1Awọn Ọba 12:1-33; 14:21-23; 2Kronika 12:1-16

Lesson 287 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Idahùn pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọrọ lile ni irú ibinu soke” (Owe 15:1)
Notes

A dé Rehoboamu ni Ade

Lẹyin ikú Sọlomọni Ọba, gẹgẹ bi è̩tọ, ọmọ rè̩ ọkunrin ni o yẹ ki o jọba. Gbogbo Israẹli ni o pejọ pọ si S̩ekemu ni ọjọ àyẹyẹ gigun-ori-oye Rehoboamu gẹgẹ bi ọba Israẹli ni ipò baba rè̩. A kò sọ ohunkohun nipa Rehoboamu ṣaaju akoko yii. Boya kò ṣe ohunkohun ti a le pọnlé to eyi ti a ba kọ silẹ nigba ti o n dagba.

S̩ugbọn ṣa a sọ fun wa nipa Jeroboamu, alaapọn ọdọmọkunrin, ẹni ti o ti fi igboya jà fun Israẹli, ti o si ti ri ojurere wọn. O ni lati sa lọ si Egipti nitori owú Sọlomọni. Nigba ti o gbọ pe Sọlomọni kú ati pe a fẹ fi Rehoboamu jọba, o pada fun ayẹyẹ naa. Woli kan ti sọ fun Jeroboamu ki o to sa lọ pe a o fun un ni è̩yà mẹwaa lati jọba le lori, kò si sí aniani pe o n woye bi asọtẹlẹ yii yoo ṣe le ṣẹ.

A di Ẹrù Wuwo le awọn Eniyan Lori

Lẹyin ti Sọlomọni ti yipada lẹyin Oluwa ti o si sin oriṣa, o ti kún fun iwọra fun ère ohun aye yii. Owo-ori ti o pọ pupọ jù ni o n gbà lọwọ awọn eniyan, o si n kó ọpọlọpọ ṣiṣẹ ati sinu iṣẹ ologun. Eyi ti jẹ inira fun awọn Ọmọ Israẹli, bẹẹ ni wọn si ti jiya labẹ akoni-ṣiṣẹ alailaanu.

Nitori ti awọn Ọmọ Israẹli, Jeroboamu wá beere lọwọ Rehoboamu bi yoo ti ṣe ọran naa si. Yoo ha ṣaanu fun awọn eniyan naa ki o si gbé ajaga ti o wuwo kuro lori awọn eniyan wọnyii? Rehoboamu beere fun ọjọ mẹta lati ronu esi ti oun yoo fun wọn.

Laaarin ọjọ mẹta ni Rehoboamu pe awọn oludamọran diẹ mọra. Wọn jẹ agbalagba laaarin awọn eniyan, boya ninu awọn ti wọn ti wa pẹlu baba rè̩ gẹgẹ bi oṣelu. Wọn jẹ ọlọgbọn eniyan, wọn si ti ni iriri fun ọpọlọpọ ọdun, wọn si mọ aini awọn eniyan naa. Rehoboamu jẹ ọdọ, o si ṣe ohun rere ni bibeere amọran lọdọ awọn eniyan ti o ni iriri bẹẹ. Awọn eniyan wọnyi sọ fun un pe bi o ba le ṣe inurere si awọn eniyan naa ki o si sọrọ daradara si wọn, tinutinu wọn ni wọn o fi gba a ni olori wọn ti wọn o si huwa rere si i. Bi yoo ba jẹ ọba lori wọn, iṣẹ rè̩ ni lati ran awọn eniyan naa lọwọ.

Jesu fi aṣẹ lelẹ fun aṣeyọri iṣẹ gẹgẹ bi olori. O wi pe: “Ẹniti o ba pọju ninu nyin, on ni yio jẹ iranṣẹ nyin. Ẹnikẹni ti o ba si gbé ara rè̩ ga, li a o rè̩ silẹ; ẹnikẹni ti o ba si rè̩ ara rè̩ silẹ li a o gbé ga” (Matteu 23:11, 12). Ni akoko miiran Jesu tun wi pe: “Ẹniti o ba pọju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ” (Luku 22:26).

