Lesson 282 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dè̩ṣẹ, a o dari ji i” (Jakọbu 5:15).Cross References
I S̩iṣe Iṣẹ Ọlọrun
1. A mu ọkunrin arọ kan lara da gẹgẹ bi ileri Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 3:1-10; Marku 16:18; Johannu 14:12-14
2. Ọlọrun fi agbara iṣẹ iyanu fun Ijọ, ṣugbọn nipa akoso ati imisi Ẹmi Mimọ ni a le lo wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 3:11, 12; 1Kọrinti 12:4-11, 28-31; Romu 12:3-8
3. Igbagbọ ninu Kristi ni agbara ti ọkunrin arọ naa fi ri imularada, Iṣe Awọn Apọsteli 3:13-16; 14:9; Heberu 11:6; Matteu 8:16-18
4. Peteru gba ijọ eniyan niyanju lati ronupiwada è̩ṣẹ wọn ati lati yipada si Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 3:17-26; 5:28-32; 14:15-18
Notes
ALAYEAgbara lati Oke Wá
Jesu paṣẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe: “Ẹ joko ni ilu Jerusalẹmu, titi a o fi fi agbara wọ nyin, lati oke ọrun wá” (Luku 24:49). Wọn gbọran si aṣẹ yii, wọn si ti gba agbara Ẹmí Mimọ ati iná. Agbara lati waasu Ihinrere Jesu Kristi jẹ ti wọn, Ọlọrun si jẹri si agbara naa nipa ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ti o n tẹle iwaasu wọn.
Jesu ṣe ileri fun awọn eniyan Rè̩ pe: “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ … nwọn o gbé ọwọ le awọn olokunrun, ara wọn ó da” (Marku 16:17, 18). Ileri yii si ti ṣẹ loju wọn; iwosan ọkunrin ti o yarọ, nipa aṣẹ Peteru ati Johannu tun jẹ ẹri pe Ọlọrun jẹ oloootọ si ileri Rè̩. Igba pupọ ni Jesu n wo awọn eniyan sàn lati fi agbara Rè̩ han ati lati fi han pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe. Igba pupọ ni O si n lo eyi lati fun wọn ni igbagbọ aaye ninu Rè̩ pe Oun lagbara lati fi è̩ṣẹ wọn ji wọn. Iṣẹ iyanu nla yii tun fi idi ẹri ajinde Rè̩ ati pe Ẹni Ayeraye ni Oun i ṣe mulẹ.
Iwosan ọkunrin arọ ti o wà ni Tẹmpili ki i ṣe ohun ti Peteru ati Johannu dá ṣe ninu ara wọn lai si iranwọ tabi imisi Ọlọrun. Bibeli sọ ni ibi pupọ pe Ẹmi Ọlọrun ni Olukọ ati Amọna Ijọ Kristi nigba ti Jesu ti fi aye silẹ. (Ka Johannu 14:16, 17, 26; 16:7-15). Jesu ti sọ fun awọn ọmọ ẹyin Rè̩ pe, “Ni yiyara yin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan” (Johannu 15:5). (Ka Johannu 8:28; 9:33 pẹlu). Lẹyin ti Jesu ti fi ayé silẹ, Ẹmí Mimọ ni O n ba iṣẹ Ọlọrun ti Jesu ti gbe kalẹ lọ.
Ẹmí Mimọ kò si labẹ akoso eniyan nigba kan ri. Ọlọrun ni olubori ninu ohun gbogbo; awọn eniyan Ọlọrun paapaa ti i ṣe olufọkansin ju lọ wa labẹ akoso Ẹmí Mimọ. Ọlọrun fi otitọ yii ye awọn eniyan Rè̩ nigba ti O beere pe ta ni ninu wọn ti o le fi ọna han Oun tabi ti o le kọ Oun. Ọlọrun wi pe: “Tali o ti tọ Ẹmí OLUWA, tabi ti iṣe igbimọ rè̩ ti o kọ ọ? Tali o mba gbìmọ, tali o si kọ ọ lẹkọ, ti o si kọ ọ ni ọna idajọ, ti o si kọ ọ ni ìmọ, ti o si fi ọna oye hàn a?” (Isaiah 40:13, 14). “Nitori tali o mọ inu Oluwa? tabi tani iṣe igbìmọ rè̩” (Romu 11:34).
