Iṣe Awọn Apọsteli 4:1-31

Lesson 283 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobḝ niwaju enia, ki nwọn ki o le mā ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yin Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo” (Matteu 5:16).
Notes

Ninu Iloro Sọlomọni

Bọya diẹ ninu awọn Ju ti wọn n lọ sinu Tẹmpili ni wakati adura ni o n fiyesi ọkunrin arọ ati alaini nì, ẹni ti o n joko lẹba Ẹnu-ọna Daradara fun ogoji ọdun sẹyin. Ojoojumọ ni a ti n gbe e wá sibẹ, ki o ba le ri owó diẹ gbà lọwọ awọn ti n wọle.

S̩ugbọn ọjọ yi yatọ -- kò tun ni ṣagbe mọ; kò tun ni joko mọ si ẹba ilẹkun alasopọ meji nì, eyi ti a fi idẹ didan ti awọn ara Kọrinti ṣe, ti o niye lori ju wura lọ. Gbogbo oju wà lara rè̩ bi o ti n rin laaarin iloro Tẹmpili.

Nibẹ ni o duro pẹlu Peteru ati Johannu. Oju rè̩ n dan bi o ti n tẹtilelẹ gbọ iwaasu Peteru. Wahala n bọ lai si aniani. Niwọn igba ti arọ nì wà ni ipo ailerin, kò si ẹni kan ti o bikita, ṣugbọn nisisiyi nigba ti a mu un lara da, ọpọ kó ara wọn jọ pọ ni iyanu. Peteru n wi pe nipa igbagbọ ninu Jesu, Ẹni ti Ọlọrun ji dide kuro ninu oku, ni a mu ọkunrin arọ yii lara dá ti o si lagbara. S̩ugbọn awọn kan laaarin awọn Ju kò gba ajinde gbọ, nitori eyi wahala dé. S̩ugbọn ni suuru naa, olori Tẹmpili ni o n bọ yii, ọlọpa ti yoo fi ohun gbogbo seto. O mu Peteru ati Johannu lọ, o si fi wọn sinu tubu ni alẹ ọjọ naa. Ohun gbogbo tun dakẹ rọrọ lẹẹkan sii ninu Tẹmpili.

Igba mélòó ni a ti maa n ri i pe ni akoko ti alaisan kan ba n jẹ irora, kò si ẹni ti o dabi ẹni pe o bikita. Tabi nigba ti ẹlẹṣẹ ba n gbe igbesi-aye è̩ṣẹ, ẹnikẹni ki i ṣaniyan tabi ki wọn kiyesi i. S̩ugbọn nigba ti agbara Ọlọrun ba wo ẹni ti n ṣíṣẹ kan san, tabi O gba ọkàn kan la, eṣu a dide, awọn ti o si yẹ ni ẹni ti i ba ni inudidun si i jù, awọn gan an ni yoo binu si i.

Niwaju Olori Alufaa

Ni akoko iṣẹ iranṣẹ Jesu ninu aye, nigba ti awọn eniyan n ri iṣẹ-iyanu ti O n ṣe, awọn kan laaarin awọn Ju dimọ pọ pe afi bi a ba da a duro ninu iṣẹ yii, bi bẹẹ kọ gbogbo eniyan ni yoo gba A gbọ. Wọn lọ sọdọ Kaiafa, ẹni ti o sọ fun wọn pe Jesu ni lati kú ni ọjọ kan fun awọn eniyan lati mu iye ainipẹkun wá fun gbogbo eniyan (Johannu 11:49-52). O n sọtẹlẹ nipa ikú ati ajinde Jesu.

Iwaju olori alufaa yii kan naa, Kaiafa, ni a tun mu Peteru ati Johannu wá ni ọjọ keji ti a wo ọkunrin arọ nì san. “Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi?” ni ibeere ti wọn beere lọwọ wọn. Anfaani miiran tun ni eyi fun Peteru lati sọrọ nipa Jesu. Ẹ má ṣe jẹ ki a gbàgbé pe Peteru jẹ ẹni ti o ti ri Agbara Ẹmi Mimọ gbà ni iyàrá òkè ni Ọjọ Pẹntekọsti. Idi rè̩ niyii ti o ṣe le fi iru igboya bẹẹ sọrọ bayii pe: “Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rè̩ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa ... nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là” (Iṣe Awọn Apọsteli 4:10-12).

Awọn Ẹlẹri fun Jesu

Ẹnu ya awọn alufaa ati awọn olóyè si igboya Peteru ati Johannu. Wọn mọ pe awọn apẹja meji wọnyi kò lọ si ile-è̩kọ bi awọn ti lọ. Bawo ni awọn ope eniyan ṣe le sọrọ bi awọn wọnyi ti ṣe? Ọkunrin nì ti a si ti mú lara da si wà niwaju wọn nibẹ pẹlu. Idahun kan ṣoṣo ni o wà: awọn ọkunrin wọnyi ti bá Jesu gbé. Ni ti iṣẹ-iyanu ti a ti ṣe lara ọkunrin arọ nì, wọn wi pe, “Awa kò si le sé̩ ẹ.”

