Orin Dafidi 46:1-11; 90:1-17

Lesson 291 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Jẹ ki ẹwà OLUWA ỌLỌRUN wa ki o wà lara wa: Ki iwọ ki o si fi idi iṣẹ ọwọ wa mulẹ lara wa, bḝni iṣẹ ọwọ wa ni ki iwọ ki o fi idi rè̩ mulẹ” (Orin Dafidi 90:17).
Cross References

I Igbẹkẹle Gbogbo Onigbagbọ

1. Ibẹru ki i daamu ọmọ Ọlọrun tootọ, nitori pe Ọlọrun ni aabo ti o daju, Orin Dafidi 46:1-3; I Johannu 4:18

2. Ihinrere fi ìye kikun fun ni, Orin Dafidi 46:4, 5; Johannu 10:10

3. Awọn ọta eniyan Ọlọrun pọ pupọ, ṣugbọn Ọlọrun mu awọn eniyan ti Rè̩ bori, Orin Dafidi 46:6-9

4. Awọn ti o duro de Oluwa yoo mọ Ọn dajudaju, Orin Dafidi 46:10, 11; Ẹksodu 14:13; Isaiah 40:31

II Ọlọrun Akoko ati Ayeraye

1. Ọjọ Ọlọrun ko lopin, Orin Dafidi 90:1, 2

2. A ke ọjọ aye ọmọ-eniyan kuru lori ilẹ aye nitori ẹṣẹ rè̩, Orin Dafidi 90:3, 5-9

3. Ẹgbẹrun ọdun ko to nkankan niwaju Ọlọrun, Orin Dafidi 90:4

4. A kọ eniyan lati maa ka iye ọjọ rè̩, Orin Daidi 90:10-12

5. Ọlọrun fi ẹwà tootọ ti n bẹ ninu ìye han fun gbogbo ẹni ti o fẹ ẹ, Orin Dafidi 90:13-17

Notes
ALAYÉ

Aabo ti O Daju

Ọlọrun ni lọwọlọwọ iranlọwọ fun gbogbo awọn ti o ba gbẹkẹle E. Igba miran wà ti yoo dabi ẹni pe gbogbo aye dojuja kọ ẹni ti o fẹ Ọlọrun ti o si n sin Ọlọrun, ṣugbọn bi o ba ṣe aṣaro nipa agbara Ọlọrun, ipa Rè̩, ati ifẹ ti O ni fun ire ọkàn ọmọ-eniyan, ọlè̩ igbagbọ yoo sọ ninu ọkàn rè̩ ti yoo sọ awọn oke wahala ati iṣoro naa di ilẹ. Onipsalmu ati awọn eniyan ti a n sọrọ nipa rè̩ ninu Orin Dafidi kẹrindinlaadọta yi dabi ẹni pe wọn ti bori oke iṣoro kan ti o dide si alaafia orilẹ-ede wọn. O le jẹ pe ogun ajeji kan ni o dide si wọn; nitori pe ni Ilu Ọlọrun -- Jerusalẹmu, ni a gbe kọ Psalmu yi; ṣugbọn a ko gba ilu naa ni akoko yi nitori pe Ọlọrun ni aabo ati agbara wọn; ọwọ agbara Rè̩ si dide fun iranwọ wọn ni akoko ti o wọ, o si gba wọn kuro ninu iṣé̩ wọn.

Igbagbọ aaye ni awọn eniyan wọnyi ni; iru igbagbọ bẹẹ yoo mi ọwọ Ọlọrun lọjọ oni lati ṣe iṣẹ iyanu nlá nlà fun awọn wọnni ti o ba ke pe E tinutinu wọn. Psalmu yi sọ fun ni nipa isẹlè̩, iji lile loju omi ati ninu afẹfẹ, sibẹ akewi yi sọ fun ni wi pe ẹru kò ba awọn eniyan naa. Igbagbọ ati igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun ayeraye ni o fi ọkan wọn balẹ. Boya titobi ewu nlá nlà ti o dojukọ wọn ti o dabi eyi ti wọn kò ni le bori ni o mu ki igbagbọ wọn gbooro ki o si rọ mọ Ọlọrun bẹẹ. Nigba ti ẹda ba sún kan ogiri ti o ba si ke pe Ọlọrun, nigba naa Ọlọrun a ni anfaani lati fi agbara Rè̩ han. Agbara Ọlọrun a maa han kedere nigba ti agbara ẹda ba pin.

