I Awọn Ọba 14:1-20

Lesson 294 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọna kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rè̩ li ọna ikú” (Owe 14:12).
Cross References

I Didawọle Ẹtan

1. Jeroboamu rán iyawo rè̩ ti o paradà bi ẹlomiran si Ahijah lati beere nipa ọmọ rè̩ ti n ṣe aisan, I Awọn Ọba 14:1, 2

2. Iyawo Jeroboamu mu ọrẹ lọwọ lọ si ọdọ Woli naa, I Awọn Ọba 14:3, 4

3. Oluwa sọ fun Ahija pe iyawo Jeroboamu n bọ wa O si fi ọrọ ti yoo sọ si i lẹnu, I Awọn Ọba 14:5, 6

II Idajọ Ọlọrun lori Jeroboamu

1. Oluwa Ọlọrun fa ijọba Israẹli ya kuro ni ile Dafidi, O si fi Jeroboamu jọba, I Awọn Ọba 14:7, 8

2. Jeroboamu ko tẹle gbogbo aṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn o ṣe buburu ju gbogbo awọn aṣiwaju rè̩ lọ, I Awọn Ọba 14:9

3. Ọlọrun sọ idajọ ti yoo wa sori ile Jeroboamu, I Awọn Ọba 14:10, 11

4. Ọmọ naa ku, ṣugbọn Israẹli ṣọfọ rè̩, wọn si sinku rè̩, I Awọn Ọba 14:12-14, 17, 18

III Asọtẹlẹ nipa Ituka Israẹli

1. Awọn ọmọ Israẹli fara mọ ẹṣẹ Jeroboamu, nitori naa Ọlọrun sọtẹlẹ nipa ikolọ wọn kuro ni ilẹ wọn, I Awọ Ọba 14:15, 16

2. Jeroboamu, ẹni ti o mu Israẹli dẹṣẹ, sun pẹlu awọn baba rè̩, I Awọn Ọba 14:19, 20

Notes
ALAYÉ

“Yio si ṣe, bi iwọ o ba tẹtisilẹ si gbogbo eyiti mo paṣẹ fun ọ, ti iwọ o mā rin li ọna mi, ti iwọ o si mā ṣe eyiti o tọ loju mi, lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ, gẹgẹ bi Dafidi iranṣẹ mi ti ṣe; emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ fun Dafidi, emi o si fi Israẹli fun ọ” (I Awọn Ọba 11:38). Ọlọrun mu ọrọ yi ṣẹ fun Jeroboamu ni ti pe o jọba lori ẹya mẹwa ni Israẹli, ṣugbọn Jeroboamu kọ lati mu ipa ti rẹ ṣẹ ninu majẹmu yi. Nisinsinyi, ọmọ rè̩ Abijah, boya tii ṣe arole ọba ni Israẹli, ṣaisan; wọn kò si le ṣe ohunkohun lati mu un lara da. Pẹlu gbogbo laalaa wọn lati gba ẹmi ọmọ naa la, aisan naa n buru si i.

Ninu Idaamu

Nigba ti Jeroboamu sún kan ògiri, o pinnu lati ranṣẹ si Woli Ahijah arugbo ti o sọ fun un pe yoo jọba. È̩ru n ba Jeroboamu lati tikara rè̩ lọ sọdọ Woli Ahijah nitori ti ko rin ninu ilana Ọlọrun ti Woli yi sọ fun un, Jeroboamu ko si fẹ gba ibawi mimuná. Jeroboamu ro pe iyawo oun ni o tọ si lati lọ nitori ti ko si ẹlomiran ti o gbọdọ mọ nipa iṣẹ abẹlẹ yi. Bi o tilẹ jẹ pe ọmọ rè̩ n ku lọ, ti iya rè̩ si ni lati wa nile lati ṣe itọju ọmọ yi, sibẹ iṣẹ yi ṣe pataki to bẹẹ ti o fi ni lati yọọda fun un lati lọ sọdọ Woli yi kánkán. S̩ugbọn ko gbọdọ lọ gẹgẹ bi aya Jeroboamu – o ni lati pa ara rè̩ dà. Bi awọn eniyan Israẹli ba gbọ pe aya Jeroboamu n lọ sọdọ Woli Oluwa fun imọran, wọn yoo mọ pe awọn oriṣa Jeroboamu ko le ṣe iranwọ nigba iṣoro. Ati pẹlu pe, bi a ba mọ pe aya Jeroboamu ni i ṣe, o n bẹru pe idahun lati ọdọ Ọlọrun wa le ṣalai mu ayọ wa nitori ẹṣẹ rè̩.

