Lesson 271 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn” (Marku 10:9).Notes
Ibẹrẹ Igbesi-aye Ọmọde
Ile-ẹkọ kin-in-ni ti Ọlọrun kọkọ ṣeto rè̩ ni ayé yii ni “ile.” Ni ọjọ wọnnì ni Ọgba Edẹni, ki ile-iwe tabi ile-isin tò wà ni ilana gbigbe pọ gẹgẹ bi ẹbi ti wà.
Ibi akọkọ ti ọmọde n ranti ni ile rè̩. Awọn olukọ rè̩ akọkọ ni baba ati iya rè̩. Ọmọde kò mọ nnkan pupọ lẹyin jijẹun ati sisun, nitori naa nigba ti o ba bẹrẹ si i sọrọ yoo bẹrẹ si beere ibeere oriṣiriṣi. Kò mọ ohun ti o tọ yatọ si eyi ti kò tọ, nitori naa awọn obi rè̩ ni lati tọ ọ ki wọn si jẹ apẹẹrẹ fun un. Ọmọde a maa yara kọ ẹkọ pupọ ju lọ nipa ṣiṣe afarawe.
Bibeli sọ fun wa pe gbogbo eniyan ni a bi ninu è̩ṣẹ, ati pe ero eniyan gẹgẹ bi è̩dá ibi ni. Nitori naa bi a kò ba tọ ọmọde sọna nipa ohun ti o ni lati ṣe, iwa buburu ni yoo maa hù. Lati kekere ni ibinu ati orikunkun yoo maa fara hàn ninu aye rè̩; bi a kò ba a wi, awọn iwa yii yoo maa dagba si i.
Igbọran
Ọkan ninu awọn ẹkọ ti o tobi ju lọ ti awọn obi ni lati kọ awọn ọmọ wọn ni igbọran, wọn si ni lati bẹrẹ lati kekere. Kò si ifẹ pupọ ninu ile ti a ti gba awọn ọmọde laaye lati maa ṣe gẹgẹ bi o ti wù wọn. Lai pẹ wọn o di amọti-ara-ẹni-nikan, wọn kò si ni bikita nipa ẹnikẹni ju ara wọn nikan ṣoṣo lọ. Aṣẹ Ọlọrun ni pe: “Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn obi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ. Bọwọ fun baba ati iya rẹ; (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri)” (Efesu 6:1, 2).
Ibawi ki i fi igba gbogbo jẹ ninà. Nigba pupọ ni awọn obi le jé̩ iranlọwọ fun awọn ọmọ wọn lọna ti yoo fi jinlẹ lọkàn wọn nipa biba wọn sọ asọye, nipa fifi òye aṣiṣe wọn yé wọn lati inu Bibeli, ati ṣiṣe alaye àbuku wọn fun wọn. Nigba ti Ọlọrun n pe awọn ẹlẹṣẹ sọdọ ara Rè̩, O ni: “Wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ” (Isaiah 1:18). Ọlọrun tun wi pẹlu pe, “Ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu” (Efesu 6:4).
S̩ugbọn nigba ti ọmọde ba kọ lati gbọran nipa ọrọ rere ati asọye gbogbo, a ni lati fi agbara mu un gbọran nipa “paṣan itọni,” tabi nina a. “Nitoripe ẹniti OLUWA fẹ on ni itọ, gẹgẹ bi baba ti itọ ọmọ ti inu rè̩ dùn si” (Owe 3:12).
Ọdọmọkunrin kan ti o di ojiṣẹ Ọlọrun nigba ti o dagba wi pe: “Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun gbogbo ijiya, ati fun gbogbo igba ti baba mi ba mi gbadura. Baba mi fi adura ati paṣan, sin ọmọ rẹ lọ sinu iṣẹ alufaa.”
Aibikita Awọn Obi
Ọlọrun yoo ṣe idajọ awọn obi ti kò ba awọn ọmọ wọn wi. Eli jé̩ olori alufa oun i ba si jẹ eniyan mimọ Ọlọrun. S̩ugbọn nigba ti o ri awọn ọmọ rè̩ ti wọn n huwa buburu, o sọ fun wọn lẹẹkan pe ki wọn má ṣe bẹẹ o si fi wọn silẹ lati maa ṣe bi wọn ti n ṣe lọ. Ọlọrun wi pe, “Emi ti wi fun u pe, emi o san ẹsan fun ile Eli titi lai, nitori iwa buburu ti on mọ; nitori awọn ọmọ rè̩ ti sọ ara wọn di ẹni ẹgàn, on kò si da wọn lẹkun” (1Samuẹli 3:13). A gba ipo alufa lọwọ Eli, ijiya rè̩ ni pe ki yoo si arugbo kan ni ile rè̩ -- gbogbo awọn ọmọ rè̩ ni yoo kú ni ọdọ.
