Owe 4:1-27

Lesson 278 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ipa-ọna awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan” (Owe 4:18).
Cross References

I Ẹkọ Rere

1. Sọlomọni fi ẹkọ rere lelẹ fun awọn ọmọde, Owe 4:1, 2; Orin Dafidi 34:11

2. Dafidi, baba Sọlomọni kọ ọ lati pa gbogbo ofin rè̩ mọ, Owe 4:3, 4; 7:2

II Ọgbọn

1. A fi han pe ọgbọn ni olubori ohun gbogbo, Owe 4:5-7; 2:2-5; Matteu 13:44

2. A ka awọn ibukun ti o n tẹle ọgbọn, Owe 4:8, 9; 1:9; 3:22

3. A ṣeleri ẹmi gigun fun awọn ti yoo rin nipa ọna ọgbọn, Owe 4:10-13, 19; 3:2

III Ipa Ọna Meji

1. A gbà wa niyanju lati yà kuro nipa ọna eniyan buburu, Owe 4:14-17; 1:10-15; Orin Dafidi 1:1

2. Ipa ọna awọn oloootọ dabi titàn imọlẹ, Owe 4:18; Matteu 5:14; 2Samuẹli 23:4

3. O dara lati pa ọkàn wa mọ pẹlu ikiyesara, Owe 4:20-27

Notes
ALAYÉ

Sọlomọni ṣe oriire lati ni obi rere. O ni anfaani lati jé̩ ọmọ ogbó Dafidi, o si dagba labẹ itọni ati ododo onigbagbọ ti o wà ninu igbesi-aye baba rè̩ nigba nì. Sọlomọni jogún ọgbọn baba rè̩ nipa iwe kikọ, imọ nipa iṣelu ati ifẹ si ohun ti i ṣe ti Ọlọrun. A tọ ọ dagba ninu isin ati ẹkọ awọn Ju. O jé̩ ogbogi ninu ẹkọ ati imọ, o kọ é̩gbè̩é̩dógún owe, orin rè̩ si jẹ ẹgbẹrun o le marun un (1Awọn Ọba 4:29-34). Sọlomọni jẹ ọkan ninu awọn ogbogi ninu ẹkọ ninu gbogbo aye. A ka a ninu Bibeli pe, “OLUWA si fẹ ẹ” (2Samuẹli 12:24).

Imọran Dafidi fun Sọlomọni

Sọlomọni bẹrẹ apa kan ninu iwe rè̩ yii pẹlu awọn ọrọ wọnyi pe, “Ẹnyin ọmọ, ẹ gbọ ẹkọ baba, ki ẹ si fiyesi ati mọ oye. Nitori ti mo fun nyin li ẹkọ rere, ẹ máṣe kọ ofin mi silẹ. Nitoripe ọmọ baba mi li emi iṣe, ẹni-iké̩ ati olufẹ li oju iya mi. On si kọ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọrọ mi duro: pa ofin mi mọ ki iwọ ki o si yè” (Owe 4:1-4). Sọlomọni fẹ fi ẹkọ baba rè̩ Onigbagbọ silẹ fun awọn iran-iran ti n bọ lẹyin.

Lati igba ti Sọlomọni ti wa ni ọmọde ni Dafidi ti n kọ ọ ni Ọrọ Ọlọrun, o si ti gbin ofin Ọlọrun ati ẹkọ ti o ye kooro si ookan aya rè̩, paapaa ju lọ o fi ye e bi o ti jẹ ohun danindanin to lati pa Ofin Ọlọrun mọ ki o le ni iye ainipẹkun. Labẹ Ofin, a pa a laṣẹ fun awọn Ju lati kọ awọn ọmọ wọn gidigidi ni ohun ti i ṣe ti Ọlọrun nigba ti wọn ba joko ninu ile wọn, nigba ti wọn ba n rin li ọna, nigba ti wọn ba dubulẹ ati nigba ti wọn ba ji ni owurọ. Sọlomọni fun wa ni apẹẹrẹ ẹkọ ti o jinlẹ ti baba rè̩ ti kọ ọ. “On si kọ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọrọ mi duro: pa ofin mi mọ ki iwọ ki o si yè” (Owe 4:4).

