Deuteronomi 4:9, 10; 6:3-15; Joṣua 24:15; Jobu 1:1-5; Orin Dafidi 78:1-8; Matteu 14:19; 15:36; Iṣe Awọn Apọsteli 27:33-37; 1Timoteu 4:4, 5; 5:4

Lesson 270 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iṣe ọmọde pāpa li a fi imọ ọ, bi iwa rè̩ ṣe rere ati titọ” (Owe 20:11).
Notes

Agbo-ile

Ninu ile kan ni igberiko ni awọn ara agbo-ile kan – baba, iya, ati awọn ọmọ mẹrin – joko ti ina ti a da sinu ààrò tabi idana. Gbogbo wọn tẹjumọ baba wọn; iyara naa si dakẹ rọrọ. Laipẹ a gbọ ohun baba bi o ti nfi tọwọtọwọ ka itan alẹ kan fun awọn ọmọ rè̩.

S̩ugbọn farabalẹ! Itan rè̩ ki iṣe nipa ọrọ asan kan ṣá. Bibeli ni o wà lọwọ rè̩ nì. Nigba ti o buṣe kika ori iwe naa, awọn mẹfẹẹfa wolẹ, wọn si papọ gbe ohun adura soke si Ọlọrun. Iná ti n kú lọ, wọn si ki ara wọn pe “O dàárọ,” olukuluku ara ile alarinrin yii si lọ dubulẹ lati sun. Nigba ti a ro ó lọ titi a rii pe iru agbo-ile bayii ki i ṣe ti ode oní, o jẹ ti igba ti o ti kọja, o ṣe e ṣe ki iru ile bẹẹ wọpọ ni nnkan bi ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin ṣugbọn iru agbo-ile bẹẹ ṣọwọn lode oni.

Ẹ jẹ ki a wo inu ile miiran, agbo-ile ọlajú ni ilu nla. Nibẹ a ri baba miiran, iya, ati awọn ọmọ wọn. Awọn naa la oju, wọn si tẹ eti silẹ lati ri ati lati gbọ itan alẹ, gẹgẹ bi iṣe wọn. S̩ugbọn kì i ṣe lati inu Ọrọ Mimọ Ọlọrun ni a ti n sọ itan naa, bi ko ṣe lati inu ẹrọ redio. Sinnima kekere kan wà nibẹ; awọn eniyan n sọrọ, wọn n rẹrin, wọn si n pariwo. Ilẹ n ṣu lọ ṣugbọn awọn ara agbo-ile yii ko dẹkun lati maa fi itara tẹti si ọrọ ti o n ti inu ẹrọ tẹlifiṣọn naa jade wá, tabi lati maa wo aworan ti o n fi hàn. Oju awọn ọmọ ti n pọn, o si ti n rè̩ wọn, ṣugbọn ere ti wọn n wo ko i ti pari; itan naa gùn pupọ.

Nigba ti eniyan ba fi igbesi-aiye awọn ọmọ ti a ti tọ dagba ninu agbo-ile mejeeji yii wé ara wọn, kò ni ṣoro fun wa lati ri anfaani iyebiye ti o wà ninu ijọsin agbo-ile. Dajudaju ibukun akunwọsilẹ ni o maa n tẹle awọn ọmọ ti a ti tọ dagba ninu ile ti wọn ti ri aaye fun pẹpẹ adura. S̩ugbọn o ṣe ni laanu lati wi pe iru ile atijọ, nibi ti ọwọ ti wà fun Ọlọrun, ti fẹrẹ di ohun igbagbe. N ṣe ni ìgba ti a wà yii n sare tete, o kun fun sisá soke ati sisá sodò. Ohun ti eniyan n ṣe lati oorọ titi di aṣaalẹ lode oni ni sisare, ṣiṣe aniyan, didù sihin-sọhun. Akokò kekere ni a n fi silẹ fun Ọlọrun.

