Lesson 269 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o bo è̩ṣẹ rè̩ mọlẹ ki yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ānu” (Owe 28:13).Notes
Labẹ Igi Sikamore
Ọna Jẹriko kún fun ogunlọgọ awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde ti wọn n há ara wọn laaye. Ni ọkankán a le ri igi sikamore kan ti o ni ewé bi igi mulberi. A ri Jesu bi O ti wà niwaju awọn ẹgbẹ ero kan ti n lọ si idi igi naa. Lojiji ni a ri ẹni kan ti o sure kọja awọn ero, ọgbẹni gbajumọ kan ti n gba owo-ori, ti a n pè ni Sakeu ni. O duro labẹ igi naa, o nawọ rè̩ lati di ẹka-igi kan mu o si gun igi naa. Ẹni kan ti kò bikita nipa ohun ti awọn eniyan n sọ nipa rè̩ ni – gbogbo ilepa rè̩ ni ọrọ.
S̩ugbọn ọjọ oni yii yatọ: boya á ti ti ilẹkun ile-iṣẹ rè̩ -- owo-ori gbigba le dawọ duro ná. O n fẹ lọnakọna lati ri ohun ti o fà ọpọlọpọ ero ti wọn n kọja ni ibi iṣẹ rè̩ yii. Bi o ti wò ilẹ lati ori igi yii, oju rè̩ ṣe mẹrin pẹlu ti Ẹni kan ti o riran rekọja oju “ọkunrin kekere yii.” Oju Ọmọ Ọlọrun riran wọnu jinlẹ o si ri ero ti o fara sin, ifẹ-inu, ilepa, eto ati ireti rè̩. Bi ẹni pe idalẹbi è̩ṣẹ bori ọkàn rè̩ lojiji -- lẹyin naa ironupiwada, oungbẹ, ifojusọna, iyalẹnu, ati nikẹyin, ayọ ti kò lopin – Sakeu fò silẹ pẹlu ọrọ wọnyi, “Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi è̩sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin” (Luku 19:8).
Tayọtayọ ni o fi gbà Jesu sinu ọkàn rè̩ gẹgẹ bi Olugbala ati Olurapada rè̩; tayọtayọ ni o tun fi gbà Jesu ni Alejo sinu ile rè̩. Wò o bi aṣisọ awọn eniyan ti o wi pe Jesu lọ jé̩ alejo fun ẹlẹṣè̩ ti pọ to! Sakeu ki i ṣe ọmọ Abrahamu nipa ibi nikan mọ, nitori pe nisisiyi o ti di ọmọ Abrahamu nipa igbagbọ.
Kò tun si airorun sùn fun Sakeu mọ, pẹlu ọkàn ti o n da a lẹbi fun gbigba ere aiṣododo. O daju pe a korira rè̩, gẹgẹ bi a ti korira gbogbo awọn ti n gba owo-ori fun ijọba Romu, nitori ojukokoro fun ere nla ti o wà ninu iṣẹ yii. Nisisiyi ti Jesu ti dariji i, o n fẹ ki eniyan dariji oun pẹlu. O mọ ofin awọn ara Romu daradara, eyi ti o wi pe ki ẹni to ba ré̩ ẹnikeji rè̩ jẹ ki o san an pada ni ilọpo mẹrin; ofin awọn Ju ni ki ẹni naa san iye owo naa ati idamarun un rè̩ pẹlu pada. O fi ifẹ ọkàn rè̩ han lati “ṣe gbogbo eyiti o tọ” nipa ọrọ ti o sọ lẹsẹ kan naa, “Bi mo ba si fi è̩sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.” Iyipada ti o wọ inu ọkunrin ti o ti jẹ ọhawọ agbowo-ode yii tobi to bẹẹ ti o fi idaji ere otitọ ti o gba fun iranlọwọ awọn talaka, èrè-aiṣododo rè̩ ni o si san pada ni ilọpo mẹrin.
