Lesson 278 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Jù gbogbo ohun ipamọ, pa aiya rẹ mọ; nitoripe lati inu rè̩ wá ni orisun ìye” (Owe 4:23).Notes
Baba Sọlomọni
A ti kọ ọpọlọpọ è̩kọ nipa Dafidi -- ọmọdekunrin darandaran nì, ẹni ti o n fi harpu kọrin, ti o kọ ọpọlọpọ orin silẹ, ẹni ti i ṣe ọba pẹlu. Pẹlupẹlu o jẹ olukọni nla, lai si aniani, o daju pe Dafidi lo ọpọlọpọ akoko lati fi maa kọ awọn ọmọ rè̩. Bi o tilẹ jẹ pe Sọlomọni nikan kọ ni baba rè̩ bi, sibẹ baba rè̩ oninu rere kọ ọ ni ẹkọ o si tọ ọ si ọnà daradara bi ẹni pe oun nikan ṣoṣo ni ọmọ ti o bi. Ọlọrun fun Sọlomọni ni agbara lati kọ akọsilẹ awọn ọrọ rere ti o gbọ lẹnu Dafidi fun anfaani awọn ọmọde ati awọn ọdọ, a si kọ wọn silẹ ninu Bibeli.
Nigba miiran awọn ọmọde ki i fẹ lati maa gbọ bi awọn obi wọn ti n sọ ọ ni asọtunsọ pe “Iwọ kò gbọdọ ṣe bẹẹ;” “O kò gbọdọ lọ si ọhun nì;” “O nilati ṣe gẹgẹ bi mo ti wi fun ọ.” S̩ugbọn iwọ tẹti silẹ gbọ bi Dafidi ọba, ọkan ninu awọn eniyan ti o tobi ju lọ ni aye yii ti wi. O dabi ẹni pe a fẹrẹ le maa gbọ bi o ti n wi pe, “Sọlomọni, ọmọ mi, ni ọgbọn, ni oye: máṣe gbagbe; ... Máṣe kọ ọ silẹ ... Ipilẹṣẹ ọgbọn ni lati ni ọgbọn; ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye” (Owe 4:5-7). Ni oru ọjọ kan a dan Sọlomọni wò: Njẹ Sọlomọni ha ti n tẹti silẹ gbọ ọrọ baba rè̩? O ha fi gbogbo ọkàn rè̩ si i bi baba rè̩ ti n tọ ọ si ọna? A ranti itan oru ọjọ kan ti Ọlọrun fi ara han Sọlomọni ni oju àla ti O si wi pe, “Bère ohun ti emi o fi fun ọ.” Ohun ti Sọlomọni beere si “dara loju Oluwa” (1Awọn Ọba 3:10). “Fi ọkàn ìmoye fun iranṣẹ rẹ lati ṣe idajọ awọn enia rẹ, lati mọ iyatọ rere ati buburu.” Otitọ ni pe lati ọdọ Ọlọrun ni ọgbọn ti Sọlomọni ni ti wá, ṣugbọn lai ṣe aniani, iru ẹkọ ti o kọ lọdọ baba rè̩ ni o fun un ni iranwọ lati beere ọgbọn.
Yiyẹra fun Idanwo
Ẹ jẹ ki a ka a siwaju si i ninu ẹsẹ ọrọ wa nipa awọn nnkan miiran ti Sọlomọni kọ lọdọ baba rè̩ ti o si n fi lelẹ fun wa pẹlu. Ẹsẹ ikẹrinla ati ikẹẹdogun n sọ fun wa pe: “Máṣe bọ si ipa-ọna enia buburu, má si ṣe rìn li ọna awọn enia ibi. Yè̩ ẹ silẹ, máṣe kọja ninu rè̩, yè̩ kuro nibẹ, si ma ba tirẹ lọ.” Bi a ba mọ ibi ti è̩ṣẹ gbe wa, bi a bá si yẹra kuro nibẹ, a o bọ lọwọ fifi ara wa fun idanwo. Kò yẹ fun wa lati bọ sinu idẹkun ti Satani dẹ silẹ fun ẹsẹ wa. Kò tọ si wa lati maa ka awọn aworan ti a n lẹ mọ ara patako tabi ara ogiri kaakiri igboro ilu lati polowo aworan sinima ti o ṣẹṣẹ de ti wọn fẹ ki awọn eniyan wa wo. Kò tọ fun wa lati maa ka awọn iwe alaworan ti n fi oriṣiriṣi iwa ọdaran hàn tabi ki a maa tẹti silẹ gbọ awọn ọrọ ibajẹ ati itiju ti n jade lati ori ẹrọ redio lati mọ iru imisi buburu ti wọn jẹ fun awọn ọdọ. Kò yẹ fun wa lati maa wọṣọ ki a maa huwa bi awọn eniyan aye.
