Iṣe Awọn Apọsteli 5:17-42

Lesson 285 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè: Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sé̩ ẹ, on na yio si sé̩ wa” (2Timoteu 2:11, 12).
Cross References

I Fifi Sinu Tubu ati Didásilẹ

1. Olori alufaa ati awọn Sadusi fi irunu ti awọn Apọsteli mọ inu tubu, Iṣe Awọn Apọsteli 5:17, 18

2. Angẹli kan ṣi ilẹkun tubu o si paṣẹ fun awọn Apọsteli lati lọ maa kọ ni ní Tẹmpili, Iṣe Awọn Apọsteli 5:19, 20

II Ajọ-Igbimọ Nla ti a pe ni Sanhedrini

1. Ajọ-Igbimọ pejọ pọ, ṣugbọn a kò ri awọn Apọsteli ninu tubu, Iṣe Awọn Apọsteli 5:21-23

2. Ẹnu ya awọn olori gidigidi, Iṣe Awọn Apọsteli 5:24

3. A ri awọn Apọsteli ninu Tẹmpili, awọn oniṣẹ si mu wọn wa pẹlẹpẹlẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 5:25, 26

III Idahun Awọn Apọsteli

1. Olori alufaa beere eredi rè̩ ti awọn Apọsteli fi ṣe aigbọran si aṣẹ igbimọ, Iṣe Awọn Apọsteli 5:27, 28

2. Peteru ati awọn ẹlẹgbẹ rè̩ dahun pe wọn gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ, Iṣe Awọn Apọsteli 5:29-32

3. Ọrọ awọn Apọsteli ru ibinu Ajọ-igbimọ soke, Iṣe awọn Apọsteli 5:33

4. Gamaliẹli damọran ikilọ nitori ki o má ba lọ jẹ pe ẹkọ awọn Apọsteli jẹ ti Ọlọrun lotitọ, Iṣe Awọn Apọsteli 5:34-39

5. A lu awọn Apọsteli ṣugbọn wọn yọ, wọn si tun bẹrẹ si iwaasu, Iṣe Awọn Apọsteli 5:40-42

Notes
ALAYÉ

Ibinu Eniyan

Awọn Apọsteli jẹ oloootọ si ileri wọn pe wọn yoo gbọ ti Ọlọrun ati pe wọn ki yoo gbọ ti awọn igbimọ ti o kilọ fun wọn pe wọn kò gbọdọ sọrọ tabi kọ ni ní orukọ Jesu mọ. Ijọ Ọlọrun n fẹsẹ mulẹ, o si n gberu. Ọlọrun ṣe iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu pupọ lati ọwọ awọn Apọsteli lati fi idi otitọ ti wọn n waasu rè̩ mulẹ. O dabi ẹni pe ibi iloro Sọlomọni ni Tẹmpili, ni awọn Onigbagbọ gbe n pejọ si, eyi si mu idaamu ati ipaya ba olori alufaa ati awọn alaṣẹ Tẹmpili.

Nigba ti olori alufaa kò le fara da ẹri-ọkàn rè̩ ti o n da a lẹbi mọ, ati owu kikoro ti o kún ookan-aya rè̩, o dara pọ pẹlu awọn Sadusi lati mu awọn Apọsteli ati lati fi wọn sinu tubu. Inu bi awọn alaṣẹ to bẹẹ ti wọn fi gbe awọn Aposteli si inu tubu ti gbogboogbo. Bi eṣu ti pete lati pa ẹmi ẹda run, o fi awọn Sadusi ati olori alufaa ṣe ohun-elo lati daya fo awọn eniyan, lati dè wọn lọna ati lati pa awọn ọmọ-ogun Ọlọrun ti n kede Otitọ lẹnu mo; ṣugbọn kò le moke. Ohun ti o buru jai ni fun ẹnikẹni lati jẹ ohun-elo lọwọ eṣu! S̩ugbọn gbogbo ọkàn ti a kò ti i ra pada ni o wà ni iru ipo bayii.

Iṣẹlẹ Ojiji

Bibeli kò sọ fun wa bi awọn Apọsteli ti pẹ to ninu tubu loru ọjọ naa; ṣugbọn ohun kan daju: Oluwa kò fi wọn silẹ, bẹẹ ni kò kọ wọn silẹ. Lai si aniani, wọn gbadura, ṣugbọn ki ilẹ to mọ, ohun kan ti wọn kò ro tẹlẹ ṣẹlẹ. Angẹli Oluwa ṣi ilẹkun tubu, o si mu awọn Apọsteli jade ni alaafia. Bi ẹni ti o kẹyin ti jade tan, awọn ilẹkun naa tì pada wẹrẹ.

