1Awọn Ọba 12:1-33; 14:21-23; 2Kronika 12:1-16

Lesson 287 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọna aṣiwere tọ li oju ara rè̩: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọn” (Owe 12:15).
Cross References

I Iṣọtẹ ni S̩ekemu

1. Awọn ẹya ti iha ariwa beere pe ki a din owo ori ti wọn n san kù fun wọn, 1Awọn Ọba 12:1-5

2. Ọba beere fun imọran lọwọ awọn ọdọ ati awọn agba, 1Awọn Ọba 12:6-11; Owe 1:25-33

3. Ọba fesi gẹgẹ bi imọran ti awọn ọdọmọkunrin fi fun un, 1Awọn Ọba 12:12-15

4. Awọn ẹya ti iha ariwa ṣọtẹ, 1Awọn Ọba 12:16-19

II Apa kan Ijọba Israẹli ni iha Ariwa

1. A fi Jeroboamu jọba, 1Awọn Ọba 12:20, 25

2. O ṣe eto ẹsin kan ti yoo jẹ anfaani fun ijọba rè̩, 1Awọn Ọba 12:26-33; Galatia 1:6

III Apa keji Ijọba Israẹli ni iha Guusu

1. Rehoboamu ṣeto fun ati ja ogun, ṣugbọn o feti si ikilọ Ọlọrun lati ṣiwọ kuro nibẹ, 1Awọn Ọba 12:21-24

2. Rehoboamu fa Juda lọ sinu ibọriṣa siwaju si i, 1Awọn Ọba 14:21-23; 2Kronika 12:1

3. Oluwa lo S̩iṣaki, Ọba Egipti, lati jẹ wọn ni iya, 2Kronika 12:2-5; Awọn Onidajọ 2:14; 3:7, 8, 12

4. Ọlọrun fi aanu han nigba ti Rehoboamu rè̩ ara rè̩ silẹ, 2Kronika 12:6-12; 1Awọn Ọba 21:29

5. Ni kukuru, ijọba Rehoboamu jẹ ijọba ti o buru jai, 2Kronika 12:13-16

Notes
ALAYÉ

Apẹẹrẹ Buburu

“Nitõtọ mo korira gbogbo lāla mi ti mo ṣe labẹ õrùn; nitoriti emi o fi i silẹ fun enia ti mbọ lẹhin mi. Tali o si mọ bi ọlọgbọn ni yio ṣe tabi aṣiwère?” (Oniwasu 2:18, 19). Ohun rere ni ẹdun ti Sọlomọni ni nipa iwa ọmọ rè̩, ṣugbọn bawo ni i ba ti dara to bi o ba ti fi apẹẹrẹ rere silẹ fun un lati tẹle. Ohun ti o ṣe ni laanu ni pe Sọlomọni yipada kuro lẹyin Oluwa ni igba ogbo rè̩. O ṣoro lati gbagbọ pe ẹni ti Oluwa bukun-fun lọpọlọpọ ju gbogbo ọba iyokù lọ ni lati kọ Ọlọrun silẹ ki o si yipada si ibọriṣa. Bawo ni o ṣe le mu ọmọ rè̩ wa si imọ Ọlọrun otitọ nigba ti igbesi-aye oun paapaa ati iwa rè̩ ṣe lodi? Bawo ni apẹẹrẹ ti o fi silẹ fun ọmọ rè̩ ati awọn eniyan pẹlu ti buru jai to! Awọn obi miiran lode oni n fẹ ki awọn ọmọ wọn tẹle ipa ọna ti awọn paapaa ti kọ silẹ. Bawo ni yoo ti dùn to bi awọn paapaa ba le fi apẹẹrẹ fun awọn ọmọ wọn!

Idajọ Wàrawàra

Gẹrẹ ti Sọlomọni kú, awọn eniyan Israẹli ranṣẹ si Jeroboamu ki o pada lati Egipti. Oluwa ti ṣeleri pe Oun yoo fun un ni ẹya mẹwaa, awọn eniyan si mọ bẹẹ, nitori naa, wọn n wa a kiri. Ipasẹ rè̩ ni awọn ẹya Israẹli mẹwaa ti iha ariwa tẹle lati tọ Rehoboamu wa pe ki o din owo ori ti wọn n san kù.

Ọlọrun ṣe Sọlomọni ni ọlọgbọn lọpọlọpọ, ṣugbọn a du ọmọ Sọlomọni ni laakaye lati ṣe ohun ti o tọ ni akoko yii. Olufunni ni gbogbo ẹbun rere ati ẹbun pipe le fa ọwọ aanu Rè̩ sẹyin nigba ti O ba fẹ mu idajọ ṣẹ. Oluwa, Ẹni ti o fi ijọba, ogo ati ọla fun Nebukadnessari ni o rè̩ è̩ silẹ ti o si ra á niye. O lagbara lati rè̩ awọn agberaga silẹ. “Ọba kò si fi eti si ti awọn enia na; nitoriti ọran na ati ọwọ OLUWA wá ni” (1Awọn Ọba 12:15). Èsì wàrawàra ti Rehoboamu fun awọn eniyan wọnyi ni Ọlọrun lo lati gba apa kan ijọba kuro lọwọ rè̩.

