Iṣe Awọn Apọsteli 4:1-31

Lesson 283 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Enia buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun” (Owe 28:1).
Cross References

I A Fi Wọn Sinu Tubu, A Si Fi Wọn Sùn

1. Iwaasu Peteru ati Johannu rú awọn alaṣẹ Ju soke, Iṣe Awọn Apọsteli 4:1, 2

2. A fi awọn ọmọ-ẹyin meji naa sinu tubu lalẹ ọjọ naa, Iṣe Awọn Apọsteli 4:3

3. Ọpọlọpọ ọkàn ni a kà kún awọn ti o gbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 4:4

4. A pe igbimọ, a si mu Peteru ati Johannu wa siwaju wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 4:5-7

II Ẹnu Ya Igbimọ

1. Ẹmi Ọlọrun fi ọrọ ọgbọn fun Peteru lati fi dahun, Iṣe Awọn Apọsteli 4:8-12

2. Ẹnu ya igbimọ si igboya awọn Onigbagbọ wọnyi, ṣugbọn a kò rí ẹsùn kan fi wọn sùn, Iṣe Awọn Apọsteli 4:13, 14

3. Awọn olori kilọ fun Peteru ati Johannu lati dẹkun ọrọ sisọ lorukọ Jesu, Iṣe Awọn Apọsteli 4:15-18

4. Peteru wi pe awọn ọmọ-ẹyin Kristi ni lati gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ, Iṣe Awọn Apọsteli 4:19-22

III Laaarin Awọn Ẹlẹgbẹ Wọn

1. Awọn ọmọ-ẹyin ti a dá silẹ lọ taara sọdọ awọn ẹlẹgbẹ wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 4:23

2. Wọn gbadura fun igboya lati sọrọ Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 4:24-30

3. Ọlọrun dahun adura wọn nipa amì ti o fara han, Iṣe Awọn Apọsteli 4:31

Notes
ALAYÈ

Iṣẹgun

Iwosan ọkunrin arọ ti o joko ni Ẹnu-ọna Tẹmpili Daradara pe ọpọlọpọ ero. Peteru ri i pe Ọlọrun ṣilẹkun anfaani silẹ, o si ki ẹnu bọ iwaasu nipa Jesu, Ẹni ti o mu ki iwosan ọkunrin arọ naa ṣe e ṣe. Bi Peteru ti n sọ nipa ikú Jesu lori agbelebu, ajinde ati igoke re Ọrun Rè̩, Ẹmí Ọlọrun bẹrẹ si kọ otitọ yii si ọkàn awọn ti o n gbọ ọ, ogunlọgọ wọn si gbà Oluwa gbọ. Iṣẹgun nlá nlà ni eyi jẹ fun awọn Apọsteli, ṣugbọn gẹrẹ lẹyin eyi ni ọta ẹmi gbogun tì wọn. Ohun mẹta ni ọta lo lati dojuja kọ Peteru ati Johannu: awọn alufaa, olori ẹṣọ Tẹmpili ati awọn Sadusi. Wọn mu awọn eniyan Ọlọrun mejeeji yii, wọn si há wọn mọ inu tubu ni gbogbo oru, nitori ti ilẹ ti ṣu ju lati pe ajọ Igbimọ awọn Ju.

Inunibini

Bayii ni inunibini ṣe dide si Igbagbọ Kristi ni akọṣe. Bi a ba ti n ka ẹkọ yii lọ a o ri i gẹgẹ bi Orukọ Jesu ati igbagbọ ninu Rè̩ ti duro gbọningbọnin ninu igbi iṣoro. Eyi jẹ apẹẹrẹ iṣẹgun ti o wà ninu igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun lati ayebaye, bi o ti wu ki onikupani ti pọ to tabi bi o ti wu ki wọn jẹ gbajumọ to. “Ọpé̩ ni fun Ọlọrun, ẹniti nyọ ayọ iṣẹgun lori wa nigbagbogbo ninu Kristi” (2Kọrinti 2:14).

