Iṣe Awọn Apọsteli 5:17-42

Lesson 285 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba n fi eke sọrọ buburu gbogbo si nyin nitori emi” (Matteu 5:11).
Notes

Idojukọ

Nigba ti a ka ọpọlọpọ eniyan kún awọn ọmọ-ẹyin Kristi, ti awọn Apọsteli Rè̩ si n ṣiṣẹ amì, iṣẹ àrà ati iṣẹ-iyanu, a dide si wọn. Lai si aniani, nitori pe awọn ti o n ṣe inunibini si awọn Apọsteli n jowú wọn ni wọn ṣe korira wọn bẹẹ. Awọn olori alufaa ati awọn alafẹnujẹ ẹlẹsìn ti a n pe ni Sadusi, awọn ti wọn kò gba pe ajinde okú wà ni wọn kún fun ibinu ati irunú si awọn Apọsteli. Wọn pinnu lati fi opin si iṣẹ awọn Apọsteli Jesu, ki wọn si fi wọn sinu tubu. A kò ri è̩sun kan si awọn Apọsteli, ṣugbọn fun igba diẹ o ṣe idiwọ fun wọn lati ṣiṣe bi wọn ti maa n ṣe e tẹlẹ. Bọya awọn Sadusi ti gbero lati fi ibẹru si ọkàn awọn ọmọ-ẹyin Kristi, ati pe nipa fifi wọn sinu tubu wọn ni ireti lati mu ẹgàn ba wọn ati iṣẹ wọn.

Lẹẹkan ri, awọn eniyan kan naa ti halẹ mọ awọn Apọsteli, wọn si ti mu ki awọn igbimọ ki o ba wọn wijọ. Nigba ti a kilọ fun awọn Apọsteli pe ki wọn má ṣe tun sọrọ tabi ki wọn kọ ni ni orukọ Jesu, wọn dahun pe “Bi o ba tọ loju Ọlọrun lati gbọ ti nyin jù ti Ọlọrun lọ, ẹ gbà a rò.” Awọn igbimọ kò ri idi rè̩ ti wọn le fi jẹ awọn Apọsteli ni iyà, ati nitori awọn eniyan, wọn jọwọ wọn lọwọ lọ. È̩ru kò ba awọn Apọsteli nitori awọn ọrọ idayafo ti wọn sọ fun wọn, nitori naa wọn tẹra mọ ati maa waasu ati lati maa kọ ni nipa Jesu.

Oloootọ si Ọlọrun

Bi iru nnkan bẹẹ ba ṣẹlẹ si awọn ẹlomiiran, wọn o dẹkun ati maa waasu fun igba diẹ. Niwọn igba ti idojukọ ba wà, awọn ẹlomiiran a maa jaya lati ṣe ohun ti wọn mọ pe o jẹ òtitọ. Awọn eniyan Ọlọrun ki i bẹru idojukọ ati idayafo. Ifẹ wọn ni lati ṣe ohun ti wọn mọ pe o tọ. Ọmọde ti o fẹran Oluwa ti a si ti gba ọkàn rè̩ là yoo mu iduro rè̩ lati ṣe ohun ti o tọ, bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọde iyoku yàn lati ṣe ohun ti o lodi, i baa jẹ nibi ere tabi ni ile-ẹkọ. Gẹgẹ bi Oluwa ti ran awọn Apọsteli Rè̩ lọwọ, bakan naa ni yoo bu ọlá fun awọn ti o ba ṣe ohun ti o tọ lode oni, yoo si ràn wọn lọwọ bi o tilẹ jẹ pe a n tọ wọn, ti a n fi wọn rẹrin, ti a si n ṣe inunibini si wọn lọpọlọpọ.

Ninu Bibeli, ni a tun ri apẹẹrẹ ti o wú ni lori nipa awọn eniyan ti wọn duro gẹgẹ bi oloootọ fun Ọlọrun nigba ti a n tẹri wọn ba ti a si n ṣe inunibini si wọn. A dayafo Daniẹli nitori adura ti o n gbà, ṣugbọn Daniẹli tẹra mọ adura, Ọlọrun si wà pẹlu rè̩ lati gbà á silẹ ninu iho kiniun (Daniẹli 6:22, 23). Nigba kan è̩wè̩, nigba ti a n mọ odi yi Jerusalẹmu ká, Sanballati ati Tobia gbiyanju ni gbogbo ọna lati dí Nehemiah aṣaaju iṣẹ naa lọwọ. È̩ru kò ba Nehemiah si ogun wọn, tabi asọtẹlẹ wọn, ati iwakiwa wọn. O n ba iṣẹ Oluwa lọ. Nigba ti a pari ogiri naa ti awọn ọta si gbọ nipa rè̩, “Nwọn woye pe, lati ọwọ Ọlọrun wá li a ti ṣe iṣẹ wọnyi” (Nehemiah 6:16).

