Iṣe Awọn Apọsteli 3:1-26

Lesson 282 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o ba gbà mi gbọ, iṣé̩ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣé̩ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba” (Johannu 14:12).
Notes

Igbesi-aye Titun

Igbesi-aye titun ti bẹrẹ fun awọn Apọsteli Jesu. Ẹmi Mimọ ti bà le wọn ni Ọjọ Pẹntekọsti, nisisiyi wọn kún fun agbara lati jade lọ lati maa ṣe iṣẹ iyanu ni orukọ Jesu. Dipo ti wọn i ba fi maa bẹru, wọn le duro pẹlu igboya fun gbogbo otitọ ti Jesu ti kọ wọn.

Lẹyin adura ọjọ mẹwaa ninu eyi ti a fi Ẹmi Mimọ baptisi wọn, ni Peteru ati Johannu lọ si Tẹmpili lati lọ gbadura. Wọn si mọ pe wọn ni lati maa gbadura. Wọn ni lati maa gbadura si i bi wọn ba n fẹ ki agbara naa ti Ọlọrun fi fun wọn wà ninu aye wọn sibẹ.

Ọkunrin ti o wà ni Ẹnu-ọna

Nigba ti Peteru ati Johannu sun mọ itosi ẹnu-ọna Tẹmpili, wọn ri ọkunrin arọ kan nibẹ ti o n ṣagbe. Kò si ẹni ti o le ṣe itọju ọkunrin arúgbó alaini yii, nitori naa o joko lẹba ẹnu-ọna, ni ireti pe awọn ti wọn wa jọsin ninu Tẹmpili yoo ṣaanu fun oun, wọn o si fun oun ni owo diẹ lati fi jẹun.

Peteru ati Johannu ṣe oninuure, ṣugbọn wọn kò ni owó. Ki ni wọn le ṣe fun ọkunrin alaini yii? Peteru wo o pẹlu ikaanu o si wi pe: “Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mā rin” (Iṣe Awọn Apọsteli 3:6).

Peteru sọrọ pẹlu idaniloju. O mọ pe Ọlọrun yoo dáhun adura oun. O mọ pe bi oun ba beere ni orukọ Jesu, iṣẹ iyanu naa yoo ṣe.

Iṣẹ ti o Tobi Ju Wọnyi Lọ

Jesu wi pe: “Ẹniti o ba gbà mi gbọ, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba” (Johannu 14:12). Nigba ti Jesu lọ sọdọ Baba, O ran Ẹmi Mimọ; nipa agbara Ẹmi Mimọ si ni awọn ọmọ-ẹyin yoo le ṣe iṣẹ iyanu ni orukọ Jesu.

Nisisiyi Peteru ni Ẹmi Mimọ, o si ti ṣe ifi-ara-rubọ to bẹẹ fun iṣẹ Oluwa ti o fi le wi fun ọkunrin arọ naa pé, “Dide ki o si mā rin.” Wò o bi eyi ti jẹ ohun abami to lati sọ fun ọkunrin ti kò i ti rin ri ni gbogbo ọjọ aye rè̩! Bọya ọkunrin yii kò tilẹ mọ itumọ ọrọ yii. Peteru di ọwọ ọkunrin arọ naa mú, o si gbe e dide. Ni ojukan naa ẹsẹ rè̩ ati egungun kokosẹ rè̩ si mokun, o si n rin – ki i ṣe pe o tun n rin bi ẹni ti o ni abuku kan rárá ṣugbọn o n rin kiakia ati pẹlu ara dida ṣáṣá. O si fo soke pẹlu.

Inu arọ naa dun to bẹẹ lati ri iwòsàn gba ti o fi wọ inu Tẹmpili lọ taara pẹlu Peteru ati Johannu lati lọ dupẹ lọwọ Ọlọrun. O mọ Ẹni ti o wò oun san, ọkàn rè̩ si kún fun ọpẹ lọpọlọpọ si Baba Ọrun, Ẹni ti o gbọ adura awọn oloootọ iranṣẹ Rè̩ meji.

Ni Orukọ Jesu

Idi kan ti Ọlọrun fi mú ọkunrin arọ nì laradá ni pe Peteru ati Johannu beere ni orukọ Jesu. Jesu ti sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe: “Ohunkohun ti ẹnyin ba si bère li orukọ mi, on na li emi ó ṣe, ki a le yìn Baba logo ninu Ọmọ” (Johannu 14:13).

