Lesson 268 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Mo wà ninu Ẹmi li ọjọ Oluwa” (Ifihan 1:10).Notes
Ọjọ Oluwa
Ki eniyan to le yà Ọjọ Oluwa si mimọ, o ni lati kọ mọ ewo ni Ọjọ Oluwa. Ninu Iwe Ifihan 1:10 ni Johannu lo ede yii, Ọjọ Oluwa, dajudaju eyi n tọka si Ọjọ Ọsẹ, ti i ṣe ọjọ kin-in-ni ọsẹ. N ṣe ni a ta Johannu nù kuro lọdọ awọn Onigbagbọ iyoku, ṣugbọn ọkàn rè̩ wà ninu ẹmi ijọsin ati ọwọ nigba ti Oluwa ba a pade nibẹ.
Ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ ni Kristi ji dide. Ọpọlọpọ igba ni O ba awọn ọmọ-ẹyin pejọ pọ ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ. Awọn ọmọ-ẹyin pejọ pọ ni Ọjọ Ọsẹ lati bu akara (Iṣe Awọn Apọsteli 20:7) ati lati mu ọrẹ wọn wá fun Oluwa (1Kọrinti 16:2). Oluwa fi ọwọ si pipade ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ nipa bibukun-fun awọn eniyan Rè̩ ti wọn n jọsin ni Ọjọ Ọsẹ ati nipa rirán Ẹmi Rè̩ ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ sori awọn ti n gbadura ni iyara oke ni Ọjọ Pẹntikọsti, ni aadọta ọjọ lẹyin ajinde Kristi. Gẹrẹ ti Kristi ti jinde ni gbogbo Onigbagbọ tootọ tẹwọ gba ọjọ yii lati maa jọsin, ti wọn si ti n yà ọjọ yii si mimọ lati igba naa wa tii fi di oni yii.
Ọjọ Isinmi ti awọn Ju yà si mimọ jẹ ọjọ keje ọsẹ. Ni igba aye Ofin oun ni ọjọ ijọsin ati isinmi ti a yà sọtọ fun ogo Ọlọrun. Oun ni ọjọ ti a fi silẹ lati maa sin Oluwa. Ni igba aye Ofin, Ọjọ Isinmi awọn Ju ni ọjọ Satide. Lati igba ti Kristi ti jinde ni Ọjọ Ọsẹ ti di ọjọ ti Onigbagbọ maa n jọsin. Ojoojumọ ni o yẹ ki a maa sin Ọlọrun ki a si maa bu ọlá fun Un, ṣugbọn ọjọ kan yii jẹ eyi ti a yà sọtọ ni pataki fun ọlá Ọlọrun.
Nitori Eniyan
Jesu kọ ni pe “a dá ọjọ isimi nitori enia, a kò dá enia nitori ọjọ isimi” (Marku 2:27). A ti dá eniyan ki a to da ọjọ isinmi. Ọlọrun ni O dá eniyan fun ogo Rè̩ -- lati maa fi ọla fun Ọlọrun ati lati maa sin In (Kolosse 1:16). Oluwa fi ọwọ fun Ọjọ Isinmi O si ya a si mimọ fun ire ati fun anfaani eniyan. Lati ni ọjọ kan fun isinmi ati ijọsin jẹ anfaani fun ara ati ọkàn eniyan pẹlu.
Ọjọ mẹfa ni a fi n ṣiṣẹ -- eyi jé̩ anfaani fun pupọ eniyan -- ọjọ kan ti o kù ni a jẹ Ọlọrun ni gbese rè̩. A gbọdọ yà ọjọ yii sọtọ, yatọ si gbogbo ọjọ miiran. Ni ọjọ yii a le gbagbe gbogbo laalaa ati igboke-gbodo ojoojumọ, a si le fi ara wa fun ironu nipa ti Oluwa ki a si maa sọrọ nipa Rè̩ gidigidi.