Ẹkọ Bibeli ninu Ile

Ẹ jẹ ki a wo inu Ọrọ Ọlọrun lati ri iru agbo-ile ti inu Rè̩ dùn si. Ọlọrun tipasẹ Mose iranṣẹ Rè̩ sọ fun awọn eniyan pe, “Ọrọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà li àiya rẹ: ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọrọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọna, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide” (Deuteronomi 6:6, 7).

Njẹ o ti gbiyanju ri lati kọ apakan ninu Iwe Mimọ sori? Nipa kika a leralera – nigba ti o ba joko ninu ile, nigba ti o ba n rin kaakiri, nigba ti o ba n lọ dubulẹ sùn, ati nigba ti o ba ṣẹṣẹ ji ni owurọ -- lai pẹ jọjọ iwọ yoo mọ ọn daradara. Ọna ti a paṣẹ pe ki awọn eniyan igba laelae fi maa kọ awọn ọmọ wọn ni ọrọ Oluwa ni yii, nitori pe awọn iwe ninu eyi ti a kọ gbogbo Ofin si kò pọ niye. A tun sọ fun wọn lati kọ ẹsẹ ọrọ Ofin yii sara takada mẹrin ti a fi awọ ọmọ malu ṣe ki wọn si so wọn mọ iwaju ori wọn tabi ọwọ wọn. A kò mọ boya nigba gbogbo ni awọn awọ wọnyi ni lati wà lara wọn, ṣugbọn àbájade gbogbo ọrọ naa ni pe wọn gbọdọ kiyesara gidigidi lati maa mu Ofin Ọlọrun ṣẹ, ki wọn maa ṣe àṣaro ninu rè̩ nigba gbogbo ki wọn má si ṣe gbagbe rè̩ lae. A tun sọ fun won pe ki wọn maa kọ ọrọ Ofin naa sara opó ile wọn ati sara ilẹkun ọna-ode wọn.

Baba Kan ti o S̩e Olóòótọ

Nigba ti akoko to fun Joṣua oloootọ iranṣẹ Ọlọrun lati kú, o pe awọn eniyan jọ o si sọ fun wọn ni ti iṣeun Ọlọrun. Gẹgẹ bi awọn ọmọde ti i duro lẹba ibusun awọn obi wọn ti n rekọja lọ lati gbọ ọrọ wọn ikẹyin, bẹẹ ni awọn Ọmọ Israẹli tẹti silẹ lati gbọ ọrọ idagbere aṣaaju wọn. Lẹyin ti o ti ran wọn leti awọn oore Oluwa, o wi pe, “Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sin OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sin li oni.” Eyi ni pe: “Ẹ maṣe fẹsẹ palẹ mọ; ẹ ṣe ipinnu loni yii; ẹ maṣe tẹle ọgọrọ eniyan, ṣugbọn ẹ fara mọ awọn oloootọ.” Joṣua kò ni ipinnu titun kankan lati ṣe; awọn ara ile rè̩, awọn ẹbi rè̩, awọn ọmọ rè̩, ati awọn iranṣẹ rè̩ -- “OLUWA ni awọn o maa sin.” Lootọ ni Joṣua jẹ onidajọ ati alakoso, ṣugbọn Ọlọrun ni O gba ipo kin-in-ni ninu igbesi-aye rè̩.

Eyi jé̩ akoko ọwọ fun Israẹli, nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba si pe ẹnikẹni lati ṣe ipinnu, o jẹ akoko ọwọ. O ha ti dahun ipe Kristi ki o si wi pe, “Bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sin?” Boya kò ṣe e ṣe fun ọ lati jere gbogbo ile-iwe rè̩ fun Kristi, tabi gbogbo awọn ti ẹ jọ jé̩ ẹgbẹ ninu ibi-ikẹkọọ kan naa paapaa. S̩ugbọn bi kò ṣe e ṣe fun ọ lati fa iye ọkàn ti o wu ọ wá fun Kristi, mu iye awọn ti o ṣe e ṣe fun ọ lati pe wá. Bi o ba n gbe igbesi-aye Onigbagbọ, ti o n ka Bibeli rẹ ti o si n gbadura, o le jere ẹni kọọkan ninu agbo-ile rẹ fun Kristi, bi wọn kò ba ti i ri igbala.

