Matteu 5:23, 24, 43-48; 18:15, 21, 22; Marku 11:23-26; Romu 12:9, 10, 14, 17, 19-21

Lesson 272 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi ẹnyin kò ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun kì yio si dari è̩ṣẹ nyin ji nyin” (Marku 11:26).
Notes

Fifé̩ awọn Ọta Wa

A mu ẹkọ yii lati inu Iwaasu Jesu lori Oke. Ninu ohun ti Jesu sọ ni nipa ifẹ ati idariji ti o maa n wà ninu Onigbagbọ. Jesu kọ ni pe idariji a maa wà ninu Onigbagbọ. Nipa bayii a mọ pe ẹni ti kò ba ni idariji ninu ọkàn rè̩ ki i ṣe Onigbagbọ.

Awọn olukọni Ju sọ fun awọn eniyan lati fẹran ọmọnikeji wọn ki wọn si korira awọn ọta wọn. Iwa ti eniyan ni eyi, ṣugbọn o lodi si ọna ti Ọlọrun. Ninu iwe ti Majẹmu Laelae a kà pe: “Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bḝni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fé̩ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA” (Lefitiku 19:18). Awọn ara Kenaani kan wà ti wọn dèna awọn Ọmọ Israẹli ti wọn si gbiyanju lati fà wọn kuro lọdọ Ọlọrun. Nipa ti awọn wọnyii gan an ni Ọlọrun sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe wọn “kò gbọdọ wá alafia wọn tabi ire wọn” (Deuteronomi 23:6). Boya nitori ọrọ bayii ni awọn olukọni Ju fi ni ero pe ki wọn korira gbogbo awọn ọta wọn.

Jesu kọ ni pe awọn ti wọn jé̩ ọmọ Ọlọrun – ani awọn Onigbagbọ tootọ -- a maa ni ifẹ si awọn ọta wọn. Onigbagbọ kò ni ifẹ si è̩ṣẹ ati ọna ibi (Orin Dafidi 97:10), ṣugbọn o ni ifẹ si ọkàn awọn eniyan, ati awọn ota rè̩ pẹlu. Jesu wi pe, “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; ki ẹnyin ki o le mā jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun” (Matteu 5:44, 45).

A kọ fun wa lati ṣe awọn ti a le kà si ọta wa ni ibi kankan. Lati inu iwe ti Paulu kọ si awọn ara Romu ni a ti kà bayii: “Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni” (Romu 12:17). Si awọn ara Tẹssalonika ni Paulu kọwe pe, “Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mā lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, larin ara nyin, ati larin gbogbo enia: (1Tẹssalonika 5:15). Ki i ṣe ti wa lati jẹ awọn eniyan niya fun iwa buburu wọn. Ọlọrun ni yoo ṣe idajọ gbogbo eniyan ti yoo si diwọn ẹsan ti o tọ fun olukuluku. “Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi ó gbẹsan” (Romu 12:19). Ni ibomiiran Oluwa tun sọ wi pe, “Ti emi ni igbẹsan, ati ẹsan, li akokò ti ẹsè̩ wọn yio yọ: nitoriti ọjọ idamu wọn sunmọtosi, ohun ti o si mbọ wa bá wọn nyára wá” (Deuteronomi 32:35).

Fifi Ire San Ibi

Jesu kọ ni pe o yẹ ki awọn Onigbagbọ maa fi oore san ibi (Luku 6:27). Ẹmi ti wọn ki i ṣe iru eyi ti n fi ibi san ibi. Awọn ẹlẹṣẹ ti o buru ju le fẹran awọn ti wọn fẹran wọn. Eyi ki i ṣe ohun ajeji tabi ohun ti o ya ni lẹnu rara. Lati tẹle apẹẹrẹ Oluwa, Onigbagbọ ni lati ṣe ju bi awọn iyoku ti ṣe – yoo fẹran awọn ti wọn korira rè̩ yoo si fi ire san ibi. Eyi ni Oluwa n fẹ ki awọn ọmọde Onigbagbọ ati awọn agba Onigbagbọ ṣe.