Idasilẹ lati ọwọ Angẹli

Awọn Apọsteli ti jẹ oloootọ, wọn si gbọran si Ọlọrun lẹnu. Wọn ti waasu, wọn si ti n kọ ni titi di igba ti awọn ọta dide si wọn, a si fi awọn Apọsteli sinu tubu. Ni akoko aini wọn, Ọlọrun kò fi wọn silẹ. Ni ọganjọ oru, nigba ti ohun gbogbo dakẹ rọrọ ti okunkun si ṣu ninu tubu, alejo kan dé. Angẹli Oluwa ṣi ilẹkun ile tubu, o mu awọn Apọsteli jade, o si ran wọn ni iṣẹ kan. Angẹli naa wi pe, “Ẹ lọ, ẹ duro, ki ẹ si mā sọ gbogbo ọrọ ìye yi fun awọn enia ni tẹmpili.” A tun paṣẹ fun wọn lọtun ni ti iṣẹ-iranṣẹ ti a fi le wọn lọwọ. Bakan naa ni gẹgẹ bi o ti wà tẹlẹ. Aṣẹ ti a pa fun wọn jẹ eyi ti o hàn gbangba. Wọn kò gbọdọ lọ waasu nibomiiran tabi ni ikọkọ nikan. Wọn ni lati lọ waasu fun awọn eniyan, ọrọ wọn si jẹ ọkan naa ti wọn ti n waasu tẹlẹ - ọrọ iye, ọrọ ti o mu iye-ainipẹkun wá, ọrọ igbala. Wọn ni lati sọ gbogbo otitọ Ihinrere.

Angẹli Oluwa naa dá awọn Apọsteli silẹ fun idi kan – fun ogo ati ọla Ọlọrun. Wọn ni lati ṣe iṣẹ Oluwa. Nigba ti Ọlọrun ba gba eniyan lọwọ è̩ṣẹ, fun idi kan ni – ki aye rè̩ ba le fi ọlá fun Ọlọrun. Nigba ti a ba ri idasilẹ kuro ninu aisan tabi kuro ninu idaamu nipa agbara Ọlọrun, a ni lati fi ogo ati ọla fun Ọlọrun nipa igbesi-aye wa ati nipa iṣẹ-isin wa si Ọlọrun. Nigba ti o ba beere fun iranlọwọ tabi idasilẹ lọwọ Ọlọrun nigba idaamu, ranti lati beere pe ki Oluwa ṣe e fun ọlá ati ogo Rè̩, ki i ṣe fun igbadun ati itura iwọ nikan, ṣugbọn ki o le jẹ ẹri si agbara Ọlọrun. A ka a ninu Orin Dafidi: “Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lāye, yio si ma yin ọ” (Orin Dafidi 119:175); ki o si “Mu ọkàn mi jade kuro ninu tubu, ki emi ki o le ma yìn orukọ rẹ” (Orin Dafidi 142:7).

Tubu ti o S̩ofo

Ni ọjọ keji awọn Apọsteli tẹsiwaju ninu iṣẹ wọn, lai si ijafara ati lai si ijiyan. Wọn mọ iṣẹ ti a fẹ ki wọn ṣe, wọn si ni itẹlọrun lati gbẹkele Ọlọrun. Inunibini naa n pọ sii pẹlu. Olori alufaa pe awọn igbimọ ati agbaagba jọ. Bi wọn ti pejọ pọ sibẹ a ran awọn alaṣẹ lati mu awọn onde naa wa. Wọn rii pe a ti ile tubu gbọningbọnin sibẹ ati pe awọn oluṣọ si duro lode niwaju ilẹkun, ṣugbọn kò si ẹni kan ninu tubu. Wọn sọ fun awọn igbimọ pe ile tubu ṣofo. Awọn ti wọn ti gbiyanju lati mu ijatilẹ ati itiju ba awọn ọmọlẹyin Kristi ni itiju, ijatilẹ ati idaamu de bá. Nigba ti awọn igbimọ n ronu lọwọ nipa ohun ti wọn o ṣe, a wa royin fun wọn pe awọn ọkunrin nì ti wọn fi sinu tubu wà ninu Tẹmpili wọn n kọ awọn eniyan. Si idaamu awọn ọta wọn, awọn Apọsteli ni igboya to bẹẹ ti wọn fi tẹsiwaju ninu wiwaasu ati kikọni ninu Tẹmpili, lai fi awọn ti o n dẹruba wọn pè.