Awọn Farisi kò fẹ gbàgbọ pe Jesu jẹ Ọmọ Ọlọrun. S̩ugbọn nipasẹ iṣé̩ iyanu ti awọn ọmọ-ẹyin ṣe ni orukọ Jesu, a yin In logo gẹgẹ bi Ẹni ti o yẹ lati maa sin. Bi wọn ba ti gbadura ni orukọ ara wọn – bi i pe ni orukọ Johannu, tabi ti Peteru, tabi ni orukọ Maria paapaa ti i ṣe iya Jesu -- Ọlọrun ki yoo gbọ adura wọn. Eniyan bi ti wa bayii naa ni wọn i ṣe. Ohun kan naa ti wọn fi yatọ ni pe wọn ti jọwọ aye wọn silẹ ni ifi-ara-rubọ kikún fun iṣẹ-isin Ọlọrun to bẹẹ ti wọn fi ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo mu ọkunrin arọ nì larada, ki o si maa rin nigba ti wọn ba gbadura ni orukọ Jesu.

Peteru ati Johannu ki i ṣe abami eniyan. Bẹẹ ni Elijah, ẹni ti o ṣe ohun ti eniyan kan kò le ṣe ninu agbara rè̩, ki i ṣe abami eniyan. Jakọbu wi pe: “Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ, ojo kò si rọ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa. O si tún gbadura, ọrun si tún rọjo, ilẹ si so eso rè̩ jade” (Jakọbu 5:17, 18).

Ronu ohun ti a le ṣe ni orukọ Jesu bi a bá le fi itara gbadura bi awọn eniyan wọnyi ti ṣe! Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe: “Ja gidigidi fun igbagbọ, ti a ti fi lé awọn enia mimọ lọwọ lẹkanṣoṣo” (Juda 3). A le ri i nigba naa pe Oluwa n fẹ ki a jijakadi fun iru agbara bẹẹ.

Ki ni ohun ti o ṣe pataki fun wa lonii? A ha ni ifẹ lati ni agbara Ọlọrun ninu aye wa ju lati maa kó ohun ini jọ fun ara wa? Ki ni ohun naa ti o n gba eyi ti o pọ ju lọ ninu akoko wa – i ha i ṣe ero bi a o ti ṣe le ni agbara Ọlọrun si i ninu aye wa, tabi ero nipa bi a o ti ṣe pọn ara wa le loju awọn ẹlomiiran? Iṣẹ ti Ọga wa ha leke ninu ọkàn wa ju iṣẹ ti wa lọ?

Idunnu ti o wà ninu Agbara

O ha ro pe ọkunrin ti a mu lara da bikita boya Peteru ati Johannu ni owó tabi pe wọn ko ni? O ti ri nnkan ti o tobi ju ohun ti owo le rà gba. Njẹ o rò pe Peteru ati Johannu n ronu nipa aini wọn? Ohun ayọ nla ti o wà ninu ayé wọn ni lati mọ pe awọn n ṣe ifẹ Ọlọrun.

Wò o bi iyalẹnu awọn eniyan naa ti pọ to bi wọn ti n sare bọ lati wa wo ohun ti o ṣẹlẹ! Ẹgbẹẹgbè̩run eniyan ni wọn kora jọ pọ ti wọn si n wo Peteru ati Johannu pẹlu iyanu. Iru awọn ọkunrin wo ni wọnyi ti o le mu ki arọ rin? Eyi tun jẹ anfaani miiran fun awọn Apọsteli lati waasu nipa Jesu.

Peteru kò tun bè̩ru awọn eniyan mọ. O dahun ibeere wọn bayii pe, “Ẽṣe ti hà fi nṣe nyin si eyi? Tabi ẽṣe ti ẹnyin fi tẹjumọ wa, bi ẹnipe agbara tabi iwa-mimọ wa li awa fi ṣe ti ọkunrin yi fi nrin?” Bi awọn eniyan Israẹli wọnyi ba gba Ọlọrun gbọ bi wọn ti n sọ ọ pe awọn gbagbọ, i ba ti ye wọn pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe ati pe ni orukọ Jesu ni a ṣe iṣẹ-iyanu yii.

A Sẹ Jesu

Wò o bi Peteru ti tako awọn eniyan wọnyi ni ojukoju! “Ẹnyin sé̩ Ẹni-Mimọ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun yin: ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ iye.” Njẹ ohun buburu nla nla ha kọ ni awọn ẹlẹsìn wọnyi ṣe?

S̩ugbọn gbogbo ọrọ Peteru kọ ni è̩sùn. Ni tootọ ni awọn eniyan wọnyi kan Jesu mọ igi, ṣugbọn wọn ṣe e ninu aimọkan ni. Ọpọlọpọ ninu awọn Farisi ati awọn akọwe ni kò mọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe. Peteru tun sọ fun wọn pe ireti ṣi wà bi wọn ba le ronupiwada.

