Lesson 289 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mā gbé igbé iwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu yio farada inunibini”(II Timoteu 3:12).Cross References
I Ẹni Ti A Pe Ti A Si Yan
1. Stefanu ti o kun fun igbagbọ ati Ẹmi Mimọ ṣe ọpọ iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu, Iṣe Awọn Apọsteli 6:8; 2;17, 18; 4:29-31; 8:5-8
II Inunibini
1. Iṣẹ-iranṣẹ Stefanu mu ki a doju ija kọ ọ gidigidi, Iṣe Awọn Apọsteli 6:9-15; 24;5-9; 25:7; Marku 14:55-59
III Idahun Stefanu
1. Stefanu bori awọn ọta rè̩ nipa alaye ti o ṣe fun wọn lati inu Iwe Mimọ, Iṣe Awọn Apọsteli 7:1-53; 2:14-36; 17:22-32; 24:25; 26:28; Luku 21:12-15
2. Ni akoko idanwo rè̩ Stefanu ri ifarahan Jesu, eyi si fun un ni iwuri ati ikiya, Iṣe Awọn Apọsteli 7:55, 56; Ifihan 1;10-16; II Kọrinti 12:1
IV Iku Ajẹriku
1. Awọn akorira Ọlọrun pa Stefanu ninu irunu ti i ṣe ti ẹmi eṣu, Iṣe Awọn Apọsteli 7:54-60; 12:2; Ifihan 6:9; 20:4; 11:9, 10
2. Stefanu tẹle Apẹẹrẹ Oluwa rè̩ nipa gbigbadura fun awọn ọta rè̩, Iṣe Awọn Apọsteli 7:59, 60; Luku 23:34; Isaiah 53:7
Notes
ALAYÉẸri Ododo
Iwe itan ati Bibeli sọ fun ni pe itajẹsilẹ ati inunibini dojukọ Ijọ Ọlọrun lẹhin iku ati ajinde Kristi. Iwaasu awọn ọmọ-ẹhin Jesu ninu eyi ti wọn tẹnumọ ọn pe Jesu ni Kristi ti Ọlọrun rán gbe inunibini dide si wọn ni ọtun. Stefanu ti a ti yàn gẹgẹ bi ọkan ninu awọn diakoni iṣaaju di ajẹriku kinni ninu Ijọ Ajagun. Stefanu ti ṣe ọpọ iṣẹ àmì ati iṣẹ iyanu laarin awọn eniyan, aṣeyọri rè̩ si mu ki awọn kan ninu awọn ẹlẹsin awọn Ju dide lati yaró ikorira wọn si Ọlọrun lara rè̩ gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin Kristi.
Nigba ti wọn ko le ri ẹsun kan wa si Stefanu lẹsẹ, awọn akorira Ọlọrun wọnyi bẹrẹ si i lo ọgbọn arekereke awọn Farisi lati ko awọn olufisun ati ẹlẹri eke jọ. Dajudaju awọn wọnyi ko yatọ si awọn wọnni ti o wà ni Jerusalẹmu ti wọn kan OLUWA mọ agbelebu nitori ipa ọna kan naa ni wọn tẹle.
Nitori ti wọn ko le ko ẹmi ati ọgbọn ti Stefanu fi n sọrọ loju, awọn olufisun rè̩ fa a lọ siwaju ajọ igbimọ. Stefanu nikan ni o lọ siwaju awọn igbimọ yi lai si iranlọwọ tabi imọran ọrẹ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi i silẹ. S̩iwaju iku Jesu O ti sọ asọtẹlẹ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ nipa inunibini ti yoo de ba wọn O si ti kọ wọn ni ohun ti wọn ni lati ṣe. Apa kan ẹkọ naa lọ bayi pe: “Nwọn o nawọ mu nyin, nwọn o si ṣe inunibini si nyin, nwọn o fi nyin le awọn oni-sinagogu lọwọ, ati sinu tubu, nwọn o mu nyin lọ sọdọ awọn ọba ati awọn ijoye nitori orukọ mi . . . Nitorina ẹ pinnu rè̩ li ọkan nyin pe ẹ kị yio ronu ṣāju bi ẹ ó ti dahun. Nitoriti emi o fun nyin li ẹnu ati ọgbọn, ti gbogbo awọn ọta nyin ki yio le sọrọ-odi si, ti nwọn ki yio si le kò loju” (Luku 21;12-15). Jesu mu ileri yi ṣẹ lọpọlọpọ fun Stefanu bi o ti n sọ ti ẹnu rè̩ niwaju awọn ika ati ọta Ọlọrun wọnyi!