Ibẹru Ọlọrun tabi ti Eniyan

A mu awọn Apọsteli lẹẹkan sii. Awọn olori è̩ṣọ mú wọn ṣugbọn ki i ṣe pẹlu ipá nitori wọn bè̩ru awọn eniyan. Ibẹru pe wọn le bi Ọlọrun ninu kò si ninu wọn ṣugbọn wọn n ṣọra ki wọn má ba rú awọn eniyan soke. Bibeli kọ wa pe a ni lati bẹru Ọlọrun ju pe ki a bẹru ohun ti eniyan le ṣe si wa (Luku 12:4, 5). A ka wi pe “ibè̩ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rè̩ le OLUWA li a o gbe leke” (Owe 29:25), ati pe a ni lati “Bè̩ru Ọlọrun, ki o si pa ofin rè̩ mọ: nitori eyi ni fun gbogbo enia” (Oniwasu 12:13).

Awọn Ọrọ Olori Alufaa

Awọn Apọsteli duro niwaju Ajọ igbimọ, igbimọ ti o ga ju lọ laaarin awọn Ju. Olori alufaa wi pe, “Awa kò ti kìlọ fun nyin gidigidi pe, ki ẹ maṣe fi orukọ yí kọni mọ?” Si eyi awọn Apọsteli dahun pe “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun jù ti enia lọ.”

Awọn Apọsteli gbọran si Ọlọrun lẹnu, ẹni ti aṣẹ Rè̩ tobi ju ti eniyan lọ. Wọn kò gbọran si aṣẹ ti awọn olori wọnyi fi fun wọn nitori pe o lodi si aṣẹ ti Oluwa fi fun wọn. Onigbagbọ jẹ ọmọ-ibilẹ rere a si maa pa ofin ibilẹ mọ. A kò ni lati rú ofin ilẹ wa afi bi wọn ba lodi si ofin Ọlọrun. Iṣẹ wa akọkọ ni lati gbọran si Ọlọrun lẹnu. O yẹ lati dá awọn Apọsteli lare fun gbigbọran si Oluwa lẹnu.

Olori alufaa kọ lati lo orukọ Jesu Ẹni ti i ṣe Messia wọn, orukọ Ẹni ti i ba ṣọwọn fun un, eyi ti o si yẹ ki o ṣọwọn fun un. Kò si aniani pe olori alufaa ranti ọjọ ti a kan Jesu mọ agbelebu nigba ti awọn Ju fi kigbe ni ohun rara si Pilatu, Baalẹ ara Romu, pe “Ki ẹjẹ rè̩ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa” (Matteu 27:25). Ki i ṣe pe awọn Apọsteli n fẹ fi Ẹjẹ Jesu tabi ẹrù ẹbi ikú Rè̩ si ori awọn eniyan naa. Iṣẹ ọwọ wọn ati ẹbi wọn ni pe Ẹjẹ Jesu wa lori wọn ati lori awọn ọmọ wọn. Awọn alaṣẹ wọnyi kò fẹ ki a dá wọn lẹbi lori buburu ti wọn ti ṣe, wọn si fẹ lati ba awọn Apọsteli wi. Ẹri ọkàn awọn igbimọ naa yoo ti maa dá wọn lẹbi dajudaju. Wọn ki ba ti ṣe bẹẹ sọrọ bi Jesu ba ti yẹ lati kú, ṣugbọn ọrọ wọn fi hàn pe wọn mọ pe O jẹ alailẹṣẹ lọrùn.

Niwaju Igbimọ

Bi awọn Apọsteli ti duro niwaju awọn alaṣẹ nla wọnni, boya ọrọ Jesu wá sinu ọkàn wọn. Jesu wi pe: “Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagọgu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi: nitori Ẹmi Mimọ yio kọ nyin ni wakati kanna li ohun ti o yẹ ki ẹ wi” (Luku 12:11, 12).

