I Awọn Ọba 13:1-34; II Awọn Ọba 23:15-18

Lesson 293 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “S̩ugbọn Peteru ati awọn Apọsteli dahùn, nwọn si wipe, Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti enia lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:29).
Cross References

I Pẹpẹ Ẹṣẹ

1. Ọlọrun ran ọkunrin kan lọ si Bẹtẹli lati fi pẹpẹ oriṣa Jeroboamu bú, I Awọn Ọba 13:1; Hosea 8:11

2. Eniyan Ọlọrun naa sọ asọtẹlẹ iparun pẹpẹ naa, o si fi ami kan hàn, I Awọn Ọba 13:2, 3; Isaiah 7:14-16; Ẹksodu 3:12; Matteu 1:23

3. Jeroboamu doju-ìja kọ Woli naa, a si ti ọwọ Ọlọrun lu u, I Awọn Ọba 13:4, 5; Numeri 12:8-10; Iṣe Awọn Apọsteli 13:9-11

4. Ọwọ Jeroboamu pada bọ sipo nipasẹ adura ati ẹbẹ Woli naa, I Awọn Ọba 13:6

II Aigbọran

1. Woli naa kọ fun ọba lati ṣe oun ni alejo, I Awọn Ọba 13:7-10; Orin Dafidi 94:20; Efesu 5:11; Owe 23:6-8

2. Ọkunrin arugbo kan lati Bẹtẹli wa purọ fun Woli naa lati mu ki o ṣa aṣẹ Ọlọrun ti, ki o si tẹle oun, I Awọn Ọba 13:11-18; Matteu 26:74; Gẹnẹsisi 27:18, 19; Luku 22:48

3. Woli Ọlọrun naa gba irọ gbọ dipo Ọrọ Oluwa, I Awọn Ọba 13:19; Titu 1:10-16; Matteu 15:7-9; I Timoteu 1:6, 7; 4:2; 6:3-5; II Timoteu 4:3, 4; II Peteru 2:1-3

III Idajọ

1. Eniyan Ọlọrun naa gbọ ọrọ Oluwa ti a ran si i pe oun ki yoo de opin irin-ajo rè̩ nitori aigbọran rè̩, I Awọn Ọba 13:20-22; I Samuẹli 13:13, 14; 15:22, 23

2. A mu idajọ Ọlọrun wa si ori eniyan Ọlọrun naa, I Awọn Ọba 13:23-25; Lefitiku 10:3; Numeri 20:2, 24; I Samuẹli 4:18; Iṣe Awọn Apọsteli 5:1-10

3. A sin eniyan Ọlọrun naa lati ọwọ woli eke naa ti o pe ara rẹ ni arakunrin eniyan Ọlọrun naa, I Awọn Ọba 13:26-32

4. A mu idajọ ṣẹ nipa pẹpẹ Jeroboamu ati ile rè̩ gẹgẹ bi asọtẹlẹ ti a ti sọ, I Awọn Ọba 13:33, 34; II Awọn Ọba 23:15-18; Isaiah 46:5-11

Notes
ALAYÉ

Ibọriṣa ati Aigbọran

Ẹkọ wa nipa pẹpẹ Jeroboamu ati Woli alaigbọran niyelori pupọ fun awọn Onigbagbọ ti ode-oni. Ninu ẹkọ yi a tun ran wa leti pe “Ọlọrun ki iṣe ojuṣaju enia” (Isẹ Awọn Apọsteli 10;34) ati pe idajọ mimuna Rè̩ yoo wa sori awọn ti Rè̩ ti o ba dẹṣẹ gẹgẹ bi yoo ti wa sori awọn abọriṣa. Ọrọ Woli Samuẹli nigba ti o ba Saulu wi nitori ti o kọ ọrọ Oluwa fara jọ ẹkọ yi: “OLUWA ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gba ohun OLUWA gbọ? Kiyesi i, igbọran sàn ju ẹbọ lọ, ifetisilẹ si sàn jù ọra àgbo lọ. Nitoripe ìṣọtẹ dabi ẹṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi ìwa buburu ati ìbọriṣa” (I Samuẹli 15:22, 23).

