Matteu 28:18-20; Filippi 3:7-21; Efesu 6:10-18; 1Timoteu 4:13; 2Timoteu 3:1-5; 4:1-8; 2Kọrinti 4:16-18; 5:1-4

Lesson 273 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “S̩e alabapin pẹlu mi ninu ipọnju, bi ọmọ-ogun rere Jesu Kristi” (2Timoteu 2:3).
Notes

Awọn Ọmọ-ogun Rere ati Ihamọra Wọn

Paulu Apọsteli fi igbesi-aye Onigbagbọ wé ogun jija tabi ija. Agbara eṣu le ninu aye, Oluwa si n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ jẹ alagbara ki wọn si ni igboya lati doju ija kọ ọ. O n fẹ ki awọn ọmọ Rè̩ jẹ ọmọ-ogun rere.

Ki Oun ba le ràn wa lọwọ lati ṣẹgun ọta yii, Oluwa fun wa ni ihamọra. Paulu wi pe, “Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro” (Efesu 6:13). A maa n fun ọmọ-ogun ti ẹgbẹ-ogun aye yii ni ihamọra aṣọ ti o ba oju ọjọ ilẹ ibi ti yoo ti lọ ja mu; a o fun un ni ibọn ati ohun-ija ti a n fi ọwọ sọ lati fi daabo bo ara rè̩, aṣibori irin-didà fun aabo, igo omi ati è̩tọ ti rè̩ ninu ounjẹ ati omi fun akoko ti o ba wà loju ogun; lẹyin eyi ni a o rán an lati lọ pade ọta.

Ohun ti a kò le fi oju ri ni ihamọra Onigbagbọ jẹ, ṣugbọn a le mọ pe o ni in nipa igbesi-aye ti o n gbe. Ẹmi Ọlọrun, otitọ, ododo, ati igbala jẹ apa kan ninu ihamọra rè̩.

Paulu fi ọmọ-ogun yii we ọmọ-ogun igbà laelae ti o mu idà ati apata lọwọ. O wi pe igbagbọ ni apata wa, Ẹmi Ọlọrun ni idà wa, ododo ni igbàyà wa, otitọ ni amure wa, imura Ihinrere si ni bata wa.

Wiwa ni Ojúfò

Gbigbe gbogbo ihamọra wọnni wọ ki i ṣe opin ohun ti Onigbagbọ ni lati ṣe lati ja ogun rè̩ ni ajaṣẹgun. O ni lati maa gbadura ki o si maa ṣọna. Satani kún fun ọgbọn arekereke lọpọlọpọ, o si n sa gbogbo ipa rè̩ lati pa ọmọ-ogun rere run. Ọna kan ṣoṣo ti a le gba fi ṣẹgun rè̩ ni lati wà ni ojúfo, ki a si mura silẹ lati kọju ija si i pẹlu Ọrọ Ọlọrun nigba kuugba ti o ba ran ohun ìjà rè̩ bi iná jade nipa iyemeji, aigbagbọ, ariwisi, tabi fifa ọkàn si è̩ṣẹ.

Satani gbe Jesu lọ sori oke giga nigba kan lati dan An wò. O n fẹ ki Jesu foribalẹ ki O si sin oun. Njẹ ki ni o rò nipa igbojugboya bẹẹ? S̩ugbọn Jesu mọ bi Oun yoo ti ṣe ṣẹgun rè̩. O fi Ọrọ Iwe Mimọ da a lohun – Satani si fi I silẹ. A le ṣe ohun ti Jesu ṣe yii bẹẹ gẹgẹ. Bi a ba ṣaapọn lati fara balẹ ka Ọrọ Ọlọrun ti a si gba gbogbo rè̩ gbọ, a o mọ ọrọ ti o yẹ lati fi dahun nigba kuugba ti a ba gbọ ọrọ èké kan nipa Bibeli, tabi ti a ba gbọ ẹkọ kan ti o lodi si eyi ti Jesu kọ ni.

Kikọni ni Ohun Gbogbo

Lara awọn ọrọ ikẹyin Jesu si awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ki O to lọ si Ọrun niyii: “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ: ki ẹ ma kọ wọn lati ma kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa li aṣẹ fun nyin” (Matteu 28:19, 20). Jesu n jẹ ki o di mimọ fun wọn pe o ṣe pataki fun wọn lati kọ awọn eniyan ni ohun gbogbo ti Oun ti kọ wọn.