Dafidi ọba paapaa ni lati jiya fun kikẹ ọmọ rè̩ ọkunrin ni àké̩bàjé̩. Bibeli sọ fun wa pe Dafidi kò wi pe bẹẹ kọ fun Absalomu ri, nigba ti Absalomu si dagba tán o huwa itiju si baba rè̩ nipa gbigbidanwo lati gba ijọba lọwọ rè̩. O hàn gbangba pe Absalomu kú lai ronupiwada.
Awọn ọmọde ti o n gbọran si obi wọn lẹnu ti a si kọ lati ṣiṣẹ ati lati ran awọn ẹlomiiran lọwọ jẹ ọmọ ti o layọ. O le ro pe a rè̩ ọ silẹ nigba ti a kò gbà ọ laye lati ṣe ifẹ inu rẹ, tabi o le ro pe awọn obi rẹ kò laanu nigba ti wọn jẹ ọ niya; ṣugbọn iwọ yoo ri i pe o ni ọpọlọpọ ọré̩ si i, awọn eniyan yoo si fẹran rẹ ju bẹẹ lọ nigba ti wọn ba ri i pe o n gbọran, o ni ifẹ, o si ni inurere.
Aworan
Njẹ ohun kan wà ti o le fi ile rẹ hàn gẹgẹ bi ile Onigbagbọ? Njẹ o ni aworan Jesu ninu yara rẹ? Awọn aworan wo ni o kọkọ n ranti? O kò le gbagbe awọn miiran ninu awọn nnkan ti o n ri lojoojumọ nigba ti o wà ni ọmọde. Ọlọrun mọ pe awọn ọmọde a maa ranti ohun ti wọn ri fun igbà pipẹ ju ohun ti wọn gbọ lọ, nitori naa O sọ fun Mose pe ki o sọ fun awọn eniyan naa lati kọ Ofin “sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun ọna-ode rẹ” (Deuteronomi 6:9). Awọn aworan daradara ati akọle ọrọ rere ninu ile wa a maa ràn wa lọwọ lati maa ranti nnkan nipa Jesu. Akọle ọrọ rere kan ni:
“Kristi ni Olori ile yii,
Ọrẹ Airi nibi ounjẹ,
Ẹniti ntẹtisilẹ jẹjẹ
Si gbogbo ọrọ ti a nsọ.”
Ile ti Rẹ
Ni ọdun diẹ si i, bi Oluwa ba fa bibọ Rè̩ sẹyin, iwọ yoo dagba iwọ yoo si fẹ lati ni ile ti rẹ. Ninu ọgba Edẹni ni a kọ ṣe igbeyawo kin-in-ni, Ọlọrun ni o si ṣe akoso igbeyawo naa. O ni: “Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rè̩ silẹ, yio si fi ara mọ aya rè̩: nwọn o si di ara kan” (Gẹnẹsisi 2:24). Eyi jẹ ọkan ninu awọn ofin akọkọ ti Ọlọrun ṣe nipa awọn eniyan. Jesu tun sọ bẹẹ O si fi kun un pe: “Nwọn kì iṣe meji mọ, bikoṣe ara kan. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn” (Marku 10:8, 9).
Ranti ofin yii nigba ti o ba dagba ti o si fẹ gbeyawo. Ranti pe ohun ti Ọlọrun wi ni pe titi de opin ẹmi rẹ ni. Ọlọrun n kọ akọsilẹ igbeyawo rẹ, O si gbọ nigba ti o wi pe, “Titi ikú yio fi yà wa.” Lai si aniani, aisan ati wahala yoo wá sinu ile rẹ. (Olukuluku eniyan ni wọn n wá si ile rè̩). Ohun ti o wọpọ si ni pe ki i ṣe gbogbo ohunkohun ti o ba fẹ ni o le ni owo to lati rà. S̩ugbọn o ti ṣeleri niwaju Ọlọrun, ni akoko igbeyawọ rẹ, lati jé̩ olotitọ, “nigba aisan ati ilera, nigba ibanujẹ ati ayọ, nigba ipọnju ati ọrọ.” S̩ọra nigba ti o ba n jẹ awọn ẹjé̩ wọnyi, lati ri i pe o pinnu lati pa wọn mọ, nitori pe Ọlọrun yoo beere wọn lọwọ rẹ.