Ilẹ ṣu ba Peteru ati Johannu ninu tubu – igbesi-aye ti o ṣajeji si wọn, ṣugbọn iriri bayii n bọ wa di ohun ti o wọpọ laaarin awọn ọmọlẹyin Onirẹlẹ ara Nasarẹti nì. Ni ilu miiran ni oni-oloni yii, ijẹwọ igbagbọ ninu Jesu Kristi le kó ẹni naa si wahala, inunibini, tubu tabi ki a tilẹ gba ẹmi rè̩. Ni akoko kan ti a saba maa n pe ni Akoko Okunkun biribiri nipa Igbagbọ, ẹgbaagbeje eniyan ni o kú iku ajẹriku, nitori ijẹwọ igbagbọ wọn ninu Kristi, ṣugbọn a sọ fun ni pe laaarin ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin, iye awọn Onigbagbọ ti a ti pa bi ajẹriku pọ niye ju ti Akoko Okunkun biribiri lọ. Awọn Apọsteli jiya pupọ ninu iji lile ti eṣu gbe dide ni akọbẹrẹ Igbagbọ -- ohun ti kò dẹkun ti kò si dinku lọnakọna nisisiyi si ti igba nì. A dupẹ wi pe ofin Ijọba orilẹ-ède wa gba olukuluku eniyan laaye lati sin Ọlọrun, ṣugbọn eyi le yipada ni ọsan-kan-oru-kan bi awọn ti kò tọ ba bọ si ipo.

Niwaju Igbimọ

Nijọ keji, a pe awọn ijoye, awọn alagba, awọn akọwe, olori alufaa ati awọn ibatan rè̩ pẹlu si ajọ igbimọ -- ti o ba-ni-lẹru gidigidi ninu ọran iṣelu ni Jerusalẹmu. A si mu Peteru ati Johannu wa siwaju igbimọ lati dahun ẹsùn ti a sùn wọn pe wọn mu ọkunrin ti o yarọ lati inu iya rè̩ wa lara da. Lai si aniani, awọn eniyan meji wọnyi ranti iru apejọpọ igbimọ bayii ni oṣu diẹ sẹyin. Ninu apejọ yii ni a gbe ṣe ẹjọ eke fun Jesu ti wọn si sọ pe ki a kan An mọ agbelebu. Peteru kò le ṣai ranti gbogbo ohun ti o ṣẹlẹ kinnikinni, nitori pe ọjọ naa gan an ni atako ọdọmọbinrin kan mu ki Peteru sẹ Oluwa. Peteru ti o duro niwaju igbimọ nisisiyi yatọ si Peteru ọjọ wọnni nitori pe iyipada nla ti ṣẹlẹ ninu ookan-aya rè̩, igbesi-aye rè̩ si ti di ọtun. Peteru sọkun kikoro, o si ronupiwada tọkàntọkan. Jesu ti dariji i, O si ti tun gba a la lọtun. Peteru ti n ba Jesu rin, o ti fi ara rè̩ rubọ fun Kristi, o si ti yan Kristi dipo ohun aye yii. A ti sọ ọkàn Peteru di mímọ nitori pe o wà ni iṣọkan pẹlu awọn ọgọfa ọmọ-ẹyin ni Yara Oke ni ọjọ Pẹntikọsti, oun pẹlu si gba agbara Ẹmi Mimọ. Boya ajọ igbimọ n ro pe ibẹru yoo mu ki Peteru ati Johannu wariri niwaju wọn; ṣugbọn Peteru ati Johannu fi igboya duro niwaju wọn, wọn si n royin ireti ti o gbà gbogbo aya wọn kan.

