Lesson 286 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Máṣe jẹ ki ānu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walā aiya rẹ” (Owe 3:3).Cross References
I Iṣubu Sọlomọni
1. Oluwa binu si Sọlomọni, 1Awọn Ọba 11:9; Romu 1:18; 2Awọn Ọba 22:13
2. Didà majẹmu ló mú ibinu Ọlọrun wa, 1Awọn Ọba 11:10, 11, 33; 3:14; 9:2-9; Deuteronomi 17:14-20
3. A fi aanu hàn fun un nitori ti Dafidi, 1Awọn Ọba 11:12, 13; 2Samuẹli 7:11-29
II Didasẹ Alaafia ati Ikú Sọlomọni
1. Ọlọrun gbe Hadadi dide, 1Awọn Ọba 11:14-22
2. Oluwa gbe ọta miiran dide, Resoni, 1Awọn Ọba 11:23-25
3. Jeroboamu gbe ọwọ rè̩ soke si Sọlomọni, 1Awọn Ọba 11:26-36
4. Ọlọrun fi majẹmu kan fun Jeroboamu, 1Awọn Ọba 11:37-39
5. Sọlomọni n wa ọna lati pa Jeroboamu, 1Awọn Ọba 11:40
6. Sọlomọni kú, 1Awọn Ọba 11:41-43
Notes
ALAYÉAigbọran
Ni ọjọ pipẹ sẹyin, ṣaaju igba aye Sọlomọni, ati ṣaaju igba ti awọn Ọmọ Israẹli de Ilẹ Ileri, Oluwa fi aṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati ọwọ Mose nipa ọba wọn. Ọlọrun sọ nipa ọba wọn pe, “On kò gbọdọ kó ẹṣin jọ fun ara rè̩, ... Bẹni ki o máṣe kó obinrin jọ fun ara rè̩, ki àiya rè̩ ki o má ba yipada: bḝni ki o máṣe kó fadakà tabi wura jọ fun ara rè̩ li ọpọlọpọ” (Deuteronomi 17:16, 17). Sọlomọni kọ eti didi si aṣẹ Ọlọrun wọnyi ni ọjọ ogbo rè̩, nitori naa Oluwa binu si i.
Gẹgẹ bi ilana Ọlọrun, ọba Israẹli ni lati fi ọwọ ara rè̩ kọ ẹdà Ofin yii, ki o si maa ka a ni ojoojumọ; “Ki àiya rè̩ ki o má ba gbega jù awọn arakunrin rè̩ lọ, ati ki o má ba yipada kuro ninu ofin na, si ọwọ ọtún, tabi si òsi: ki on ki o le mu ọjọ rè̩ pẹ ni ijọba rè̩, on, ati awọn ọmọ rè̩, lārin Israẹli” (Deuteronomi 17:20). Ki i ṣe pe Sọlomọni ni ọrọ Ofin yii ni ikawọ rè̩ nikan, Oluwa ti fi ara han an nigba meji tọtọ, O si paṣẹ fun un lati pa ofin Rè̩ mọ.
Ki i S̩e Òpe
O hàn kedere pe Sọlomọni ki i ṣe ope nipa Ofin Ọlọrun. Aṣẹ wọnyi rọrun, Sọlomọni paapaa si kún fun ọgbọn; ṣugbọn oun kunà lati tẹle Ofin Ọlọrun ati lati lo ọgbọn ti Ọlọrun fi fun un. Ẹnikẹni ti o ṣe ainaani Ọrọ Ọlọrun lọjọ oni kò le ri awawi kan wi. Bibeli ti de ilẹ gbogbo, Ẹmi Ọlọrun si jẹ oloootọ si ọkàn kọọkan, ṣugbọn sibẹ, ogunlọgọ ọkàn ni kò rin ni ọna Ọlọrun. Diẹ ninu wọn le wi pe wọn kò mọ, ṣugbọn gbogbo wọn ni o wà ni airiwi. Bi ẹnikẹni tilẹ wà ti kò ni anfaani lati mọ Bibeli i kà, sibẹ eredi kan kò si fun un lati ya ope si imọ Ọlọrun: “Nitori ohun ti ā le mọ niti Ọlọrun o farahàn ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi i hàn fun wọn. Nitori ohun rè̩ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi oyé ohun ti a da mọ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rè̩ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi” (Romu 1:19, 20).
Awọn ifihan pataki ninu ala – bi iru eyi ti a fi han fun Sọlomọni -- jẹ iyanu gidigidi, ṣugbọn a kò fi eyi fun gbogbo Onigbagbọ. Ọdọ Oluwa ni ọgbọn ribiribi ti Sọlomọni ni ti wa; ṣugbọn imọ ọna igbala kò kan ọgbọn giga, nitori pe o han kedere to bẹẹ ti o fi le ye òpe. Abajọ ti Oluwa fi binu si Sọlomọni nitori pe o ti ri ifarahan pataki; a ti fun un ní ọgbọn ju gbogbo awọn eniyan lọ; a si ti ti ọwọ Ọlọrun bukun un lọpọlọpọ. Ọlọrun jare lati binu nitori ti Sọlomọni yipada kuro lẹyin Ọlọrun, o mọọmọ ṣe afojudi si aṣẹ Ọlọrun. Akoko imọ giga ni a wà yii, Ọlọrun si ti fi ọrọ ati ọpọ ibukun dé orilẹ-ède wa lade, ṣugbọn ọkàn ọpọ eniyan ti gbega soke si Ọlọrun.
