Owe 1:1-33; 2:1-22

Lesson 275 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọn, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!” (Jobu 28:28).
Notes

Ohun ti Sọlomọni Yàn

Sọlomọni, ọmọ Dafidi, jẹ ẹni ti o lọgbọn pupọ. Lẹyin ikú baba rè̩, Sọlomọni jọba lori awọn Ọmọ Israẹli. Ni akoko naa Oluwa fara han Sọlomọni O si wi pe, “Bère ohun ti emi o fi fun ọ.” Sọlomọni mọ pe ẹrù nla ni lati jọba lori iru ọpọlọpọ eniyan bẹẹ. Sọlomọni beere pe ki Ọlọrun fun oun ni “ọkàn imoye” lati ṣe idajọ awọn eniyan naa (1Awọn Ọba 3:9). Inu Ọlọrun dùn si ohun ti Sọlomọni yàn yii, O si fun un ni ọkàn imoye gẹgẹ bi o ti beere. Lẹyin ọgbọn, Ọlọrun fun Sọlomọni ni ọlá, ati ọrọ pẹlu, ati ẹmi gigun. Ọlọrun n fẹ ki Sọlomọni gbọran si ofin Oluwa (1Awọn Ọba 3:13, 14).

Ọgbọn lati ọdọ Ọlọrun

Ọlọrun bukun fun Sọlomọni O si fun un ni ọgbọn ti o jù ti gbogbo eniyan lọ (1Awon Ọba 4:31). Ọpọ eniyan ni o gbọ nipa ọgbọn Sọlomọni. Wọn lọ lati bẹ ẹ wo ki wọn le gbọ ọrọ rè̩ (I Awọn Ọba 4:34). A ti kọ nipa Ayaba S̩eba ẹni ti o tọ Sọlomọni lọ lati ri idahun gbà si awọn ibeere rè̩ ti o ṣoro (Ẹkọ 259).

Sọlomọni lo ọgbọn ti Ọlọrun fi fun un. O kọ “ẹgbẹrun o le marun” (1,005) orin silẹ, o si pa ẹgbẹẹdogun (3,000) owe (1Awọn Ọba 4:32). A kọ wọn silẹ ki awọn eniyan ba le jèrè ninu ọgbọn ti Ọlọrun fun Sọlomọni, bi o tilẹ jẹ pe Sọlomọni tikara rè̩ kò lo igbesi-aye rè̩ jalẹ gẹgẹ bi awọn owe ti o pa.

Owe

Owe jẹ ọrọ ṣoki ti n kọ ni ni ẹkọ. Owe jẹ gbólóhùn ọrọ diẹ ti n ṣe alaye ohun pupọ fun ni. A ki i fi gbolohun ọrọ miiran kún owe ki itumọ rè̩ to ye ni. Igba pupọ ni Jesu n fi awọn owe ti n kọ ni ni ẹkọ sọrọ. Ọpọlọpọ gbolohun ni o wà ninu wọn, ṣugbọn iwa rere tabi è̩kọ ti o wà ninu wọn ni a le pe ni owe.

Awọn owe miiran tun wà yatọ si ti Sọlomọni. A maa n pe wọn ni ọrọ àṣàrò, ọrọ laelae, ọrọ itọni-sọna, ati ọrọ igba nì. Ọpọ igba ni a maa n sọ wọn mọ ọrọ, a si rì ì wi pe otitọ ni wọn. Awọn owe ti awọn eniyan pa yii, bi o tilẹ jẹ pe wọn ti mú ki ọpọlọpọ eniyan ṣe rere, sibẹ wọn kò mu ki awọn eniyan wá Ọlọrun ati igbala Rè̩. Iwe Owe ju akojọpọ awọn owe lasan lọ, nitori pe nipasẹ imisi Ọlọrun ni a fi ko wọn jọ, wọn si ṣe iyebiye fun anfaani wa nipa ti ẹmi. A tọka si diẹ ninu awọn owe Sọlomọni ninu Majẹmu Titun, a si kọ wọn silẹ nibẹ pẹlu. (Wo Romu 2:6; Heberu 12:5, 6; 1Peteru 4:8). Ọpọlọpọ wọn ni a mọ daradara; awọn eniyan ti kò tilẹ mọ Bibeli pupọ si n lo wọn nigba gbogbo lode oni.