Otitọ nipa itọni ati iṣẹ Ẹmi Mimọ ni a n tẹnu mọ gidigidi ninu ẹkọ yii nitori pe awọn miiran n bẹ ti yoo fẹ tọka si ọkunrin arọ ti a mẹnu kan ninu ẹkọ wa yii lati fi han pe eniyan le gba agbara lọdọ Ọlọrun lati wo ẹnikẹni ti wọn ba fẹ san, gẹgẹ bi o ba ti tọ loju wọn lai fi ifẹ ati itọni Ọlọrun pe. Bi o tilẹ jẹ pe a kò ri kà ninu ẹkọ wa pato pe Ọlọrun rú igbagbọ Peteru ati Johannu soke fun iwosan ọkunrin arọ yii, sibẹ a gbagbọ pe Ọlọrun ni o dari wọn lati ṣe e, kò si sí ibikibi ninu Iwe Mimọ ti o lodi si ero bayii.
A kò ti i kọ Ọrọ Ọlọrun ti a mọ ni Majẹmu Titun lọjọ oni silẹ nigba naa, Ọlọrun si n fẹ ki iru iṣẹ iyanu bayii ki o ṣe ni gbangba fun ẹri ti o daju nipa ajinde Kristi ati otitọ Ọrọ Rè̩. Ogunlọgọ alaigbagbọ ni o yipada si Ọlọrun nipa iṣẹ iyanu bawọnnì. Iṣẹ iyanu kò dẹkun si ìgba laelae nikan, Ọlọrun n ṣe iṣẹ iyanu sibẹsibẹ. Akọsilẹ Ọrọ Ọlọrun wà ni ikawọ wa lonii, eyi si ni iṣipaya ifẹ Ọlọrun ti o ga ju lọ ti yoo fi fun araye titi Kristi yoo fi pada bọ lẹẹkeji. Iṣẹ iyanu kò wa lati dipo iwaasu Ọrọ Ọlọrun lati mu awọn eniyan wa si ironupiwada ati igbala. Iṣẹ iyanu ti o ga ju lọ ti Ọlọrun ṣe ni iyipada ọkàn bi wọn ti gbagbọ ninu Kristi si igbala lẹyin ti wọṅ ti gbọ Ọrọ Ọlọrun!
A mọ pe oye nnkan wọnyi ye Peteru nipa ọrọ ati iwaasu rè̩ si awọn eniyan ti o pejọ lẹyin ti a ti wo ọkunrin arọ naa san. O dabi ẹni pe awọn diẹ ninu awọn ti o pejọ ni ero pe Peteru ati Johannu ni o wo ọkunrin arọ naa san ninu agbara wọn. Ọrọ ti Peteru sọ fun awọn ti o pejọ ṣe pataki lọpọlọpọ. “Ẹnyin enia Israẹli, ẽṣe ti hà fi n ṣe nyin si eyi? tabi ẽṣe ti ẹnyin fi tẹjumọ wa, bi ẹnipe agbara tabi iwa-mimọ wa li awa fi ṣe ti ọkunrin yi fi nrìn? …orukọ rè̩, nipa igbagbọ ninu orukọ rè̩, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ: ati igbagbọ nipa rè̩ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin” (Iṣe Awọn Apọsteli 3:12, 16).
Igbagbọ ninu Orukọ Rè̩
Peteru kò jafara lati fi ogo fun Kristi fun iwosan arọ naa. O tè̩ ẹ mọ awọn ti o pejọ leti pe igbagbọ ninu orukọ Jesu Kristi ni o rán agbara iwosan ọkunrin arọ naa sọkalẹ.
Ọlọrun ki i ṣe iṣẹ iyanu lati té̩ ọfintoto ẹda lọrun (Matteu 12:38, 39). Ọpọlọpọ oniyemeji tì kò mọkan ni wọṅ ti yipada si Ọlọrun nitori pe Ọlọrun wo wọn san tabi ki o ṣe iṣẹ iyanu miiran fun wọn ni akoko iṣoro. Nigba miiran iṣẹ iyanu kan a maa jẹ ki titobi Ọlọrun di mimọ dajudaju fun eniyan ju bi ohunkohun miiran ti le fi han fun un lọ. Ọlọrun a maa fi agbara ipa Rè̩ ati ododo Rè̩ han fun awọn ọkàn ti o n fẹ otitọ, nitori ti O n fẹ ki awọn eniyan ki o gba Oun gbọ. Ohun pupọ ni Ọlọrun n ṣe lati ru igbagbọ wọn soke, ki wọn le yipada, ki a si fi è̩ṣẹ wọn ji. Iwosan ọkunrin arọ yii jẹ ọkan ninu ọna bẹẹ.