Ofin Kẹrin
Lori Oke Sinai ni Mose, alakoso awọn Ọmọ Israẹli, ti gba Ofin lati ọwọ Ọlọrun. Lara ohun ti o wà ninu Ofin naa ni awọn Ofin Mẹwaa. Ọkan ninu awọn ofin naa, ẹkẹrin, sọ nipa Ọjọ Isinmi. O wi pe, “Ranti ọjọ isimi, lati yà a simimọ” (Ẹksodu 20:8). Oluwa fi ye Mose ati awọn Ọmọ Israẹli pe ọjọ mẹfa ni wọn ni lati ṣe iṣẹ wọn ṣugbọn ọjọ keje ọsẹ jé̩ ọjọ ti wọn ni lati sinmi. “Nitori ni ijọ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ keje, o si yà a si mimọ” (Ẹksodu 20:11).
Ni ọjọ isinmi yii ti i ṣe ọjọ alaafia ati ọjọ idakẹjẹ, wọn gbọdọ maa ranti bi awọn ti jé̩ ẹru ri ni Egipti ṣugbọn ti Oluwa mu wọn jade “nipa ọwọ agbara, ati ninà apa” (Deuteronomi 5:15).
Ọjọ Isinmi
Ni ti ọjọ yii Oluwa wi pe “Iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan.” O gbọdọ jé̩ ọjọ isinmi fun gbogbo eniyan – ati ọmọde, ati iranṣẹ, ati alejo, ati awọn ohun-ọsin – ki a le “tù wọn lara” (Ẹksodu 23:12). Nigba ti a ba lo Ọjọ Ọsẹ fun lilọ si ile isin, kika Bibeli, gbigbadura, ati sisọrọ nipa Oluwa, a maa n ni itura nipa ti ara ati nipa ti ẹmi. Ọkàn wa maa n ri ounjẹ ati ibukun. Ara wa si maa n ni isinmi kuro ninu laalaa ojoojumọ. Nigba ti eniyan ba n fi Ọjọ Ọsẹ ṣe iṣẹ ti o yẹ ki o ṣe laaarin ọsẹ, tabi ti eniyan ba n fi Ọjọ Ọsẹ wá igbadun aye, ebi ẹmi a maa pa ọkàn oluwarè̩, aarẹ ara ni oluwarè̩ a si maa fi bẹrẹ iṣẹ ọsẹ titun.
Idajọ Ikú
Lati ya Ọjọ Isinmi si mimọ jé̩ aṣẹ Oluwa, ireti Rè̩ si ni pe ki gbogbo eniyan gbọran. Labẹ Ofin, idajọ kikoro ni o wà fun ṣiṣaibọwọ fun Ọjọ Isinmi. A ka pe “ẹniti o ba bà a jé̩ on li a o pa nitõtọ: nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ kan ninu rè̩, ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rè̩” (Ẹksodu 31:14). Lode oni, awọn ti wọn bá taku ni ṣiṣe aibọwọ fun Ọjọ Isinmi yoo ri pe ki i ṣe ebi ti ẹmi nikan ni o n pa wọn, ṣugbọn pe awọn tilẹ ti kú nipa ti ẹmi.
Ni ọdun diẹ sẹyin, gbogbo orilẹ-ède wa ni o ya Ọjọ Oluwa si mimọ. A ti awọn ile itaja, a kò si ṣiṣẹ ninu oko, o si fẹrẹ jé̩ gbogbo eniyan ni o n lọ ile-isin lati sin Ọlọrun. Ni ilu miiran a tilẹ ṣe ofin ti yoo jẹ awọn ti o ba ba Ọjọ Oluwa jẹ niya. Awọn ofin ilẹ wa fi aye silẹ fun ni lati bu ọla fun Ọjọ Oluwa. Nitori bẹẹ Ọlọrun yé̩ orilẹ-ède wa si bi O ti maa n ṣe fun awọn ti o ba bụ ọlá fun Un. S̩ugbọn nisisiyi Satani ti sé ọpọlọpọ eniyan ni ọkàn le o si ti yi wọn pada kuro lọdọ Ọlọrun. Eniyan pupọ ni wọn n lepa igbadun ara wọn ti wọn si n wi pe ki a pa awọn ofin ti wọn fi ọwọ fun Ọjọ Ọsẹ ré̩.
