Owe 3:1-35

Lesson 277 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọmọ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ” (Owe 3:1).
Notes

Kò si Ayọ ninu Ọrọ

Nipasẹ iriri, Sọlomọni Ọba ti ri idi ohun ti o n mu ki inu awọn eniyan dun – ki i si i ṣe ohun ti aye yii le fi fun ni. Sọlomọni n gbe ibi ti o lẹwa lọpọlọpọ, laaarin awọn iṣura aye, ti o dara ju lọ. Awọn ọkọ oju omi ti o ni kò dẹkun a ti maa lọ si ilẹ ajeji lati mu ohun titun ti o si niyelori wá fun un. Awọn iranṣẹ rè̩ a maa sare sihin ati sọhun lati mu aṣẹ rè̩ ṣẹ; bẹẹ ni awọn ọmọ-ogun rè̩ ṣetan lati fi agbara ogun jija gba odindi ilu bi o ba fẹ bẹẹ.

Sọlomọni Ọba fẹ ọmọbinrin ọba kan lati ilẹ Egipti, eyii si mu ki o ri ojurere ọba Egipti. O ni ọpọlọpọ ohun ti awọn ẹlomiiran maa n ṣe laalaa pupọ lati ni, ohun ti ọkàn wọn maa n ṣafẹri, ti wọn si n jijakadi pupọ lati ni; sibẹsibẹ pẹlu gbogbo nnkan wọnyii, o wi pe: “Gbogbo rè̩ asan ni.” Kò ri inudidun ninu gbogbo ohun ini aye yii.

Alaafia ti o wà ninu Ọgbọn

Bi kikó ọrọ jọ, ọlá, ati okiki kò ba mu ayọ wa, ki ni ohun naa ti o le mu un wá? Ọgbọn Ọlọrun ni. Iwọ ha mọ bi a ti ṣe le ri i gba? A ki i kọ ọ ninu iwe ni ile-è̩kọ. Sọlomọni kọ otitọ naa o si wi pe: “Ibè̩ru OLUWA ni ipilẹṣẹ ọgbọn.” Nitori naa a ri i wi pe ohun ti n pilè̩ ayọ ninu ọkàn wa ni pe ki a fẹran Jesu to bẹẹ gẹẹ ti a o fi maa ṣe ifẹ Rè̩, ki a si maa fi ibẹru ṣọra ki a má ba mu Un binu.

Sọlomọni wi pe: “Ọmọ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ.” Ohun kan naa ti Ọlọrun ti palaṣẹ fun Mose ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin nipa Ofin ni Sọlomọni n tun sọ nihin yii: “ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọrọ isọ nigba ti iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọna, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide” (Deuteronomi 6:7). Bi a ba fi ẹmi adura gbin Ọrọ Ọlọrun si ọkàn awọn ọmọde, wọn ki yoo le gbagbe. Kò si bi aayan è̩kọ Bibeli ti le pọ to ni ọjọ iwaju ti o le ṣe atunṣe aibikita lati kọ awọn ọmọde nigba ti wọn wa ni kekere.

Ọrọ Naa ninu Ọkàn

Awọn ẹlomiran a maa sa gbogbo agbara wọn lati kọ awọn ofin Ọlọrun. Wọn a kọ ọpọlọpọ ẹsẹ sori ninu Ọrọ Ọlọrun, wọn a si maa gbiyanju lati maa pa ofin Ọlọrun mọ. S̩ugbọn Sọlomọni mọ wi pe yoo gba eniyan ni ohun ti o ju eyi yii lọ ki o to le ni ayọ. O wi pe “Jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ.” Nigba ti a ba di atunbi ni tootọ, ofin Ọlọrun yoo maa gbe inu ọkàn wa. Ẹda wa yoo pada di ọtun, a o si maa ṣe ifẹ Ọlọrun nitori pe a fẹ Ẹ. Nigba naa ni ayọ wa bè̩rè̩.

