Iṣe Awọn Apọsteli 2:1-47

Lesson 281 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalẹmu, titi a o fi fi agbara wọ nyin, lati oke ọrun wá” (Luku 24:49).
Cross References

I Ifi Agbara Ẹmi Mimọ Wọ Ni gẹgẹ bi Iriri Kẹta ti Onigbagbọ

1. S̩iwaju iku Rè̩, Kristi ṣeleri iriri kẹta yii fun gbogbo awọn Onigbagbọ, Johannu 14:15-18, 26; 15:26, 27; 16:7-15; Luku 11:13; 24:49; Iṣe Awọn Apọsteli 1:4-8; Fi Matteu 3:11 we Johannu 1:33

2. Awọn Woli Majẹmu Laelae paapaa ti sọ asọtẹlẹ nipa ti itujade Ẹmi Mimọ, Matteu 13:17; 1Peteru 1:9-12; Joẹli 2:21-29; Isaiah 32:15; 59:20, 21; Esekiẹli 36:25-27; 39:27-29

3. Awọn apẹẹrẹ ti o wà ninu Majẹmu Laelae fi iriri mẹta ti o wa fun awọn Onigbagbọ ti isisiyi hàn:

4. (a) Ohun mẹta ti o ṣẹlẹ lori Oke Moria, Gẹnẹsisi 22:1-18; 1Kronika 21:18-27; 2Kronika 5:1-14

5. (b) Ipele mẹta ọtọọtọ ti o wà ninu Agọ-ajọ ati Tẹmpili nibi ti wọn ti n sin Ọlọrun, Ẹksodu 40:17-35; Fi Heberu 9:1-12 we 10:9-22

6. Awọn ti a ti sọ di mimọ nikan nipa ibuwọn È̩jẹ nì lẹẹkeji ni wọn le gbà agbara Ẹmi Mimọ, Heberu 12:14; 13:11, 12; Fi Lẹfitiku 4:1-12; 6:24-30 we 16:1-28; Efesu 5:25-27; Esekiẹli 36:22-29

II Dide Olutunu

1. Awọn ọmọ-ẹyin ọgọfa lọkunrin ati lobinrin wa ni iṣọkan, eyi ti o fi han pe a ti sọ wọn di mimọ, Iṣe Awọn Apọsteli 2:1; Heberu 2:11; Johannu 17:17-23; Orin Dafidi 133:1

2. Olutunu dé gẹgẹ bi Jesu ti ṣeleri, Iṣe Awọn Apọsteli 2:2-4

3. A fun ni ní ami ti o daju ti kò si ṣe e jiyàn rè̩ pe eyi yii ni Ẹmí Mimọ naa – Olutunu, ti a ti ṣeleri Rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 2:5-13, 16; Joẹli 2:28, 29

4. Gbogbo itujade Ẹmí Mimọ lẹyin eyi ni o ni ẹri kan naa bi ti iṣaaju, Iṣe Awọn Apọsteli 10:44-48; 15:7-9; 19:1-7; 1Kọrinti 14:18, 22

III Apọsteli ti o Kún fun Ẹmí Mimọ ati Iwaasu Rè̩

1. Peteru ti a fi Agbara Ẹmi ati aṣẹ titun yii wọ dide, o si waasu fun ijọ eniyan, Iṣe Awọn Apọsteli 2:14, 15

2. O fi idi iṣẹ-iranṣẹ rè̩ yii mulẹ nipa lilo Ọrọ Ọlọrun ti o fi aṣẹ ti o ri gba yii han gbangba, Iṣe Awọn Apọsteli 2:16-21; 2Timoteu 4:5; 2Peteru 1:19-21

3. Lẹyin ti o ti fi ẹri isọtẹlẹ yii han, O waasu nipa Jesu, Iṣe Awọn Apọsteli 2:22-36; 4:12; Johannu 10:7-9

IV Ohun Ti O S̩ẹlẹ nigba ti A Tu Ẹmí Mimọ jade sori Awọn ti o Fetisilẹ

1. Ileri Kristi ṣẹ, a si fi agbara ọtun fun awọn Apọsteli, Iṣe Awọn Apọsteli 1:8; 2:37, 43; 4:13, 33; 6:10

2. Ninu idahun Peteru ni a ri ileri iyanu fun awa ti o wà laye ni akoko Arọkuro Ojo yii, Iṣe Awọn Apọsteli 2:38-40

3. Ẹri nla ti ifiwọni Agbara Ẹmi Mimọ, ni awọn ami ti o maa n tẹle iṣẹ iranṣẹ awọn ti a fi agbara naa wọ, Iṣe Awọn Apọsteli 2:41-47; Marku 16:15-18

