Gẹnẹsisi 18:23-32; 32:9-12, 24-28; Isaiah 58:1-11; Daniẹli 9:3-23; Matteu 6:16-18; 17:21

Lesson 267 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “S̩ugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwè̩” (Matteu 17:21).
Notes

Ibasọrọ ti o Ladun

Adura jẹ biba Ọlọrun sọrọ. Awọn ọmọde paapaa le gbadura; Ọlọrun a maa tẹti silẹ a si dahun adura wọn. “Adura awọn aduroṣinṣin ni didùn-inu rè̩” (Owe 15:8).

Awọn ọmọde ti a kọ ni è̩kọ rere a maa gbadura nigba ti wọn ba ji ni owurọ, wọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oorun wọn ni oru, wọn a si beere pe ki O pa wọn mọ ni gbogbo ọjọ naa. Ki wọn to lọ si ori ibusun wọn ni alẹ wọn a tun gbadura, wọn a ni ki O tọju wọn ni gbogbo oru ki O si bukun baba ati iya wọn, awọn arabinrin ati arakunrin wọn ati gbogbo awọn ọrẹ wọn. Wọn maa n dupẹ lọwọ Jesu fun ounjẹ ti wọn n jẹ.

Gbogbo awọn adura wọnyi dabi ibasọrọ didun laaarin awọn ọrẹ ati olufẹ. Jesu n fẹ lati jé̩ Ọrẹ wa, bi a si ti n ba A sọrọ sii, bẹẹ ni yoo maa fẹran wa sii, bẹẹ ni a o si tubọ maa dabi Rè̩.

Nigba ti awọn ọmọde ba dagba diẹ ju bẹẹ lọ wọn a bẹrẹ si mọ wahala nigba miiran. Wọn le ṣaisan tabi ki wọn pa ara wọn lara. Ni akoko yii wọn o ke pe Oluwa pe ki O ran awọn lọwọ ki O si wò wọn sàn. Wọn o ni inu didun pe O jé̩ Ọrẹ wọn nigba ti ara wọn dá, to bẹẹ ti O fi wà ni tosi lati ran wọn lọwọ nigba ti wọn n fẹ imularada.

Igba Mimọ Rere ati Buburu

Nigba ti awọn ọmọde ba dàgbà to lati mọ rere yatọ si buburu – akoko ti wọn mọ idalẹbi ọkàn fun è̩ṣẹ -- wọn ni lati gbadura ju ti atẹyinwa lọ. Bi wọn ba n fẹ wà ni imurasilẹ lati pade Jesu, wọn ni lati gbadura si I ki wọn si beere pe ki O dari è̩ṣẹ wọn ji wọn. Nigba ti wọn ba ronupiwada, ti wọn si ṣeleri lati sin In titi laelae, yoo dariji wọn, a o si tun wọn bi sinu ẹbi Ọlọrun. Lati jé̩ ọmọ Ọlọrun jé̩ iriri ti o jinlẹ ju lati jẹ ọrẹ lọ.

Bi ọjọ ti n gori ọjọ, ti eniyan si n dagba si i, wahala ti o pọ ju bẹẹ lọ yoo bẹrẹ si yọju. Ọlọrun n pe awọn ọmọ Rè̩ lati ṣe ifararubọ ti o jinlẹ ju ti atẹyinwa lọ. Boya a ti bẹrẹ si ṣe eto igbesi-aye wa ati awọn nnkan ti a fẹ ṣe, lẹsẹ kan naa Ọlọrun a si ni ki a fi gbogbo rè̩ silẹ lati ṣe ohun ti O n beere. O le jẹ pe a ni lati gbadura gidigidi ki a to le ṣẹgun ifẹ-inu wa ki a si ṣetan lati tẹle ifẹ Oluwa.