Ija Ilara

Iṣẹ iyanu iwosan ti o ṣe kò ṣe e bo mọlẹ. Kedere ni o han si wọn nitori pe ọkunrin ti a wosan naa duro ti Peteru ati Johannu. Ni ikẹyin, ile ẹjọ pada di ibi ti a gbe n wadii bi iṣẹ iyanu ti ṣe ṣẹlẹ -- otitọ ti o yẹ ki o ti di mimọ fun gbogbo igbimọ lai ku ẹni kan. Aṣiiri ọrọ naa niyii. Olori alufaa ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ ni o kan Jesu mọ agbelebu. Bi a ba gba awọn Apọsteli laaye lati waasu Ihinrere ti ajinde Kristi lai da wọn lẹkun, eyi yoo mu itiju ba olori alufaa, ẹbi Ẹjẹ Kristi yoo si wá sori awọn olufisun Rè̩. Ẹwẹ, awọn alufaa ni o n ṣe akoso Tẹmpili, wọn si n ṣe ilara agbara ati okiki ti awọn Apọsteli ni laaarin awọn eniyan bi wọn ti n waasu ẹkọ Kristi. Aṣẹ wọn ninu Tẹmpili yoo maa dinku siwaju ati siwaju bi wọn kò ba ṣe idèna itankalẹ Ihinrere.

Awọn Sadusi gbà ọran inunibini naa kanri, nitori pe ẹkọ nipa ajinde lodi si isin asan ti wọn gbe lọwọ. Wọn kò gba pe angẹli tabi ẹmi wà. Opin yoo de kánkán ba awọn Sadusi bi wọn ba fi awọn Apọsteli silẹ lati maa waasu wọn lọ.

Ojulowo Otitọ

Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ tẹlẹ pe idanwo n bọ. O sọ bayii pe, “nwọn o nawọ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagọgu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi” (Luku 21:12). Jesu ṣeleri fun wọn pe, “Ẹ pinnu rè̩ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun. Nitoriti emi ó fun nyin lí ẹnu ati ọgbọn, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju” (Luku 21:14, 15). A mu ileri naa ṣẹ nigba ti Peteru ati Johannu duro niwaju igbimọ lati dahun è̩sùn ti a fi wọn sùn.

Awọn Apọsteli waasu, iná otitọ Ọlọrun ran ninu ookan àyà awọn ti wọn waasu fun, kò si si ẹni ti o jẹ tako wọn mọ. Peteru sọ oju abẹ niko bi o ti n fi ọrọ iwaasu rè̩ gún awọn ti o kan Jesu mọ agbelebu loju. Idahun Peteru si awọn olufisun rè̩ sọ ni ṣoki nipa Jesu ati iṣẹ Rè̩ layé ati è̩ṣẹ ti awọn Ju dá nipa kíkọ Olugbala; lopin ọrọ rè̩, o fi igbala lọ gbogbo wọn pe, “Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:12).

Ẹkọ Lẹsẹ Jesu

Awọn Ijọ eniyan ti o wà pẹlu olori alufa kò le gboju fo eyi da pe awọn Apọsteli ti wà pẹlu Jesu, wọn si ti kẹkọọ lẹsẹ Rè̩. Wọn ranti ifọkàntan ti o daju ti Jesu ni ninu Ọlọrun, iru eyi ti o han ninu awọn Apọsteli pẹlu. Otitọ ni itan Jesu, ohunkohun ti o wu ki olori alufaa le wi. Otitọ ajinde kò ṣe e bo mọlẹ, tayọtayọ ni igbimọ i ba fi sẹ ajinde Jesu bi o ba ṣe e ṣe. Awọn Onigbagbọ tọka si iboji ti o ṣofo, awọn alaṣẹ paapaa si mọ ninu odo ọkàn wọn pe iboji naa ṣofo ni tootọ. Ọwọ kan ni wọn i ba fi bi isìn Igbagbọ wó bi awọn alaṣẹ ba le fi han pe Jesu kò jinde kuro ninu oku; ṣugbọn wọn kò le ṣe e. Ajinde Olugbala ni ipilẹ ti ọrọ Peteru duro le lori, Ẹmi Mimọ si fi agbara fun un lati sọrọ. Ajọ igbimọ “kò ri nkan wi si i.”

