Johannu 19:31-42; Matteu 27:62-66; Johannu 20:1-31

Lesson 276 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Nigba diẹ si i, aiye ki ó si ri mi mọ; ṣugbọn ẹnyin ó ri mi: nitoriti emi wà lāye, ẹnyin ó wà lāye pẹlu” (Johannu 14:19).
Cross References

I Ikú ati Isinku

1 Awọn Ju gba aṣẹ fun awọn ọmọ-ogun Romu lati mu ikú Jesu yá kankan, Johannu 19:31, 32

2 Jesu ti kú ná, ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ-ogun fi ọkọ gun Jesu ni ẹgbẹ, Johannu 19:33-37; Sekariah 12:10

3 Josẹfu ati Nikodemu gba okú Jesu, wọn tọju rè̩ fun sisin, wọn si gbe e sinu isa-okú ti Josẹfu tikara rè̩, Johannu 19:38-42; Matteu 27:60; Marku 15:43-46; Luku 23:50-53

II Ẹṣọ nibi Iboji

1. A ranti ọrọ Jesu pe yoo tun ji dide ni ọjọ kẹta, Matteu 27:62, 63; Johannu 2:18-22

2. Awọn Farisi ati awọn olori alufaa bẹru ki awọn ọmọ-ẹyin má ba wa ji oku Jesu gbe lọ loru, Matteu 27:64

3. Pilatu yan è̩ṣọ kan, a si fi edidi di okuta ẹnu iboji ki ẹnikẹni ma ṣe fọwọ kan an, Matteu 27:65, 66

III Ajinde

1. Ni ọjọ kẹta, ki ilẹ to mọ, angẹli Oluwa kan sọkalẹ lati Ọrun wá, o si yi okuta naa kuro lẹnu ọna iboji, Johannu 20:1; Matteu 28:1, 2

2. Jesu Kristi jinde kuro ninu isa oku lati wà laaye titi lae, Matteu 28:6; Marku 16:6; Luku 24:5-7; 1Kọrinti 15:4-6; Ifihan 1:8, 18

3. Maria Magdalene ti o kọkọ tete ji lọ si iboji ni o sare lọ sọ fun Peteru ati Johannu, Johannu 20:1, 2

4. Peteru ati Johannu yara sure lati lọ wadii, Johannu 20:3-10; Luku 24:12

5. Maria duro leti iboji; o ri ère gba, ni ti pe Jesu si fara han an, Johannu 20:11-18

IV Ifarahan Jesu fun Awọn Ọmọ-ẹyin

1. Ni alẹ ọjọ kan naa ti i ṣe Ọjọ Oluwa, Jesu fara han awọn ọmọ-ẹyin lati gba wọn niyanju ati lati mu inu wọn dun, Johannu 20:19-23; Marku 16:14-18

2. Tọmasi, ti a n pe ni Didimu, kò si nibẹ lakọkọ ti Jesu fara han, kò si gbagbọ pe Jesu jinde nitootọ, Johannu 20:24, 25

3. Ni ọjọ kẹjọ lẹyin naa, ni Ọjọ Oluwa bakan naa, Jesu fara han lẹẹkeji, nigba ti Tọmasi wà nibẹ, Johannu 20:26

4. Jesu mu iyemeji Tọmasi kuro, Johannu 20:27-31

Notes
ALAYÉ

Ọkàn Ibinujẹ

Awọn ọmọlẹyin Jesu tootọ dide ni kutukutu owurọ ọjọ kin-in-ni ọsẹ lẹyin ikú Rẹ lori igi agbelebu. Ọjọ yii ki i ṣe ọjọ ayọ fun wọn -- ẹgbẹ wọn yii kò layọ rara – nitori ibanujẹ ti ko ṣe e fẹnusọ bá ọkan wọn. A ti mu Jesu Kristi Oluwa ati alakoso wọn ọwọn, a si ti fi ibinuku kan An mọ agbelebu; Jesu, Ẹni ti O ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu laaarin wọn; Ẹni ti O ti kọ wọn bi a ti ṣe le sun mọ Ọlọrun; Ẹni ti O ti sọ fun wọn nipa awọn ohun meremere ti o wà ni Ọrun ati iṣẹ oró ti n bẹ ni ọrun apaadi; Ẹni ti wọn ti fi ọkan tan wi pe yoo jẹ Ọba ati Messia wọn laye yii.