Awọn alufaa gbagbọ pe a ni lati dá iru iwaasu bayii duro. A ni lati sọ fun Peteru ati Johannu ki wọn má tun sọrọ fun ẹnikẹni ni orukọ Jesu mọ. Peteru ati Johannu kò le fara mọ iru aṣẹ bẹẹ. Wọn wi pe: “Bi o ba tọ li oju Ọlọrun lati gbọ ti nyin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a rò. Awa kò sá le ṣaima sọ ohun ti awa ti ri, ti a si ti gbọ.” Jesu ti fi imọlẹ kan fun wọn, “nwọn kò si lè fi si abè̩ oṣuwọn.”

Iyin si Ọlọrun

Iwaasu Peteru kún fun agbara Ọlọrun to bẹẹ gẹẹ ti o fi lé ni ẹgbè̩ẹdọgbọn (5,000) eniyan ti o gbagbọ. Wọn yin Ọlọrun logo fun iṣẹ-iyanu ti wọn ti ri. A ha le pa iṣẹ iyanu yii mọlẹ? A ha le sé̩ ẹ? Njẹ awọn olori ati awọn alufaa ha le dá igbe iyin naa duro bi? Rara, kò ṣe e ṣe!

Njẹ loni ẹnu wa ha le pamọ lati fi iyin fun Ọlọrun nigba ti ẹlẹṣẹ kan ba ronupiwada è̩ṣẹ rè̩ ti o si ri ayọ igbala? A ha le pa ẹnu wa mọ nigba ti ibùkún Ọlọrun ba n sọkalẹ nibi pẹpẹ adura? Nigba ti Ọlọrun ba tu ibukun ati Ẹmi Rè̩ jade sinu awọn ọkàn ti ebi n pa, tabi nigba ti alaisan kan ba ri iwosan, o ha yẹ ki a tẹ iyin ti o n ru soke si Ọlọrun ninu ọkàn wa mọlẹ bi? A kò gbọdọ ṣe bẹẹ, nitori bi a ba pa ẹnu wa mọ, o dàbi ẹni pe okuta yoo kigbe soke.

Igbimọ kan ni Jerusalẹmu tabi agbajọ awọn eniyan kan kò le pa Ihinrere ré̩ ni ọjọ wọnni nigba ti Ijọ ṣẹṣẹ bẹrẹ si ṣiṣẹ. A kò le pa a lẹnu mọ lonii pẹlu. O ti tàn ká gbogbo aye: awọn alaisan n ri iwosan, bẹẹ ni awọn ẹlẹṣẹ n ri idande kuro ninu è̩ṣẹ. Agbara Ọlọrun si wà ninu aye lonii: “Nipa igbagbọ ninu orukọ rè̩” awọn alaisan n ri iwosan. “Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.”

Wò o bi ipade adura awọn Onigbagbọ yoo ti ri ni ọjọ naa nigba ti a dá Peteru ati Johannu silẹ kuro lọwọ awọn igbimọ! A gbagbọ pe ọkunrin nì lati ẹba Ẹnu-Ọna Daradara yoo pẹlu wọn ninu ipade adura naa. Agbara Ẹmi Mimọ sọkalẹ, ibi ti wọn pejọ si mi tìtì. Kò si ifasẹyin kan ninu ọkàn awọn eniyan Ọlọrun wọnyi; kaka bẹẹ wọn jade lọ wọn si n fi igboya waasu Ọrọ Ọlọrun.

Lai si Ibẹru

Ẹ jẹ ki a pinnu ninu ọkàn wa pe a ki yoo bẹru lati sọ nipa Jesu. Bi anfaani kan ba ṣi silẹ fun wa lati sọ ọrọ kan fun Un, a kò gbọdọ tiju lati sọ ohun nla ti O ṣe fun wa pẹlu igboya.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ewo ninu iwaasu Peteru, ni diẹ ninu awọn eniyan naa kọ pe awọn kò fara mọ?
  2. Njẹ a ri awọn ti o gbagbọ? Mélòó ni wọn?
  3. Njẹ o rò pe Peteru ati Johannu jẹ ọmọwé?
  4. Ta ni a n pe ni okuta pataki igun ile?
  5. Ki ni ṣe ti awọn olori ati awọn agbagba kò le sé̩ iṣẹ-iyanu ti wọn ti ri?
  6. Ki ni idahun Peteru ati Johannu fun igbimọ nigba ti a sọ fun wọn pe ki wọn má ṣe tun sọrọ nipa Jesu mọ?
  7. Ki ni ṣẹlẹ nigba ti awọn eniyan naa gbadura?
  8. Njẹ o ha yẹ fun eniyan lati tiju pe ki a mọ oun ni Onigbagbọ?