Johannu 19:31-42; Matteu 27:62-66; Johannu 20:1-31

Lesson 276 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ, bi o tilẹ kú, yio yè” (Johannu 11:25).
Notes

S̩iṣe Ifẹ Rè̩

Bi Jesu ti n kú lọ lori igi agbelebu O wi pe, “O pari.” Itumọ eyi ni pe Oun ti pari iṣẹ ti Ọlọrun fun Oun lati ṣe. Lati igba ti Jesu ti wà ni ọmọde ni o ti jẹ è̩dun ọkàn Rè̩ lati ṣe ifẹ Ọlọrun. Nigba ti Jesu jẹ ọmọ ọdun mejila O wi pe, “Ẹnyin kò mọ pe, emi kò le ṣàima wà nibi iṣẹ Baba mi?” (Luku 2:49). Lẹyin eleyi O tun wi pe: “Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rè̩”(Johannu 4:34). Nigba ti o ku diẹ ki a kàn Jesu mọ agbelebu O wi pe, “Baba, wakati na de: ... emi ti pari iṣẹ ti iwọ fifun mi lati ṣe” (Johannu 17:1, 4). Ninu eyi, Jesu fi apẹẹrẹ rere lelè̩. O jẹ idunnu Ọlọrun, o si jẹ ọranyan fun wa gẹgẹ bi ọmọ ẹyin Rè̩, lati ṣe ifẹ Rè̩. O sàn fun wa lati ṣe ifẹ Ọlọrun gan an ju pe ki a kàn ni ifẹ ati ṣe e lọkàn - ẹ jẹ ki a kuku ṣe ohun ti o yẹ lati ṣe.

Ikú Kristi kò fi opin si awọn ẹkọ Rè̩. Awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ n ba iṣẹ naa lọ nipa wiwaasu ati nipa titan Ihinrere kalẹ. Kò le ṣe alai kú ki awa ki o ba le ri idariji è̩ṣẹ wa gbà, nitori “laisi itajẹsilẹ kò si idariji” (Heberu 9:22). Jesu ni Ọdọ-agutan Ọlọrun ti a ta Ẹjẹ Rè̩ silẹ ki ẹnikẹni ti o ba gba A gbọ ki o le ri idariji è̩ṣẹ gbà (Johannu 3:16; Matteu 26:28).

Imuṣẹ Asọtẹlẹ

A kàn Jesu mọ agbelebu laarin ole meji gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti sọ tẹlẹ: “A si kà a mọ awọn alarekọja” (Isaiah 53:12; Marku 15:28). Nitori o jẹ ọjọ ipalẹmọ Ọsẹ, “ki okú wọn ma bà wa lori agbelebu.” Awọn ọmọ-ogun wá lati ṣẹ egungun itan awọn ti a ti kàn mọ’gi wọnyi ki wọn ba le tete kú, ṣugbọn a ri pe Jesu ti kú. Wọn kò ṣé̩ egungun itan Jesu bi wọn ti ṣe fun awọn iyoku. Sibẹsibẹ, ọkan ninu awọn ọmọ-ogun fi ọkọ gún ihà Jesu, “lojukanna è̩jẹ ati omi si tú jade.” Awọn woli ti sọtẹlẹ nipa nnkan wọnyi pẹlu. (Ka Sẹkariah 12:10; ati Orin Dafidi 34:20).

Isinku Rè̩

Ọjọ ti a sin Jesu jé̩ ọjọ ibanujẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Ọrọ ti Jesu sọ fun wọn nipa iku Rè̩ kò ye wọn ni kikún. Wọn ti nireti pe yoo gbe ijọba kan kalẹ láyé ni akoko naa, ṣugbọn nisisiyi O ti kú. Ẹrù ba awọn ọmọ-ẹyin, wọn rè̩wè̩si, wọn si kún fun ibanujẹ.

Awọn ọkunrin meji kan wà ninu igbimọ Sanhedrini, igbimọ awọn Ju, ti wọn gba ẹkọ Jesu gbọ. Ni akoko ti ibanujẹ da ori awọn ọmọ-ẹyin iyoku kodò awọn ọkunrin meji yii fi ifẹ ti wọn ni si Jesu hàn. Ọkan ninu wọn, Josẹfu ara Arimatea, tọ Pilatu lọ pẹlu igboya, o si gba aṣẹ lati ṣe itọju okú Jesu. Ẹni keji, Nikodemu, mú adapọ ojia ati aloe olowo iyebiye wá. A lo nnkan wọnyi lati fi ṣe itọju okú Jesu ki a to sin In, gẹgẹ bi àṣà awọn Ju.

