohunkohun ti o kò ni fẹ ki a ba ki o maa ṣe nigba ti Jesu bá dé.” O n kiyesi irin wa niwaju Rè̩; awọn ti wọn si n da ara wọn pọ mọ ayé, ara, ati èṣu yoo ba ara won ninu àgò Satani nigba ti Jesu ba wa mu Iyawo ti n reti Rè̩ lọ. Ki Ọlọrun rú ifẹ ọkàn wa soke ki O si ta wa ji ki ẹ “má si da ara nyin pọ mọ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun” (Romu 12:2), to bẹẹ ki a le pẹlu awọn ti a o pa lara da lati goke lọ pade Jesu nigba ti O ba fara han ninu awọsanma. “Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rè̩: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai” (1Johannu 2:17).
Questions
AWỌN IBEERE- Sọ idajọ ti a pinnu lori “awọn ọmọbinrin Sioni”?
- Iru ọṣọ wo ni o ṣe iyebiye loju Ọlọrun?
- Darukọ iru ọṣọ kan ti a sọ fun ni lati maa fi ṣe ara wa lọṣọ.
- Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti wọn bá ba ara wọn jẹ?
- Bawo ni a ṣe le bori idanwo?
- Ki ni ero Ọlọrun nipa igberaga?
- Ki ni aṣẹ ti a pa fun awọn obinrin nipa wiwọ aṣọ ọkunrin?
- Bibeli ha lodi si lilo ọṣọ?
- Ki ni Bibeli sọ nipa fifi ooya oniná jo irun wa gẹgẹ bi obinrin?
- Awọn wo ni yoo jé̩ Iyawo Kristi?