Lesson 290 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rè̩ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọrọ mi mọ, nwọn ó si pa ti nyin mọ pẹlu” (Johannu 15:20).Cross References
I Inunibini ati Itankalẹ Ihinrere
1. A tu awọn eniyan mimọ kaakiri Judea ati Samaria, Iṣe Awọn Apọsteli 8:1; 1:8
2. Paulu ṣe ọpọ iṣẹ ibi laarin Ijọ Ọlọrun, Iṣe Awọn Apọsteli 8:2-4; 26:9-12
3. Iṣẹ-iranṣẹ Filippi ni Samaria yọri si iyipada ọpọ ọkàn, Iṣe Awọn Apọsteli 8:5-8; Marku 16:15-18
II Iyipada Simoni nipa Iṣẹ-iranṣẹ Filippi
1. Simoni n ṣe iṣẹ oṣó laarin awọn ara Samaria, Iṣe Awọn Apọsteli 8:9-11
2. A gba awọn ara Samaria kuro lọwọ iṣẹ oṣo nipasẹ Ihinrere, Iṣe Awọn Apọsteli 8:12
3. Iṣẹ iyanu ti Simoni ri mu un lọkan pupọ, o si gbagbọ, Iṣe Awọn Apọsteli 8:13
III Ẹmi Buburu ti Simoni ni ati Iṣubu Rè̩
1. A rán Peteru ati Johannu lọ si ọdọ awọn ara ilu Samaria, awọn eniyan naa si gba Ẹmi Mimọ, Iṣe Awọn Apọsteli 8:14-17
2. Simoni mu owo wa fun wọn ki o ba le ni agbara lati maa fi Ẹmi Mimọ fun ni, Iṣe Awọn Apọsteli 8:18, 19
3. Peteru ba Simoni wi, Iṣe Awọn Apọsteli 8:20-25
Notes
ALAYÉSi Gbogbo Aye
“Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si mā wasu Ihinrere fun gbogbo ẹda” (Marku 16:15) ni iṣẹ ikẹhin ti OLUWA fi le awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lọwọ. (Wo Matteu 28:18-20 pẹlu). Niwọn bi iṣẹ yi ti jẹ ti gbogbo Onigbagbọ, a saba ma n pe e ni Aṣẹ Nla ti Jesu fi le awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lọwọ. Awọn ọmọ-ẹhin ti duro de ifiwọni agbara lati oke wá, Ẹmi Mimọ si ti ba le wọn gẹgẹ bi ileri Ọlọrun. S̩ugbọn o dabi ẹni pe wọn ko lọkan lati yọ ẹsẹ si ita rara. Ara ti tu wọn. Oluwa n wo awọn alaisan san, ọpọ si n ri igbala; wọn si n yọ nitori ohun nla ti Oluwa n ṣe ni orilẹ-ede wọn. Boya wọn tilẹ le beere pe, “Eeṣe ti a o fi isọji yi ti ina rè̩ n jo geregere nihin silẹ lọ si ilu okeere ti o kún fun wahala ati iṣoro?” S̩ugbọn Oluwa ti paṣẹ fun wọn pe, “Lọ”.
Inunibini
Igba gbogbo ni eṣu n gbiyanju lati bori Ijọ Jesu ati lati pa a run. Iwe itan sọ fun wa pe ẹgbaa Onigbagbọ ni a pa ni akọbẹrẹ inunibini ti o dide si Ijọ Ọlọrun. S̩ugbọn ohun ti Satani pinnu lati fi pa Ijọ Ọlọrun run gan an ni o pada di ohun-elo fun ifẹsẹmulẹ ati itankalẹ Ihinrere. Awọn Ju ko fẹ gba ẹkọ ajinde Kristi. Nitori naa, nigba ti awọn ọmọ-ẹhin Jesu n tẹnumọ ẹkọ yi, ti wọn si n fi otitọ rè̩ han, o di ẹbi nlá-nlà ru awọn Ju nitori ti wọn kan Messaiah wọn mọ agbelebu. Bi awọn Apọsteli ti n tẹnumọ ọran ajinde Kristi ati ẹbi awọn eniyan yi, ogun inunibini naa tubọ n le si i.
Inunibini ko ṣe idena fun Ijọ Ọlọrun nigba kan ri, kaka bẹẹ, Ijọ Ọlọrun a maa gberu, a si maa dagba si i ninu idanwo ati iṣoro bẹẹ. Nigba ti awọn okuta wọnni n ba Stefanu lọtun, losi, titi o fi “sun” Stefanu kò mọ pe iku rè̩ ni ibẹrẹ inunìbini ti yoo mu ki Ihinrere tan de ilẹ gbogbo. Boya oun paapaa ko mọ iru iṣẹ ribiribi ti iduro ṣinṣin rè̩ fun Ọlọrun yoo ṣe.
