Iṣẹ Awọn Apọsteli 2:1-47

Lesson 281 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8).
Notes

Ileri Oluwa

Ni alẹ ti o kẹyin ti Jesu lo pẹlu awọn Apọsteli Rè̩ ki a to kan An mọgi, O ṣeleri fun wọn pe Olutunu nì lati Ọrun yoo wá lati maa gbe inu wọn. Olutunu nì yoo tubọ sọ fun wọn sii nipa Jesu ati nipa Ọrun, yoo si maa kọ wọn ni ohun ti o yẹ ki wọn ṣe, ati ibi ti o yẹ ki wọn lọ.

Ati ju bẹẹ lọ, lẹyin ti Jesu jinde kuro ninu oku, O sọ fun wọn pe Ẹmi Mimọ yoo bà lé wọn. O ṣeleri fun wọn pe: “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà lé nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Ẹmi Mimọ ni Ẹni kan naa ti i ṣe Olutunu ti Jesu sọ fun wọn nipa Rè̩. Yoo maa tù wọn ninu, yoo maa kọ wọn, yoo si fun wọn lagbara.

Oye ohun wọnni ti Jesu n sọ kò yé awọn ọmọ-ẹyin ni kikún, wọn si tun n fẹ lati mọ bi Jesu yoo gbe Ijọba Rè̩ kalẹ sori ilẹ aye nigba naa. Boya wọn n rò pe agbara Jesu jẹ nipa ti ara, ati pe yoo tobi to bẹẹ ti awọn le fi ni anfaani lati ti ipasẹ rè̩ bori Ijọba Romu. S̩ugbọn Jesu jẹ ki wọn mọ pe eyi kọ ni o ṣe pataki. Oun n fẹ ki wọn ni agbara nipa ti ẹmi lati bori Satani. O n fẹ ki wọn ṣe ẹlẹri Oun ki Ẹmi Mimọ ba le ti ipasẹ wọn yi awọn ẹlẹṣẹ pada si Ijọba Ọrun.

Ipade ni Jerusalẹmu

Jesu sọ fun wọn pe ni Jerusalẹmu ni Ẹmi Mimọ yoo ti bà lé wọn, ati pe “ki iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.” Nitori eyi awọn ọmọ-ẹyin pada lọ si Jerusalẹmu taara, wọn si bẹrẹ si gbadura. Ọgọfa eniyan ni wọn wà ninu ipade naa, wọn n sin, wọn si n yin Ọlọrun logo. Wọn kò tun banujẹ nipa ikú Jesu mọ, ṣugbọn wọn n yọ nitori pe O ti ṣẹgun ikú ati pe O si ti lọ si Ọrun. Wo o bi ayọ iṣẹgun naa ti pọ to fun wọn pe Olugbala wọn ti jinde kuro ninu oku, lati fi han pe Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe!

Wọn wà ninu ipade adura yii fun ọjọ mẹwaa, ogo Ọlọrun si hàn lara wọn. Gbogbo wọn ni a ti sọ di mimọ, ti wọn si n sin ni iṣọkan ẹmi; nitori eyi Ẹmi Mimọ Ọlọrun ni ayè lati bukun wọn. Gbogbo awọn Apọsteli ati awọn obinrin ti wọn ti n tẹle Jesu lẹyin, laaarin awọn ti Maria iya Rè̩ wà, ni wọn yin Oluwa wọn ti a ti ṣe logo.

Ọjọ Pẹntekọsti

Aadọta ọjọ lẹyin Ajọ Irekọja, awọn Ọmọ Israẹli a maa ṣe iranti fifi Ofin fun wọn lori Oke Sinai nipa ṣiṣe ajọyọ kan ti a n pe ni Ajọ Ọsẹ tabi Ajọ Pẹntekọsti. Jesu, Ọdọ-agutan Irekọja wa, kú ni Ọjọ Ajọ Irekọja. Aadọta ọjọ lẹyin eyi, nigba ti Ọjọ Pẹntekọsti de, awọn ọgọfa wà sibẹ ti wọn n sin, ti wọn si n yin Ọlọrun logo. Aarẹ kò mu wọn, bẹẹ ni wọn kò ti i pada si ile wọn, ṣugbọn wọn n duro sibẹ gẹgẹ bi Jesu ti paṣẹ. Lojiji wọn gbọ iro kan ti o dàbi iró ẹfuufuu lile lati Ọrun wá. O si kún gbogbo ile nibi ti wọn gbe joko. Ẹmi Ọlọrun ni o bà le wọn, Ẹmi Mimọ ti Jesu ti ṣeleri.

