Lesson 292 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun ji i dide kuro ninu òku, a o gbà ọ là” (Romu 10:9).Cross References
I Iṣe-iranṣẹ Filippi si Iwẹfa ara Etiopia
1. A ti ọwọ angẹli kan ran Filippi lọ si iju nibi ti o gbe ba ọkunrin ara Etiopia kan pade, Iṣe Awọn Apọsteli 8:26-28
2. Ẹmi sọ fun Filippi pe ki o darapọ mọ ọkunrin naa ninu kẹkẹ, Iṣe Awọn Apọsteli 8:29
3. Iwẹfa yi n ka asọtẹlẹ nipa Kristi, Iṣe Awọn Apọsteli 8:30-33; Isaiah 53:7, 8
4. Filippi gùn le asọtẹlẹ naa lati waasu Jesu fun iwẹfa yi, Iṣe Awọn Apọsteli 8:34, 35
II Iyipada ati Iribọmi Iwẹfa naa
1. Iwẹfa naa beere pe ki a ṣe iribọmi fun oun, o n fi han pe a ti kọ ọ nipa aṣẹ Jesu lori ọran yi, Iṣe Awọn Apọsteli 8:36
2. A sọ fun un pe, “Bi iwọ ba gbagbọ tọkantọkan, a le baptisi rẹ”, Iṣe Awọn Apọsteli 8:37; 3:19; Marku 11:24; 16:15-18; Johannu 1:12; 3:14-16; 6:35; 12:46; Romu 1:16
3. Lẹhin iribọmi, iwẹfa yi n yọ bi o ti n ba ti rè̩ lọ, Iṣe Awọn Apọsteli 8:38-40; Romu 8:16; I Peteru 1:8; Orin Dafidi 51:12
Notes
ALAYÉFifi Isọji Silẹ
Filippi, ẹfangẹlisti, ọkan ninu awọn diakoni meje ti a yàn lati ran awọn Apọsteli lọwọ, wà nibi isọji agbayanu kan ni ilu Samaria. Ọpọ ọkan ni o ti gba Ọrọ Ọlọrun ti Filippi waasu rè̩ fun wọn gbọ ti wọn si n ṣe inudidun ninu ayọ ati alaafia ti wọn ṣẹṣẹ ri gba. A ran Peteru ati Johannu wa si Samaria lati ọdọ awọn Apọsteli iyoku, Ọlọrun si ti lo wọn gidigidi lati mu ki awọn ara Samaria lọ sinu awọn ẹkọ ati iriri ti o jinlẹ nipa ti Ẹmi. Peteru ati Johannu ti pada si Jerusalẹmu, nigba naa ni angẹli Oluwa ba Filippi sọrọ lati dide ki o si lọ si iha guusu.
Bi o ti ṣe pe ẹsẹ ni wọn fi n rin pupọ ju lọ nigba nì, a ri i pe irin ajo ti Ọlọrun pe Filippi lati rin yi ki i ṣe kekere. Filippi ni lati gba Jerusalẹmu kọja, ilu ti o ṣẹṣẹ fi silẹ ni lọọlọọ nitori inunibini. A ko sọ fun wa boya o duro lati ba awọn Apọsteli sọrọ nibẹ. Ohun ti a mọ ni pe o n ba ajo rè̩ lọ si iha guusu titi Ọlọrun fi paṣẹ fun un pe ki o da ara rè̩ pọ mọ kẹkẹ ninu eyi ti iwẹfa ara Etiopia kan wà.
Rírí Ọlọrun
Ọkunrin ara Etiopia oniṣẹ ọba yi ti lọ si Jerusalẹmu lati jọsin. O jẹ ẹni kan ti o ni ibẹru Ọlọrun ti ọkan rè̩ si n poungbẹ lati ni Ọlọrun ni igbesi-aye rè̩. S̩ugbọn gbogbo eto isin ti o ri ni Tẹmpili kuna lati tan oungbẹ ọkan rè̩. Melomelo ni awọn eniyan ti o ti wọ ile-isin nibi ti eto ati adabọwọ isìn gbe gbilẹ ṣugbọn ti ina Ọlọrun kò si, ti wọn si ti tun jade lọwọ ofo pẹlu ibanujẹ nitori ti Ẹmi ati agbara Ọlọrun ko si ninu ile-isin bẹẹ! Nigba kan ri ninu igbesi-aye awọn ọmọ Israẹli, Ogo Ọlọrun kun Tẹmpili ni Jerusalẹmu to bẹẹ ti awọn alufa kò le duro lati ṣiṣẹ isin wọn. Ni aipẹ ọjọ ṣaaju akoko ti iwẹfa yi wa si Jerusalẹmu, awọn alufa ti n bẹ ninu Tẹmpili kan naa yi ni o ṣe balogun agbajọ awọn eniyankeniyan ti n kigbe mọ Jesu wi pe, “kan an mọ agbelebu.” Wọn ti kọ Ọmọ Ọlọrun silẹ! Ifarahan Ọlọrun ko si laarin wọn mọ! Ijọ ti ko ba ni Kristi ti kú ikú ti ẹmi. Bakan naa ni pẹlu ọkan kọọkan; niwọn igba ti Kristi ba gunwa ninu ọkàn kan, ọkan naa yoo kun fun iye nipa ti ẹmi ati ireti; ṣugbọn nigba ti awọn ohun miran ba le Kristi jade, ọkàn naa yoo kú ikú ti ẹmi.