A So Wọn Pọ
Paulu Apọsteli kọwe: “Obinrin ti o ni ọkọ, iwọn igbati ọkọ na wà lāye, a fi ofin dè e mọ ọkọ na; ṣugbọn bi ọkọ na ba kú, a tú u silẹ kuro ninu ofin ọkọ na. Njẹ bi o ba ni ọkọ miran nigbati ọkọ rè̩ wà lāye, panṣaga li a o pè e: ṣugbọn bi ọkọ rè̩ ba kú, o bọ lọwọ ofin na; ki yio si jẹ panṣaga bi o ba ni ọkọ miran” (Romu 7:2, 3). Ọlọrun si ti wi pe kò si panṣaga obinrin tabi panṣaga ọkunrin ti yoo wọ Ijọba Ọlọrun. A kà wọn pẹlu awọn abọriṣa ati ọmuti ati apaniyan (Galatia 5:19-21).
Jesu tun wi pe, ẹnikẹni ti o ba fé̩ ẹni ti o ti gbeyawo lẹẹkan ri ti o si ṣe ikọsilẹ, ṣe panṣaga (Matteu 5:32). A bé̩ Johannu Baptisti lori nitori pe o sọ fun Hẹrọdu pe è̩ṣẹ ni fun un lati fẹ iyawo arakunrin rè̩. Eyi jẹ kókó ẹkọ pataki, bi kò ba ri bẹẹ, Johannu Baptisti ki ba ti fẹ lati lọ sinu tubu ki o si fi ẹmi rè̩ lelẹ fun wiwaasu rè̩.
Wo rekọja ohun ti o le fi oju ri nigba ti o ba n rò lati gbeyawo. Njẹ ọdọmọkunrin daradara ti gbogbo ọkàn rẹ n fa si nì ni iru baba ti o n fẹ fun awọn ọmọ rẹ? Njẹ o ṣetan lati fi orukọ ti rẹ silẹ, orukọ rere rẹ, ki o si tẹriba fun un? Ọmọbinrin kekere ti o n ba ọ ṣe àwàdà pupọ ni yoo ha jé̩ iya rere fun awọn ọmọ rẹ? Yoo ha se ounjẹ rẹ fun ọ ki o si ṣe itọju ile rẹ daradara fun ọ? Bi awọn ọdọ yoo ba ronu nipa awọn ibeere wọnyii, ituka laaarin ọkọ ati aya lẹyin ọdun kan tabi meji ti wọn ṣe igbeyawo ki yoo pọ to bi o ti ri nisisiyi.
Idi rè̩ ti ikọsilẹ ọkọ ati aya fi pọ ni pe a gba awọn ọmọde laaye lati maa dagba lai si ibawi. Ohun gbogbo ti wọn n fẹ ni a fi fun wọn lai jẹ pe wọn ṣiṣẹ fun un, wọn a si maa nireti lati ri ohun gbogbo ti wọn n fẹ gbà lẹyin ti wọn ba dagba. Wọn a maa tẹnu mọ ati ṣe ifẹ-inu wọn ninu imọti-ara-ẹni-nikan, dipo ki wọn fi ohun ti awọn ẹlomiiran n fẹ sinu ero wọn.
Ranti pe ajọṣepọ ni igbeyawo jé̩ ninu eyi ti olukuluku ni lati gbe ẹru ti o kan an, ki o si ṣe ipa ti rè̩. Olukuluku ni lati kọ lati sọ nipa iṣoro rè̩ lọna ti o tọ, ki wọn si tun fohun ṣọkan.
Ọkan ninu Ẹmi
Bi o ba jẹ Onigbagbọ, ri i daju pe ẹni ti o yàn jé̩ Onigbagbọ. Ọrọ Ọlọrun wi pe: “Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ: nitori idapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo”? (2Kọrinti 6:14). Si rii daju pe ẹni ti o ṣe igbeyawo pẹlu rè̩ kò i ti gbeyawo kan tẹlẹ.