Onipsalmu wi pe: “Nitorina li awa ki yio bẹru, bi a tilẹ ṣi aiye ni idi, ti a si ṣi awọn òke nla nipò lọ sinu okun.” Boya eyi jẹ apẹẹrẹ bi wahala wọn ti dabi ẹni pe o pọ to. S̩ugbọn ọjọ kan n bọ, ki yoo si pẹ mọ, ti ọrọ wọnyi yoo ṣẹ gan an ninu ayé: “Ọjọ Oluwa mbọwa bi ole li oru; ninu eyi ti awọn ọrun yio kọja lọ ti awọn ti ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yio si ti inu oru gbigbona gidigidi di yiyọ, aiye ati awọn iṣẹ ti o wà ninu rè̩ yio si jóna lulu” (II Peteru 3:10). Kiki awọn ti o ni igbagbọ aaye ninu Ọlọrun alaaye nikan ni yoo là ni ọjọ naa. “Njẹ bi gbogbo nkan wọnyi yio ti yọ nì, iru enia wo li ẹnyin iba jẹ ninu ìwa mimọ gbogbo ati ìwa-bi-Ọlọrun?” (II Peteru 3:11).

Omi Iye

Laarin ilu Jerusalẹmu ni isun omi nla ti ki i gbẹ kan wà. Omi ti o gbooro ṣugbọn ti ko jin yi ṣan la aarin ilu kọja. Ni ti ọkọ títù, omi yi kò jamọ nkankan. Ohun ti o ya ni lẹnu ni pe bi Jerusalẹmu ti jẹ ilu pataki ati olokiki ka gbogbo aye to nigba ni, a ko gbe e ka ori omi ti a le tu ọkọ lori rè̩. Sibẹ nigba ti ogun ba do ti ilu, iru anfaani ti iru omi naa yoo ṣe ko kere. Orisun omi mimu ko gbọdọ bọ si ọta lọwọ, tabi ki wọn se e mọ si ẹhin odi ilu nitori ti ẹmi awọn eniyan rọ mọ ọn.

Odo S̩iloa le ṣalai jin to fun ọkọ ti o ni àjè̩, ṣugbọn iṣẹ ti o n ṣe tayọ eyi nì. Lati inu odo yi ni a ti la oju iṣan omi kaakiri igboro ni arọwọto gbogbo awọn olugbe Jerusalẹmu. Omi yi n bẹ larọwọto gbogbo ara ilu, lati tan oungbẹ wọn. S̩iloa jẹ apẹẹrẹ oore-ọfẹ Ọlọrun Israẹli ti ki i tase fun awọn eniyan Rè̩.

Ninu ọkan ninu awọn asọtẹlẹ nipa Messia ni a gbe ri ọrọ wọnyi: “Ọpá-alade ki yio ti ọwọ Juda kuro, bḝli olofin ki yio kuro lārin ẹsè̩ rè̩, titi S̩iloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ tirè̩” (Gẹnẹsisi 49:10). Ko ṣadede ṣẹlẹ pe ọkan ninu orukọ Ọmọ Ọlọrun ṣe gẹgẹ pẹlu orukọ isun omi yi ti ki i gbẹ ti o n ṣan ninu ilu Ọlọrun, nitori pe Jesu ni Orisun ibu aanu Ọlọrun ti o ṣi silẹ fun gbogbo olugbe aye. Ni ọjọ ikẹhin, ti i ṣe ọjọ nla ajọ, Jesu duro O si kigbe wi pe, “Bi orungbẹ bá ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu” (Johannu 7:37). Ibu oore-ọfẹ Ọlọrun ko dabi omi S̩iloa ti ko jinlẹ ṣugbọn ailopin ni. Woli Esekiẹli ṣe apejuwe odo ti n ṣan lati Ile Oluwa lọna bayi: “Odò ti nko le wọ; nitori omi ti kun, omi ilúwẹ, odò ti kò ṣe rekọja” (Esekiẹli 47:5). Oore-ọfẹ Ọlọrun ki i wọn awọn ti o ba ni ọkan lati ṣafẹri ati lati ri i gba.