Oluwa yoo tẹ ọkan kọọkan ti ebi Ọlọrun ba n pa lọrun lọnakọna A ti ri iwe pupọ gba lati ọdọ awọn wọnni ti o ri iwe Igbagbọ Apọsteli he nibi ti o bọ si lọna jijin rére ni iha guusu Amẹrika nibi ti a ti n wà diamọndi. Wọn ko mọ bi awọn iwe wọnyin ti ṣe de ibi ti wọn ti ri wọn, ṣugbọn wọn ka wọn, ati nipa otitọ ti o wà ninu awọn iwe wọnyi, wọn ti ri Ọlọrun. Oluwa pe Filippi jade kuro ninu isọji nlánlà nitori ki ọkunrin kan ṣoṣo yi le ri igbala. Nitori ọkan kan ṣoṣo ti n poungbẹ lati gbe igbesi-aye mimọ, Ọlọrun yoo ran Otitọ yi gbogbo aye ka bi o ba gba bẹẹ, lati de ọdọ ọkan otitọ ti o n poungbẹ lati gbe igbesi-aye ti o dara.
Wiwá Otitọ
Nigba pupọ ni a maa n pe awọn ẹni ti o wà ni ipo ọla ni aafin ni “iwẹfa” bi o tilẹ jẹ pe wọn ki i ṣe iwẹfa nipa ti ẹda. Ọkunrin yi jẹ olori gbogbo iṣura Kandake, Ayaba Etiopia. O jẹ ẹni ti a fi ọkàn tan. S̩ugbọn o n wa ohun kan ti yoo fun ọkan rè̩ ni itẹlọrun. Lai si aniani, o ni ọpọlọpọ ọrọ aye yi; bi eyi ba le fun un ni itẹlọrun, oun ki ba ti lọ si Jerusalẹmu lati lọ jọsin. Oungbẹ ẹmi a maa mu ki eniyan lọ sihin ati sọhun lati wa itẹlọrun ti ọkàn wọn n fẹ. Ọpọ ọkàn ni ko mọ ohun ti o le tan oungbẹ yi; nitori eyi wọn a maa lepa afẹ aye yi lati té̩ ọkan wọn lọrun, nikẹhin wọn a rii pe asan ati imulẹmofo ni aye yi jasi. Ọlọrun nikan ni o le tẹ ọkàn ti ebi n pa lọrun.
Eyi ki i ṣe igba kinni ti a kọ kà nipa iwẹfa ara Etiopia ti i ṣe olododo ti o si n fẹ lati ṣe ifẹ Ọlọrun. Ninu ijọba Sedekiah, nigba ti awọn eniyan buburu gbe Jeremiah sọ sinu ọgbun lati rì sinu ẹrẹ, Ebedmeleki ara Etiopia ti i ṣe iwẹfa ninu ile ọba gbọ, o si lo anfaani ipo rè̩ lọdọ ọba lati jẹ ki a mu Jeremiah jade kuro ninu ọgbun naa. Ebedmeleki sọ aṣọ akisa fẹlẹfẹlẹ si Jeremiah ki o ba le fi i si abiya rè̩ nitori ki okùn ma ba bo o lara nigba ti wọn ba n fa a goke. Ko si ikorira orilẹ-ede lọkàn Ebedmeleki, nitoriti alawọ dudu ni oun, Jeremiah si jẹ Ju. Iwẹfa naa fẹran Jeremiah, o si bọlá fun un nitori ti i ṣe Woli Oluwa. Eniyan dudu yi ṣe iranwọ lati yọ Ju yi jade kuro ninu ọgbun! Ninu ẹkọ wa oni, a ri i pe Filippi ti i ṣe Ju ti a bi si ilu awọn Griki mu ọna ajo ti o jinna rere pọn lati sọ itan Jesu fun ara Etiopia kan.