Boya laaarin awọn ẹgbẹ rẹ ni ile-iwe tabi laaarin awọn ọmọde ti n gbe ni adugbo rẹ, a ri ọmọ kan ti o n ṣe ikà si ọ ti o si n fi eke sọrọ rẹ ni buburu. Bawo ni o ṣe le ṣe oore fun un dipo iwa buburu ti o ti hu si ọ? O le gbadura fun un – Jesu gbadura pe ki Ọlọrun dariji awọn ti wọn tilẹ kan An mọ agbelebu (Luku 23:34). O le ṣe oore fun ẹni ti o ṣe alai ni. O le fi ifẹ rẹ hàn si i nipa sisọ nipa ohun rere miiran ti o maa n ṣe, ati nipa yiyan an ṣe ẹnikeji rẹ nigba ti o ba n ṣire.

O le dabi ẹni pe o ṣoro lati fi oore san iwa buburu ti a hu si ọ, ṣugbọn ohun ti iwọ o fẹ lati ṣe ni ti ifẹ Ọlọrun ba n gbe inu ọkàn rẹ. Bi o ba ri i pe o ṣoro fun ọ lati fẹran ọta rẹ, gbadura pe ki Ọlọrun fun ọ ni oore-ọfẹ lati fi ire san ibi.

Nipa ṣiṣoore fun awọn ti wọn ṣe ikà si ọ, idalẹbi yoo wọ ọkàn wọn lọ, oju ara wọn yoo si tì wọn. O le sọ wọn di ọrẹ rẹ, o si le jere wọn fun Oluwa. A kọ wa pe, “Bi ebi ba npa ọta rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba ngbẹ ẹ, fun u li omi mu: ni ṣiṣe bḝ iwọ ó kó ẹyin ina le e li ori” (Romu 12:20).

Ifẹ Laaarin Awọn Onigbagbọ

Ohun ti o ṣe iyebiye pupọ ni Jesu kà ifẹ si laaarin awọn ọmọ- lẹyin Rè̩. Ni akoko kan, Jesu wi pe, “Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin” (Johannu 15:12). Ifẹni yii laaarin awọn Onigbagbọ, jé̩ ohun iyanu. Oun ni o n so awọn ọmọ Oluwa papọ. O ṣe dandan fun eniyan lati ri pe oun pa ifẹ fun awọn eniyan Ọlọrun mọ ninu ọkàn rè̩. Eniyan gbọdọ ṣọra gidigidi ki ohunkohun má ṣe jé̩ ikọsẹ laaarin oun ati ẹlomiiran. Nigba miiran o maa n gbà pe ki eniyan ni ọkàn ti o rẹlẹ ati inu ti o tutu lọpọlọpọ ki o ba le pa ifẹ otitọ yii mọ.

Bi Satani ba le fi èdè-aiyede kan si aarin iwọ ati ọkan ninu awọn eniyan Ọlọrun, iṣẹgun nla ni eyi jé̩ fun un. O ṣanfaani ki o tete lọ ba arakunrin tabi arabinrin naa ninu Ihinrere lati ṣe ilaja, ki Satani ba le tete sa kuro, ki ifẹ Onigbagbọ ba le mu ọ sun mọ awọn eniyan Ọlọrun si i.

Ilaja

Jesu mọ pe Satani yoo gbiyanju lati mu iyapa wa saarin awọn ọmọ Oluwa nipa mimu ede aiyede ati ohun ikọsẹ wa si aarin wọn. Jesu jẹ ki a mọ ohun ti o yẹ ki a ṣe ti a o fi bori awọn nnkan bayii: “Nitorina bi iwọ ba nmu è̩bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ; fi è̩bun rẹ silẹ nibè̩ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn è̩bun rẹ” (Matteu 5:23, 24).

Nigba ti o ba n gbadura, bi o ba wá sinu ọkàn rẹ pe arakunrin kan ni ohun kan ninu si ọ, lọ ba oluwarè̩, yanju ọrọ naa pẹlu rè̩, ki o si ba a laja ki o to pada wá sibi pẹpẹ lati ru ẹbọ iyin ati ifararubọ fun Ọlọrun. Nigba ti ẹni kan kò ba ni ifẹ si ẹnikeji rè̩ ninu ọkàn rè̩, Oluwa kò ni inudidun si ẹsìn ti òde ara. O ju Onigbagbọ kan ṣoṣo lọ ti o ti fi pẹpẹ silẹ, ti o lọ ba ọkan ninu awọn arakunrin laja lori aṣiṣe kan, ti o si ti pada wá gba ibukun lọdọ Oluwa.

