Lesson 277 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle OLUWA; ma si ṣe tè̩ si ìmọ ara rẹ” (Owe 3:5).Cross References
I Pipa Ofin Ọlọrun Mọ
1. Baba kan ran ọmọ rè̩ leti pe ki o ma ṣe gbagbe ofin Ọlọrun, Owe 3:1, 3, 21; Deuteronomi 4:9; 6:12; 8:11
2. Pipa ofin Ọlọrun mọ n fun ni ní ọjọ gigun, ẹmi gigun ati alaafia, Owe 3:2; Deuteronomi 5:33; 11:18-21; Orin Dafidi 119:165
3. Nipa pipa ofin Ọlọrun mọ, a maa n ri ojurere Ọlọrun ati eniyan, Owe 3:4; Orin Dafidi 19:11; Jeremiah 32:41; Daniẹli 1:9; Luku 2:52; Iṣe Awọn Apọsteli 2:47
4. Ofin Ọlọrun jẹ aabo fun gbogbo awọn ti o gba a, Owe 3:21-26; 1Samuẹli 2:9; 2Samuẹli 22:29-31; Orin Dafidi 119:105; 112:7
II Gbigbẹkẹle Oluwa
1. Ọlọrun yoo tọ ipa ọna awọn ti o gbẹkẹle E, Owe 3:5, 6; Orin Dafidi 37:3; Isaiah 26:3, 4; Orin Dafidi 23:2, 3
2. A ni lati kọ igbe-ara-ẹni-ga silẹ ati igbẹkẹle ninu ara ki a to le ni ọgbọn atoke wa, Owe 3:7, 8; 26:12; Isaiah 29:9-16; 1Kọrinti 1:18-24
3. Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan mọ riri gbogbo oore Rè̩ si wọn nipa sisan idamẹwaa ohun-ini wọn, Owe 3:9, 10; Ẹksodu 22:29, 30; Malaki 3:8-11; 1Kọrinti 16:2; Heberu 7:1-9
III Ibawi Ọlọrun
1. A kò gbọdọ gan ibawi Ọlọrun, ṣugbọn ki a gba a fun ire wa, Owe 3:11, 12; Deuteronomi 8:5, 6; Heberu 12:5-13
IV Niniyelori Ọgbọn
1. A kò le sọ bi ọgbọn ti ni iyi to ati bi o ti niye lori to, Owe 3:13-20; Jobu 28:12-28; Owe 2:1-9; 1Kọrinti 2:1-16
V Iwarere si Awọn Aladugbo
1. Ifẹ Ọlọrun mu ki a le pa awọn ofin mọ, Owe 3:27-30; Lefitiku 19:18; Marku 12:29-33; Matteu 22:37-40; Romu 13:8-10
VI A ko Gbọdọ ṣe Ilara Eniyan Buburu
1. A kò gbọdọ ṣe ilara eniyan buburu nitori ti idajọ yoo wa sori wọn, Owe 3:31-35; Orin Dafidi 37:1-40; Owe 24:19, 20
Notes
ALAYÉMa ṣe Gbagbe Ofin Mi
Eyi fara jọ pupọ iwe Owe ti o bẹrẹ pẹlu ikilọ yii pe, ma ṣe gbagbe Ofin Ọlọrun, ki o si fi ọkan gidigidi si imọran Olootu Iwe naa gidigidi. A tọka si Ofin Lefi ninu eyi ti Ọlọrun paṣẹ fun Mose lati kọ awọn Ọmọ Israẹli. A pa a laṣẹ fun wọn lati so Ofin yii, (ti a kọ) mọ iwaju ori wọn, ati lati kọ wọn si ara opo ati atẹrigba ile wọn (Ka Deuteronomi 6:6-9; 11:18-20). Ifẹ Ọlọrun ni pe ki Ofin Rè̩ ki o wà ni tosi ọdọ awọn Ọmọ Israẹli ninu igbokegbodo wọn ojoojumọ, ki wọn ki o le maa ranti anfaani ti wọn ni labẹ Ofin ati iṣẹ wọn si Ọlorun. Nipa siso ẹsẹ diẹ ninu Ọrọ Ọlọrun mọ iwaju ori wọn, Ọlọrun n fẹ ki o di mimọ fun wọn wi pe Ofin yii ni lati di ara fun wọn.