Awọn miiran ro pe awọn kan ninu ẹkọ Bibeli kò ṣe pataki, wọn a si maa sọrọ nipa kiki eyi ti wọn gba pe o ṣe pataki. Awọn ẹlomiiran ni ero ti o yatọ nipa ohun ti o ṣe pataki. S̩ugbọn ọmọ-ogun alagbara ni ẹni ti o gba gbogbo ẹkọ Oluwa pe wọn ṣe pataki; a si maa gbe igbesi-aye rè̩ gẹgẹ bi awọn ẹkọ naa.

Arekérekè Èṣu

Ija laaarin rere ati buburu ti bẹrẹ lati igba nì ninu Ọgba Edẹni. Satani fi ọgbọn arekereke ṣẹgun ija rè̩ akọkọ pẹlu Adamu ati Efa. Kò lo ibọn tabi afẹfẹ olóró tabi agbara è̩ṣé̩. Ọrọ ẹnu ni o fi ṣẹgun. Ọrọ ni o fi tan awọn obi wa akọkọ jẹ.

A le gba ikilọ nipa eyii ki a si ṣọra nipa ohun ti a n tẹti wa silẹ lati gbọ. Satani ti ni irírí ẹgbaa mẹta (6,000) ọdun sii lati igba naa, o si ti kọ ọpọlọpọ arekereke sii. Nitori na Onigbagbọ ni lati maa wà ni iṣọra nigba gbogbo ki a má baa fi ikẹkun mu un lọ si ọna è̩ṣẹ.

Ifẹ è̩ṣẹ ati ọrọ aye yii a maa tan ọpọlọpọ lọ sinu àgọ ọtá. S̩ugbọn awọn miiran wà ti kò bikita nipa iru nnkan wọn ọn ni; nitori naa eṣu a tun wa ọna miiran lati tan wọn jẹ. Oun a maa rán awọn woli eke lati fara hàn bi awọn iranṣẹ Ọlọrun. Awọn miiran a maa gba eke ti a sọ fun wọn gbọ nitori pe wọn kò ni ifẹ otitọ. Wọn n fẹ lati pa awọn è̩ṣẹ kan mọ ninu ọkàn wọn.

Paulu pade awọn olukọni eke kan, o si pe wọn ni “awọn ẹniti nṣiṣẹ è̩tan.” S̩ugbọn o ni ki i si i ṣe ohun iyanu pe iru awọn eniyan bayii wà, nitori Satani tikara rè̩ n pa ara rè̩ dà di angẹli imọlẹ. “Nitorina ki iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rè̩ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn” (2Kọrinti 11:13-15).

Iwa Buburu ni Ibi Giga

Awọn miiran ninu awọn olukọ eke yii, awọn ohun-elo ti Satani n lò tilẹ mọọmọ dide pẹlu ipinnu lati ṣiṣẹ fun iṣubu eniyan. Wọn a lọ si ile-ẹkọ ti o jẹ ti awọn ẹlẹsin Kristi, wọn a si dara pọ mọ awọn akẹkọọ ti o ni ipinnu rere, wọn a fara hàn bi ẹni pe wọn fẹran Oluwa ni gbogbo akoko naa. Lẹyin ti a ba fi aṣẹ fun wọn lati lọ waasu, wọn a lọ sinu awọn ile-isin ni ilẹ wa wọn a si gun ori aga iwaasu lati maa tan ẹkọ buburu kalẹ lati yi ọkàn awọn eniyan pada si buburu.

S̩ugbọn awọn iranṣẹ Satani miiran wà ti a ti tàn jẹ, boya ti kò mọ pe awọn ti “lọ kuro ninu igbagbọ.” O le jẹ pe wọn ti mọ Oluwa nigba kan ri wọn si ti fi tọkantọkan ṣe iṣẹ-isin Rè̩; ṣugbọn nipa fifa sẹyin ninu adura gbigba ati kika Bibeli, wọn ti sọ Ẹmi Ọlọrun nù. Ni ọna diẹdiẹ, wọn ti yà kuro ninu awon ẹkọ Ọrọ Ọlọrun. Ifẹ wọn ti fà si awọn nnkan aye yii, wọn si ti jẹ ki ifẹ ohun aye yii wọ inu ọkàn wọn. Dipo ti wọn i ba fi maa kọ awọn eniyan ni gbogbo aṣẹ Jesu, awọn nnkan ti ijọ wọn n fẹ lati gbọ nikan ni wọn n kọ wọn. Ọpọlọpọ ijọ ni o n sọ bi awọn Ọmọ Israẹli ti sọ ni igba aye Isaiah: “Má sọtẹlẹ ohun ti o tọ fun wa, sọ nkan didùn fun wa, sọ asọtẹlẹ itanjẹ” (Isaiah 30:10). Wọn le ṣe alai sọ ọ ni ọrọ ẹnu wọn, ṣugbọn wọn a maa wi pe ki awọn oniwaasu gbà wọn laaye nipa è̩ṣẹ ti o wà ninu aye wọn, ni ọna bẹẹ ohun kan naa ni wọn n sọ.

