Lesson 280 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Alaiṣõtọ enia, irira ni si awọn olododo; ẹniti o si ṣe aduro-ṣinṣin li ọna, irira ni si enia buburu” (Owe 29:27).Cross References
I Owe lati inu Ọgbọn Ọlọrun
1. Aidaniloju ohun aye yii mu ki a mọ pe o yẹ lati tẹle ipa-ọna ọgbọn nigba gbogbo, Owe 27:1; 28:22; 29:1; 25:6, 7, 27; Orin Dafidi 39:5; Jakọbu 4:13-15; 1Peteru 1:24
2. Yiyin ara ẹni ati ipọnni a maa ti ni sinu ewu, Owe 27:2, 5, 6, 14, 21; 28:23; 29:4, 5, 23; Jobu 32:21; Orin Dafidi 12:3; 1Tẹssalonika 2:1-6; Isaiah 47:10, 11; Esekiẹli 31:10-14; Obadiah 4; Matteu 23:12
3. Ibinu, irunu ati owu jẹ è̩ṣẹ buburu, Owe 27:3, 4; 29:21, 22; 14:17; 16:32; 23:17; Oniwasu 7:9; Jakọbu 1:19; 3:16; Orin Dafidi 37:1, 8; Matteu 5:22; Romu 13:13; 1Kọrinti 13:4; Galatia 5:26; Jakọbu 3:14, 15
4. A fi niniyelori ọrẹ tootọ han, Owe 27:9, 10, 15-17; 29:9; Oniwasu 4:9, 10; 1Samuẹli 18:1; Filippi 2:25; 2Timoteu 1:16, 17
5. Oungbẹ fun ohun ti ẹmi a maa mu ibukun ti ẹmi wa; lai si eyi, ọkàn a di rirù, Owe 27:7, 8, 19, 20; 28:18; 29:18; Matteu 5:6; Amọsi 8:11, 12; Isaiah 55:1-3; Johannu 4:14; 6:35; 7:37
6. Ohun ti o ga ju lọ laye yii ti a gbọdọ lepa lati ni ni ọgbọn Ọlọrun, Owe 27:11-13, 22; 29:3, 11, 20; 2:1-9; 4:7; Jobu 28:28; Matteu 7:24; 2Kronika 1:10-12; Jakọbu 1:5
7. Jijẹ oloootọ ninu iṣẹ wa si Ọlọrun ati eniyan a maa mu ere wa, Owe 27:18, 23-27; 28:19, 20; Efesu 6:5-8; Matteu 10:42; 24:31-46; Orin Dafidi 126:5, 6; Johannu 4:36
8. A fi iṣe, ihuwasi, ati ireti ainipẹkun ti awọn olododo ni we iṣe, ihuwasi ati ireti ainipẹkun ti eniyan buburu, Owe 28:1-18, 25, 26; 29:6-8, 24, 25; 14:32; Jobu 27:8; Orin Dafidi 10:1-18; 33:18; 71:5; 146:5; Iṣe Awọn Apọsteli 24:15; Jeremiah 17:5-8; 1Johannu 3:1-3
9. S̩iṣe ojusaju eniyan jẹ è̩ṣẹ si Ọlọrun ati si eniyan, Owe 28:21; 29:12-14, 26, 27; Lefitiku 19:15; Deuteronomi 1:17; Jobu 13:10; Jakọbu 2:1-9; Efesu 6:9
10. Iṣẹ obi ni lati ba ọmọde wi; iṣẹ ọmọde si ni lati bọwọ fun awọn obi, Owe 28;24; 29:15, 17, 21; 13:24; 19:18; 22:6, 15; 23:13; Ẹksodu 20:12; Efesu 6:1-4; Kolosse 3:20; Heberu 12:5-11
11. Aanu jẹ ọkan ninu awọn eso ododo, Owe 28;27, 28; 29:2, 7, 10; 3:3; Mika 6:8; Matteu 5:7; Jakọbu 2:13
12. Ija were a maa mu ọkàn rù ninu ohun ti ẹmi, ki i si ṣiṣẹ ire si ipa ti Ọlọrun, Owe 29:9, 11, 20, 22; 17:14; 20:3; Filippi 2:3; 2Timoteu 2:14, 23, 24; Titu 3:9; Jakọbu 3:16; 1Kọrinti 1:11; 3:3
13. Ododo yoo leke lẹyin gbogbo idojukọ, Owe 29:16, 27; Isaiah 3:10; Orin Dafidi 34:15; 37:3-9, 25, 35-37