Ki ni ṣe ti awọn eniyan fi n bá Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ jà? – Orisun ire kan ṣoṣo layé yii. Ajọ igbimọ mọ pe Otitọ ni ọrọ yii, sibẹ wọn taku ninu iṣọtẹ wọn si Ọlọrun. Igberaga kò jẹ ki wọn yi pada si ohun ti ọkàn awọn tikara wọn n jẹ wọn lẹrii si. Ohun kan naa ni awọn ti ayé n sọ pẹlu. Ọlọrun n fi ọna ti O n fẹ ki awọn eniyan gba han wọn, ṣugbọn wọn kọ lati rin ni ọna naa. “Ẹniti o ba mọ rere iṣe ti kò si ṣe, è̩ṣẹ ni fun u” (Jakọbu 4:17). È̩ṣẹ ki yoo wọ Ọrun.

Gbigbọ ti Ọlọrun

Nigba ti igbimọ ri i pe wọn kò ri ohunkohun ká mọ awọn Apọsteli lọwọ lati jẹ wọn niyà, wọn gbero lati pa wọn lẹnu mọ nipa ihàlẹ. Wọn paṣẹ fun Peteru oun Johannu ki wọn má ṣe waasu rara, bẹẹ ni kí wọn ma ṣe fi orukọ Jesu sọrọ fun ẹnikẹni mọ -- etí didi ni aṣẹ yii bọ si. Awọn Onigbagbọ a maa fara mọ ofin adajọ ati ijọba niwọn igba ti wọn kò ba lodi si ofin Ọlọrun. Peteru ati Johannu dá igbimọ lohun pe, “Bi o ba tọ li oju Ọlọrun lati gbọ ti nyín jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a ro.” Olukuluku oloootọ eniyan ní yoo wi pe o ṣe pataki ju lọ lati gbọ ti Ọlọrun.

“O tọ li oju Ọlọrun”. Eyi ni opin ire ije ati itara gbogbo awọn Onigbagbọ. Ni nnkan bi ọgọrun ọdun sẹyin, alufaa kan sọ bayii pe, “Ohun ti o ni lati jẹ akọmọna wa ni eyi pe -- ṣiṣe ohun ti o tọ. Ohun ti o tọ ni ki a ṣe, ki i ṣe eyi ti o lere; ohun ti o tọ, ki i ṣe ohun ti o dùn mọ ni; ohun ti o tọ, ki i ṣe ohun ti o mu afẹfẹ-yẹyẹ lọwọ; ohun ti o tọ, ki i ṣe ohun ti n fun ni ni ọlá ayé. Bi a ba fẹ mọ ohun ti o tọ, a ni lati tẹle ofin Ọlọrun, kì i ṣe ofin adabọwọ ọmọ-eniyan – nitori akọmọna Onigbagbọ ni lati ṣe ohun ti o tọ li oju Ọlọrun”.

Sọdọ Awọn Ẹgbẹ Wọn

Ajọ igbimọ halè̩ mọ Peteru ati Johannu siwaju sii, wọn si jọwọ wọn lọwọ lọ. Lẹsẹkẹsẹ ti a dá wọn silẹ, wọn tọ awọn ẹlẹgbẹ wọn lọ lati royin ohun gbogbo ti olori alufaa ati awọn agbagba sọ fun wọn. Iroyin ìhalè̩ yii mu ki gbogbo wọn gbohun adura soke ni ọkàn kan. Awọn ọmọ-ẹyin kò gbadura fun igbẹsan lori awọn ti n ṣe inunibini si wọn, ṣugbọn wọn gbadura fun igboya lati sọrọ Ọlọrun. Wọn bẹbẹ pe ki iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu ki o maa ṣe lọpọlọpọ, “ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mā ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ rẹ”. Wọn gbadura tọkàntọkàn, nitori pe nigba ti wọn gbadura tan, “ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmi Mimọ, nwọn si nfi igboiya sọ ọrọ Ọlọrun.” Ifẹ Ọlọrun ni lati dahun adura yii pẹlu ẹri ti o fara han, ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fi gbogbo ọkàn rè̩ gba iru adura bayii yoo ri idahun si adura rè̩. Ọlọrun yoo ba ọkàn rẹ jẹrii. Ọlọrun yoo fi igboya fun ẹnikẹni ti o ba ni itara lati waasu ọrọ Rè̩.