Ohun kan ti a tun ni lati fiyesi ni pe, Ọlọrun wi pe, “Nitori na li ọkunrin yio ṣe ma fi baba on iya rè̩ silẹ, yio si fi ara mọ aya rè̩” (Gẹnẹsisi 2:24). Lati igba naa lọ wọn di ara kan, a yà wọn sọtọ kuro lọdọ awọn obi wọn. Awọn ọkọ ati iyawo ti wọn jé̩ ọdọ yoo layọ pupọ ju bẹẹ lọ bi wọn ba n gbé lọtọ ki wọn si jumọ maa yanju iṣoro wọn lai maa sare tọ awọn obi wọn lọ fun ibakẹdun nigbakuugba ti ède-aiyede ba ti wà. O maa n gba ọdun to niye nigba miiran fun ẹni meji lati kọ lati mọ iwà ara wọn, yoo si gba suuru ati ipamọra lọdọ awọn mejeeji lati mu ki ayé wọn layọ.
Iṣẹ Ọkọ
Ẹ jẹ ki a rò nipa awọn iṣẹ ti Ọlọrun fi lelẹ fun ọkọ. “Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ijọ, ti o si fi ara rè̩ fun u; ... Bḝli o tọ ki awọn ọkunrin ki o mā fẹran awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikarawọn.Ẹniti o ba fẹran aya rè̩, o fẹran on tikararè̩” (Efesu 5:25, 28).
Nigba ti ọkunrin ba jé̩ è̩jé̩ igbeyawo, itumọ eyi ni pe o di olori ẹbi kan, o si gba ojuṣe gbigbe ẹru ẹbi naa. Bibeli sọ pe ẹni ti kò ba pese fun awọn ara ile rè̩ o buru ju alaigbagbọ lọ (1Timoteu 5:8). Jé̩ ki o da ọ loju pe o mura tan lati ṣe ojuṣe yii ki o to gbeyawo.
Iṣẹ ti o ṣe pataki ju lọ fun ọkunrin lati ṣe fun ẹbi rè̩ ni lati fi aṣẹ Ọlọrun kọ awọn ọmọ rè̩. Nigba ti Ọlọrun pe Abrahamu lati jẹ baba awọn eniyan ayanfẹ Rè̩, O wi pe: “Nitoriti mo mọ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rè̩ ati fun awọn ara ile rè̩ lẹhin rè̩, ki nwọn ki o ma pa ọna OLUWA mọ lati ṣe ododo ati idajọ” (Gẹnẹsisi 18:19).Wo iru ibanujẹ ti yoo mu ba obi bi awọn ọmọ rè̩ tilẹ dagba ti wọn si di alagbara nipa ti ara, ti wọn ni imọ, ti wọn si dara lati wò, ṣugbọn ti wọn sọ ẹmi wọn nu ninu ọrun apaadi.
Ọlọrun n sọ fun wa pe ẹni ti yoo ṣe akoso ijọ ni lati le ṣe akoso ile rè̩, “ti o mu awọn ọmọ rè̩ tẹriba pẹlu iwa àgba gbogbo” (1Timoteu 3:4).
Peteru Apọsteli fun ọkọ ni aṣẹ diẹ nipa bibu ọlá fun aya rè̩: “Bẹ gẹgẹ ẹnyin ọkọ, ẹ mā fi oye bá awọn aya nyin gbé, ẹ mā fi ọla fun aya, bi ohun èlo ti kò lagbara, ati pẹlu bi ajumọ-jogun ore-ọfẹ iye; ki adura nyin ki o má bā ni ìdena” (1Peteru 3:7). Bi eniyan kò ba bu ọlá fun iyawo rè̩ ki o si fẹran rè̩, Oluwa kò ṣeleri lati gbọ adura rè̩. A kò ni bu ọlá fun iṣẹ ti o n ṣe fun Oluwa bi o ba jé̩ onikanra ati alaini inurere si ẹbi rè̩ ninu ile.
Ọkunrin ni lati jẹ apẹẹrẹ rere niwaju awọn ọmọ rè̩. Njẹ o fẹ ki awọn ọmọ rẹ maa ṣe bi o ti n ṣe nigba ti nnkan ba ṣẹlẹ ti o lodi si ifẹ rẹ? Baba ni lati ṣọra lati pa ileri rè̩ mọ nipa awọn nnkan keekeekee; tabi bi kò ba le mu ileri rè̩ ṣẹ, o ni lati ṣọra lati ṣe àlaye idi rè̩ ti o fi ri bẹẹ. O ni lati jẹ olotitọ bi o ba n fẹ ki awọn ọmọ oun bu ọlá fun oun.
