Lesson 279 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ li ọna iye” (Owe 6:23).Cross References
I Ọgbọn ti o ti inu Imoye Jade
1. A fi hàn pe iṣẹ onigbọwọ ni ìdẹkùn pupọ, Owe 6:1-5
2. Ire ti ó wà ninu aapọn ṣiṣe ati ègún ti ó wà ninu iwa ọlẹ ni a fi han kedere, Owe 6:6-11
3. Iparun ojiji awọn eniyan buburu daju, Owe 6:12-15
II Ohun ti Ọlọrun Korira
1. A pe awọn agberaga ni irira si Ọlọrun, Owe 6:16, 17; 11:2; 13:10; 16:18; 21:4; Orin Dafidi 10:4; 119:21; Habakkuku 2:4; Marku 7:20-23; 1Timoteu 3:6; 1Johannu 2:16
2. Ètè eke wà ni iru ipo buburu kan naa, Owe 6:17; 11:1; 19:9; Orin Dafidi 15:1, 2; 63:11; Isaiah 44:24, 25; Efesu 4:25; Ifihan 21:8
3. Apaniyan wà ninu ẹgbẹ kan naa, Owe 6:17; Gẹnẹsisi 4:8-15; 49:5-7; Ẹksodu 20:13 ati Matteu 19:18. Fi Matteu 5:21, 22 wé 1Johannu 3:15; Romu 1:28-32; 1Peteru 4:15; Ifihan 21:8
4. A fi iru ipo ti àyà ti n humọ buburu wà niwaju Ọlọrun han, Owe 6:18; Gẹnẹsisi 6:5-7; 8:21; Orin Dafidi 10:2; 38:12; 33:10; Romu 1:20-25; 2Kọrinti 10:5; Jobu 5:12
5. Ọlọrun korira ayọnilẹnu ati iwa buburu rè̩, Owe 6:18; 1:10-19; 4:14-19; Isaiah 59:1-8; Mika 2:1-3; Iṣe Awọn Apọsteli 13:10, 11; Romu 3:10-18; Orin Dafidi 10:4-11
6. Ẹlẹri eke ki yoo lọ lai jiya, Owe 6:19; 19:5, 9; 24:28; 25:18; Orin Dafidi 24:3, 4; Matteu 5:33; Ẹksodu 20:7; 23:1; Deuteronomi 19:16-21; Sẹkariah 5:3, 4; Malaki 3:5
7. Irira ti o kẹyin ninu awọn nnkan ti a tò wọnyi ni ẹni ti n da ija silẹ laaarin awọn arakunrin, Owe 6:19; 16:28; 2Tẹssalonika 3:11, 12; 1Timoteu 5:13; 1Peteru 4:15; Hosea 8:7; Galatia 6:8
Notes
ALAYÉOgunlọgọ iwe ni awọn eniyan ti kọ lati ọdụnmọdun lati sọ awọn ọna ti ọmọ eniyan n gba ti o dun mọ Ọlọrun ati awọn ọna wọnni ẹwẹ ti wọn n gba ti kò dùn mọ Ọlọrun. S̩ugbọn ninu Bibeli ni a le ri awọn ohun wọnni ti kò dùn mọ Ọlọrun ni ṣoki ati lọna kukuru ti o si rọrun lati ye ni. Eyi yii ni koko pataki ti ẹkọ wa yii duro le lori.
Ninu ori iwe ti a yàn fun ẹkọ wa yii, awọn ẹsẹ diẹ ti o ṣaaju sọ awọn ọrọ ti o le ṣi wa niye lati jẹ ọlọgbọn ninu ohunkohun ti a n ṣe, yala nipa ti ara tabi nipa ti ẹmi. Bi a si ti n ṣe àṣàrò lori ohun ti i ṣe koko ẹkọ wa gan an, a kò fẹ ki ẹnikẹni ni ero pe, awọn ibomiran ti a kò mẹnu ba ninu ori iwe yii kò nilaari to bi awọn ẹsẹ ti ẹkọ wa duro le lori. Aye kò to fun ni lati ṣe ayẹwo ẹsẹ kọọkan ninu ori iwe yii kinnikinni; niwọn igba ti ẹkọ ti wà ninu awọn ẹsẹ ti o ṣaaju kò fẹ alaye mọ, a o bẹrẹ si fọ alaye lori ẹkọ yii si wẹwẹ, bi o tilẹ jẹ pe o mọ ni iba ṣoki, ṣugbọn sibẹ o kó ohun gbogbo ja, o si kún fun ọgbọn ati ẹkọ lọpọlọpọ.