Ọna meji ti idajọ Ọlọrun gba sọkalẹ ninu ẹkọ yi jẹ ohun afiyesi gidigidi nitori pe idajọ naa sọkalẹ nitori ẹṣẹ buburu meji: ekinni ni ibọriṣa; ekeji ni igbọjẹgẹ pẹlu aigbọran si Ọrọ OLUWA. A ti kọ ninu awọn ẹkọ wa atẹhinwa pe Ọlọrun ko gba fun awọn eniyan Rè̩ lati lọwọ ninu ìbọriṣa rara. Ifẹ Ọlọrun ni pe ki awọn eniyan Israẹli ki o jẹ “MIMỌ SI OLUWA,” nitori eyi wọn ni lati ya ara wọn sọtọ fun Oluwa ati ohun ti i ṣe ti Rè̩. Ko si ọna miran bi ko ṣe pe ki Ọlọrun ran idajọ Rè̩ wa sori gbogbo isìn ibọriṣa iru eyi ti Jeroboamu gbe kalẹ. O mọọmọ gbe pẹpẹ oriṣa naa kalẹ lati yi ọkàn awọn Ọmọ Israẹli pada kuro ninu ìsìn Jehofa ki o ba le tẹ ilepa ti o ni lọkàn ara rè̩ lọrun. Wiwa ti eniyan Ọlọrun wa lati kigbe mọ pẹpẹ è̩ṣẹ yi, ti o si fi ami idajọ Ọlọrun ti o n bọ wa hàn, ni igba ikẹhin ti Ọlọrun yoo ran ikilọ si ọba buburu ati apẹhinda ti iye rè̩ ti ra yì. A saba maa n sọ wi pe iṣisẹ meji ni eniyan n gbe ki o to kuro ninu igbagbọ patapata: ẹni naa yoo kọ kọ Ọlọrun silẹ, lopin rè̩, Ọlọrun yoo kọ oun naa silẹ. Idajọ ni igbesẹ ti o kẹhin ti Ọlọrun fi n ba eniyan lo; ni ti Jeroboamu ọjọ aanu rè̩ fẹrẹ de opin.

Ko si Igbọjẹgẹ

Nigba ti iranṣẹ Ọlọrun yi n jiṣẹ ti a fi le e lọwọ, Ọlọrun sọ fun un pe, “maṣe jẹ onjẹ, ma si ṣe mu omi, bẹni ki o ma si ṣe pada li ọna kanna ti o ba wa.” Nigba ti ọba rọ Woli yi lati ba a lọ si ile, Woli naa kọ, ohun ti o tọna si ni eyi. S̩ugbọn o ṣe ni laanu pe Woli Ọlọrun naa ko kọ jalẹ lati ṣe alabapin ninu ounjẹ awọn abọriṣa wọnyi. Oluwa sa ti wi pe, “Nigbati emi o wi fun olododo pe, yiyè ni yio ye; bi o ba gbẹkẹle ododo ara rè̩, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rè̩ li a ki yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rè̩ ku” (Esekiẹli 33:13).

Woli agba kan ti o n gbe Bẹtẹli le Woli yi ba bi o ti joko labẹ igi oaku kan; ọgbẹni yi si fi ẹtan mu Woli yi ba a pada. Igbọran di è̩ṣẹ! Nigba ti Woli naa si n jẹ ounjẹ ọgbẹni yi, ọrọ Oluwa tọ Woli yi wa wi pe iku ni ere aiṣedeedee rè̩. Eniyan Ọlọrun ti o ṣubu sọwọ ẹtan woli eke yi le ṣai jẹ ẹni iṣaaju ti o ṣubu bẹẹ, ṣugbọn o jẹ apẹẹrẹ ohun ti o n ṣẹlẹ si ẹni ti o kọ otitọ Ọlọrun silẹ lati gba eke gbọ. Ọkan ninu awọn ọna ti o buru ju ti Eṣu n lo lati pa ọkàn ọmọ-eniyan run ni lati fi ara rè̩ han bi Ojiṣẹ Ọlọrun. Igba pupọ ni o n wá gẹgẹ bi angẹli imọlẹ; ko ya ni lẹnu bi awọn iranṣẹ rè̩ ba pa ara wọn da bi angẹli imọlẹ (II Kọrinti 11:14, 15).

O yẹ ki a tẹnumọ ọn gidigidi wi pe iṣina ni lati maa tẹle àla, ìran, isọtẹlẹ, iṣipaya, ati awọn ohun miran ti awọn eniyan n pe ni ifarahan Ẹmi Ọlọrun lai gbe wọn ka ori Ọrọ Ọlọrun. Ọrọ Ọlọrun ni iran ati ifarahan ti o ga ti o si pe ju lọ ti Ọlọrun yoo gba fi ba eniyan lo titi Oun yoo tun fi pada wa. “Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni” (Isaiah 8:20).