Bi Ajọ Igbimọ ba ti n reti idahun pẹlẹ lati ọwọ awọn Apọsteli, dajudaju o ni lati jẹ iyanu fun wọn nitori pe, pẹlu igboya Peteru ati awọn iyoku kigbe gbọnmọgbọnmọ pe, Ọlọrun ti bu ọlá fun Jesu O si ti gbe E ga lati jẹ Ọmọ alade ati Olugbala. Peteru tè̩ siwaju pe Ọlọrun ti yan Jesu lati mu ironupiwada wá fun Israẹli ati lati dari è̩ṣẹ wọn ji wọn. O waasu Ihinrere pe ironupiwada yoo mu idariji wá. Peteru kò ṣe awawi tabi ki o tọrọ idariji fun ohun ti awọn Apọsteli ṣe. Kàkà bẹẹ o tun ẹjọ naa wi pe awọn ti oun n sọrọ fun ni o mu ki a kan Jesu mọ agbelebu, ati pe niwọn igba ti wọn ba n tabuku si orukọ Jesu ti wọn si n ṣe aigbọran si I, wọn n huwa abuku si Ọlọrun.

Àyà wọn Gbọgbẹ de Inu

Ọrọ Peteru gẹgẹ bi ẹlẹri kò gba awọn Apọsteli silẹ niwaju awọn ajọ igbimọ. Nitori pe aya awọn igbimọ naa “gbà ọgbé̩ de inu” fun ibinu ati idalẹbi ọkan, wọn pinnu lati pa awọn Apọsteli.

Igba kan tun wà nigba ti Peteru waasu bi iru eyi, to bẹẹ ti o jẹ pe nigba ti wọn gbọ “ọkàn wọn gbọgbẹ” wọn si mọ pe a kò le ṣai gbà wọn la (Iṣe Awọn Apọsteli 2:37). Ni ọjọ naa ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni o gbagbọ ti wọn ronupiwada, ti a si baptisi wọn. Iwaasu Ihinrere jé̩ iye fun awọn ti o gbagbọ, ṣugbọn fun ajọ igbimọ, ti o kọ Ihinrere silẹ, o jẹ ikú nipa ti ẹmi (2Kọrinti 2:15, 16).

Gamaliẹli

Ni akoko yii, nigba ti o dabi ẹni pe a fẹ lati pa awọn Apọsteli, ẹni kan ninu igbimọ fun wọn ni amọran kan. Farisi ni i ṣe, ọga ju lọ laaarin awọn amofin ti orukọ rè̩ n jẹ Gamaliẹli, ẹni ti a mọ pupọ ti a si fẹran pupọ laaarin awọn eniyan naa. O gbà wọn ni iyanju pe ki a mu awọn Apọsteli bi sẹyin diẹ, o si kilọ fun awọn igbimọ nipa ohun ti wọn gbèrò lati ṣe si awọn ọkunrin wọnyi. Gamaliẹli sọ apẹẹrẹ awọn meji, awọn ti ẹkọ wọn gbilẹ fun saa kan ṣugbọn ti wọn parẹ kuro lai si iranwọ lati ọwọ awọn igbimọ.

Gamaliẹli gbà ni ọkàn rè̩ pe bi iṣẹ awọn Apọsteli bá jẹ ti eniyan, “a o bi i ṣubu,”ṣugbọn bi o ba jẹ iṣẹ Ọlọrun, wọn kò ni le bi i ṣubu. Gamaliẹli kò sọ wi pe oun ni igbagbọ ninu iṣẹ ti awọn Apọsteli n ṣe. Ohun ti o sọ fi hàn ni tootọ pe o mọ pe kò si ohun ti o tobi ju agbara Ọlọrun lọ ati pe kiki iṣẹ ododo Oluwa nikan ni o le duro titi lae (Ka Orin Dafidi 127:1 ati Owe 21:30). Ọpọlọpọ ẹkọ ati igbekalẹ ni o ti wà, eyi ti o jẹ pe, bi ọdun ti n gori ọdun, wọn ti pìn yé̩lẹyè̩lẹ tabi ki a ti fi kún wọn, tabi ki a tilẹ ti pa wọn tì patapata, “ṣugbọn ọrọ Oluwa duro titi lai” (1Peteru 1:25).

