Owe 27:1-27; 28:1-28; 29:1-27

Lesson 280 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o bo è̩ṣẹ rè̩ mọlẹ ki yio ṣe rere; ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ānu” (Owe 28:13).
Notes

Ọjọ Ọla

Ninu awọn Iwe Owe, Sọlomọni kọ nipa oriṣiriṣi nnkan. Oluwa mi si Sọlomọni lati kọ wọn silẹ fun ire ati fun anfaani gbogbo eniyan. Awọn ti a kò i ti gba ọkàn wọn là yoo ni òye lati mọ iru anfaani ti o wà ninu biba Ọlọrun laja ati gbigbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun, nigba ti wọn ba kà a. Awọn ti a si ti gba ọkàn wọn là pẹlu ni anfaani lati fiyesi awọn ikilọ ti o wà ninu Iwe Owe.

“Máṣe leri ara rẹ niti ọjọ ọla.” Sọlomọni kilọ fun wa pe ẹnikẹni kò mọ ohun ti o le ṣẹlẹ ni ọjọ kan. Ọpọlọpọ igba ni awọn eniyan maa n ṣe eto ọjọ ti o jinna rére silẹ. Wọn a ṣeto silẹ lai ni Ọlọrun ninu ero wọn.

Àká ti o Tobi Ju

Ninu Bibeli, a ri apẹẹrẹ ọkunrin ọlọrọ kan ẹni ti o leri ara rè̩ ni ti ọjọ ọla. Nnkan lọ deedee fun ọkunrin naa. Àká rè̩ kò le gba gbogbo eso oko rè̩. O pinnu lati wó àká rè̩ palẹ ki o kọ eyi ti o tobi. O pinnu lati kó gbogbo eso ati ọka rè̩ sinu awọn àká ti o tobi ti o ṣẹṣẹ fẹ kọ. Lẹyin eyi, o rò o wi pe, oun yoo sinmi nitori pe oun ni ounjẹ ti yoo tó fún ọpọlọpọ ọdun. Oun yoo wi fun ara rè̩ pe, “Ọkan, ... simi, mā jẹ, mā mu, mā yọ” (Luku 12:19). O ti ṣe eto ọpọlọpọ ọjọ iwaju silẹ, lai si ironu nipa ti Ọlọrun ati lai gbadura. S̩ugbọn kò mọ ohun ti ọjọ ọla yoo mu wá fun oun, ki a má ṣẹṣẹ wa sọ ti ọpọlọpọ ọjọ.

Ọlọrun sọ fun ọkunrin ọlọrọ naa pe, “Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?” Bakan naa ni o ri pẹlu awọn ti n ro nipa ara wọn ti wọn kò rò nipa Ọlọrun. Wọn le ni ọrọ ni tootọ ṣugbọn wọn kò ni ọrọ lọdọ Ọlọrun. Ohun iṣura aye wà fun igba kukuru! Wo o bi o ti ṣanfaani tó lati to iṣura jọ si Ọrun nipa ṣiṣe iṣẹ fun Oluwa ati nipa lilo igbesi-aye wa fun Un (Matteu 6:19, 20).

Bi Oluwa ba Fẹ

Ọrọ Sọlomọni kò kọ fun eniyan lati mura silẹ fun ọjọ ọla. Jijọ ara-ẹni loju ati aijọwọ ara-ẹni fun Ọlọrun ni ohun ti o buru ti yoo si mu ibanujẹ ati iparun bá ni. Onigbagbọ a maa gbẹkẹle Ọlọrun, a si maa sọ ni ti ọjọ-iwaju pe “bi Ọlọrun ba gba” pe ki o ri bẹẹ, tabi “bi Jesu ba fa bibọ Rè̩ sẹyin” di igba naa. “Eyi ti ẹ bá fi wipe, Bi Oluwa ba fẹ, awa o wà lāye, a o si ṣe eyi tabi eyini” (Jakọbu 4:15).