Odi

Ni gbogbo aye ni a ti mọ Jerusalẹmu, Ilu Ọlọrun, bi odi alagbara. Ilu ti kò rọrun lati gba ni, nitori oke nla ti o yi i ka. Ibi aabo nla gidigidi ni ilu yi jẹ paapaa nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ba n sin Ọlọrun wọn ni ẹmi ati otitọ. Ni igba pupọ ni iru akoko bayi, Ọlọrun tikara Rè̩ ni n pa awọn ọta wọn run tabi ki O le wọn pada ki wọn to sunmọ ilu tabi ki wọn to fa ọrun wọn lati ta ọfa si i (Isaiah 37:33). Bi ọta tilẹ gbogun ti i, wọn ko ni le wọ inu ilu niwọn igba ti igbagbọ ati igbẹkẹle awọn ọmọ Ọlọrun ba wa ninu Rè̩.

Apejuwe daradara ti Onipsalmu ṣe nipa itẹdo ati ayika ilu yi ni itumọ pataki nipa ti ẹmi. Olukuluku Onigbagbọ ninu aye yi duro gẹgẹ bi odi otitọ lati kọjuja si agbara ibi ati awọn eniyan buburu ti o wa kaakiri ninu aye yi. Ọlọrun ti pese ihamọra ti ẹmi fun awọn ọmọ Rè̩ ninu aye yi, awọn ti o ba si gbe e wọ ni a fun ni anfaani lati ṣẹgun ẹṣẹ ati eṣu. Ọlọrun ti ṣe agbàra yi awọn eniyan Rè̩ ka gẹgẹ bi O ti ṣe fun Jobu (Jobu 1:10). Ko si iyọnu, ipọnju, idanwo tabi ohunkohun miran ti o le de ba ọmọ Ọlọrun, afi bi Ọlọrun ba gba a laye. Bi Ọlọrun ba gba awọn nkan wọnyi laye lati wọ inu ọgba ki o si wa sọdọ awọn ọmọ Rè̩, gẹgẹ bi O ti fi aye silẹ fun ipọnju lati de ba Jobu, sibẹ ọmọ Ọlọrun le ni idaniloju iṣẹgun bi igbagbọ ati igbẹkẹle rè̩ ba duro gbọningbọnin ninu Baba wa ti n bẹ ni Ọrun. Niwọn igba ti igbagbọ ati igbẹkẹle ba n bẹ ninu ọkan kan ti o si n gbe ojulowo igbesi-aye Onigbagbọ, ko si ohun-kohun ti o le bi ile iṣọ Ọlọrun ti o wà ninu ọkan rè̩ wó. Awa ju ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹni ti O fẹ wa (Romu 8:35-39).

Ọlọrun Ayeraye

Gbogbo ohun ti o wa ninu aye yi ni o ni ibẹrẹ ati opin; ṣugbọn Ọlọrun alagbara, ti o da aye ati ohun gbogbo ti o wà ninu rè̩, wa lati “ayeraye de ayeraye.” Oun kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọdun. O ṣoro fun eniyan ẹlẹran ara lati moye otitọ yi, paapaa ju lọ bi a ko ba ti i ra ọkan rè̩ pada ki o si ni irẹpọ pẹlu Ọlorun Ọrun.