Ki i ṣe ohun ajeji mọ nisisiyi lati ba awọn eniyan ti n ṣe oriṣiriṣi iṣẹ ni oko ati ile itaja; eyi kò si dùn mọ Ọlọrun ninu. Iriri ti fi han pe ki i sàn pupọ fun awọn eniyan nigba ti wọn ba ba Ọjọ Oluwa jẹ nipa ṣiṣe iṣẹ. Awọn Onigbagbọ kaakiri ti sọ ọ di iwà wọn lati yẹra fun iṣẹ ṣiṣe fun èrè nipa ti ara ni Ọjọ Isinmi. Wọn maa n yàn lati ṣiṣẹ nibi ti wọn yoo ti ni anfaani lati lo Ọjọ Isinmi fun sisin ati bibu-ọla fun Ọlọrun. Awọn Onigbagbọ miiran ti kọ igbega lẹnu iṣẹ, awọn miiran ẹwẹ ti fi iṣẹ silẹ nitori pe o di ọranyan fun wọn lati ṣiṣẹ ni Ọjọ Oluwa. Ọlọrun n yẹ wọn si O si n fi ibukun sori wọn nitori iduro wọn yii. Awọn ti wọn n ya Ọjọ Oluwa si mimọ fi han pe awọn ka a si iyebiye lati ni idapọ pẹlu Ọlọrun, ati lati jẹ olóòótọ si I, ju lati wà lẹnu iṣẹ ti wọn lọ. Awọn iṣẹ kan wà ti o jẹ dandan pe ki a ṣe wọn ni Ọjọ Isinmi. S̩ugbọn kò ha si iṣẹ miiran ti Onigbagbọ le ṣe?
Imurasilẹ
Akọsilẹ wà ninu Bibeli nipa ọkunrin kan ti o tipa ṣiṣẹ igi ni Ọjọ Isinmi ṣaibọwọ fun ọjọ naa (Numeri 15:32). Ọkunrin yii jiya è̩ṣẹ rè̩. Nipasẹ aṣẹ Oluwa, pipa ni a pa a. I ba ṣe pe ọkunrin yii ti mura silẹ bi o ti tọ, oun kì ba ti duro de ọjọ mimọ yii ki o to ṣẹgi.
Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli n rin lọ ninu aginju, Oluwa rán manna lati fi bọ wọn, Oluwa si kilọ fun wọn lati mura silẹ de Ọjọ Isinmi ki o má ba si eredi kankan fun wọn lati ṣiṣẹ ni ọjọ naa. Ni oroowurọ ni awọn Ọmọ Israẹli n kó manna naa nitori pe “nigbati õrùn si mu, o yọ.” Ni oroowurọ ọjọ mẹfa laaarin ọsẹ ni wọn n ri manna naa kó; ṣugbọn awọn ti kò fiyesi ikilọ Oluwa ti wọn si gbiyanju lati kó manna ni ọjọ keje kò ri nnkankan. Oluwa ti sọ fun wọn pe ni owurọ ọjọ kẹfa ki wọn kó iwọn ti yoo to fun wọn lati jẹ fun ọjọ meji nitori ọjọ mimọ ni ọjọ ti o tẹle e. Oluwa wi pe “Ẹ yan eyiti ẹnyin ni iyan, ki ẹ si bọ eyiti ẹnyin ni ibọ; eyiti o si kù ẹ fi i silẹ lati pa a mọ dé owurọ” (Ẹksodu 16:23).
O dun mọ Oluwa pe wọn mura silẹ de ọjọ mimọ. Manna ti wọn ba kó lé ni ọjọ kẹfa ki i rùn bẹẹ ni ki i yọ idin; ṣugbọn ni igbakigba miiran ti wọn ba kó ju iwọn ti ọjọ kan, n ṣe ni manna naa maa n rà ti o si n yọ idin.