Kò si ile tubu ti o le se awọn ọkunrin alagbara ninu Ọlọrun wọnyi mọ pẹ títí, nitori pe igi ti Ọlọrun gbin ni wọn i ṣe -- Ijọ Ọlọrun. Bi gbongbo igi ba gbẹ, ibajẹ yoo de ba igi pẹlu; nitori pe Ijọ kò i ti ni agbara to lati fẹsẹmulẹ lai si ẹkọ ti o ye kooro. Ipinnu ọta ni lati pa iṣẹ awọn Apọsteli run ati lati mu è̩gan ba orukọ wọn nipa fifi wọn sinu tubu; ṣugbọn Ọlọrun yi ipinnu wọn pada si ire lati fi itara ati imoye fun awọn ojiṣẹ Rè̩. Otitọ Iwe Mimọ nì ti o wi pe, “Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsin laisimi, on o gbà ọ la” (Daniẹli 6:17) ṣẹ ni oju wọn korokoro, Oluwa ran Angẹli naa si awọn Apọsteli pe ki wọn pada lọ si Tẹmpili, ki wọn si maa sọ “gbogbo ọrọ iye yi” fun awọn eniyan. A kò dá awọn Apọsteli silẹ lati lọ fi ara pamọ kuro lọdọ awọn ti o n ṣe inunibini si wọn. Iṣẹ Ọlọrun ni wọn n ṣe, o si ṣe pataki; nitori naa Ọlọrun paṣẹ fun wọn lati tun bẹrẹ iṣẹ naa nibi ti ọta gbe ṣi wọn lọwọ. Iṣiri pupọ ni isọdọtun iṣẹ-iranṣẹ yii jẹ fun awọn Apọsteli.

Eṣu Pòfo

Eṣu kò i ti i dẹkun lati maa ba Onigbagbọ ja. Ọnakọna ni o n gbà lati ṣe idena awọn ẹgbẹ oloootọ yii ninu ire-ije wọn. Igba miiran o n fi aisan ati ipọnju kọlu wọn lati din igboke-gbodo wọn fun iṣẹ Ọlọrun kù. Nigba pupọ ni Ọlọrun si n sọ ìmọ eṣu di asan, a si maa mu ki ogo ati agbara Ọlọrun di mimọ nibi ti eṣu ti pete iparun. S̩ugbọn Ọlọrun ki i fi agbara fun awọn eniyan Rè̩ lati té̩ ifẹkufẹ ara wọn lọrun; O n fi agbara fun ni lati fi ṣiṣẹ fun Un. Ohun danindanin ni fun Onigbagbọ lati lo oore-ọfẹ Ọlọrun ni ọna ti Ọlọrun là silẹ.

Ajọ Apapandodo

Awọn eniyan ti o pejọ laarọ ọjọ keji kò mọ niwọn. Olori alufaa ati gbogbo awọn ti o wà lọdọ rè̩, igbimọ ilu ati awujọ awọn Ju kó ara wọn jọ lati ṣe idajọ. Boya olori alufaa lero pe oun le da awọn Apọsteli niji nipa ọpọ onidajọ ti o pe jọ si ajọ igbimọ lati dè wọn lọna itẹsiwaju ninu iṣẹ-iranṣẹ wọn; ṣugbọn Ọlọrun ni o ṣeto rè̩ bẹẹ, ki ọpọ awọn ijoye Ju le ní anfaani lati ri imọlẹ Ihinrere. Olori alufaa ni alaga. O pe igbimọ jọ, o si ran awọn onṣẹ lati lọ mu awọn ti wọn pe ni ọdaran naa wa lati inu tubu. Lai si aniani, lẹyin ti awọn onṣẹ ti lọ tán, olori alufaa kò ni ṣalai sọ eredi rè̩ ti oun fi pe awọn igbimọ jọ, ati igboke-gbodo awọn Apọsteli. Dajudaju, olori alufaa n ṣe eyi pẹlu gbogbo itara ati igbona ọkàn. Elewu eniyan ni awọn ọkunrin ti a n mu bọ wa siwaju wọn yii jẹ, paapaa ju lọ si olori alufaa -- ẹsẹ ẹni ti n mì nilẹ bayii. Pupọ ninu awọn ọkunrin wọnyi ni kò fi ikilọ igbimọ ijelo pe, bi wọn kò ba si fẹ ki isin Tẹmpili parun, a ni lati wa ọna lati tu ẹgbẹ Onigbagbọ wọnyi ká. Awọn agbátẹrù ẹgbẹ yii ni a fẹrẹ mu de iwaju wọn yii. Nitori naa igbimọ ni lati gbero lori ọna ti o tọ lati gbà.

