Iṣe Awọn Apọsteli 4:32-37; 5:1-16

Lesson 284 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ini iṣura nipa ahọn eke, o jẹ ẽmi ti a ntì sihin tì sọhun lọwọ awọn ti nwá ikú kiri” (Owe 21:6).
Cross References

I Ijọ Akọbẹrẹ

1. Ijọ awọn ti o gbagbọ wà ni ọkàn kan ati inu kan, Iṣe Awọn Apọsteli 4:32; Romu 15:5, 6; Filippi 1:27; 2:2; 1Peteru 3:8

2. Pẹlu agbara nla ni wọn n jẹri ajinde Kristi, Iṣe Awọn Apọsteli 4:33; 1:8, 22

3. A tà ile ati ilẹ, a si ṣe ipin-fun-ni rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 4:34-37; 2:45

II Anania ati Safira S̩e Agabagebe

1. Anania ati Safira tà ilẹ ini wọn, wọn si fi apa kan owo naa pamọ, Iṣe Awọn Apọsteli 5:1, 2

2. Peteru ba Anania wi, Ọlọrun si ran idajọ sori rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 5:3-6; Numeri 30:2

3. Safira pẹlu ṣeke, o si gba idajọ kan naa; Iṣe Awọn Apọsteli 5:7-11

4. Awọn ami ti o maa n tẹle awọn ti o gbagbọ fara han, o jẹ ki wọn mọ daju pe Ọlọrun ni inu-didun si Ijọ ẹniyan Rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 5:12-16; Marku 16:17, 18

Notes
ALAYÉ

Iṣọkan

Ikú ati ajinde Jesu lẹyin iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ laye fun ọdun mẹta ati aabọ, ati itujade Ẹmi Mimọ ní Ọjọ Pẹntekọsti, mu iyipada ti o yà ni lẹnu wa si ọkàn ati igbesi-aye awọn ọmọ-ẹyin Jesu. Wọn mọ pe wọn ki í ṣe ti ara wọn mọ nitori ti a ti rà wọn ni iye kan – pẹlu Ẹjẹ iyebiye ti Jesu. A pe wọn jade lati oriṣiriṣi ọna òwò wọn lati jẹ ọmọ-lẹyin Onirẹlẹ Ara Nasarẹti nì. O tì ba wọn sọrọ nipa Ijọba ti n bọ wa, olukuluku wọn si n ni ète ati àba wọn nipa Ijọba naa ati iṣakoso rè̩. Wọn ti fi oju wọn ri I bi O ti n ṣe iwosan fun awọn alaisan ati bi O ti n tù awọn onirobinujẹ ọkàn ninu, ti o bọ ọpọ eniyan, ti O ji okú dide, ti O si ba awọn oluṣe buburu wi. Wọn gbọ bi O ti ba awọn agabagebe ti o wà nigba nì wi ati bi O si ti yin obinrin opo nì ti o fi gbogbo ohun ti o ni sinu apoti iṣura. Wọn wà pẹlu Oluwa wọn nibi Ounjẹ Alẹ Ikẹyin, wọn si ri I bi a ti fi I le awọn ọta Rè̩ lọwọ. S̩aaju akoko yii, wọn ri I bi a ti gba A silẹ lọwọ awọn ti o fẹ pa A. Wọn gbọ bi Oluwa wọn ti gbadura fun isọdimimọ wọn, ki wọn le ni iṣọkan, ti Ẹjẹ nì n fi fun ni nipa isọdimimọ. A si ti sọ wọn di mimọ.

Boya ni iru iṣọkan ti o wà laaarin wọn nigba nì tun wa ninu Ijọ Ọlọrun loni. Gbogbo wọn wà ni ọkàn kan ati inu kan. Gbogbo ilepa ara ati ojukokoro ni a ti mu kuro ni igbesi-aye wọn. Wọn ti di ọmọ-ẹgbẹ “ijọ ti o li ogo, li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ... mimọ ati alaini àbuku” (Efesu 5:27). Wọn ti di ọmọ-ẹgbẹ Ijọ Onigbagbọ ti a n pe ni Iyawo Kristi, Ijọ Akọbi, awọn Aṣẹgun ni kikún. A ti sọ wọn di mimọ patapata; wọn si ti ri iriri ologo yii gbà ṣaaju iriri iyanu kẹta ni -- Ẹmi Mimọ ti wọn ri gbà ni ọjọ Pẹntekọsti (Iṣe Awọn Apọsteli 2:1. Tun wo Heberu 2:11 ati Johannu 17:21, 23).