Wò o bi Rehoboamu i ba ti ṣe aṣeyọri to gẹgẹ bi ọba bi o ba ṣe pe o sin awọn eniyan rè̩ gẹgẹ bi Ọlọrun ti lana silẹ! Ninu Orin Dafidi ti o kẹyin o kọ bayii pe: “Ọlọrun Israeli ní, Apata Israeli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakoso enia lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun” (2Samuẹli 23:3).

Gbogbo imọran rere yii lọ lasan lori Rehoboamu. O pè ninu awọn ọdọ ọré̩ rè̩, o si beere ohun ti wọn rò. Wọn jé̩ ọlọkàn giga wọn kò si ni ifẹ awọn eniyan naa. Wọn wi fun Rehoboamu pe ki o mu ki àjàgà naa wuwo nigba meji sii, ki o si fi iyà jẹ awọn eniyan naa lọna ti o tilẹ buru ju eyi ti baba Rehoboamu ti ṣe.

A Já Awọn Eniyan naa Tílè̩

Nigba ti Jeroboamu pada lẹyin ọjọ mẹta lati gbọ ipinnu Rehoboamu, ohun ti o gbọ niyii: “Baba mi mu ki àjaga nyin ki o wuwo, emi o si bù kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin.” Wo iru ọrọ ailaanu bẹẹ! Ro o wo iru ijatilẹ ti yoo mu ba ọkàn awọn eniyan yii! Wọn ti ro pé ọba titun yii yoo mù igba alaafia ati inudidun bá wọn, ṣugbọn wo ohun ti wọn gbọ!

S̩ugbọn Ọlọrun ni eto kan fun awọn eniyan Rè̩. Gbogbo imọ ailaanu yii kọ ni yoo ṣẹ sori wọn. A o jẹ Sọlomọni ni iyà è̩ṣẹ rè̩ nipa mimu ki Jeroboamu jọba lori è̩yà Israẹli mẹwaa, dipo Rehoboamu. Awọn eniyan wọnyi kò le gba lati tẹriba fun Rehoboamu nigba ti kò fi bẹẹ bikita fun wọn, nitori naa wọn kọ ọ silẹ. Kiki è̩yà Juda ati Bẹnjamini nikan ni wọn tẹriba fun Rehoboamu.

Dajudaju, inu Rehoboamu kò dùn si iyapa yii nitori naa o gbá ogun nlá nlà jọ --ọkẹ mẹsan (180,000) eniyan – o si n fẹ lọ taara lati ṣẹgun awọn è̩yà ọlọtẹ wọnyii. S̩ugbọn oju Ọlọrun n wo gbogbo rè̩, O si ran Woli kan lati sọ fun Rehoboamu pe ifẹ inu Oun ni pe ki Israẹli ati Juda wà ni ọtọtọ. Kò gbọdọ si ogun. Rehoboamu gbọran, bẹẹ ni alaafia si wà ni ilẹ naa.

Lati igba yii lọ a o maa gbọ nipa orilẹ-ède meji, Juda ati Israẹli, dipo Israẹli nikan ṣoṣo. Itan awọn ọdun ti o tẹle eyi n fi han bi awọn è̩ya wọnyii ti gbé ọpọlọpọ ogun dide si ara wọn. Ọba ọtọtọ ni wọn n ni titi di igba naa ti a fi kó gbogbo wọn lọ si igbekun Assiria ati Babiloni ni ọpọlọpọ ọdun lẹyin eyi. Ni akoko ti ẹkọ ti a n kọ yii ṣẹlẹ Jeroboamu ni ọba Israẹli, Rehoboamu si ni ọba Juda.

Ileri Ọlọrun fun Jeroboamu

Ọlọrun ti ṣe ileri iyanu fun Jeroboamu: “Emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ fun Dafidi, emi o si fi Israeli fun ọ” (1Awọn Ọba 11:38). A mọ nipa ibukun ti o wà lakoko ijọba Dafidi nitori pe o gbọran si Ọlọrun lẹnu. Nisisiyi Ọlọrun n fẹ lati ṣe iru nnkan bẹẹ fun Jeroboamu bi o ba pa ofin Ọlọrun mọ.