S̩akiyesi pe ninu ẹkọ Jesu a kò sọ fun ni ẹni ti o jẹbi tabi bi ọran naa ti wuwo to. Yala iwọ ni o jẹbi tabi ẹnikeji ni, yala ọran naa wuwo ni tabi o dàbi ẹni pe kò ni laari, bi o ba jé̩ pe ède-aiyede ni o wà, bi kò ba tilẹ si ẹnikẹni ti o jẹbi, ofin kan naa ni Oluwa fi fun ni lati tẹle.

Ẹri-ọkàn Rere

Oriṣiriṣi nnkan ni o le fa ikunsinu laaarin awọn ọmọ Ọlọrun. Nigba pupọ o le jẹ ède-aiyede – ti ẹni kan ṣi ẹni keji gbọ nigba ti a kò gbero ibi si i rara -- ṣugbọn o ri ohun ti o fara jọ ibi ti o le pa oun lara ti o si le bi i ninu. Nigba miiran o le jẹ idaji ohun ti o ṣẹlẹ ni ẹni keji gbọ, nigba ti o si gbọ gbogbo ohun ti o ṣẹlẹ, ọran naa wa yatọ patapata, o wa ri i pe kò si idi rara lati binu.

Nigba miiran eeṣi le ṣẹlẹ, yala nipa àjálù tabi aikiyesara. Njẹ o ti i ṣeeṣi fọ digi ferese kan ri? Lai ṣe aniani Satani gbiyanju lati ni ki o sa lọ tabi lati wi pe ẹlomiiran ni o ṣe e. Bi o ba lọ ba ẹni ti o ni in ti o jẹwọ fun un ti o si sanwo ferese ti o bajẹ, iwọ mọ bi ọkàn rẹ ti balẹ to pe ẹri-ọkàn rẹ mọ niwaju awọn ẹlomiiran bi o tilẹ jé̩ pe o dùn ọ pe o fọ digi onidigi. Bi o ba jẹ pe n ṣe ni o gbiyanju lati fara pamọ, iwọ yoo ranti bi idalẹbi ti kún ọkàn rẹ, ti ara rẹ kò si balẹ, ti ẹru si n ba ọ pe wọn le mu ọ. Kò ha sàn lati ṣe ohun ti o tọ ki o si ni ẹri-ọkàn ti o mọ gaara niwaju Ọlọrun ati awọn eniyan ẹlẹgbẹ rẹ?

Nipa ọgbọn àrekérekè, nipa ẹtan, tabi nipa idanwo, o ṣe e ṣe ki Satani mu ọ ṣe ohun ti kò tọ, paapaa bi o kò ba ti n gbadura pupọ. Ni iru akoko bẹẹ o le pa arakunrin kan lara nipa titẹti si Satani. Boya lai tilẹ mọ idi rè̩, tabi lai mọ bi ọran naa ti wuwo to, tabi lai ronu, tabi lai mọọmọ ṣe e, o ṣe aṣiṣe kan ti o pa ẹni kan lara. Iru nnkan bayii maa n ṣẹlẹ. O le dùn wa pe iru nnkan bẹẹ ti ṣẹlẹ, ṣugbọn o yẹ ki a ṣe atunṣe lẹsẹkẹsẹ dipo ki a jẹ ki wọn maa tabuku si ifẹ wa ati igbesi-aye wa gẹgẹ bi Onigbagbọ.

A kò gbọdọ gbagbe ohun ti Bibeli sọ ti a si kọ ninu Ẹkọ 269 nipa atunṣe. Ki a ba le pa ifẹ Onigbagbọ ni mọ ninu ọkàn wa ki a si le maa jẹ ọkan ninu awọn ẹbi Ọlọrun, a ni lati rè̩ ara wa silẹ bi a ba ṣè̩, ki a jẹwọ ikuna wa, ki a tọrọ idariji lọwọ ẹni ti a ṣè̩, ki a ṣe atunṣe, ki a si ṣe ohun ti yoo mu ki è̩ṣẹ naa tan.