Ajinde Kristi ati ireti ajinde Ijọ Ọlọrun ni ohun pataki ti iwaasu ati ẹri wọn duro le lori. Iwaasu wọn lori ajinde ni o mu ki gbogbo ọrun apaadi ati gbogbo ogun Satani doju ija kọ awọn Apọsteli ati awọn ọmọ-lẹyin Jesu. S̩ugbọn wọn ti ri ireti ọtun gbà ninu Ọlọrun, ani ireti ajinde. Ireti yii ni a si sọ di ireti aaye nitori pe Kristi ti jinde kuro ninu oku. Ni ọdun diẹ lẹyin eyi, Paulu sọ bayii pe, “Bi a kò ba si ji Kristi dide, asan ni igbagbọ nyin, ẹnyin wà ninu è̩ṣẹ nyin sibẹ.” Eyi fi ẹri ati iduro ti awọn Apọsteli mu ni atetekọṣe han wa.

Wọn n gbọ mìmì ati ihàlẹ, wọn mọ inunibini ti yoo de ba wọn lati ọdọ awọn ẹni ibi, nitori ti wọn n waasu ireti aaye, wọn si n kọ ni ni ẹkọ Ijọ Ọlọrun ti o n fun ọkàn ni iye, awọn ọmọ-ẹyin Jesu bẹrẹsi fi itara gbadura pe ki Ọlọrun le fun wọn ni igboya lati waasu Ọrọ naa, ati pe ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o le maa ṣe ni orukọ Jesu.

Ayọ nlá nlà gba ọkàn wọn; ifẹ gbigbona si Oluwa ati si ara wọn gbà ọkàn olukuluku wọn kan, eyi si mu ki awọn ọkàn ti a ti sọ di mimọ wọnyi tubọ wà ni iṣọkan pipé. A fi ibeere yii siwaju ọjọgbọn kan pe, “Ki ni ọré̩ jẹ?” O dahun pe: “Ọkàn kan ti o n gbe inu ara meji.” Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe “Ijọ awọn ti o gbagbọ si wà li ọkàn kan ati inu kan.” A so wọn pọ ṣọkan ninu ifẹ ati iṣọkan Onigbagbọ ti i ṣe ti awọn ti a sọ di mimọ -- eyi ti aye kò le mọ ti kò si le ni.

Wọn kò ka ohun ini wọn si ti wọn mọ, kò si si ẹni kan ninu wọn ti o ṣe alaini. Wọn ni ohun gbogbo pọ ṣọkan. Awọn ti o ni ile ati ilẹ tà wọn, wọn si mu owo ohun ti wọn tà wa sọdọ awọn Apọsteli lati pin in fun olukuluku, gẹgẹ bi aini rè̩ ti pọ to.

A sọ fun wa pe Jose ti awọn Apọsteli sọ apele rè̩ ni Barnaba ni ilẹ kan, o tà a, o si mu owo rè̩ wa, o si fi lelẹ ni ẹsẹ awọn Apọsteli. A kò sọ fun wa pe Ọlọrun ni o beere eyi ni ọwọ rè̩, ṣugbọn o fi tọkàntọkàn jọwọ ohun gbogbo ti o ni fun Oluwa. A kò mọ iye ti owo ilẹ naa jẹ. O le pọ, o si le kere. Iyekiye ti o wu ki o jẹ, o jọwọ gbogbo rè̩ lọwọ fun iṣẹ Oluwa.