Nigba miran Ọlọrun a maa tọ awọn eniyan ti Rẹ lọna iyanu ati awamaridi, gẹgẹ bi O ti ṣe ṣamọna awọn Ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti pẹlu awọsanma ni ọsan ati ọwọn ina li oru; ṣugbọn nigba ti O ba lo awọn nkan wọnni, wọn ki i lodi si Ọrọ Ọlọrun. Ọlọrun ni yoo jẹ ẹni ayinlogo ninu awọn nkan wọnyi; wọn ki i si tako ohun ti Ọlọrun sọ ninu Ọrọ Rè̩. Ogunlọgọ awọn woli eke ni n bẹ ninu aye loni, awọn iranṣẹ Eṣu, gbogbo wọn ni n fọwọ sọya pe wọn ni ẹbun ẹmi pataki ti o kàmama ati pe wọn ni imọ pataki nipa ifẹ Ọlọrun, iru eyi ti a ko ri ka ninu Bibeli. Ọpọlọpọ ni a ti tanjẹ lati tẹle awọn woli eke wọnyi lẹhin nitori ọrọ didun ati ahọn ipọnni wọn gẹgẹ bi o ti ri fun Woli ti a ka nipa rè̩ ninu ẹkọ wa yi.

Biba Iṣẹ Eṣu Kẹgbẹ pọ

Ki i ṣe pe eniyan Ọlọrun ti o yipada kuro ninu ofin Oluwa lati maa tẹle awọn ti n sọ eke dẹṣẹ nikan, ṣugbọn o di alabapin ninu iwa buburu ẹni ti o n ba kẹgbẹ. O fi apẹẹrẹ buburu lelẹ gbangba nipa jijẹ ninu ounjẹ woli eke ni ati nipa idapọ pẹlu rè̩. O n di ọgbun ti o wa laarin ara Kristi tootọ ati awọn nkan wọnni ti i ṣe eke ati ibi ti o fi ẹsin ṣe bojuboju. Ko tọna fun awọn ọmọ Ọlọrun lati ni idapọ pẹlu awọn wọnni ti n fi ẹnu nikan jẹwọ pe ọmọ-ẹhin Kristi ni wọn i ṣe ṣugbọn ti wọn ki i ṣe bẹẹ. Paulu kọwe si Ijọ Efesu pe, “Ẹ má si ba aileso iṣẹ okunkun kẹgbẹ pọ, ṣugbọn ẹ kuku mā ba wọn wi” (Efesu 5:11). Johannu Ayanfẹ kọwe si awọn eniyan mimọ pe “Bi ẹnikẹni ba tọ nyin wá, ti ko si mu ẹkọ yi wá, ẹ máṣe gba a si ile, ki ẹ má si ṣe kí i. Nitori ẹniti o ba kí i, o ni ọwọ ninu iṣẹ buburu rè̩” (II Johannu 10, 11). (Ka Galatia 1:8). Dajudaju ọgbẹni agba ara Bẹtẹli yi ko mu otitọ wa fun Woli Ọlọrun ṣugbọn o purọ fun un.

Ki i saba rọrun fun ẹni ti o ti mọ otitọ Ọlọrun, ṣugbọn ti o yipada lati gba ẹtan eṣu dipo Ọrọ Ọlọrun, lati pada si igbagbọ otitọ ninu Kristi. Pupọ ẹsẹ Iwe Mimọ ni o kilọ fun awọn eniyan kikankikan nipa ewu ati idajọ ti o wà fun gbogbo awọn ti o kọ otitọ Ọlọrun silẹ lati tẹle eke Satani. Ọlọrun ti kilọ tẹlẹ fun Woli Rè̩ nipa ohun ti o le ṣẹlẹ, ki o ma ba baa ni airotẹlẹ eyi si fa ibinu Ọlọrun wa sori rè̩, gẹgẹ bi O ti kilọ fun Adamu ati Efa ninu Ọgba Edẹni pe ọjọ ti wọn ba jẹ ninu igi ìmọ rere ati buburu ni wọn yoo ku. Ẹkọ yi fi han fun ni pe Woli Ọlọrun yi gba ikilọ yi gbọ nitori pe o kọ fun Jeroboamu lati ṣe e ni alejo. Nigbooṣe o kọ ikilọ naa nitori pe ẹni kan sọ fun un wi pe Ọlọrun ran oun ni iṣẹ si i, eyi ti Woli yi paapaa ko mọ nipa rè̩.

Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun a maa jẹ ki ifẹ Rè̩ di mimọ fun olukuluku ọmọ Ọlọrun nipa Ẹmi Rè̩ ati Ọrọ Ọlọrun, O tun le jẹ ki ifẹ Rè̩ di mimọ fun wa pẹlu imọran awọn ojiṣẹ Ọlọrun. A yan awọn ojiṣẹ Ọlọrun gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo Ọlọrun. Nigba ti ọrọ kan ba ta koko ti o si rú ni loju, a le mọ ifẹ Ọlọrun nipa rè̩ nipa bibeere imọran lọdọ awọn ojiṣẹ Ọlọrun.

Gbigba imọran lati ọdọ awọn ojiṣẹ Ọlọrun ṣe deedee pẹlu Ọrọ Ọlọrun. Paulu sọ fun awọn eniyan mimọ pe, “Ẹ mā gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mā tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣiro, ki nwọn ki o le fi ayọ ṣe eyi li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin” (Heberu 13:17). Ọrọ iyanju kan lati inu Majẹmu Laelae sọ bayi pe, “Ẹ gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ, bẹli a o fi ẹsẹ nyin mulẹ; ẹ gbà awọn woli rẹ gbọ, bḝli ẹnyin o ṣe rere” (II Kronika 20:20). (Ka II Kọrinti 10:8; 13:10; Iṣe Awọn Apọsteli 15:1-6 pẹlu). Imọran awọn ojiṣẹ Ọlọrun duro lori ọrọ Ọlọrun; nigba pupọ ni o jẹ pe lati inu Ọrọ Ọlọrun gan an ni wọn yoo gbe ti mu imọran naa jade.

Ohun ti o ṣẹlẹ si Woli Ọlọrun yi yatọ si eyi. Alejo kan ti o fi ara rè̩ pe eniyan Ọlọrun ni o tọ ọ lọ. Dajudaju Woli Ọlọrun yi gba ohun ti alejo yi sọ lai wadi bi otitọ ni tabi bẹẹ kọ. A ko fi awọn eniyan Ọlọrun silẹ ninu okunkun ti ki yoo fi mọ iyatọ ti o wà laarin otitọ ati eke. Ẹmi Ọlọrun ati Bibeli ni awọn amọna meji ti o daju ti a fi fun awọn eniyan mimọ ninu aye lati mọ ohun ati ifẹ Oluwa wọn. Ọlọrun n fẹ ki a tẹtilelẹ si Ẹmi Ọlọrun ki a si fi Ọrọ Ọlọrun dan awọn ti n tọ wa wá wo, ki a ba le mọ ẹni ti o yẹ ki a gba tabi ti o yẹ lati takete si. Ohun ti o buru jai ni fun eniyan lati kọ ifẹ Ọlọrun ti o di mimọ fun un silẹ. O ni lati gbe gbogbo ifarahan ti o ba wa si ọna rè̩ ka ori Ọrọ Ọlọrun. Bi ọkan kan ba kọ ẹri ati itọni Ẹmi Ọlọrun silẹ, ti o si ṣe aigbọran si i, Ẹmi Ọlọrun yoo fi iru ọkàn bẹẹ silẹ, ọkàn naa yoo si di ohun ọdẹ lọwọ eṣu (Ka II Timoteu 2:26).

Iwa buburu ti awọn eniyan n hu lode oni nipa yiyi pada kuro ninu otitọ, ẹkọ ati itọni Ọlọrun lati fetisi ọrọ awọn eke woli yoo yọri si ibi. Ẹkọ eke yoo gbilẹ yoo si de gongo ni akoko ijọba Aṣodi-si-Kristi ni igba Ipọnju Nla. Aṣodi-si-Kristi yoo fi ara rè̩ pe Ọlọrun, awọn eniyan yoo si gba a gbọ. Bibeli wi pe, “Nitori ti nwọn ko gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gba wọn la . . . Ọlọrun ran ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gba eke gbọ: ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti ko gba otitọ gbọ, ṣugbọn ti nwọn ni inudidun ninu aiṣododo” (II Tẹssalonika 2:10-12). Nitori ti awọn eniyan yipada kuro ninu otitọ, Ọlọrun yoo mu ki wọn gba eke gbọ, ki idalẹbi wọn ki o le daju. Nitori ti wọn kọ lati tẹle Kristi, wọn yoo maa sin Eṣu (Ka Isaiah 8:6-8).