Adura Agbayọri Jakọbu

A ka nipa adura ti Jakọbu gbà. O ti fi ọkàn rè̩ fun Ọlọrun, o si n fẹ lati sin In. Ọlọrun ti dariji i fun iwa è̩tan rè̩ si arakunrin rè̩ nigba ti o wa ni ọmọde; ṣugbọn Jakọbu ṣi wa ni ọna jijin si ile, jinna si ẹgbọn rè̩.

Jakọbu ti fi ọgbọn arekereke gba ogun-ibi lọwọ Esau, o ti tan baba rè̩ ti kò riran jẹ lati fun un ni ibukun naa, o si ti di ọlọrọ nipa fifi ọgbọn è̩wé̩ ṣiṣẹ fun baba iyawo rè̩. S̩ugbọn nigba ti Ọlọrun sọ fun un pe ki o pada si ile lati dojukọ arakunrin rè̩ ti o ti huwa aitọ si, iṣoro de ba Jakọbu. O ni lati gbadura si Ọlọrun fun iranlọwọ, o si gbadura gidigidi.

Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi ọna ti Jakọbu fi gbadura. Ọlọrun ti ṣeleri fun Jakọbu pe Oun yoo ba a lọ bi o ba pada si ile. Sibẹsibẹ Jakọbu ni lati gbadura lati gba ileri yii.

Ni akọkọ, Jakọbu bu ọlá fun Ọlọrun gẹgẹ bi Ọlọrun awọn baba rè̩. Ọlọrun ti ba wọn dá majẹmu, O si ti dahun adura wọn. Eyi fun Jakọbu ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo gbọ ti oun naa pẹlu. A maa n ni igbagbọ ati igboya si i lati gbẹkẹle Ọlọrun pe yoo dahun adura wa nigba ti a ba ronu nipa awọn adura miiran ti Ọlọrun ti dahun fun wa ati fun awọn olufẹ wa. Tabi bi eniyan ba ṣẹṣẹ mọ Jesu, ti ẹni naa kò ti i mọ nipa awọn adura ti a ti dahun bẹẹ, o le kà nipa awọn adura wọnyi ninu Bibeli ki o si ri igbagbọ gbà nipasẹ wọn.

Nigba naa ni Jakọbu rè̩ ara rè̩ silẹ; “Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ānu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ.” Kò si ẹni kan ninu gbogbo wa ti o yẹ fun ohunkohun lati ọdọ Ọlọrun. Gbogbo wa ni a ti dẹṣẹ, nipa Ẹmi Ọlọrun nikan ni a si n fi pè wa wá si ironupiwada. A gbà ọkàn wa là nitori pe Jesu fẹran wa to bẹẹ ti O fi kú fun wa ni Kalfari; nipasẹ Ẹjẹ ti o ta silẹ ni a ṣe le ṣẹgun ọta wa ẹmi, ki a si gba awọn ibukun ti Ọlọrun ti ṣeleri fun wa.

Lẹyin eyi Jakọbu rán Ọlọrun leti awọn ileri Rè̩: “Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọpọlọpọ.” Bi a ba n fẹ ohun kan lọdọ Ọlọrun a ni lati kọkọ lọ sinu Bibeli ki a si mọ bi o ba ṣe deedee pẹlu Ọrọ Rè̩. Nigba ti a ba ni idaniloju pe ohun ti a fẹ beere tọna, nigba naa a le gbadura pẹlu idaniloju pe Oun yoo gbọ ti wa.

Lẹyin eyi, Jakọbu bẹrẹ si i ṣe ifararubọ. O fi gbogbo agbo ẹran ati ọwọ ẹran rè̩ ranṣẹ rekọja odo. Awọn ni ohun ini rè̩ ni aye, gbogbo ohun ti o ni. Eyii jẹ apẹẹrẹ pe o fi wọn fun Ọlọrun. Lẹyin eyii o ran awọn ẹbi rè̩ -- awọn olufẹ rè̩ ti o ṣọwọn fun ọkàn rè̩ -- rekọja si apakeji odo. Kò si ohun ti o kù afi oun nikan. O si ni lati fi ara rè̩ fun Oluwa pẹlu.