Wo bi iwa omugọ eniyan ti pọ to! N jẹ Ọlọrun ti O mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ lọla, ti yoo si sọ boya ọmọ na yoo kú tabi yoo yè, kò ha ni le mọ ẹni ti o mu ibeere yi wa, bi oluwarẹ tilẹ pa ara rè̩ dà? Imọ Ọlọrun ga rekọja ọrọ eniyan nitori Oun ni olumọ ero inu ati ète ọkan. “Kò si si ẹda kan ti ko farahan niwaju rè̩, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rè̩ ẹniti awa ni iba lo” (Heberu 4:13).

Adura

Ọlọrun n gbọ O si n dahun adura, paapaa ju lọ bi adura naa ba ti inu ọkàn pipe ati ọkan diduro ṣinṣin wa si ọdọ Rè̩. O yẹ ki ọkan awọn ẹlẹṣẹ ti o ba tọ Ọlọrun wa balẹ pe bi wọn ba gbadura ironupiwada pe, “Ọlọrun, ṣānu fun mi ẹlẹṣẹ” pẹlu igbagbọ, wọn yoo ri idahun si adura wọn gbà. S̩ugbọn ṣa ni igba pupọ ni awọn alaiwa-bi-Ọlọrun n gbadura fun ohunkohun ti i ṣe ifẹkufẹ ara ati ohun ti kò le ṣe ọkàn wọn ni ire. Bibeli kọ akọsilẹ idahun si iru adura yi, ẹkọ ti a si ri kọ nibẹ kò ṣe e gbagbe. Bi adura wa kò ba jẹ adura ti a gba tọkàn tọkàn pẹlu ipinnu o san ki a má tilẹ gbadura rara.

Iṣẹ ti Jeroboamu ran si Woli yi jẹ adura lọna kan tabi lọna miran ṣugbọn o kún fun agabagebe. Oun ko wa iranlọwọ Ọlọrun lọnakọna – ohun ti o n fẹ ni lati mọ boya ọmọ rè̩ yoo ku tabi yoo yè. Ahijah ti sọ tẹlẹ pe Oluwa yoo kọ ile ti o daju fun Jeroboamu bi o ba le gbọran. Jeroboamu fi gbogbo ọkan rè̩ rọ mọ ileri yi bi o tilẹ jẹ pe aigbọran ti wọ ọ lẹwu. Nigba ti ikú doju kọ Hesekiah, o gbadura tọkantọkan bayi, pe, “Nisisiyi, OLUWA, mo bè̩ ọ, ranti bi mo ti rin niwaju rẹ li otitọ ati pẹlu aiya pipé, ati bi mo si ti ṣe eyiti o dara li oju rẹ” (Isaiah 38:3). S̩ugbọn Jeroboamu yẹra kò fẹ sọ nipa igbesi-aye rè̩ atẹhinwa, nitori igbesi-aye ẹṣẹ yoo mu idalẹbi wa sọkan rè̩. Dajudaju ko si ẹlẹṣẹ tabi ẹṣẹ ti oju Ọlọrun wa olododo ko ri.

Jeroboamu ko mọ pe Ọlọrun n lo aisan ọmọ rè̩ ti o fẹran yi lati mu ọkan rè̩ wa si ironupiwada. Bi oun ba ti ṣi ọkàn rè̩ paya pẹlu irobinujẹ, ti o si ti bẹ Woli naa lati ba a gbadura agbayọri ni akoko idaamu yi, dajudaju Ọlọrun yoo gbọ adura naa, yoo si da ọmọ naa si gẹgẹ bi o ti wo ọwọ Jeroboamu san nigba kan ri. S̩ugbọn gẹgẹ bi ọjọgbọn kan ti sọ, ọpọ eniyan a maa fẹ ki a sọ fun wọn ni ti ire ti n bọ wa ba wọn ju pe ki a sọ aṣiṣe wọn ati ohun ti o yẹ ki wọn ṣe fun wọn. Ibi ti o wa niwaju Jeroboamu i ba fo o dá bi o ba jẹ ti yàn lati rin gẹgẹ bi ilana Ọlọrun. Ọna meji ni o ṣi silẹ fun olukuluku eniyan lode oni: “Gbõro li ẹnu-ọna na, ati onibú li oju-ọna na ti o lọ si ibi iparun: ọpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibẹ wọle. Nitori bi hihá ti ni ẹnu-ọna na, ati toro li oju-ọna na, ti o lọ si ibi iye, diẹ li awọn ẹniti o nri i” (Matteu 7:13, 14). Ohun ti a ba yàn ni yoo sọ ibi ti a o gbe lo ayeraye. Eeṣe ti iwọ ki yoo fi gba oju-ọna tooro ti o lọ si iye ati ibugbe rere?