Ogún Iwa-bi-Ọlọrun

Bi o ba jẹ ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ti awọn obi rẹ ti kọ lati fẹran Oluwa ati lati sin In; ti awọn obi rẹ ba ti kọ ọ ni ofin Ọlọrun, o ṣe olori ire pupọpupọ. Inu Ọlọrun a maa dun si awọn obi agba ati awọn obi ti wọn tun jẹ obi fun awọn obi agba, awọn ti wọn ti fi ọrọ naa kọ awọn ọmọ wọn, “Ki awọn iran ti mbọ ki o le mọ, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn: ki nwọn ki o le ma gbé ireti wọn le Ọlọrun, ki nwọn ki o má si ṣe gbagbe iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ki nwọn ki o pa ofin rè̩ mọ” (Orin Dafidi 78:6, 7). Kò si obi ti o le ṣe etutu fun è̩ṣẹ awọn ọmọ rè̩. O le gbadura fun awọn ọmọ rè̩ ọkunrin ati obinrin, ṣugbọn bi awọn ọmọ kò ba yi pada si Ọlọrun ki wọn si ronupiwada è̩ṣẹ wọn, wọn yoo ṣegbe.

Ijọsin Ojoojumọ

Nigba ti wọn ba n ka Bibeli ni akoko adura agbo-ile, ṣi “eti” ọkàn rẹ silẹ. Bi o ba ṣe bẹẹ, iwọ yoo mọ iyatọ laaarin ohun ti o tọ ati ohun ti kò tọ, iwọ yoo si ni igboya lati kọ fun awọn ti wọn ba pe ọ si ohun ti ẹri-ọkàn rẹ sọ fun ọ pe kò yẹ ki Onigbagbọ lọwọ si.

Bi a ba ri ọmọkunrin tabi ọmọbinrin kan ninu awọn ti n ka ẹkọ yi ti kò ni baba tabi iya Onigbagbọ, a rọ ọ pe ki o fi akoko kan silẹ ni owurọ ki o to lọ si ile-iwe ati ni aṣaalẹ fun adura. Ni akoko yii, ka Bibeli rẹ ki o si pade Oluwa ninu adura. Akoko ti o dara ju lọ ni owurọ. Fun Ọlọrun ni akoko ti o dara ju lọ; ki i ṣe igba ti o ba ti rẹ ọ ti o si ti rọ bi ewe. O le ri adidun gba lọdọ Rè̩ eyi ti yoo mu ki ọkàn rẹ balẹ laaarin gbogbo irukerudo ti o le ṣẹlẹ ni ọjọ naa.

Adura nidi Ounjẹ

Tẹlẹ ri ti akoko ounjẹ ba tó, n ṣe ni awọn ara ile maa n joko yi tabili ka ti wọn si maa n tẹriba; nigba naa baba wọn a si gbadura si ounjẹ naa. S̩ugbọn fun ọpọlọpọ agbo-ile ti o wà ni ilẹ wa loni, eyi fẹrẹ ti di ohun atijọ. Ọrọ Ọlọrun fun ni ni apẹẹrẹ pupọ lati kọ ni pe o yẹ ki olukuluku eniyan maa tọrọ ibukun Ọlọrun lori ounjẹ rè̩ ki o to jẹ ẹ. Nibi ounjẹ alẹ ikẹyin ti Jesu jẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni oru ọjọ naa ti a fi I han, O mu akara, nigba ti O si ti dupẹ O bu u (I Kọrinti 11:23, 24). Gbogbo wa ni a mọ itan mejeeji ti awọn ogunlọgọ eniyan ti a bọ yo. Ni igba mejeeji ki wọn to bẹrẹ si i jẹ ounjẹ ni Jesu gbé oju soke Ọrun, O busi ounjẹ naa O si dupẹ, ki O to gbe e fun awọn ọmọ-ẹyin lati pin in fun awọn eniyan. Paulu pẹlu dupẹ lọwọ Ọlọrun ki o to jẹ ounjẹ rè̩ (Iṣe Awọn Apọsteli 27:33-37). Kò ha yẹ ki a fi ọpẹ fun Ọlọrun fun ounjẹ ojoojumọ ti O n pese fun wa lọpọlọpọ to bayii, paapaa fun awa eniyan dudu?