Saulu ẹni ti o gba aṣẹ lọdọ awọn olori, jẹ balogun awọn abinuku gbogbo awọn ọmo-ẹhin Kristi, o si n ṣe inunibini si wọn ni iha gbogbo. O tilẹ n wọ ile wọn kiri lati wọ wọn jade ati lati gbe wọn ju sinu tubu – bi o ti ri ni awọn orilẹ-ede pupọ ni nkan bi ọdun diẹ sẹhin.
Oluwa wi pe, “Nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sa lọ si omiran” (Matteu 10:23). Nitori naa wọn “lọ si ibi gbogbo, nwọn nwasu ọrọ na.” Eyi jẹ eto Ọlọrun lati tan Ihinrere kalẹ. Ẹni kan sọ pe awọn eniyan mimọ ti n sa kiri wọnyi dabi fitila pupọ ti a fi ina Ẹmi Mimọ tan, awọn wọnyi si n gbe itanṣan imọlẹ mimọ ti o ti kọ mọ si awọn paapaa yi kaakiri.
Ogun Ajakaye Keji
Ni iwọn ọdun diẹ sẹhin, pupọ ninu awọn ọdọmọkunrin wa ri ọwọ ipe Ọlọrun lara wọn. Wọn fẹ tan Ihinrere igbala kalẹ ki wọn si jẹ ki awọn ẹlomiran mọ ọna ti wọn le gba bọ lọwọ ẹṣẹ ati wahala wọn. Ninu ogun ajakaye keji yi, wọn lo anfaani ti o ṣi silẹ fun wọn lati jẹri fun Oluwa; bi wọn si ti n ja fun orilẹ-ede wọn, ni ilu okeere ati lọna jijin, wọn gbe igbesi-aye ọmọ Ọlọrun. Nipa ṣiṣe bẹẹ wọn fi han pe agbara Ọlọrun le pa Onigbagbọ mọ lai lẹṣẹ, o si le fun wọn ni aṣẹ ati itọni ti wọn n fẹ ninu iṣẹ-isin wọn fun Ọlọrun. Nitori ijolootọ wọn ati igbẹkẹle girigiri ninu Ọlọrun, wọn pada pẹlu ina Ọlọrun ninu ọkan wọn, pẹlu imurasilẹ ati ifẹ lati ṣe iṣẹ ti o yàn fun wọn lati ṣe, ibikibi ti o wu ki iṣẹ naa gbe wọn lọ.
Wiwaasu Ọrọ Naa
Ninu inunibini ti o dide si ijọ akọkọbẹrẹ yi, awọn ọmọ-ẹhin Jesu bẹrẹ si i waasu Ọrọ Ọlọrun kaakiri. A kò i ti i kọ awọn Ihinrere mẹrẹẹrin ati awọn Episteli nigba naa, ṣugbọn akọsilẹ Majẹmu Laelae ko ṣajeji si awọn ọmọ-ẹhin, wọn si n mu Ọrọ Ọlọrun yi lo lati waasu fun awọn ti o wa labẹ akoso wọn. S̩ugbọn koko ẹkọ wọn duro lori Jesu. Wọn n sọ awọn nkan wọnni ti Jesu ti kọ wọn fun awọn eniyan -- ọkan ninu ohun ti Jesu si kọ awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ ni pe Oun ni Messia naa ti a ti ṣeleri, Ọmọ Ọlọrun (Johannu 5:17-40).
Jesu ti kọ awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ nipa ibi titun (Johannu 3:1-16). O ti kọ wọn nipa ipadabọ Rè̩ lẹẹkeji ati Ijọba Rè̩ (Matteu 16). O ti kọ wọn lẹkọ nipa iwa mimọ ati ododo, O si ti gbadura fun isọdimimọ wọn (Johannu 17:1-26; Matteu 5:48). O ti kọ wọn nipa Olutunu ti n bọ wa ati agbara ti Ẹmi Mimọ yoo fi fun wọn (Johannu 14:15-18). O ti kọ wọn nipa ipadabọ Rè̩ lẹẹkeji ati Ijọba Rè̩ (Matteu 24). O ti sọ ti iku ati ajinde Rè̩ fun wọn – nkan wọnni si ṣẹ ni oju wọn korokoro. Ni kukuru, ohun gbogbo ti n bẹ ninu Iwe Mimọ ni wọn waasu rè̩ fun awọn ti o ti sọnu sinu aye ẹṣẹ.