Sọlomọni kò kọ awọn owe yii lati fi gba okìkí gẹgẹ bi awọn ti n ṣe iwe tabi lati fi gba orukọ nla fun ara rè̩. O kọ wọn silẹ fun anfaani ati fun ilo gbogbo eniyan, ki i ṣe fun kiki awọn Ọmọ Israẹli, awọn ti o n jọba le lori nikan. Gẹgẹ bi awọn owe Sọlomọni wọnyi ti wulo fun awọn Ọmọ Israẹli nigba ti wọn, bẹẹ gẹgẹ ni gbogbo wọn lai kù ọkan silẹ wulo fun wa lọjọ oni. A sọ bayii pe kò si gbolohun ọrọ kan ninu gbogbo Iwe Owe ti o ba igbà ti awọn Ọmọ Israẹli mu ti kò si ṣe deedee pẹlu igbesi-aye gbogbo eniyan lonii.

Niniyelori Wọn

Awọn owe naa yoo ran eniyan lọwọ lati mọ rírì imọ ati ìtọni, wọn yoo si jé̩ ìranwọ lati huwa ati lati maa sọrọ ọlọgbọn. Wọn yoo jẹ ìranwọ fun wa lati le mọ iyatọ laaarin rere ati buburu, yoo si maa tọni si ọna ki a má ba ṣìṣe. Wọn yoo jẹ iranwọ fun eniyan lati ṣe akoso ọrọ rè̩ bi o ti tọ, yoo si maa tọ ni sọna lati maa rin ninu otitọ ati idajọ.

Ẹnikẹni ti o ba fẹ ni o ni anfaani lati jere nipasẹ akọsilẹ Sọlomọni wọnyi. Wọn rọrun, itumọ wọn si ja gaara to bẹẹ ti o le fi ye gbogbo eniyan. Wọn jẹ anfaani fun awọn ti wọn n fẹ lati kọ è̩kọ, ti wọn si mọ pe o yẹ fun wọn lati kọ è̩kọ. Ọkunrin gbajumọ kan ti o n ṣe iwe, ẹni ti o kọ ọpọlọpọ ori ninu Iwe Owe sori nigba ọdọ rè̩, sọ nikẹyin wi pe awọn owe wọnyi ni o niye lori ju lọ ti wọn si ṣe pataki ju lọ ninu gbogbo ẹkọ ti oun kọ.

Bi o tilẹ ṣe pe awọn ọmọ Sọlomọni ni o fi owe wọnyi bá sọrọ, sibẹsibẹ ki i ṣe kiki awọn ọmọ rè̩ ni owe yii wa fun, wọn wà fun awọn ọmọ ẹlomiiran pẹlu. O dàbi ẹni pe awọn ọdọ ni ọpọlọpọ ninu owe wọnyi wa fun, nitori pe igba yii jé̩ igba ti a n kọ è̩kọ, igba ti eniyan maa n gba è̩kọ si ọkàn, igba ti a le di nnkan mu ṣinṣin ninu ero wa, ti a si le ranti wọn daradara. Igba ọdọ pẹlu jẹ igba ti iriri eniyan kò to nnkan rara ti o si yẹ lati ni ofin ti yoo maa ṣe amọnà wa.

Lati Bẹru Ọlọrun

Sọlomọni fi ọna meji lelẹ nipasẹ eyi ti a le fi kọ ọgbọn. Sọlomọni kò damọran pe ki a ka ọpọlọpọ iwe ki a si lọ si ile ẹkọ fun ọpọlọpọ ọdun. Wọnyi kò le ṣe e ṣe fun gbogbo eniyan, ṣugbọn ohun ti o ṣe e ṣe fun gbogbo eniyan ni Sọlomọni fi lelẹ. Sọlomọni wi pe ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ. Bi eniyan ba bẹru Ọlọrun, yoo fi ọwọ fun Ọlọrun ati fun Ọrọ Rè̩ pẹlu nipa ṣiṣe ifẹ Ọlọrun ati ni sisin In.

Awọn ti wọn n wi pe kò si Ọlọrun a maa fi ara hàn bi ẹni pe akẹkọ ati olufẹ ọgbọn ni tootọ ni awọn jé̩, ṣugbọn wọn jé̩ ọta ati ajeji si ọgbọn tootọ, nitori pe wọn kò ni inudidun si oju rere Ọlọrun, wọn kò si bẹru ibinu Rè̩. “Aṣiwere wi li ọkàn rè̩ pe, Ọlọrun kò si” (Orin Dafidi 14:1).