Ireti ilepa ati ipinnu awọn ọmọ-ẹyin Jesu n ga siwaju ati siwaju ni akoko iṣé̩-iranṣẹ Rè̩, ṣugbọn ni ọjọ kan ṣoṣo ni pupọ ninu ireti wọnyi di asan loju wọn.

Ẹgbẹ oloootọ yii duro ti Jesu ni gbogbo igba ti O fi wà lori agbelebu. Wọn wà nibẹ nigba ti òkunkun biribiri bolẹ lọsan gangan. Wọn si gbọ nigba ti Ọmọ Ọlọrun Olubukun n gbadura idariji fun awọn onikupani Rè̩; wọn gbọ nigba ti O n ṣe ileri iye ainipẹkun fun ole nì ti o n kú lọ, ti a kàn mọ agbelebu pẹlu Rè̩; wọn si gbọ nigba ti Jesu kigbe ni ohun rara wi pe, “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ mi silẹ?” Agbo kekere yii duro ti Oluwa wọn titi O fi jọwọ Ẹmi Rè̩ alailabawọn lọwọ; ṣúgbọn òye wọn kuru lọpọlọpọ lati mọ anfaani iyebiye ti ohun ti wọn n fi oju wọn ri yii yoo mu ba awọn ẹlẹṣẹ ni gbogbo agbaye.

Josẹfu ati Nikodemu

Gẹrẹ ti Jesu ti jọwọ ẹmi Rè̩ lọwọ, ni Josẹfu ara Arimatea wá si ọdọ Pilatu lati tọrọ okú Jesu. O ya Pilatu lẹnu pe Jesu ti kú kiakia bẹẹ, nitori naa o ran onṣẹ lati mọ bi otitọ ni; lẹyin naa ni o to yọọda fun Josẹfu lati gbe okú naa. Nikodemu wá lati ran Josẹfu lọwọ, awọn mejeeji si ṣiṣẹ naa kankan: wọn gbe oku Jesu sọkalẹ kuro lori igi agbelebu, wọn fi aṣọ ọgbọ we E pẹlu ikunra oloorun didun, wọn si sin In sinu iboji titun ti Josẹfu tí o gbẹ sinu apata ninu ọgba ti o wà ni tosi. Awọn ọmọ-ẹyin ti o duro ti agbelebu mọ ibi ti iboji naa wa, wọn si pada si ile wọn pẹlu ibanujẹ ọkàn. Niwọn igba ti ọjọ keji jẹ ọjọ Isinmi, wọn kò le ṣe ohunkohun titi di ọjọ ti o tẹle ọjọ isinmi.

Irekọja Tootọ

Gbogbo asọtẹlẹ Iwe Mimọ nipa ikú Jesu ati isinku Rè̩ ni a muṣẹ perepere. Awọn Ju kò mọ pe ni ọjọ ipalẹmọ ase ọdọọdun yii, wọn n ṣe ọna lati mu ki a pa Irekọja tootọ -- ki i ṣe apẹẹrẹ tabi ojiji ohun ti n bọ wa, bi ko ṣe Irekọja tootọ. “Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa” (1Kọrinti 5:7). Bi o tilẹ jẹ pe a ti lana rè̩ silẹ lati ipilẹṣẹ aye wi pe Jesu yoo yọọda ẹmi Rè̩ fun Ẹbọ ki ẹlẹṣẹ le ye, sibẹ Ọlọrun fi ègún le gbogbo awọn ti o ba lọwọ ninu ikú Rè̩ lori. Ki i ṣe awọn Ju nikan ni o jẹbi ninu ọran yii. Gbogbo è̩ṣẹ ti a da ṣaaju akoko ti a bi Kristi tabi lẹyin naa, jẹ okunfa ikú Jesu; ohun kan ṣoṣo ti o le mu ẹbi yii kuro ni pe ki ẹlẹbi sá wa sọdọ Kristi ti a kan mọ agbelebu fun aanu ati ibuwọn Ẹjẹ etutu Rè̩. “Nigbati emi ba ri è̩jẹ na, emi o ré nyin kọja” (Ẹksodu 12:13). Ọlọrun Olodumare ni o sọ ọrọ wọnyi.