Notes
ALAYÉẸkọ lati inu Iwe Owe
A le ṣe iwaasu lori ẹsẹ kọọkan ti o wà ninu ori iwe ti a yàn fun ẹkọ wa yii. Bi a ba ṣe akiyesi itọka, a o ri i pe oriṣiriṣi ẹkọ ni a kó pọ ninu awọn ori iwe mẹta ti a yàn yii. Ọpọlọpọ owe wọnyi ni o rọrun lati ye ni, to bẹẹ ti kò fi yẹ lati tun ṣe alaye, paapaa ju lọ bi a ba jẹ ẹni ti o n lo Bibeli ti o ni itọka ibi kan si ekeji, ti a si wo awọn ẹsẹ ti o tọka si ara wọn ninu Ọrọ Ọlọrun. Eredi itọka ati alaye ti a n ṣe ninu Iwe Aṣayan Ẹkọ Bibeli wọnyi ni lati mu ki akẹkọọ ni oye nipa awọn ẹkọ kọọkan ti a n kọ ati ibi ti awọn ẹsẹ ti o jẹ mọ awọn ẹkọ yii wa ninu Bibeli, to bẹẹ ti olukuluku akẹkọọ yoo fi le pin Ọrọ Otitọ bi o ti yẹ ati nipa bẹẹ ki o le gba ẹkọ ti Ọlọrun fẹ fun un ni kikún. Fun awọn àlaye wọnyi a ṣe akojọ diẹ ninu awọn koko ẹkọ ti a kò fi igba gbogbo mẹnu ba ninu awọn ẹkọ miiran.
Aidaniloju Ọjọ Ọla
Ọlọrun wi pe, “Kiyesi i, nisisiyi ni akokò itẹwọgbà, kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.” Ọrọ yii kan naa wa fun wa lọjọọjọ ninu irin-ajo wa ni gbogbo ọjọ aye wa. Pẹlu awọn ibomiiran gbogbo ninu Ọrọ Ọlọrun, Iwe Owe tun fun ni ni imọran, diẹ nihin ati diẹ lọhun lori ẹkọ yii. A ka a ninu iwe Owe pe: “Máṣe leri ara rẹ niti ọjọ ọla, nitoriti iwọ kò mọ ohun ti ọjọ ọla yio hù jade.”
Ninu ohunkohun ti o ba jẹ mọ igbala ọkàn wa, iwa alaigbọn ni pe ki a fi ohun ti o yẹ ki a lepa ki a si gbà loni di ọjọ ọla. Ninu ẹkọ wa yii, a le ri i pe Ọlọrun ki i ṣe ojusaju eniyan, bakan naa ni Oun ki i ṣe ojusaju ìgbà tabi ibì kan. O ṣe tan lati gbọ adura atọkanwa ẹni ti o ba ronupiwada, adura naa yoo si gbà nibikibi ti o wu ki a ti gba a. Ifẹ Ọlọrun ni lati gbọ iru adura bẹẹ pẹlu; igbagbọ ti o rú ọkàn adura bẹẹ soke, bi o tilẹ kere, yoo mu ki Ọlọrun fi igbagbọ ti o ju bẹẹ lọ kún un; ki ibukun igbala le jẹ ti ọkàn naa ti ebi ẹmi n pa.
Iwa omugọ ni lati fi ohun ti o jẹ mọ igbala ọkàn wa falẹ nitori pe a kò mọ boya ẹmi wa yoo di ọla. Iṣẹju kan pere le ṣe ayipada gbogbo igbesi-aye wa ni ayeraye. Iṣẹju kan tó lati mu ẹnikẹni ninu wa lọ si ọrun aremabọ. A kò mọ bi ọjọ naa ti sun mọ tosi to tabi bi o ti pẹ to. Boya iṣẹju kan ni o kù fun wa láyé. Bi a ba fi adura ti o le mu ki a ri idariji Ọlọrun gba di ọjọ ọla, o tumọ si eyi pe, a gba pe ti wa ni ọjọ ọla ti o le ṣalai ba wa ni ilẹ alaaye. A le ṣalai ri ọjọ ọla ti a ti yàn pe nigba naa ni a o gbadura ironupiwada ati nipa bayii ki a di ero ọrun apaadi.