Jesu ti lọ si Ọrun, wọn kò si le yi ohun ti wọn ti ṣe si I pada; ṣugbọn O tun n pada bọ, wọn si tun ni anfaani miiran lati mura silẹ de E. Awọn sa ni ayanfé̩; awọn ni ọmọ Abrahamu ẹni ti Ọlọrun ba da majẹmu pe, “Ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye.” Ọlọrun si n fẹ lati lo wọn lati kọ awọn ẹlomiiran nipa ọna igbala.

Ọrọ Awọn Woli

Ni wiwaasu nipa Kristi, Peteru ko kọ awọn eniyan naa ni ẹkọ titun. O ran wọn leti ohun ti awọn woli ti kọ silẹ ni ọpọlọpọ ọdun ti o ti kọja. Awọn eniyan wọnyi mọ ọrọ awọn woli. Ki ni ṣe ti wọn kò mọ pe Jesu ni awọn asọtẹlẹ wọnni n tọka si.

Mose ti wi pe: “Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé woli kan dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ẹnyin o ma gbọ tirè̩ li ohun gbogbo ti yio ma sọ fun nyin.” Awọn eniyan naa i ba ti ṣọra lati fi eti si ọrọ wọnyi, nitori pe ikilọ kan jade pẹlu ọrọ wọnyi: “Yio si ṣe, olukuluku ọkàn ti kò ba gbọ ti woli na, on li a o parun patapata kuro ninu awọn enia” (Iṣe Awọn Apọsteli 3:22, 23). Jesu ni Woli naa, bi wọn kò ba si gba A gbọ, a o pa wọn run.

Samuẹli, ati awọn woli iyoku pẹlu, ni wọn ti sọtẹlẹ nipa Jesu. Olukuluku awọn woli ti wọn ti sọrọ ni o sọ nipa wiwa Jesu, ni ọna ti o yé ni gbangba tabi ni ọna miiran. Wọn ti sọtẹlẹ pe wundia kan ni yoo bi I, ni Bẹtlẹhẹmu, lati inu ẹya Judah, ati pe ọba kan yoo gbiyanju lati pa A nigba ti O wà ni ọmọ-ọwọ; nigba ti O ba si dàgbà, awọn eniyan Rè̩ yoo dide si I, wọn o kan An mọ agbelebu, ati pe yoo jinde. Gbogbo nnkan wọnyi ni o si ti ṣẹlẹ gegẹ bi ati kọ wọn sinu Iwe awọn woli.

Idi rè̩ ti awọn Ju wọnyi kò fi le gbagbọ ni pe è̩ṣè̩ wà ninu ọkàn wọn; ṣugbọn Peteru n mu ki o ye wọn pe anfaani kan wà fun wọn sibẹ. Wọn ni lati ronupiwada, ki wọn banujẹ fun è̩ṣẹ wọn, ki wọn si yipada kuro ninu wọn, nigba naa wọn o ni igbagbọ. Rò bi aanu Ọlọrun ti tó lori awọn ẹlé̩ṣè̩ wọnyi! Awọn ni wọn kàn Jesu mọ agbelebu, sibẹ awọn ni a kọ rán Kristi ti O jinde si lati fun wọn ni anfaani kan si i.

Awọn diẹ gbagbọ, ṣugbọn ọpọlọpọ ni kò gbagbọ. Nitori aigbagbọ wọn, awọn jagunjagun alagbara lati Romu dó tì wọn, lẹyin ọdun marundinlogoji, a si pa ilu Jerusalẹmu run. Lati igba naa titi di akoko ti a wà yii ni a ti n ṣe inunibini si awọn Ju ti a si n ṣé̩ wọn ni ìṣẹ iru eyi ti a kò le fi ẹnu sọ tan, nitori pe wọn kọ Kristi ti O wá lati fi ohun ribiribi fun wọn.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni Peteru ati Johannu n lọ nigba ti wọn ri ọkunrin arọ nì?
  2. Ki ni Peteru sọ fun ọkunrin naa?
  3. Ki ni ṣẹlẹ nigba ti Peteru di ọwọ ọkunrin naa mu?
  4. Nipa agbara wo ni Peteru ṣiṣẹ iyanu yii? Ni orukọ ta ni?
  5. Lori ki ni Peteru fi è̩sùn kan awọn Ju?
  6. Iru anfaani wo ni Peteru fun wọn?
  7. Ki ni awọn Ju le ṣe ti o le jẹ iranwọ fun wọn lati gba Jesu gbọ?
  8. Njẹ iṣẹ-iyanu n ṣẹlẹ sibẹ ni aye isisiyi bi?