Notes
ALAYÉ

Gbogbo awọn Onigbagbọ tootọ lode oni ni o ni anfaani ologo, yala wọn mọ bẹẹ tabi wọn kò mọ. Akoko É̩mi Mimọ ni a wa yii – akoko Ijọ Ọlọrun. Igbà yii jẹ akoko ti a n fi ẹkunrẹrẹ iriri ibukún Ọlọrun fun gbogbo awọn ti o ba fi “igboya wá si ibi itẹ ore-ọfẹ.” Akoko yii ni awọn Woli Majẹmu Laelae n foju sọna si pẹlu iyanu ati ireti. Akoko yii ni nnkan wọnni ti awọn angẹli fẹ lati ri ṣẹlẹ. Akoko yii ni a le ri, ti a si le mọ, ti a si le gbà nnkan wọnni ti awọn ẹni mimọ igba nì fẹ ri, ti wọn fẹ mọ, ti wọn si fẹ gbà.

Abajọ ti Jesu fi sọ wi pe ẹni ti o kere ju lọ ninu Ijọba yii pọ ju ẹni ti o tobi ju lọ ni igbà Majẹmu Laelae! Ohun ti Jesu sọ kò fi han wi pe awa tayọ awọn ti igba nì ninu iwa mimọ, tabi ododo tabi iwa-bi-Ọlọrun, nitori pe ohunkohun ti o wu ki a jé̩ --ati eyikeyi ti awọn ti igbà nì jé̩ -- nipa oore-ọfẹ Ọlọrun ti o fara han ninu Kristi Jesu ni. Ohun ti Jesu n sọ fun wa ni pe ojuṣe ati afo ti a ni lati dí nipa ipe ti a pe wa tayọ ti wọn, paapaa ju lọ ayè ti a wà ni akoko ikẹyin yii nipa ojuṣe wa ni ti ipadabọ Rè̩ lẹẹkeji.

Ẹkun Ibukun Iriri

Nipa iyipada ninu ohun gbogbo bi ọdun ti n yi lu ọdun, itumọ awọn ọrọ miiran ninu ede ti a n fọ a maa yipada, nigba miiran ẹwẹ, ohun ti ọrọ miiran duro fun nisisiyi le fun ni ni iriri ọtun. Ni ọdun pupọ sẹyin, “ja-a-niyan-danwo” ni ede ti a maa n lo nigba ti a ba n sọrọ nipa iriri Onigbagbọ ti o daju; fun apẹẹrẹ, iriri ologo ti idalare ati isọdimimọ patapata. Ohun ti ọrọ yii duro fun nigba nì yatọ si ohun ti itumọ rè̩ jẹ ni ode-oni. Nigba naa a maa n pe iṣẹ oore-ọfẹ ti o daju ti Ọlọrun pese fun awọn eniyan Rè̩ ni “igbagbọ ja-a-niyan-danwo.” S̩ugbọn itumọ ọrọ yii ti yatọ si ti igba nì ninu ede asiko paapaa ju lọ nisisiyi ti ọkàn ọmọ-eniyan tè̩ si ati gbé ireti ati igbagbọ rè̩ kalẹ lori ọgbọn ayé ati ero kukuru ti ẹda. Kaka ki awọn eniyan ni iriri aanu ati oore-ọfẹ Ọlọrun lọjọ oni, ohun ti wọn n ṣe ni pe wọn n gbe e wo bi bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ; nitori eyi igbagbọ ja-a-niyan-danwo ko fi han bi ẹni pe a ni iriri ati idaniloju oore-ọfẹ igbala Ọlọrun yii gan an, agbara iwẹnumọ ati agbara Ẹmi Ọlọrun. Igbagbọ nipa iriri ni ede ti a n lo nisisiyi dipo igbagbọ ja-a-niyan-danwo, nitori pe ohun ti Ọlọrun le fi fun ni – ani eyi ti O n fi fun ni -- tayọ ohun ti a n gbe wo pe o ri bẹẹ tabi kò ri bẹẹ. Irirí ni, ti o daju gbangba, a si mọ bẹẹ, o fidi mulẹ ṣinṣin pẹlu.