Bakan naa ni o ri pẹlu gbogbo ohun ti a n ṣe nigbesi aye wa. A kò le fọwọ sọya ni ti ọjọ ọla. Ọla ki i ṣe ti wa afi bi Ọlọrun tikara Rẹ ba da ẹmi wa si lati ri i. Ọjọ oni nikan ni ti wa; bi a ba si lo o fun ọlá ati ogo Ọlọrun, ti a si n ṣe ohun ti ọwọ wa ri ni ṣiṣe pẹlu gbogbo ọkàn wa, nipa bayii a n mu gbogbo ifẹ Ọlọrun fun wa ṣẹ. Eyi kò tumọ si pe a kò gbọdọ ni ilepa kan ninu aye ti a le jijakadi fun. Eyi kò si fi han pe a kò gbọdọ foju sọna fun ohun ti o jẹ ifẹ Ọlọrun fun wa. Ohun ti a n sọ ni pe ohunkohun ti a ba n ṣe, tabi ti a n rò, ohunkohun ti a ba n pète – gbogbo rè̩ wa ni ọwọ Ọlọrun gẹgẹ bi ifẹ Rè̩ ti a fi han fun wa, niwọn bi O ba ti fun wa layè, oore-ọfẹ ati agbara lati mu un ṣẹ. Bi a ba kuna lati fi ti Ọlọrun pè ninu eto wa, dajudaju, a n ṣe lodi si ifẹ Rè̩ nitori ti O ti paṣẹ fun wa pe nigba ti a ba n ṣe eto wa o yẹ “ti ẹ bá fi wipe, bi Oluwa ba fẹ, awa o wà lāye, a o si ṣe eyi tabi eyini” (Jakọbu 4:15).
Yiyìn Ara Ẹni ati Ipọnni
Ọjọgbọn kan ti igba nì sọ bayii pe, “Ko si ẹyọ kan laaarin ogún ọlọgbọn eniyan ti o jẹ yin ara rè̩.” Awọn meji miiran tun sọ ohun ti o fara jọ eyi pẹlu; “Awọn apọnni ni ọta ti o buruju” ati “Ki a fẹ ara ẹni ni ipọnni ti o tobi ju lọ.” S̩ugbọn ede ti Ọrọ Ọlọrun lo lati bu è̩té̩ lu iwa è̩ṣẹ yii le ju ọrọ wọnyi lọ, nitori ti kò si ohun ti o lodi si ẹmi Ihinrere tootọ ju awọn iwa buburu wọnyi lọ. È̩ṣẹ wọnyi tete ran ọkàn si iparun ju eyikeyi lọ. Ẹṣẹ igberaga ti a ti kẹkọọ nipa rè̩ ṣaaju ninu iwe yii, ni o n ṣe okunfa awọn è̩ṣẹ mejeeji yii.
Ọrọ Ọlọrun sọ wi pe, “OLUWA yio ké gbogbo ète ipọnni kuro, ati ahọn ti nsọrọ ohun nla” (Orin Dafidi 12:3). Iwe Mimọ sọ bayii nipa ti ẹni ti o n yin ara rẹ: “Iwọ si ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi ni, kò si ẹlomiran lẹhin mi. Nitorina ni ibi yio ṣe ba ọ; iwọ ki yio mọ ibẹrẹ rè̩: ibi yio si ṣubu lù ọ; ti iwọ kì yio le mu kuro: idahoro yio deba ọ lojiji: iwọ kì yio si mọ” (Isaiah 47:10, 11). Kò ṣanfaani ki a ṣẹṣẹ maa wa orisun ọgbọn miiran kiri ju Ọrọ Ọlọrun lati mọ ki ni yoo jẹ ipin ati opin ẹni ti kò ba yọwọ kuro ninu è̩ṣẹ meji wọnyi.
Ibinu ati Owu
“Ẹni ibinu rú ija soke, ati ẹni ikannu pọ ni irekọja.” Olukuluku eniyan ni o ni iriri jamba ti ibinu ati irunu n ṣe – lati inu iriri ati iwa oun tikara rẹ ki o to ni iyipada ọkàn, bi o ba jẹ Onigbagbọ, tabi ninu igbesi-aye ati iwa awọn ti o n ba lo lọjọọjọ. Ọpọlọpọ ni o ti huwa ọdaran ti o buru jai nipasẹ imisi iwa ti ara wọnyi. Ẹmi ti bọ, dukia ti ṣegbe tabi kí o bọ sọwọ ole, wahala ẹda pọ si i, pẹẹ-ntuka ti bọ si agbo-ile, awọn ọmọ ti kò mọkan di ẹni ti a fi silẹ lai si itọju ninu aye buburu yii, nitori ibinu ati irunu.