Lati Bọwọ fun Awọn Obi Wa

“Ọmọ mi, gbọ ẹkọ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ ofin iya rẹ silẹ.” Nigba ti ọmọde ba gbọran ti o ba si pa ọrọ awọn obi rẹ mọ, eyi ni bibu ọlá fun wọn. Ninu ofin karun-un a sọ fun wa pe ki a bọwọ fun baba ati iya wa (Ẹksodu 20:12). Lati bọwọ fun awọn obi ni lati bu ọlá fun wọn ati lati gbọran si wọn lẹnu. Sọlomọni ni in lọkàn wi pe awọn obi – baba ati iya – yoo kọ awọn ọmọ, ati pe wọn o si lo agbara ti wọn ni lori wọn lati fun wọn ni ofin fun anfaani awọn ọmọ. Sọlomọni ni in lọkàn wi pe ki i ṣe kiki pe ki awọn obi fun awọn ọmọ ni ofin nikan, ṣugbọn pe wọn ni lati kọ awọn ọmọ wọn pẹlu.

A ṣe ileri èrè kan fun awọn ti wọn bu ọlá fun awọn obi wọn, ti wọn si pa è̩kọ wọn mọ. “Awọn ni yio ṣe ade ẹwà” niwaju Ọlọrun, eyi ti o ṣe iyebiye ju ọgbọn aye ati ọrọ aye lọ. Paulu kọ nipa eyi si awọn ara Efesu. O wi pe: “Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn obi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ. Bọwọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri), ki o le dara fun ọ, ... Ati ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu: ṣugbọn ẹ mā tọ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa” (Efesu 6:1-4).

Ẹgbẹ Buburu

Sọlomọni kilọ fun ni nipa awọn ti wọn le fi ibalo wọn mu ni ṣina. Diẹdiẹ a le fa eniyan lọ si ọna buburu. Kikó ẹgbẹ buburu le jẹ iṣisẹ kin-in-ni si iṣubu. Bibeli sọ fun ni pe “Ẹgbé̩ buburu bà iwa rere jẹ” (1Kọrinti 15:33); “ẹniti o ṣe ẹlẹgbẹ jẹguduragudu, o ti baba rè̩ li oju” (Owe 28:7). Jehu ọmọkunrin Woli kan wi fun Jehoṣafati Ọba Juda pe: “Iwọ o ha ma ràn enia buburu lọwọ, iwọ o si fẹran awon ti o korira OLUWA? njẹ nitori eyi ni ibinu ṣe de si ọ lati ọdọ OLUWA” (2Kronika 19:2). Awọn wo ni ọrẹ rẹ timọtimọ? O ha le wi gẹgẹ bi ti Onipsalmu pe “Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bè̩ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ rẹ mọ” (Orin Dafidi 119:63)?

Iṣisẹ kin-in-ni si iṣubu le jẹ gbigba ipe lati ọwọ awọn eniyan buburu bayii, “Ba wa ká lọ.” Lẹyin eyi wọn o fẹ ki o jẹ ẹgbẹ wọn ki o ba le ni ipin ninu iwa buburu wọn ati èrè wọn pẹlu. A fi alailaanu ati wọbia ọlọṣa kan ṣe apejuwe. Nigba ti a ba fa eniyan lọ sinu è̩ṣẹ, ẹni naa yoo padanu ohun rere gbogbo nipa ti ẹmi. Ọna eniyan buburu jẹ irira fun Ọlọrun, o si jẹ ipalara fun eniyan. Sọlomọni wi pe, “Fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọna wọn.” O tè̩ si ọna iparun. Njẹ o ti i sọkalẹ gè̩rẹgè̩rẹ oke kan ri? Iwọ o ranti pe o rọrun lati sare sọkalẹ ju lati rin lọ; ṣugbọn bi o si ti n sọkalè̩ si i, bẹẹ ni ire sisa rẹ n pọ si i – titi yoo fi dàbi ẹni pe o kò ni le dasẹ duro mọ. Kiakia ni ire naa n pọ si i titi o fi ṣakiyesi pe bi ohun kan kò ba da ọ duro, iwọ yoo fi ara pa. Bẹẹ gẹgẹ ni o ri pẹlu awọn ti n ṣubu lọ sinu iparun. Wọn kò pinnu lati rin jinna bẹẹ tẹlẹ, ṣugbọn wọn dede ri i pe wọn n jin sinu ọfin è̩ṣẹ ju bi wọn ti lero tẹlẹ ri. Afi bi wọn ba kigbe pe Ọlọrun fun iranwọ, bi bẹẹ kọ wọn o ṣubu sinu iparun.

