Owe 6:1-19

Lesson 279 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu” (Owe 16:18).
Notes

Igbesi-aye Eniyan Lojoojumọ

Nipasẹ imisi Ẹmi Mimọ, Sọlomọni ni oye pupọ nipa awọn eniyan. O mọ iru iṣoro ti a maa n ba pade lojoojumọ. O mọ pe awọn ẹlomiran yoo jẹ ọlẹ, bẹẹ ni awọn ẹlomiran yoo jẹ alaapọn, awọn ẹlomiran yoo fi owo wọn pamọ, bẹẹ ni awọn ẹlomiran yoo ná ti wọn ni ìnakuna. Sọlomọni kọ ọpọlọpọ owe rè̩ silẹ lati sọ fun awọn eniyan ohun ti o dara lati ṣe.

Iwa awọn eniyan lode oni kò yatọ si iwa awọn eniyan niwọn ẹgbẹẹdogun ọdun sẹyin nigba ti Sọlomọni n jọba. A o ri idahun ninu akọsilẹ rè̩ fun gbogbo idaamu ti a le ba pade lojoojumọ.

Ẹri ti Onigbagbọ n jé̩ ninu ile-isin Ọlọrun kò le sọ asọtán igbesi-aye rè̩. Sọlomọni fiye si ọna ti eniyan n gba lo igbesi-aye rè̩ ninu ile pẹlu awọn ẹbi rè̩, bi o ṣe n huwa ni ibi iṣẹ laaarin awọn oṣiṣẹ miiran ati bi o ṣe n ba awọn alejo lo nibi iṣẹ rè̩. Ọlọrun n ṣe akiyesi gbogbo iṣẹ awọn eniyan, kò si fẹ ki o ṣe ọlẹ, tabi ki o gberaga, tabi onija, tabi ẹni ti n fi nnkan ṣofo.

Oluwa ti sọ fun wa pe, a ni lati maa ṣiṣẹ titi Oun yoo fi de. A ni lati maa jẹun, ki a si da aṣọ sọrun, ati pe ki a ṣeto ibugbe ti a o maa gbé. A ni lati ṣe itọju awọn àgbàlagbà, awọn alaisan ati awọn ti wọn yarọ, ati awọn ọmọde pẹlu. Nipa igbesi-aye ti o dara, a le jẹ ọṣọ fun Ijọ Rè̩.

Iwa Ọlẹ

Awọn eniyan wa ti wọn kọ lati jẹ iranwọ fun ẹlomiran ati fun ara wọn paapaa. Kò si ẹni ti inu rè̩ n dun lati wa ni tosi iru ọlẹ eniyan bẹẹ. Awọn ẹranko ati awọn kokoro keekeekee ṣe alaapọn ju awọn eniyan miiran lọ. Kiyesi iṣe eerùn. Sọlomọni wi pe: “Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rè̩, ki iwọ ki o si gbọn.” Ki ni a n pe ni ọlẹ? Iwe atumọ ede fun wa ni itumọ rè̩: “Ẹni ti o kún fun ìwà ilọra ati imẹlẹ.” Nipa bẹẹ, ọmọde ti ki i fẹ lati ṣe iranlọwọ fun awọn obi rè̩, ṣugbọn ti o n fẹ ki ẹlomiran maa ṣe iranṣẹ fun oun, ọlẹ ni.

Ọmọde ti o ba jẹ ẹni ti o le ṣiṣẹ yoo ni inu didun. Ohun ti o ti maa n ṣẹlẹ ri ni wi pe ki awọn ọmọde, nigba ti wọn ṣi kéré, maa ṣe iṣẹ ti yoo mu owo wá fun obi wọn; nigba ti ẹbi ba bẹrẹ si pọ, iṣẹ a maa pọ nilẹ lati ṣe. Olukuluku ni yoo ni iṣẹ ti rè̩, awọn ọmọde a si maa fara mọ ọn nigba ti a ba yan iṣẹ fun wọn. Iwọnba owo diẹ ti wọn ba gbà a maa kún wọn loju, tabi ohunkohun ti a ba fi fun wọn gẹgẹ bi èrè.