Ayọ wọn ti pọ to! Rò o wo, Ẹmi Mimọ, Ẹni Kẹta ninu Mẹtalọkan, wá n gbe inu ọkàn ọmọ eniyan. O si wọ inu ọkàn ẹni kọọkan wọn. Wọn o ti yọ to, wọn o si ti yin Oluwa logo to!

Ede Titun

Njẹ o mọ bi wọn ṣe mọ pe Ẹmi Mimọ bà lé wọn? O ti ẹnu ẹni kọọkan wọn sọrọ ni èdè ti wọn kò mọ. Ede ti wọn si n sọ wọnyi si yé awọn ara ilẹ miiran ti wọn n sọ ède wọnyi.

Gẹgẹ bi eyi ti jẹ akoko ajọ è̩sin, ọpọlọpọ awọn olufọkansin ni o wá lati orilẹ-ède àjèji gbogbo lati wá pa awọn ọjọ mimọ naa mọ. Nigba ti awọn wọnyi gbọ nipa ohun ti o n ṣẹlẹ laaarin awọn onirẹlẹ ọgọfa ọmọ-ẹyin Jesu, wọn lọ lati tẹti lelẹ. Bẹẹ ni olukuluku awọn eniyan si n gbọ ti ẹni kan n sọrọ ni ède ilẹ ti rè̩ -- wọn n sọ nipa iyanu iṣẹ Ọlọrun. Ẹmi Ọlọrun ni O n sọrọ lati ẹnu awọn Ju ti kò mọwé wọnyi, ti O si n lo ahọn wọn lati fi yin Ọlọrun ni ède ti awọn tikara wọn kò mọ. Ẹmi Ọlọrun n sọ fun wọn sii nipa Jesu, gẹgẹ bi Jesu ti ṣeleri pe yoo (Ẹmi Mimọ) ṣe. Kò ya wa lẹnu nigba naa pe ẹnu ya awọn alejo naa. A ha ti gbọ iru nnkan bẹẹ ri?

Asọtẹlẹ Joẹli

Bẹẹ ni, ni nnkan bi ẹgbẹrin (800) ọdun sẹyin ṣaaju ọjọ yii, Woli Joẹli ti sọtẹlẹ pe eyi yoo ṣẹlè̩; Peteru si fi igboya dide pẹlu awọn mọkanla o si wi fun ajọ nla awọn eniyan wọnni pé asọtẹlẹ Woli Joẹli ni a n mu ṣẹ yii. “Eyi li ọrọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá.” Wo iru idaniloju ati agbara nla ti o wà ninu ọrọ Peteru wọnni! Oun ni eyi; ileri Ọlọrun ni a muṣẹ.

Peteru fi han gbangba nipa ọrọ igboya ti o sọ, pe oun ti ri agbara gba lati ṣe ẹlẹri fun awọn wọnni ti wọn ti n ṣẹfẹ pe awọn ọmọ-ẹyin mu ọti-waini yó ni. Peteru ti sẹ Oluwa lẹẹkan ri niwaju ọmọdebinrin kan, nitori pe è̩ru ba a lati duro fun otitọ. S̩ugbọn nisisiyi, lẹyin ti Ẹmi Mimọ ti bà le e, kò si ohun ti o le da a duro lati sọ gbangba wi pe Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun; ati pe oun Peteru jẹ ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩.

O tako awọn Farisi fun pipa ti wọn pa Jesu. O sọ gbangba fun wọn lai bè̩ru pé, “On li ẹnyin mu, ti ẹ ti ọwọ awọn enia buburu kàn mọ agbelebu, ti ẹ si pa.” Eyi nì to lati mu wọn binu, ṣugbọn Peteru n fẹ ba wọn sọrọ si i nipa Kristi – “Ẹniti Ọlọrun gbé dide.” Wọn kò fẹ lati gbagbọ pe Jesu jinde, nitori pe nigba naa wọn ko le ṣai gbagbọ pẹlu pe Ọmọ Mimọ ti Ọlọrun ni Oun i ṣe.