Iwe Mimọ sọ bayi nipa Jesu pe, “ẹni niwaju Pontu Pilatu, ti o jẹri ijẹwọ rere” (I Timoteu 6:13), Ọlọrun si ran Stefanu lọwọ lati ṣe bẹẹ gẹgẹ. Gbogbo awọn ti o joko ni igbimọ tẹjumọ ọn, wọn si ri i pe oju rè̩ dabi oju angẹli.
Ọrọ Stefanu
Ọrọ Stefanu niwaju igbimọ awọn Ju jẹ iwaasu ti o yẹ ki olukuluku Onigbagbọ maa ka nigbakuugba. Dajudaju Stefanu ni imọ ti o ga nipa eto Ọlọrun fun Israẹli, o si dabi ẹni pe o ti kẹkọ pupọ ninu Iwe Mimọ. Bi o tilẹ jẹ pe awọn olufisun rè̩ n gbe ara wọn ga gẹgẹ bi ẹni ti n pa ofin Ọlọrun mọ, Stefanu ṣe alaye fun wọn yekeyeke ninu Ọrọ Ọlọrun to bẹẹ ti eyi jẹ idalẹbi fun wọn pe wọn ti kuna ninu iṣẹ wọn si Ọlọrun ati Ofin Rè̩. Stefanu sun gbogbo Israẹli ni ẹsun fun iwa ọdaran ti wọn ti n hu lati ayebaye eyi ti o de gongo nigba ti wọn kan Kristi mọ agbelebu, iwa buburu ti ko lẹgbẹ. Nipa ọgbọn ati itọni Ẹmi Mimọ Stefanu fi han pe olukuluku ni o lọwọ ninu ẹṣẹ yi ti wọn si jẹbi ẹsun ti o fi wọn sun. Nkan yi bìrí le awọn olufisun Stefanu lori, wọn ri ara wọn gẹgẹ bi ẹlẹbi niwaju Ọlọrun.
Nigba ti ara awọn olufisun wọnyi ko gba a mọ, wọn rọlu Stefanu lati sọ ọ ni okuta pa; ṣugbọn Ọlọrun ṣi Ọrun paya fun eniyan mimọ Rè̩ yi, iru eyi ti boya, ṣaaju rè̩ tabi lẹhin rè̩ ko ti i si ẹlẹran ara ti o ni iru anfaani bẹẹ. Bi Stefanu ti tẹjumọ Ọrun, o ri ogo Ọlọrun ati Jesu ti o duro li ọwọ ọtun Ọlọrun – iran agbayanu ti kò lẹgbẹ! Iwe Mimọ kò tun sọ igba miran fun wa ti Jesu duro lọwọ ọtun Ọlọrun.
Gẹgẹ bi ajumọ-jọba ati ẹni ti o dọgba pẹlu Ọlọrun Baba, Jesu yoo joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun gẹgẹ bi O ti sọ fun olori alufa pe Oun yoo ṣe (Matteu 26:64). Ọba n joko lori itẹ ni, awọn eniyan si ni lati dide lati juba Rè̩. Itumọ iduro ti Jesu dide duro nihin yi ni ati fi iyì ati ọlá fun akọni ninu igbagbọ yi ti o ti duro ti otitọ gbọningbọnin, lai fi ti awọn akorira Ọlọrun ti o yi i ka pè, bi o ti fẹrẹ to akoko fun un lati fi ẹmi rè̩ ṣe edidi ẹri rè̩.
Iku ajẹriku ti Stefanu ku fi Ijọ Ọlọrun igba ni lakalaka. Igboya ati akọ igbagbọ ti Stefanu ni ko ṣalai ṣe iṣẹ rere ninu ọkan ọkunrin kan ti a n pe ni Saulu ara Tarsu. Saulu lohun si iku Stefanu, o si dabi ẹni pe o jẹ ọkan pataki ti o rú ibinu awọn eniyan ti o sọ Stefanu ni okuta pa. Adura ti Stefanu tilẹ tun n gba fun awọn ti n pa a ku lọ tubọ ru Saulu ninu ṣùṣù si awọn ọmọ-ẹhin Jesu. Lai pẹ yoo tun gbe inunibini dide si awọn Onigbagbọ, ṣugbọn, nigbooṣe, Ọlọrun yoo yi i pada si igbagbọ Kristi.
Bi a ti n ṣe aṣaro nipa ti iṣoro ti o dide si Stefanu yi, adura Onipsalmu wa si iranti wa wi pe, “Bi emi tilẹ nrìn ninu ipọnju, iwọ ni yio sọ mi di āye: iwọ o nà ọwọ rẹ si ibinu awọn ọta mi, ọwọ ọtún rẹ yio si gbà mi. OLUWA yio ṣe ohun ti iṣe ti emi li aṣepe: OLUWA ānu rẹ duro lailai: máṣe kọ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ” (Orin Dafidi 138:7, 8). A mọ pe Ọlọrun kò kọ eniyan mimọ yi silẹ.