O dabi ẹni pe ikannu kikoro ti awọn Ju ni si Jesu kò loṣuwọn. Pẹlu ibinuku ni wọn fi ran awọn ọmọ ogun Romu jade lati ṣé̩ ẹsẹ awọn ti a kàn mọ agbelebu lati mu ki ikú wọn ya kánkán; ṣugbọn aṣẹ Ọlọrun nipa Ọdọ-agutan fun ase irekọja ni pe, “Ẹnyin kò gbọdọ fọ ọkan ninu egungun rè̩.” Ati pẹlu pe, “Nwọn kò gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rè̩ de ojumọ tabi ki nwọn ṣé̩ ọkan ninu egungun rè̩.” Ẹmi Ọlọrun gba ẹnu Onipsalmu sọ bayii pe, “O pa gbogbo egungun rè̩ mọ: kò si ọkan ti o ṣé̩ ninu wọn” (Orin Dafidi 34:20). Awọn ọmọ-ogun ṣẹ egungun ẹsẹ awọn meji ti a kàn mọ agbelebu pẹlu Jesu, ṣugbọn agbara Ọlọrun dá wọn lọwọ kọ, kò jẹ ki wọn le fi ọwọ kan Jesu. Dajudaju kò ṣanfaani lati ṣé̩ ẹsẹ Rè̩ nitori ki O ba le tete ku; Oun sa ti kú ná. Ọkan ninu awọn ọmọ-ogun fi ọkọ gun un li ẹgbẹ, “lojukanna è̩jẹ ati omi si tú jade.” Lati igba naa ni ọgbẹ yii ti jẹ ẹri ti o daju si awọn alahesọ ati awọn alaigbagbọ pe lai si aniani, Jesu kú ni tootọ.

Ẹsin Asán

Ifẹ agalamaṣa fun ọjọ Isinmi mu ki awọn Ju fẹ lati sọ awọn wọnni ti a kàn mọ agbelebu kalẹ; ṣugbọn i ha ṣe eyi ni eredi ti wọn fi ṣe bẹẹ? Ohun iṣoro ha kọ ni fun wọn lati tapa si ẹri-ọkàn wọn ti o n da wọn lẹbi? Awọn Ju dá ọran ti o buru ju lọ laye yii, ẹri-ọkàn wọn si n da wọn lẹbi. Wọn lero pe bi wọn ba gbe oku awọn wọnni ti a kan mọ agbelebu kuro lori igi ti wọn kò si ri wọn mọ, boya ara yoo rọ wọn diẹ, wọn yoo si wa ni anfaani lati fi ọkàn balẹ ṣe iṣẹ isin wọn. S̩ugbọn duro na o! A kò le gan Ọlọrun! Oun ti ri ete ọkàn ọmọ eniyan ṣaaju ki O to wo iṣẹ ọwọ rè̩. Adabọwọ isin kò le mu è̩ṣẹ arankan ati itajẹsilẹ kuro lookan aya. Ibinu-fufu awọn Ju gbona sibẹ si Kristi, sibẹ wọn n lepa lati té̩ Ọlọrun lọrùn, Ẹni ti oju Rè̩ ri ohun gbogbo nipa pipa Ọjọ Isinmi mọ gẹgẹ bi ofin. Ohun ti o buru ju lọ ni pe, ọmọ eniyan kò ti i yipada titi di ọjọ oni. Wọn ṣi n sa ipa wọn lati tu Ọlọrun loju lẹekan lọsẹ pẹlu iṣẹ ode-ara ati eto isin, ṣugbọn ọkàn wọn kún fun agidi ati iwa buburu gbogbo lai si ironupiwada.