Awọn ẹlomiiran ṣetan lati jẹwọ ikuna wọn fun Ọlọrun, ati lati bẹbẹ fun idariji Rè̩; ṣugbọn Bibeli kọ ni pe eniyan ni lati bá eniyan ẹlẹgbẹ rè̩ laja pẹlu. Ọna eniyan kò i ti i tọ niwaju Ọlọrun niwọn igba ti oluwarè̩ kò ba tilẹ gbiyanju rara lati mu ọna rè̩ tọ lọdọ eniyan. Kò yẹ ki eniyan maa fi akoko dá ọla lati ṣe atunṣe nitori pe titi oun yoo fi ṣe e oun kò le ri ojurere Ọlọrun ni kikún. Jesu le de ba a nibi ti o ti n fi akoko dá ọla. Njẹ o ro pe iru ẹni bẹẹ yoo le wà ni imura silẹ lati pade Oluwa?

Ẹmi Idariji

Ki ni yẹ ki eniyan ṣe bi o ba jẹ pe oun ni a ṣè̩ ti a si palara? Njẹ o yẹ ki o maa ṣofofo kaakiri nipa sisọ pe ẹni kan ti ṣe láifi si oun, ki o si maa pariwo nnkan ti a ṣe si i kaakiri? Bibeli kọ wa pe ki a lọ ba ẹni ti o ti ṣè̩ wa, ki a si sọ ikuna rè̩ fun un, ki a si gbiyanju lati ṣe ilaja. Bi ọran naa kò ba yanju a le pe ẹlẹri kan lati dá si ọrọ naa ki o le yanju (Ka Matteu 18:15-17). O ti dara to lati tẹle awọn ẹkọ Oluwa, dipo ki a jẹ ki ija maa tàn kalẹ laaarin awọn arakunrin!

Ni Iye Igba Ailonka

Ni akoko kan Peteru bi Oluwa leere iye igba ti oun ni lati maa dariji arakunrin rè̩ ti o ba ṣẹ ẹ. Peteru ro pe nnkan ribiribi ni lati dariji eniyan lẹrinmeje ọtọọtọ, ṣugbọn ẹrinmeje laaarin igbesi-aye eniyan tabi laaarin ọjọ kan paapaa kò tó. Jesu dahun wi pe, “Titi di igba ādọrin meje” (Matteu 18:21, 22). Ki ni n jẹ aadọrin meje? Igba ẹẹdẹgbẹta o din mẹwaa (490) ni. Dajudaju o gbà pe ki eniyan ni ifẹ Ọlọrun ati ọpọlọpọ suuru ninu ọkàn rè̩ ki o le maa dariji nigba ti ẹni kan naa ba ṣẹ ẹ ni iye igba ti o pọ to bayii. Ohun ti Oluwa n reti ni pe ki a dariji; O pa a laṣe ni; O si n fun Onigbagbọ ni agbara ati oore-ọfẹ lati ni iru ifẹ ati ẹmi idariji bayii ninu ọkàn rè̩. Itumọ ọrọ Jesu ni pe kò si opin si ati maa dariji fun Onigbagbọ.

Gẹgẹ bi Awa ti n fi È̩ṣẹ Awọn Eniyan Ji

Nnkan ribiribi ni ẹmi idariji jẹ, ṣugbọn bẹẹ si ni o tun jẹ ọranyan pẹlu. Ipo ti o lewu ni awọn ti wọn n wi pe awọn kò le dariji ẹlomiiran lae wà. Bi awọn ti wọn n gba adura Oluwa ti n sọ ni pe (Matteu 6:9-13) “Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndariji awọn onigbese wa.” Gẹgẹ bi wọn ti n dariji ni wọn n gbadura pe ki a maa dariji awọn naa. Nigba ti wọn kò ba dariji ẹlomiiran, wọn kò le reti pe ki Ọlọrun dariji wọn. “Bi ẹnyin ko ba dariji, Baba nyin ti mbẹ li ọrun ki yio si dari è̩ṣẹ nyin ji nyin” (Marku 11:26).