Mimu Ohun Wiwọ Pada si Titọ
Iṣẹlẹ yii ninu igbesi-aye ẹni kan ti o ṣe atunṣe igbesi-aye buburu rè̩ atijọ fi otitọ yii han pe Ọlọrun n beere atunṣe nigba ti a ba ri igbala. Nigba ti Jesu ba wọ inu ọkàn kan, lẹsẹkẹsẹ ni Oun yoo fi ifẹ kan sinu ọkàn naa lati fé̩ lati dá ohun ti o ti ji pada, lati tọrọ idariji fun irọ ti o ti pa, ki o si ṣe atunṣe gbogbo awọn iwa-buburu rè̩ atijọ. Nigba pupọ ni o jẹ pe nigba ti eniyan ba wa si ibi pẹpẹ adura ti o si n gbadura fun igbala, awọn iwa-buburu ti o ti hù a maa wa siwaju rè̩ ni ọkọọkan. Bi o ba ṣeleri fun Ọlọrun pe oun yoo ṣe atunṣe gbogbo rè̩, Ẹjẹ Jesu yoo bò ọkàn rè̩ yoo si ri idariji è̩ṣẹ gbà lati Ọrun wá. Lẹyin eyi lai jafara, o ni lati “mu ògo padà, ki o si san ohun ti o ti jí padà, ki o si nrin ni ilana iye, li aiṣe aiṣedẽde” (Esekiẹli 33:15). Jesu yoo si tun dariji ni fun awọn nnkan ti kò ṣe e ṣe fun eniyan lati ṣe atunṣe rè̩.
Ni igba Majẹmu Laelae, ni abẹ Ofin, bi eniyan kan ba da è̩ṣẹ kan – bi i pe o purọ, o tan ẹlomiiran jẹ, o bura èké, o mu ohun ti ki i ṣe ti rè̩, tabi o ri ohun ti o sọnu he ti o si purọ nipa rè̩ -- o ni lati mu ọna rè̩ tọ nipa dida ohun naa pada ki o si fi idamarun un le e. Lẹyin eyi yoo mu àgbò kan ti kò ni abuku lati inu agbo ẹran rè̩ yoo si tọ alufaa lọ ẹni ti yoo si ṣe etutu fun un niwaju Oluwa. “A o si dari rè̩ ji; nitori ohunkohun ninu gbogbo ohun eyiti o ti ṣe ti o si jẹbi ninu rè̩” (Lefitiku 6:7). A le ri i pe o jẹ ọranyan fun un lati kọkọ bá arakunrin rè̩ laja ná ki o to mu ẹbọ rè̩ tọ Ọlọrun wá.
Gbigba Idariji ti Ọlọrun ati ti Eniyan
Ẹ jẹ ki a gbe aworan kan nipa ohun kan ti o ṣẹlẹ ninu Tẹmpili ni igba laelae kalẹ niwaju wa. A ri Ọmọ Israẹli kan pẹlu ẹran rè̩ ni è̩gbẹ rè̩. O wọ agbala awọn Ọmọ Israẹli lọ nibi ti o gbe duro fun alufaa lati gba ẹbọ rè̩. A o pa ẹran naa, a o si mu un wa sori pẹpẹ irubọ. O n fẹ idariji, pẹlu gbogbo ọkàn rè̩ ni o duro nibẹ, boya o tilẹ wà ni ori ila ni. Ni akoko ọwọ yii, o ranti lojiji pe arakunrin kan ni ohun kan ninu si oun. N jẹ o ha wi pe, “Lẹsẹkẹsẹ ti mo ba ti pari irubọ yi ng o tọ arakunrin mi lọ lati ba a laja?” Rárá! O fi ẹbọ naa silẹ niwaju pẹpẹ, o si tọ arakunrin rè̩ lọ o si ṣe atunṣe ohunkohun ti kò tọ laaarin wọn.
Ni ọna bayii ni irubọ wọn fi n jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun ni igba laelae; loni a ko le nireti pe Jesu yoo dariji wa bi a kò ba fẹ lati ṣe atunṣe gbogbo ohun ti kò tọ ti a ṣe si ẹlomiiran, nigba ti a ni agbara lati ṣe e. Bi a kò ba le fẹran arakunrin wa ti a ri, bawo ni a ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti a kò ri? Jesu wi pe, “Bi iwọ ba nmu è̩bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ, fi è̩bun rẹ silẹ nibè̩ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn è̩bun rẹ” (Matteu 5:23, 24).
Wo o bi a ti maa n wá ọkàn wa ri daradara ki a to jẹ ninu Ounjẹ Alẹ Oluwa! Awọn eniyan a maa kiyesara gidigidi lati ri i pe kò si ohunkohun laaarin awọn ati arakunrin ati pe kò si ohunkohun laaarin awọn ati Olugbala wọn. Nigba gbogbo ni a ni lati ni “ẹri-ọkàn ti kò li è̩ṣẹ sipa ti Ọlọrun, ati si enia nigbagbogbo” (Iṣe Awọn Apọsteli 24:16), itumọ eyi ti i ṣe pe ki yoo si idalẹbi ninu ọkàn wa.