Eto Eniyan

Awọn ijoye Ju paapaa kò ni idaniloju ninu ara wọn. Lai si aniani, pupọ ninu wọn ni o ri Nikodemu ati Josẹfu nigba ti wọn n yi okuta nla nì di ẹnu iboji nibi ti a sin okú Jesu si. Wọn ranti ẹkọ Jesu nigba ti wọn beere ami lọwọ Rè̩, ti O si da wọn lohun wi pe, “Ẹ wó tẹmpili yi palè̩, ni ijọ mẹta Emi o si gbé e ró” (Johannu 2:19). Nigba ti wọn n ṣe idajọ eke, awọn Ju lọ itumọ ọrọ ti Jesu sọ fun wọn, wọn n fi I sun pe O fẹ wó Tẹmpili wọn; ṣugbọn ninu ọkàn wọn, wọn mọ itumọ ọrọ ti Jesu sọ fun wọn. Nisisiyi wọn tọ Pilatu wa wi pe Jesu ti ṣeleri fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe Oun yoo jinde ni ọjọ kẹta. Wọn fẹ ki a fi edidi di iboji naa, ki a si yan awọn ọmọ-ogun lati maa ṣọ ọ ki awọn ọmọ-ẹyin má ba wa ji oku Jesu gbe. Lẹẹkan si i, otitọ yii tun fara han. “Nitõtọ ibinu eniyan yio yin ọ” (Orin Dafidi 76:10). Ọlọrun yi ète asan awọn ijoye Ju ti wọn fẹ fi gbè ara wọn lẹsẹ pada di ẹri fun gbogbo awọn alaigbagbọ pe lotitọ ati lododo ni Jesu jinde.

Agbara Ajinde

Iranlọwọ eniyan kò jamọ nnkankan lowurọ ọjọ ti Kristi jinde. Ẹnikẹni kò fi ikanju gbe okú Jesu jade kuro ninu iboji, nitori Apọsteli nì ri i pe aṣọ ọgbọ wọnni wa letoleto nibi ti wọn wà, ati pe gèle ti o wa nibi ori Jesu wà ni kiká bẹẹ. Awọn ọrẹ Jesu kò wá lati gbe E lọ, nitori kò si ọrẹ tootọ ti o jẹ tabuku si okú mimọ bayii nipa gbigbe E lọ nihoho. Jesu gba ẹmi ti O ti fi lelẹ fun araye pada. Ki ilẹ to mọ ni owurọ ọjọ kin-in-ni ọsẹ lẹyin ti a ti kan An mọ agbelebu, Ẹmi Kristi pada sinu ara Rè̩, Jesu si jinde kuro ninu okú; “Ẹniti Ọlọrun gbé dide, nigbati o ti tú irora ikú: nitoriti kò ṣe iṣe fun u lati di ì mu” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:24). Edidi ijọba Romu fọ tuutu, awọn oluṣọ wariri, wọn si dabi okú, a si yi okuta kuro lẹnu iboji. Jesu ṣẹgun ikú, ọrun apaadi ati iboji. “Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn” (1Kọrinti 15:20).

Ihin ayọ nla ti ajinde Jesu kò ti i de eti igbọ awọn ọmọ-ẹyin obinrin ki wọn to fi ile wọn silẹ ni kutukutu owurọ lati lọ ṣe itọju ara Jesu. Ibanujẹ gba ọkàn wọn kan sibẹ bi wọn ti n lọ si iboji ni afẹmọjumọ. Bi wọn ti n sun mọ iboji, aya wọn ja pa, nitori okuta nla – ti o wuwo to bẹẹ ti wọn kò le nikan gbe e – ni a ti yi kuro lẹnu iboji. Wọn wọ inu iboji, ṣugbọn si iyalẹnu wọn, okú Jesu kò si nibẹ mọ. Ohun ti wọn ri ni awọn ọkunrin meji alaṣọ didan ti o wi fun wọn pe: “Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alāye lārin awọn okú? Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili, pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹṣẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde” (Luku 24:5-7).