Ọrọ Ọlọrun ṣeleri fun ni wi pe a o kọ Ofin yii sinu tabili ọkàn ẹran. Nigba ti eniyan ba di atunbi ni a n kọ Ọrọ yii sinu tabili ọkàn ẹran, kò si ni dẹkun titi opin igbesi-aye Onigbagbọ. Eyi wà ninu Majẹmu Titun, o si jẹ ẹri tootọ si iyipada ọkàn, nitori pe Ọlọrun ṣe ileri fun Israẹli nipa Woli Jeremiah pe “Lẹhin ọjọ wọnni, li OLUWA wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi. Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rè̩, ati è̩gbọn, aburo rè̩ wipe, Mọ OLUWA: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn” (Jeremiah 31:33, 34). Ninu ọkan ninu iwe ti Paulu kọ si awọn ara Kọrinti o sọ bayii pe, “Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, ki iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmi Ọlọrun alāye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran” ( 2Kọrinti 3:3). (S̩e atunyẹwo Ẹkọ 157, 158 ati 159) fun oye kikún nipa Majẹmu Titun, ki o si ka ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun wọnyi pẹlu: (Heberu 8:10; 10:16). Bi o tilẹ jẹ pe ni iwọn iba ṣoki ni ẹkọ wa mẹnuba riranti ofin Ọlọrun, o daju pe ọran pataki ti o kó ohun gbogbo já ti o si wà ninu eto nla ti igbala Ọlọrun ni a tọka si yii.
Ọjọ Gigun ati Alaafia
Ẹni ti ofin Ọlọrun ba wà ninu ookan aya rè̩ ki i saba ranti ọrọ ati ileri ti o wà ninu ẹkọ yii: “Ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ.” Siwaju si i Ọrọ Ọlọrun ṣe ileri aabo lakoko ti idagiri ba de lojiji: “Máṣe fòya è̩ru ojiji, tabi idahoro awọn enia buburu, nigbati o de. Nitori OLUWA ni yio ṣe igbẹkẹle rẹ, yio si pa ẹsẹ rẹ mọ kuro ninu atimu” (Owe 3:2, 25, 26). Jẹ ki ẹnikẹni ti o ba n fẹ ibi isadi, alaafia ati aabo, yipada si Ọlọrun alaaye ti n fun ni ní iye, ti O si n fun ni lọpọlọpọ.
Ikede pupọ ni n jade bi ọgbọn awọn oniṣegun ti n gori ọgbọn lati fun ni ni ọjọ gigun nipa lilo awọn egbogi asiko, ile itọju asiko ati fifaramọ ile egbogi fun itọju awọn alaisan ti o gbamuṣe ju ti atẹyinwa lọ ati oniruuru nnkan bawọnni gbogbo. S̩ugbọn awọn ẹri ti a fun ni lati fi idi ọrọ wọn mulẹ duro lori kikó ohun pupọ papọ fun ọdun pupọ lati fi we ara wọn. Wọn kò ṣeleri aabo tabi iranwọ lati kó ẹnikẹni yọ nigba ti idagiri tabi ajalu ojiji ba de ba a. Ọlọrun fun ọmọ-eniyan ni aadọrin ọdun, bi o ba si ṣe pe nipa agbara wọn to ọgọrin ọdun, gbogbo awari ọgbọn ọmọ-eniyan kò le yi Ọrọ Ọlọrun pada. Onipsalmu sọ fun ni pe, “Adọrin ọdun ni iye ọjọ ọdun wa; bi o si ṣepe nipa ti agbara, bi nwọn ba to ọgọrin ọdun, agbara wọn lāla on ibinujẹ ni; nitoripe a kì o pẹ ke e kuro, awa a si fò lọ” (Orin Dafidi 90:10).
Igbẹkẹle Ninu Oluwa
Apa keji ninu ẹkọ wa yii n kọ wa pe ki awọn eniyan ni igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun, ki wọn ki o fi ọkàn tan An, ki wọn gba A gbọ tọkantọkan, ki wọn joloootọ si I, ki wọn si ni ireti ninu Rè̩. Ọpọlọpọ eniyan ni o wà lode oni ti kò ni igbagbọ pe Olugbala kan tabi Ọlọrun kan wà nibi kan, wọn gba wi pe, “bi Ọlọrun kan ba wa rara” kò bikita fun awọn ọmọ-eniyan. Ọpọlọpọ si wa ti wọn wi pe ọna ti Bibeli gba lati gbe ìmọ Ọlọrun kalẹ kò ba ode-oni mu, igba ti lo o, paapaa ju lọ pe kò wulo ni ode-oni mọ.