Isìn Atọwọda

Nigba ti Rehoboamu kọ lati mu ibeere wọn ṣẹ, awọn ẹya mẹwaa iha ariwa ṣọtẹ si ọba, wọn si fi Jeroboamu jọba. Ki ijọba Jeroboamu ba le fẹsẹ mulẹ, o ni lati rin ninu ofin Oluwa. Kaka ki o gbọran ki o si gbẹkẹle Ọlọrun, o tẹle ọgbọn ara rè̩, o si gbe isin ara rè̩ kalẹ. Kò wa otitọ bi kò ṣe agalamaṣa ti o fẹ fi gbe ijọba rè̩ ro. O gbe isin atọwọda ti o rọrun fun awọn Ọmọ Israẹli kalẹ, ogunlọgọ si tẹwọ gba a. Akọmọna ti o fi gbe isin rè̩ kalẹ ni pe, “O pọju fun nyin lati mā goke lọ si Jerusalẹmu,” o si tọwọ Israẹli bọ isin ti o kún fun ase ati apejẹ, ṣugbọn ti kò ni agbara ninu lati tun igbesi-aye awọn eniyan ṣe.

Iru ẹsin gbajumọ ti o kún fun ase ti Jeroboamu gbe kalẹ fi ara jọ pupọ ẹsin Igbagbọ afẹnujẹ ti ode-oni. Ọpọlọpọ eniyan ni o ti yapa kuro ninu ilana igba ni lati tọ ọna ti o rọrun. Wọn kò ka a si ohun danindanin fun wọn mọ lati kunlẹ ni ibi pẹpẹ atijọ nì, ni ironupiwada pipe, lati di ọmọ Ọlọrun. Bi o ba ti gbọwọ lọwọ alufaa, ti o si kọwọ bọ iwe pẹlẹbẹ, wọn a si wi pe, “gba Kristi ni Olugbala rẹ”, lẹyin eyi wọn ti gba pe o ti di Onigbagbọ. S̩ugbọn igbala tootọ tayọ eyi. Adura fun aanu Ọlọrun pẹlu ẹkun kikoro ni ironupiwada tootọ, iyipada ọkàn ati ẹri lati ọdọ Ọlọrun pe a dari è̩ṣẹ ji, ni ọna ti Ọlọrun la silẹ ti awọn ti o fẹ wa ni imurasilẹ fun Ọrun si n gba. Ki ni anfaani ilana isìn, apejẹ ati isin afaraṣe bi oluwarẹ ko ba jogun iye ainipẹkun nikẹyin?

Isin Jeroboamu dun mọ awọn ti o fẹ è̩ṣẹ, awọn ti kò ri ohun ti o buru ninu ọti mimu, ijo tabi awọn adùn è̩ṣẹ miiran gbogbo. Aye kún fun awọn ẹlẹsìn ti kò gbagbọ pe o ṣeeṣe lati gbe igbesi-aye ailẹṣẹ lode oni. Wọn di oju wọn si otitọ, wọn si n wa ọna miiran lati yẹ Ọrọ Ọlọrun yii silẹ ti o sọ gbangba pe, “Ẹnikẹni tí a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ” (1Johannu 3:9). Ọpọlọpọ awọn ti o n pe ara wọn ni ẹlẹsìn ni o n jalankato pe wọn wà ni ọna otitọ, bi o tilẹ jẹ pe wọn n gbe igbesi-aye è̩ṣẹ, to bẹẹ ti ẹnikẹni yoo fi bè̩ru pẹlu iwariri wi pe awọn wọnyi wà lara awọn ti kò “gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là.” Ọrọ Ọlọrun sọ bayii pe, “nitori eyi, Ọlọrun rán ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gbà eke gbọ: ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo” (2Tẹssalonika 2:10-12).