A kò mọ bi oye Woli yi ti jinlẹ to nipa pe ki a ni idapọ pẹlu awọn ẹlẹkọ eke, ṣugbọn Ọlọrun ti kilọ fun un pe ki o má ṣe duro tabi jẹun pẹlu ẹnikẹni ni ilu yi. Ikilọ ti Ọlọrun fun un yi to lati ṣe amọna rè̩ bi o ba feti sii, Ọlọrun ki i ṣe onroro tabi alaiṣododo. Idajọ otitọ Ọlọrun ni pipa ti kinniun pa eniyan Ọlọrun yi. Idapọ rè̩ pẹlu woli eke ati ẹlẹtan eniyan yi jẹ iṣelodi si ofin Ọlọrun to bẹẹ ti idajọ Ọlọrun fi wa si ori rè̩ nitori aigbọran rè̩.

Lati fi oju tinrin aanu Ọlọrun ki a si mọọmọ dẹṣẹ ni ẹṣẹ nla nì. Onipsalmu gbadura pe ki a pa oun mọ kuro ninu è̩ṣẹ buburu bẹẹ (Orin Dafidi 19:13). S̩ugbọn ni akoko yi ti ipadabọ Jesu kù si dẹdẹ o dabi ẹni pe ọpọ eniyan ni kò bikita fun idajọ Ọlọrun ti yoo de ba wọn nitori afojudi ti wọn n ṣe si ofin Ọlọrun. Ọpọlọpọ ọkàn ni o di ẹkọ eke mu ti wọn si n waasu rè̩ ni gbangba, nipa ṣiṣe bẹẹ, wọn bọ sinu ikẹkun Satani, nikẹhin wọn yoo si di ẹni idalẹbi. Ni akoko ìkẹhin yi, ti oriṣiriṣi ẹsin ngbilẹ --ti pupọ ninu wọn jẹ ọgbọn ori ati igbekalẹ ọmọ eniyan – o jẹ ohun danindanin fun Onigbagbọ lati tẹle apẹẹrẹ awọn eniyan mimọ Ọlọrun ti wọn fetisilẹ si iwaasu Paulu. Wọn pada lọ si ile wọn “nwọn si nwa inu iwe mimọ lojojumọ bi nkan wọnyi ri bḝ” (Iṣe Awọn Apọsteli 17:11). O yẹ ki ọkan wa balẹ pẹsẹ lori ọrọ Jesu pe ‘Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rè̩, yio mọ niti ẹkọ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi” (Johannu 7:17). Ọkan ti o ba fẹ mọ ifẹ Ọlọrun ati otitọ Ọlọrun yoo gbọ ohùn Ọlọrun, a ki yoo si tan an jẹ; ṣugbọn ẹni ti o ba n fetisi awọn alahesọ nitori pe wọn gbe orukọ Jesu lori, lai dan ẹmi wọnyi wo nipa Ẹmi ati Ọrọ Ọlọrun, yoo bọ sinu ikẹkun Satani lai si aniani.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eredi rè̩ ti Woli nì fi wa lati ke mọ pẹpẹ Jeroboamu?
  2. Ohun ibi meji wo ni a kilọ fun wa nipa rè̩ ninu ẹkọ wa yi?
  3. Eredi rè̩ ti eniyan Ọlọrun yi fi ṣe aigbọran si aṣẹ Ọlọrun?
  4. Eredi rè̩ ti idajọ Ọlọrun fi wa sori eniyan Ọlọrun yi?
  5. Bawo ni Onigbagbọ ṣe le mọ ẹni ti n ṣe ti Ọlọrun yatọ si ẹni ti ki i ṣe bẹẹ?
  6. Kin ni yoo ṣẹlẹ si ọkàn ti o kọ otitọ Ọlọrun silẹ lati gba eke gbọ?
  7. Eredi rè̩ ti awọn eniyan yoo fi gba eke gbọ dipo otitọ ni igba ikẹhin yi?
  8. Kin ni Bibeli sọ fun wa nipa idapọ pẹlu awọn woli eke?
1