Lesson 274 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nwọn si ṣẹgun rè̩ nitori è̩jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọrọ ẹrí wọn” (Ifihan 12:11).Notes
Bibọ Jesu Lẹẹkeji
Bibeli sọrọ nipa bibọ Jesu lẹẹkeji, eyi ti o daju pe yoo ṣẹlẹ lai pẹ yii. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe Oun yoo fi wọn silẹ Oun yoo si lọ sọdọ Baba Oun. O wi pe: “Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:3). Jesu fi wọn silẹ ni tootọ. Awọn eniyan naa tẹju mọ Ọn bi O ti n lọ soke ti awọsanma si gbà A kuro ni oju wọn. Awọn ọkunrin meji ti a wọ ni aṣọ àla sọ fun wọn pe: “Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bḝ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si orun” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:11).
Ipalarada Ijọ
Bibọ Jesu yoo pin si ipa meji. Ninu ipa kin-in-ni ni Ipalarada Ijọ, eyi ti Bibeli pe ni “ajinde ekini” (Ifihan 20:5, 6). Ni akoko naa Ẹmi yoo mu awọn eniyan mimọ ti wọn wà laaye ati awọn ti wọn ti sun, apapọ awọn ti i ṣe Ijọ tootọ -- yoo si kó wọn lọ “lati pade Oluwa li oju ọrun” (1Tẹssalonika 4:17).
Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nipa awọn nnkan ti n bọ wa ṣẹlẹ nihin ninu aye. Wọn beere pe: “Nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? Kini yio si ṣe àmi wiwa rẹ ati ti opin aiye?” Jesu sọ fun wọn nipa ogun, iyan, ajakalẹ-arun, ati isẹlẹ ti yoo wà ni ibi pupọ. O sọ fun wọn pe awọn eniyan yoo maa korira ara wọn, wọn o maa tan ara wọn, wọn o maa ṣofofo ara wọn, wọn o maa sé̩ ara wọn, wọn o si maa pa ẹni keji wọn. O sọ fun wọn siwaju sii pe a o si “wasu Ihinrere ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède.” O wa fi kún un pe, “Nigbana li opin yio si de.”
Gbogbo nnkan wọnyii ni o ti ṣẹ. Gbogbo asọtẹlẹ nipa awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ ṣaaju bibọ Jesu lẹẹkeji ni o ti ṣẹ. Nigbakuugba ni Jesu lè de. Nitori naa ni a ṣe n kilọ fun wa pe o yẹ ki a mura silẹ fun bibọ Rè̩. A ki yoo gbọ ikede kankan pe ti o ba di akoko kan pato Jesu yoo gba Ijọ soke. Ojiji ni bibọ Jesu yoo jẹ -- “gẹgẹ bi manamana ti ikọ lati ila-õrun, ti isi mọlẹ de iwọ-õrun” (Matteu 24:27). Kò si ẹni kan ti o mọ wakati naa gan an ti Jesu yoo fara hàn, afi Ọlọrun Baba nikan (Matteu 24:36).
Ireti Onigbagbọ
Lati wà ni imurasilẹ de bibọ Jesu ni ireti olukuluku Onigbagbọ. Paulu kọwe si awọn Onigbagbọ ni Kọrinti pe bi o ba jẹ pe ni kiki aye yi nikan ni awa ni ireti ninu Kristi awa jasi “òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia.” S̩ugbọn Onigbagbọ ni ireti ninu Kristi ninu aye yii ati pẹlu ninu aye ti n bọ, nitori o gbà awọn ileri Ọlọrun gbọ. Ireti yii jẹ “idakọro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duro ṣinṣin” (Heberu 6:19). Ireti yii ni o mu ki Onigbagbọ wẹ ara rè̩ mọ, ani bi Kristi ti mọ (1Johannu 3:3).
Lati Wà Lọdọ Jesu
Ki ni ṣe ti awọn Onigbagbọ pọn bibọ Jesu lẹẹkeji le to bẹẹ? Ki ni ṣe ti wọn n foju sọna ti wọn si n duro de e? Awọn ti wọn ba ti ṣe tan fun bibọ Jesu yoo gbọ “ohùn olori awọn angẹli” ati “ipè Ọlọrun.” “Awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ jinde;” nigba naa ni a o si gba awọn ti wọn wà laaye “soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun” ati lati maa wa titi lae lọdọ Jesu (1Tẹssalonika 4:16, 17).
Melomeloo ni awọn ti wọn ti n poungbẹ lati ri oju Olurapada wọn! Melomeloo ni aayun Ọrun ti n yun! Anfaani ti awọn ti wọn ti mura silẹ fun Ajinde Kin-in-ni yoo ni yoo ju pe ki wọn kan kófiri Olugbala wọn, tabi ki wọn wò O fun saa diẹ, tabi ki wọn kan ba A pade! Laelae ni wọn o wà lọdọ Jesu. Wọn o dapọ pẹlu awọn ẹgbẹ akọrin ti n kọ hallelujah ni Ọrun lati wi pe, “Halleluiah; ti Oluwa Ọlọrun wa ni igbala, ati ọlá agbara” (Ifihan 19:1). Wọn o jẹ “alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mā jọba pẹlu rè̩ li ẹgbè̩run ọdún.” Ninu Ifihan 20:6 a kà pe, “Olubukun ati mimọ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na.”