“Ohun mẹfa li OLUWA korira: nitõtọ, meje
li o ṣe irira fun ọkàn rè̩.”
Bayii ni a ṣe tọka si awọn ẹsẹ mẹrin ti a n kẹkọọ le lori. A ni lati ṣe aṣaro lori ẹsẹ wọnyi bi a ba fẹ mọ anfaani awọn ẹsẹ ti o tẹle e ni kikun.
Jehofa, Ọlọrun gbogbo agbaye ti o n ba ni da majẹmu ti o si n pa majẹmu mọ; Ọlọrun Alaanu, Onifẹ ati Oloore; Ọlọrun pipe ati mimọ; Ọlọrun ti oju Rè̩ kan si ẹṣẹ; ti ki i ṣe ojusaju eniyan ni a pè ni “OLUWA” nihin yii; kò si si ẹlomiran. Ọlọrun yii ni agbara lati korira – ikorira pipe, ti o si tọ, eyi yii ni a si le pè ni iwa-mimọ Rè̩ pipe ti kò ni abuku rara.
A le rii nigba naa pe, nigba ti eniyan ba ni ikorira, o dẹṣẹ -- è̩ṣẹ ipaniyan paapaa. S̩ugbọn ikorira ti i ṣe ti Ọlọrun yatọ si eyi ti o n wà ninu ọkàn ẹni ti kò ti di atunbi. Nigba pupọ ni awọn eniyan n fẹ gbẹsan nitori ikorira. Eniyan korira nitori owu ti o kún fun è̩ṣẹ ti o wà ninu ọkàn rè̩, ati nitori ti a kò gba a laye lati té̩ ifẹ ọkàn rè̩ lọrun tabi lati mu ipinnu ọkàn rè̩ ṣẹ. S̩ugbọn ohun ti Ọlọrun korira ni è̩ṣẹ. O korira è̩gbin, iwa aimọ ati ohun ti kò tọ. O korira iṣọtẹ. Gẹgẹ bi ohun ẹtọ Rè̩, Ọlọrun korira igberaga nitori yoo ran ọkàn sinu egbe ati iparun ayeraye bi a ba gba a laye ninu ọkàn.
Ọlọrun korira ohunkohun ti o ba lodi si ifẹ pipe Rè̩, nitori ọnakọna ti o ba lodi si ti Rè̩ yoo yọri si iparun ati egbe ayeraye. Ọlọrun korira tita ẹjẹ alaiṣẹ silẹ. Ọlọrun korira awọn ohun miiran pẹlu; bi a si ti n ṣe àṣàrò lori wọn, a o mọ eredi rè̩ ti Ọlọrun fi korira wọn ti O si ni ẹtọ pipe lati ṣe bẹẹ ni mimọ ati lododo. S̩ugbọn fun eniyan lati ni ero pe oun ni ẹtọ lati ni ọkàn ikorira nitori pe Ọlọrun paapaa ni ikorira si awọn ohun ti kò tọ, ki i ṣe ohun miiran bi ko ṣe eyi pe, oluwarẹ naa jẹbi ohun kin-in-ni ti a darukọ ninu awọn wọnni ti Iwe Mimọ sọ fun ni pe irira ni si Ọlọrun. Ẹnikẹni ti o ba fi eyi dá ara rè̩ lare lati ni ẹmi ikorira kún fun igberaga. Nitori naa, ẹ jẹ ki a ṣe ayẹwo ẹṣẹ buburu ti o wọpọ yii.
Igberaga ninu Ọkàn Eniyan
Itumọ igberaga ni jijẹ ọlọgbọn loju ara ẹni, tabi lati fè̩ soke nitori ipo, ọla tabi awọn ohun-ini. Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe igberaga a maa tan ẹni ti o ba gba a laye ninu ọkàn rè̩ jẹ. Alaye yii ati aṣẹ ti ó wà ninu Ọrọ Ọlọrun nipa iṣẹ buburu ti igberaga n ṣe fi han gbangba pe ohun ti o lewu pupọ ni.