Awọn ti igba nì ni iriri idariji è̩ṣẹ ati iwẹnumọ ọkàn. Wọn ni idalare ati isọdimimọ nipa itoye Ẹbọ Pipé ti Jesu n bọ wa rú, nipa wiwo Agbelebu nipa igbagbọ ti Ọlọrun fi sinu ọkàn wọn. Akọsilẹ nipa igbesi-aye wọn, ọrọ iwuri ati ipọnni ti a ri ka nipa wọn ninu Bibeli ati oungbẹ atọkanwa wọn ti aanu ati oore-ọfẹ Ọlọrun tẹlọrun fi han wa pe wọn ni idande kuro ninu è̩ṣẹ lọna ti kò yatọ si ti wa. A tọka si wọn ninu Majẹmu Titun gẹgẹ bi apẹẹrẹ igbagbọ ati iwa-bi-Ọlọrun (Iṣe Awọn Apọsteli 2:29, 30; 28:25; 2Peteru 1:21; Heberu 11). Nitori naa o daju pe nigba ti Jesu ṣeleri Olutunu, ati nigba ti O wi pe Olutunu naa kò ti i de, ati pe kò si le de bi kò ṣe pe Oun (Jesu) ba goke re Ọrun, ki i ṣe eyikeyii ninu awọn iṣẹ oore-ọfẹ mejeeji ti awọn ti igba Majẹmu Laelae lọkunrin ati lobinrin ri gbà lati igba nì ni o n tọka si. Agbara Ẹmi Mimọ ki i ṣe iriri isọdimimọ patapata, gẹgẹ bi awọn miiran ti n kọ ni, nitori pe a n sọ awọn eniyan di mimọ nigba laelae. Olutunu kò ti i de, bẹẹ ni ki yoo si de -- kò tilẹ le sọkalẹ -- sori awọn Onigbagbọ bi kò ṣe pe Jesu ba goke re Ọrun.

Maria, iya Jesu, jé̩ ẹni ti a ti sọ di mimọ, sibẹsibẹ o jẹ ọkan ninu awọn ti o duro, ti wọn si gba Ẹmí Mimọ (Iṣe Awọn Apọsteli 1:14). A kà ninu Iwe Mimọ pe isọdimimọ a maa mu ki a wà ni iṣọkan pẹlu ara wa ati pẹlu Ọlọrun (Johannu 17:21, 23; Heberu 2:11). A si tun ri kà pe awọn ọgọfa (120) eniyan ti o gbà ileri Baba wà ni iṣọkan (Iṣe Awọn Apọsteli 2:1). Kò si ọna miiran ti a tun le tumọ ẹsẹ Bibeli yii si ju pe gbogbo awọn ọgọfa eniyan naa ni a ti sọ di mimọ patapata.

Adura ti Jesu gbà fun isọdimimọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti gbà ṣaaju ọjọ Pẹntẹkọsti. Gbogbo wọn wà ni ọkàn kan ni ọjọ naa! Maria mimọ, iya Jesu, ti a ti sọ di mimọ wà ni ọkàn kan pẹlu Apọsteli nì ti a tun mu pada bọ sipo lẹyin ti o ti sé̩ Oluwa rè̩ ni ọjọ diẹ ṣiwaju. Apọsteli oniyemeji nì wà ni iṣọkan pẹlu awọn Apọsteli ti wọn n ṣafẹri ipo ọlá ninu ijọba Jesu. Ọkunrin ti o ti jẹ agbowo-ode ri ti awọn eniyan korira nì, wa ni iṣọkan pẹlu ẹni ti a le pe ni ajihinrere kin-in-ni laaarin awọn ọmọ-ẹyin -- ọkunrin ti o ro ihin ayọ dide Kristi fun ẹni ti yoo di alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ ninu Ọgba Ajara Oluwa.

Gbogbo wọn ni o wà ni ọkàn kan! Awọn wọnyi ni Ẹmí Mimọ ba le! Kò si ohun kan ti o le fun ni ni iru iṣọkan bẹẹ bi kò ṣe iṣẹ iwẹnumọ pipé. O ṣoro fun awọn ti a ti sọ di mimọ ati awọn ti a kò i ti sọ di mimọ lati wà ni iṣọkan. Gbogbo wọn gbọdọ ni iriri iṣẹ oore-ọfẹ keji ni igbesi-ayé wọn ki iru iṣọkan bẹẹ to le wa.