Kò si oorun fun Jakọbu ni oru ọjọ naa bi o ti n ba Angẹli naa jijakadi. Jakọbu ka ibukun ti Ọlorun ti ṣeleri fun un si ohun ti o ṣe pataki ju gbogbo nnkan iyokù ti o le fẹ lọ. Bi o ba jẹ ọranyan fun un lati gbadura ni gbogbo oru ki o ba le ri ibukun ti o n fẹ gbà, o ti mura tan lati ṣe e. Angẹli naa yè̩ egungun itan Jakọbu ni orike, sibẹsibẹ Jakọbu tẹsiwaju lati maa gbadura. O si gbadura agbayọri!

Iṣẹgun Jakọbu nipa adura naa pọ to bẹẹ ti Angẹli naa fi yi orukọ rè̩ pada. A ki yoo tun pe e ni Jakọbu mọ, itumọ eyii tii ṣe ajinnilẹsẹ, ẹni ti o ti gba ogun-ibi arakunrin rè̩, ṣugbọn Israẹli ni a o maa pe e, “nitoripe iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori.” O ti gba Jakọbu ni adura agbayọri ti o gùn pẹlu ijakadi ni oru naa. O ti gba a ni ifararubọ gbogbo nnkan ti o ni patapata. Njẹ kò yẹ ki o gba a to bẹẹ? Ronu awọn ibukun ti o ri gba! Ki i ṣe kiki pe o le ba arakunrin rè̩ pade ni alaafia ni ọjọ keji nikan – eyi ni ohun ti o beere fun -- ṣugbọn a pe e ni ọmọ-alade ti Ọlọrun; lati igba naa ni a ti n fi orukọ rè̩ pe awọn eniyan Ọlọrun ani awọn Ọmọ Israẹli. Awọn ọmọ Jakọbu mejila ni o di olori awọn ẹya mejila ni Israẹli – nitori pe Jakọbu gbadura titi ó fi ri idahun gbà.

Adura Ìpè̩ Abrahamu

Baba nla Jakọbu, Abrahamu, ni ẹlomiiran ti o tun gbadura. O gbọran si aṣẹ Ọlọrun ninu ohun gbogbo, igba pupọ ni o si maa n gbadura. Ọlọrun le wi nipa rè̩ pe: “Mo mọ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rè̩ ati fun awọn ara ile rè̩ lẹhin rè̩, ki nwọn ki o ma pa ọna OLUWA mọ lati ṣe ododo ati idajọ; ki OLUWA ki o le mu ohun ti o ti sọ fun Abrahamu wá fun u.”

Irẹpọ timọtimọ wà laaarin Ọlọrun ati Abrahamu to bẹẹ ti Ọlọrun fi sọ ti iparun ti o ba ni ninujẹ naa fun Abrahamu ki o to mu idajọ wá sori Sodomu ati Gomorra. Abrahamu mọ pe olododo ni Ọlọrun, ati pe kò le ṣe ohunkohun bi kò ṣe eyi ti o tọ. Ọlọrun ṣeleri pe Oun ki yoo pa awọn eniyan rere run pẹlu awọn eniyan buburu. Sibẹsibẹ iwuwo nlá kan wọ ọkàn rè̩ lati gbadura si Ọlọrun lati dá ẹmi awọn olododo ti o wà ni Sodomu si.

Abrahamu beere lọwọ Ọlọrun bi yoo ba dá ilu naa si nitori aadọta olododo. Ọlọrun ni Oun yoo ṣe bẹẹ. Marundinlaadọta nkọ? Bẹẹ ni, Ọlọrun yoo da ilu naa si nitori olododo marundinlaadọta. Njẹ bi o ba jẹ pe ogoji ni n kọ? Ọlọrun yoo da ilu naa si nitori ogoji, tabi ọgbọn, tabi ogun. Sibẹsibẹ iwuwo wà ninu ọkàn Abrahamu. Njẹ ti kò ba si to ogun n kọ? Awọn eniyan ti o wà nibẹ yoo ha padanu ohun gbogbo ti wọn ni ninu iparun ilu naa?