Eṣu a maa dan eniyan wò nipa ero ọkàn ati awọn ohun ti a n fi oju ri. Nigba ti idanwo ba ṣubu lu eniyan ti ẹni naa si jọwọ ara rè̩ fun un, ti o si ṣe ohun ti o mọ pe è̩ṣẹ ni, ọkàn rè̩ kò si labẹ Ẹjẹ Jesu mọ. Sọlomọni kọwe pe, “Jù gbogbo ohun ipamọ, pa aiya rẹ mọ; nitoripe lati inu rè̩ wá ni orisun ìye.” A ka ninu Marku 7:21, 22, wi pe lati inu ọkàn ni ọpọlọpọ ohun buburu ti i jade wá: “iro buburu, panṣaga, àgbere, ipania, olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọbia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, ati iwère.”
Apẹẹrẹ -- Buburu ati Rere
Eṣu mọ bi à ti i tan ni jẹ. Ninu Ọgba Edẹni, eso ti Ọlọrun ni wọn kò gbọdọ jẹ ni o fi tàn wọn; ni ilẹ oko tútu yọyọ ti pẹtẹlẹ Jọrdani, ilẹ ọlọra ni o fi tàn wọn jẹ; ni ilu Jẹriko, nigba ti awọn Ọmọ Israẹli lọ lati gba ilú naa, dindi wura kan ati ẹwu Babeli ni o fi tan ẹni kan. Bi o ṣe ti Esau ni, ounjẹ ni o fi tan an – kiakia ni o ta ogun-ibi rẹ fun ipè̩tẹ.
A ranti itan Balaamu, ati itàn Gehasi, ọmọ-ọdọ Eliṣa. Awọn mejeeji lepa ere ini aye yii. Anania ati Safira fẹ lati gba ere nipa ṣiṣe èrú, ṣugbọn eyi ni o ṣe ikú pa wọn. S̩ugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun Jesu, Ẹni ti o bori idanwo! O lagbara lati gbà wa lọwọ iṣubu bi a ba tẹju wa mọ Ọn.
Onigbagbọ tootọ a maa ni àmì ọmọ Ọlọrun, bẹẹ ni a si le fi àmì yii mọ ọn bẹẹ gẹgẹ. Awọn eniyan le rò pe o yatọ tabi pe ìwà rè̩ ko ba ti aye iwoyi mu, ṣugbọn eyi san ju pe ki a jẹ gbajumọ ni aye ki a má si ni ojurere lọdọ Ọlọrun. A sọ bayii pe “iwa ni ohun ti eniyan jẹ gan an; okiki ni ohun ti a ro pe eniyan jé̩.”
Yiyẹra fun Irora Aya
Awọn ọdọ miiran rò wi pe wọn ni lati kọ lọ lo igba diẹ ninu è̩ṣẹ ki wọn ba le jẹri fun Jesu lẹyin ti a ba gba ọkàn wọn la. Èrò iṣina ni eyi. Ọmọdebinrin kan wi nigba kan bayii pe, “Inu mi dun pe mo jade lọ sinu aye mo si ti tọ iwa è̩ṣẹ aye wo, nitori pe bi n kò ba tọ wọn wo bẹẹ, i ba ṣoro fun mi lati ni itẹlọrun.” Irọ bayii jẹ ti eṣu, o si ti n pa iru irọ bẹẹ lati igba iṣẹdalẹ aye, nitori pe Satani ba Efa dá iru amọran bẹẹ ni atetekọṣe, nigba ti o sọ fun Efa pe yoo di ọlọgbọn bi o ba jẹ ninu eso ti a ni ki o má ṣe jẹ. S̩ugbọn eniyan kò ni lati lọ sinu è̩ṣẹ ki o to le jẹ ọlọgbọn, “Ọgbọn aiye yi wèrè ni lọdọ Ọlọrun” (1Kọrinti 3:19). Eniyan kò ni lati kọkọ lọ ṣe alabapin ninu ibi inu aye yii ki o to le mọ pe irora àyà, ibanujẹ, abamọ ni wọn n kó ba ẹnikẹni. Kò tọ ki eniyan lọ tọ gè̩dè̩gé̩dè̩ ikoro è̩ṣẹ wo ki o to mọ pe wọn a maa bu ni ṣan bi ejo. Boya a le ri igbadun aye fun igba diẹ ninu afé̩ è̩ṣẹ, ṣugbọn ayọ ati alaafia ti o daju a maa jade wa nipa kikọ gbogbo è̩ṣẹ silẹ ati nipa wiwá ati riri Olufunni ni ẹbun rere ati ẹbun pipé gbogbo. Ọdọmọbinrin kan ti o ri igbala lai pẹ yii wi pe ohun kan ṣoṣo ti o n mu ibanujẹ ba oun ni ero awọn ọdun wọnni ti oun ti fi ṣofo ninu è̩ṣẹ.