Kò si Akoko ti o Wọ

Bibeli sọ fun wa nipa ọkunrin miiran ti igbesi-aye rè̩ ni lati jẹ ikilọ fun awọn ti kò i ti ri igbala. Ni akoko ti a mu Paulu Apọsteli, ti a si fi i sinu tubu nitori pe o n waasu Ihinrere, Fẹliksi baalè̩ “ranṣẹ pè Paulu, o si gbọ ọrọ lọdọ rè̩ nipa igbagbọ ninu Kristi Jesu.” Nigba ti Paulu n sọ asọye fun un nipa “ododo, ati airekọja, ati idajọ ti mbọ” è̩ru ba Fẹliksi nitori ti è̩ṣẹ rè̩ da lẹbi. O ran Paulu lọ, o si wi pe, “Nigbati mo ba si ni akokò ti o wọ, emi o ranṣẹ pè ọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 24:25). O ṣogo ninu ara rẹ pe akoko ti o wọ yoo wà lati gbadura; ṣugbọn a kò ka a pe Fẹliksi ri igbala. Bi a kò ba i ti gba ọkàn rẹ là, má ṣe fi ọjọ igbala rẹ di ọla. Ki i ṣe fun wa lati mọ akoko tabi igba (Iṣe Awọn Apọsteli 1:7). Bawo ni eniyan ṣe le ṣogo ni ti ọjọ rè̩? Wá Ọlọrun fun igbala, gbẹkẹle Ọlọrun, gbọran si I lẹnu, iwọ yoo ṣetan fun ohunkohun ti o wu ki o le de.

Yiyin Ara-ẹni

“Jẹ ki ẹlomiran ki o yìn ọ, ki o máṣe ẹnu ara rẹ.” Ninu owe yii Sọlomọni kò sọ idi rẹ fun wa ti oun fi wi bẹẹ, bẹẹ ni kò si sọ ohun ti yoo ti ẹyin rè̩ jade gẹgẹ bi o ti ṣe ninu ọpọlọpọ ọrọ rè̩. Lati maa yin ara-ẹni, tabi lati gbe ara-ẹni ga kò ni ere fun ẹnikẹni. Idena ni. Bi eniyan ba n yin ara rè̩, o n wa iparun ara rè̩ ni (Owe 17:19). Awọn eniyan ki i fẹ lati maa feti si ẹni ti o n fi iyin fun ara rè̩. Wọn a maa rò pe o jọ ara rè̩ loju ni. Nigba ti o ba pari ọrọ rè̩ tan, awọn eniyan a maa ni ero buburu nipa rè̩ ju pe ki wọn ni ero giga nipa rè̩ bi oun ti ro tẹlè̩.

Ninu ẹkọ Jesu a kilọ fun wa pe “ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rè̩ ga, li a o rè̩ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rè̩ ara rè̩ silẹ li a o gbé ga” (Matteu 23:12). Ki ni le mu yínyin ara-ẹni wa bi kò ṣe lati gbe ara ẹni ga loju awọn ẹlomiran? Bi eniyan ba ṣe nnkan fun iyin eniyan, o ti gba ere rè̩ ná (Matteu 6:1, 2).

Farisi Kan

A kà ninu Bibeli nipa ọkunrin kan ti o yin ara rè̩. Oun ni Farisi nì ti o lọ sinu Tẹmpili lati gbadura (Luku 18:10-14). Dipo ti i ba fi gbadura si Ọlọrun, o gbadura “ninu ara rè̩”. O sọ nipa ohun rere gbogbo ti o ṣe bi ẹni pe Ọlọrun kò mọ ati bi ẹni pe Ọlọrun kò ti sọ pe “gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin” (Isaiah 64:6). Farisi naa kò darukọ inu rere ati ododo Ọlọrun, nitori pe kò ni iru awọn nnkan wọnyi ninu aye rè̩. Kaka bẹẹ, Farisi yii n fi iyin fun ara rè̩ lori rere ti o ṣe dipo ti i ba fi “kun fun eso ododo lati ọdọ Jesu Kristi, fun ogo ati iyìn Ọlọrun” (Filippi 1:11), dipo ti i ba fi di “ìgbaiya ododo nì mọra” (Efesu 6:14) eyi ti i ṣe apa kan ninu ihamọra ti ẹmi.