Wiwaasu Jesu
Bi Filippi ti sunmọ kẹkẹ ni, o gbọ ti iwẹfa yi n ka iwe Isaiah ori kẹtalelaadọta eyi ti o jẹ iyanu. Wo anfaani iyebiye ti o ṣi silẹ lati sọ itan Jesu fun ọkunrin yi! Filippi ko jẹ ki anfaani yi bọ sọnu. Nigba ti iwẹfa naa ka ẹsẹ ti o wi pe, “A fàa bi agutan lọ fun pípa; ati bi ọdọ-agutan iti iyadi niwaju oluré̩run rè̩, bḝni ko yà ẹnu rè̩,” o fẹ mọ nipa ẹni ti Woli naa n tọka si. Lati ori iwe yi kan naa ni Filippi gbe bẹrẹsi waasu Jesu. Filippi fi han fun iwẹfa naa pe Jesu Kristi mu gbogbo asọtẹlẹ ti o wa ninu Majẹmu Laelae nipa Messia ti a ṣeleri rè̩ ṣẹ. Lai si aniani, bi o ti n tẹsiwaju ninu iwaasu rè̩, o ṣe alaye nipa gbogbo ẹkọ ti o wà ninu ẹsin igbagbọ fun un. Wọn kò ni ṣe alai sọrọ nipa ibi Jesu, igbesi-aye Rè̩, ẹkọ, iṣẹ iyanu, ijiya, ikú ati ajinde Rè̩ ati ilana iribọmi. Anfaani iyebiye ni eyi jẹ fun Filippi, boya o tilẹ ro ninu ara rè̩ pe oun ni lati mẹnu kan gbogbo ẹkọ Kristi ni ọjọ naa nitori pe oun le ṣe alai ni anfaani lati ri iwẹfa yi mọ.
Iwẹfa naa gba ọrọ Filippi gbọ; nigba ti wọn si de ibi omi, o fẹ ki a ṣe iribọmi fun oun. Filippi si wi pe, “Bi iwọ ba gbagbọ tọkantọkan, a le baptisi rẹ.” Eyi fi han dajudaju pe igbagbọ atọkanwa ṣe danindanin ninu ọran igbala. “Nitori ọkan li a fi igbagbọ si ododo; ẹnu li a si fi ijẹwọ si igbala” (Romu 10:10). Oluwa a maa ba ọkan lo, ṣugbọn lai si iyipada ti ọkan, ko le si iyipada patapata ninu iṣẹ ti ode ara . Eniyan le ṣe atunhu iwa diẹdiẹ, ṣugbọn oun ki yoo di “ẹda titun” titi Ọlọrun yoo fi dari irekọja rè̩ ji ti yoo si fun un ni agbara lori ẹṣẹ nipa È̩jẹ Jesu. Iwẹfa naa ni igbagbọ atọkanwa, o si fẹ ki a ṣe iribọmi fun oun. Jesu wi pe, “Ẹniti o ba gbagbọ, ti a ba si baptisi rè̩ yio la” (Marku 16:16).
Iribọmi
Iribọmi jẹ ami ode ara lati fi iṣẹ ti o ti ṣe ninu ọkan han. Ọpọlọpọ eniyan ni o gbagbọ nipa ero ọkan lasan ti a si baptisi wọn ni ireti pe omi yoo wẹ è̩ṣẹ wọn nu. S̩ugbọn lai pẹ wọn yoo rii pe ko si iyipada kan ninu ọkàn wọn nitori pe iṣẹ ara n bẹ ni igbesi-aye wọn gẹgẹ bi o ti ri ki a to baptisi wọn. Awọn miran n kọ ni pe iribọmi ki i ṣe danindanin, wọn si pa a ti patapata. A ti baptisi awọn miran nigba ti wọn wa ni ọmọ ọwọ; wọn si ro pe eyi ti to. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọun kọ wa pe a ni lati gbagbọ ki a to ṣe iribọmi. Iru igbagbọ ti a mẹnu ba nihin yi ni igbagbọ ti n mu idahun wa lati Ọrun, idaniloju pe a ti fi ẹṣẹ wa jì, ti igbesi-aye wa si ti yipada. Ami yoo tẹle iru igbagbọ bayi, Ẹmi Ọlọrun yoo si ba ẹmi oluwarẹ jẹri wi pe o ti di ọmọ Ọlọrun.