Wo bi idaamu ati ipaya awọn alaṣẹ ti o pejọ pọ yoo ti pọ to nigba ti awọn onṣẹ pada de ti wọn si sọ pe awọn Apọsteli kò si ninu tubu. A sé ilẹkun naa pinpin (boya awọn onṣẹ nikan ni o ni kọkọrọ ilẹkun ile tubu lọwọ), awọn oluṣọ tabi olutọju ile tubu si wà ni iduro ṣanṣan ni ipo wọn. Awọn alagba wọnyi kò ni ṣai fi ọwọ họ ori wọn pẹlu idaamu ati ipaya pe wọn kò mọ ibi ti nnkan yii yoo yọrí si.

S̩iṣiṣẹ ninu Ọgba Ajara

Njẹ nisisiyi, awọn Apọsteli n ba iṣẹ Baba wọn lọ. Ni kutukutu, bi awọn eniyan ti bẹrẹ si kó ara wọn jọ ninu Tẹmpili, awọn Apọsteli bẹrẹ si kọ awọn eniyan ni gbangba. Ọlọrun tikara Rè̩ ni o fun wọn ni igboya nipa iṣẹ ti O fi ran wọn; nitori pe bi Ọlọrun ba ran wa niṣe, a kò gbọdọ bè̩ru ohun ti o le de, bi a ba sa ti jẹ oloootọ si ipe ti a pe wa. Ibanujẹ ni igbẹyin adabọwọ igboya; ṣugbọn nigba ti Jesu ba fi igboya sinu ọkàn, ti Ẹmi Ọlọrun si n tọ ni, iṣẹgun ni yoo yọrisi.

Ẹni kan sọ fun igbimọ pe awọn Apọsteli wà ninu Tẹmpili, nitori naa wọn ran olori ẹṣọ ati awon onṣẹ lọgan lati mu wọn wa siwaju igbimọ. Nitori ibè̩ru awọn eniyan, olori ẹṣọ ṣe awọn eniyan Ọlọrun jẹjẹ, o si mu wọn wa siwaju igbimọ. Olori alufaa sùn wọn ni ẹsùn pe, “Awa kò ti kilọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yi kọni mọ? sì wo o, ẹnyin ti fi ẹkọ nyin kún Jerusalẹmu, ẹ si npete ati mu è̩jẹ ọkunrin yi wá si ori wa.” Wo bi ọkunrin naa kò ti jẹ darukọ Jesu ninu ọrọ rè̩. Idalẹbi wà lọkàn wọn nipa orukọ yii, paapaa ju lọ, olori alufaa, ẹni ti o jẹ ọkan pataki ninu awọn ti o ditẹ lati kan Jesu mọ agbelebu. Oun pẹlu awọn ọmọ-lẹyin rè̩ ti sọ nigba kan ri pe, “Jẹ ki ẹjẹ Rè̩ ki o wà lori wa ati awọn ọmọ wa”; ṣugbọn nisisiyi o dabi ẹni pe wọn bẹrẹ si mọ iwuwo è̩jẹ Jesu. Olori alufaa nikan ni orukọ Jesu ha jẹ idalẹbi fun? Oun nikan ni o ha kan Ọmọ Ọlọrun mọ’gi? Rara o! A di ẹrù è̩ṣẹ gbogbo agbaye le Jesu lori nigba ti a fi kọ sori igi agbelebu. È̩ṣẹ temi ati tirẹ ni o kan An mọ ígi; bi a ba si taku sinu è̩ṣẹ, ẹbi è̩jẹ Jesu yoo wa lori wa -- ẹbi naa yoo si pọ jọjọ!

Awọn Apọsteli Alaapọn

Asọdun diẹ le wà ninu ọrọ ti olori alufaa sọ, ṣugbọn sibẹ o fi iru aapọn ati aayan ti awọn Apọsteli n ṣe lati tan Ihinrere kalẹ hàn. “Ẹnyin ti fi ẹkọ nyin kún Jerusalẹmu.” Inu awọn Apọsteli yoo ti dùn to lati ri ọpọlọpọ eniyan ti o yi wọn ká lati gbọ ẹkọ ti o ye kooro. Nigba ti a mu ọkunrin ti o wà ni Ẹnu-ọna Tẹmpili Daradara lara da, Oluwa yàn ẹgbẹẹdọgbọn ọkàn kún Ijọ. Iyalẹnu ni iye ọkàn ti Ọlọrun n yàn kún Ijọ jẹ nigba nì ati nisisiyi pẹlu; nitori pe opitan ti o kọ akọsilẹ mimọ yii sọ bayii pe, “A si nyàn awọn ti o gbà Oluwa gbọ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:14).