Alufaa (Oluṣọ-agutan) kan wi bayii pe, “Nigba ti mo wà ni ọmọde ti mo n gbọ ti awọn Onigbagbọ n jẹri nipa iru è̩ṣẹ buburu ti o tobi ninu eyi ti a ti gbà wọn, mo ro pe irẹjẹ ni fun mi nitori pe n kò ni anfaani lati lọ da iru è̩ṣẹ bawọnnì. Lẹyin ọdun diẹ ni o ṣẹṣẹ wa n ye mi bi Ọlọrun ti bukun fun mi lọna iyanu to. Ki i ṣe lati inu ẹrè̩ è̩ṣẹ ni O ti gba mi là, ṣugbọn nipasẹ anfaani awọn obi Onigbagbọ ati ẹgbẹ rere, ni Oluwa gbà mi lọwọ lilọ sinu ẹrè̩ è̩ṣẹ.” Nigba ti ẹnikan ti o ti lo ọpọlọpọ ọdun nídii iṣẹ yiyọ awọn eniyan ninu ibi ti è̩ṣẹ kó ba wọn n ba awọn oṣiṣẹ ati awọn olukọni Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi, ati awọn obi sọrọ, o wi pe, “Iṣẹ yin ṣe pataki ju iṣẹ awọn Ajihinrere lọ. Ẹyin n daabo bo gbogbo igbesi-aye eniyan ki o má ba fọ; awa n so o pọ lẹyin ti o ti fọ tán. Ẹyin a ma gba ni silẹ lọwọ irora aya ati abamọ; awa a ma gbiyanju lati mu irora aya kuro ninu ọkàn ti ibanujẹ bá ... Ọpọ aimoye ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ni o n yọ lọ kuro lọwọ yin, ẹyin obi, ... olukọni, ati ẹyin oniwaasu; aikiyesara yin ni o mu ki a ni lati maa ṣe iṣẹ yíyọ awọn eniyan kuro ninu ohun buburu ti è̩ṣẹ ko ba wọn ... O ṣe anfaani pupọ-pupọ ju lọ lati ṣe iranwọ fun eniyan ki o má ṣe lọ sinu kòtò ẹgbin è̩ṣẹ, ju pe ki o ti bọ sinu rè̩ tan, ki a si maa gbiyanju lati yọ ọ jade lẹyin ti o ti fi ara kó ibajẹ, ti o si ti fọ wé̩wé̩.”
Niniyelori Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi
Ki i ṣe gbogbo awọn ọmọde ni o ni anfaani obi ti o bẹru Ọlọrun gẹgẹ bi Sọlomọni ti ni. Ọpọlọpọ obi ni wọn ṣe alaibikita ninu iṣẹ wọn, nitori pe wọn ki i rán awọn ọmọ wọn lọ si Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi deedee, bẹẹ ni wọn ki i si ka Ọrọ Ọlọrun si wọn leti; nipa eléyìí wọn kùnà lati gbin irugbìn ododo sinu ọkàn awọn ọmọ keekeekee wọnyi. Awọn ọmọde ti wọn n wa si Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi deedee ni anfaani daradara lati mọ rere yatọ si buburu, ati lati gba ìhámọra ti wọn yoo fi doju kọ idanwo ninu aye, ju awọn ti wọn ki i wá si Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi lọ. Olukọ Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi kan sọ fun awọn ọmọ ile-ẹkọ rè̩ nigba kan pe, “Ẹnikẹni ninu ẹyin ọdọmọkunrin wọnyi ni o le di alufaa Ọlọrun.” Ọkan ninu awọn ọmọdekunrin wọnyi wi ni ọkàn rè̩ lẹsẹkẹsẹ pe, “Emi ni yoo jẹ ọmọ naa.” Bi o tilẹ jẹ pe kò jù ọmọ ọdun mẹtàlá tabi mẹrinla lọ nigba naa, lati ọjọ naa titi di ọjọ ti o kọ waasu, kò ni ohun miiran lọkàn ju lati jẹ alufaa Ọlọrun lọ. Nigba ti o di ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni o ri igbala, lẹyin eyi o si di alufaa Ọlọrun. Onidajọ kan, niwaju ẹni ti awọn ọdọmọkunrin ni ẹgbẹẹgbè̩rún ti fara han ri, sọ nigba kan bayii pe “Awọn ọmọdekunrin ti wọn n lọ si Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi ki i wa siwaju mi.”