Asọtẹlẹ Dafidi

Peteru sọ nipa asọtẹlẹ Dafidi, gẹgẹ bi Jesu ti n ti ẹnu Dafidi baba nla wọn sọrọ: “Iwọ ki yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-òkú, bḝni iwọ ki yio jẹ ki Ẹni Mimọ rẹ ki o ri idibàjé̩.” Awọn Ju wọnyi bọwọ fun Dafidi; o si yẹ ki wọn ti fi ọkàn si ọrọ rè̩ pẹlu, nitori pe o bọla fun Oluwa, o si sọ nipa ajinde Rè̩. Nisisiyi Dafidi ti ku o si ti rekọja, iboji rè̩ nikan ni o wà lọdọ wọn. S̩ugbọn Jesu tobi ju Dafidi to bẹẹ ti O fi jinde kuro ninu òkú ti O si fi iboji ofo silẹ.

Bi Dafidi ba ti sọtẹlẹ niwọn ẹgbè̩rún ọdụn ṣiwaju akoko yii, ti o si gba ajinde Jesu gbọ, ki ni ṣe ti awọn wọnyi kò le gbagbọ, awọn ti wọn fi oju ara wọn ri i? Jesu rin laaarin wọn fun ogoji ọjọ lẹyin ti O jinde kuro ninu okú. Gbogbo awọn ọgọfa wọnyi ni ẹlẹri si ajinde Rè̩.

Ọkàn Wọn Gbọgbẹ

Awọn eniyan wà laaarin awọn ti n gbọ ọrọ Peteru ti o gbagbọ pe otitọ ni ọrọ ti o n sọ. Ọkàn wọn bẹrẹ si i ba wọn wi fun kikọ ti wọn kọ Jesu silẹ, wọn si n fẹ mọ ohun ti wọn le ṣe ki wọn to le ri iru agbara ti Peteru ni gbà. Peteru sọ fun wọn pe, wọn ni lati kọ ronupiwada, ki a si gbà wọn là kuro ninu è̩ṣè̩. Ẹlẹsìn eniyan ni wọn i ṣe, ẹni ti n lọ si ile isin, ti wọn n san idamé̩waa wọn, ti wọn si ni itara pupọ. S̩ugbọn wọn kò i ti ronupiwada è̩ṣè̩ wọn.

Peteru sọ fun wọn pe bi wọn ba n fẹ iru agbara ti oun ni, wọn ni lati gbagbọ pe Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun ati pe lẹyin ti a ba gbà wọn là, a ni lati baptisi wọn ninu omi gẹgẹ bi Jesu ti palaṣẹ -- ni orukọ ti Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ -- ki i ṣe gẹgẹ bi wọn ti n ṣe té̩lẹ, ki i si i ṣe gẹgẹ bi baptisimu ti Johannu paapaa.

Agbara nipa Ifi-ara-rubọ

Awọn eniyan wà ni ayé isisiyi ti wọn n fẹ lati ni agbara Ọlọrun ninu ayé wọn ki wọn ba le ṣiṣẹ fun Oluwa, ṣugbọn wọn kò ṣetan lati jọwọ ohun ti Ọlọrun n fẹ ki wọn jọwọ silẹ. Peteru ni lati ṣe ọpọlọpọ ifi-ara-rubọ ki o to le ri agbara ti o ni yii gbà. Peteru ti fi igba kan gbẹkẹle agbara ti rè̩ o si ti ṣeleri lati bá Jesu lọ ani titi de oju ikú. O ti gbe ètò ti rè̩ kalè̩ o si ti n ṣe aṣaaju fun awọn Apọsteli. Oun a maa sọrọ akikanjú, o si ni in lọkàn ni tootọ lati té̩ Jesu lọrùn. S̩ugbọn ọpọ igbà ni o ti kùnà lati mu ifẹ inu rè̩ ṣẹ nitori pe kò ni agbara lati ṣe e. Yẹyẹ lásán ti a fi Peteru ṣe mú ki o sẹ Oluwa!

Nigba ti Peteru ri bi oun ti jẹ alailagbara to, o jade lọ, o si sọkún kikoro. Ninu adura ti o dapọ mọ ẹkún rè̩ yii, o pa gbogbo ipinnu ti rè̩ tì, o si beere fun iranlọwọ Ọlọrun. A dariji i, bẹẹ ni o si tun di Onigbagbọ. Lẹyin eyii, nigba ti Jesu fara han awọn mọkanla nigba ti wọn n pẹja, ti O si wi fun Peteru pe, “Iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi?” Peteru ni anfaani lati dahun pẹlu gbogbo ọkàn rè̩ wi pe kò si ohun ti o tun ṣe pataki fun oun bi iṣẹ isin Oluwa. Lẹẹmẹta ni Jesu beere titi Peteru kò fi mọ ohun ti oun i ba fi dahun mọ. O ti ṣe ifi-ara-rubọ de opin ẹmi rè̩, bẹẹ ni o si kigbe pe: “Oluwa, iwọ mọ ohun gbogbo” (Johannu 21:17). Bẹẹ ni, Jesu mọ ohun gbogbo, bẹẹ ni O si mọ ohun ti o wà ninu ọkàn wa pẹlu. O mọ bi a bá ti jọwọ ohun gbogbo silẹ tabi bẹẹ kọ.