Ririn ni Ailewu

Nigba ti a ba gba ọkàn wa là, igbesi-aye titun bẹrẹ ninu wa. A o mọ alaafia Ọlọrun lara, ifẹ Rè̩ a si kún inu aye wa. Ayọ Ọlọrun a maa fun wa ni okun, a si tun fun wa ni ilera. S̩ugbọn a ni lati maa gbe ninu aye sibẹ, idanwo a si maa yi lu wa. Ọna wa ki i fi igba gbogbo rọrun. Nigba naa ni a o wa mọ ju bi a ti mọ tẹlẹ ri ohun ti ifẹ Ọlọrun jasi fun wa. “Nigbana ni iwọ o ma rìn ọna rẹ lailewu, ẹsẹ rẹ kì yio si kọ. Nigbati iwọ dubulẹ, iwọ kì yio bè̩ru: nitõtọ, iwọ o dubulẹ, orun rẹ yio si dùn.”

Igba pupọ ni a maa n gbọ ti awọn eniyan maa n jẹwọ pe awọn ki i le sun loru nigba ti wọn jẹ ẹlé̩ṣè̩. Iwà buburu wọn ni o kó idaamu bá wọn, wọn a si maa ro pe gbogbo aye ni o korira wọn, ati pe ẹnikẹni kò tilẹ bikita nipa wọn. S̩ugbọn nigba ti Jesu de inu ọkàn wọn, a gbe ẹru wuwo naa kuro. Wọn ni anfaani lati sùn ni alaafia ki wọn si gbadun oorun wọn. Ọlọrun ti kọ wọn pe Oun n ṣe itọju wọn, ati pe Oun ni O n fun wọn ni oorun alaafia.

Ọpọlọpọ awọn Onigbagbọ ti wọn lọ si oju ogun ni igba ogun ni o jẹri si otitọ yii pe Oluwa a maa fun awọn ọmọ Rè̩ ni isinmi ni igba yii pẹlu. Ninu gbogbo idaamu bi wọn ti n ṣọna pe boya ọta n bọ, ati bi ikú ti sun mọ wọn to, wọn si le turaká ki wọn si sinmi ninu idaniloju pe angẹli Oluwa wà ni tosi lati pa wọn mọ.

Bi è̩rù ba n ba ọ, sọ fun Jesu. Sọ fun Un pe ki O mu è̩rù rẹ kuro. Bi iwọ ba jẹ Onigbagbọ, awọn angẹli Rè̩ yoo maa ṣọ ọ, wọn yoo si maa pa ọ mọ ni ailewu.

Òye Wa

Imọran miiran ti o dara ti Sọlomọni tun fun wa ni wi pe, “Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle OLUWA, ma si ṣe tè̩ si ìmọ ara rẹ.” Igba pupọ ni a maa n fẹ ki ohun gbogbo yọri si bi a ba ti ṣeto rè̩, a si maa n rè̩wè̩si bi kò ba ri bẹẹ. Ọlọrun mọ ohun ti o dara fun wa ju bi awa ti mọ lọ, O si n fẹ ki a gbẹkẹle ọgbọn Oun. O mọ ibanujẹ ti o le de ba wa, “bi baba ti iṣe iyọnu si awọn ọmọ, bḝli OLUWA nṣe iyọnu si awọn ti o bè̩ru rè̩” (Orin Dafidi 103:13). Ẹni ti o ni inu didun ni ẹni ti o mọ pe Ọlọrun fé̩ mọ ohun gbogbo ti oun n ṣe, o si ni itẹlọrun pe ki Oluwa maa tọ iṣisẹ oun.

A ṣe ileri ara lile fun wa bi a ba pa ifẹ Ọlọrun mọ, bi a kò ba si taku lati rin ninu ifẹ ọkàn wa. Ẹmi gigun ati igbesi-aye alaafia ni ogún ọkunrin naa ati obinrin naa ti o fi ara rè̩ rubọ fun Ọlọrun. Ọlọrun paṣẹ pe ki awọn ọmọde gbọran si awọn obi wọn lẹnu, ati pẹlu eyii ni a wi pe: “Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye” (Efesu 6:3).