Kò ṣoro fun ni lati ri i nigba naa pe nigba ti a ba n sọrọ nipa ẹkunré̩rẹ awọn iriri ibukun ti o daju wọnyi, a n sọ nipa iṣisẹ mẹta ti a kò gbọdọ ṣe alai ni. Lọna kin-in-ni, a ni lati dari è̩ṣẹ wa ji wa ki a to le sọ wa di ẹbi Ọlọrun. Lọna keji ẹwẹ, a ni lati sọ wa di mimọ nipa ibuwọn Ẹjẹ nì lẹẹkeji ki a ba le dá aworan Ọlọrun ti a ti sọnu pada sinu ọkàn wa, eyiyii ni Iwe Mimọ pe ni ododo ati iwa mimọ. Lopin gbogbo rè̩, niwọn bi o ti ṣe e ṣe fun awọn ti igba Majẹmu Laelae lati ri awọn ìriri mejeeji wọnyi gba, ti o si daju pe awọn ọgọfa eniyan ti o wà ni Yara Oke tun ni iriri miiran ti o daju, eyi ti Jesu ti ṣeleri, ti awọn woli Majẹmu Laelae si sọ asọtẹlẹ pe awọn ti Majẹmu Titun ni ileri yii wa fun, a le ri i nigba naa pe iriri iṣisẹ mẹta ti o daju wà fun wa. Iriri nla ologo kẹta yii ni gbigbà Ẹmi Mimọ Olutunu ti Jesu sọ nipa rè̩ (Johannu 14:15-18, 26; 16:7-15). Eyi ni baptismu Ẹmi Mimọ ati iná ti Johannu Baptisti sọ nipa rè̩ (Matteu 3:11).

Baptismu Ẹmí Mimọ ati Ina

Nigba ti Jesu fi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ, O sọ fun wọn pe Olutunu yoo wa lati tọ wọn si ọna otitọ gbogbo, yoo fun wọn ni agbara fun iṣẹ isin, yoo bá araye wí niti è̩ṣẹ, ododo ati idajọ ti o n bọ wa. Gbogbo nnkan wọnyi ti ṣẹ, o si n ṣẹ lọwọlọwọ. Adura Jesu fun isọdimimọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ gbà, a si ti mu ilerí Rè̩ pe Oun yoo ran Ẹmí Mimọ ṣẹ.

A kò sọ fun awọn ọgọfa ọmọ-ẹyin nì bi Ẹmí Mimọ yoo ṣe fi ara Rè̩ han. Bẹẹ ni a kò sọ fun ni gan an bi Oun yoo ṣe wá, bi yoo ṣe fi ara Rè̩ han, tabi ohun gbogbo ti yoo fi wá ṣe, ti yoo ṣe ninu wa, tabi ti yoo ṣe nipasẹ wa nigba ti a ba rì wa bọ inu Rè̩. S̩ugbọn kò si iyemeji lọkàn awọn ọgọfa nì tabi lọkàn awọn ti o wà ni tosi nigba ti Ẹmí Mimọ dé. Ẹmí ki i saba fi ara Rè̩ han ni ọna kan naa, ṣugbọn awọn ohun kan wà ti Oun ti n ṣe nigba gbogbo, ti kì yoo si ṣe alai ṣe nigba kan. O ṣe pataki fun ni lati yẹ Ọrọ Ọlọrun wò lati mọ ki ni awọn ohun pataki wọnyi jẹ.

Lọna kin-in-ni, Ẹmi Olutunu a maa fun ni ni agbara fun iṣẹ-isin. Oun yoo si maa tọ wa. Ẹmí Mimọ yoo tọ wa si ọna otitọ gbogbo. Oun yoo rán wa leti ohun gbogbo. Nigba ti a ba fi Ẹmí Mimọ wọ wa, yoo maa gbe inu wa, ṣugbọn tẹlẹ ri, O wà pẹlu wa ni. Oun yoo ṣe wa ni ẹlẹri fun Kristi, yoo si ran wa jade lati tan ihinrere kalẹ. Ọpọlọpọ ninu awọn alafẹnujẹ Onigbagbọ lode oni ni o gbà pe Ẹmí Mimọ n ṣe gbogbo nnkan wọnyi. S̩ugbọn eyi nikan kọ ni O n ṣe; ki i si ṣe ẹri wọnyi nikan ni n fara han nigba ti O ba wọ inu Onigbagbọ.

Awọn ami ati ẹri miiran gbogbo fara han nigba itujade Akọrọ Ojo ni atetekọṣe. Awọn alatako ẹkọ Ọrọ Ọlọrun ti o yanju ketekete n jiyàn pe bi ọkan ninu awọn ami iṣaaju ba jé̩ ohun danindanin ti a gbọdọ ni loni, a kò gbọdọ gboju fo awọn iyoku dá. Laisi ani-ani, ohun ti o ni lati ṣẹlẹ ni ọjọ nla naa, ti ilana ti atijọ kọja lọ, ti Majẹmu Titun si bẹrẹ pẹlu gbogbo ẹkunré̩rẹ iriri ni lati jé̩ ohun nla gidigidi. Bi a ba tilẹ wo bi ọjọ naa ti ṣe pataki to, o ya ni lẹnu bi ohun ti o ṣẹlẹ kò fi pọ ju bẹẹ lọ. A mu Ileri naa ṣẹ. Olutunu naa ti de. Okunkun ti o ṣú dudu ti rekọja, a si ti bẹrẹ si fun ni ni ẹkunré̩rẹ ibukún. Otitọ ni, ọpọlọpọ iṣipaya ati ami ni o fara han nigba nì, iru eyi ti kò si mọ ni akoko yii. Kò le ṣe alai ri bẹẹ bi a ba wo bi ọjọ naa ti tobi tó ati bi iṣẹlẹ naa ti jé̩ ohun ribiribi tó.

