1Awọn Ọba 11:9-43

Lesson 286 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọrọ mi duro: pa ofin mi mọ ki iwọ ki o si yè” (Owe 4:4).
Notes

Sọlomọni Bẹrẹ Daradara

Ọlọrun fara han fun Sọlomọni ni Gibeoni, ni alẹ ọjọ iyanu nì nigba ti o sun. A kà wi pe, “Solomoni si fẹ OLUWA, o si nrin nipa aṣẹ Dafidi baba rè̩” (1Awọn Ọba 3:3). Lẹẹkan sii boya ọdun mẹwaa lẹyin eyi. Ọlọrun fara han fun Sọlomọni nigba iyasimimọ Tẹmpili daradara nì. Ọkàn Sọlomọni ọba sun mọ Ọlọrun timọtimọ bi o ti n gbadura pe “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ loke ọrun, tabi ni isalẹ ilẹ, ti ipa majẹmu ati ānu mọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti n fi gbogbo ọkàn nwọn rin niwaju rẹ” (1Awọn Ọba 8:23).

Sọlomọni jé̩ ẹni ibukun nitori pe o ni baba ti o bẹru Ọlọrun, ẹni ti i ṣe Dafidi, “ẹni bi ọkàn mi” (Ọlọrun) (Iṣe Awọn Apọsteli 13:22). Fun saa kan ẹkọ ti a fi kọ Sọlomọni nipa sisin Ọlọrun fi idi mulẹ ṣinṣin ninu igbesi-aye rè̩.

Awọn ọmọdekunrin ati awọn ọmọdebinrin ti wọn ni obi Onigbagbọ ni anfaani ti o daju ni igbesi-aye wọn. Bi wọn ba feti si ẹkọ iwa-bi-Ọlọrun yoo ṣe iranlọwọ fun wọn lati ri igbala ni kete ti wọn ba ti dagba to lati loye pe wọn ti dẹṣẹ. Nigba naa, bi wọn ti n lọ si ile-ẹkọ wọn, bi wọn ba ranti lati gbadura lojoojumọ ni owurọ ati ni aṣaalẹ, wọn yoo ni anfaani lati pa ifẹ Jesu mọ ninu ọkàn wọn. Kò ṣanfaani lati sọ igbala nu ati lati lọ dẹṣẹ nipa lilọ sinu afẹ aye. Kò si ayọ aye kan ti a le fi wé wiwa ninu adura lori eekun wa nigba ti ibukun Ọrun ba n tú jade. Ihinrere Jesu a maa mu ayọ ba ọkàn ẹni ti o tilẹ kere ju lọ. Anfaani Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi wà nibi ti wọn n kọ ekọ nipa Jesu ati ifẹ Rè̩; anfaani wa fun awọn ọmọde lati kọrin ati lati lo ohun-elo orin ni akoko isin awọn ọdọ. A maa n gbà wọn niyanju lati ṣiṣẹ fun Jesu ni oriṣiriṣi ọna miiran gbogbo.

Ikuna Sọlomọni

A mọ dajudaju pe Sọlomọni fẹ Oluwa nigba ti o wà ni ọdọmọde, ọpọ ohun rere ni o si tun wà fun un ni ti ọjọ iwaju niwọn igba ti o ba le tẹle Oluwa. S̩ugbọn o ba ni ninu jé̩ iru iyipada ti o de ba ọba nla yii nigba ti o “ṣe buburu niwaju OLUWA” (1Awọn Ọba 11:6)! Jẹ ki a kà ẹsẹ diẹ sii lati inu ori è̩kọ wa, eyi ti o fi han wa pe kò sun mọ Ọlọrun timọtimọ: “Nigbati Solomoni di arugbo, ... ọkàn rè̩ kò si ṣe dede pẹlu OLUWA Ọlọrun rè̩, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rè̩.” “Solomoni si ṣe buburu niwaju OLUWA, kò si tọ OLUWA lẹhin ni pipé gẹgẹbi Dafidi baba rè̩.” “Kò pa eyiti OLUWA fi aṣẹ fun u mọ” (1Awọn Ọba 11:4, 6, 10).

