Iṣe Awọn Apọsteli 4:32-37; 5:1-16

Lesson 284 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ati ẹniti o si nṣeke kì yio mu u jẹ” (Owe 19:5).
Notes

Iṣọkan

Lẹyin ti a dá wọn silẹ lati inu tubu, awọn Apọsteli tẹsiwaju ni wiwaasu Ihinrere. Wọn n sọrọ pẹlu igboya ti a fi fun wọn nigba ti a fi Ẹmi Mimọ kún wọn bi wọn ti n gbadura. Wọn n waasu nipa Jesu ati ajinde Rè̩. Wọn n sọrọ pẹlu agbara nla gẹgẹ bi wọn ti n jẹri ti wọn si n fi ododo hàn. Jesu ti ṣeleri wi pe wọn o gba agbara wọn o si ṣe ẹlẹri fun Oun nigba ti wọn ba gba Ẹmi Mimọ (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8).

Ọpọlọpọ ni awọn ti o gbagbọ. Ni ọjọ kan bi Peteru ti n waasu, ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan gbagbọ a si baptisi wọn (Iṣe Awọn Apọsteli 2:41). Ni igba miiran, laaarin awọn ti wọn gbọ ọrọ Ihinrere ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan ni wọn gbagbọ (Iṣe Awọn Apọsteli 4:4). Ifẹ ati iṣọkan so awọn Onigbagbọ wọnyi pọ, nitori pe Jesu ti wi fun wọn pe ki wọn fẹran ara wọn (Johannu 15:12). O ti gbadura fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe ki gbogbo wọn jẹ ọkan (Johannu 17:21, 22). Wọn wà ni ọkàn kan ati inu kan, gẹgẹ bi Paulu ti kọ ọ silẹ pe awọn ọmọ-ẹyin Jesu ni lati wà (Romu 15:6; Filippi 1:27; 2Kọrinti 13:11).

Wọn Ta Ohun-ini Wọn

Bi o tilẹ jẹ pe kò si idaniloju ẹri kan pe a sọ fun wọn lati ṣe bẹẹ, awọn ọmọ-ẹyin Jesu ta ohun ti wọn ni, wọn si fi owó naa fun awọn Apọsteli. Pẹlu ifẹ inu ọkàn wọn ni wọn yọọda lati ṣe eyi – a kò sọ tabi fi ipa mu ẹnikẹni lati ṣe bẹẹ. O dàbi ẹni pe ohun ti o tobi pupọ ninu ọkàn awọn ti o gbagbọ wọnyi ni lati ni ohun-ini ti ẹmi. Iṣura ni Ọrun (Matteu 6:19-21) ni o dàbi ẹni pe o ṣọwọn fun wọn ju ohunkohun lọ.

A kò kó owó naa jọ ki a si fi pamọ ni ìkọkọ. Awọn Apọsteli lawọ wọn si ṣe ipinfunni fun awọn alaini. Ẹmi Ihinrere tootọ ni lati ràn awọn ẹlomiran lọwọ, nitori Bibeli wi pe, “Ọlọrun fẹ oninu-didun ọlọrẹ” (2Kọrinti 9:7). Ki i ṣe pe Ọlọrun maa n beere lọwọ eniyan pe ki o tà ohun-ini rè̩ ki o to le di Onigbagbọ. S̩ugbọn bi o ba ṣe pe eniyan fẹran ohun-ini rè̩ de ipo ti o jẹ pe o di ohun idiwọ fun un lati le sin Ọlọrun, yoo gba pe ki ẹni naa ta wọn. Akọsilẹ kan wà ninu Bibeli nipa ọdọmọkunrin ọlọrọ kan ẹni ti ohun-ini rè̩ duro gẹgẹ bi idena laaarin oun ati Ọlọrun. O beere lọwọ Jesu nipa ohun rere ti oun le ṣe lati jogun iye-ainipẹkun (Matteu 19:16). O ti gbe igbesi-aye ti o dara, o fẹran awọn aladugbo rè̩, o si pa ninu awọn ofin mọ pẹlu. O wa beere, “Kili o kù mi kù?” Ọdọmọkunrin yii ni ọrọ pupọ, o si fẹran wọn ju bi o ti fẹ Ọlọrun lọ. Jesu wi fun un pe yoo ni ọrọ ni Ọrun bi o ba le tà awọn ohun-ini rè̩ ki o si fi wọn fun awọn talaka. Ọdọmọkunrin yii lọrọ lọpọlọpọ, o si fẹ ọrọ rè̩ bi ẹmi rè̩. O lọ kuro ni ibanujẹ. Ohun-ini rè̩ di i lọwọ lati sin Ọlọrun (Marku 10:22).