Ọgọọrọ eniyan ni asiko ọlaju yii ni o ti pa isin Ọlọrun ninu ẹwà iwa mimọ tì, wọn si ti fi ohun titun miiran dipo gẹgẹ bi awọn Hellene igbà nì ti i maa ṣe. Awọn Hellene gẹgẹ bi orilẹ-ède pinnu lati wá otitọ, nitori eyi ni opin ìlepa gbogbo eniyan. Nigba ti wọn kò ri i, wọn bẹrẹsi i tọ afé̩ lẹyin bi ẹni pe afé̩ ṣiṣe ni ohun ti o dara ju lọ ti ọwọ ọmọ-eniyan le tè̩ ni aye yii. Nitori eyi wọn bọ sinu ibajẹ ti o buru jai, ijọba wọn fọ, wọn si di ẹrú awọn ara Romu ti o ṣẹgun wọn.
Iru ipo kan naa ni aye ọlaju ti ode-oni wà. Ẹni kọọkan ti kọ imọ Ọlọrun otitọ, ati imọ rere ati ibi silẹ, o ti ka ero pe idajọ n bọ wa sori ẹni ti o ba ṣe ibi si isọkusọ ti igba nì ti kò fi ẹsẹ mulẹ ni aye ode-oni, nipa bẹẹ wọn di òṣónú ti o buru jai; wọn kò fọkàn tan ẹnikẹni, bẹẹ ni wọn kò ni ipilẹ tabi ireti iye ainipẹkun ninu ẹsin ti o wu ki o jẹ, wọn si di ẹni irira niwaju Ọlọrun. Ohun ti o mu ki o ri bẹẹ ni pe wọn ti ṣa aṣẹ Ọlọrun tì, eyi ti o wi pe, “Maṣe tè̩ si ìmọ ara rẹ.”
Itọni Obi
Ẹni ti o kọ iwe yii sọrọ nipa ohun ti o kan ẹni kọọkan, eyi nì ni itọni ti awọn obi ni lati fun awọn ọmọ wọn. Ọkan ninu awọn ami ikẹyin ọjọ ni pe awọn ọmọ yoo jẹ “aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ” (Wo 2Timoteu 3:1-5; Romu 1:30). Bi awọn eniyan ba jẹ aṣaigbọran si obi wọn nipa ti ara, o daju pe wọn yoo jẹ aṣaigbọran si Ọlọrun ti O wà ni Ọrun.
A sọ fun ni ni ibi pupọ ninu Bibeli pe, “ẹniti OLUWA fẹ on ni itọ” (Owe 3:12), ṣugbọn bi awa ba wa ni aisi ibawi, njẹ a ki i ṣe ọmọ (Wo Heberu 12:3-11).
Ọgbọn
Sọlomọni ọba, ti o kọ pupọ ninu Iwe Owe jé̩ ẹni ti o ni ọrọ lọpọlọpọ. Kò si ọna ti eniyan n gba lati ṣafẹ ati lati té̩ ifẹ ọkan rè̩ lọrún ti Sọlomọni kò gbà. Akọsilẹ rè̩ ninu iwe ti a n pe ni Oniwasu, nipa asán aye yii kò lẹgbẹ. Sọlomọni tun ṣe atunwi ọrọ baba rè̩ ninu Owe pé, “Ipilẹṣẹ ọgbọn ni lati ni ọgbọn: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni òye” (Owe 4:7).
Bi o ba jẹ pe mè̩kúnnù kan ni o sọ iru ọrọ bayii, ọpọlọpọ eniyan ni yoo da ṣiọ rè̩, nitori pe wọn o sọ pe kò ni ẹtọ lati sọrọ nitori ti kò mọ ohunkohun nipa ọrọ ati igbadun ti o wà ninu rè̩. S̩ugbọn Sọlomọni ni ọrọ bi ọmọ-eniyan ti le ni to, nitori naa, a ni lati fara mọ imọran rè̩, nitori ti o kún fun imisi Ọlọrun ati idaniloju, otitọ ni, ẹni ti o ni iriri aye ni o n sọrọ yii.