Lode oni awọn ẹlomiran ni agbegbe miiran a maa ni owo ti o pọ, nitori eyi awọn ọmọ wọn ki i ṣe iranwọ rara lati ba awọn obi ṣiṣẹ ti yoo mu owo wa. Ọpọlọpọ iru awọn ọmọ bẹẹ a maa dagba lai mọ riri owo, tabi bi a ti ṣe n ṣiṣé̩ gba owo, tabi bi a ṣe n nawo ni ọna ti o tọ. Wọn a maa beere ohunkohun ti wọn ba ro pe o yẹ fun wọn lati ni lọwọ awọn obi wọn, wọn a si maa taku pe wọn ni lati fun wọn.

Ọpọlọpọ igbà ni awọn iya maa n ro wi pe o sàn ki awọn ṣe iṣẹ tikara wọn, ju pe ki wọn kọ awọn ọmọbinrin wọn bi a ti i ṣe e, ki wọn si fi ṣe dandan fun wọn lati ṣe iranlọwọ fun wọn. Nitori eyi awọn ọmọbinrin wọnyi a maa dagba lai mọ riri iru iṣẹ ati eto ti wọn ni lati ṣe ki wọn to le ni ile alaafia. A kò kọ wọn lati mọ bi a ti i ba ni gbe ẹrù ati bi a ti i ṣe iranlọwọ fun ni. Wọn fẹran lati ṣire ju lati ṣiṣẹ lọ; nitori eyi, nigba ti wọn ba dagba, igbeyawo wọn a maa yọri si ikọsilẹ.

Awọn Ẹda Keekeekee ti o Lọgbọn

Sọlomọni kọ ọpọlọpọ iwe nipa è̩dá o si mọ nipa ìwa ati iṣe awọn kokoro. Kò si aniani pe yoo ti maa kiyesi awọn eera bi wọn ti n gbe ẹrù ti o tobi ju awọn tikalara wọn lọ lọpọlọpọ, ki o wo pẹlu iyanu bi o ti n ro ibi ti awọn ẹda wọnyi n gbe ẹrù naa lọ. Boya o ti yẹ ité̩ wọn wò, o si rii pe wọn kó è̩é̩rún ounjẹ jọ daradara de igba otutu. Ni gbogbo ìgbà è̩è̩rùn awọn ẹda kekere wọnyi a maa ṣe aisinmi, wọn a si maa sare, wọn a maa yara bọ sihin ati sọhun lati kó ounjẹ wọn jọ de igba otutu. Wọn kò ni oye bi eniyan ṣugbọn Ọlọrun ti fi iru ọgbọn kan si wọn lọkàn ti o n sọ ohun ti wọn ni lati ṣe fun wọn.

Ọna ti awọn eera n gba kọ itẹ wọn jẹ iyanu. Nigba miiran ọpọ yàrá ni yoo wa labẹ ilẹ. Nigba miiran wọn a kọ ile wọn bi ahéré tabi òkiti sori ilẹ. Wọn a maa pin eyi si ilu ti o niye, wọn a si la ọna ti yoo so wọn pọ lori ilẹ, tabi ki wọn gbẹ ọna si abẹ ilẹ.

Olukuluku olugbe Ilu Eera ni o kún fun iṣẹ. Awọn miiran a maa kọ itẹ, awọn miiran a si maa là ọna. A sọ fun ni nipa iru eera kan ti i maa gbá gbogbo ilẹ ayika ìtẹ rè̩ mọ féfé to iwọn ẹsẹ mé̩wàá tabi mejila ki irugbin kan ti a n pe ni irẹsi eera ki o le hu yika (lai si omiran.) Awọn eera kan wà ti a yà sọtọ lati jẹ jagunjagun. Wọn a maa jade lọ nigba miiran lati lọ kó awọn eera miiran ni ẹrú. Wọn a kó awọn ẹyín wọn pada sinu ìtẹ ki wọn le pa ọmọ; wọn a si mú ki awọn ẹrú naa maa ṣe iṣẹ ninu ìtẹ. Awọn eera a maa sin awọn kòkòrò tíntìntín kan lati maa fun wọn ni “wàrà” gẹgẹ bi awọn malu wa ti n ṣe fun wa.