S̩ugbọn ẹ jẹ ki a yẹ awọn ami ati iṣipaya wọnyi wo. Ẹfuufu lile si wa. Awa paapaa kò ha ti ni iriri ẹfuufu lile bayii nigba ti Ẹmí Ọlọrun ba sọkalẹ saarin awọn ọmọ Ọlọrun, bi wọn ti n ṣọna, lati kún inu ẹni kan ati lati fun un ni agbara fun iṣẹ isin ninu Ọgba Ajara Ọlọrun? O ṣe e ṣe ki a má fi eti ode-ara gbọ iro naa ni akoko yii, ṣugbọn bakan naa ni iṣẹ Ẹmí. Ohun gbogbo ti Ọlọrun wi pe Ẹmí Mimọ yoo ṣe fun ẹni ti n wa iriri yii ni o n ṣe nisisiyi gẹgẹ bi ti igba nì.

“Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rè̩ o si bà le olukuluku wọn” ni akoko itujade Akọrọ Ojo ni atetekọṣe; eyi paapaa ti ri bẹẹ, nipa ti ẹmi ni akoko Arọkuro Ojo. Iná ti a le foju ri kò ṣé̩ yọ mọ lati igbà itujade iṣaaju, ṣugbọn iṣẹ ti Ẹmi Mimọ n ṣe ati awọn ẹri ti o ti ṣeleri jẹ ọkan naa nisisiyi gẹgẹ bi ti igba nì.

Ọpọlọpọ ariyanjiyan ati iyemeji ni o ti wà ninu ọkàn awọn eniyan lori ẹri kan ti o kù ti a fẹ mẹnu kan yii. S̩ugbọn eyi kò yẹ ki o ri bẹẹ. Kò gbọdọ si iyemeji rara. Bibeli sọ fun ni pe gbogbo awọn ọgọfa (120) wọnyi ni a fi Ẹmí Mimọ kún, ṣugbọn pupọ ninu awọn alaigbagbọ ni kò fẹ fara mọ iyoku ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun naa. O sọ bayii pe gbogbo wọn si “bè̩rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn li ohùn.”

I ha ṣe pe ami yii kò si mọ? Igbà ibẹrẹ Ijọ nikan ha ni ami yii wa fun? Ni tootọ, diẹ ninu awọn ami naa jé̩ ti ọjọ Pẹntekọsti ni akọkọbẹrẹ, a gbagbọ bẹẹ, o si han pẹlu pe a kò tun fi iru ami bẹẹ fun ni lẹyin ọjọ yii! Gbogbo wọn kún fun Ẹmí Mimọ; ileri naa wa fun wa bakan naa loni ati fun awọn pẹlu. Pẹlupẹlu, gbogbo wọn ni o fi ede miiran sọrọ gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn ni ohùn. Ẹri yii ki i ṣe fun ọjọ Pẹntekọsti nikan, ṣugbọn o wà fun awa naa loni. Eyi jẹ ami ti Bibeli fi lelẹ fun ẹri gbigba agbara Ẹmí Mimọ ati iná. Eyi ni edidi Ẹmí Mimọ ti o fi han pe iṣẹ naa ti ṣe. Gbogbo ẹni ti o ba ri ẹbun agbara yii gba yoo ri i pe Ọlọrun gbà ètè ati ahọn wọn, wọn ó si bẹrẹ si yin Ọlọrun pẹlu ède ti ẹni ti n sọ ọ kò mọ tẹlẹ ri, ṣugbọn ede kan pato ni, ti o ṣe e ṣe ki ẹni ti o wà ni tosi gbọ, ani nigba pupọ ni awọn ẹni ti o wà ni tosi n gbọ ède yii.