Ikuna lati San Gbogbo Rè̩

S̩ugbọn a ri i pe kò ṣoro lati ṣubu kuro ninu iru oore-ọfẹ yii. Anania ati Safira aya rè̩ tà ilẹ ini kan, wọn si fi apa kan ninu owo rè̩ pamọ fun ara wọn. Apẹẹrẹ awọn alafẹnujẹ Onigbagbọ ni eyi, awọn ti o fi ohun ti i ṣe ti Oluwa du U. Awọn miiran n ja A lole akoko wọn; wọn ko ni aye fun iṣẹ Oluwa. Awọn wọnyi ni akoko fun afẹ ati iṣẹ oojọ wọn, ṣugbọn wọn kò naani isin Ọlọrun. Igba ti o ba rọrun fun wọn nikan ni wọn n wa si ile Ọlọrun, bi wọn ba ni ailera diẹ tabi wọn ni iṣẹ kekere kan lati ṣe, wọn yoo fi eyi kẹwọ lati fi ṣe awawi eredi rẹ ti wọn kò fi le fi ifẹ, akoko ati isin wọn ti o tọ si Ọlọrun fun Un. Awọn miiran n ja Ọlọrun lole talẹnti wọn. Kaka ki wọn lo talẹnti wọn fun Oluwa, wọn kọ lati ṣe bẹẹ, nigba miiran ẹwẹ, wọn le yọọda eyi ti o wu wọn ninu talẹnti ti a fi fun wọn, wọn n ṣe diẹ ninu ohun ti o yẹ ki wọn ṣe karakara.

Eke

Ohun ti o buru ju nipa Anania ati Safira ki i ṣe apa kan owo ti wọn fi pamọ, bi kò ṣe pe wọn ṣeke nipa ohun ti wọn ṣe. Wọn fẹ ki awọn Apọsteli lero pe wọn ti fi ohun gbogbo lelẹ; nitori naa è̩tan ati agabagebe ni o pilẹ ohun ti wọn ṣe yii. Lai si aniani Anania ati Safira ti ro ọrọ yii laaarin ara wọn, wọn si ti pinnu lati fi apa kan owo naa pamọ lati ri ohun ti wọn yoo mu lo ni igba ogbo wọn. O ṣe e ṣe ki wọn ti ro pe akoko le de ti Ipese Ọlọrun le dasẹ, bi eyi ba si ṣẹlẹ, wọn n fẹ ohun ti wọn yoo fi ọkàn tè̩. Wọn fẹ ìyé̩sí awọn ti o fi gbogbo ini wọn lelẹ,bẹẹ ni wọn ko si fẹ padanu ohun ini aye yii; nitori naa, wọn pinnu lati fi apa kan owo ilẹ naa pamọ ki wọn si fara han bi ẹni pe gbogbo rè̩ ni wọn fi silẹ. Anania ati Safira kò tilẹ ronu pe Ọlọrun ni awọn n ba ṣowo, ki i ṣe eniyan. Wọn gbagbe pe, “Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ikọkọ, ibā ṣe rere, ibā ṣe buburu” (Oniwasu 12:14).

Peteru kò wi pe “Anania o ti ṣeke si mi.” O wi pe, “Anania, Ẽṣe ti Satani fi kún ọ li ọkàn lati ṣeke si Ẹmi Mimọ? ... enia ki iwọ ṣeke si bikoṣe si Ọlọrun.” Nigba ti Anania gbọ ọrọ wọnyi, o ṣubu lulẹ, o si kú; awọn ọdọmọkunrin si gbe e jade wọn si lọ sin in.

Ni iwọn nnkan bi wakati mẹta lẹyin eyi, aya rè̩ wọle lai mọ ohun ti o ṣẹlẹ si ọkọ rè̩. Peteru beere bi iye bayii ni wọn ta ilẹ naa. O si dahun wi pe “Lõtọ iye bḝ ni.” Peteru ba a wi, o si wi pe, “Ẽṣe ti ẹnyin fohùn ṣọkan lati dán Ẹmi Oluwa wò?” O si ṣubu lulẹ ni ẹsẹ Peteru lẹsẹ kan naa; awọn ọdọmọkunrin ti o ṣẹṣẹ n pada bọ nibi ti wọn ti lọ sinku ọkọ rè̩ gbe e jade, wọn si lọ sin in.

Idajọ

Ọlọrun ran idajọ Rè̩ sọkalẹ kankan nitori è̩ṣẹ yii. Ẹṣẹ wọn buru jai to bẹẹ ti Ọlọrun fi ran idajọ gbigbona lẹsẹkẹsẹ. Idajọ le ṣai wa kankan nitori iru è̩ṣẹ bayii, tabi omiran bẹẹ, tabi fun oniruuru è̩ṣẹ miiran ti a n dá, ṣugbọn dajudaju lai si ironupiwada, ẹlẹṣẹ ki yoo lọ lai jiya. Eniyan le jiya diẹ laye yii nitori è̩ṣẹ rè̩, ṣugbọn eyi kó fi han pe ijiya rè̩ ni aye ti n bọ yoo dinku. Ori gbogbo ẹniti o ba kú lai ronupiwada è̩ṣẹ wọn ni a o dà si ọrun apaadì titi laelae.