Ohun-ini ti Ẹmi

Ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu kò ni ohun-ini ayé ti o pọ, ṣugbọn eyi ti wọn ni ni wọn jọwọ fun Oluwa ni ifi-ara-rubọ fun iṣẹ-isin Rè̩. Wọn ni ohun-ini ti ẹmi pẹlu eyi ti wọn le fi jẹ ibukun fun awọn ẹlomiran. Ni ọjọ kan Peteru ati Johannu ṣe iranlọwọ fun ọkunrin arọ kan. Peteru wi pe, “Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu ti Nasareti, dide ki o si mā rin.” Mimu ti a mu ọkunrin arọ yii lara dá, ti ki yoo tun jẹ arọ mọ tobi fun un jù pe ki a fun un ni owo lọ. Awa pẹlu le gbadura, ki a sọ ọrọ ẹri wa, ki a si sọrọ iwuri fun awọn ti wọn wà ni ipò aini nipa ti ẹmi. Ninu Isaiah 41:6 a kà pe, “Olukulùku ràn aladugbo rè̩ lọwọ; o si wi fun arakunrin rè̩ pe, Ẹ mu ara le.”

Barnaba

Laaarin awọn ti wọn tà ohun-ini wọn ti wọn si mú owo naa wá fun awọn Apọsteli ni ẹni kan ti a darukọ rè̩ ni pataki. Oun ni ọkunrin ti orukọ rè̩ n jẹ Jose ṣugbọn ti awọn Apọsteli pe ni Barnaba. Ni ọjọ iwaju Oluwa lo ọkunrin yii ni ọna ti o tobi jọjọ. Kò jẹ ki ohunkohun di oun lọwọ lati sin Oluwa. O fi ara rè̩ ati talẹnti rè̩, ati ohun-ini rè̩ pẹlu fun Ọlọrun. Barnaba ba Paulu dọrẹ, o si ṣe iranlọwọ fun un nigba ti Paulu ṣẹṣẹ ni iyipada ọkàn (Iṣe Awọn Apọsteli 9:26, 27). Lẹyin eyii a ran Barnaba lọ si Antioku lati lọ mu awọn eniyan naa ni ọkàn le, nitori pe “on jẹ enia rere, o si kún fun Ẹmi Mimọ, ati fun igbagbọ: enia pupọ li a si kà kún Oluwa” (Iṣe Awọn Apọsteli 11:24). Barnaba ba Paulu lọ ni irin-ajo rè̩ kin-in-ni fun Ihinrere, lẹyin eyi, oun pẹlu Marku lọ si Kipru (Iṣe Awọn Apọsteli 15:39). Nipa bẹẹ Barnaba ri ọpọlọpọ ibukun gba, oun pẹlu si tun jẹ ibukun fun ọpọlọpọ eniyan.

Anania

Ọkunrin kan ati iyawo rè̩ tà ohun-ini wọn pẹlu, ṣugbọn wọn fi ninu owó naa pamọ. Nigba ti Anania fi diẹ ninu owó naa fun awọn Apọsteli, o ṣe bi ẹni pe gbogbo rè̩ ni oun mu wá. Bọya Anania kò tilẹ sọ ohunkohun. O fi ara han bi oninuure ati olufọkansin ṣugbọn è̩tan wà ni ọkàn rè̩. Lai si aniani o n fẹ iyin eniyan. O si n fẹ owo naa pẹlu. Anania kò le gbẹkẹle Ọlọrun lati ṣe itọju rè̩ bi o ba fi gbogbo ohun ti o ni fun Oluwa. Anania dabi ẹni ti o n fẹ lati sin Ọlọrun pẹlu mammoni papọ (Matteu 6:24).