Ki ni ṣe ti Oluwa kò ha ni fi yàn kún awọn ti o gbagbọ? Gbogbo wọn wà ni ọkàn kan ati inu kan. Nigba ti inunibini ba dide ti ewu si yi wọn ká, wọn yoo gbadura titi Ẹmi Mimọ yoo fi fi edidi di adura wọn, ibi ti wọn pejọ si a si mì titi. Kò si ẹni kan ti o n wá ohun ti rẹ. Wọn a maa yọ ninu iyà nitori ti wọn kà a si ohun ayọ lati jiya nitori orukọ Jesu. Bi Ijọ Ọlọrun ba ni ẹkunré̩ré̩ ọṣọ ti ẹmí wọnyi lọjọ oni, agbara ati okiki rè̩ laaarin awọn eniyan ki yoo ṣe e fẹnu sọ. A dupẹ lọwọ Ọlọrun fun gbogbo eyi ti O ti fi fun wa, ṣugbọn a kò gbọdọ ti i ni itẹlọrun si eyi. “Nko gbọdọ ṣaima kọwé si nyin, ki ng si gbà nyin niyanju lati mā ja gidigidi fun igbagbọ, ti a ti fi lé awọn enia mimọ lọwọ lẹkanṣoṣo” (Juda 3).

Idà Mimú Ọlọrun

Bi Peteru ati Johannu Apọsteli keji ti ya ẹnu wọn gbooro lati dahun ẹsùn ti igbimọ fi sùn wọn, Ẹmi Mimọ fi ọrọ ọlọgbọn kún ẹnu wọn. Otitọ naa gún awọn ti o n gbọ ọrọ wọn lọkàn ṣinṣin. Ihin ìgbala ni, bi wọn ba jẹ feti si ipe Ihinrere, ṣugbọn wọn yàn lati taku sinu igberaga wọn ati lati kọjuja si Ọlọrun. Ọrọ ti i ba jẹ “õrùn iye si iye” wa di “õrùn ikú si ikú” fun wọn. Ohun ti o wu wọn ninu ọkàn wọn ni wọn yàn. Dajudaju Ọlọrun ti fun wọn ni anfaani kan si i lati ronupiwada.

Irunu igbimọ naa pọ to bẹẹ ti wọn fi gbero lati pa awọn Apọsteli. S̩ugbọn Ọlọrun ran igbala si wọn. Ọkan ninu wọn, Farisi kan ti a n pe ni Gamaliẹli, la awọn onidajọ loye pe, o ṣe e ṣe ki awọn eniyan wọnyi jẹ ti Ọlọrun. Bi ẹkọ yii ba jẹ ti eniyan, yoo parun, ṣugbọn bi o ba jẹ ti Ọlọrun, kò si ohun ti ajọ Igbimọ Ju tabi ẹnikẹni le ṣe lati dá Ọrọ Ọlọrun duro. Igbimọ gbà ohun ti Gamaliẹli sọ, ibinu wọn si lọ silẹ diẹ. Wọn lu awọn Apọsteli, wọn si kilọ fun wọn pe ki wọn má ṣe sọrọ ni orukọ Jesu mọ, wọn si jọwọ wọn lọwọ lọ. “Nwọn si lọ kuro niwaju ajọ igbimọ: nwọn nyọ nitori ti a kà wọn yẹ si iya ijẹ nitori orukọ rè̩.” Njẹ wọn fara mọ ikilọ igbimọ? Agbẹdọ! Ni ojoojumọ ni wọn wà ni Tẹmpili – ibi ti o jẹ ojutaye ju lọ ni Jerusalẹmu, wọn n kọ ni, wọn si n waasu Jesu Kristi, ni gbogbo ile.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti olori alufaa ati awọn Sadusi fi kún fun irunu?
  2. Angẹli Ọlọrun yọ awọn Apọsteli kuro ninu tubu. Ohun ti o fara jọ eyi ha ti ṣẹlẹ nigba kan ri?
  3. Ki ni ṣe ti a fi mu awọn Apọsteli jade kuro ninu tubu? Wọn sa ni lati duro niwaju ajọ igbimọ ni ọjọ keji.
  4. Bawo ni ọkàn ajọ igbimọ ti ri nigba ti a kò bá awọn Apọsteli ninu tubu?
  5. Nibo ni a gbe ti rí awọn Apọsteli?
  6. Ẹsùn wo ni igbimọ naa fi sun awọn Apọsteli?
  7. Ki ni Peteru fi dahun?
  8. Ki ni Ọlọrun lò lati gbà awọn Apọsteli kuro lọwọ ajọ igbimọ?
  9. Iru ọkàn wo ni awọn Apọsteli fi gba ijiya wọn?