Tẹlẹ ri awọn ọkunrin wọnyi n bẹru lati jẹwọ pe ọmọ-ẹyin Jesu ni wọn i ṣe. S̩ugbọn ni akoko yii iṣe wọn fi bi ifẹ wọn si Oluwa ti tobi to hàn. Akoko yii jẹ akoko ìyiiriwò, sibẹ awọn ọkunrin meji wọnyi kò lọra lati fi hàn pe ọmọ-ẹyin Rè̩ ni awọn i ṣe. Ọlọrun ha le gbẹkẹle wa lati mú iduro wa nipa ohun ti o tọ? O ha le gbẹkẹle wa lati jẹ oloootọ si I nigba ti a ba n dan wa wò? O ha le gbẹkẹle wa lati jade fun Un nigba ti iṣẹ ba delẹ lati ṣe?

Fun Oluwa

Isinku Jesu ṣẹlẹ gẹgẹ bi asọtẹlẹ ti a ti sọ ṣaaju (Isaiah 53:9). Josẹfu ara Arimatea jẹ ọlọrọ (Matteu 27:57). O ti pese ibojì titun kan ti a gbé̩ ninu apata silẹ fun ara rè̩ ninu ọgbà. Ifẹ ọkàn Josẹfu ni lati lo iboji yii fun Oluwa. Awa naa loni le ni awọn ohun kan ti a le pe ni ti wa, ti a si ti ṣeto lati lo fun ara wa. Wọn le jé̩ aye wa, akoko wa, talẹnti wa, ati ohun ini wa. A ha ṣetan lati lo wọn fun Oluwa ati fun iṣẹ-isin Rè̩? Josẹfu ara Arimatea fi ohun ti o ti pese silẹ fun ara rè̩ fun Jesu. A té̩ Jesu si ibi ti Josẹfu ti ṣeto silẹ fun ilo ara rè̩, a si yi okuta nla di ẹnu-ọna iboji naa.

A Yan Oluṣọ

Awọn olori alufaa ati awọn Farisi ranti ọrọ ti Jesu ti sọ bi o tilẹ ṣe pe awọn ọmọ-ẹyin fẹrẹ gbagbe. Wọn sọ fun Pilatu pe Jesu ti wi pe Oun yoo jinde ni ọjọ kẹta. Wọn sọ fun Pilatu pe ki o paṣẹ ki a kiyesi iboji naa daju ki òkú Jesu ba le wà nibè̩. Pilatu da wọn lohun pe, “Ẹnyin ní oluṣọ: ẹ mā lọ, ẹ ṣe e daju bi ẹ ti le ṣe e”, bi ẹni pe oun naa n ṣiyemeji lọkan rè̩ pe boya ni o le ṣe e ṣe fun wọn lati sé Oluwa mọ inu iboji naa. Gamaliẹli ọgá ninu awọn amofin, sọ iru ọrọ bẹẹ nigba ti o wi pe, “Bi ti Ọlọrun ba ni, ẹnyin kì yio le bì i ṣubu” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:39). Awọn olori alufaa ati awọn Farisi gbiyanju lati ṣe iboji naa daju, nipa fifi edidi di okuta naa, wọn si yàn iṣọ sibẹ.

Iboji Ofifo

Lẹyin Ajọ Irekọja, ni kutukutu owurọ, nigba ti òkùnkùn si ṣu, Maria Magdalene lọ si ibi iboji Jesu. Nigba ti o ri i pe a ti yi okuta kuro lẹnu iboji, ti iboji si ṣofo, kò ranti pe Jesu ti sọ fun wọn nipa ajinde Rè̩ (Matteu 16:21; 20:19; Johannu 2:19). Maria Magdalene sare tọ Peteru ati Johannu lọ. O wi pe, “Nwọn ti gbé Oluwa kuro ninu iboji, awa kò si mọ ibiti wọn gbé té̩ ẹ si.” Awọn ọkunrin mejeeji naa jumọ sáre lọ si ibi iboji naa. Johannu ni o kọ de ibẹ, boya nitori pe oun ni o kere ju, o si le sare jù.

Nigba ti Johannu de ibi ti a tẹ Jesu si, o duro lode o si wo inu rè̩. Nigba ti Peteru de o sare wọ inu iboji lọ, Johannu si tẹle e. Wọn ri aṣọ ọgbọ naa ni ẹgbẹ kan, ṣugbọn gèlè ti a ti fi we Jesu lori wà ni ọtọ gedegbe. Lai si aniani, Jesu ti sọ fun wọn nipa ajinde Rè̩. Wọn ti gbọ ṣugbọn kò yé wọn. Bi wọn ti duro sibẹ ti wọṅ si n wo iboji naa, igbagbọ bẹrẹ si i ṣiṣẹ lọkàn Johannu. “O si ri, o si gbagbọ.”