Ọkàn ti o Yó

Farisi naa rò pe oun dara to bẹẹ ti oun kò fi ni ohunkohun lati beere lọwọ Ọlọrun. Kò ri ohunkohun gbà lọdọ Ọlọrun, bẹẹ ni o si lọ si ile lai ni idalare. Nipa eyi, o jẹ apẹẹrẹ kan ninu owe Sọlomọni pe, “Ọkàn ti o yó fi ẹsẹ tẹ afara-oyin.” Itumọ eyi ti o lọ bayii pe ẹni ti kò mọ ohun ti oun ṣe alai ni kò le gbadun ohun ti o dara ju lọ fun un. Bakan naa ni nipa ti ẹmi nigba ti eniyan ba lọ si ile Ọlọrun bi Farisi nì ti ṣe. Nigba ti eniyan ba rò pe oun kò ṣe alai ni ohunkohun, awọn ileri ti o tilẹ ṣọwọn ju lọ kò ni jọ ọ loju, a si pada ni ọwọ “ofo” (Luku 1:53). Ẹni ti o ba lọ si ile Ọlọrun pẹlu ebi nipa ti ẹmi – ti o n poungbẹ lati mọ sii nipa Ọlọrun ati Bibeli – a maa gbadun ohun gbogbo ti a n ṣe ninu ìsìn. Ni tootọ iwaasu, orin, ati ẹri ti o gbọ le fi ikuna rè̩ han an, ṣugbọn yoo lọ si ile pẹlu itẹlọrun nitori pe o gbadura, o si fiyesi ohun ti o gbọ.

Awọn Ọrẹ

Boya o ti ri i pe bi o ba n fẹ lati ni awọn ọré̩ o ni lati ni iwa ikonimọra (Owe 18:24). Ọpọlọpọ eniyan ni o ni ọrẹ ni iwọn. Awọn ẹlomiran ro pe awọn ni ọré̩ ṣugbọn awọn ọrẹ wọnyi kò ju awọn ti wọn ti mọ té̩lè̩. A maa n wi bayii pe ẹnikẹni ti o ba le fi inu rere huwa si ni ni a n pè ni ọré̩. Nigba pupọ ni Sọlomọni darukọ “ọré̩” ninu awọn akọsilẹ rè̩. Ninu ori ikẹta-dinlọgbọn Iwe Owe, ẹsẹ marun un ni o n sọ nipa ọré̩. Sọlomọni n sọ fun wa pe ki a pọn ọré̩ tootọ lé. Awọn ọrẹ atijọ ti fi han pe wọn jẹ ọrẹ tootọ; wọn mọ abuku ọré̩ wọn, wọn a si maa wá ire rè̩. Wọn a maa ṣe iranlọwọ lati maa tọka si abuku eniyan ati rere ti o n ṣe pẹlu, ki o ba le bori awọn ikuna wọnni.

Imisi Rere tabi Buburu

Sọlomọni wi pe awa eniyan a maa ni agbara lori iwà awọn ọrẹ wa. “Ọkunrin ni ipọn oju ọré̩ rè̩.” Iru imisi wo ni iwọ maa n mu wá sinu igbesi-aye awọn ọrẹ rẹ? O maa n fi è̩tan pọn wọn le to bẹẹ ti wọn o fi lero pe o n ṣe eyi lati fi wa ojurere wọn ni? Sọlomọni wi pe iru iyin bẹẹ si ọré̩ wa “li a kà si egun fun u” ati pe “ẹniti o npọn ẹnikẹji rè̩ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rè̩.” Lẹyin ti awọn ọrẹ rẹ ba ba ọ sọrọ tan wọn ha n pada lọ pẹlu ironu pe i ba tilẹ san fun wọn ju bi o ba ṣe pe wọn kò ba ọ sọrọ rara? Tabi wọn ha pada pẹlu idunnu ati iṣiri lati sin Oluwa?

Ọrẹ Jesu Kan

Sọlomọni wi pe “Ọré̩ a ma fẹni nigbagbogbo” (Owe 17:17). Eyi yii ni pe ọrẹ a maa fẹ ni ni igba aini ati wahala, gẹgẹ bi igba ti ohun gbogbo n lọ deedee ti a si n yìn wa. Awọn ọrọ Sọlomọni n fi han ni gbangba bi a ṣe le mọ ọrẹ tootọ. Iwọ ha jẹ ọré̩ tootọ fun awọn ẹlomiran bi?