Were Ọgbọn Eniyan

Jeroboamu ni ọkan ati ilana ti ara rẹ lati mu ki ijọba rè̩ fẹsẹ mulẹ. Oun ko ni igbagbọ ninu Ọlọrun alaaye ti o fi awọn eniyan Israẹli si ikawọ rè̩; ṣugbọn ọgbọn ti ara ti i si pe ki o fi igbẹkẹle rè̩ sinu agbara ati ohun ti a le fi oju ri. Ọkan ninu awọn ohun ti Jeroboamu ṣe gẹrẹ ti o de ori oye ni pe o sọ awọn ilu S̩ekemu ati Penueli di ilu olodi. O ni igbẹkẹle ninu odi ti a fi ogiri mọ ju agbara Jehofa, nitori ti kò i ti mọ otitọ yi pe aabo wa daju bi a tilẹ wa ni oju ọgbagade pẹlu agbara Ọlọrun ju pe ki a fi gbogbo ogiri aye yi ṣe ibi aabo wa. Jeroboamu fẹ ki ijọba rè̩ fi idi mulẹ ṣinṣin, nitori eyi, o yipada kuro ninu ilana Ọlọrun ayeraye, o si fi igbẹkẹle rè̩ sinu awọn ohun ti n ṣegbe. Nisinsinyi ti Jeroboamu n fẹ iranlọwọ loju mejeeji, iranlọwọ ko ti ọdọ Ọlọrun wa.

Iru iwa were bayi ni awọn eniyan aye n hu titi di oni. Wọn n wa iranlọwọ ni gbogbo ọna ti wọn mọ lati ṣe aṣeyọri, lati ni alaafia, ilera ati ẹmi gigun; ṣugbọn wọn ko gba ọna taara. Ọrọ ti Ọlọrun sọ nipa eyi yanju kedere: “Ẹniti yio ba fẹ ìye, ti yio si ri ọjọ rere, ki o pa ahọn rè̩ mọ kuro ninu ibi, ati ete rè̩ kuro ni sisọ è̩tan: ki o yà kuro ninu ibi, ki o si mā ṣe rere; ki o mā wa alaafia, ki o si mā lepa rẹ. Nitori oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rè̩ si ṣi si ẹbẹ wọn” (I Peteru 3:10-12). Eyi ni ọna Agbelebu, ọna Onigbagbọ, ọna ti Jesu Kristi tọ -- ọna si Ogo. Jesu wa si aye ki eniyan le ni iye ani “ki nwọn le ni i lọpọlọpọ;” ṣugbọn eniyan melo ni o n fẹ rìn ni ipa ọna ti n fun ni ni ayọ tootọ ni aye yi ati iye anipẹkun, ẹwa ati adun ti a ko le fi ẹnu sọ!

Iṣẹ ti o Wuwo

Iyawo Jeroboamu pa ara rè̩ dà wa si ọdọ Woli Ahijah. Ko si eniyan kan ni gbogbo orilẹ-ede naa ti o da ayaba na mọ; Ahijah ki ba ti mọ pe iyawo Jeroboamu ni i ṣe nitori ti oju rè̩ ti n ṣe baibai fun ogbo, ṣugbọn Ọlọrun sọ fun un pe obinrin naa n bọ lọdọ rè̩, ki o tilẹ to de ẹnu-ọna ile Woli yi. Gẹrẹ ti Ahijah gbọ iro ẹsẹ rè̩, o wi pe “Wọle wá, ìwọ aya Jeroboamu, ẽṣe ti iwọ fi ṣe ara rè̩ bi ẹlomiran? nitori iṣẹ wuwo li a fi ran mi si ọ.”

Pupọ eniyan ti o ju ẹyọ kan lọ ni o ti tan eniyan ẹlẹgbẹ wọn jẹ nipa fifi ara han lode bi ẹlẹsin. Wọn a fi iṣe wọn pamọ nigba ti wọn ba wa laarin awọn eniyan to bẹẹ ti awọn eniyan fi n pe wọn ni Onigbagbọ. Ọpọlọpọ eniyan ni o jafafa ninu ẹkọ Bibeli ti ẹnu wọn si yọ gẹgẹ bi awọn ogbogi ninu ẹkọ Bibeli, ti ẹnu wọn si tun dun ninu ẹkọ nipa isìn Ọlọrun. Ogunlọgọ eniyan ninu aye ni o n fara han gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, sibẹ wọn ko i ti di ẹbi Ọlọrun nipa ibi titun ti o ṣe pataki nipa eyi ti Jesu kọ Nikodemu. (Wo Johannu 3:1-21). Oju Oluwa n wo ohun ti o wa labẹ iboju – Oluwa ki i wo oju bi ko ṣe ọkàn. Bi a ba ti fi Ẹjẹ Jesu wọn ọkàn kan, kò sewu; ṣugbọn ti Ẹjẹ naa kò ba si nibẹ, ohùn nì yoo fọ si wọn li eti wi pe: “Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rè̩” (Matteu 25:41).