Dajudaju eyi tayọ sisọ ọrọ jagba-jagba, were-were ti kò ni itumọ. Ki i ṣe ohun ti a kò le ṣakoso rè̩ ti yoo mu ki a maa gbọn pè̩pè̩ tabi ki a maa ta-lu-gi-ta-lọpẹ ki a si maa fo ṣanlẹ. Ki i ṣe èdè ti ẹnikẹni kò mọ itumọ rè̩ ni aye yii. Ede kan pato ti o le tete ye ni ni, ati eyi ti awọn eniyan orilẹ-ède ti o n sọ ède yii le mọ ki wọn si jẹri si bi wọn ba wa ni tosi. Ọrọ ti o ja gaara, ti o si kún fun ọgbọn ni; eyi ti o n ti inu Ọlọrun wa, ti Ẹmí Mimọ si n gbe jade lati ètè amọ yii. Ki i ṣe ohun ti o n mu Ẹmí Ọlọrun ti o wà ninu awọn ẹni ti o wà ni tosi binu, ṣugbọn Oun a maa gba ẹnu awọn eniyan sọrọ to bẹẹ ti gbogbo awọn ẹni ti o ba wà nibẹ le ri ibukun, imulọkanle ati isọji Ẹmí gba.

Ami ti Bibeli fi lelẹ yii ha tun fara han nigba miiran bi? Bẹẹ ni, nigba ti awọn ara ile Kọrneliu gba Ẹmí Mimọ ni nnkan bi ọdun mẹjọ lẹyin Ọjọ Pẹntekọsti, wọn fi oniruuru ède sọrọ, wọn si n yin Ọlọrun logo (Iṣe Awọn Apọsteli 10:44-48; 15:7-9). Lẹyin ọdun mẹtalelogun ti a tu Ẹmí Mimọ jade ni iṣaaju, Paulu lọ si Efesu, “nwọn si nfọ ède miran” (Iṣe Awọn Apọsteli 19:1-7). Ni igba mejeeji wọnyi, kò si akọsilẹ wi pe “iró ẹfufu lile” wà tabi pe “ẹla ahọn bi ti iná” bà le wọn, ṣugbọn Ọlọrun yi ahọn wọn pada lati sọ ède titun gẹgẹ bi ẹri Bibeli fun iṣẹ aṣepe ti fifi Ẹmí Mimọ wọ ni. Iṣẹ Ẹmí yii kò pin si ọjọ kin-in-ni ti a kọ fi I fun ni, ṣugbọn o tun fara han ni igba mejeeji ti a ti mẹnukan yii, lai sọ ohunkohun nipa ẹgbẹẹgbẹrun igbà miiran gbogbo ninu itan Ijọ Ọlọrun, nigba ti a tun ti tu Ẹmí Mimọ jade.

Arọkuro Ojo

Nigba ti Peteru ṣe iwaasu iyanu rè̩ ni Ọjọ Pẹntekọsti, o fi asọtẹlẹ woli Joẹli gbe ọrọ rè̩ lẹsẹ nipa ohun nla ti o ṣẹlẹ. Fi ara balẹ kà ọrọ iwaasu rè̩, iwọ yoo si rii pe apa kan ninu asọtẹlẹ Joẹli nikan ni o mẹnu kan. Apa kan ninu ọrọ ti Peteru fi pari iwaasu rè̩ ni pe “fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè.” Nitori naa, asọtẹlẹ yii tabi fifi Ẹmí Mimọ wọ ni gẹgẹ bi ti ọjọ Pẹntekọsti ki i ṣe fun akoko awọn Apọsteli nikan. Ileri naa wa fun “gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wà ó pè;” o wà fun gbogbo awọn ti o “jina rére.” Ileri ti o wà ninu asọtẹlẹ yii jẹ ti wa pẹlu. Nitori naa bi a ba n rin ninu ẹkunré̩rẹ imọlẹ Ihinrere – ti a si n ṣe afẹri awọn iriri Onigbagbọ ni ẹkunré̩rẹ -- awa pẹlu yoo ri Ẹmí Mimọ gbà.

Awa naa pẹlu yoo ha fi ède titun sọrọ nigba naa, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wa ni ohun? Dajudaju, lai si aniani! Agbara Ọlọrun, Etò Rè̩, Ọrọ Rè̩, ati awọn ileri Rè̩ wa bakan naa lana, loni ati titi lae. Ifedefọ gẹgẹ bi Ẹmí ti fun ni ni ohun jẹ ẹri ti Bibeli fi fun ni nipa aṣepari iṣẹ yii. Ẹri yii ṣe danindanin lọjọ oni, gẹgẹ bi o ti ṣe pataki ní ọjọ kin-in-ni nì ti a tú Ẹmí Mimọ jade ati igbà miiran gbogbo lẹyin naa ti a kọ akọsilẹ rè̩ fun wa.