Iribọmi ni Orukọ Jesu Oluwa
Filippi ọkan ninu awọn diakoni meje ti a yàn lati jẹ oluranlọwọ fun awọn Apọsteli, lọ si Samaria lati waasu Kristi fun awọn ara Samaria. Awọn ara Samaria gba ọrọ rè̩ gbọ, Oluwa si ṣe iṣẹ iyanu laarin wọn, ayọ pupọ si wa ni ilu naa, ọpọ ọkan ni a si ṣe iribọmi fun.
Akọsilẹ Ọrọ Ọlọrun sọ fun ni pe a ṣe iribọmi fun awọn ti o yi pada wọnyi “ni orukọ Jesu Oluwa.” Awọn ti o tako ẹkọ Ọrọ Ọlọrun nipa Mẹtalọkan ti lọ mọ iba ọrọ ṣoki yi, wọn si ti da a tumọ yatọ si bi a ti ṣe lo o laarin awọn ọrọ miran, pẹlu ọkàn lati tako ẹri Mẹtalọkan ti o daju ti o wa ninu ilana iribọmi ti Jesu fi lelẹ (Matteu 28:19). Eyi jẹ apẹẹrẹ bi Eṣu ati awọn ẹmẹwa rè̩ ti n ya Ọrọ Ọlọrun nipa si ohun ti o duro le lori gan an ti wọn si n lọ itumọ rè̩ lati gbe ẹkọ eke kalẹ.
Ohun ti a n fi ye ni ninu ẹkọ yi ni pe awọn eniyan yi, ti ko ti ni anfaani ẹkọ Ihinrere Jesu Kristi nitori ti wọn jẹ ara Samaria, ti wa di ọmọlẹhin Kristi ni tootọ nitori ti wọn “ti gba Ọrọ Ọlọrun.” O han gbangba nihin pe a kò sẹ ẹkọ Mẹtalọkan nitori ti a mẹnukan Ọlọrun Baba ati Jesu Kristi Ọmọ ninu ẹsẹ kan (Iṣe Awọn Apọsteli 8:12) ati pe ninu ẹkọ yi pẹlu a ri i ka bi wọn ti gbadura pe ki Ẹmi Mimọ wọ inu ọkàn awọn ti o ṣẹṣẹ yipada wọnyi, gẹgẹ bi O ti wọ inu ọkàn awọn ọgọfa ọmọ-ẹhin nì ní ọjọ Pẹntekọsti.
A pe iribọmi ni iribọmi “li orukọ Jesu Oluwa” nihinyi lati fi iyatọ si iribọmi ti Johannu Baptisti n ṣe. Bibeli fi iyatọ gbangba kedere saarin iribọmi ti i ṣe ti Johannu Baptisti ati ti Kristi, gẹgẹ bi a ti le ri i ninu Ọrọ Ọlọrun ti a o tọka si wọnyi.
Lọna kinni, iribọmi Johannu jẹ “baptismu ironupiwada fun imukuro ẹṣẹ” (Marku 1:4; Luku 3:3; Iṣe Awọn Apọsteli 13:24; 19:4), ṣugbọn eyi ti Jesu fi lelẹ wa fun awọn Onigbagbọ nikan, o si jẹ apẹẹrẹ igbesi-aye titun ti wọn ti bẹrẹ si i gbe nipa Ẹjẹ Jesu (Romu 6:1-6).
Awọn eniyan ti n gbọ iwaasu Jesu nigba ti O n sọ nipa ipo ti Johannu wa laarin awọn woli Majẹmu Laelae, pin si ipa meji. A ti baptisi awọn ti ipa kinni sinu “baptismu Johannu Baptisti,” Bibeli si sọ fun ni pe wọn “da Ọlọrun lare.” Awọn ti ipa keji ko ṣe baptismu Johannu, a si kọwe rè̩ pe wọn “kọ ìmọ Ọlọrun fun ara wọn” (Luku 7:29, 30). Bibeli sọ nibomiran pe awọn eniyan naa wa si “baptismu rè̩” (Johannu); yatọ si awọn ẹsẹ wọnni ti a tọka si ninu Bibeli, ibi pupọ ni a ti sọ nipa “baptismu Johannu” (Wo Matteu 21:25; Marku 11:30; Luku 20:4 fun apẹẹrẹ).