Ẹtan

Ọlọrun fi han Peteru pe Anania kò ṣe otitọ. Ọlọrun a maa wo ọkàn O si mọ iru ipinnu ti o wà ninu rè̩. Eniyan kò le tan Ọlọrun. Bi ẹni kan ba si fẹ tàn eniyan, Ọlọrun a maa fi han fun awọn iranṣẹ Rè̩ tabi awọn olukọni, tabi awọn obi rè̩.

Peteru mọ pe Satani ti fi idanwo naa si ọkàn Anania, Anania si ti jọwọ ara rè̩ fun idanwo naa. Bi a ba dan ọ wo nigbakuugba lati ṣe eyi ti kò tọ, mọ pe Satani ni o mu amọran naa wá ti o si n fẹ lati fi i si ọ lọkàn.

Peteru rán Anania leti pe ki i ṣe pe a paṣẹ fun un tabi fi ipa mu un lati tà ohun ini rè̩ ki o si fi owó rè̩ fun awọn Apọsteli. Anania ṣe eyi lati inu ọkàn rè̩ wá. Lẹyin ti o tà a paapaa, a kò beere pe ki Anania mu owo naa wa fun awọn Apọsteli. Ki i ṣe è̩ṣẹ fun Anania lati mú apa kan ninu owó naa wá. Anania ṣè̩ nigba ti o n gbiyanju lati tan awọn Apọsteli jẹ. O n fẹ fi è̩tan ṣe bi ẹni pe oloootọ ni oun nigba ti ki i ṣe bẹẹ. Iṣe rè̩ fi han pe o fẹ owo ati pe ko gbẹkẹle Ọlọrun ati awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Peteru wi fun Anania pe, “Enia ki iwọ ṣeke si bikoṣe si Ọlọrun.”

Idajọ

Anania le ti ni ireti pe a o yin oun, a o si kan saara si oun pe oun ṣe ohun ti o dabi ẹni pe o dara. Bọya o tilẹ ti pinnu ohun ti yoo sọ bi wọn ba bi oun leere ohun kan. Nigba ti akoko naa tó, kò lè fọhun. Idajọ yara sọkalẹ kánkán si ori ọkunrin yii ti o ti pinnu lati ṣe ibi. Idajọ naa bani lẹru -- ṣugbọn bakan naa ni è̩ṣẹ yii. Ninu ipinnu Anania lati ré̩ Ọlọrun jẹ, o fi oju tinrin agbara Ọlọrun. Kò ṣe e ṣe fun eniyan lati purọ fun awọn iranṣẹ Ọlọrun lai jẹ pe Ọlọrun gan an ni eniyan naa ṣe e si. Eyi ni lati jẹ ikilọ fun awọn ẹlomiran lati maa fi otitọ ba Ọlọrun ati awọn eniyan Rè̩ lò.

Nigba ti Anania gbọ ọrọ Peteru, o ṣubu lulẹ, o si kú, lai ni anfaani ironupiwada. Lai sọ ohunkohun fun iyawo rè̩, a di okú Anania a si gbe e jade lati lọ sin, gẹgẹ bi iṣe wọn nibẹ lati sin okú lẹsẹkẹsẹ ti o ba kú.

Safira

Wakati mẹta lẹyin eyi, Safira, iyawo Anania lọ sọdọ awọn Apọsteli. Oun pẹlu ọkọ rè̩ ti gbimọ pọ lati purọ lori owó ti wọn mu wá yii. Wọn ti fohun ṣọkan ni ìkọkọ lati fi apa kan ninu owo yii silẹ ati lati wi pe gbogbo rè̩ ni wọn fi lelẹ.

Bọya Safira pẹlu ti n reti iyin ati ọla; ṣugbọn nigba ti Peteru bi i leere o fi ara rè̩ hàn pe oun pẹlu lọwọ ninu è̩ṣè̩ ati iwa abuku Anania -- kò sọ otitọ nipa owo naa. Kò ṣe awáwí bẹẹ ni a kò si fun un ni ayè lati ronupiwada. A sọ idajọ rè̩ fun un, bẹẹ ni ikú dé kánkán. Nigba ti Peteru sọ fun un ohun ti o ṣẹlẹ si Anania ati pe oun paapaa yoo kú, o ṣubu lulẹ ni ẹsẹ rè̩ o si kú. Nigba ti awọn ọkunrin ni pada de lati ibi isinku Anania, okú iyawo rè̩ pẹlu ti wà nilẹ lati sin si ẹgbẹ rè̩.