O Jinde

Ẹnikẹni kò gbe Jesu lọ. O ti jinde kuro ninu òku, aṣọ-isinku Rè̩ si wa nilẹ ninu iboji. Iṣẹ-iyanu nla yii ṣẹlẹ bi Jesu ti ṣeleri. Jesu ti ji awọn ẹlomiran dide kuro ninu oku - ọmọ opo Naini (Luku 7:15), ọmọbinrin Jairu (Matteu 9:18, 25), ati Lasaru paapaa, ẹni ti a ti sinku rè̩ niwọn ọjọ mẹrin sẹyin (Johannu 11:17, 44). S̩ugbọn Jesu jinde kuro nipo oku nipa agbara Ọlọrun. S̩iwaju eyii tabi lẹyin eyii a kò gbọ pe iru iṣẹ-iyanu bẹẹ ṣẹlẹ. Jesu ni agbara lori ikú, ati isa-oku (Romu 6:9). O jẹ aṣẹgun lori ikú, niwọn bi Oun si ti wà laaye, awa o wà laaye pẹlu (Johannu 14:19).

Eso Akọso

“Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn” (1Kọrinti 15:20). Nitori pe Kristi jinde, awa pẹlu yoo jinde (1Kọrinti 15:23). Nigba bibọ Jesu, ipe Ọlọrun yoo dun, “awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ jinde: Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lāye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bḝli awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa” (1Tẹssalonika 4:13-17). Jesu ni ẹni kin-in-ni ti O jinde kuro ninu okú ni ọna bẹẹ. O ṣe eyii fun wa. A fi “tọrẹ è̩ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa” (Romu 4:25).

Igbagbọ ninu Ajinde

O ṣe pataki fun awọn eniyan ni aye isisiyi lati ni igbagbọ ninu ajinde. Igbagbọ ninu ajinde ṣe pataki fun igbala eniyan. Bibeli wi pe: “Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là” (Romu 10:9).

Ajinde Kristi fi ireti kan sinu ọkàn olukuluku onigbagbọ (1Peteru 1:3). “Olukuluku ẹniti o bá si ni ireti yi ninu rè̩, a wè̩ ara rè̩ mọ, ani bi on ti mọ” (1Johannu 3:3). Eyii ni pe eniyan ni lati pese ọkàn rè̩ ati aye rè̩ silẹ fun bibọ Jesu. A ni lati sọ ọ di mimọ nipa Ẹjẹ Jesu, ki a si fọ ọkàn rè̩ mọ kuro ninu è̩ṣẹ. A ni lati ni agbara Ọlọrun ninu aye wa ki a ba le jẹ ohun ipe nì ni igba bibọ Jesu. Yoo ti jẹ akoko iyanu tó fun awọn ti o ba gbọran si Ọrọ Oluwa! Iwọ ha ti mura silẹ fun akoko naa ti Jesu yoo wa mú awọn eniyan Rè̩ lọ?

Kristi ti O wà Laaye

Olugbala ti o wà laaye ni awa n sìn, ki i ṣe eyii ti o wà ni isa-oku sibè̩. Kristi wa lagbara lati ṣe ohun gbogbo, O si fun wa ni ireti nla. A mọ pe Kristi wà laaye, nitori pe O wà laaye ninu ọkàn awọn eniyan Rè̩. Yoo fi ara Rè̩ hàn fun gbogbo awọn ti n ṣe afẹri Rè̩, gẹgẹ bi O ti ṣe fun Maria Magdalene ninu ọgba. Kò mọ pe Oluwa ni titi O fi pe e ni orukọ rè̩. Lẹyin eyii, O fara hàn fun awọn ọmọ-ẹyin miiran. Awọn miiran ninu wọn kò mọ Jesu titi O fi là wọn ni oju. Awọn miiran è̩wè̩ kò si gbagbọ titi wọn fi ri Oluwa wọn ni ojukoju. Jesu wi pe, “Alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a fi n ṣe iranti ọjọ Ajinde?
  2. Ireti wo ni o fi fun Onigbagbọ?
  3. Ninu iboji ta ni a sin Jesu si?
  4. Ta ni sin Jesu?
  5. Ki ni ṣe ti inu awọn ọmọ-ẹyin fi bajẹ?
  6. Ki ni ṣe ti awọn olori alufaa ati awọn Farisi kò le ṣe iboji nì daju?
  7. O ti pẹ to lẹyin isinku Jesu ki O to jinde?
  8. Sọ diẹ ninu awọn asọtẹlẹ ti a muṣe ni igba iku, isinku ati ajinde Jesu.
  9. Bawo ni awọn ọmọ-ẹyin ṣe mọ pe Jesu ti jinde ati pe O wà laaye?
  10. Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu wà laaye loni?