Niwọn bi a ti mọ pe è̩ṣẹ buburu yii a maa ṣiṣẹ bi ayọkẹlẹ pẹlu arekereke gbogbo, ohun danindanin ni lati maa yẹ ara wa wo ki diẹ kinun ninu irugbin rè̩ ki o má ba yọ wọ inu wa. S̩ugbọn ẹlomiiran le wi pe, “Igberaga diẹ kinun ti kò lẹsẹ nilẹ ni temi. Kò si ohun ti o buru ninu eyi nì, bẹẹ ni kò lewu.” Bi o ba le tan ẹnikẹni ti o gba a laaye jẹ pẹlu ọgbọn è̩wé̩ ati arekereke, a kò gbọdọ gba a laye, a ni lati wẹ ẹ nu kuro ninu ọkàn.
Aṣiṣe ti o buru pupọ ni lati gba ohunkohun ti yoo pa wa run nikẹyin laaye, nitori pe a gba fun un lati tan wa jẹ, kò si fi ara rè̩ han bi oluparun gẹgẹ bi o ti ri gan an. Niwọn igba ti ẹni kan ba le ya ẹnu rè̩ lati sọ iru ọrọ bayii jade lati fi idi ipilẹṣẹ è̩ṣẹ buburu yii mulẹ, o fi han pe lai si aniani, è̩tan naa ti bẹrẹ ninu ọkàn rè̩. Awọn ohun ti a le pe ni ipilẹ è̩ṣẹ kékèké yii kò kere rara. Wọn buru pupọ; lai jẹ pe a fa wọn tu, ki a si pa wọn run, ibi ni yoo yọri si. Iṣẹ iparun wọn ti bẹrẹ, ṣugbọn è̩ṣẹ yii fi è̩tan bo ara rè̩ ni aṣiirí ki ẹlẹṣẹ ma le tete fura si iṣẹ ibi ti è̩ṣẹ naa n ṣe. Abajọ ti Ọlọrun fi korira igberaga!
Boya iwọ le beere wi pe, “Ki ni ẹṣẹ ti o wa ninu igberaga?” Igberaga a maa mu ki eniyan ti i ṣe iṣẹ-ọwọ Ẹlẹda ki o fè̩ soke, a si maa rè̩ Ọlọrun ti i ṣe Ẹlẹda silẹ. Igberaga a maa mu ki eniyan jọ ara rè̩ loju to nnkan, eyi si mu ki o jẹbi è̩ṣẹ ibọriṣa; nitori pe o juba ohun miiran yatọ si Ọlọrun. Oriṣa ni ohunkohun ti o ba dipo Ọlọrun ninu wa. Bi a ba ni igberaga nitori ipo wa, ọlà wa tabi awọn ohun-ini wa, awọn nnkan wọnyi ti gba ipo Ọlọrun ninu ọkàn ati ifẹ wa. Ki i ṣe kiki è̩ṣẹ irera tabi itabuku si ogo Ọlọrun nikan ni awọn agberaga jẹbi rè̩, wọn jẹbi è̩ṣẹ ibọriṣa pẹlu. Ọlọrun yoo da awọn abọriṣa lẹbi, yoo si ba wọn wi, irira si ni ọkàn agberaga loju Rè̩.
Ètè Eke Ọmọ-eniyan
Niwọn igba ti Ọlọrun ti n da majẹmu ti O si n pa majẹmu mọ, ati niwọn bi O ti da eniyan ni aworan ara Rè̩; ti O si fẹ ki eniyan dabi Rè̩ nigba gbogbo, ayẹwo ẹsẹ kukuru ti o wà ninu ẹkọ wa yoo fi han wa pe irira ni awọn ti o ba n ṣeke jẹ si Ọlọrun.
Awọn eniyan ti pin eke si oriṣiriṣi ọna. Wọn wi pe kò si è̩ṣẹ ninu irọ bi a ba pa lati fi bo ara wa ni aṣiiri. S̩ugbọn Ọlọrun ti fi idajọ le “gbogbo awọn eleke” lori wi pe wọn yoo ni ipa ti wọn ninu ikú keji ninu eyi ti kò si ireti ati là.
“Gbogbo eke,” dajudaju, ti kó ohun ti awọn eniyan n pe ni irọ funfun mọ eke ṣiṣe. Gbogbo ọgbọn ẹwẹ ti eniyan n lo, ọgbọn mẹbẹmẹyẹ, yala laaarin ẹni kan si ẹni keji tabi si orilẹ-ede, nibi ti a gbe sọ pe Rara nigba ti o yẹ ki a sọ pe Bẹẹ ni, nibi ti a ṣe ileri ti a kò ni ero lati mu ṣẹ, tabi nibi ti a sọrọ ti o lodi si eyi ti i ṣe otitọ; eke ni gbogbo wọnyi jasi, Ọlọrun si ti sọ pe wọn kò dara.