Nigba ti eniyan ba ti mura silẹ ti o ba si ti fi ero si ati pa Ọjọ Isinmi mọ, anfaani ki i si pupọ fun ohun ti yoo mu ki a ṣaibọwọ fun un. Onigbagbọ a maa mura silẹ de Ọjọ Isinmi nipa fifi ile, ounjẹ, aṣọ, àgbàlá ati mọto rè̩ si eto ki ọjọ yii to wọle de. Ọjọ Isinmi kii ṣe ọjọ ti o yẹ lati maa ṣe awọn iṣẹ pé̩pè̩pé̩ ti o wa ni ile. O yẹ ki awọn ọmọde ṣe eyi ti o ba ṣe e ṣe silẹ ninu iṣẹ ile wọn. S̩ugbọn bi kò ba ṣe e ṣe, eyii kò fi àye silẹ fun wọn lati kuna lati ṣe ojuṣe wọn, tabi lati ṣe iranwọ, tabi lati wà ni ìmọtótó. Yiya Ọjọ Oluwa si mimọ kii sọ ni di ọlẹ, nitori ọwọ wa maa n kún fun iṣẹ Oluwa.
Ibukun
Ọpọlọpọ ibukun ni o wà -- alaafia, itẹlọrun, ipamọ, ati ifarahan Oluwa – bi awọn Ọmọ Israẹli ba pa ofin Ọlọrun mọ, lara eyi ti pipa Ọjọ Isinmi mọ ati bibọwọ fun ibi mimọ Oluwa (Lefitiku 26:2) jẹ ọkan. Yatọ si awọn ibukun wọnyi, a ṣe ileri fun awọn eniyan Ọlọrun pe ti wọn ba pe Ọjọ Isinmi ni adùn, a o gbe wọn ga, a o si fun wọn ni ìni. Wọn o ri inudidun ninu gbigbọran si Oluwa ti wọn ba n bu ọla fun Un ni ọna ti Rè̩, ti wọn ba si n sọ ọrọ ti Rè̩ dipo ti ara wọn (Isaiah 58;13, 14). Nigba ti eniyan ba fẹran Ọlọrun ni tootọ ti o si n gbọ ti Rè̩, ninu isin Oluwa ni ayọ rè̩ ti o tobi ju lọ yoo gbe wà. Ọjọ Isinmi jẹ akoko ti o dara lati bẹrẹ si i kọ ẹkọ ati akọsori fun ẹkọ ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi fun ọsẹ ti n bọ.
O dabi ẹni pe awọn miiran ka Ọjọ Isinmi si ti ara wọn, ninu eyi ti wọn le ṣe bi wọn ti n fẹ. Wọn sọ Ọjọ Isinmi di ọjọ afẹ ati ti ere idaraya, lai ṣe aṣaro nipa Ọlọrun.
Rira ati Tita
Gbọnmọgbọnmọ ni Oluwa tẹnu mọ bibu ọwọ ti o yẹ fun Ọjọ Isinmi. Fun ogo Ọlọrun ni gbogbo nnkan ti a ba ṣe. A ti sọ pe lẹyin è̩ṣẹ ibọriṣa kò si è̩ṣẹ miiran ti a n fi igba gbogbo ba awọn Ju wi fun bi è̩ṣẹ biba Ọjọ Isinmi jé̩. Apẹẹrẹ igba kan ti a ba awọn Ọmọ Israẹli wi fun ṣiṣai bu ọwọ fun Ọjọ Isinmi jé̩ ni igba aye Nehemiah.
Nehemiah pada si Jerusalẹmu lati ba awọn Ọmọ Israẹli tun odi ti o yi ilu naa ka kọ, lẹyin ti awọn ọta wọn ti wo o lulẹ. Nehemiah ri i pe n ṣe ni awọn Ọmọ Israẹli n ba Ọjọ isinmi jé̩. Wọn gba awọn eniyan laaye lati maa kore ọka ati lati maa kó ere oko wọ inu ilu ni Ọjọ Isinmi. O ṣe e ṣe ki wọn woye pe awọn kò le ṣai má kore ọka wọn nigba ti o ba pọn, ṣugbọn ohun ti o tọ ni ki a rán awọn eniyan naa leti wi pe ọrọ Oluwa sọ bayii pe: “Ijọ mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe iṣẹ, ṣugbọn ni ijọ keje ni ki iwọ ki o simi: ni ìgba ifunrugbìn, ati ni ìgba ìkore ni ki iwọ ki o simi” (Ẹksodu 34:21).