Ọlọrun sọ nipa Abrahamu ati ẹbi rè̩ pe, “Nitoriti mo mọ ọ pe, on o fi aṣẹ fun awọn ọmọ rè̩ ati fun awọn ara ile rè̩ lẹhin rè̩, ki nwọn ki o ma pa ọna OLUWA mọ lati ṣe ododo ati idajọ” (Gẹnẹsisi 18:19). Iwọ ha ti ṣeto aye rẹ niwaju Ọlọrun ni ọna ti O le fi wi bayii nipa ti rẹ pe, “Mo mọ ọmọde yii, mo si mọ baba rè̩ ati iya rè̩, mo si mọ bi wọn ti ṣe n lo igbesi-aye wọn; wọn kì yoo yà si apa ọtún tabi apa osi, ṣugbọn wọn o duro ninu ọna tooro nì ti o n tọka si Ọrun.”
Igbesi - aye ti a ṣe Ilana Rè̩
“Ronu ipa ọna rẹ.” Bi o ba ni ireti pe iwọ yoo jẹ olukọni tabi ẹni ti n tun mọto ṣe, o ni lati kọ iṣẹ yii ki o si mọ ọn. Igbesi-aye ti o dara a maa ti ipasẹ pe ki a ronu jinlẹ daradara wá, ati pe ki a fi ọgbọn ṣe eto rè̩ silẹ daradara. Bakan naa ni igbesi-aye Onigbagbọ ri. Onigbagbọ ti yipada kuro lẹyin Satani o si ti kuro ninu ọna ti o lọ si iparun, o si n lepa lati ṣe ifẹ Ọlọrun ati lati wọ Ọrun. Ilana Ihinrere ni o n fi ṣe akoso eto aye rè̩ gbogbo. Gbogbo ilepa ati aniyan ọkàn rè̩ ni lati sa gbogbo ipa rè̩ tán fun Ọlọrun ati lati jèrè ọpọlọpọ ọkàn laaarin igba kukuru ti o ni i lo ni aye. Bi o ba n fẹ lati pẹlu awọn ti n lo ohun-elo orin ninu ile-Ọlọrun, o ni lati gba è̩kọ, ki o si fara balẹ kọ è̩kọ orin daradara. Bi anfaani kan ba ṣi silẹ fun un nipa ohun ti aye yii, ero kin-in-ni ti yoo wá sinu ọkàn rè̩ ni pe: “Yoo ha di iṣẹ mi fun Ọlọrun lọwọ bi? Mo ha le maa ṣe iṣẹ yii ki n si le maa wa si gbogbo ipade ijọsin nile Ọlọrun deedee? Bi yoo ba mu ki n fi ọkan ninu iṣẹ mi fun Oluwa silẹ, emi ki yoo ṣe e.” Iwọ o wà lai lewu bi o ba kọ gbogbo ọna ti o le mu ki itara rẹ fun Ọlọrun dinku, tabi eyi ti o le mu ki agbara ti o fi di Ọlọrun mu dinku. Nigba ti a ba fi àyè ẹni silẹ fun iṣẹ Ọlọrun a o tubọ maa jẹ alabukunfun nipa ti è̩mí bi a ba le maa ṣe akiyesi gidigidi lati ṣọ ètè wa, ati oju wa, ati ọkàn wa pẹlu: “Mu arekereke kuro lọdọ rẹ, ati ète è̩tan jina rére kuro lọdọ rẹ. Jẹ ki oju rẹ ma wó ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ.”
Ki olukuluku ọdọ fi eti si ọrọ ọkunrin ti o jẹ ọlọgbọn ju lọ yii daradara: “Ọmọ mi, fetisi ọrọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọrọ mi, . . . pa wọn mọ li ārin aiya rẹ.” Eyi yii jẹ ofin pẹlu ileri: “Nitori iye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn” (Owe 4:20-22).
Questions
AWỌN IBEERE- Lati ọdọ ta ni Sọlomọni ti gba ọgbọn rè̩?
- Sọ diẹ ninu awọn nnkan ti a ṣeleri fun awọn ti o wá ọgbọn ni awari.
- Ọna wo ni a le gba yẹra fun idanwo?
- Iyatọ wo ni o wà laaarin ọna olododo ati ọna eniyan buburu?
- Ki ni ṣe ti o fi ṣe pataki lati “pa ọkàn wa mọ”?
- Ki ni a n pe ni “arekereke” ati “ète è̩tàn”?
- Awọn ofin ti o ni ileri mélòó ni a le ri ninu ori iwe yii?
- Ninu Bibeli lati ibẹrẹ de opin ta ni a ṣeleri ẹmi gigun fun?