Ikú Ojiji

Igba miiran ti wà bẹẹ ti awọn eniyan ṣe alainaani ofin Ọlọrun ti wọn si rú u, ti idajọ Oluwa si ti yara sọkalẹ lojiji, ti o si ké wọn kuro. A ti kà nipa iṣọtẹ Kora ni akoko awọn Ọmọ Israẹli (Ẹkọ 105). Kora ati awọn ti o fara mọ ọn, ati awọn ti o dẹṣẹ pẹlu rè̩, ni a parun. “Ilẹ si yà ẹnu rè̩, o si gbe wọn mì, . . . Awọn, ati ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, sọkalẹ lọ lāye si ipò-okú, ilẹ si pa ẹnu dé mọ wọn, nwọn si run kuro ninu ijọ” (Numeri 16:32, 33). Akọsilẹ miiran gbogbo si tun wà ninu Bibeli nipa awọn eniyan ti Oluwa fi iku ojiji da lẹjọ fun è̩ṣẹ wọn (Numeri 14:37; 2 Awọn Ọba 1:10-12).

S̩ugbọn ki i ṣe gbogbo ẹlẹṣẹ ni o n ṣubu ti wọn si n kú lojiji; ki i si i ṣe gbogbo ikú ojiji ni idajọ fun è̩ṣè̩. Nigba miiran awọn eniyan Ọlọrun a maa kú lojiji bi o ba jẹ pe ọna Ọlọrun ni eyi lati fi mu wọn lọ. S̩ugbọn, nigba ti ikú ba de lojiji sori ẹlẹṣẹ, kò ni akoko lati gbadura ati lati ronupiwada – o ti pé̩ jù fún un lati ri idariji gbà ati lati wà ni alaafia pẹlu Ọlọrun. Ọlọrun kò ni inudidun si ikú eniyan buburu (Esekiẹli 33:11); ṣugbọn “Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rè̩ li oju Oluwa” (Orin Dafidi 116:15).

Alabapin ninu È̩ṣè̩

Ohun ti o ṣẹlẹ si Safira ni lati kọ wa lọgbọn. Kò bá Anania lọ fi owo naa fun wọn, nipa eyi kò lọwọ si è̩ṣẹ rè̩ lójúkojú. Safira ṣe iranlọwọ lati bo Anania ninu è̩ṣè̩ rè̩, o si purọ lati ran an lọwọ. O jé̩ alabapin ninu itanjẹ Anania.

A ba jẹ le ṣọra ki a má ba di alabapin ninu è̩ṣè̩ awọn ẹlomiran nipa didáabo bo ẹni ti o jẹbi ati nipa gbigba è̩ṣẹ wọn laaye. Onigbagbọ ki i bò è̩ṣẹ mọlè̩; kàkà bẹẹ a maa bá wọn wi (Efesu 5:11).

Otitọ tabi Irọ

Ninu iṣé̩ rẹ ni ile-è̩kọ ati ninu eré rẹ pẹlu, má ṣe lọwọ si iwa buburu awọn ẹlomiran nipa kikunà lati duro fun otitọ. Ki i ṣe gbogbo igbà ni a n fi ẹnu purọ; a maa n hu u ni iwà pẹlu. A baa hù u ni ìwà tabi ki a sọ ọ lẹnu, “Kò si eke ninu otitọ” (1Johannu 2:21).

Nigba ti a kọ ẹkọ ninu Owe, a kọ pé Ọlọrun korira irọ (Owe 6:16-19). Eke ni èṣu ati baba èké (Johannu 8:44). Bi ẹni kan kò ba sọ otitọ, ti Satani ni i ṣe, kò si le lọ si Ọrun afi bi o ba ronupiwada ki o si maa sọ otitọ. Ninu Ifihan 21:8, a kà wi pe awọn èké gbogbo “ni yio ni ipa tiwọn ninu adagun ti nfi ina ati sulfuru jò.”