Ni akoko yii Ijọ Ọlọrun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni; fun anfaani Ijọ, Oluwa ran idajọ lẹsẹkẹsẹ lati fi han pe Oun kò ni inu didun si è̩tan, irẹjẹ ati agabagebe. Bi Oluwa ba fi tọkọ-taya yii silẹ laaye, ọpọlọpọ ni yoo ti ipasẹ wọn ni ireti pe suuru Ọlọrun yoo fi aanu gba wọn. Ọlọrun mọ pe, “nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pāpa lati huwa ibi” (Oniwasu 8:11). Ọlọrun fi ijiya Anania ati Safira ṣe apẹẹrẹ ododo ati idajọ Rè̩.

Iṣẹ Iyanu

Ẹru nlá si ba gbogbo Ijọ ati gbogbo awọn ti o gbọ nipa ohun ti Ọlọrun n ṣe laaarin awọn eniyan Rè̩. Idajọ ti Ọlọrun ran yii ṣiṣẹ gidigidi nitori pe ibè̩ru Ọlọrun wọ gbogbo ọkàn; ohun gbogbo ti o ba si ni afarawe agabagebe ati è̩tan ni a n mu kuro laaarin wọn lẹsẹkẹsẹ. Ipá ati agbara ẹkọ awọn Apọsteli gbà gbogbo ọkàn awọn eniyan kan; lati jẹri si otitọ ẹkọ yii, Ọlọrun n ti ọwọ awọn Apọsteli ṣiṣẹ ami ati iṣẹ iyanu.

Ihin yii tàn ka gbogbo Jerusalẹmu ati awọn ilu ti o yi i ka. Ọpọ eniyan si wa, wọn gbe awọn abirun wa lati ibi gbogbo. Eniyan pọ pupọ to bẹẹ ti wọn kò fi le sun mọ Peteru, wọn si n gbe awọn alaisan sori akete ati ohun irọgbọku lẹba ọna, pe bi Peteru ba n kọja, ki ojiji rè̩ ṣiji bo wọn. Bibeli sọ fun ni pe “a si ṣe dida ara olukuluku wọn.” Iru eyi ni igbagbọ awọn ọlọkàn tité̩ wọnyi, bayii ni agbara Oluwa si ti pọ to laaarin ijọ ni akọbẹrẹ. Irẹlẹ awọn Apọsteli ni o mu ki wọn ni agbara ati kí Ẹmi Mimọ maa ṣiṣẹ ribiribi ninu iṣẹ-iranṣẹ wọn. Wọn kò sọ wi pe wọn ni agbara kan tabi iwa mimọ adabọwọ ti wọn lati fi ṣiṣẹ iyanu. Iṣẹ iwosan n ṣe nipa orukọ Jesu ati nipa igbagbọ ninu orukọ Rè̩. Ẹ jẹ ki a “mā ja gidigidi fun igbagbọ, ti a ti fi lé awọn enia mimọ lọwọ lẹkanṣoṣo” (Juda 3).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ipo ti Ijọ Ọlọrun wà nipa ti Ẹmi ni akoko yii?
  2. Ki ni Jose ṣe nipa ilẹ ti o ni?
  3. Ki ni Anania ati Safira ṣe nipa ohun ini ti wọn ni?
  4. Oju wo ni Ọlọrun fi wo ohun ti Anania ati Safira ṣe?
  5. Ki ni idajọ yii mu ba Ijọ ati gbogbo awọn eniyan ni apapọ?
  6. Ki ni n ṣẹlẹ si wa lọjọ oni ti a ba ṣeke tabi ti a ba ṣè̩tàn?
  7. Bawo ni Ọlọrun ti ṣe iṣẹ iyanu pọ to nipa adura awọn Apọsteli?
  8. Nigba ti wọn kò le de ọdọ awọn Apọsteli, ki ni awọn kan ṣe nipa awọn alaisan ti wọn gbe wa?