Imurasilẹ
Ọrun jẹ ibi ti a pese silẹ (Johannu 14:2) fun awọn eniyan ti wọn ti mura tan (Ifihan 19:7). Jẹ ki a wo bi eniyan ti ṣe le mura silẹ fun Ọrun ki o si ṣe tan fun bibọ Oluwa. Bibeli sọ ọna naa fun wa, eyi ti o jẹ ọkan naa fun ọmọde ati agba. Bi eniyan ba fẹ di ti Oluwa, o ni lati jẹ ki Ẹjẹ Jesu wẹ è̩ṣẹ oun nù (Ifihan 7:14). Nigba ti eniyan ba ri igbala, Oluwa a maa fun un ni agbara lati maa wà lai dẹṣẹ (1Johannu 3:9). Nigba ti eniyan ba dẹṣẹ oun kii tun ṣe ọmọ Ọlọrun mọ. “Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni” (1Johannu 3:8), “ẹrú è̩ṣẹ” si ni (Johannu 8:34).
Eniyan ni lati duro ninu ifẹ Ọlọrun ki o si maa gbọran si Ọrọ Ọlọrun ki o ba le maa ṣe ọmọ-ẹyin Rè̩ (Johannu 8:31). “Ẹniti o ba foriti i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22). Bibeli kọ ni pe eniyan ni lati rin ninu imọlẹ ti Jesu tàn fun un (1Johannu 1:7). Imọlẹ ti o pọ ni awa ti a ti n ka awọn iwe Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi wọnyi ni. A ni imọlẹ nitori a ti gbọ nipa bi a ti n ri igbala (Romu 10:9), nipa ṣiṣe atunṣe (Ẹkọ 269), nipa bi o ti ṣe dandan pe ki a gbe igbesi-aye iwa-mimọ, aileeri ati ailabuku (1Peteru 1:15, 16; 2Peteru 3:11; Efesu 5:26, 27), ati nipa ileri baba, eyi ni fifi Ẹmi Mimọ wọ ni, eyi ti Jesu paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ẹyin Oun gbà (Iṣe Awọn Apọsteli 1:4, 5, 8).
Nigba ti eniyan ba n rin ninu gbogbo imọlẹ ti o ni, oun yoo mọ ninu ọkàn rè̩ pe oun wà ni imura-silẹ lati pade Oluwa. Oun yoo pa ara rè̩ mọ “lailabawọn kuro li aiyé” (Jakọbu 1:27). Oun yoo maa ṣọnà, yoo si maa reti bibọ Jesu lai pẹ (Titu 2:11-13). Iwọ ha ni òye pe o ti mura tan fun bibọ Oluwa? Bi kò ba jẹ bẹẹ, ki ni ṣe ti o kò gbadura ki o si wá Ọlọrun titi iwọ yoo fi mọ daju pe o ti ṣe tan fun ipalarada?
Awọn Aṣẹgun
Ki eniyan to le ṣe tan fun bibọ Jesu, o ni lati jé̩ aṣẹgun ni kikún. Ẹni ti o ṣẹgun ni kikún lori aye, ara, ati eṣu. “Eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ wa” (1Johannu 5:4). Abajọ ti a fi sọ fun wa lati maa “ja gidigidi fun igbagbọ ti a ti fi lé awọn enia mimọ lọwọ lẹkanṣoṣo” (Juda 3)! A ni iṣẹgun nipa igbagbọ wa ninu Jesu Kristi. Eniyan le jẹ aṣẹgun nipa igbagbọ, “nitori è̩jẹ Ọdọ-Agutan na,” ati nitori ọrọ ẹri wọn (Ifihan 12:11). Ka ileri ti a ṣe fun awọn ti o ba ṣẹgun ninu Ifihan 2:7, 11, 17, 26; 3:5, 12, 21. A pa gbogbo awọn ibukun wọnyii pọ ninu ileri kan yii: “Ẹniti o ba ṣẹgun ni yio jogún nkan wọnyi; emi o si mā jẹ Ọlọrun rè̩, on o si mā jẹ ọmọ mi” (Ifihan 21:7). Wo bi ọkàn wa ti kún to bi a ti n kà nipa awọn nnkan wọnni ti Ọlọrun ti pese silẹ fun awọn eniyan Rè̩! Bawo ni o ti yẹ to fun wa lati maa wá ọkàn wa ri, ki a si maa bẹru ki a má ba kuna ati “wọ inu isimi rè̩” (Heberu 4:1)!
O n Bọ bi Ọba
Apa kan ninu bibọ Jesu ni ifarahan Rè̩ ati Ipalarada Ijọ jẹ. Apa keji ṣẹlẹ nigba ti Oluwa ba pada wa bi Aṣẹgun, pẹlu “ẹgbẹgbārun awọn enia rè̩ mimọ” (Juda 14) lati jẹ “ỌBA AWỌN ỌBA ATI OLUWA AWỌN OLUWA” (Ifihan 19:16). A o gbọ ohun nla lati Ọrun wá, wi pe, “Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rè̩; on o si jọba lai ati lailai” (Ifihan 11:15).