Awọn miiran gba pe kò si ohun ti o buru ninu irọ ti eniyan ba pa lati ran iṣẹ Ọlọrun lọwọ. Otitọ ni gbogbo ọna Ọlọrun. Jesu ni Otitọ. Ẹmi Mimọ a si maa tọ ni si Ọna Otitọ gbogbo. Otitọ ni Ọrọ Ọlọrun. Ọlọrun kò le dẹṣẹ. Ọlọrun ki i ṣeke. Awọn iranṣẹ Rè̩ kò si gbọdọ dẹṣẹ, tabi ṣeke ninu ohunkohun, ki a má tilẹ ṣẹṣẹ sọ ni ti titan Ihinrere Rè̩ kalẹ.
Ipaniyan
Ni atetekọṣe, Kaini pa Abẹli, nipa bẹẹ o di apaniyan kin-in-ni. Idajọ Ọlọrun daju o si wa sori Kaini kánkán; oun tikara rẹ jẹwọ pe ijiya naa ju eyi ti oun le fara da lọ. Ọlọrun ni O fun wa ni ẹmi, Oun ni O si ni ẹtọ lati gba a pada. Labẹ Ofin Mose, Ọlọrun fi aṣẹ yii le awọn alaṣẹ lọwọ, lati mu ẹmi eniyan kuro bi wọn ba ṣẹ si awọn ofin kan ni ilu. Bakan naa ni O paṣẹ pato pe ki a pa gbogbo awọn orilẹ-ede akorira Ọlọrun run, ki a ba le fopin si ọna iparun ti wọn n tọ. S̩ugbọn ni tootọ Oun, Ọlọrun nikan, ni O ni ẹtọ lati mu ẹmi eniyan kuro.
Ipaniyan ni pe ki a mọọmọ pa ẹlomiiran nitori pe a ti ni ohun kan ninu si i tẹlẹ. Ipaniyan ninu ogun ti kò tọ jé̩ ipaniyan. Ki a pa ẹni ti o wà ninu irora nitori pe aanu rè̩ n ṣe wa, tabi ki a ṣé̩ oyun jẹ ipaniyan. Ki a ṣeeṣi gba ẹmi eniyan tabi ki a pa ẹranko ki i ṣe ipaniyan. A ṣe alaye itumọ “Iwọ kò gbọdọ pa enia” fun wa ninu Majẹmu Titun. Lọna kin-in-ni a tun un sọ nibẹ bayii pe “Iwọ kò gbọdọ pa enia” (Matteu 19:18). Jesu ṣe alaye ofin yii, O si fi han fun ni pe ohun ti o ga ni Ofin yii beere lọwọ olukuluku ẹni ti o wà labẹ Majẹmu Titun nipa titẹnumọ ọn fun ni wi pe, a jẹbi è̩ṣẹ ipaniyan bi a ba korira arakunrin wa. (Matteu 5:21, 22; 1Johannu 3:15).
Ẹni ti o pa ara rè̩ jẹbi è̩ṣẹ ipaniyan. Ẹnikẹni kò ni ẹtọ lati pa ara rè̩. Otitọ ni pe ẹnikẹni ti o ba pa ara rè̩ ṣẹ si oun tikara rè̩, ati nitori eyii, o ni lati jere è̩ṣẹ rè̩. S̩ugbọn ẹni ti o ba pa ara rè̩ ṣẹ si Ọlọrun pẹlu, yoo si duro niwaju Itẹ Idajọ Ọlọrun lati jihin ohun ti o ṣe.
Awọn Ohun Irira Mẹrin Iyoku
Awọn ohun mẹrin iyoku ti Ọlọrun korira ti a kò ti i mẹnukan kò kere si awọn iyoku niwaju Ọlọrun. “Aya ti nhumọ ohun buburu” ati “ẹlẹri eke ti nsọ eke jade” wa ni ohun ti a ti sọrọ nipa rè̩ ṣaaju nigba ti a n ṣe alaye nipa ètè èké ọmọ-eniyan. Ọkàn ọmọ-eniyan lati igba iṣubu eniyan ni atetekọṣe ti di ibajẹ, o si n tè̩ si ibi. Satani kò jafara lati kó awọn wọnni lẹru, ani awọn wọnni ti o ṣaigbọran si Ọlọrun, ti wọn yàn lati lọ sinu egbe ju ati lọ si ijọba alaafia. Lati igba naa ni aiwa-bi-Ọlọrun ti n gbilẹ si i lori ilẹ aye. Aiwa-bi-Ọlọrun pọ to bẹẹ nigba kan ti Ọlọrun fi pa gbogbo olugbe aye run, afi iwọn iba eniyan diẹ ni O dá si ninu Ọkọ. S̩ugbọn olori è̩ṣẹ awọn ti o kú ni akoko Ikun Omi, ati awọn ẹda ti kò kọ è̩ṣẹ silẹ lati Igba Ikun Omi, ni eyii pe, “Gbogbo ìro ọkàn rè̩ kìki ibi ni lojojumọ” (Gẹnẹsisi 6:5).