Eke Olukọni

Boya eniyan le maa ro pe adabọwọ isìn ti Jeroboamu gbe kalẹ ki yoo pẹ to bẹẹ titi ki a to gbe e tì si apa kan, ṣugbọn è̩ṣẹ ti fidi mulẹ ṣinṣin ninu ọkàn ẹda, ọkàn ti kò di atunbi si buru to bẹẹ ti Israẹli fi tẹle isin ibọriṣa (ẹgbọrọ malu) titi a fi kó wọn lẹru ni nnkan bi igba ọdun lẹyin naa. Woli ni sọ fun ni wi pe, “Ọkàn enia kún fun è̩tan jù ohun gbogbo lọ, o si buru jayi! Tani o le mọ ọ? Emi, OLUWA, ni iwá awari ọkàn enia, emi ni ndan inu wò, ani lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọna rè̩, ati gẹgẹ bi eso iṣe rè̩” (Jeremiah 17:9, 10). Ọkàn awọn ẹlomiiran gbooro to bẹẹ ti wọn ṣe tan lati gba ohunkohun ti a ba ti fi orukọ ẹsìn pe gbọ, ṣugbọn a gbọdọ ṣọra nipa awọn eke woli. “Awọn woli eke wà larin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ mu adámọ ègbé wọ inu nyin wá, ani ti yio sẹ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn. Ọpọlọpọ ni yio si mā tẹle ìwa wọbia wọn; nipa awọn ẹniti a o fi mā sọ ọrọ-odi si ọna otitọ. Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mā fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falè̩ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé. Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti wọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun-apadi ...” (2Peteru 2:1-4). Ki i ṣe gbogbo awọn ti o n pe orukọ Jesu ni Ọlọrun yoo tẹwọ gba. O fi ye wa wi pe, bi a ba fẹ jogun Ijọba Ọrun, a ni lati ṣafẹri otitọ, ki a si maa gbe igbesi-aye ailẹṣẹ.

Rehoboamu

Rehoboamu kò mọ bi iṣọtẹ ti fidi mulẹ to titi igba ti o fi ran Adoramu, ti i ṣe olori iṣẹ-irú, lọ si Israẹli. Nigba naa ni Rehoboamu yara gun kẹkẹ rè̩ lati sa lọ si Jerusalẹmu fun aabo; o si kó gbogbo ẹgbẹ-ogun ẹya Juda ati Bẹnjamini jọ lati fopin si ọtẹ naa. O hu iwa ọlọgbọn, nitori ti o feti si ọrọ Oluwa, oun kò si jade lọ lati ba Israẹli ja mọ. Rehoboamu ati awọn ijoye rè̩ pẹlu huwa ọlọgbọn nitori ti wọn rè̩ ara wọn silẹ nigba ti S̩iṣaki ọba Egipti goke wa lati ba Jerusalẹmu ja; ṣugbọn Rehoboamu “ṣe buburu, nitori ti kò mura ọkàn rè̩ lati wá OLUWA” (2Kronika 12:14).

Opin Akoko Alaafia

Gẹrẹ ti Sọlomọni kú ni ẹwà ijọba ti Ọlọrun fi fun un ti wọmi nitori ibọriṣa. A pin ijọba naa si meji, awọn ẹya mẹwaa ti o wà ni iha ariwa ni a n pe ni Israẹli, awọn ẹya meji iyoku ti o wa ni iha guusu ni a n pe ni Juda. Ki i ṣe pe ipinya de ba ijọba yii nikan, ṣugbọn ni ọdun karun-un ti Rehoboamu bẹrẹsi jọba, S̩iṣaki ọba Egipti wa si Jerusalẹmu o si kó iṣura ile Oluwa ati ti ile ọba lọ. Dipo asà wura, Rehoboamu rọ asà idẹ. Wọn sa ipa wọn lati mu ki ẹwa ode ki o wà sibẹ, ṣugbọn ogo tootọ ti fi Jerusalẹmu silẹ lọ; wura rè̩ ti di idẹ, ayọ rè̩ si dabi “kimbali olohùn goro.” O yẹ ki awọn Ọmọ Israẹli ki o sọkun, ki wọn si ṣọfọ, o si yẹ ki awọn ọmọbinrin Jerusalẹmu ki o pohun rere ẹkun nitori ti ogo ijọba wọn ti wọmi, nitori pe Juda kọ Ọlọrun rè̩ silẹ!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni imọran ti Israẹli fi siwaju Rehoboamu?
  2. Ki ni iwọ ti ro idahun rè̩ si?
  3. Ki ni ṣe ti Rehoboamu fi fesi bẹẹ?
  4. Awọn ẹya wo ni o wà pẹlu Jeroboamu? Meloo ni o wà pẹlu Rehoboamu?
  5. Fun ọdun meloo ni ijọba naa fi wà lọtọọtọ?
  6. Ki ni kò jẹ ki Rehoboamu bá Israẹli ja?
  7. Ki ni ṣe ti Jeroboamu fi gbe ère malu wura kalẹ?
  8. Nibo ni Jeroboamu gbe ni imọ isìn ti o gbe kalẹ yii?
  9. Bawo ni Ọlọrun ṣe fi aanu han fun Rehoboamu?
  10. Ki ni koko ohun ti a sọ nipa ijọba Rehoboamu?