Jijẹ Ìyà fun Oluwa

Awọn Igbimọ gbà lati ṣe gẹgẹ bi amọran Gamaliẹli lati duro lati ri ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn Apọsteli ati ẹkọ wọn. Igbimọ naa kò pa ẹnikẹni laaarin awọn Apọsteli naa ni akoko yii. Ki wọn to fi wọn silẹ, wọn lu wọn, wọn si paṣẹ fun wọn ki wọn má tun sọrọ ni orukọ Jesu mọ. Lai si aniani, nipa lilu awọn Apọsteli, awọn alaṣẹ Ju ti ni ireti pe wọn o mu itiju ba wọn, wọn o si kún fun è̩rù. S̩ugbọn inunibini yii kò ṣe iru nnkan bẹẹ lara awọn Apọsteli rárá. Wọn gba iyà yii pẹlu ayọ. Wọn yọ pe a kà wọn yẹ lati jiya fun Jesu. Awọn Apọsteli n ba iṣẹ wọn lọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun wọn. Wọn kò fà sẹyin ninu iṣẹ wọn. Wọn n kọ ni lojoojumọ ninu Tẹmpili gẹgẹ bi Jesu ti ṣe nigba ti akoko ikú Rè̩ kù fé̩ẹfé̩ẹ (Luku 19:47; Matteu 26:55). Wọn n waasu ni gbangba ati ni ìkọkọ -- ninu Tẹmpili ati ninu ile kọọkan. Wọn kò yi ọrọ iwaasu wọn pada. Wọn n waasu sibẹ nipa Jesu ati agbara Rè̩ lati gbàlà.

Awọn igbimọ kò i ti ri ohun ti wọn n fẹ bẹẹ ni wọn kò ri èrè kankan gbà ninu gbogbo bi wọn ti n ṣe lodi si iwaasu Ihinrere. Awọn Apọsteli yọ ninu iyà wọn. Lai si aniani wọn tun ni ipinnu sii lati tubọ jé̩ oloootọ si Ọlọrun. Dajudaju okun ifẹ ti o so wọn pọ tubọ lagbara sii, wọn si n tẹ siwaju lati maa tan Ihinrere kalẹ. Inunibini si awọn ọmọ-ẹyin Jesu fun wọn ni anfaani lati sọrọ niwaju awọn ajọ igbimọ nla, nipa bẹẹ awọn ẹlomiiran ni anfaani lati gbọ nipa Ihinrere laaarin awọn ti kò ni anfaani lati gbọ té̩lè̩. Awọn ti o n ṣe inunibini si awọn Apọsteli ni o n jiya gan an, nitori pe wọn kọ Ihinrere silẹ; ṣugbọn awọn Apọsteli layọ bi wọn ti n tan Ihinrere ti igbala kalẹ.

Ọpọlọpọ laaarin awọn ọmọ-ẹyin Kristi, lati igbà yii wá ni a ti ṣe inunibinu si, ani titi di ọjọ oni ni a n ṣe inunibini si, ti a o si ma ṣe inunibini si. “Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mā gbé igbé iwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini” (2Timoteu 3:12), ṣugbọn ère kan wà fun wọn. Jesu wi pe: “Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn nfi eke sọrọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. Ẹ mā yọ, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ: nitori ère nyin pọ li ọrun: bḝni nwọn sá ṣe inunibini si awọn woli ti o ti mbẹ ṣaju nyin” (Matteu 5:11, 12). Paulu, Apọsteli kan, ẹni ti o jiya ti a ṣe inunibini pupọ si ati ọpọlọpọ ohun miiran nitori Kristi ati Ihinrere, wi pe “Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sé̩ ẹ, on na yio si sé̩ wa” (2Timoteu 2:12).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a fi awọn Apọsteli sinu túbu?
  2. Ta ni ṣi ilẹkun ile tubu ti o si mu awọn Apọsteli jade?
  3. Ki ni ọrọ nì ti angẹli Oluwa mu wa?
  4. Nibo ni awọn alaṣẹ gbe ri awọn Apọsteli?
  5. Ki ni awọn Apọsteli ṣe nigba ti awọn igbimọ bi wọn leere ọrọ?
  6. Ki ni amọran Gamaliẹli?
  7. Ki ni ṣe ti a na awọn Apọsteli?
  8. Ki ni ṣe ti awọn Apọsteli fi yọ?
  9. Ki ni inunibini?
  10. Ki ni ohun ti a le ṣe bi a ba ṣe inunibini si wa?