Niwọn bi apa kan ninu asọtẹlẹ Joẹli ti Peteru lo ninu iwaasu rè̩ ti jẹ mọ itujade Ẹmí Mimọ ni Ọjọ Pẹntekọsti nikan, o yẹ ki a yẹ gbogbo asọtẹlẹ naa wo lati ri awọn nnkan wọnni ti o jẹ mọ wa. Joẹli sọ asọtẹlẹ itujade oriṣi meji: ekinni yoo dabi akọrọ ojo ti ilẹ Palẹstini, ekeji yoo dabi arọkuro ojo ṣaaju igba ikore. Akọrọ ojo ni a fi n gbin irugbin ni ilẹ Palẹstini, arọkuro ni o si n mu eso gbó fun ikore. Bakan naa ni itujade Ẹmí Mimọ yoo ri. Akọrọ Ojo ni lati fi ẹsẹ Ijọ Ọlọrun ti akoko Majẹmu Titun yii mulẹ -- ni ibẹrẹ idagbasoke rè̩. Arọkuro Ojo wa fun aṣepe Ijọ Ọlọrun fun ikore.

Fiyesi awọn nnkan wọnni ti Joẹli mẹnukan nipa awọn itujade wọnyi. A kò sọ akoko ti Akọrọ Ojo yoo rọ fun ni, ṣugbọn a sọ akoko ti Arọkuro Ojo yoo rọ fun ni pato pe oṣu kin-in-ni ọdun awọn Ju ni yoo jẹ. A sọ fun ni pe akoko ti eyi ba ṣẹlẹ ni yoo jẹ opin aye!

Bọya a le wi pe awọn Ọmọ Israẹli nikan ni asọtẹlẹ wọnyi wà fun ati pe awọn asọtẹlẹ nipa Arọkuro Ojo tọka si akoko ipadabọ awọn Ju, bi kò ṣe pe Apọsteli ni fi eyi kún un pẹlu pe ileri yii wà fun awọn ti o jinnà rére pẹlu, ani awọn ti Oluwa yoo pe. A kò kà awọn Ju si orilẹ-ède ti o “jìna rére.” Awọn Keferi ni ọrọ yii tọka si, awọn ni a si maa n sọ pe o wà “lokere rére”, “lode,” “alejo,” “igi oróro igbé̩.” Itumọ meji ni ọrọ asọtẹlẹ yii ni, otitọ ni eyi. A kò sọ pe awọn Keferi ti igbà nì nikan ni a tọka si bi awọn ti o “jina rére,” bakan naa ni ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii kò tọka si awọn Onigbagbọ ti o “jina rére” ni akoko igba naa -- awọn ti o n wa agbara Ẹmí Mimọ ni akoko Arọkuro Ojo. Ileri yii wa fun oriṣi awọn eniyan (Onigbagbọ) meji wọnyi.

Ifedefọ gẹgẹ bi Ẹmí ti fun ni ni ohùn jẹ ọkan ninu awọn ohun ti Ọlọrun ṣeleri pe Oun yoo ṣe ni akoko itujade kọọkan. “Enia gbogbo” – Ju ati Keferi – yoo ri I gbà; a si fi eyi kún un pẹlu pe, “Awọn ọmọ nyin ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ.” Awọn ohun ti o tun fi ẹsẹ awọn itọka wọnyi mulẹ gẹgẹ bi aṣẹ ati iyanu to wà ninu ifedefọ loni ni awọn ohun iyanu miiran gbogbo ti Ọlọrun tun ṣeleri pẹlu pe yoo ṣẹlẹ. A o maa fi ẹbun ala ati iran fun ni; niti pe gbogbo ẹni ti o gba Ẹmí Mimọ le ṣalai ni eyikeyi ninu awọn ẹbun mejeeji wọnyi han gbangba, nitori pe awọn kan yoo maa la ala, awọn miiran yoo si maa riran.