Jobu, eniyan Ọlọrun ti o ni ohun ini lọpọlọpọ, sọ bayii nipa bi ọgbọn ti niye lori to: “A kò le fi wura rà a, bḝli a kò le ifi òṣuwọn wọn fadaka ni iye rè̩. A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri. Wura ati okuta kristali kò to ẹgbé̩ rè̩, bḝli a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rè̩. A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọn si jù okuta rubi lọ. Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbé̩ rè̩, bḝli a kò le ifi wura daradara diye le e” (Jobu 28:15-19).
Wo bi itumọ ti awọn mejeeji wọnyi fi fun ohun ti o niye lori tootọ ti yatọ si itumọ ti awọn ẹni ti ara fi fun ohun ti i ṣe ọrọ tootọ.
Ki ni ọgbọn? ati òye? “Kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọn, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li òye!” (Jobu 28:28).
Ifẹ Ọmọnikeji
“Ifẹ kì i ṣe ohun buburu si ọmọnikeji rè̩: nitori na ifẹ li akója ofin” (Romu 13:10). Nihin Paulu sọ itumọ apa kan ninu ẹkọ wa. Wo bi ibi yoo ti dinku to ninu aye bi awọn eniyan ba le tẹle imọran Ọlọrun ti o kọ wa bi a ti ṣe le gbe ni alaafia pẹlu aladugbo wa nipa pe ki a ma ṣe fawọ ire sẹyin lọdọ awọn ẹni ti o tọ si, ati pe ki a ma ṣe ba eniyan jà lainidi (Owe 3:27, 30).
Jesu Kristi, Ọmọ Alade Alaafia, ni Ọna alaafia pipe laaarin gbogbo eniyan. “Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni ... ṣugbọn bi ebi ba npa ọtá rẹ, fun u li onjẹ; bi ongbẹ ba n gbẹ ẹ, fun u li omi mu: ni ṣiṣe bḝ iwọ ó kó ẹyín ina le e li ori. Maṣe jẹ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi rere ṣẹgun buburu” (Romu 12:17, 20, 21). Jesu wi pe, “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin” (Matteu 5:44). Lati ran awọn eniyan Rè̩ lọwọ lati pa ofin yii mọ, Jesu fi alaafia fun wọn. O wi pe, “Alafia ni mo fi silẹ fun nyin, alafia mi ni mo fifun nyin: kì iṣe gẹgẹ bi aiye iti fi funni li emi fifun nyin” (Johannu 14:27).
Ihinrere fi ara han ninu awọn ẹsẹ ti a yàn fun ẹkọ wa yii; a si tun ni òye ti o ye kooro sii nipa irẹpọ tootọ ti o gbọdọ wa laaarin awọn eniyan nigba ti a ba wo iru ifẹ ti Ọlọrun ni si gbogbo ẹda. “Ọlọrun fẹ araiye tobḝ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun” (Johannu 3:16). A sọ fun ni ni iye igba ninu Bibeli pe a ni lati dabi Jesu; Oluwa tikara Rè̩ si sọ fun awọn ti wọn n gbọ ọrọ Rè̩ pe wọn ni lati dabi Baba wọn ti O wà li Ọrun, Ẹni ti o “S̩eun fun alaimore ati fun ẹni-buburu” (Luku 6:35). Koko imọran ti a fi le awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ ninu ẹkọ wa yii ni pe, “Máṣe ilara aninilara, má si ṣe yàn ọkan ninu gbogbo ọna rè̩”, “Awọn ọlọgbọn ni yio jogun ogo: ṣugbọn awọn aṣiwere ni yio ru itiju wọn” (Owe 3:31, 35).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati so apa kan ninu ofin mọ ara wọn?
- Bawo ni a ṣe le kọ Ofin Ọlọrun si ookan àyà?
- Ki ni yoo mu ọjọ gigun, ẹmi gigun ati alaafia wá?
- Eelo ni iye ọgbọn?
- Bawo ni a ṣe le ni ọgbọn?
- Ki ni itumọ wiwà ni alaafia pẹlu aladugbo?
- Ki ni ṣe ti a kò fi ni lati ṣe ilara awọn eniyan buburu?