S̩iṣe Afẹri Ọgbọn

Ọkan ninu awọn imọran ti a fi fun ẹni ti n bọ wa jọba lọla yii ni pe, “Ni ọgbọn, ni oye: máṣe gbagbe; bḝni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọrọ ẹnu mi. Máṣe kọ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ. Ipilẹṣẹ ọgbọn ni lati ni ọgbọn: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye” (Owe 4:5-7). A mọ pe ẹkọ ti a n kọ wa nihin yii ni pe ki a ṣafẹri ọgbọn tootọ ti i ṣe ọgbọn Ọlọrun: nitori pe Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe ki a wa ọgbọn nitori ti yoo mu wa tọ, ki a si fẹ ẹ nitori ti yoo pa wa mọ. Ọgbọn ati ìmọ ayé kò ni agbara lati mu ni tọ, bẹẹ ni kò si le pa wa mọ. Ibẹru Ọlọrun ni ipilẹṣẹ ọgbọn, ibẹru ẹni iwa-bi-Ọlọrun a maa fun ni ni ironupiwada kuro ninu è̩ṣẹ. Nigba ti a ba gba ọgbọn yii, yoo ṣi wa ni iye, a o si ni oye ti ẹmi.

Bi Sọlomọni tilẹ jẹ ọmọde, dajudaju, o fara balẹ gbọ ẹkọ baba rè̩, o si fi wọn si ookan aya rè̩. Lẹyin ti Sọlomọni di ọba, Ọlọrun fara han an, o si beere ohun ti o n fẹ. Sọlomọni wi pe, “Fun mi li ọgbọn ati ìmọ nisisiyi, ki emi le ma wọ ile, ki n si ma jade niwaju enia yi: nitoripe, tani le ṣe idajọ enia rẹ yi ti o pọ to yi” (2Kronika 1:10).

Sọlomọni mọ pe alailagbara ni oun i ṣe ati pe oun ni lati sinmi le Ọlọrun fun ọgbọn lati ṣe akoso awọn eniyan “ti o pọ bi erupẹ ilẹ.” Ibeere rè̩ dùn mọ Ọlọrun, O si fun un lọpọlọpọ ju bi o ti n fẹ lọ. Lẹyin ti Ọlọrun ti fun un ni ọgbọn, O tun fun un ni ọrọ, ọlá ati ọlà. “Gbé e (ọgbọn) ga, on o si ma gbé ọ leke: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra. On o fi ohun-ọṣọ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ” (Owe 4:8, 9).

Ipa Ọna Meji

Ọkan ninu awọn imọran ti baba Sọlomọni fun un ni pe “Máṣe bọ si ipa-ọna enia buburu, má si ṣe rìn li ọna awọn enia ibi” (Owe 4:14). Nihin yii a ri i pe ipa-ọna meji ni o lọ si ayeraye. Ọkan ninu wọn ni ọna gbooro ti o lọ si iparun ayeraye. Ipa ọna keji ni ọna awọn oloootọ.

Ọpọ eniyan ni o n tọ ipa ọna gbooro ti o lọ si iparun nitori pe adun è̩ṣẹ n fa wọn. O le jẹ adun ile ijó, tabi ti ibi idaraya, tabi ti kaadi, tabi ere bọọlu; o si le jẹ pe wọn wa ni ọna gbooro nitori iwa aibikita. Awọn miiran n tọ ipa ọna gbooro nitori ti ọkàn wọn ṣọtẹ si Ọlọrun. Awọn miiran n tọ ọna yii nitori ti wọn n bẹru ohun ti awọn ọrẹ wọn yoo sọ si wọn. Awọn miiran wa nibẹ nitori pe wọn fẹ owo ati iṣura aye yii ju ọrọ oun iṣura Ọlọrun – ireti oun idaniloju iye ainipẹkun pẹlu Ọlọrun ni Ọrun. Awọn miiran n tọ ọna gbooro nitori ti wọn kò fẹ ru itiju Agbelebu Kristi. Awọn miiran si wà nibẹ nitori ti wọn n wá ọna ti o rọrun ju ọna tooro, wọn si ti gbe isin kan kalẹ fun ara wọn tabi ki wọn maa tẹle isin atọwọda awọn ẹlomiiran. Awọn miiran si wà nibẹ nitori ti wọn kò naani igbala ọkàn wọn.