Awọn miran si n bẹ ti ko fẹ ki a ri wọn bọmi. Wọn gba pe ki a tu omi dà le wọn lori bi awọn paapaa ti wa ni ikunlẹ ninu omi. S̩ugbọn a ka a ninu Bibeli wi pe, “Tabi ẹ ko mọ pe gbogbo wa ti a baptisi sinu Kristi Jesu, a ti baptisi wa sinu ikú rè̩? Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ pẹlu rè̩: pe gẹgẹ bi a ti ji Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba, bḝni ki awa pẹlu ki o mā rin li ọtun ìwa. Nitori bi a ba ti so wa pọ pẹlu rẹ nipa afarawe ikú rè̩, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rè̩” (Romu 6:3-5).
Filippi ati iwẹfa lọ sinu omi. Filippi si ri iwẹfa naa bọmi. A mọ pe iwẹfa naa ti ni iyipada ọkàn tootọ, nitori pe o n ba ọna rè̩ lọ o si n yọ. O gbagbọ, o si pa aṣẹ Oluwa mọ, ẹrù rè̩ bọ. Igbọran yi nikan to lati fun un ni ayọ nla. Iwẹfa ara Etiopia yi ri ohun ti kò ri gba ninu adabọwọ eto isin ti wọn n ṣe ninu Tẹmpili ni Jerusalẹmu gba ninu aginju nipa iwaasu eniyan kan ṣoṣo ti o sọ itan igbala Ọlọrun fun un.
Kò si ẹgbẹ akọrin olohun didun lati kọrin iyin si Ọlọrun, ṣugbọn ayọ n bẹ ninu ọkàn awọn eniyan meji wọnyi ti wọn bu ọla fun Ọlọrun ti wọn si pa ofin Rè̩ mọ ni ọjọ naa ninu aṣalẹ ti o gbona janjan. A kò ri ohun amì kankan nipa eto isin kan pato ni ọjọ naa nipasẹ eyi ti a le fi dari ọkunrin ti o ronupiwada yi gẹẹ bi ọkan rè̩ ti n poungbẹ fun otitọ, ṣugbọn Ọlọrun wa nibẹ lati tọ ọ ati lati ran an lọwọ lati gbagbọ ati lati gba igbala ti a ti ṣeleri rè̩. A ko le diwọn Ọlọrun si ibi kan. O le ṣiṣẹ nibikibi. Bẹẹ ni kò si si ọna miran ti a le gba ha Ọlọrun mọ ki o ma le ṣiṣẹ. Ọlọrun le ṣiṣẹ pẹlu ẹnikẹni ti o ba le ṣi ọkàn oungbẹ rè̩ paya ninu adura rè̩ ti n lọ siwaju itẹ Aanu Ọlọrun.
Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ lati lọ si gbogbo aye, ki wọn si maa waasu Ihinrere fun gbogbo ẹda, “ki ẹ si mā baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ” (Matteu 28:19; Marku 16:15). Anfaani ologo ni lati pa gbogbo aṣẹ ati ilana Ọlọrun mọ; ayọ tootọ yoo si jẹ ti wa bi a ba ṣe bẹẹ. Iwẹfa nì n ba ọna rè̩ lọ, o n yọ. Bẹẹ gẹẹ ni yoo ri fun olukuluku Onigbagbọ ti o ba pa aṣẹ Jesu mọ ti a si ṣe iribọmi fun un nigba ti anfaani ba ṣi silẹ lẹhin ti o ti di atunbi.
Questions
AWỌN IBEERE- Tani Filippi? Iṣẹ wo ni a fun un ṣe nigba kan?
- Kin ni Oluwa sọ fun Filippi lati ṣe ni akoko yi?
- Tani Filippi ba pade ni aginju?
- Nibo ninu Iwe Mimọ ni iwẹfa yi n ka? Tani a n sọ nipa rè̩ lori iwe naa?
- Kin ni ibere ti iwẹfa naa fi siwaju Filippi?
- Bawo ni Filippi ṣe dahun ibeere ti iwẹfa naa beere lọwọ rè̩?
- Nigba ti wọn de ibi omi, kin ni iwẹfa naa fẹ ṣe?
- S̩e alaye ìru iribọmi ti Iwe Mimọ kọ ni nipa rè̩.
- Awọn wo ni o ni ẹtọ lati ṣe iribọmi? Eeṣe ti iribọmi kò wẹ è̩ṣẹ nu?
- Apẹẹrẹ kin ni iribọmi jẹ?