Biba È̩ṣẹ Jagun

Iṣẹ Ijọ tootọ, Ijọ Ajagun, ni lati kọju ija si è̩ṣẹ nibikibi ti o ba gbe wà. Ọna ti a le gbà ṣe eyi ni aṣeyọri ni lati kọkọ ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn wa, lẹyin eyi ki a ni isọdimimọ, ki a si gba agbara Ẹmi Mimọ eyi ti o n fun ni ni Ida ti Ẹmi.

Nigba ti a ba ti ni ihamọra wọnyii, a ni lati maa ṣe ifararubọ aye wa fun iṣẹ-isin -- ifararubọ ti o jinlẹ ti o gbà wa ni ohun kan. Gbogbo agbara Satani ni o fi n ja, Ijọ Ajagun si ni lati fi gbogbo ọkàn ja bẹẹ bi o ba n fẹ lati bori.

Awọn miiran a maa kọ awọn eniyan pe ki i ṣe ọranyan tabi pe kò ṣe e ṣe lati gbe igbesi-aye ailẹṣè̩. Dajudaju gbigbe igbesi-aye ailẹṣẹ ni ipilẹ iriri wa gẹgẹ bi Onigbagbọ! Bi a kò ba gbà wa là kuro ninu è̩ṣẹ wa, a kò yatọ si awọn ẹlẹṣẹ iyoku. “Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o tàn nyin; ẹniti o ba nṣe ododo, o jasi olododo, gẹgẹ bi on ti iṣe olododo. Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni” (1Johannu 3:7, 8). Nitori naa ki i ṣe ohun ti o ṣoro lati mọ bi a ba jé̩ Ọmọ Ọlọrun tabi bẹẹ kọ.

Fifasẹyin

Awọn miiran wà ti wọn gbà pe eniyan ni lati di atunbi ki o si mọ pe a ti dari è̩ṣẹ oun ji, ṣugbọn wọn kọ lati gbagbọ pe a le sọ eniyan di mimọ ki o si maa gbe igbesi-aye iwa-mimọ. “Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin.” “Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwaẽri, ṣugbọn fun ìwamimọ” (1Tẹssalonika 4:3, 7). Awọn miiran n jiyan pe wiwà ni mimọ ati yiya ara ẹni sọtọ ti ara ni eyi n sọ nipa rè̩. S̩ugbọn o jinlẹ ju eyii lọ. Paulu tè̩ siwaju ninu akọsilẹ rè̩ si awọn ara Tẹssalonika bayii “Ki Ọlọrun alafia tikararè̩ ki o sọ nyin di mimọ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ patapata li ailabukù ni ìgbà wíwa Oluwa wa Jesu Kristi” (1Tẹssalonika 5:23).

Awọn ẹlomiiran wà ti wọn n waasu iwa-mimọ, wọn n tẹnu mọ ọn pe o ṣe pataki lati gbe igbesi-aye aileeri, ṣugbọn wọn fa sẹyin kuro ninu fifi Ẹmi Mimọ wọ-ni. Jesu wi pe: “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Ọlọrun n fẹ ki awọn ẹlẹri Oun ni agbara lati sọ ìtan Jesu, ki Ẹmi Ọlọrun ba le fi ọwọ tọ ọkàn awọn eniyan.

Awọn iranṣẹ Ọlọrun miiran mọ pe awọn ṣe alai ni agbara yii, wọn si n fẹ ṣe ju bẹẹ lọ fun Oluwa, ṣugbọn wọṅ ki yoo wá orisun agbara yii. Olukuluku ẹni ti a ti gbàla ti a ti sọ di mimọ, lati ẹni ti o kere ju lọ titi de ẹni ti o dagba ju lọ, ni o le ri agbara yii gba bi o ba le ṣe ifararubọ aye rè̩ ni kikún fun Oluwa. Ọlọrun ṣeleri nipasẹ Woli Joẹli pe, “Emi o tú ẹmi mi jade si ara enia gbogbo” (Joẹli 2:28). Eyi yii ni ifi Ẹmi Mimọ wọ ni ti o n kún inu aye awọn ti a ti sọ di mimọ nipasẹ Ẹjẹ Jesu nigba ti wọn ri isọdimimọ.