Tooro ni ipa ọna awọn oloootọ, iba awọn eniyan diẹ ni o si n lepa lati tọ ọ. A ṣe apejuwe rè̩ lọna ti o wu ni lori, Onigbagbọ tootọ si mọ bẹẹ bi wọn ti n ka nipa rè̩ pe: “Ipa-ọna awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan” (Owe 4:18). Ipa ọna eniyan buburu ṣú dùdù, o ṣokunkun, o si lewu; ọna olododo mọlẹ kedere o si dara. Onigbagbọ n rin ninu ofin Ọlọrun lai lẹgan: itanṣan imọlẹ igbala ti o ti gbà si n tan si gbogbo awọn ti o yi i ka ati si gbogbo awọn ti o wà labẹ akoso rè̩ lọna kan tabi lọna miiran.

Ipamọ Ọkàn

Ọkàn ni orisun iye nipa ti ara. Bakan naa ni o ri nipa ti ẹmi, a saba maa n sọ wi pe ọkàn ni ibi igunwa Oluwa Iye ati Ogo, ati pe omi iye nipa ti ẹmi n ṣàn lati ọdọ Rè̩ wa nigba ti O ba gunwa nibẹ bi alakoso gbogbo agbara, ọgbọn ati ero ọkàn. A ni lati ṣọra gidigidi lati ri i daju pe ohun kọlọfin kan kò dábu ìsun omi iye to bẹẹ ti kò fi ni le ṣàn geere mọ.

Lẹyin naa a gbọdọ mu ẹgan ati arekereke kuro lọdọ wa; ki a si maa wo ọkankan gan an lai ya si ọtun tabi si osi. Bi ọkàn ba mọ laulau, gbogbo ero ati ète rè̩ ni yoo dara ti yoo si jẹ mimọ. Iwara-papa, inu-fufu ati ahọn lile ki yoo si mọ rara. Kiyesi ipa ọna ti ẹsẹ rẹ n tọ lati ri i pe kò si iwa ibi kan nibẹ. Kiyesi gbogbo iwa ati iṣe rẹ.

Opin

Ni ibomiiran ninu Bibeli a sọ fun wa pe, opin gbogbo ọrọ naa ni pe: “Bè̩ru Ọlọrun, ki o si pa ofin rè̩ mọ: nitori eyi ni fun gbogbo enia. Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibā ṣe rere, ibā ṣe buburu” (Oniwasu 12:13, 14).

Ninu igbesi-aye wa gẹgẹ bi Onigbagbọ, a n gbọ ọpọlọpọ ẹri lati ẹnu awọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ti o ti yan ọna ara wọn, lai fi ifẹ Ọlọrun pè; ṣugbọn Ọlọrun, ninu aanu Rè̩, mu wọn wa sinu idajọ. Awọn miiran ninu wọn ni obi ti i ṣe Onigbagbọ ti o ti kọ wọn ni ọnà otitọ, ti wọn kò si dẹkun lati maa gbadura fun wọn niwọn igba ti wọn wa laaye. Ninu igbesi-aye è̩ṣẹ wọn, nigba pupọ ni ohun adura awọn obi wọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun n lù bi agogo ninu eti inu wọn, ẹkọ ti a si ti fi kọ wọn a maa wa si iranti wọn. Nipa bayii, Ọlọrun a tun mu wọn wa si ironupiwada.

Awọn miiran ti kò ni anfaani ẹkọ Onigbagbọ sọ fun ni pe Ọlọrun ni o dari wọn wa sinu imọlẹ Ihinrere lọna kan tabi omiiran. Awọn pẹlu awọn ti o ti mọ nipa Ofin ati ilana Ọlọrun ti jiya è̩ṣẹ wọn, a si ti da wọn lẹjọ, ninu aanu, fun riru ofin Ọlọrun ati ti eniyan. Ọlọrun si ti fi àyè silẹ fun ibanujẹ ati iṣoro lati dé bá wọn ki wọn ba le mọ pe idalẹbi nla wà fun wọn bi wọn ba taku si ọna iṣina wọn.