Sọlomọni wi pe awọn eera jẹ ọkan ninu awọn nnkan mẹrin ti o kere lori ilẹ aye, ṣugbọn ti wọn kún fun ọgbọn lọpọlọpọ, “alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba è̩run” (Owe 30:24, 25). Nigba ti otutu ba si de, wọn a sinmi ni itura ninu ile wọn, wọn a ni ounjẹ tẹrùn, ara wọn a si gbona.

Pipese silẹ Fun Ayeraye

Ki i ṣe kiki bi a ti ṣe le jẹ alaapọn ninu iṣẹ oojọ wa nikan ni a le ri kọ lara awọn eera, ṣugbọn a le mu iru ẹmi alaapọn ti wọn ni lati lo o ninu iṣe wa nipa ti ẹmi. Akoko yii gan an ni a ni lati mura silẹ fun ayeraye. Yoo ti pẹ ju nigba ti “ikore ba kọja, ti igba è̩run si ti dopin.”

Ọrọ Ọlọrun n sọ fun ẹlẹṣẹ loni pe, “Ọlẹ, iwọ o ti sùn pẹ to? Nigbawo ni iwọ o dide kuro ninu orun rẹ?” Ọpọlọpọ awọn ọdọ ni o n ba ọna igbadun wọn lọ, ti wọn n yọ ninu afẹ è̩ṣẹ, lai ronu idajọ. Yoo ti pẹ to ki wọn to le taji lati mọ iru ewu ti o wà niwaju wọn nipa yiyi ero wọn kuro lọdọ Ọlọrun? A mọ pe awọn àgbà ni lati kú -- ṣugbọn ọdọ a maa kú pẹlu. Aisan le dede pa ọmọde ti o ni ilera pipe tẹlẹ laaarin ọjọ diẹ. Agbako ifarapa le mu wọn kuro kia pẹlu.

Igba ọdọ ni akoko lati wá Oluwa, nigba ti ẹri ọkàn ṣi rọ ti o si le gbọ rírọ Jesu. Bi awọn eniyan ba tubọ n se aya wọn le nigba ti Ọlọrun n ba wọn sọrọ, akoko n bọ ti ki yoo si imisi lati wá Oluwa mọ.

Alufaa (Oluṣọ-agutan) kan sọ itan yii nigba kan: “Mo wọ abule agbẹ kan ni irọlẹ ọjọ kan ti o motutu ni oṣu ikọkanla ọdun mo si lo wakati kan lati bá awọn ẹbi naa sọrọ Ọlọrun. Baba arugbo kan – oninuure ti o si ni ifẹ --tẹle mi de ẹnu-ọna o si wi pe, ‘Mo dupẹ fun ibẹwo rẹ, mo si ro pe eleyii ki yoo jẹ opin. Gẹgẹ bi o ti bẹrẹ iṣẹ rẹ laaarin wa, mo fẹ fun ọ ni amọran kan. Jọwọ fi awa arugbo silẹ, ki o si dari wahala iṣẹ rẹ sọdọ awọn ọdọ inu agbo rẹ. Ogoji ọdun sẹyin, mo n ronu gidigidi nipa ẹmi mi; ọpọlọpọ ninu awọn arakunrin mi ni wọn ní iyipada àyà, ṣugbọn emi kò si ninu wọn. Lẹyin eyi, labẹ iṣẹ iranṣẹ alufaa miiran, ọpọlọpọ ni wọn tun yipada, ṣugbọn n kò pẹlu. Nisisiyi fun ọpọlọpọ ọdun, emi kò tilẹ ni ero kankan lori ọrọ bẹẹ mọ! Mo mọ pe ẹlẹṣẹ ti o ti sọnu ni mo jẹ. Mo mọ pe nipasẹ Jesu Kristi nikan ṣoṣo ni mo le ri igbala; mo gba nnkan ti o n waasu gbọ, ṣugbọn mo dabi okuta ti o duro rigidi, bẹẹ ni ọrọ naa kò ṣe nnkankan fun mi. Mo lero lati wà bayii ki n si kú bakan naa. Nitori naa jọwọ wa silẹ ti awa ti è̩ṣẹ wa, si lọ lo agbara rẹ fun igbala awọn ọdọ.’