S̩ugbọn Iwe Mimọ kò dakẹ. Nibẹ ni a gbe ka eyi pe, “Ibinu ni ìka, irunu si ni kikún-omi; ṣugbọn tani yio duro niwaju owú?” O han gbangba nihin yii pe bi ibinu ati irunu ti buru tó niwaju Ọlọrun, owu tun buru ju bẹẹ lọ. Irira ni gbogbo è̩ṣẹ wọnyi niwaju Ọlọrun, ẹnikẹni ti o ba si gba è̩ṣẹ wọnyi layè ninu ọkàn rè̩ kò ti i ri agbara Ọlọrun ti n gba ni kuro ninu è̩ṣẹ, bi bẹẹ kọ o ti di afasẹyin. Ẹlẹṣẹ ni oun i ṣe. Kò si labẹ aabo ati oore-ọfẹ Ọlọrun. Ọmọ èṣu ni oun i ṣe.
Awọn ẹlomiiran n jiyàn wi pe a ni lati ni iriri Isọdi-mimọ patapata -- iṣẹ oore-ọfẹ keji ti n tẹle idalare nipa igbagbọ ti o si n ṣaaju gbigba Ẹmi Mimọ ati ina – ki a to mu ibinu kuro ninu ọkàn. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọrun fi ye wa kedere pe Onigbagbọ ni lati bọ kuro ninu è̩ṣẹ wọnyi nigba ti a ba da a lare. O sọ bayii pe: “Njẹ awọn iṣẹ ti ara farahàn, ti iṣe wọnyi; ... ibinu, asọ ... arankàn ... ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin ... pe, awọn ti nṣe nkan bawọnni kì yio jogún ijọba Ọlọrun” (Galatia 5:19-21).
Ija
Ọjọgbọn miiran ni akoko ti wa yii ti o fara mọ ẹkọ Bibeli kọ akọsilẹ yii pe, “Irin-iṣẹ eṣu ni ìja è̩sìn.” Ẹmi Mimọ sọ fun wa bayii pe “nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá” (Owe 13:10). Ọlọrun ti paṣẹ fun wa pe ki a “fi ija silẹ” (Owe 17:14) ati pe “Ọlá ni fun enia lati ṣiwọ kuro ninu ìja” (Owe 20:3).
Awọn miiran lero pe kò si ohun ti o buru ninu ìja ati asọ bi o ba jẹ pe nipa ọran è̩sìn ni. Awọn kan naa sọ fun ni pe eke kò buru – ni kukuru, wọn n fi ye ni pe è̩ṣẹ ki i ṣe è̩ṣẹ mọ -- bi o ba ti jẹ pe nipa iṣẹ-ìsin wọn ni wọn gbe dá a. S̩ugbọn Ọlọrun ti O sọ ninu Ọrọ Rè̩ pe gbogbo awọn ti n ṣeke ni a o gbe ju sinu adagun ina ni O sọ pe: “Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararè̩ lọ” (Filippi 2:3). O si tun kilọ fun wa lati “yà kuro ninu ọrọ asan, nitoriti nwọn ó mā lọ siwaju ninu aiwa-bi-Ọlọrun.” O tun sọ fun wa pẹlu pe ki a yà kuro ninu ibeere wère ati alaini ẹkọ ninu, “bi o ti mọ pe nwọn a ma dá ìja silẹ”, nitori pe “Iranṣẹ Oluwa kò si gbọdọ jà; bikoṣe ki o jẹ ẹni pẹlẹ si enia gbogbo, ẹniti o le kọni, onisru, ẹniti yio mā kọ awọn aṣodi pẹlu iwa tutu; bi bọya Ọlọrun le fun wọn ni ironupiwada si imọ otitọ” (2Timoteu 2:16, 23-25). A si tun sọ fun wa pe ki a “yà kuro ni ìbere wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn” (Titu 3:9).