Si Awọn Obi ati Awọn Ọmọ

Awọn ọmọ ti a tọ dagba ninu agbo-ile ti pẹpẹ adura ti di apatì, nibi ti a kò bọwọ fun Ọlọrun, a maa bọ sinu ayé ti o kun fun idanwo iru eyi ti yoo wọ ọkàn lọ sinu egbe ayeraye, ayafi bi a ba fun wọn ni anfaani lati wá Ọlọrun ati lati ri I. Lara ibi ti o n di idẹkun fun ọkàn awọn ọdọmọde ni: sinima, ẹrọ amohunmaworan, awọn itan nipa iwa ọdaran ti a n sọ lori ẹrọ redio, aṣọ ti kò bo itiju, taba mimu, ijo ni ile-iwe, apejẹ ayé, ati awọn iwe itan nipa iwa ipa ti awọn ọmọde maa n kà. Kò ha yẹ ki olukuluku obi ati olukuluku olukọ Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi fi pẹlẹpẹlẹ kọ awọn ọmọ ni Ọrọ Ọlọrun ki a ba le pese wọn silẹ lati dojukọ awọn agbara iwa buburu? Awọn oluṣọ-agutan fi yé ni pe ikooko ki i mu agutan nla niwọn igba ti o ba ti le ri ọdọ-agutan kì mọlẹ. Gẹgẹ bi ọdọ-agutan keekeekee ni awọn ọmọde jẹ, alailera.

Ihinrere wà fun awọn obi ati awọn ọmọde bakan naa. Bi igbokegbodo rẹ ba pọ to bẹẹ ti o kò fi n ri aye lati gbadura, mọ pe igbokegbodo rẹ ti pọ ju. Bi a kò ba fun ọmọde ni ẹkọ Bibeli ninu ile, ti a kò ba si ran an lọ si Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi, nibo ni yoo ti gbọ nipa Ọlọrun? Dajudaju ki i ṣe ninu awọn ile-iwe ti ijọba ti a ti fa igi le ẹkọ Bibeli.

Ọrọ Ọlọrun paṣẹ pe, “Tọ ọmọde li ọna ti yio tọ: nigbati o si dàgba tan, ki yio kuro ninu rè̩” (Owe 22:6). Ogún ayeraye ni awọn ti kò fi akoko silẹ lati ṣe eleyi fi n dù awọn ọmọ wọn. Pẹpẹ adura wà ninu ile rẹ bi?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni yẹ ki a bè̩ru?
  2. Bawo ni ifẹ wa si Ọlọrun ṣe ni lati pọ to?
  3. Sọ ọna ti a ni ki awọn Ọmọ Israẹli fi maa kọ awọn Ọmọ wọn ni Ofin Ọlọrun.
  4. Iru baba wo ni Joṣua jé̩?
  5. Ibi melo ni o le tọka si ninu Iwe Mimọ nipa fifi ọpẹ fun Ọlọrun ki a to jẹ ounjẹ wa?
  6. Iru ibukun wo ni o maa n jẹ ti awọn ti a tọ dagba ninu agbo-ile Onigbagbọ?
  7. Njẹ ojoojumọ ni o n ka Bibeli ti o si n gbadura?