“Mọ ọ ni gbogbo ọna rẹ.” Ninu ohun gbogbo a ni lati ronu ifẹ Ọlọrun. Awọn ẹlomiran le ro pe awọn ki yoo fi ọran kekere yọ Ọlọrun lẹnu – pe wọn ti kere ju ohun ti Ọlọrun le fi iye si lọ. S̩ugbọn Ọlọrun wi pe ninu gbogbo ọna wa a ni lati kiyesi ifẹ Rè̩, Oun yoo si bukun fun wa.

Ibawi

Ki a ba le kọ wa lọgbọn, a ni lati tọ wa sọna tabi ki a ba wa wi nigba miiran. Boya a ti ṣe aṣiṣe nipa aimọkan tabi nipa aibikita, Oluwa yoo jẹ ki a mọ; bi o ba si tọ bẹẹ ni oju Rè̩, yoo jẹ wá niya. Itọni yii yoo mu ki a jẹ ọlọgbọn si i bi a ba gba a. Nitori pe “ẹniti OLUWA fẹ on ni itọ, gẹgẹ bi baba ti itọ ọmọ ti inu rè̩ dun si.”

Nigba ti Paulu Apọsteli n kọwe si Ijọ titun, si awọn Heberu Onigbagbọ, o mẹnu ba ẹsẹ ọrọ yii. Ọpọlọpọ nnkan ni wọn si ni lati kọ ṣugbọn wọn binu nigba ti Paulu bá wọn wi. O si n gbiyanju lati fi ye wọn pe a n bá wọn wi nitori pe Ọlọrun fẹran wọn ni.

Nigba ti awọn obi ba n ba awọn ọmọ wọn wi, o ṣoro fun awọn ọmọ lati gbà pe awọn obi wọn fẹran wọn ni; ṣugbọn titọni sọna nipa ibawi ni yoo mu ki wọn jẹ ọmọ rere, iru eyi ti ki yoo mu itiju ba awọn obi.

Aanu

A maa n gbadun aanu ati ifẹ Ọlọrun. O n fẹ ki awa naa fi ifẹ ati aanu hàn fun awọn ẹlomiran pẹlu. Ọna kan ti a le gbà ṣe eyi ni pe ki a lọ bẹ awọn alaisan wò ki a si mu òdòdó lọ fun wọn, tabi ki a ba wọn tẹ ibusun wọn tabi ki a fun wọn ni ounjẹ.

Nigba kan Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe nigba ti awọn olododo ba de iwaju Oun nigba idajọ, Oun yoo wi fun wọn pe “Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa: nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile: mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ mi wa” (Matteu 25:34-36).

Ọpọlọpọ ninu awọn olododo ti yoo duro niwaju Jesu ni wọn ko i ti ri Jesu ri. Yoo si jẹ iyanu fun wọn bi wọn ti ṣe le ri anfaani lati fun Un ni ohun mimu ati ohun jijẹ. Nigba naa ni yoo wi fun wọn pe: “Niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakọnrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi” (Matteu 25:40). Wọn ti fi aanu hàn fun awọn ti o wà ninu wahala. Nitori eyi ẹ jẹ ki a maa ran awọn ẹlomiran lọwọ ni orukọ Jesu, ki a maa ṣe e fun wọn bi ẹni pe a n ṣe e fun Jesu.

Iranlọwọ ti a n ṣe fun awọn ẹlomiran a maa mú inu wa dùn. Jesu wi pe, “Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 20:35). O wi pẹlu pe, “Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amìpọ, akún-wọsilẹ, li a o wọn si àiya nyin” (Luku 6:38). Awọn ẹlomiiran ti dan an wo wọn si ti ri pe bi awọn ti n fi fun ẹlomiran, bẹẹ ni wọn n ni si i fun ara wọn.