Ebi Ẹmi ati Ododo ti o S̩ẹgun
Afo kan wà ninu ọkàn ọmọ-eniyan ti awọn ohun igba isisiyi tabi ẹsìn adabọwọ kan kò le di bi kò ṣe sisìn Ọlọrun otitọ ati alaaye. Ọpọlọpọ eniyan ni o n gba ọna adabọwọ ara wọn lati tán ebi ati oungbẹ ninu agbara wọn, ṣugbọn Iwe Mimọ sọ wi pe “Oju enia ki ini itẹlọrun.” Ọrọ Iwe Mimọ ti o sọ bayii pe, “Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo” ti kún fun itunu to!
A le ni itẹlọrun, ṣugbọn ki i ṣe ninu awọn ohun ti aye yii. Awọn ti ebi n pa ti oungbẹ si n gbẹ si ipa ododo nikan ni o le ni itẹlọrun tootọ. Nitori naa a le wi pe awọn olododo nikan ni o ni alaafia tootọ. “Yio si dabi igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rè̩ jade li akokò rè̩; ewe rè̩ kì yio si rè̩; ati ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede” (Orin Dafidi 1:3).
A ti ri i ti ẹni iwa-ika fi ara rẹ gbilẹ bi igi ọpẹ, ṣugbọn o kọja lọ, kò si mọ. A wa a kiri, ṣugbọn a kò ri i. S̩ugbọn olododo, ani ẹni pipe a maa ni alaafia ni aye yii ati ni aye ti n bọ pẹlu. Ọkan ninu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ninu ẹkọ yii sọ bayii pe, “Nigbati awọn enia buburu ba n pọ si i, irekọja a pọ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn.” Awọn olododo yio “jẹ eso iṣe wọn” (Isaiah 3:10) wọn “yio gbà bi igi ọpẹ” (Orin Dafidi 92:12). Awọn olododo “yio ma ràn bi õrun ni ijọba Baba wọn” (Matteu 13:43). Awọn olododo ni yoo jẹ ẹgbẹ ọmọ ogun nla ti yoo tẹle Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa nigba ti O ba pada bọ ninu ogo lati gbe Ijọba Rè̩ kalẹ ninu aye yii; yoo si jọba fun ẹgbẹrun ọdun (Ifihan 19:14).
Ireti nla ologo! O le dabi ẹni pe eniyan buburu n gbilẹ, ṣugbọn ijiya ayeraye wà fun wọn dajudaju. Awọn oninunibini le maa halẹ ki wọn si maa tẹri awọn eniyan ba, ṣugbọn a o ṣi wọn lọwọ lojiji, a o si mu wọn lọ si ayeraye lai nireti, afi bi wọn ba ronupiwada ki wọn si kuro ni ọna buburu wọn. S̩ugbọn “awọn ọlọgbọn yio si ma tàn bi imọlẹ ofurufu: awọn ti o si nyi ọpọlọpọ pada si ododo yio si ma tàn bi irawọ lai ati lailai” (Daniẹli 12:3). “Ọpé̩ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi” (1Kọrinti 15:57).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni a n pe ni Owe?
- Ki ni a sọ fun ni nipa aidaniloju aye yii ati ihà ti a gbọdọ kọ si i ninu ẹkọ wa yii ati nibomiiran gbogbo ninu Bibeli?
- Sọ awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o fi han pe ohun buburu ni iyin-ara ẹni ati ipọnni.
- Ki ni è̩ṣẹ ti o pilẹ iyin ara-ẹni ati ipọnni?
- Ki ni awọn è̩ṣẹ miiran ti ibinu n sun ni lati dá?
- Ki ni awọn è̩ṣẹ miiran ti owu n sun ni lati dá?
- Ki ni ṣe ti ilepa ọgbọn Ọlọrun fi ni lati jé̩ ohun ti o leke lọkàn olukuluku eniyan ninu aye yii?
- Njẹ iṣé̩ obi ni lati maa ba awọn ọmọ wọn wi? Ihà wo ni o yẹ ki awọn ọmọde kọ si obi wọn?
- Ki ni ṣe ti ija fi jẹ iwa were? Ki ni ṣe ti o fi n mu rírù ba ọkàn ti kò si jẹ ki a le ṣe ohun pupọ ni aṣeyọri fun Ọlọrun?
- Sọ awọn ẹsẹ Bibeli ti o fi iṣẹgun awọn olododo hàn.