Pẹlupẹlu, nigba ti Paulu beere lọwọ awọn ọmọ-ẹhin ti o wa ni Efesu nipa ifiwọni Ẹmi Mimọ, wọn dahun pe baptismu Johannu nikan ni awọn mọ. Paulu si sọ fun wọn pe “ki nwọn ki o gba ẹniti mbọ lẹhin gbọ, eyi ni ni Kristi Jesu.” Ọrọ Ọlọrun sọ fun ni pe nigba ti awọn Onigbagbọ wọnyi ti o wà ni Efesu gbọ ọrọ lati ẹnu Paulu “a baptisi awọn naa pẹlu li orukọ Jesu Oluwa” (Iṣe Awọn Apọsteli 19:1-5).
Nipa eyi, a le ri i pe Ẹmi Mimọ n kọ ni pe iribọmi jẹ apa kan eto Ọlọrun fun wa ati fun idande wa. O n kọ wa pe lẹhin ti awọn ara Samaria ti ni iyipada ọkàn, a ṣe iribọmi fun wọn, ki i ṣe baptismu si ironupiwada gẹgẹ bi Johannu ti n ṣe bi ko ṣe iribọmi ti ẹni irapada gẹgẹ bi Kristi ti fi lelẹ. Iwe Mimọ kọ ni pe iribọmi ti Jesu Kristi fi lelẹ ni a n ṣe “li orukọ Baba ati ni ti Ọmọ ati ni ti Ẹmi Mimọ.” Igba kan ṣoṣo pere ni a n ri ẹni ti a baptisi sinu omi ki i ṣe nigba mẹta ọtọọtọ, igba kọọkan fun ẹni kọọkan ninu Mẹtalọkan. Nipa bayi a le ri i pe kò si otitọ ninu ijiyan yi pe a gbe eto iribọmi Kristi le orukọ mẹta ọtọọtọ ti Jesu n jẹ. Ẹkọ eke ti Satani gbe jade lati tan aye jẹ ni eyi jẹ.
Simoni Oṣo
Ọkunrin oṣo kan ti a n pe ni Simoni wa ni ilu Samaria, ti i maa ṣe oṣo ni ilu naa ti o si n mu ki gbogbo eniyan gba wi pe eniyan nla kan ni oun i ṣe. O ti n fi ọgbọn arekereke tan wọn jẹ tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti o ri i pe ododo ni iṣẹ iyanu ti Filippi n ṣe, ati pe a ṣe wọn nipa agbara Ọlọrun, ki i ṣe nipa ọgbọn arekereke ọmọ eniyan, oun pẹlu gbagbọ, a si baptisi rè̩. Pe iru eniyan bayi le gba Kristi gbọ ki o si ri igbala, jẹ iṣẹ iyanu pataki.
Riran Peteru ati Johannu
Nigba ti Ijọ ti o wà ni Jerusalẹmu gbọ pe awọn ara Samaria ti gba Ọrọ Ọlọrun, wọn ran Peteru ati Johannu jade lati ran Filippi lọwọ ninu isọji naa ati lati fi ẹsẹ awọn ara Samaria mulẹ ninu igbagbọ. Awọn Apọsteli sọ fun awọn ara Samaria nipa gbigba agbara Ẹmi Mimọ, nitori ti wọn mọ pe ileri naa wa “fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39). Awọn ara Samaria ti ri igbala a si ti sọ ọkan wọn di mimọ, eyi si ti fi ara han ninu igbesi-aye wọn. Nitori naa wọn lẹtọ lati wá ati lati gba Ẹbun Agbara nla ti Ọlọrun ti ṣeleri lati fi fun awọn eniyan ti o wà ni akoko yi.
Ipade Adura Nla
Awọn eniyan ti a ti dari ẹṣẹ wọn ji ti a si ti wẹ ọkan wọn mọ nipa ibuwọn Ẹjẹ iyebiye ti Jesu lẹẹkeji nikan ni a n fi Ẹmi Mimọ fun. Awọn iṣẹ oore-ọfẹ meji ti Ọlọrun wọnyi ni a n pe ni idalare ati isọdimimọ patapata. Peteru ati Johannu ri oju awọn ti o ṣẹṣẹ di ẹbi Ọlọrun wọnyi bi o ti n dan ati bi Ẹmi Ọlọrun ti fara han laarin wọn; wọn si ri bi ọkan wọn ti n poungbẹ lati tubọ ni ẹkunrẹrẹ Ọlọrun ni igbesi-aye wọn. Nitori naa awọn Apọsteli sọ fun wọn nipa Olutunu ti Jesu ti ran si aye lati tọ awọn eniyan Rè̩ si ọna otitọ gbogbo. Awọn ara Samaria fi tọkantọkan gba otitọ yi, ina adura nla si ran laarin wọn.