Iwa buburu le pamọ fun eniyan, ṣugbọn Ọlọrun ri gbogbo rè̩. Kò si ohun ti o pamọ kuro ni oju Rè̩, gbogbo ohun ti i ṣe ibi ni a o si mu wa si imọlẹ lati gba idajọ. Gbogbo iṣẹ rere ti awọn eniyan Ọlọrun ṣe ni kọrọ ni Ọlọrun yoo fun wọn ni ere rè̩ ni gbangba.

Imọran rere ti o dara ju lọ ti Sọlomọni fun awọn ọmọde ni pe: “Ranti ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ” (Oniwasu 12:1).

Ranti Ọlọrun ni igba èwe rẹ ki iwọ ba le ni ẹmi gigun ati igbesi-aye alaafia; ki iwọ ki o le bọ kuro ninu wahala ati ibanujẹ ti i ṣe ipin ẹlẹṣẹ. Inu Ọlọrun yoo ti dun to si awọn wọnni ti wọn ni igbala lati igba èwe wọn; ẹni ti kò wọ inu ibi-iṣire ori àtàgé ri, ti kò ta kaadi ri tabi ti kò si wọ inu ile ijó ri; ẹni ti o gba imọran awọn obi ẹni iwa-bi-Ọlọrun, ti kò jẹ ki ẹsẹ oun ṣina si ọna è̩ṣè̩. Iru awọn ọmọde bẹẹ jé̩ alabukunfun ninu Oluwa.

Sibẹsibẹ, idariji ati ifẹ Ọlọrun ni kikún wà fun awọn wọnni ti wọn ti fi ile Onigbagbọ silẹ, ti wọn si ti lọ sinu igbesi-aye è̩ṣè̩ ati ti ibanujẹ, ati fun awọn wọnni pẹlu ti kò ni anfaani itọni Onigbagbọ. Igbesi aye iṣẹ-isin fun Ọlọrun wa niwaju, bẹẹ ni ere si wà ni Ọrun pẹlu fun awọn ti ó wa sọdọ Ọlọrun ti wọn si sìn In tọkantọkan, nigbakuugba ti o wu ki o jé̩ ninu igbesi-aye wọn bi wọn ba gbadura lati wa aanu Ọlọrun. Bi Ọlọrun ba ti dariji, kò tun ni ranti è̩ṣẹ naa mọ. Bi Ọlọrun ba ti ran oore-ọfẹ idariji si wa ni yoo nu è̩ṣẹ ti o wa ni igbesi-aye wa nù kuro. Yoo ṣe wa gẹgẹ bi ẹni pe a kò dẹṣẹ ri. Oluwa korira è̩ṣẹ. O ta Ẹjẹ Rè̩ silẹ lati ra ẹlẹṣẹ pada. O fẹran ẹlẹṣẹ ṣugbọn O korira è̩ṣẹ rè̩.

Ọlọrun da wa ki a ba le wà ni alaafia, ṣugbọn ninu Rè̩ nikan ni a gbe le ni ayọ. Ranti Rè̩ nitori ifẹ Rè̩, nitori aanu Rè̩, itọju Rè̩, ati nitori aabo Rè̩. Iwọ n ranti Rè̩ bi? Bawo ni a ṣe le gbagbe Rè̩? O fi ẹmi Rè̩ lelẹ fun wa!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni fún Sọlomọni ni iru ẹkọ ọlọgbọn bẹẹ?
  2. Ki ni o pè ni pataki ohun ti a gbọdọ ni?
  3. Darukọ ohun diẹ ti ọgbọn yoo ṣe fun ọ.
  4. Sọ nipa ipa-ọna meji ti a tọka si ninu ẹkọ yii.
  5. Ki ni Sọlomọni sọ fun wa pe ki a mu kuro lọdọ wa?
  6. Bawo ni a ṣe le pa ọkàn wa mọ?