“Mo ṣe akiyesi bi ọkunrin yii ti n ṣe si. Ijoko rè̩ kò ṣofo ni ile-isin ri; ṣugbọn asọtẹlẹ otitọ ni o sọ nipa ara rè̩. Bi o ti sọtẹlẹ gan an ni o ṣe lo aye rè̩; bẹẹ ni o si kú. Bẹẹ ni a tẹ ẹ silẹ nikẹyin ninu saree rè̩ lai nireti, laaarin awọn ijọ eniyan ti Ọlọrun ti fi ọpọlọpọ igba ṣi ferese Ọrun silẹ fun.” O! awọn ọdọ i ba jẹ tete taji ki wọn to mu Ẹmi Ọlọrun binu bi wọn ti maa n ṣe nigba gbogbo ti O si n lọ kuro lọdọ wọn! Ọrọ Ọlọrun paṣẹ pe: “Ranti ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ, nigbati ọjọ ibi kò ti ide, ati ti ọdun kò ti isunmọ etile, nigbati iwọ o wipe, emi kò ni inu didun ninu wọn” (Oniwasu 12:1).

Oju Igberaga

Ọlọrun kò le fi oju rere wo è̩ṣẹkẹṣẹ, ṣugbọn Sọlomọni darukọ ohun meje ti Ọlọrun korira gidigidi. Ekinni ni oju igberaga. Awọn ẹlomiran a maa sọ bayii pe awọn kò ti i ṣe ohun ti o buru pupọ, ati pe nitori eyi awọn ni idaniloju pe Ọlọrun yoo mu wọn lọ si Ọrun. S̩ugbọn oju igberaga paapaa jẹ irira nla niwaju Ọlọrun. Lai si aniani oju igberaga a maa ti inu igberaga ọkàn jade wa. Ọlọrun ti wi pe awọn ọlọkan-tutu ni yoo jogun aye.

O ti gbọ nipa Sodomu, ilu ti Ọlọrun fi ojo ina ati sulfuru lati Ọrun parun nitori iwa buburu wọn. Njẹ o mọ awọn è̩ṣẹ kan ti a ri ninu rè̩, eyi ti o fa ibinu Ọlọrun wa sori awọn eniyan naa? È̩ṣẹ Sodomu ni yii: “Irera, onjẹ ajẹyo ati ọpọlọpọ orayè wà ninu rè̩, ati ninu awọn ọmọ rè̩ obirin; bḝni on kò mu ọwọ awọn talaka ati alaini lókun. Nwọn si gberaga, nwọn si ṣe ohun irira niwaju mi” (Esekiẹli 16:49, 50).

A da Sodomu lẹbi nitori pe awọn eniyan rè̩ gberaga. Wọn ro wi pe awọn san ju awọn eniyan iyoku lọ. Boya wọn tilẹ sọrọ bi ọkunrin ọlọrọ ni: “Ọkàn, iwọ li ọrọ pipọ ti a tò jọ fun ọpọ ọdún; simi mā jẹ, mā mu, mā yọ” (Luku 12:19). S̩ugbọn Ọlọrun korira igberaga wọn, iwa ọlẹ wọn, ajẹju wọn ati pe wọn kò ṣe iranlọwọ fun awọn alaini. Ẹ jẹ ki a fi iye si gbogbo Ọrọ Ọlọrun ki a ba le ṣetan lati pade Jesu nigba ti O ba dé.