È̩rù Nla

Ki ni ohun naa ti ikú Anania ati Safira mú wá saarin awọn eniyan naa? Eleyii mu è̩rù wá ba gbogbo awọn ti o gbọ. È̩rù nla ba wọn, wọn si mọ bi èke ṣiṣe ti buru tó, ati bi o ti jẹ pataki to lati huwa otitọ si Ọlọrun. Wọn mọ wi pe “ohun è̩ru ni lati ṣubu si ọwọ Ọlọrun alāye” (Heberu 10:31). Bọya a tilẹ rán wọn leti ọrọ ti awọn ará igbà ni sọ: “Tani yio le duro niwaju OLUWA Ọlọrun mimọ yi?” (1Samuẹli 6:20), ati idahun Dafidi ninu Orin Dafidi 24: “Ẹniti o li ọwọ mimọ, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rè̩ soke si asan, ti kò si bura è̩tan.”

Ikú Anania ati Safira kò dá itankalẹ Ihinrere duro bẹẹ ni kò si di i lọwọ. Awọn eniyan Oluwa n ba iṣẹ wọn ati isin wọn lọ. Iye awọn ti o gbagbọ n pọ si i, bẹẹ ni ọpọlọpọ, lọkunrin ati lobinrin ni a n yàn kún Ijọ. Ibukun Oluwa si wà lori awọn eniyan naa nitori pe a ti mu è̩ṣè̩ kuro laaarin wọn. Ki a to le ni ibukun Ọlọrun loni, a ni lati mu è̩ṣè̩ kuro ninu aye awọn eniyan ati kuro laaarin awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Bi è̩ṣẹ ba wa sibẹ ninu ọkàn ati ayé, Ọlọrun kò ni le ṣiṣẹ bi Oun i ba ti fẹ lati ṣiṣẹ.

Iṣẹ Iyanu

Nipa agbara Ọlọrun awọn Apọsteli n ṣiṣẹ iyanu laaarin awọn eniyan naa. Ọpọ eniyan wá lati inu ilu ati awọn orilẹ-ède yika Jerusalẹmu. Ọpọ iṣẹ ami ati iṣẹ-iyanu ni o si ṣe – a mú awọn alaisan lara da, a lé awọn ẹmi aimọ jade, gbogbo awọn ti a si mú wa sọdọ awọn Apọsteli ni a mu lara dá. Awọn eniyan naa ni idaniloju ati igbagbọ to bẹẹ ti wọn n gbe awọn alaisan wá si ẹba ọnà, ki ojiji Peteru “le ṣijibò omiran ninu wọn.”

Boya awọn iṣẹ-iyanu wọnyi ni Jesu n tọka si nigba ti O fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni ileri ti Olutunu ti O si wi pe: “Ẹniti o ba gbà mi gbọ, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba” (Johannu 14:12). Awọn iṣẹ-iyanu wọnyi jé̩ diẹ ninu awọn ami ti Jesu wi pe yoo maa tẹle awọn ti o gba Oun gbọ (Marku 16:17, 18). Ni akoko yii pẹlu, awọn ami wọnyi ṣi n tẹle awọn Onigbagbọ tootọ, bi wọn ba gbadura, pẹlu igbagbọ, ni orukọ Jesu fun ọlá ati ogo Rè̩. (Ka Iṣe Awọn Apọsteli 4:29, 30; ati Romu 15:18, 19).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni fun awọn Apọsteli lagbara lati sọrọ pẹlu igboya?
  2. Ki ni iṣọkan?
  3. Sọ ohun ti o mọ nipa Barnaba.
  4. Bawo ni Peteru ṣe mọ pe Anania kò sọ otitọ?
  5. Ta ni mu ki Anania ati Safira dawọ le e lati ṣe è̩tàn?
  6. Ọna wo ni Anania ati Safira fi dẹṣẹ?
  7. Ki ni idajọ Ọlọrun lori Anania ati Safira?
  8. Ki ni inu Oluwa ti ri si èké ṣiṣe?
  9. Ki ni ikú Anania ati Safira mú wa sinu ọkàn awọn eniyan naa?
  10. Bawo ni awọn Apọsteli ṣe le ṣe iru iṣẹ-iyanu bawọnni?