Bi ẹ ba n fẹ ki Oluwa gbọ adura yin ki O si dahun, ẹ ni lati “dariji, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni” (Marku 11:25). O yẹ ki a fiyesi pe Jesu kò wi pe kiki igba ti wọn ba bè̩bè̩ pe ki a dariji wọn nikan ni ki a dariji. Ẹmi idariji wà ninu ọkàn Onigbagbọ tootọ yala ẹni ti o ṣẹ tọrọ idariji tabi kò tọrọ. Igbala wa le duro lori bi a ti n dariji awọn ẹlomiiran.

Kò si bi è̩ṣẹ naa ti le buru to, ani ki o tilẹ jẹ pe ẹmi eniyan kan ba a lọ tabi apa rè̩ ni o ge, tabi pipadanu eniyan kan ninu ẹbi wa tabi ohun ini wa, tabi orukọ rere wa ni ẹni kan bajẹ tabi ilera wa ni o mu ipalara ba – ohunkohun ti o wu ki o jẹ -- a ni lati dariji ni bi a ba n reti aanu lati ọdọ Ọlọrun. Lori ẹkọ yii o yẹ ki a ka iwe pẹlẹbẹ kan ti akọle rè̩ jẹ, “Fun È̩ṣẹ Ẹlomiran,” eyi ti Igbagbọ Apọsteli (The Apostolic Faith) tè̩ jade.

Lati Dariji ati Lati Gbagbe

Ki ni itumọ idariji? Lati dariji ni lati dá silẹ ati lati mú kuro lọkàn. Lara idariji ni gbigbagbe wà. Lati dariji ni lati gbagbe. Kò si oṣuwọn fun idariji. A kò le dariji eniyan ni aabọ tabi ki a dariji i niwọn diẹ. A o ṣe bakan ni tabi bamiiran – ninu ki a dariji eniyan tọkàntọkàn tabi ki a má dariji rara.

Nigba ti Oluwa ba dariji, Oun ki i ranti è̩ṣe naa mọ (Heberu 8:12; 10:17; Jeremiah 31:34). “Bi ila-õrun ti jina si iwọ-õrun,” bẹẹli O maa n mu irekọja wa jinna si wa (Orin Dafidi 103:12). Bi ìyọnú Rè̩ ti pọ to, n ṣe ni O maa n sọ gbogbo “è̩ṣẹ wa sinu ọgbun okun” (Mika 7:19). Hẹsekiah sọrọ nipa Oluwa pe, “Iwọ ti gbe gbogbo è̩ṣẹ mi si è̩hin rẹ” (Isaiah 38:17). Bibeli sọ fun wa pe “bi Kristi ti dariji nyin, gẹgẹ bḝni ki ẹnyin ki o mā ṣe pẹlu” (Kolosse 3:13). Nigba ti eniyan ba dariji ni tootọ, ki i ṣe ẹnu nikan ni yoo fi dariji, ṣugbọn lati inu ọkàn ati nipa iṣe rè̩ pẹlu. Yoo dariji lati inu odo ọkàn rè̩ wá pẹlu ifẹ Onigbagbọ tootọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Onigbagbọ ti n ṣe si ọta rè̩?
  2. Ta ni ọta ti rẹ?
  3. Ta ni i ṣe ẹnikeji rẹ?
  4. Ki ni Onigbagbọ fi n san ibi ti a ṣe si i?
  5. Ki ni itumọ “kikó ẹyin ina le e li ori”?
  6. Aṣẹ wo ni Jesu pa fun awọn ọmọ-lẹyin Rè̩ ninu Johannu 15:12?
  7. Bi ẹni kan ba ni ohun kan ninu si ọ, ki ni Jesu wi pe ki o ṣe?
  8. Ki ni yoo ṣẹlẹ bi o ba kọ lati dariji ẹlomiiran?
  9. Ki ni maa n ṣẹlẹ si awọn è̩ṣẹ wa nigba ti Jesu ba dariji wa?
  10. Bawo ni iwọ o ti ṣe mọ nigba ti a ba dariji ọ ni tootọ?