A n kilọ fun olukuluku. Iwọ o ha ṣe bi ẹyẹ ti o jọwọ ara rè̩ fun tàkúté lati mú nitori pe o ni iwọra lati jẹ ohun ọdẹ, bi o tilẹ jẹ pe o ri àwọn naa ti a dẹ silẹ ni gbangba?

Yiyan Tirẹ

Bi Sọlomọni ti ni anfaani lati yan eyi ti o wu u, bẹẹ gẹgẹ ni ẹni kọọkan wa pẹlu ni anfaani yii. Oluwa jẹ oloootọ lati pe gbogbo eniyan pe ki wọn tẹle Oun. A le yan lati ni ibẹru Ọlọrun, eyi ti i ṣe ipilè̩ṣè̩ ọgbọn (Owe 9:10). Awọn eniyan wà ti oye wọn nipa ohun ti ẹmi kò to nnkan, wọn si yàn lati wà lai ni in ju bẹẹ lọ -- wọn “fẹ aimọkan.” Awọn ẹlomiiran a maa fi ohun mimọ ṣè̩fè̩, wọn a si maa kẹgan awọn ti o gbẹkẹle Ọlọrun -- wọn a “ma ṣe inudidun ninu iwa è̩gan wọn.” Awọn ẹlomiiran korira pe ki a ba wọn sọrọ nipa Ọlọrun ati gbigbe igbesi-aye ododo. Wọn “korira imọ.”

Wọn ti yan lati wa lai ni Ọlọrun, ṣugbọn sibẹ Ọlọrun n ba wọn wi, O si n kilọ fun wọn lati yipada kuro ninu ọna buburu wọn gbogbo. Ẹri-ọkàn wọn n tako wọn pe wọn kò huwa ọlọgbọn. Ọlọrun ti pe wọn, ṣugbọn wọn ko feti si ohùn Rè̩. Ọlọrun ti na apa Rè̩ lati ran wọn lọwọ, ṣugbọn wọn kọ lati rọ mọ Ọn. Woli Isaiah wi pe, “Ẹ wá OLUWA nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e, nigbati o wà nitosi” (Isaiah 55:6). Sọlomọni pẹlu kọ wa pe akoko kan n bọ ti eniyan yoo ke pe Oluwa, ti Ọlọrun ki yoo si da a li ohun. Awọn ti wọn ti kọ lati feti si ohun Ọlọrun yoo ke ni ọjọ idaamu wọn, ṣugbọn Ọlọrun yoo kọ lati tẹti si wọn. Wọn ti kọ lati ni ibẹru Ọlọrun ṣugbọn ibẹru miiran yoo de ba wọn (Owe 1:26). Ipaya wọn yoo di ipọnju ati irora aya. Wọn yoo wá Ọlọrun ṣugbọn wọn ki yoo ri I. Wọn yoo ke pe Ọlọrun, ṣugbọn ki yoo dahun. Iwọ ha ti tẹti silẹ si ipe Ọlọrun, ki o si yàn lati ni ibẹru Ọlọrun ninu ọkàn rẹ?

Iparun tabi Iye

Ki ni ṣe ti iwọ ki yoo fi jẹ ọlọgbọn ki o si yipada si Ọlọrun nigba ti O ṣi n gbọ adura? Olukọ rẹ ni Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi yoo ran ọ lọwọ lati wá Ọlọrun, lati ronupiwada ati lati beere lọwọ Ọlọrun pe ki O tọ ọ gẹgẹ bi imọ Rè̩.

Awọn ti wọn pinnu lati fara mọ ọna buburu yoo ri i daju pe è̩ṣẹ a maa fa ikú. “È̩ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bi ikú” (Jakọbu 1:15). “Ikú li ère è̩ṣẹ, ṣugbọn è̩bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 6:23). Ọlọrun ké ni ohun rara si awọn Ọmọ Israẹli pe, “Ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọna buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, ile Israẹli?” (Esekiẹli 33:11).

Awọn ti o tẹti silẹ si ipe Ọlọrun, ti wọn si gbọran si I, yoo wà ni ibi aabò ati inu-didun. Oluwa jẹ asà fun awọn ti n rìn deedee. Awọn ọrọ Sọlomọni wọnyi dabi awọn ọrọ baba rè̩. Dafidi wi pe, “OLUWA li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi” (Orin Dafidi 18:2). Oluwa yoo tọju awọn eniyan Rè̩, yoo si pa wọn mọ, ṣugbọn wọn ni lati gbọran ki wọn si gbẹkẹle Ọlọrun. Paulu wi pe: “Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu” (Efesu 6:11). (Ka Efesu 6:13-17 nipa oriṣiriṣi nnkan wọnni ti wọn jẹ ihamọra naa, ọkan ninu eyi ti i ṣe “apata igbagbọ, nipa eyiti ẹnyin ó le mā fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì”).