Bi Peteru ti mọ pe eredi iṣẹ iyanu ti Jesu n ṣe ni pe ki awọn eniyan le gba Oun gbọ gẹgẹ bi Kristi Ọmọ Ọlọrun, ati pe Oun lagbara lati dari è̩ṣẹ wọn ji, lẹsẹkẹsẹ, Peteru fa ọkàn awọn eniyan kuro lọdọ ọkunrin arọ nì sọdọ Ẹni ti o ṣe iṣẹ iyanu naa. (Ka Marku 2:1-12). Peteru ran wọn leti kikọ ti wọn ti kọ Jesu gẹgẹ bi Kristi naa, ati bi wọṅ ti lohùn si ikú Rè̩ pe ki a kan An mọ agbelebu, ati bi Ọlọrun si ti n beere lọwọ wọn lati ronupiwada nisisiyi. O han gbangba lai si iyemeji pe ohun ti Peteru sọ tọna, o si tọ, ani pe o fi han fun awọn eniyan pe ohun danindanin ni fun wọn lati ni igbala, kàka ki oun i ba fi tẹnumọ agbara Ọlọrun lati wosan, nitori pe ẹgbẹẹdọgbọn eniyan ni o yipada si Kristi nipa iwaasu Peteru.
Iwosan nipa Agbara Ọlọrun
Ọpọlọpọ awọn ti o kún fun àgálámàṣà, ti wọn n fi ẹkọ Bibeli nipa iwosan nipa agbara Ọlọrun ṣòwò ṣe jamba pupọ fun iṣẹ Ọlọrun. Aya ki i fo wọn lati fi ara wọṅ han bi ẹni ti o ni “ẹbun iwosan” ati pe wọn ni agbara lati wo ẹnikẹni san ti o ba tọ wọṅ wa fun iwosan. Wọn n fi iwaasu Ihinrere ṣe bojuboju lati maa “polowo iwosan”fun awọn eniyan. Wọn ki i saba sọ pe o ṣe danindanin lati di atunbi, nitori pe owo ti awọn ti o n gbokegbodo nidi ipolowo iwosan yoo gba lọwọ awọn eniyan ni o leke lọkàn wọn, imọ wọn nipa igbala tootọ si kuru lọpọlọpọ.
Otitọ ni pe ẹbun iwosan jẹ ọkan ninu awọn ẹbun Ẹmí ti a fi fun Ijọ Kristi. (Ka 1Kọrinti 12:9, 28). Iyemeji kò gbọdọ si ninu ọkàn wa rara nipa awọn ti o sọ ara wọn di oluwosan. Jesu kò ṣe “ipade iwosan” ri! Gbogbo awọn ti o wa sọdọ Rè̩ fun iwosan ni O wosan, ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ a maa sọ fun wọn pe ki wọn máṣe dẹṣẹ mọ ki ohun ti o buru ju bẹẹ lọ ki o má ba de ba wọn (Ka Johannu 5:14). Igba gbogbo ni Jesu maa n fa ọkàn awọn eniyan kuro lọdọ ara Rè̩ si ọdọ Baba Rè̩ Ọrun, lati ọdọ Ẹni ti Oun ti wá. Ohun ti Ọmọ Ọlọrun tootọ kò jẹ ṣe ni pe ki o gba ogo iṣẹ ti Ọlọrun ṣe fun ara rè̩. Peteru ati Johannu tọka awọn eniyan si Jesu, ki i ṣe si ara wọn, wọn si jẹ ki o di mimọ fun wọn pe ki i ṣe agbara tabi iwa-mimọ wọn ni o wo ọkunrin arọ naa san.