Sọlomọni wi pe, “Ọré̩ kan si mbẹ ti o fi ara mọni jù arakunrin lọ” (Owe 18:24). Ta ni ọré̩ yii ṣe? Eyi kò le jẹ ẹlomiran bi kò ṣe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun. Ni igba aini O fi ara Rè̩ han ni Ọré̩ fun Maria ati Marta, awọn arabinrin Lasaru (Johannu 11:5). Jesu pe awọn Apọsteli ni ọré̩ Rè̩ (Johannu 15:15). Ọpọlọpọ orin daradara ni a ti kọ silẹ nipa Jesu Ọré̩ wa. Eyi ti a fẹrẹ mọ ju lọ ni eyi ti o wi pe:

“Ọrẹ wo l’a ni bi Jesu

Ti O ru ’banujẹ wa!

Anfani wo lo pọ bayi

Lati ma gbadura si.

Alafia pupọ l’a n sọnu,

A si ti jẹ ’rora pọ,

‘Tori a kò n fi gbogbo nkan

S’adura niwaju Rè̩!”

Ko si aniani pe iwọ o fé̩ lati yan Jesu ni Ọré̩ rẹ. Bi a ba ti gba ọ là, ti o si n gbọràn si aṣẹ Oluwa, iwọ pẹlu Jesu jẹ ọré̩, nitori O ti wi bayi pe, “Ọré̩ mi li ẹnyin iṣe, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin” (Johannu 15:14).

Enia Buburu

Ọpọlọpọ igba ni Sọlomọni maa n sọ nipa anfaani ti o wà fun awọn ti a gbala. A maa fi igbesi-aye awọn olododo we ti awọn alaiṣododo. Sọlomọni wi pe, “Enia buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun.” O ha ranti ẹkọ kan ti a ti ṣe sẹyin, eyi ti o ba ọrọ Sọlomọni yii lọ? Njẹ awọn Ọmọ Israẹli ha ti ni igboya ati ọkàn akin ri nigba ti wọn gbẹkẹle Oluwa? N jẹ awọn ọta wọn ha ti sá ri, bi o tilẹ ṣe pe a kò lé wọn?

Aanu

Sọlomọni ṣe ju pe ki o kan ṣe apejuwe igbesi-aye eniyan buburu. O fi iyatọ ti o wà laaarin awọn ti wọn n gbe igbesi-aye iwa-mimọ ati awọn ti n gbe igbesi-aye buburu hàn. Lẹyin kikilọ fun awọn ti a kò i ti gbala, Sọlomọni tun tọni sọna nipa wiwá Ọlọrun fun aanu ati igbala. Sọlomọni wi pe, “Ẹniti o bo è̩ṣẹ rè̩ mọlẹ ki yio ṣe rere; ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ ọ silẹ yio ri ānu.” Nigba ti eniyan ba ṣetan lati gba pe ẹlẹṣẹ ni oun, ti o beere fun idariji lọdọ Ọlọrun, niwọn-igba ti o pinnu lati yipada kuro ninu è̩ṣẹ rè̩, Oluwa yoo ṣaanu, yoo si dariji ẹni naa.

Kikọ È̩ṣẹ Silẹ

O ṣe e ṣe fun eniyan lati jẹwọ è̩ṣẹ rè̩, sibẹ ki o má si ri igbala, nitori pe kò ṣetan lati kọ wọn silẹ. Saulu jẹ iru eniyan bẹẹ. A paṣẹ fun un lati lọ pa ilu Amaleki run, ati lati pa a run patapata lai da ohun kan si. S̩ugbọn Saulu ati awọn eniyan naa dá Agagi Ọba si, ati awọn ti o dara jù ninu awọn ẹran, “nwọn kò si fẹ pa wọn run patapata.” Saulu ṣe aigbọran, lẹyin eyi o si wi pe oun ti mu aṣẹ Oluwa ṣẹ. Ọlọrun ran Woli Rè̩, ti i ṣe Samuẹli, si Saulu. Nigba ti a si bi i leere nipa awọn agutan ati malu ti o dá si, Saulu yi ẹbi naa sori awọn eniyan, o si wi pe oun bè̩ru awọn eniyan naa. Saulu gbà nikẹyin pe oun dẹṣẹ, ṣugbọn kò fẹ lati kọ gbogbo è̩ṣẹ rè̩ silẹ. Ọlọrun kọ ọ silẹ ni ọba, nitori pe Saulu kọ Ọrọ Ọlọrun silẹ (1Samuẹli 15:23). A fi ijọba Saulu fun ẹlomiran, bẹẹ ni Saulu kú lai tun ri igbala mọ.