Irọ

Ahọn eke jẹ nnkan miiran ti Ọlọrun korira. Boya o ti n ro pe awọn “irọ funfun” keekeekee ti o maa n pa lati yọ ara rẹ kuro ninu wahala tabi lati fi ni ojurere lọdọ eniyan kò buru ju; ṣugbọn Ọlọrun n ba ọ sọ nipasẹ Sọlomọni pe Oun korira iru nnkan bẹẹ. Ọlọrun n fẹ ki awọn ọmọ Rè̩ maa sọ otitọ lati inu ọkàn wá, ki wọn má si ṣe huwa irọ kan rara. Gbogbo awọn ti wọn n purọ -- ki i ṣe kiki awọn ti n pa “irọ nla” nikan – ni yoo ni ipin wọn ninu adagun iná, pẹlu awọn apaniyan, awọn oṣo, ati awọn abọriṣa (Ifihan 21:8). “Irira loju OLUWA li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn inu rè̩” (Owe 12:22).

Ninu gbolohun kan naa ti o n sọ nipa opurọ, a gbọ nipa apaniyan. Boya o ti n ro pe ipaniyan jẹ è̩ṣẹ ti o buru pupọ, ṣugbọn pe irọ pipa kò ṣe nnkan. Ọrọ Ọlọrun n sọ nipa wọn bakan naa pe Ọlọrun korira wọn.

Ero Buburu

Ọlọrun korira ọkàn “ti ngbèro ohun buburu.” Ero buburu le jẹ gbigbero lati ṣe aiṣododo ni ọjọ ti n bọ. “Egbe ni fun awọn ti ngbìmọ aiṣedede, ti nṣiṣẹ ibi lori akete wọn! nigbati ojumọ mọ nwọn ṣe e, nitoripe o wà ni agbara ọwọ wọn” (Mika 2:1). Iru awọn eniyan bẹẹ ni ẹsẹ wọn maa “nyara lati ṣe ìkà.” Ọlọrun korira eleyii naa pẹlu. Ero buburu le sọ si wa lọkàn ṣugbọn a ni lati mu wọn kuro ninu ero wa, ki a má si ṣe jẹ ki wọn wọ inu ọkàn wa.

Ẹlẹri èké ti n purọ jẹ ọkan naa pẹlu ahọn èké. Èké ṣiṣe ni lati jẹ è̩ṣè̩ ti o buru pupọ nitori pe Ọlọrun darukọ rè̩ lẹẹmeji ninu awọn nnkan ti O korira.

Iru eniyan miiran ti o n fa irunú Ọlọrun wá sori ara rè̩ ni “ẹniti ndá ija silẹ larín awọn arakunrin.” Oun ni ẹni ti a le maa pe ni adijasilẹ. A maa sọ ọrọ ti yoo mu ki awọn eniyan má le fi ọkàn tán ara wọn tabi ki wọn korira ẹlomiran. A ba jẹ le maa ṣọra ki a má ba pa ẹnikẹni lara nipa ọrọ ti a n sọ.

A n fẹ iyọnu Ọlọrun lori aye wa. Bi a ba fi ọkàn si ohun ti Bibeli kọ wa lati ṣe, ti a si ṣe e, a o gbọ ohun Ọlọrun bayii pe “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ bọ sinu ayọ Oluwa rẹ.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni a n pe ni ọlẹ?
  2. Ki ni Sọlomọni sọ pe ki ọlẹ ṣe? Nitori ki ni?
  3. Ẹkọ wo ni a le ri kọ lara awọn eera?
  4. Awọn agba a maa kú, ṣugbọn awọn ọdọ n kọ?
  5. Darukọ ohun meje ti Ọlọrun korira gẹgẹ bi a ti darukọ wọn ninu ẹkọ yii.
  6. Ki ni è̩ṣẹ Sodomu gẹgẹ bi akọsilẹ ti o wà ninu Esekiẹli 16:49, 50?
  7. Ki ni Ọlọrun sọ nipa eke ṣiṣe ati ẹni ti n ṣèké?
  8. Ki ni a n fẹ ki Ọlọrun sọ fun wa nigba ti a ba duro ni idajọ?