Ninu Bibeli a kà wi pe: “Bi o ba kù ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bere lọwọ Ọlọrun, ẹniti ifi fun gbogbo enia li ọpọlọpọ, ti kì isi iba-ni-wi; a o si fifun u” (Jakọbu 1:5). Ọgbọn ti Ọlọrun n fi fun ni yii yatọ si ẹkọ ti a n kọ ninu aye. Eniyan ni lati lọ si ile-ẹkọ ki o ba le kọ ẹkọ lati ni idagbasoke ninu imọ nitori pe eyi yoo jẹ iranwọ fun ni lati ni iriri ati imọ lati le gbadun aye ni kikún, ki a si le ṣiṣẹ fun ounjẹ-oojọ wa, bi Oluwa ba fa bibọ Rè̩ sẹyin. Bi iwọ kò ba kọ bi a ti n kawe, bawo ni iwọ yoo ti ṣe le kẹkọọ lati inu Biberi rẹ? S̩ugbọn lati ni è̩kọ ati imọ kò tó: a ni lati ni Oluwa ati ọgbọn Rè̩.

Jobu n beere wi pe: “Nibo li a o gbe wá ọgbọn ri, nibo si ni ibi oye?” (Jobu 28:12). Jobu si tun dahun pẹlu pe, “Kiyesi i, Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọn, ati lati jade kuro ninu ìwa buburu eyi li oye!” (Jobu 28:28). A paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati gbọran, lati pa ofin Oluwa mọ ati lati maa ṣe wọn. “Nitoripe eyi li ọgbọn nyin ati oye nyin li oju awọn orilẹ-ède, ti yio gbọ gbogbo ìlana wọnyi, ti yio si wipe, Ọlọgbọn ati amoye enia nitõtọ ni orilẹ-ède nla yi” (Deuteronomi 4:6). Ọpọlọpọ eniyan ni wọn ni imọ ohun ti o tọ, ṣugbọn lati ni ọgbọn ni lati ṣe ohun ti o tọ, ti o si yẹ. (Ka Jakọbu 3:13-18, eyi ti o sọ nipa ọgbọn ti aye ati ti ọrun).

Iṣura

Sọlomọni gbani niyanju lati maa lepa ọgbọn Ọlọrun gẹgẹ bi a ti n wa iṣura ti a fi pamọ. Ọpọ eniyan ni o n fẹ lati dá wà, ki wọn si maa fi gbogbo agbara wọn ṣiṣẹ fun igba pipé̩, nibi ti o lewu, lati wá ohun alumọni aye yii. Wọn a maa fi ounjẹ ti o tọ, itura ati isinmi dù ara wọn nigba pupọ. Ọkunrin kan ti a sọ nipa rè̩ fun ni ninu owe ti Jesu pa ta gbogbo ohun ti o ni, lati ra perli olowo iyebiye kan (Matteu 13:46). Bawo ni a ti n fi gbogbo agbara wa lepa nnkan ti Ọlọrun to, bawo ni a si ti n ṣiṣẹ fun ohun ti i ṣe ti Ọlọrun to?

Ninu Orin Dafidi, Dafidi pẹlu kọ akọsilẹ nipa è̩rù Oluwa. O wi pe, “Ọkunrin wo li o bè̩ru OLUWA? on ni yio kọ li ọna ti yio yàn” (Orin Dafidi 25:12); ati “Ore rẹ ti tobi to, ti iwọ fi ṣura dè awọn ti o bẹru rẹ: ore ti iwọ ti ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ enia!” (Orin Dafidi 31:19).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Sọlomọni i ṣe?
  2. Bawo ni o ti ṣe di ọlọgbọn to bẹẹ?
  3. Ki ni ṣe ti Sọlomọni fi kọ owe silẹ?
  4. Ki ni a n pe ni owe?
  5. Ki ni ipilẹṣẹ ọgbọn?
  6. Ki ni ṣe ti ọmọde fi ni lati gbọran si awọn obi rẹ lẹnu?
  7. Ọna wo ni awọn ẹlẹṣẹ n gba tàn eniyan?
  8. Ọna wo ni a le gbà lati fi wa ọgbọn Ọlọrun?
  9. Ki ni Ọlọrun maa n ṣe fun awọn ti wọn ba bẹru Rè̩?
  10. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ti kò bẹru Ọlọrun?