Ni oṣu kẹrin, ọdun 1906, ti i ṣe oṣu kin-in-ni ọdun awọn Ju, ni Los Angeles – ni Amẹrika ati ni deedee akoko kan naa ni ibi pupọ ni aye – a tu Ẹmí Mimọ jade sori awọn wọnni ti a ti sọ di mimọ patapata ti o n duro de ileri Baba. Asọtẹlẹ Joẹli ṣẹ titi kan oṣu naa gan an ti o sọ fun ni, gbogbo awọn ami kan naa ti Ẹmí Mimọ fun ni, ti a kọ silẹ pe o han nigba aye awọn Apọsteli ni o tun han ni ipilẹṣẹ itujade Arọkuro Ojo naa. Gbogbo awọn ti a fi Ẹmí Mimọ kún ni o ti ni isọdimimọ tẹlẹ. Ẹmí Mimọ fi agbara fun wọn fun iṣẹ isin nigba ti O bà le wọn: gbogbo ètè ti o dakẹ jẹjẹ tẹlẹ ri wa bẹrẹsi jà gidigidi fun Igbagbọ, awọn ojo adakẹjẹjẹ ti wọn ki i fọhun rara tẹlẹ ri wa di onigboya eniyan Ọlọrun lọkunrin ati lobinrin. Wọn fi ède titun sọrọ gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn ni ohun; lai si iyatọ si ti igba mẹtẹẹta ti a kọ sinu Bibeli. Lẹẹkan si i awọn ọmọ-ẹyin tun jade lati tan Ihinrere ka gbogbo agbaye pẹlu agbara Ẹmí Mimọ, Ẹmí Olutunu nì si n ṣe amọna wọn.

Ko si ohunkohun ninu ọkàn ẹni ti oungbẹ ododo n gbẹ ti o n fẹ lati diwọn tabi sẹ eyikeyi ninu iṣẹ Ọlọrun ninu ọkàn awọn eniyan. Gbogbo awọn ti “ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo” a maa fi itara ṣe afẹri lati gba gbogbo ibukun ti Ọlọrun fẹ fi fun wọn. Bi iyemeji ba wà ninu ẹni kan nitori pe wọn jẹ ope tabi nitori ero ti o ti wà lọkàn wọn tẹlẹ ri, lẹsẹkẹsẹ ni Ẹmí Mimọ yoo mu iyemeji bẹẹ kuro, nitori o ti ṣeleri lati tọ wa si ọna Otitọ gbogbo. O wà ninu aye loni, Oun yoo si tọ gbogbo awọn ti o ba fẹ itọni, O wa pẹlu gbogbo awọn ti ọkàn wọn n fa si Ọrun; nigba ti wọn ba si gba ibukun iriri ologo yii sinu ọkàn wọn, Oun kì yoo wa pẹlu wọn nikan, ṣugbọn yoo tọ wọn wá ninu irẹpọ ọtun. Lati igba naa lọ, ati niwọn igba ti wọn ba jẹ oloootọ si Ọlọrun, Oun yoo maa gbe inu wọn. Ọkan ninu awọn ami pe O n gbe inu wọn ni pe nigba ti O wọ inu wọn O gba ẹnu wọn sọrọ ni ède ti wọn kò mọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ni akoko wo ni Kristi ṣeleri Olutunu? Tọka si diẹ ninu awọn ileri wọnni bi iwọ ba le ṣe bẹẹ.
  2. Awọn asọtẹlẹ Majẹmu Laelae wo ni o sọ fun wa nipa itujade Ẹmí Mimọ?
  3. S̩e alaye bi a ti fi awọn iriri mẹtẹẹta wọnyi han ni apẹẹrẹ ti Majẹmu Laelae.
  4. Ẹsẹ Bibeli wo ni o fun ni ni ikiya lati sọ pe ẹnikẹni ti o ba n wa Ẹmí Mimọ ni lati kọ ni isọdimimọ?
  5. Sọ awọn ohun ti o dọgba ninu akọsilẹ iyasimimọ Tẹmpili Sọlomọni ati itujade Ẹmí Mimọ ni Yara Oke.
  6. Ki ni Ẹri Bibeli nipa fifi agbara Ẹmí Mimọ wọ ni? Njẹ iru ẹrí yii tun fara han nigba wọnni ti a tun fi Ẹmí Mimọ wọ ni ni ìgba aye awọn Apọsteli? Ami yii ha fara han ni akọbẹrẹ itujade ti Arọkuro Ojo? Awọn ti n gba Ẹmí Mimọ loni ha n ri ẹri kan naa?
  7. Ka Heberu 13:8 Ki o si sọ ohun ti ẹsẹ yii ni i ṣe pẹlu ẹri Bibeli nipa fifi Ẹmí Mimọ wọ ni lọjọ oni.
  8. Anfaani wo ni irírí ologo yii ṣe ninu iṣẹ iranṣẹ awọn Apọsteli? Sọ iyatọ ti o wà ninu igbesi-aye ẹni kọọkan ninu awọn Apọsteli ki wọn to gba Ẹmí Mimọ ati lẹyin ti wọn gbà Ẹmí Mimọ?
  9. Ki ni itumọ pe ki a ṣe iṣẹ-iranṣẹ ẹni ni aṣepe?
  10. Kọ Iṣe Awọn Apọsteli 2:39 sori ki o si ka ileri ti a ṣe nipa awa ti igba ikẹyin yii.