Ẹjẹ Awọn Eniyan Mimọ
Stefanu ni Kristiani kinni ti o ku iku ajẹriku. O dapọ mọ ẹgbẹ awọn olootọ lati ayebaye ti o fi igboya sọ ẹri wọn fun aye ti o kún fun awọn akorira Ọlọrun ati aṣodisi-Kristi, bi o tilẹ jẹ pe o gba wọn ni ẹmi wọn. Ki i ṣe awọn eniyan ti o fi ibinu kikoro pa Stefanu ni o kọ gba iru ọna bayi. Lati atetekọṣe ni Satani ti jẹ apaniyan, oun ko si ni jafara lati gbiyanju lati pa ẹnikẹni ti o ba lodi si ilana rè̩ lode oni.
Kaini, ọkan ninu ẹbi kinni ni aye fi owu kikoro pa Abẹli arakunrin rè̩ nitori ti Ọlọrun tẹwọgba ẹbọ Abẹli, ṣugbọn O kọ ẹbọ tirẹ. Kaini ro pe ohùn Ọlọrun ti n ba a sọrọ nipa aiṣedeedee rè̩ yoo dẹkun laelae bi oun ba pa arakunrin oun. Kaini mọ pe Abẹli jẹ apẹẹrẹ ododo Ọlọrun; Kaini si lero pe bi oun ba ti le gba ẹmi Abẹli, oun yoo pa idalẹbi ẹri-ọkan oun lẹnu mọ.
Awọn eniyan gba pe, “Ohun ti oju ko ba ri, ki i rin ni lara” ṣugbọn Ọlọrun ko ṣe e fi ọwọ rọ ti bẹẹ. Gẹrẹ ti Kaini pa arakunrin rè̩, o gbọ ohun Ọlọrun ti n beere pe, “Nibo ni Abẹli arakunrin rẹ wà?” Kaini ri i pe ko si ẹni ti o le fi ara pamọ fun ẹri-ọkan buburu tabi kuro loju Ọlọrun -- Ẹni ti oju Rè̩ ri ohun gbogbo. Ni ọdun pupọ lẹhin eyi, Onipsalmu kọ akọsilẹ ohun ti o fara jọ ọrọ yi pe “Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sare kuro niwaju rẹ? Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: ... Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun; Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si di mi mu. Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka, Nitõtọ òkunkun ki iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati okunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ” (Orin Dafidi 139:7-12).
Awọn è̩ṣẹ ayebaye ti a kò jẹwọ rè̩ ati ẹjẹ awọn alaiṣẹ ti awọn ogunlọgọ apaniyan ti ta silẹ lati igba ti aye ti ṣẹ ki yoo fara sin ninu iboji awọn ajẹriku lọkunrin ati lobinrin, awọn ti o gbekuta lati waasu otitọ Ọlọrun. Nigba ti awọn eniyan ba fi ibinu ṣùṣù ọrun apaadi dide si awọn eniyan mimọ Ọlọrun, ki wọn má ṣe gbagbe pe Ọmọ Ọlọrun paapaa ni wọn dide si bẹẹ. Jesu wi pe: “Bi aiye ba korira nyin, ẹ mọ pe, o ti korira mi ṣaju nyin ... Ibaṣepe emi kò ti wá ki ng si ti ba wọn sọrọ, nwọn kì ba ti li ẹṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn di alairiwi fun ẹṣẹ wọn. Ẹniti o ba korira mi, o korira Baba mi pẹlu” (Johannu 15:18, 22, 23).
Bibeli sọ fun wa pe awọṅ eniyan mimọ Ọlọrun gbe aworan Kristi wọ. (Ka Efesu 4:24; Kolosse 3:10). Ni ireti ati pa iranti ati aworan Kristi Olododo ti wọn korira run – eyi ti wọn n ri ninu igbesi-aye awọn enian mimọ -- awọn eniyan buburu gbiyanju lati pa awọn eniyan mimọ run, ṣugbọn lẹhin ti wọn ba ti ṣe eyi tan, wọn a ri i pe idalẹbi a gba ọkan wọn kan ju ti atẹhinwa lọ.