Awa pẹlu ni ileri Ọlọrun ninu Ọrọ Rè̩, ṣugbọn gbogbo rè̩ wa lori pe bi a ba gbọran si Ọlọrun lẹnu. Awọn ofin Rè̩ fun iwa hihu ni o hàn gbangba ninu Bibeli, bi a bá si le tẹle wọn a le nireti lati gbadun awọn ibukun naa.

Titi di igba yii Jeroboamu ti mú ifẹ Ọlọrun ṣẹ. Bi o ba ṣe pe o ti tẹ siwaju lati maa beere itọsọna lọwọ Rè̩, oun i ba ti ni anfaani lati gbadun ijọba alaafia fun ọjọ pipé̩. S̩ugbọn lai pẹ, o bẹrẹ si i maa ro bi oun yoo ṣe le mu ki awọn eniyan naa maa tẹriba fun oun titi. Ọlọrun ti fi itẹ fun un, dajudaju Ọlọrun funra Rè̩ ni i ba ṣe eyi fun un pẹlu. Dipo ti i ba fi gbé̩kè̩lé Ọlọrun, o bè̩rè̩ si i ṣeto ni ọna ti rè̩ bi oun yoo ṣe le ṣakoso lọna ti rè̩, o si kó ara rè̩ sinu wahala.

Ọpọlọpọ ninu awọn wahala wa ni o n de ba wa ni ọna bayii. A maa n fẹ lati ṣe eto igbesi-aye wa ju pe ki a fara balẹ tẹle eto Ọlọrun fun wa, nitori eyi a maa n jiyà. Ọlọrun mọ ohun ti o dara fun wa ju bi awa ti mọ lọ; a le gbà ara wa lọwọ ọpọ ibanujẹ bi a bá le maa beere itọsọna Oluwa ninu ohun gbogbo.

È̩ṣẹ Jeroboamu

Olu-ilu ijọba Rehoboamu ni Jerusalẹmu; Jeroboamu rò ninu ara rè̩ pé bi awọn Ọmọ Israẹli bá lọ si Jerusalẹmu lọ jọsin, wọn le tun tẹle Rehoboamu lẹyin, ki wọn si fi oun Jeroboamu silẹ. O rò pe oun le pa awọn eniyan naa mọ kuro lọdọ Rehoboamu nipa ṣiṣe pẹpẹ isin kan si itosi ki awọn eniyan naa má tun lọ si Jerusalẹmu mọ. O yá ẹgbọrọ malu meji o si gbé wọn kalẹ fun awọn eniyan lati maa bọ. O sọ fun awọn Ọmọ Israẹli pe: “Wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wa!”

Njẹ o ranti ohun ti o ṣẹlẹ si awọn Ọmọ Israẹli ni igba kan ti wọn sin ere ẹgbọrọ malu? Ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni a fi oju ida pa ni ọjọ kan, Israẹli si jiya nipa ajakalẹ arun lẹyin eyi nì. Ọlọrun wi fun wa pe Ọlọrun owú ni Oun ati pe Oun fẹ ki a sin Oun, ani Oun nikan.

Ẹnikẹni ni o mọ pe ère ẹgbọrọ malu kò le mu awọn Ọmọ Israẹli jade lati Egipti nibi ti wọn ti jẹ ẹrú. Ẹgbọrọ malu ti o wà laaye paapaa kò tilẹ le ṣe e. Ire wo ni awọn ẹgbọrọ malu wura meji yii le ṣe fun Israẹli nisisiyi? Pẹlupẹlu Jeroboamu fi awọn eniyan alaiyẹ ṣe alufaa; o si pa ọjọ mimọ ajọ kan dà. Wọnyii ni nnkan ti Ọlọrun tikara Rè̩ ti yàn, ọmọ eniyan kò si lẹtọ lati yi i pada. Iṣe Jeroboamu jé̩ è̩ṣẹ niwaju Ọlọrun, bẹẹ ni buburu ti o ṣe si n tọ ọ lẹyin fun ọpọlọpọ ọdun siwaju si i. O fẹrẹ jẹ pe nigbakuugba ti a bá ti darukọ rè̩, ni a maa n sọrọ wọnyii pè̩lú: “Ẹniti o mu Israẹli dẹṣẹ.” Eyi ni iranti ti Jeroboamu fi silẹ fun ara rè̩ -- o mu Israẹli dẹṣè̩.