Irẹlẹ
Irẹlẹ jẹ è̩bun rere ti o ṣọwọn. Nigba ti Sọlomọni wà ni ọdọmọde, o kún fun irẹlẹ lọpọlọpọ, ọrọ ti o jade lati ẹnu rè̩ nigba nì ni eyi pe, “Ati emi, ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ jijade ati wiwọle” (1Awọn Ọba 3:7). Pẹlupẹlu, Sọlomọni mọ bi irẹlẹ ti niyelori to, nitori awọn ọrọ rè̩ fi han pe, “Ere irẹlẹ ati ibè̩ru OLUWA li ọrọ, ọlá ati ìye” (Owe 22:4). O tun sọ bayii pe, “O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun” (Owe 16:19). O mọ pe “Igberaga enia ni yio rè̩ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá” (Owe 29:23). A saba maa n sọ pe, igbagbọ ni a fi n ri gba ju lọ, ifẹ ni n ṣiṣẹ pupọ ju lọ, ṣugbọn irẹlẹ ni i ṣe olupamọ pupọ ju lọ. Ki ibukun Ọlọrun ki o to ba wa gbe kalé̩, a ni lati “rin ni irè̩lẹ pẹlu Ọlọrun” (Mika 6:8). Akoko ikẹyin ni eyi nigba ti awọn eniyan jẹ “alagidi, ọlọkàn giga, (ati) olufẹ fāji jù olufẹ Ọlọrun lọ” (2Timoteu 3:4).
Ibọriṣa ati Igbọjẹgẹ
Nigba ti Sọlomọni té̩ pẹpẹ fun Aṣtoreti, Kemoṣi ati Moleki, awọn oriṣa Keferi, ki yoo ṣalai dá ara rẹ lare wi pe oun ṣe e lati té̩ awọn aya oun lọrun ati lati mu ki irẹpọ pọ si i laaarin oun ati awọn ẹmẹwa rè̩ ti o n ti ilu okeere wá si aafin rè̩. Boya iru ero yii ni o wà ninu awọn alakoso Igbimọ Apapọ orilẹ-ède ti wọn fi kọ lati maa fi adura ṣi ipade wọn nitori ki wọn má ba ṣẹ awọn ọmọ-ẹgbẹ wọn ti kò ni igbagbọ ninu Ọlọrun. Irira ni ẹmi igbọjẹgẹ si Ọlọrun. “Oluwa si binu si Sọlomọni.” Itiju ni fun ọkunrin tabi obinrin naa ti o yipada kuro ni ọna otitọ lati té̩ aya, ọkọ, tabi ẹnikẹni lọrun! Itiju ni fun orilẹ-ède naa ti ọrọ akọmọna rè̩ i ṣe eyi pe “Ọlọrun ni awa gbẹkẹle”, bi o ba kuna lati jẹwọ orukọ Ọlọrun nitori ti o wà laaarin awọn ti kò ni igbagbọ ninu Ọlọrun. Jẹ ki gbogbo awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ mu iduro wọn gẹgẹ bi Elijah, ti o wi pe: “Bi OLUWA ba ni Ọlọrun, ẹ mā tọ ọ lẹhin” (1Awọn Ọba 18:21).
Ọrọ
“Máṣe gbẹkẹle inilara, ki o má si ṣe gberaga li olè jija; bi ọrọ ba npọ si i, máṣe gbe ọkàn nyin le e” (Orin Dafidi 62:10). Lati ọwọ Ọlọrun ni Sọlomọni gbe gba ibukun ati ọrọ, ṣugbọn o daju pe o gbe ọkàn le ọrọ rè̩ (Wo 1Awọn Ọba 3:13). Awọn Ọmọ Israẹli sọ fun Rehoboamu pe Sọlomọni sọ ajaga wọn di wiwuwo. Eyi fi han bi ẹni pe Sọlomọni n gbà owo-ori pupọ ju bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, lati fi kó ọrọ jọ fun ara rè̩ ati fun eto inawo ijọba rè̩. “Olõtọ enia yio pọ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya” (Owe 28:20). Niwọnbi o ti jẹ pe Ọlọrun ni o n fun ni ni agbara lati ni ọrọ, awọn miiran ro pe “ere ni iwa-bi-Ọlọrun”; ṣugbọn a n kilọ fun wa lati yẹra kuro ninu ero bẹẹ, nitori pe, “Iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni. Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ. Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ, ìwọnyi yio té̩ wa lọrùn. S̩ugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ ama bọ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imā rì enia sinu iparun ati ègbé. Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ, nwọn si fi ibinujẹ pupọ gún ara wọn li ọkọ” (1Timoteu 6:5-10).