Akọso

A sọ fun wa wi pe ki a fi aanu hàn si awọn ẹlomiran, ṣugbọn a paṣẹ fun wa pẹlu lati fi “akọso” ninu ohun-ini wa bu ọlá fun Oluwa. Eyi ni wi pe a ni lati san idamẹwaa wa. Idamẹwaa ohun gbogbo ti a n gbà jẹ ti Ọlọrun, a kò si gbọdọ lo o fun ara wa. “Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, li OLUWA awọn ọmọ-ogun wi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobḝ ti ki yio si aye to lati gbà a” (Malaki 3:10). A o gba ibukun nipa ti ẹmi ati nipa ti ara pẹlu. “Bḝni aká rẹ yio kún fun ọpọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun.”

Ọlọrun ṣeleri fun awọn Ọmọ Israẹli nigba ti wọn wọ inu ilẹ Kenaani, pe ojo yoo wà nigba ti wọn ba gbin eso wọn, ati nigba ti o ba to akoko fun eso lati gbó. S̩ugbọn O wi pe ojo ki yoo rọ nigba ikore, ki o má ba ba ohunkohun jé̩ - bi wọn ba gbọran si aṣẹ Rè̩. Ohun gbogbo yoo maa ṣe deedee bi awọn Ọmọ Israẹli ba gbọran; ṣugbọn wọn kò pa aṣẹ Ọlọrun mọ, nitori naa wọn kò le gbadun gbogbo anfaani nlá nlà wọnyi.

A Ké Awọn Oluṣe Buburu Kuro

“Máṣe ilara aninilara, má si ṣe yàn ọkan ninu gbogbo ọna rè̩.” O le dabi ẹni pe eniyan buburu n ri rere ninu aye ju Onigbagbọ lọ, ṣugbọn Dafidi wi pe: “A o ke awọn oluṣe buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de OLUWA ni yio jogun aiye” (Orin Dafidi 37:9). Awọn Onigbagbọ tootọ yoo ṣe akoso lori aye yii pẹlu Jesu fun ẹgbẹrun ọdun, nigba ti O ba tun pada wa.

Nini Idapọ pẹlu Oluwa

Aṣiiri Oluwa wà pẹlu awọn olododo. Wọn a maa gbadun idapọ timọtimọ pẹlu Rè̩, ṣugbọn iru idapọ yii ni awọn eniyan aye kò mọ. Oluwa a maa sọ nipa ifẹ Rè̩ fun wọn, ati pe Oun n fẹ ki wọn ba Oun gbe ninu Ogo Oun. Nipasẹ Bibeli a ni anfaani lati mọ ileri Rè̩ iyebiye; bi a ba si pa ofin Rè̩ mọ, gbogbo ileri wọnni yoo jẹ ti wa. “Aṣiri OLUWA wà pẹlu awọn ti o bè̩ru rè̩; yio si fi wọn mọ majẹmu rè̩” (Orin Dafidi 25:14).

“Ibukun ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọn ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ninu ki ni Sọlomọni n wá inu didun?
  2. Ki ni Sọlomọni sọ nipa awọn nnkan aye yii?
  3. Ki ni ipilẹṣẹ ọgbọn?
  4. Nibo ni a ti le ri ofin Ọlọrun?
  5. Ninu ọna mélòó ni a ni lati mọ Ọlọrun?
  6. Ki ni Ọlọrun maa n ṣe fun awọn ọmọ Rè̩ ti o ba ṣe aṣiṣe? Ki ni ṣe ti O n ṣe bẹẹ?
  7. Ki ni ṣe ti awọn obi maa n ba awọn ọmọ wọn wi?
  8. Sọ apẹẹrẹ ṣiṣe aanu.
  9. Ki ni akọso?
  10. Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn oluṣe buburu?