Ronu iru agbara ti Peteru ri gba nigba ti a ti fi Ẹmi Mimọ wọ ọ. Nipasẹ iwaasu rè̩ ni ọjọ naa ẹgbẹẹdogun eniyan ni o yipada. Eyi pẹlu si jẹ ibẹrẹ nikan fun iṣẹ iranṣẹ rè̩ ti o kún fun Ẹmi Ọlọrun.

Agbara Naa ninu Wa

Bi a ba n fẹ agbara naa ti a n ri gbà nigba ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ wa, a ni lati ṣe iru ifi-ara-rubọ ti Peteru ṣe. A ni lati jọwọ ara wa, ọkàn wa, ati ẹmi wa patapata fun Jesu lati lo wọn bi O ba ti fẹ. Jesu wi pe a o gba agbara naa nigba ti Ẹmi Mimọ ba bà le wa. Bi a si ti n ṣe ifi-ara-rubọ sii ti a si n lo agbara ti O fun wa sii, ni a o maa ri gba sii.

Lẹyin igba ti a ba gba ọkàn eniyan là, ifi-ara-rubọ rè̩ yoo mu un lọ sinu iwa-mimọ. Ifi-ara-rubọ pẹlu igbagbọ ninu ileri Ọlọrun ni yoo mu ki a ri isọdimimọ gba. Eyi yii ni iwẹnumọ “tẹmpili Ẹmi Mimọ” “Ẹnyin kò mọ pe ara nyin ni tẹmpili Ẹmi Mimọ” (1Kọrinti 6:19). Ẹmi Mimọ ki yoo wá sinu tẹmpili alaimọ, nitori eyi, a ni lati sọ wa di mimọ ki a si wè̩ wa nù nipa iriri isọdimimọ. Nigba yii ni a to ni è̩tọ lati beere pe ki Ẹmi Mimọ wa sinu wa lati maa ba wa gbé.

Peteru wi pe, “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè.” Awa pẹlu wà ninu “awọn ti o jina rére.”

O ti to iwọn ẹgbàa ọdun ti awọn ọmọ-ẹyin gba Ẹmi Mimọ ni Ọjọ Pẹntekọsti, sibẹsibẹ awa pẹlu ni ode oni si n ri imuṣẹ ileri kan naa ninu ọkàn wa nigba ti a ba jẹ ipe Ọlọrun bi a bá si jọwọ ara wa patapata fun Un gẹgẹ bi ifẹ Rè̩. Bẹẹ ni a si n ri ami kan naa gba gẹgẹ bi ẹri pe Ẹmi Mimọ ti wọ inu ọkàn wa: eyi nì ni fifi ède titun sọrọ gẹgẹ bi Ẹmi Mimọ ba ti fún wa ni ohùn.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ni ọjọ wo ni Ẹmi Mimọ kọ sọkalẹ?
  2. Awọn wo ni wọn ri Ẹmi Mimọ gbà ni ọjọ naa?
  3. S̩e àpèjúwe iyipada ti o ṣẹlẹ ninu Peteru nigba ti o gba Ẹmi Mimọ.
  4. Ta ni ẹni ti o ti sọté̩lè̩ nipa Ẹmi Mimọ ni iwọn bi ẹgbẹrin ọdún ṣaaju?
  5. Ọjọ mélòó lẹyin ọjọ Ajọ Irekọja ni Ọjọ Pẹntekọsti?
  6. Bawo ni awọn eniyan ṣe mọ pe Ẹmi Mimọ ti bà le wọn?
  7. Ki ni awọn alejo ti o wà ni Jerusalẹmu rò nipa ohun ti o ṣẹlẹ yii?
  8. Ki ni Peteru sọ fun awọn eniyan wọnyi pe wọn ni lati ṣe ki wọn to le ri agbara yii gbà?
  9. Awọn ta ni a ṣeleri Ẹmi Mimọ fun?
  10. Amì wo ni a n ri gbà nigba ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ wa?