Bawo ni Ọlọrun yoo ti ni suuru pẹ tó lati maa gbọ ipẹ Abrahamu fun awọn ọkàn. Njẹ bibeere ti o n beere lai danu duro yii kò ha ti ni tan wa ni suuru? Kò su Ọlọrun lati gbọ adura Abrahamu.

Abrahamu mọ pe Ọlọrun ti gba fun oun lọpọlọpọ, nikẹyin o ni: “J, ki inu ki o máṣe bi OLUWA, ḝkanṣoṣo yi li emi o si wi mọ. Bọya a o ri mẹwa nibè̩.” Ọlọrun dahun: “Emi ki yio run u nitori mẹwa.” Opin adura naa ni eyii. Abrahamu ti gba agbayọri adura pẹlu Ọlọrun, a si gbe iwuwo na kuro, bi o tilẹ jẹ pe idajọ naa dé sibẹ. A pa Sodomu ati Gomorra run nitori pe a kò tilẹ ri olododo mẹwaa ninu gbogbo orilẹ-ède naa. A mu awọn olododo kuro ni ilu naa, a si rọjo ina ati sulfuri lati ọrun lati run gbogbo è̩ṣẹ ati awọn ẹlẹṣẹ ti o kù nibẹ.

Ayé ti a fi fun Ọlọrun

Jakọbu ati Abrahamu ri idahun gbà si adura wọn nitori pe wọn gbe igbesi-aye wọn lati wu Ọlọrun ati nitori pe wọn gbadura pẹlu gbogbo ọkàn titi idahun fi de. Awọn eniyan wà ninu itan awọn ọmọ Israẹli ti wọn gbadura pẹlu gbogbo agbara wọn, wọn tilẹ gbaawẹ paapaa, ṣugbọn ti won kò ri idahun gbà. Ohun ti o fa a ni pe wọn kò gbé igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun. Ohun ti o yẹ ki wọn ṣe ni yii dipo ti wọn fi n ṣe aṣehan nla pe awọn n gbaawẹ wọn si n banujẹ fun è̩ṣẹ wọn: “Awẹ ti mo ti yàn kọ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga. Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi n pa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ.” (Isaiah 58:6, 7).

Ire wo ni o wà ninu adura gigùn ati aawẹ wọn bi awọn eniyan kò ba huwa rere si awọn eniyan ti wọn n ba gbé? Jakọbu Apọsteli kọwe: “Bi arakunrin tabi arabirin kan ba wà ni ihoho, ti o si ṣe aili onjẹ õjọ, ti ẹnikan ninu nyin si wi fun wọn pe, Ẹ mā lọ li alafia, ki ara nyin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nkan wọnni ti ara nfẹ fun wọn; ère kili o jẹ?” (Jakọbu 2:15, 16).

Gbigba Aawẹ

Awẹ gbigba (eyi ti o jẹ ṣiṣe alaijẹun) ki i ṣe ohun ti a gbọdọ ṣe lati fi han fun awọn eniyan pe a n ṣe ohun ti o dara. Jesu wi pe: “Nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na. S̩ugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ; ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ikọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ikọkọ yio san a fun ọ ni gbangba” (Matteu 6:16-18).

A ri apẹẹrẹ aawẹ gbigba ninu Bibeli, nigba ti Ọlọrun fi iwuwo sinu ọkàn awọn eniyan Rè̩. Mose lọ si ori oke, o gbadura, o si gbaawẹ fun ogoji ọjọ ni igba ti Ọlọrun fun un ni Ofin. O mọ iwuwo ẹru ṣiṣe alakoso aadọjọ ọkẹ (3,000,000) eniyan lọ si Ilẹ-Ileri, o si n fẹ iranlọwọ lati ọdọ Ọlọrun. O gbadura gidigidi, o si wà lai jẹun.