Isin Mimọ

“Gbogbo awọn ti o fẹ mā gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini” (2Timoteu 3:12). Ohun ti o han si gbogbo Onigbagbọ ni pe bi wọn o ba jẹ oloootọ si ipe ti a pe wọn, wọn kò le ṣalai ri idojukọ lati ọdọ awọn eniyan aye. Idojukọ yii le jẹ ti è̩gan tabi iyọṣuti si, o le jẹ idaduro ni ibi iṣẹ; o le jẹ fifi igbega du ẹni naa, o le jẹ oriṣiriṣi iyọlẹnu kéékèèkéé, o si le jẹ atako ojukoju; ṣugbọn ohun kan ni o daju: ayé ki yoo fi ojurere wo awọn oloootọ Onigbagbọ, nitori pe igbesi-aye wọn n da awọn ti n ṣakiyesi wọn lẹjọ. Ki gbogbo awọn Ọmọ Ọlọrun gbẹkẹle Baba wọn ti o wà lọrun pe yoo mu wọn la gbogbo idanwo yii já. Idanwo naa le gba wọn ni ọpọlọpọ adura; ṣugbọn nigba ti o ba pari, eniyan Ọlọrun yoo le tubọ fi igboya sọrọ Ọlọrun. Kí ni tun le ni ere ju eyi lọ?

Ohun ti a tun gbọdọ ṣe akiyesi ni pe: Awọn ọmọ-ẹyin Kristi ran awọn igbimọ leti nipa Kristi paapaa. Ẹnikẹni ki i ṣe Onigbagbọ tootọ bi kò ṣe pe gbogbo ọrọ ati iṣe rè̩ ati gbogbo igboke-gbodo rè̩ ba ran aye leti nipa Jesu. “Bi o ti nṣiro li ọkàn rè̩, bḝ li o ri” (Owe 23:7). Iwa awọn miiran laaarin awọn Onigbagbọ ẹgbẹ wọn dabi ti angẹli; wọn a fara han bi ẹni ti n sin Ọlọrun tọkàn-tọkàn, ṣugbọn jẹ ki wọn jade kuro ninu ile Ọlọrun, wọn a maa huwa jagbajagba. Eyi ki i ṣe isin tootọ. Igbagbọ kì i ṣe isin ti a n fi aṣọ han nigba ajọdun. Onigbagbọ tootọ le gbe igbesi-aye rere lati ibẹrẹ titi de opin ọsẹ, kọlọfin kan kò si fun wọn. Ni gbogbo akoko ati ni ibi gbogbo, igbagbọ tootọ a maa fi Olupilẹṣẹ ati Olumuniduro han.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a fi Peteru ati Johannu sinu tubu? Ta ni fi wọn sibẹ?
  2. Darukọ diẹ ninu awọn eniyan ti o wà ninu igbimọ nibi ti a ti fi Peteru ati Johannu sùn. Njẹ a ti gbọ nipa awọn eniyan wọnyi tẹlẹ ri?
  3. Ki ni ohun ti igbimọ gbe ẹsùn ti wọn fi awọn Apọsteli sùn le lori?
  4. Bawo ni Peteru ṣe dahun?
  5. Ki ni ohun meji ninu iwa Peteru ati Johannu ti o mu ki ẹnu ya igbimọ?
  6. Ọna wo ni ajọ igbimọ gba lati pa awọn Apọsteli lẹnu mọ ki wọn ma ṣe waasu Jesu?
  7. Ọna wo ni a le gba lo ofin igbọran ti Peteru fi siwaju igbimọ ninu igbesi-aye wa bi Onigbagbọ?
  8. Ki ni awọn ọmọ-lẹyin ṣe nigba ti wọn gbọ ihalẹ igbimọ?
  9. Bawo ni Ọlọrun ṣe fi idahun Rè̩ han?