Titan Ihinrere Kalẹ

Awọn obinrin naa gba ihin otitọ naa gbọ, wọn si pada kankan pẹlu ayọ lati sọ fun awọn ọmọ-ẹyin, ṣugbọn ọrọ wọn dabi ahesọ loju wọn. Awọn ọmọ-ẹyin meji sare lọ si ibi iboji lati lọ fi oju wọn ri ohun ti o ṣẹlẹ. Ọkan ninu wọn pada tọ awọn iyoku lọ, o si gbagbọ, ṣugbọn ẹni keji pada o si bẹrẹ si wo suu nipa ohun ti o ti ṣẹlẹ. Bi a ba wo bi Jesu ti tẹnumọ ikú ati ajinde Rè̩ pọ to, yoo jẹ iyanu fun ni eredi rè̩ ti awọn ọmọ-ẹyin fi lọra to bẹẹ lati gba ohun ti o ṣẹlẹ ni oju wọn kòrókòró yii gbọ; ṣugbọn àyè ti ọkàn wọn wà yii mu ki ahesọ awọn Ju wi pe awọn ọmọ-ẹyin ni o wá ji okú Jesu gbe jé̩ isọkusọ patapata. Wọn kò sọ itan ti ko da wọn loju tabi ahesọ nipa Olugbala ti o jinde. Pupọ ninu wọn ni kò gbagbọ pe Jesu jinde titi wọn fi ri I laaye. Tọmasi sọ pe oun ki yoo gbagbọ afi bi oun ba fi oju ri Jesu ki oun si fi ọwọ kan àpá ti o wà ni ìha Rè̩. Jesu rè̩ ara Rè̩ silẹ lati té̩ Tọmasi lọrùn, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ O gbà a niyanju pe “Tọmasi, nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ.”

Ayọ kún ọkàn Tọmasi lọpọlọpọ nigba ti o han si i gbangba pe otitọ ni ihin ajinde. Ẹnikẹni le ṣe alabapin ayọ kan naa bi o ba le fi igbagbọ wo Kristi ni igbọran si aṣẹ Rè̩. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe, “Nitoriti emi wà lāye, ẹnyin ó wà lāye pẹlu” (Johannu 14:19). Gbogbo awọn ọmọ-ẹyin Kristi tootọ ni o gba wi pe ileri yii jẹ ti wọn.

Iṣẹlẹ ti o Ga Julọ ni Aye

Ẹbọ arukun ati ajinde Jesu ṣe pataki gẹgẹ bi ìbí Rè̩ tabi gbigbe ti O gbe ara eniyan wọ. Kò si iṣẹlẹ ti o ga ju eyi lọ lati ìṣè̩dálè̩ aye. Kò ṣe e ṣe fun Un lati kú ati lati jinde bi kò ṣe pe O ba wá si aye ni àwọ eniyan; ṣugbọn ikú ati ajinde Rè̩ ni o fi otitọ ibi ati igbesi aye Jesu ye ni. Ajinde ni o fi ìye, ireti ati agbara fun Ihinrere. “S̩ugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde: Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwāsu wa: asan si ni igbagbọ nyin pẹlu” (1Kọrinti 15:13, 14). S̩ugbọn igbagbọ tootọ kò lọ lasan. Kristi ti o jinde fi idaniloju fun olukuluku ọkàn ti o ba gbagbọ pe Oun wà laaye. Iwọ ọkàn ti kò mọ agbara Kristi ti o jinde, dán Ọlọrun wò tikara rẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti awọn Ju pinnu lati gbe okú awọn ti a kàn mọ agbelebu kuro lori agbelebu?
  2. Ọna wo ni awọn Ju fẹ gba lati mu ki ikú Jesu yá kankan?
  3. Tọka si mẹta ninu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti a mu ṣẹ nigba ikú ati isinku Jesu.
  4. Ta ni ọkan ninu awọn ti o kọ de iboji ni ọjọ kin-in-ni ọsẹ?
  5. Ki ni ṣẹlẹ ni iboji?
  6. Ki ni Peteru ati Johannu ṣe nigba ti wọn gbọ ihin naa?
  7. Ọna wo ni Jesu gba fi ara Rè̩ han fun Maria Magdalene?
  8. Bawo ni Jesu ṣe wọ yara nibi ti awọn ọmọ-ẹyin pejọ si?
  9. Ki ni Tọmasi sọ nipa ifarahan Jesu?
  10. Ki ni Jesu sọ fun Tọmasi nigba ti o fara han lẹẹkeji?