A le ṣalai ni agbara lori odindi ijọba orilẹ-ède kan bi ti Jeroboamu, ṣugbọn kò si ẹni ti o dẹṣẹ ti kò ni kó bá ẹlomiran. Kò si ẹni kan ti o wà laaye fun ara rè̩ nikan ṣoṣo; bi o ba si mú ẹlomiran dẹṣẹ, idajọ Ọlọrun yoo wa si ori rè̩.

È̩ṣẹ Rehoboamu

Rehoboamu pẹlu yipada si ibọriṣa. Nibẹ gan an laaarin ojiji Tẹmpili mimọ Ọlọrun ni o ṣe pẹpẹ fun ibọriṣa. Labẹ igi tutu, nibikibi ti awọn eniyan ba fẹ ni aworan awọn ọlọrun keferi wà.

Ọlọrun kò jẹ ki è̩ṣẹ naa rekọja lai si ijiya. Ni nnkan bi ọdun marun-un lẹyin ti Rehoboamu jọba, S̩iṣaki, ọba Egipti wa pẹlu ẹgbaafa (1,200) kẹkẹ ogun, ọkẹ mẹta (60,000) awọn ẹlẹṣin, ati ọpọlọpọ eniyan ti a kò le kà lati bá Juda ja. Wọn wọ ilu naa lọ taara, wọn si ṣẹgun awọn ilu olodi paapaa pẹlu. S̩ugbọn nigba ti ogun awọn ara Egipti bẹrẹ si sun mọ Jerusalẹmu, Rehoboamu pinnu pe akoko to lati ṣe nnkankan. S̩ugbọn ki ni o le ṣe?

Woli Ọlọrun kan wa ni Juda, o si wá sọ ọrọ Oluwa fun Rehoboamu pe: “Ẹnyin ti kọ mi silẹ, nitorina li emi si ṣe fi nyin silẹ si ọwọ S̩iṣaki.” Eyi ni o ṣe okunfa idaamu ti o de ba Rehoboamu ati Juda: wọn ti fi Ọlọrun silẹ. Ohun ti o tọna ti wọn si le ṣe nisisiyi ni pe ki wọn pada sọdọ Ọlọrun.

Rehoboamu ati awọn ijoye rè̩ rẹ ara wọn silẹ niwaju Oluwa, wọn si wi pe, “OLUWA li olododo.” Nigba ti Ọlọrun ri i, O yara fun wọn ni idasilẹ. O wi bayi pe ọba S̩iṣaki ki yoo pa wọn run, ṣugbọn wọn o maa sin in. Fun igba diẹ ohun gbogbo n lọ deedee ni Juda, ṣugbọn jalẹ gbogbo ọdun mẹtadinlogun ti Rehoboamu fi jọba ni ogun wà laaarin Jeroboamu ati Rehoboamu. Nigba ti Rehoboamu kú, Abija, ọmọ rè̩ ọkunrin jọba lori Juda.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Darukọ ọmọ Sọlomọni ti o jọba lẹyin rè̩.
  2. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi wi pe Oun o mu apa kan Israẹli kuro lábé̩ idile Sọlomọni?
  3. Ki ni ṣe ti a kò gba gbogbo ijọba kuro lọwọ rè̩?
  4. Ọna wo ni Rehoboamu pinnu lati gba ṣe akoso awọn eniyan ninu ijọba rè̩?
  5. Ki ni aṣẹ Ọlọrun fun awọn olori ati awọn ti o n fẹ lati di eniyan nla?
  6. Awọn è̩yà wo ni a fun Rehoboamu lati ṣakoso?
  7. Ta ni a fi ẹya mẹwaa iyokù fun?
  8. Ọna wo ni ẹnikẹni le gbà ṣanfaani nipasẹ ibukun Ọlọrun?
  9. Ki ni è̩ṣẹ Jeroboamu?
  10. Iru iranti wo ni Jeroboamu fi silẹ fun ara rè̩?
  11. 2