Li atetekọṣe, a da eniyan ni aworan ati iri Ọlọrun, lai si aniani, iye ainipẹkun si jẹ ọkan ninu ogun ibi rè̩. A ko ha gbin Igi Iye sinu Ọgba Edẹni? Ọlọrun fi anfaani fun eniyan ti kò mọ ẹṣẹ lati jẹ ninu Igi Iye naa. S̩ugbọn è̩ṣẹ wọ inu ọkan ọmọ-eniyan, o si ti i jade kuro ninu ọgba, nipa bayi o sọ anfaani awọn ileri ati ibukun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun un ni ipo ailẹṣẹ rè̩ nu. Ẹṣẹ ninu ọkàn ọmọ-eniyan sọ ọ di ẹni kikú, nitori ti Ọlọrun ti kilọ fun wọn pe aigbọran si ofin Oun yoo yọri si iku; ṣugbọn iyipada ko si ni ti pe ẹmi rè̩ ki yoo kú. Ẹmi yoo wa titi aye ainipẹkun. Iku ara ki i ṣe iku ẹmi. Adamu gbe aadọrindinlẹgbẹrun (930) ọdun laye ṣugbọn o ku nitori ẹṣẹ ti o ti dá ni atetekọṣe. Lati igba yi ni ọjọ aye eniyan ti dabi ibu atẹlẹwọ, o n kere si i lati igba de igba. Onipsalmu sọ pe eniyan kò le lero lati gbe pupọ ju ọgọrin ọdun laye, otitọ si ni eyi titi di ọjọ oni.

O dabi ẹni pe ero wọnyi ni o gba ọkan ẹni ti o kọ Orin Dafidi aadọrun kan. Ayeraye ni Ọlọrun, bẹẹ si ni ẹmi olukuluku eniyan. Iru igbesi-aye ti eniyan ba gbe, ati bi ọkan rè̩ ba ti ri pẹlu Ọlọrun ati iru ihà ti o kọ si aṣẹ ati ilana Ọlọrun, ni o n fi iru ipo ti ẹmi oluwarẹ yoo wa ni ayeraye han. Onipsalmu tẹnu mọ otitọ yi pe kukuru ni ọjọ ọmọ-eniyan ninu aye, nitori eyi o gbọdọ lo anfaani ti o ba ni lati làkàkà lati wa oju Ọlọrun ni kutukutu. Ninu eyi nikan ni o ti le ri ire ti o tobi ju lọ laye. Awọn eniyan a maa fi ọna yi silẹ lati kọ wá ire lọna miran, ṣugbọn bi a ba fẹ ni itẹlọrun tootọ, ninu Ọlọrun ni a gbe le ni i nipasẹ Jesu Kristi ati Etutu ti O ṣe lori igi Agbelebu. “Bḝni ki iwọ ki o kọ wa lati mā ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọn” (Orin Dafidi 90:12). Oye ti a ni nipa iriri ninu aye yi tilẹ yẹ ki o kọ wa pe kò ṣanfaani lati maa lepa afẹ aye yi ti kò duro pẹ, nigba ti o jẹ pe ayọ ti o ga ju lọ ti eniyan ẹlẹran-ara le ni ninu aye yi ni irapada ọkàn rè̩ kuro ninu ẹṣẹ -- lati ri ojurere Ọlọrun ati lati ni idapọ pẹlu Ẹlẹda rè̩. Ki i ṣe itẹlọrun ati alaafia nikan ni iriri igbala ọkan n fun ni, o n fun ni ni ileri iye ainipẹkun pẹlu bi a ba jẹ olootọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eeṣe ti ọmọ Ọlọrun fi ni igboya bẹẹ?
  2. Kin ni ọjọ ori Ọlọrun?
  3. Ọdun melo ni i ṣe ọjọ kan niwaju Ọlọrun?
  4. Bawo ni Onipsalmu ṣe ṣapejuwe gigun ọjọ eniyan ni aye?
  5. Ọdun melo ni Onipsalmu pe akoko aye eniyan ni aye yi?
  6. Bawo ni iye ọdun ti Onipsalmu pe ni iye ọjọ wa ti jẹ otitọ to ni ode-oni?
  7. Igba wo ninu igbesi-aye rẹ ni o yẹ ki o bẹrẹ si wa oju rere Ọlọrun?
1