Wo bi inu Peteru ati Johannu yoo ti dun to lati ri bi awọn ara Samaria ti n fi aye wọn rubọ ti wọn si n jọwọ rè̩ lọwọ fun Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ pe awọn Ju korira wọn! Peteru ati Johannu di alabapin ninu ipade adura nla naa; bi wọn si ti n gbadura ti wọn gbe ọwọ le wọn, a fi Ẹmi Mimọ ati ina baptisi awọn ara Samaria wọnyi. Nitori ti ileri naa jẹ ti wọn ati ti awọn ọmọ wọn, ati ‘gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa o pe” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39), a mọ pe o wà fun awa naa loni pẹlu. Kò pin sọdọ awọn ọgọfa eniyan ti o wà ni yara oke nikan. Ki i ṣe awọn Ju ti o di Onigbagbọ nikan ni a fi fun. Ko pin sọdọ Ijọ akọkọbẹrẹ nikan. Iriri ologo yi wa fun gbogbo awọn ti a ti sọ ọkan wọn di mimọ -- Ju tabi Keferi – ti o fi gbogbo ọkan wọn ṣafẹri rè̩. Iwọ ha ti ri ileri Baba gbà lati igba ti iwọ ti gbagbọ?
Igbiyanju lati Ra Agbara Ọlọrun
Nigba ti Simoni oṣo ri iṣẹ agbara Ẹmi Mimọ, oun naa fẹ ni agbara yi. O ti pẹ ti o ti n mu ki eniyan gba pe oun jẹ ẹni nla, ti o lagbara lati ṣiṣẹ iyanu. Boya eredi rè̩ ti o fi n fẹ agbara yi ni pe o fẹ ki okiki ti oun ti ni tẹlẹ ri tubọ maa kàn si i. Bibeli wi pe, “Bi enia kan ba n ro ara rè̩ si ẹnikan, nigbati ko jẹ nkan, o ntàn ara rè̩ jẹ” (Galatia 6:3). Simoni ko wa agbara Ọlọrun lọna ti Bibeli la silẹ gẹgẹ bi awọn ara Samaria ti ṣe. O fẹ fi owo ra a. Boya Peteru ranti nigba naa ohun ti o ṣẹlẹ si Anania ati Safira. S̩ugbọn ko si ẹmi igbọjẹgẹ ati ifẹ owo ninu Peteru. O wi fun Simoni pe, “Ki owo rẹ ṣegbe pẹlu rẹ.”
Bi olukuluku alufa ti n waasu Ọrọ Ọlọrun lode oni ba le ni iru ẹmi Peteru, ki yoo si ẹni kan ninu Ijọ Ọlọrun ti yoo maa fi igbagbọ ṣe bojuboju lati maa lepa itẹiwaju iṣẹ oojọ rè̩. Peteru ko gba owo Simoni ki o si gba a lọwọ wi pe ọmọluwabi ni, ki o le maa ri ojurere rẹ, kaka bẹẹ Peteru ba Simoni wi lẹsẹkẹsẹ, o si wi fun un pe ki o ronupiwada iwa buburu rè̩ nitori ti ọkàn rè̩ ko ṣe deedee niwaju Ọlọrun.
A kò le fi ara pamọ niwaju Ọlorun. Ọlọrun ni “olumọ ero inu ati ete ọkan ... ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rè̩ ẹniti awa ni iba lo” (Heberu 4:12, 13). A ko sọ fun wa boya Simoni ronupiwada ẹṣẹ rẹ tọkantọkan ṣugbọn o bẹ Peteru ki o gbadura pe ki ọkan ninu idajọ naa ki o má ṣe ba oun. Bibeli kilọ fun ni wi pe, “Jù gbogbo ohun ipamọ, pa aiya rẹ mọ; nitoripe lati inu rè̩ wá ni orisun ìye” (Owe 4:23).
Questions
AWỌN IBEERE- Tani ẹni kan pataki ti n ṣe inunibini si awọn Onigbagbọ ni akoko yi?
- Tani mu Ihinrere lọ si Samaria?
- Ẹni kan pataki wo ni o yipada ni ilu naa?
- Tani a ran lati Jerusalẹmu lati ṣe iranlọwọ ninu isọji yi?
- Iriri nla wo ni awọn eniyan mimọ ti o wà ni Samaria ri gba lọwọ Ọlọrun ni akoko yi?
- Kin ni Simoni oṣo fẹ ṣe?
- Kin ni esi ti Peteru fi fun Simoni?