Ninu awọn Ọmọ Israẹli jẹ oniṣowo. Iṣẹ oojọ wọn ni lati maa ra ati lati maa tà. Boya wọn kò ṣi ile itaja wọn, ṣugbọn ni Ọjọ isinmi awọn Ọmọ Israẹli n ra ọja lọwọ awọn ara Tire ti wọn kó ẹja wọ ilu. O ṣe e ṣe ki awọn Ọmọ Israẹli má maa ṣe iṣẹ ti wọn ni Ọjọ Isinmi, ṣugbọn wọn n mu ki awọn ẹlomiiran ṣiṣẹ, wọn si n ba ọjọ naa jẹ nipa rira ohun jijẹ ati “oniruru ohun èlo” (Nehemiah 13:15, 16). Nehemiah ba awọn Ọmọ Israẹli wi o si beere wi pe, “Ohun buburu kili ẹnyin nṣe yi, ti ẹ si mba ọjọ isimi jẹ?” Ohun ti Nehemiah ṣe kọja biba wọn wi lasan, o ti ilẹkun ẹnu-bode ilu o si yàn ìṣọ sibẹ “ki a má ba mu ẹrù wọle wá li ọjọ isinmi.” Nigba ti awọn oniṣowo ati awọn ti n ta oniruuru nnkan tun n fi ẹsẹ palẹ lẹyin odi, o le wọn kuro nibẹ o si kilọ pe oun o “fọwọ bà” wọn ti oun ba tun ri wọn nibẹ.
Gẹgẹ bi ti akoko Nehemiah, awọn Onigbagbọ loni ki i ṣiṣẹ ni Ọjọ Isinmi. Wọn a maa mura silẹ de Ọjọ Isinmi, wọn ki i si tà tabi rà, tabi san owo ọja ni ọjọ naa, nitori pe ki i ṣe ọranyan fun wọn lati ṣe bẹẹ, ati pe ṣiṣe bẹẹ tabuku si Ọlọrun.
Awọn Olukọ Ju
Ègún wa lori awọn ti wọn ba fi kún tabi ti wọn ba yọ kuro ninu ọrọ Ọlọrun (Owe 30:6; Ifihan 22:18, 19). Ọwọ ti o le ju ni awọn olukọ miiran ninu awọn Ju fi mu ofin ẹkẹrin. Wọn fè̩ ọrọ Oluwa wọn si tun fi kún un. Nigba ti Jesu wa ninu aye yii ni ọrọ naa ṣẹlẹ. Ni ọjọ kan bi Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti n kọja lọ laaarin oko ọka, ebi n pa wọn; nitori naa wọn bẹrẹ si i maa ya ipẹ ọka jẹ. Awọn Farisi ri wọn, wọn si tako wọn pe kò yẹ ki wọn ṣe bẹẹ ni Ọjọ Isinmi. Wọn kò lodi si ṣiṣa ti wọn ṣa ọka ninu oko oloko, nitori ofin gba wọn laye lati jẹun ninu oko ẹnikeji wọn niwọn bi wọn kò ba yọ doje si ọka rè̩ ti wọn kò ba si kó ninu eso-ajara rè̩ sinu nnkan lọ sile (Deuteronomi 23:24, 25). Awọn Farisi ro pe Jesu ati awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ kò bọwọ fun Ọjọ Isinmi. Ni tootọ ni wọn ya ninu ọka naa jẹ, ṣugbọn ebi ni o pa wọn. Jesu kọ ni pe ti o ba jẹ iṣẹ aanu tabi eyi ti o jẹ ọranyan ni eniyan ṣe ni Ọjọ Isinmi, oluwarè̩ kò jẹbi biba Ọjọ Isinmi jẹ. Jesu fun ni ni apẹẹrẹ lati fi han pe eniyan kò jẹbi riré ofin Ọlọrun kọja bi o ba jẹ wi pe ọna miiran kò si fun un. Dafidi kò ha jẹ alaijẹbi nigba ti kò si ọna miiran fun un bi kò ṣe lati jẹ akara ifihan, eyii ti kò tọ fun un lati jẹ bi kò ṣe fun awọn alufaa (1Samuẹli 21:6; Marku 2:25, 26)? Awọn alufaa ti n ṣiṣẹ ni Ọjọ Isinmi kò ha jẹ alaijẹbi nitori pe ojuṣe wọn ni wọn n ṣe lati maa pa awọn ọrẹ-ẹbọ fun ijọsin nibi Tẹmpili (Numeri 28:9, 10)?