Nigba ti eniyan ba sin Oluwa pẹlu gbogbo ọkàn rè̩, ti ọnà rè̩ si té̩ Oluwa lọrun, “On a mu awọn ọtá rè̩ pāpa wà pẹlu rè̩ li alafia” (Owe 16:7). S̩ugbọn bi eniyan bá kọ Oluwa silẹ o daju pe idaamu yoo de. Nitori ikùnà Sọlomọni, Ọlọrun wi fun un pé, “Ni yiya emi o fà ijọba rẹ ya kuro lọwọ rẹ.” Ogo ati agbara ti Ọlọrun fi fun Sọlomọni, ati anfaani lati jé̩ ọba lori gbogbo awọn eniyan naa ni a o gba kuro lọwọ rè̩, nitori pe o ṣe aigbọran. A ti kilọ fun un; kò si awáwi fun un: o mọ pe oun ni lati ni ọkàn pipe niwaju Ọlọrun bi Dafidi baba rè̩ ti ni.

Ọrọ ti o n Pọ Si i

S̩ugbọn ifẹ aye ati afẹ è̩ṣè̩ ti kó wọ inu ọkàn Sọlomọni. Aye rè̩ kún fun oriṣiriṣi igbadun. O gbiyanju lati té̩ ọkàn rè̩ lọrun pẹlu àriyá, orin, ọti waini ati ọrọ. Pẹlu ọpọlọpọ wura ati okuta iyebiye ti n wá lati Ofiri lọdọọdun, turari olowo iyebiye lati ọwọ awọn oniṣowo ti o n ti ọna jijin wa, igi kedari daradara lati Lẹbanoni wá, wura, fadaka, ehin-erin ati awọn ẹrù òwò ti o ṣe iyebiye ni ọdun mẹta-mẹta lati Tarṣiṣi wa, Sọlomọni “a mā jẹ, a mā mu, a si mā ṣe àriya.” S̩ugbọn ayọ tootọ ati alaafia ti o wà titi ki i ti ipa bẹẹ wá. Sọlomọni mọ eyi dajudaju pẹlu, nitori pe a ni awọn akọsilẹ lati ọwọ rè̩ wa ti o n sọ fun wa pe, “Bè̩ru Ọlọrun ki o si pa ofin rè̩ mọ: nitori eyi ni fun gbogbo enia” (Oniwasu 12:13). S̩ugbọn ohun kan ni pe ki a mọ ohun ti a ni lati ṣe, ohun miiran si ni pe ki a ṣe e. “Ẹniti o ba mọ rere iṣe ti kò si ṣe, è̩ṣẹ ni fun u” (Jakọbu 4:17). Idajọ Ọlọrun lori Sọlomọni dàbi idajọ kan ti a sọ si ijọ kan: “Emi o pọ ọ jade kuro li ẹnu mi ... iwọ wipe, Emi li ọrọ, emi si npọ si i li ọrọ, emi kò si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ kò si mọ pe, òṣi ni iwọ, ati àre, ati talakà, ati afọju, ati ẹni ìhoho” (Ifihan 3:16, 17).

Awọn ti o yà kuro lọdọ Oluwa ti wọn si rú ofin Rè̩ yoo ba idaamu pade lai si aniani. Nigba ti ọba Saulu ṣaigbọran si Oluwa, a kọ ọ ni ọba, ati ni ikẹyin o sọ ẹmi rè̩ nù (1Samuẹli 15 ati 31). Bẹlṣassari ọba gberaga, awọn ọta rè̩ si gba ijọba rè̩, wọn si pa a (Daniẹli 5). Ọlọrun n ba awọn eniyan lo bakan naa loni gẹgẹ bi o ti n ba awọn ti igba nì lo. Ibukun Ọlọrun a maa tẹle awọn ti o ba gbàgbọ, ṣugbọn ègún Ọlọrun wa lori awọn ti o ba ṣe orikunkun si ati yipada si ọdọ Ọlọrun.