Ifẹ ọkàn ọmọ-eniyan, ibi ni. È̩ṣẹ ni ọkàn rè̩ n fa si nigba gbogbo. O n gbero è̩ṣẹ, o si n dẹṣẹ. Eyi ni abayọrisi ẹda è̩ṣẹ rè̩. Kò si ohun rere kan ti a le reti lọwọ rè̩ ni ipo aidi atunbi yii. Ọna kanṣoṣo ti o ṣi silẹ ti o le gba ni ọna Agbelebu, nipa adura ironupiwada, bi o ba fẹ bọ kuro ninu idajọ ayeraye. Ọna otitọ kò si ninu rè̩. O le ṣeke – o si le sọ otitọ -- bi o ba ti wọ fun un, oun a si maa ṣe ohun ti ẹni ti o yàn ni oluwa dipo Ẹni kan ṣoṣo ti i ṣe Oluwa Tootọ, Oluwa Ọlọrun Olodumare, ba palaṣẹ fun un. Eniyan, ni ipo aidi atunbi yii jẹ irira si Ọlọrun. Oun kò le bọ kuro ninu ipo oṣi ati ainireti yii bi kò ṣe pe o ba yipada kuro ninu è̩ṣẹ rè̩ ki o si wa aanu Ọlọrun ti o n rọ ọ nigba gbogbo lati ronupiwada ki o si ye.
“Ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si iwa-ika” ati “ẹniti ndá ija silẹ larin awọn arakunrin” jẹ ohun kan naa. Iyatọ ti o wa laaarin wọn nikan ni ibi ti wọn gbe ṣiṣẹ ibi yii ati awọn ti wọn palara tabi ti wọn ṣì lọna.
A ṣe alaye fun ni wi pe iwa ika jẹ wahala tabi iyọnu ti o ti ọwọ ẹda wa. Ọlọrun pe wa si alaafia. O paṣẹ fun ni lati jẹ onipamọra, alaanu, oninuure ati oniwa-tutu. Ohun ti o lodi si eyi ni oniyọnu n ṣe. Ẹni ti o n da rogbodiyan silẹ tabi ti o n ni inudidun si i nigba ti awọn ẹlomiiran ba da a silẹ, dajudaju kò mu ifẹ Ẹni Mimọ ju lọ nì ṣẹ ti O fẹ ki gbogbo wa dabi Oun. O paṣẹ fun wa lati “mā lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa” (Heberu 12:14).
Irira ni ẹni ti o ba n da ija silẹ niwaju Ọlọrun, paapaa ju lọ bi o ba n da ija silẹ laaarin awọn arakunrin. Iru ẹni bẹẹ n lakaka ni tootọ lati da iṣẹ Ọlọrun rú ati lati ṣe ìdena Ijọba Kristi. Lọna bayii, o ti gba ẹmi aṣodisi-Kristi.
Nibi ti alaafia wa, ẹni ti o n da ija silẹ a maa da ogun silẹ. Nibi ti ifọkantan ara ẹni wa, oun a maa da aifọkantan ara ẹni silẹ. Nibi ti igbẹkẹle, igbagbọ ati ireti gbe wa, ẹni buburu ti Ọlọrun korira yoo maa da ṣíọ ọkan tabi gbogbo iwa rere wọnyi. Awọn kan n funrugbin nipa oore-ọfẹ ati ọgbọn Ọlọrun, ṣugbọn oun a maa fa irugbin ti wọn gbin tu. Awọn miiran n fi gbogbo ipa wọn ṣiṣẹ lati kọle ti igbi kò ni le bì wo, ti yoo wà fun itẹsiwaju Ijọba Ọlọrun, ṣugbọn ẹni irira yii n ṣiṣẹ nikọkọ lati bì eyi ti a gbe ro fun ọla ati ogo Ọlọrun nikan wó.