Aago Aiṣododo
Ni akoko ti o wọ, Ọlọrun yoo fi ẹri ti o daju ti ko si ṣe e ja-niyan han ni kikun fun aye ti o kọ Kristi yi ni ti ẹṣẹ ati ipaniyan wọn. Eyi yoo si tun jẹ ẹri lati fi han wi pe lai si Kristi, ọkan ọmọ-eniyan buru jai o si dibajẹ. Boya eyi jẹ eredi kan ti o mu ki Ọlọrun fi aye silẹ ki a pa awọn eniyan Rè̩ bi ajẹriku. Jesu sọ fun awọn oninunibini igba aye Rẹ pe, “Ẹnyin ejo, ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin o ti ṣe yọ ninu ẹbi ọrun apadi? Nitorina, ẹ kiyesi i, Emi rán awọn woli, ati amoye, ati akọwe si nyin: omiran ninu wọn li ẹnyin ó pa, ti ẹnyin o si kàn mọ agbelebu; ati omiran ninu wọn li ẹnyin o nà ni sinagogu nyin, ti ẹnyin o si ṣe inunibini si lati ilu de ilu: Ki gbogbo ẹjẹ awọn ọlõtọ, ti a ti ta ilẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati è̩jẹ Abẹli olododo titi de è̩jẹ Sakariah ọmọ Barakiah ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ” (Matteu 23:33-35).
Stefanu fi igboya waasu Kristi, ododo ati igbala kuro lọwọ ẹṣẹ. Nitori ti awọn akorira Kristi kò le ko Stefanu loju ni ti ẹsun ti o fi wọn sùn nipa iwa buburu wọn, wọn fi ìrunu kikoro kọlu u wọn si pa a ni ireti pe awọn yoo pa a lẹnu mọ. Lai pẹ jọjọ, Ọlọrun gbẹsan Stefanu lara wọn, nitori pe idajọ gbigbona Ọlọrun wa sori awọn Ju ti akoko naa. Iparun ti awọn ọmọ-ogun Romu pa Jerusalẹmu run ni ibẹrẹ imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu nipa idajọ ti n bọ wa sori wọn. Idajọ gbigbona naa yi ko tase awọn Ju, o si wa lori wọn titi di oni-oloni. Idajọ naa kò tii de opin sibẹ, ki yoo si dopin titi di akoko Ipọnju Nla nitori pe sibẹsibẹ wọn taku sinu aigbagbọ ati kikọ Jesu Kristi gẹgẹ bi Messia ati Ọba wọn ti n bọ wa.
Lode oni, a le ri i bi awọn orilẹ-ede miran ti n ṣe inunibini si awọn wọnni ti o jẹwọ igbagbọ ninu Kristi. A fi ye ni pe awọn wọnni ti a pa laarin ọdun melo kan sẹhin nitori ijẹwọ igbagbọ wọn ninu Kristi pọ ju ti akoko miran lọ. Ẹgbẹgbẹrun ọna ẹgbẹgbẹrun eniyan ni wọn pa ni ọdun diẹ sẹhin ni China ati Korea nikan. Akoko ti a n pa awọn Onigbagbọ bi ajẹriku ko i ti dopin, awọn eniyan Ọlọrun ni lati gbaradi lati fi ẹjẹ wọn ṣe edidi ẹri wọn bi o ba gba bẹẹ. Jesu wi pe, “Ọmọ-ọdọ kò tobi ju oluwa rè̩ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn o ṣe inunibini si nyin pẹlu” (Johannu 15:20). O tun sọ wi pe, “Iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ” (Ifihan 2:10).
Jesu wi pe ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmi rè̩ nu nitori Oun ati nitori Ihinrere yoo ri i gba pada. Stefanu sọ ẹmi rè̩ nipa ti ara nu nitori pe o n waasu Ihinrere lemọlemọ, ṣugbọn o ri iye ainipẹkun gba dipo rè̩. Nigba iṣoro ati ipọnju kikoro, o ri iran Ọrun, a si gbe e lọ siwaju Ọlọrun tikara Rè̩. Ileri Ọlọrun fun gbogbo eniyan ni pe bi a ba tilẹ sọ ẹmi wa nu nitori Ihinrere a o ri i gba pada. Iye ti kò nipẹkun yoo jẹ ti wa.
Questions
AWỌN IBEERE- Eeṣe ti awọn eniyan fi korira Stefanu?
- Tani ran Stefanu lọwọ ninu iṣoro rè̩?
- Bawo ni awọn olufisun Stefanu paapaa ṣe di ẹlẹbi niwaju Ọlọrun?
- Eeṣe ti Ọlọrun fi iran Kristi ninu ogo han Stefanu nigba idanwo rè̩?
- Eeṣe ti awọn ti o gbọ ọrọ Stefanu fi pa a?
- Eeṣe ti awọn eniyan buburu fi n fẹ lati pa awọn Onigbagbọ?
- Eeṣe ti a fi n pa awọn Onigbagbọ bi ajẹriku titi di oni-oloni?