Jesu sọ fun awọn Farisi naa pe oye Ọrọ Ọlọrun ni kò yé wọn, bi bẹẹ kọ wọn kì ba ti dẹbi fun awọn ti kò jẹbi. Awọn Farisi kiyesara lati ṣe apa kan ninu awọn ofin Oluwa ṣugbọn won gboju fo iyokù. Awọn Farisi ranti awọn ase ati irubọ, ṣugbọn wọn kò loju aanu. Oluwa sọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati ẹnu Woli Hosea pe aanu ni Oun n fẹ, ki i ṣe ẹbọ, ati imọ Ọlọrun ju ọrẹ-ẹbọ sisun lọ (Hosea 6:6). Ọlọrun ni ki eniyan Oun ki o “ṣe otitọ, ki o si fẹ ānu, ati ki o rìn ni irẹlẹ” pẹlu Ọlọrun (Mika 6:8). Eyii ni pe ki i ṣe ni Ọjọ Isinmi nikan bi kò ṣe lojoojumọ laaarin ọsẹ ni a ni lati ṣe nnkan wọnyi; awọn Farisi si n kùna lati ṣe wọn.
Nigba ti awọn Farisi bi Jesu leere boya o tọna lati mu ni lara da ni Ọjọ Isinmi, O dahun pe o “tọ lati mā ṣe rere li ọjọ isimi” (Matteu 12:12). Jesu ran wọn leti pe ti agutan wọn ba bọ sinu iho, wọn o ṣe aapọn lati yọ ọ jade ni Ọjọ Isinmi. Melomeloo ni eniyan fi san ju agutan lọ lati ṣoore fun ni Ọjọ Isinmi?
Ni akoko yii ti ọpọlọpọ kò tilẹ bikita fun Ọlọrun ati Ọjọ Oluwa, ewu ti o wà fun ọgọọrọ eniyan ki i ṣe mimu ofin naa le jù bi ti awọn Farisi, bi kò ṣe ewu aika a si. Ẹ jẹ ki awa, gẹgẹ bi Onigbagbọ, jẹ apẹẹrẹ fun awọn ẹlomiiran nipa yiya Ọjọ Oluwa si mimọ.
Questions
AWỌN IBEERE- Ewo ni Ọjọ Oluwa?
- Ewo ni ọjọ isinmi ati ti ijọsin fun Onigbagbọ?
- Bawo ni a ṣe le ya Ọjọ Oluwa si mimọ?
- Ki ni Onigbagbọ maa n ṣe ni Ọjọ Isinmi?
- Ki ni Onigbagbọ ki i ṣe ni Ọjọ Isinmi?
- Ọjọ wo ni a yà sọtọ fun ọlá ati ogo Ọlọrun?
- Bawo ni eniyan ṣe le mura silẹ fun Ọjọ Isinmi?
- Iru igbadun wo ni a le ri ni Ọjọ Isinmi?
- Iṣẹ wo ni ọmọde le ṣe ni Ọjọ Isinmi lati bu ọla fun Oluwa?
- Ki ni itumọ ọrọ ti Jesu sọ wi pe: “A dá ọjọ isimi nitori enia, a kò dá enia nitori ọjọ isimi”?