Ẹ jẹ ki a tilẹ gbà pe Bibeli kò tilẹ sọ ohunkohun nipa atunṣe. Njẹ ẹri-ọkàn rẹ kò ha ni sọ fun ọ pe o ni lati da ohun ti o ji pada, tabi ki o san owo rè̩ pada, bi o ba n fẹ lati ni akọsilẹ rere lati le ni ipin ninu ibugbe loke? N jẹ ọkàn rẹ ki i sọ kẹlẹkẹlẹ fun ọ pe o ni lati jẹwọ awọn irọ wọnni ki ọkàn rẹ ba le bọ lọwọ idalẹbi?
Atunṣe kò pari si mimu ọna wa tọ nipa ọran owo bi ole, ere aiṣododo, igbese; ṣugbọn jijẹwọ irọ, fifi ọrọ banijẹ, atako eniyan lọna aiṣododo, ikorira, ati odì yiyàn pẹlu -- awọn nnkan wọnni ninu eyi ti eniyan ti le pa awọn ẹlomiiran lara ninu ọrọ ati iṣe. O le wi pe, “Arakunrin mi kò mọ pe mo sọrọ buburu nipa oun.” N jẹ ẹni ti o sọrọ naa fun n kọ? Dajudaju o pa a lara, boya oun naa si tun sọ ọ fun ẹlomiiran. O ni lati tọ ẹni ti o sọ fun lọ ki o si jẹwọ. A ni lati ṣe atunṣe awọn iwa buburu ni aye yii tabi ki o lọ dahun fun wọn ni aye ti n bọ. O sàn ki a ṣe atunṣe wọn nihin yii nigba ti “Oludamọran” nla ni, Ẹni ti kò kuna ri ninu ṣiṣe alagbawi ṣi le lọ ṣiwaju wa lati rọ ọkàn awọn ti a ṣe buburu si. “È̩ṣẹ awọn ẹlomiran a mā han gbangba, a mā lọ ṣaju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mā tẹle wọn” (1Timoteu 5:24).
Jijẹ Ipe
Oju Oluwa n wo ẹni ti o n ṣafẹri otitọ ati iwa rere, ọkàn Rè̩ si nfẹ, Ẹmi Rè̩ npe, o si nkanlẹkun ọkàn ẹniti o nfẹ lati ri Jesu ti o si mura tan lati sa ipa rè̩. Sakeu yara lati tọ Jesu wa. Ọna bẹẹ li a n gba ri nnkan gba lọwọ Jesu -- ṣe ohun ti O ba wi, ki o si ṣe e lẹsẹkẹsẹ. Samuẹli ọmọdekunrin nì dahun lẹsẹkẹsẹ, “Emi nĩ.” Abrahamu paapaa dahun kiakia, “Emi nĩ.” Isaiah dahun pe, “Emi nĩ; rán mi.” Awọn kan wà ti wọn n dahun si ipe Ẹmi ni akoko yii. Iwọ nkọ? Njẹ a ti pe orukọ rẹ? Njẹ o ti dahun ipe ti Ẹmi npe ki o si wi pe, “Ngo yipada kuro ninu è̩ṣẹ mi; ngo si ṣe eyiti o tọ ati eyi ti o yẹ; emi o mu ògo padà, ngo dá eyiti mo ti ji pada; emi o rin ninu ilana iye, li aiṣe aiṣedede”? Gbogbo awọn ti o ṣe eyi ni ileri wà fun pe “yiyè ni yio yè, on ki o kú” (Esekiẹli 33:14, 15). Iye-ainipẹkun n duro de awọn ti nwọn ṣe gbogbo eyiti Ọlọrun mbère lọwọ wọn.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni Bibeli sọ nipa ohun ti o sọnu ti a ri he?
- Njẹ a gbọdọ dá nnkan ti a jí pada fun ẹniti o ni i?
- Bi arakunrin rẹ ba ni ohun kan ninu si ọ, njẹ o yẹ ki o duro titi di igba ti o ba tọ ọ wà lati ṣe atunṣe?
- Sọ bi Sakeu ti ṣe ṣe atunṣe tirè̩?
- Njẹ o yẹ lati jẹwọ irọ?
- Ki ni itumọ pe ki a jẹ “Ọmọ Abrahamu”?
- Njẹ ọmọ Abrahamu li awa iṣe?
- Njẹ a le nireti lati lọ si Ọrun bi a kò ba mu gbogbo ohun ti o wọ padabọ si titọ?