Iṣẹ Aya
Ẹ jẹ ki a ronu nipa awọn iṣẹ aya. “Ẹnyin aya, ẹ mā tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi fun Oluwa. Nitoripe ọkọ ni iṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi ti ṣe ori ijọ enia rè̩, on si ni Olugbala ara” (Efesu 5:22, 23).
Ninu iwe Owe a ri aworan daradara kan ti i ṣe ti obinrin oniwa rere kan, a si sọ nipa rè̩ pe: “Aiya ọkọ rè̩ gbẹkẹle e laibè̩ru ... Rere li obirin na yio ma ṣe fun u, ki iṣe buburu li ọjọ aiye rè̩ gbogbo ... O fi ọgbọn yà ẹnu rè̩; ati li ahọn rè̩ li ofin iṣẹun. O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rè̩, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ” (Owe 31:11, 12, 26, 27). Iwọ ha mọ ohun ti ère rè̩ jé̩? “Awọn ọmọ rè̩ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bāle rè̩ pẹlu, on si fi iyin fun u” (Owe 31:28).
Iṣẹ awọn agba obinrin ni lati sọ fun awọn ọdọmọbinrin bi wọn ṣe le ṣe ile wọn ni ile ti o layọ fun ara wọn ati ẹbi wọn. Iṣẹ wọn ni lati kọ wọn lati ni iwa-agba, “lati fẹran awọn ọkọ wọn, lati fẹran awọn ọmọ wọn, lati jẹ alairekọja, mimọ, òṣiṣé̩ nile, ẹni rere, awọn ti ntẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ọrọ Ọlọrun máṣe di isọrọ-òdi si” (Titu 2:4, 5). Iṣẹ ti aya ni lati mu ki ile wà ni imọtoto, lati ṣe itọju awọn ọmọ rè̩ daradara, ki o pese ounjẹ silẹ ni akoko de ọkọ rè̩ nigba ti o ba ti ibi iṣẹ dé. Ile rè̩ ni lati jẹ ile ti o gbamuṣe, ile ti o layọ nibi ti awọn ẹbi rè̩ yoo ni igbadun laaarin ara wọn. Ọlọrun ni eyi jé̩ ohun pataki, bi kò ba si ṣe e, itiju ni obinrin naa jẹ fun Ihinrere, o si n mu ki a sọ ọrọ odi si Bibeli. È̩ṣẹ ti o buru ju ni ọrọ òdi.
Bi iya kan ba kún fun iṣẹ to bẹẹ ti kò ri aye lati tọ awọn ọmọ rè̩ bi o ti yẹ, ẹjọ ta ni yoo jẹ bi wọn ba ya eniyan buburu ti wọn si padanu ẹmi wọn ni ọrun-apaadi? Nigba ti a ba bi ọmọ kan, Ọlọrun fi abojuto ẹmi kan ti ki i kú laelae si ọwọ awọn obi rè̩, ojuṣe ti O si n fẹ ki wọn ṣe ni lati kọ ọmọ naa bi o ti ṣe le ri igbala.
Ohun pataki ju lọ ni pe ki awọn obi ka Bibeli si etigbọ awọn ọmọ wọn ki wọn si ba wọn gbadura. Alabojuto iṣẹ ofin kan ti ọpọlọpọ eniyan mọ a maa sọ bayii pe: “Ẹbi ti o ba n gbadura pọ, a maa wà ni irẹpọ.”
Bi a ba gbe ile kan ró gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun, yoo jé̩ ile ti o layọ, ki yoo si si ohun ti yoo mu ikọsilẹ wá. Awọn ọmọ ti a bi ninu ile yii ti a si kọ lati gbọran si aṣẹ obi wọn ati si Ọrọ Ọlọrun, yoo ni anfaani daradara lati dagba bi ẹni ti o ṣe e gbẹkẹle, ọkunrin ati obinrin ti o yẹ lati bu ọlá fun.
Questions
AWỌN IBEERE- Awọn ta ni olukọ akọkọ ati pataki ju lọ fun awọn ọmọde?
- Ki ni ofin Ọlọrun nipa awọn ọmọde?
- Ki ni awọn nnkan ti o yẹ ki o fi si ero nipa ẹni ti o fẹ gbé ni iyawo?
- Titi di igbà wo ni ẹjẹ igbeyawo wà fun?
- Sọ diẹ ninu awọn iṣẹ ọkọ.
- Sọ diẹ ninu awọn iṣẹ aya.