Ohun ti awọn “a-fi-gbagbọ-ṣe-wosan” wọnyi n ṣe yatọ si eyi. Awọn eniyan wọnyi lọkunrin ati lobinrin a maa sa gbogbo ipa wọn lati fà ọkàn awọn eniyan sọdọ ara wọn; ṣugbọn igbekalẹ bẹẹ lodi si Ẹmi Ọlọrun. Kristi ni Ẹni ayinlogo nibikibi ti a ba gbe n waasu Ihinrere ni tootọ, a ki i si gbe ẹkọ Bibeli kan ga ju awọn iyokù lọ. Kristi kò diyelé agbara iwosan Rè̩, ẹnikẹni ti o ba si n ṣe bẹẹ jẹbi fifi Ihinrere ṣòwò. Bibeli sọ fun ni pe, “Ẹnikẹni ti o ba ṣefefe ninu è̩bun è̩tan, o dabi awọsanma ati afẹfẹ ti kò ni òjo” (Owe 25:14). O tun sọ bayii pe, “Ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni” (Matteu 10:8).
Ẹnikẹni ti o ba ni ẹbun iwosan tootọ yoo maa fi gbogbo ogo fun Kristi, gẹgẹ bi awọn ọmọ-ẹyin ti ṣe. Wọn yoo jẹ olufọkansin tootọ ati ẹni mimọ lọkunrin ati lobinrin, wọn ki yoo si fẹ okiki aye ati ere rè̩. Ọlọrun sọ bayii pe: “Emi li OLUWA: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran” (Isaiah 42:8).
Iwosan nipa agbara Ọlọrun wà ninu eto irapada, o si wà ninu Ẹbọ Etutu Kristi pẹlu. (Ka 1Peteru 2:24; Matteu 8:16, 17; Isaiah 53:5). Ọfẹ ni fun gbogbo eniyan, o si wà fun gbogbo eniyan, a si le ri i gbà nipa igbagbọ ninu Kristi, gẹgẹ bi Peteru ti sọ fun ni. A ka a pe: “Orukọ rè̩, nipa igbagbọ ninu orukọ rè̩, on li o mu ọkunrin yi lara le.” Igbagbọ ninu Kristi ati pe Oun ni etutu fun è̩ṣẹ wá ati pe nipa ìnà Rè̩ ni a n mu wa lara da, yoo fun ni ni ibukun imularada.
Jakọbu sọ fun ni pe: “Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura … Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? Ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rè̩, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa; Adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dè̩ṣẹ, a o dari ji i” (Jakọbu 5:13-15). Ọna ti o dara lati gba wa sọdọ Ọlọrun fun iwosan ni eyi. Gbogbo awọn ti o ba wa sọdọ Ọlọrun ni ọna ti o tọ ni o n ri iwosan, nitori Ọlọrun jẹ oloootọ si Ọrọ Rè̩. O ṣoro lati ri iwosan gbà lọwọ awọn “adamọdi oluwosan” wọnyi, igbà pupọ ni aṣiiri wọn si maa n tú.
Nipa igbagbọ ni gbogbo eniyan nibi gbogbo fi le ri ibukun Ọlọrun gbà. Ọlọrọ tabi talaka, onde tabi ominira, Ju tabi Hellene – gbogbo wọn ni o le ri ibukun Ọlọrun gbà nipa igbagbọ. Ọlọrun ki i ṣe ojusaju eniyan, ẹnikẹni kò ni iṣogo kan niwaju Ọlọrun, bẹẹ ni a kò le ri oju rere Ọlọrun nipa iṣẹ rere wa. Sibẹ nipa igbagbọ bi ọmọde kekere, a le mi ọwọ Ọlọrun lati rọjo ibukun Rè̩ si wa lori. I baa ṣe iwosan fun ara, tabi idariji è̩ṣẹ fun ọkàn, mejeeji ni a le ri gba nipa igbagbọ ninu Ọlọrun.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni Peteru ati Johannu ṣeleri lati fun ọkunrin arọ dipo owo?
- Bawo ni a ṣe wo ọkunrin arọ naa san?
- Ki ni ṣe ti Peteru ati Johannu fi kọ lati gbà iyín fun iwosan ọkunrin arọ naa?
- Bawo ni a ṣe le ri iwosan gbà lọjọ oni?
- Ọlọrun ha n ṣe iṣẹ iyanu sibẹ lọjọ oni? Awọn wo ni O n ṣe e fun?
- Ki ni abajade iwaasu Peteru fun awọn eniyan ti o pejọ?