Awọn Ọta
“OLUWA si gbe ọta kan dide si Sọlomọni” (1Awọn Ọba 11:14). Ọlọrun ti gbe ijọba nla le Sọlomọni lọwọ, o si ti sọ oun paapaa di ẹni nla, ṣugbọn Ẹni ti o gbìn tun lagbara lati fa ohun ti O ti gbìn tu. Ọlọrun fun Sọlomọni ni alaafia, ṣugbọn O lagbara lati gba alaafia naa kuro lọwọ rè̩. Samuẹli sọ fun Saulu pe, “OLUWA ti kọ ọ silẹ, o si wa di ọta rẹ” (1Samuẹli 28:16). Awọn ọta wa ninu aye yii le ṣe wa nibi pupọ, ṣugbọn wo bi yoo ti buru to lati ni Ẹni naa lọta ti O lagbara “lẹhin ti o ba pa-ni tan, lati wọ-ni lọ si ọrun apadi” (Luku 12:5).
Hadadi ara Edomu ni ekinni ninu awọn ọta Sọlomọni; ekeji ni Resoni ara Damasku; ẹkẹta ni Jeroboamu, iranṣẹ Sọlomọni ati olori ile Josẹfu. Ọta ode ni awọn meji iṣaaju jẹ fun Sọlomọni, ṣugbọn ẹkẹta jẹ ọta ile, ninu ijọba rè̩ paapaa. Ọlọrun ṣe ileri ẹya mẹwaa fun Jeroboamu lẹyin ikú Sọlomọni, ṣugbọn o dabi ẹni pe Jeroboamu gba ijọba naa tikara rè̩ ki Sọlomọni to kú. Ohun ti a ba ṣe ṣaaju akoko Ọlọrun ki i yọri si rere. Bi Jeroboamu ba tẹle aṣẹ Oluwa, ile rè̩ yoo wà titi, ijọba rè̩ yoo si dabi ti Dafidi.
Ọgbọn
Sọlomọni ni ọgbọn pupọ, ṣugbọn o pada kuro lẹyin Oluwa. Jeroboamu jẹ ọkunrin alagbara -- oṣiṣẹ eniyan -- ṣugbọn kò feti si aṣẹ Ọlọrun: “Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọn aiye yi di wère?” “Kì iṣe ọpọ awọn ọlọgbọn enia nipa ti ara, ki iṣe ọpọ awọn alagbara, kì iṣe ọpọ awọn ọlọlá li a pè” (1Kọrinti 1:20, 26). Ki ni anfaani ọgbọn aye yii bi kò ba fun ni ni iye ainipẹkun? O san ki a pe wa ni “òpe” ki a wọ Ijọba Ọrun nikẹyin ju pe ki a pe wa ni ẹni nlá, kí a lọ si ọrun apaadi.
Sọlomọni ṣe awari ohun gbogbo ti o wà labẹ oorun. O dán ọgbọn wò; o si dán ọrọ wò pẹlu; o dán idaraya; orin ati ọti waini wò; o tilẹ lọ sinu iwa yẹpẹrẹ ti ibọriṣa. S̩ugbọn o pari rè̩ si pe, “asan ni gbogbo rè̩ ati imulẹmofo” (Oniwasu 1:14) gẹgẹ bi o ti ṣiro rè̩ si. O si pari ohun gbogbo si eyi pe, “Opin gbogbo ọrọ na ti a gbọ ni pe: Bè̩ru Ọlọrun ki o si pa ofin rè̩ mọ: nitori eyi ni fun gbogbo enia” (Oniwasu 12:13). A ni ireti pe Sọlomọni kẹkọọ ninu ọrọ ìkẹyin yii o si ronupiwada ṣaaju ọjọ ti o “sùn pẹlu awọn baba rẹ, a si sin i ni ilu Dafidi baba rè̩” (1Awọn Ọba 11:43).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Oluwa fi binu si Sọlomọni?
- Njẹ Dafidi tabi Saulu yipada si ibọriṣa?
- Ki ni ṣe ti Hadadi ara Edomu fi ṣọtẹ si Sọlomọni?
- Ki ni ṣe ti Oluwa fi fa ọwọ idajọ rè̩ sẹyin ni ọjọ Sọlomọni?
- Ilu wo ni awọn mẹta ti o ṣọtẹ si Sọlomọni ti jade wa?
- Ipo wo ni Jeroboamu dimu ki o to salọ si Egipti?
- Ipa meji wo ni o wà ninu ileri ti Ọlọrun ṣe fun Jeroboamu?
- Ki ni yoo mu ki ile Jeroboamu maa jọba titi?
- Bawo ni Sọlomọni ti dagba to ki o to ku?
- Njẹ Sọlomọni gbadun anfaani ileri ti Ọlọrun ṣe fun un ninu 1Awọn Ọba 3:14?