Akoko yii ni “Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rè̩.” A o si kó gbogbo awọn orilẹ-ède jọ siwaju Rè̩. Oluwa yoo si ya wọn si ọtọ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti i yà “agutan rè̩ kuro ninu ewurẹ” (Matteu 25:31, 32). Awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ni agutan naa -- wọn fara balẹ, wọn ni suuru, wọn si wulo. Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ni ewurẹ -- alagidi, ọlọtè̩, alaiṣe-iṣakoso. Lootọ ni a ti fun wọn ni anfaani lati jọ maa gbe papọ nihin ninu aye, ṣugbọn ọjọ ti a o ṣe ipinya n bọ.
Awọn agutan yoo gbọ bi Ọba ti n wi pe, “Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pese silẹ fun nyin lati ọjọ iwa.” A o fun awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ni ogún, iṣura iyebiye ti a ti pese silẹ fun awọn eniyan Ọlọrun. Ki ni ṣe ti a fi fun wọn ni ere wọnyi? Wọn ṣe oloootọ wọn si gbọran. Iṣẹ wọn fi hàn pe wọn jẹ ẹni ti a ti gbala -- awọn ti a ti fi Ẹjẹ Jesu rà. Wọn sẹ ara wọn, wọn si fi ifẹ hàn fun awọn ẹlomiiran; ni orukọ Jesu ati fun ogo Rè̩ ni wọn si ṣe ohun ti wọn ṣe.
Ohun ti awọn alaiwa-bi-Ọlọrun yoo gbọ ni pe: “Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, ... niwọn bi ẹnyin kò ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin kò ṣe e fun mi.” A o jẹ awọn alaiwa-bi-Ọlọrun niya fun ohun ti wọn kuna lati ṣe. Igbesi-aye wọn yoo fi hàn pe wọn kò ni igbala, wọn kò si gbọran si Bibeli, ati pe ohun ti wọn ṣe, wọn kò ṣe e fun ogo Jesu. A o ran wọn leti akoko ti wọn kò jẹ ran awọn ẹlomiiran lọwọ nigba ti o jẹ pe o yẹ ki wọn ṣe bẹẹ. “Awọn wọnyi ni yio si kọja lọ sinu iya ainipẹkun: ṣugbọn awọn olõtọ si iye ainipẹkun.”
Olubori
Awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun yoo ni iye ainipẹkun nitori pe ikú, ti i ṣe “ọtá ikẹhin ti a ó parun,” ni a o “gbé mi ni iṣẹgun” (1Kọrinti 15:26, 54). Kristi yoo di Aṣẹgun lori gbogbo awọn ota Rè̩ (1Kọrinti 15:24, 25) – Satani (Ifihan 20:10), awọn ọmọ-ẹyin Satani (Ifihan 20:15), ati ikú ati ipo-okú (Ifihan 20:14). Nitori Kristi yoo jẹ Aṣẹgun ati Olubori, awọn eniyan Rè̩ -- eyi nì ni Ijọ-- yoo jẹ aṣẹgun pẹlu. “Ọpé̩ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi” (1Kọrinti 15:57).
Nigba naa ni igbala awọn Onigbagbọ yoo di kikún. Wọn o di aṣẹgun lori ikú, ipo-oku, ati iboji, nipa agbara Jesu. Awọn Onigbagbọ yoo ti ṣẹ ogun wọn ikẹyin. A kò ni tun dan wọn wò lati dẹṣẹ mọ! Wọn kò tun ni ba Satani jijakadi mọ! Wọn kò tun ni mọ aisan tabi ipọnju, ibanujẹ tabi ikú, ẹkún tabi irora mọ! “Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn” (Ifihan 21:4).
A, ayọ ati iṣẹgun nla nla! Ibori ati gbigba ere! Gbogbo iwọnyi ati ju bẹẹ lọ ni ohun ti n duro de awọn wọnni ti wọn ba yọọda lati mu iduro wọn fun Jesu, ti wọn npese ara wọn silẹ fun Ọrun, ti wọn si n foju sọna fun Oluwa ati Olugbala wọn Jesu Kristi.
Questions
AWỌN IBEERE- Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu n bọ wa lai pẹ?
- Darukọ awọn iṣẹlẹ mejeeji apapọ eyi ti a n pè ni bibọ Jesu lẹẹkeji.
- Ki ni yoo ṣẹlẹ nigba ti a ba gba Ijọ soke?
- Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn Onigbagbọ ti won ti kú?
- Bawo ni eniyan ti ṣe le mọ pe oun ti ṣe tan fun bibọ Jesu?
- Fun iwọn igbà wo ni awọn Onigbagbọ yoo fi wà lọdọ Jesu?
- Ọna wo ni eniyan fi le jẹ aṣẹgun?
- Ileri wo ni a ṣe fun ẹni ti o ba ṣẹgun?
- Ta ni yoo jẹ Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa?
- Awọn wo ni yoo duro niwaju Jesu fun idajọ?