Ọpọlọpọ ọdun lẹyin eyi, nigba ti Daniẹli jé̩ Woli ni Israẹli, oun paapaa ni iwuwo lọkàn fun awọn Ọmọ Israẹli ti o kún fun è̩ṣẹ. O pinnu lati wa Oluwa nipa “adura ati è̩bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọfọ, ati ẽru” (Daniẹli 9:3). O kọkọ ran Ọlọrun leti awọn ileri Rè̩. Lẹyin eyi o jẹwọ awọṅ è̩ṣẹ ti rè̩ ati è̩ṣẹ awọn eniyan naa. Gbigbadura jinlẹ gidigidi pẹlu aawẹ mu ibukun iyanu wá sori rè̩. Angẹli Gabriẹli mu awọn asọtẹlẹ ti o jẹ iyanu to bẹẹ ti a fi kọ wọn sinu Bibeli tọ ọ wá.

Nigba ti Satani n dan Jesu wo ninu aginju, O gbaawẹ fun ogoji ọjọ. Jesu n ba Ọlọrun sọrọ ninu adura lojoojumọ, ṣugbọn ni gbogbo akoko idanwo ti o le yii, kò jẹun. Nigba ti awọn ọmọ-ẹyin tọ Ọ wa nigba kan, ti wọn n fẹ mọ idi rè̩ ti wọn kò fi le lé awọn ẹmi eṣu kan jade, O da wọn lohun bayii: “Irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwè̩” (Matteu 17:21). Nigba miiran o maa n gba ni ju pe ki a gbadura gidigidi lati gba agbara lọdọ Ọlọrun fun iṣẹ kan pataki. A le ni iwuwo ti o pọ to bẹẹ ti ifẹ lati jẹun yoo lọ kuro; tabi a le ti ipasẹ aijẹun fi bi o ti mu wa lọkàn to han fun OLUWA, a o si ri ọtọọtọ ibukun gba lọdọ Rè̩.

Awọn ẹlomiiran ti sọ aawẹ di ilana isin, lai si Ẹmi Ọlọrun, wọn a si tẹra mọ ọn titi yoo fi pa ilera wọn lara. Iru eyii kii ṣe ti Oluwa. Ọjọ mẹta lẹẹkan fun aawẹ ti gùn to. Nigba ti Oluwa ba mi si eniyan lati pa ounjẹ rè̩ tì fun igba kan ki o si fi gbogbo aya rè̩ si mimu ẹbẹ rè̩ wá sọdọ Oluwa, Oluwa yoo dahun yoo si san ere fun un.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni awọn ọmọ kekere maa n beere lọwọ Oluwa nigba ti wọn ba n gbadura?
  2. Ki ni ọmọde ni lati gbadura fun bi o ba ni idalẹbi ọkàn nitori è̩ṣẹ?
  3. Ki ni Jakọbu ṣe ki o to bẹrẹ si i gbadura ni Jabboku?
  4. Ki ni Jakọbu gbadura fun? Bawo ni o ti ṣe ri gba to ju eyi ti o beere lọ?
  5. Ki ni Abrahamu ṣe nigba ti Ọlọrun sọ fun un pe a o pa Sodomu run?
  6. Nitori ẹni meloo ni Ọlọrun ṣe mura tan lati dá Sodomu silẹ?
  7. Ki ni ṣe ti Jakọbu ati Abrahamu n reti pe Ọlọrun yoo dahun adura wọn?
  8. Ki ni itumọ “aawẹ”?
  9. Nigba wo ni o yẹ ki eniyan gbaawẹ?
  10. Bawo ni eniyan ti gbọdọ ṣe nigba ti o ba n gbaawẹ?