Ahijah sọ fun iyawo Jeroboamu ohun ti yoo ṣẹlẹ gan an. Ọrọ rè̩ kò pọ, ṣugbọn o sọ opin ijọba Jeroboamu ati ẹbi rè̩. Ọmọ ti o n ṣaisan naa yoo ku gẹrẹ ti ẹsẹ iya rè̩ ba wọ ilu. Ọmọ kekere naa ni ọkàn rere si Oluwa Ọlọrun Israẹli; nitori naa, Ọlọrun mu ki gbogbo Israẹli ki o ṣọfọ rè̩, ki wọn si sin in tẹyẹtẹyẹ; ṣugbọn awọn iyoku ninu ile Jeroboamu ku ni ọjọ aipe, a ko si sin wọn. Gbogbo jamba yi de ba Jeroboamu nitori ẹṣẹ ati iṣọtẹ rè̩ si Ọlọrun. Asọ-tun-sọ otitọ yi kò le pọju ani pe: bi ọkàn kan, tabi idile, tabi orilẹ-ede ba mọọmọ taku sinu ẹṣẹ, ẹṣẹ naa ni yoo pa wọn run.

Imunidẹṣẹ?

Ọrọ Ọlọrun lati ẹnu Ahijah tayọ idajọ ti yoo de ba ile Jeroboamu nikan. Ẹṣẹ awọn Ọmọ Isaẹli wa si iranti Ọlọrun ni akoko yi kan naa. Jeroboamu ti yá ere wura, o si gbe e kalẹ ṣugbọn awọn Ọmọ Isaẹli fi tifẹtifẹ tẹle ọna ti o rọrun bi o tilẹ jẹ pe wọn mọ pe wọn n ru ofin Ọlọrun nipa ṣiṣe bẹẹ. Ahijah jẹ ọkan ninu awọn Woli wọnni ti o sọ nipa ituka awọn Ọmọ Israẹli nitori ẹṣẹ wọnyi. Alaafia ki yoo si fun awọn Ọmọ Israẹli mọ, ṣugbọn wọn yoo dabi ifoofo ti n ho loju omi – ti o n bi siwa, bi sẹhin ninu àiroju ati airaye. Lopin gbogbo rè̩, a o tu wọn ka kọja ipẹkun odo. Ẹnu Oluwa ni a ti sọ ọ; lẹhin awọn ọdun ti o tẹle e, a mu asọtẹlẹ naa ṣẹ ni kin-ni-kin-ni.

Boya awọn Ọmọ Israẹli dá Jeroboamu lẹbi nitori wahala ti o de ba wọn. Oun kọ ha ni o sún wọn dẹṣẹ? Eeṣe ti awọn paapaa fi tẹle e sinu ẹṣẹ? Ẹni ti o ba ṣẹ ni Ọlọrun n ka ẹbi si lọrun. Ọpọlọpọ awawi ni awọn eniyan n ṣe lojoojumọ nitori ẹṣẹ. Awọn miran n di ẹbi ẹṣẹ ti wọn ru ohun kan tabi omiran. Olukuluku ni yoo ru ẹbi ẹṣẹ ara rè̩. Ẹjẹ Jesu ti pese Etutu fun ẹṣẹ olukuluku, Ọlọrun si ti pese agbara lati gbe igbesi-aye ailẹṣẹ fun ọkan ti o ba jẹ fi tinutinu tẹle Ọlọrun. “Ẹniti o ba ṣẹgun li emi o fifun lati joko pẹlu mi lori ité̩ mi, bi emi pẹlu ti ṣẹgun, ti mo si joko pẹlu Baba mi lori ité̩ rè̩” (Ifihan 3:21).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Eredi rè̩ ti aisan ọmọ Jeroboamu fi ka a lara to bẹẹ?
  2. Eredi rè̩ ti aya Jeroboamu fi para da nigba ti o n lọ si ọdọ Woli Ọlọrun?
  3. N jẹ iparada rè̩ tan Woli naa jẹ?
  4. Tani dá Jeroboamu lohun, Woli ni tabi Oluwa?
  5. Awọn idajọ ti o ba ni lẹru wo ni o wa ninu esi naa?
  6. Eredi rè̩ ti idajọ wọnyi fi ni lati wa si ori Jeroboamu ati ile rè̩?
  7. Ere wo ni a fi fun Abijah fun ohun rere ti a ri ninu rè̩?
  8. Kin ni de ba awọn Ọmọ Israẹli nitori ẹṣẹ ti wọn n da si Oluwa?
  9. Bawo ni o ti pẹ to ki ọrọ ti a sọ lati ẹnu Woli ni to ṣẹ?
1