Ọkàn Kristi

Nigba ti Paulu Apọsteli n kọwe si awọn ara Filippi o ni: “Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu: ... (ẹniti) o rè̩ ara rè̩ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú” (Filippi 2:5, 8). Ijà wa le jẹ eyi ti yoo yọri si ikú. A ha mura tan lati ṣe eyi fun Oluwa wa? Ninu ija ti awọn ara Korea gbe ti akoso alohun-gbogbo-ṣọkan, ọpọlọpọ ni awọn Onigbagbọ ti wọn fi igbagbọ wọn ninu Kristi hàn nipa fifi ẹmi wọn lelẹ dipo pe ki wọn sẹ Olugbala wọn. Ọlọrun rii pe Oun le gbẹkẹle awọn eniyan wọnyii, awọn ti kò ka ẹmi wọn si ohun ti o ṣọwọn fun wọn titi dé ikú.

S̩ugbọn nigba miiran o maa n jẹ ohun ti o ṣoro lati wà ni aaye fun Jesu ju lati kú fun Un lọ. Awọn ẹlomiiran wà ti wọn le jade gbangba ki wọn si fi gbogbo rè̩ lelẹ lẹẹkan giri ninu itara gbigbona tabi ipenija; ṣugbọn bi o ba jẹ pe wọn ni lati maa gbé, lati ọdun de ọdun, ki wọn si maa fi awon itẹlọrun nnkan ayé du ara wọn lati le jẹ agbatẹru Ihinrere yii, wọn le fa sẹyin kuro ninu isẹra-ẹni yii. Ki Oluwa ran wa lọwọ lojoojumọ lati gbe agbelebu wa ki a si tẹle Jesu, ki a si gbagbe ifẹ ti wa ati igbadun wa nitori ti Rè̩!

Paulu wi pe: “S̩ugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi. Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbé̩ (pantiri) ki emi ki o le jère Kristi” (Filippi 3:7, 8).

Paulu sọ idi rè̩ ti oun fi ṣe ifararubọ yii: “Ki emi ki o le mọ ọ, ati agbara ajinde rè̩, ati alabapin ninu ìya rè̩, nigbati mo ba faramọ ịkú rè̩; bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú” (Filippi 3:10, 11). Eniyan yoo wa laaye titi ayeraye yala ni Ọrun tabi ni ọrun apaadi. Paulu n fẹ lati jiya ohun gbogbo ni aye yii ki o ba le de ibi ajinde kin-in-ni, ki o ba le wa laaye ki o si ba Jesu jọba titi laelae.

Ireti kan naa ni awọn Onigbagbọ ilẹ Korea wọnni ni ti wọn ṣe n fi ẹmi wọn lelẹ fun Kristi. Ni ajinde awọn oku wọn o jade wa lati ba Oluwa wọn gbe titi lae. Ki ni o jámọ bi ara ba ni lati jiya diẹ nihin yii? Bi ikuuku lasan ni igbesi-aye wa nihin yii jasi nigba ti a ba fi we ayeraye ọdun ailopin. Kiki ohun ti a ba ti ṣe fun Oluwa ni a o kà si nigba ti a ba duro niwaju Onidajọ gbogbo aye.

Jesu fi aye Rè̩ lelẹ fun wa ki a ba le ri igbala. Njẹ ohun iyanu ha kọ ni yoo ja si bi a ba le duro niwaju Rè̩ ki a si wi pe a ti fi aye wa fun Un ninu iṣẹ-isin ifararubọ? Lati jẹ ajẹriku paapaa, bi o ba gbà bẹẹ?

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ọmọ-ogun Onigbagbọ ni i ba jagun?
  2. Ki ni ihamọra Onigbagbọ?
  3. Ki ni aabo wa ti o daju lati dojukọ Satani?
  4. Meloo ninu awọn ẹkọ Kristi ni O sọ fun wa pe ki a fi kọ awọn eniyan?
  5. Sọ diẹ ninu awọn ọna ti Satani n gba fi tan awọn eniyan jẹ.
  6. Bawo ni a ti ṣe le sọ iyatọ laaarin Onigbagbọ ati ẹlẹṣè̩?
  7. Nitori ki ni Paulu ṣe n fẹ lati ṣofo ohun gbogbo?
  8. Ki ni Ọlọrun n reti lọwọ wa?