Olufunni ni Ẹbun Rere

Sọlomọni jé̩ ọlọrọ pupọ. Ki i ṣe è̩ṣẹ niwaju Ọlọrun lati ni ohun ini pupọ; kò si ohun ti o buru ninu pe ki a ni ninu awọn ohun didara ayé yii. S̩ugbọn, ninu Bibeli a kilọ fun wa pe bi ọrọ ba n pọ si i, a kò gbọdọ gbe ọkàn wa le e (Orin Dafidi 62:10). Ọlọrun n fẹ wi pe ninu ohun rere ti Oun fi fun wa, ki a fi ran awọn ẹlomiran lọwọ lati inu ọkàn wa. Ọrọ jẹ ibukun fun awọn kan, o si jẹ ègún fun awọn ẹlomiran. Awọn ẹlomiran a maa fè̩ soke nigba ti ọrọ ba n pọ si i. O gba pe ki a ni agbara ẹmi Ọlọrun pupọ si i lati le duro nigba ti ohun gbogbo n lọ deedee, ju igba ti a wà ninu aini. A ni lati lawọ pẹlu ohunkohun ti Ọlọrun ba fi fun wa, ki a fi tinutinu ṣe ipinfunni ere ti a n jẹ pẹlu awọn ẹlomiran. Nipa ṣiṣe bẹẹ a n ran awọn ti o wà ninu aini lọwọ, ati ju eyi nì lọ pẹlu a o ṣe iranlọwọ lati tan Ihinrere kalẹ lọ si ọna jijin ati itosi. S̩ugbọn ibukun Ọlọrun ki i si lori awọn ti o n ná gbogbo ohun ti wọn ni lori ara wọn nikan; nitori pe ni otitọ ati ni ododo ibukun ti iru awọn eniyan bẹẹ ni wá lati ọdọ Olufunni ni ẹbun rere ati ẹbun pipe.

Aanu Ọlọrun ti o Tobi

Ni ikẹyin ọjọ aye Sọlomọni, a ri bi o ti jẹ pe sibẹsibẹ aanu dapọ mọ idajọ. Nitori ti Dafidi baba rè̩, Oluwa ṣe rere fun un bi o tilẹ jẹ pe o yipada kuro lọdọ Ọlọrun. Ọlọrun wi pe, “Emi kì yio fà gbogbo ijọba na ya; emi o fi ẹyà kan fun ọmọ rè̩, nitori Dafidi iranṣẹ mi” (1Awọn Ọba 11:13); “ki Dafidi iranṣẹ mi ki o le ni imọlẹ niwaju mi nigbagbogbo, ni Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn fun ara mi lati fi orukọ mi sibẹ” (1Awọn Ọba 11:36).

Ẹ jẹ ki a wò bi igbẹyin aye Sọlomọni ti ri nigba ti a ba fi we igbẹyin aye Dafidi. A kà nipa Dafidi pé: “O kú rere, o kún fun ọjọ, ọrọ ati ọlá” (1Kronika 29:28). S̩ugbọn awọn ọrọ akọsilẹ ti a ri nipa igbẹyin aye Sọlomọni ni yii “Nigbati Solomoni di arugbo ... ọkàn rè̩ kò si ṣe dede pẹlu OLUWA Ọlọrun rè̩, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rè̩” (1Awọn Ọba 11:4). Wo o bi iyatọ naa ti to! A sọ fun wa pe “ẹniti o ba foriti i titi fi de opin on na ni a ó gbalà” (Matteu 10:22).

Sọlomọni kò fiyesi amọran Dafidi baba rè̩ to bi o ti yẹ ki o ṣe, nitori baba rè̩ wi fun un pe, “Gbọ, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọrọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ” (Owe 4:10). Bi o ba ti ṣe bẹẹ, oun pẹlu i ba ti dagba ki o si di arugbo rere. Kàkà bẹẹ o kú ki o to tó “adọrin ọdun” ti rè̩. Ẹ jẹ ki olukuluku ọdọ kiyesi ọna rè̩ ki o si gbọran si ofin kin-in-ni pẹlu ileri ti Ọlọrun fi fun ni ninu Ọrọ Rè̩.

“Ẹnyin ọmọ, ẹ mā gbọ ti awọn obi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ.

“Bọwọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri),

“Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye” (Efesu 6:1-3).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ nipa ifarahan Oluwa mejeeji fun Sọlomọni.
  2. Ki ni Ọlọrun ṣeleri lati fun un nigba ti O fara han an lẹẹkinni?
  3. Ki ni ṣe ti Ọlọrun wi pe “Ni yiya emi o fà ijọba rẹ ya kuro lọwọ rẹ?”
  4. Ki ni ṣe ti a kò gba gbogbo ijọba kuro lọwọ rè̩?
  5. Darukọ awọn ti o kó wahala ba Sọlomọni.
  6. Ileri wo ni Ọlọrun ṣe fun Jeroboamu?
  7. Lori adehun wo ni awọn ileri naa duro le?
  8. Ọdun mélòó ni Sọlomọni jọba?
  9. Bawo ni igbẹyin aye rè̩ ti ri bi a ba fi wé igbẹyin aye Dafidi?
  10. Ta ni a ṣeleri ẹmi gigun fun?