Ẹṣẹ ti o Pamọ

Ọkunrin miiran ti o gbiyanju lati bo è̩ṣẹ rè̩ mọlẹ ni Akani. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli lọ ba ilu Ai jagun, a ṣẹgun awọn Ọmọ Israẹli, dipo ti wọn i ba fi ni iṣẹgun gẹgẹ bi ileri Ọlọrun. Jọṣua beere idi rè̩ lọwọ Ọlọrun. Ọlọrun sọ fun Jọṣua pe è̩ṣẹ wà ninu agọ -- ẹni kan ti “mú ninu ohun iyasọtọ ni” o si ti fi i pamọ saarin ohun ti rè̩. Ọlọrun wi pe Oun ki yoo wà pẹlu awọn Ọmọ Israẹli mọ bi kò ṣe pe wọn ba pa è̩ṣẹ run laaarin wọn. S̩ugbọn Akani kò jẹwọ nigba ti Jọṣua sọ ọrọ yii fun awọn Ọmọ Israẹli. Ni ẹyà kọọkan, idile kọọkan, agbo-ile kọọkan, ati nikẹyin ọkunrin kọọkan ni wọn fara han niwaju Jọṣua. Ọlọrun fi Akani han pe oun ni ẹlẹṣẹ. Sibẹ Akani kò sọ ohunkohun. Nigba naa ni Jọṣua paṣẹ fun un pe ki o jẹwọ ki o si sọ ohun ti o ṣe. A mu Akani nipá lati jẹwọ pe oun ti dẹṣẹ (Joṣua 7:20). O wi pe, “Mo ri ... mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sa wò o, a fi wọn pamọ ni ilẹ lārin agọ mi.” Nigba ti Akani ro pe è̩ṣẹ oun fi ara pamọ, Ọlọrun tu u si gbangba. A pa Akani. Akani jẹwọ è̩ṣẹ rè̩ ṣugbọn kò ri aanu gbà nitori pe kò i ti i yipada kuro ninu è̩ṣẹ rè̩, bẹẹ ni kò si ronupiwada niwaju Ọlọrun.

Awọn Ileri

Sọlomọni sọrọ ni ti awọn ileri ibukun ti Ọlọrun ṣe fun awọn ti wọn ba le gbé igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun, ninu awọn ileri naa si ni: ìbukún (Owe 29:18), ọlá (Owe 29:23), ipamọ (Owe 29:25), ayọ (Owe 29:6), imoye (Owe 28:5), ọrọ (Owe 28:10), ati idasilẹ (Owe 28:18). O tun sọrọ ileri idajọ ati iparun lori awọn ti wọn n fi igba gbogbo ati igbakuugba kọ ipe Ọlọrun.

Ninu awọn akọsilẹ Sọlomọni wọnyi, a ri ọna ti Ọlọrun là silẹ fun igbala, ati ni idakeji -- ọna awọn ẹlẹṣẹ. Ọna wo ni iwọ yàn? Iye ni tabi iku? Ibukun tabi ègún? Ire tabi iparun? Sọlomọni wi pe, “Ẹniti a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe”; ṣugbọn “Olõtọ enia yio pọ fun ibukún.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Bawo ni Onigbagbọ ṣe n sọrọ nipa ọjọ ọla?
  2. Ta ni “ọkàn ti ebi n pa”?
  3. Ta ni Ọré̩ ti o dara ju lọ ti eniyan le ni?
  4. Awọn wo ni ọrẹ Jesu?
  5. Ki ni iyatọ laaarin jijẹwọ è̩ṣẹ ati kikọ ọ silẹ?
  6. Ki ni a sọ nipa ẹni ti o n ja baba tabi iya rè̩ ni ole?
  7. Ki ni ṣe ti kò dara lati maa ṣe ojusaju eniyan?
  8. Ki ni ṣe ti a ni lati maa tọ awọn ọmọde sọnà?
  9. Ki ni ibawi?
  10. Ta ni yoo maa “pọ si i ni ibukún”?