Adarugudu silẹ yii ki i saba sọ otitọ. A maa ṣeke, a si maa lo ayidayida. Oun kò ni i fi otitọ ṣe nitori iṣẹ rè̩ a maa gberu ninu eke ati nibi ti ẹni kin-in-ni gbe n wo ẹni keji pẹlu ifura. Oun a maa tẹle ipasẹ oluwa rè̩, ani Satani, ẹni ti i ṣe olufisun awọn arakunrin, oluwa rè̩ paapaa kò si jafara lati fun un ni gbogbo iranwọ ti o n fẹ lati mu ki iṣẹ buburu rè̩ ki o le gbilẹ kan.
Iṣọra ṣe Danindanin
Ẹ ma ṣe jẹ ki a fara mọ ọta ẹmi nipa ṣiṣe ohunkohun ti Ọlọrun korira, tabi ti o ṣe irira loju Rè̩. A le ri ninu ede ti a lo ninu ẹkọ wa pe ki i ṣe awọn ohun wọnni ti a darukọ nihin nikan ni Ọlọrun korira ṣugbọn O ka awọn ẹni ti o n ṣe wọn si ẹni irira.
A kò yẹ fun ifẹ Ọlọrun, aanu irubọ Rè̩ tabi iṣeun ifẹ Rè̩. S̩ugbọn O fi ohun rere ati ẹbun pipe wọnni fun wa nitori ifẹ, aanu ati iṣeun ifẹ Rè̩. Niwọn bi ẹwa iwa mímọ wọnyi ti jẹ pipe ti kò si lopin, eyi mu ki o ṣe e ṣe fun ẹda ti o buru ju lọ lati le ri wọn gba. Ọrun apaadi yoo jẹ ibi ti o buru jai nitori pe gbogbo awọn ti o wà nibẹ yoo mọ daju pe Ọlọrun korira wọn. Ki Ọlọrun ki o korira ẹni kan, ki ifẹ Ọlọrun si oluwarẹ ki o dẹkun, ki Ọlọrun si fa ọwọ aanu Rè̩ sẹyin, ki iṣẹun ifẹ Rè̩ si ẹni naa dẹkun jẹ ohun ti o buru jai ju ohun ti ahọn le royin lọ.
A dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori pe kò si ohun ti o yẹ ki o fa wa sinu ipo ipọnju ati ainireti yii. Ẹsẹ akọsori kekere kan ti a mọ dunju ti a si maa n kà nigbakuugba lati inu Bibeli wa to lati fun wa ni ireti ti a n fẹ. Bi a ba gba iṣẹ ti ẹsẹ akọsori yii ran si wa, ti a si gba Ẹbun ti Ọlọrun fi fun wa, awa yoo ni ayọ ayeraye, alaafia ti kò ṣe e fẹnusọ, ibukun ati ere ayebaye miiran wọnni ti Oun ti ṣeleri fun wa. A dupẹ pe “Ọlọrun fẹ araiye tobḝ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rè̩ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun”! (Johannu 3:16).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti a fi ni lati ṣọra nipa jijẹ onigbọwọ fun ẹlomiiran?
- Ki ni awọn ẹsẹ diẹ ti o ṣaaju ninu ẹkọ wa sọ fun wa lati ṣe bi a ba ti tọrùn bọ ajaga yii?
- Ki ni ẹda ti Ọlọrun lo bi apẹẹrẹ lati kọ wa lẹkọọ nipa iṣẹ ṣiṣe?
- Ki ni ere ọlẹ ṣiṣe nipa ohun ti i ṣe ti ẹmi tabi ti ara?
- Ki ni opin eniyan buburu?
- Darukọ awọn ohun meje ti Ọlọrun korira ti o si jẹ irira si I.
- Mu awọn nnkan wọnyi lọkọọkan, ki o sọ eredi rè̩ ti Ọlọrun fi korira awọn ohun meje wọnyi ati ki ni abayọrisi wọn bi a ba gba wọn laaye lai mu wọn kuro.
- Sọ ori ati ẹsẹ miiran ti o wà ninu Majẹmu Titun ati Laelae ti o fi ibi ti o wà ninu awọn ohun meje wọnyi hàn.
- Ki ni ireti ẹni ti o jẹbi nnkan wọnyi?
- Kọ Romu 5:8 sori, ki o si ka a fun awọn ti iwọ ro pe kò ni ireti ninu Ọlọrun.